Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
AUGUST 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 28-31
“Jèhófà San Ìlú Abọ̀rìṣà Kan Lẹ́san”
it-2 1136 ¶4
Ìlú Tírè
Ìlú náà pa run. Nígbà tí Nebukadinésárì sàga ti ìlú Tírè, àwọn ọmọ ogun Nebukadinésárì ṣiṣẹ́ débi pé “orí wọ́n pá” gbogbo “èjìká wọn sì bó.” Torí pé Nebukadinésárì kò gba “owó ọ̀yà” kankan fún bí Ọlọ́run ṣe lò ó láti mú ìdájọ́ wá sórí ìlú Tírè, Jèhófà ṣèlérí fún un pé òun á fún un ní ilẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo ọlà rẹ̀. (Isk 29:17-20) Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Júù kan tó ń jẹ́ Josephus ṣe sọ, ó ní ọdún mẹ́tàlá ni Bábílónì fi sàga ti Tírè (Against Apion, I, 156 [21]), ó sì ná wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ akitiyan tí Nebukadinésárì ṣe tàbí bí ìsàgatì náà ṣe gbéṣẹ́ tó, síbẹ̀ ó dájú pé ẹ̀mí àti dúkìá tó lọ sí ìsàgatì náà pọ̀ gan-an.—Isk 26:7-12.
it-1 698 ¶5
Ilẹ̀ Íjíbítì, Ará Íjíbítì
Ìwé àwọn ará Bábílónì kan tí wọ́n kọ lọ́dún kẹtàdínlógójì ìṣàkóso Nebukadinésárì (ìyẹn 588 S.K.K) sọ̀rọ̀ nípa ìjà tí wọ́n bá Íjíbítì jà. A ò lè sọ bóyá èyí tí wọ́n fi ṣẹ́gun Íjíbítì ló ń tọ́ka sí àbí àwọn ogun tí wọ́n ti máa ń bá ara wọn jà. Lọ́nà kan ṣá, Nebukadinésárì gba ọlà Íjíbítì gẹ́gẹ́ bí owó ọ̀yà fún ìdájọ́ tó mú wá sórí ìlú Tírè, tó ń ta ko àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Isk 29:18-20; 30:10-12.
g86 11/8 27 ¶4-5
Ṣé Gbogbo Owó Orí Ló Yẹ Ká Máa San?
Ka lè mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo òhun tí Ẹlẹ́dàá wa pàápàá ṣe nígbà tó san ohun tó jẹ fún ìjọba kan tó bá a ṣiṣẹ́. Jèhófà bínú lọ́nà òdodo nígbà tó ní kí wọ́n pa ìlú Tírè àtijọ run. Ọlọ́run lo àwọn ọmọ ogun Bábílónì lábẹ́ ìdarí Nebukadinésárì láti pa wọ́n run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bábílónì ṣẹ́gun, síbẹ̀ ohun kékeré kọ́ ni ogun yẹn ná wọn. Jèhófà ronú pé ó yẹ kí òun san àsanfidípò fún wọn nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe fún un. Ó sọ nínú Ìsíkíẹ́lì 29:18, 19 pé: “Ọmọ ènìyàn, Nebukadirésárì fúnra rẹ̀, ọba Bábílónì, mú ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ńláǹlà kan lòdì sí Tírè . . . Ṣùgbọ́n ní ti owó ọ̀yà, kò sí ìkankan fún un àti fún ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ láti ọwọ́ Tírè, fún iṣẹ́ ìsìn tí ó ti ṣe lòdì sí i. “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò fi ilẹ̀ Íjíbítì fún Nebukadirésárì ọba Bábílónì, òun yóò sì kó ọlà rẹ̀ lọ, yóò sì kó ohun ìfiṣèjẹ ńlá láti ara rẹ̀, yóò sì piyẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀; èyí yóò sì di owó ọ̀yà fún ẹgbẹ́ ológun rẹ̀.’ ”
Ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ọba tó jẹ́ onírera, onímọtara-ẹni-nìkan àti abọ̀rìṣà ni Nebukadinésárì. Bíbélì sì tún sọ bí àwọn ọmọ ogun Bábílónì ṣe máa ń hùwà ìkà sí àwọn tí wọ́n bá kó nígbèkùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò fọwọ́ sí irú àwọn ìwà yìí, síbẹ̀ ó mọ̀ pé gbèsè téèyàn bá jẹ, ó ti di dandan kó san-án, torí náà ó san àsanfidípò tó yẹ fún wọn.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 604 ¶4-5
Ìjẹ́pípé
Ẹni tó kọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ àti ọba Tírè. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ nínú Jòhánù 8:44 àti bí Jẹ́nẹ́sísì orí 3 ṣe sọ, ẹ̀dá ẹ̀mí kan ló pilẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ẹ̀dá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ọba Tírè,” ni ọ̀rọ̀ arò tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 28:12-19 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ohun tó sọ ṣàpèjúwe ẹ̀dá ẹ̀mí tó kọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí ìgbéraga “ọba Tírè,” bó ṣe fẹ́ sọ ara rẹ̀ di ‘ọlọ́run,’ bí wọ́n ṣe pè é ní “kérúbù,” ó tún mẹ́nu ba “Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run.” Gbogbo àpèjúwe yìí bá ohun tí Bíbélì sọ mu nípa Sátánì Èṣù. Torí òun náà gbé ara rẹ̀ ga, ó lo ejò ní ọgbà Édénì, òun sì tún ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.”—1Ti 3:6; Jẹ 3:1-5, 14, 15; Iṣi 12:9; 2Kọ 4:4.
Ọba Tírè tí Bíbélì kò dárúkọ rẹ̀, tó ń gbé ní ìlú kan tí òun fúnra rẹ̀ sọ pé ó jẹ́ ìlú tí ó “pé ní ẹwà fífanimọ́ra,” tó sọ̀ pé òun “kún fún ọgbọ́n, tí ó sì pé ní ẹwà,” tó jẹ́ “aláìní-àléébù [Heb., ta·mimʹ]” ní àwọn ọ̀nà rẹ láti ìgbà ìṣẹ̀dá, títí a fi rí àìṣòdodo nínú rẹ̀. (Isk 27:3; 28:12, 15) Ó jọ pé àwọn alákòóso ìlú Tírè lápapọ̀ ni ọ̀rọ̀ ewì yìí ń bá wí, kì í ṣe ọba kan ní pàtó. (Fi wé àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọba Bábílónì” tí Bíbélì kò sọ orúkọ rẹ̀” ní Ais 14:4-20.) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ pé ohun tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni bí ìlú Tírè ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn láyé ìgbà tí Ọba Dáfídì àti Sólómọ́nì fi ń ṣàkóso. Nígbà yẹn, Ìlu Tírè tiẹ̀ tún ṣètìlẹ́yìn nígbà táwọn èèyàn Ọlọ́run ń kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà lórí Òkè Móráyà. Torí náà, níbẹ̀rẹ̀ kò sí àléébù kankan lára ìlú Tírè, ní ti pé ó ní àjọse tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà. (1Ọb 5:1-18; 9:10, 11, 14; 2Kr 2:3-16) Àmọ́, nígbà tó yá, àwọn ọba tó jẹ ní ìlú Tírè kò tẹ̀ lé ipa ọ̀nà “aláìní-àléébù” yẹn mọ́, ìyẹn ló mú kí àwọn wòlíì Ọlọ́run náà Jóẹ́lì, Ámósì àti Ìsíkíẹ́lì kéde ìdájọ́ lé wọn lórí. (Joe 3:4-8; Amo 1:9, 10) Yàtọ̀ sí pé ìwà “Ọba Tírè” àti Olórí Ọ̀tá Ọlọ́run jọra, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún jẹ́ ká rí i pé tí Bíbélì bá sọ pé èèyàn kan tàbí ohun kan “pé” tàbí pé ó jẹ́ “aláìní-àléébù,” kò túmọ̀ sí pé ó pé pérépéré láìkù síbì kan.
Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Sí Wọn?
NÓFÌ àti Nóò lorúkọ tí wọ́n fi ń pe Mémúfísì àti Tíbésì tí wọ́n ti fìgbà kan jẹ́ olú ìlú lílókìkí gan-an fún ilẹ̀ Íjíbítì. Nófì (Mémúfísì) wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́tàlélógún ní ìhà gúúsù ìlú Cairo, ní apá ìlà oòrùn Odò Náílì. Àmọ́ nígbà tó yá, Mémúfísì pàdánù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú ìlú Íjíbítì. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ṣáájú Sànmánì Tiwa, Íjíbítì ti ní olú ìlú tuntun, ìyẹn Nóò (Tíbésì), tó wà ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlómítà ní ìhà gúúsù Mémúfísì. Tẹ́ńpìlì Karnak tí wọ́n sọ pé òun ni ilé títóbi jù lọ tí wọ́n tíì fi òpó kọ́ wà lára ọ̀pọ̀ tẹ́ńpìlì tí wọ́n wó lulẹ̀ ní Tíbésì. Wọ́n ya Tíbésì àti tẹ́ńpìlì Karnak rẹ̀ sí mímọ́ fún ìjọsìn Ámọ́nì tó jẹ́ olórí ọlọ́run àwọn ará Íjíbítì.
Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa Mémúfísì àti Tíbésì? A kéde ìdájọ́ búburú lórí Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì àtàwọn ọlọ́run rẹ̀, àgàgà olú ọlọ́run, ìyẹn “Ámọ́nì láti Nóò.” (Jeremáyà 46:25, 26) A ó sì “ké” ogunlọ́gọ̀ àwọn olùjọsìn tó ń wọ́ lọ síbẹ̀ “kúrò.” (Ìsíkíẹ́lì 30:14, 15) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Gbogbo ohun tó ṣẹ́ kù fún ìjọsìn Ámọ́nì ni àwókù tẹ́ńpìlì. Ìlú Luxor òde oní wà ní apá kan lára ibi tí Tíbésì ìgbàanì wà, àwọn abúlé kéékèèké sì wà láàárín àwọn àwókù rẹ̀.
Ní ti Mémúfísì ní tirẹ̀, kò sí ohun tó ṣẹ́ kù síbẹ̀ ju àwọn ibojì rẹ̀. Louis Golding, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ pé: “Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni àwọn ará Arébíà tó ṣẹ́gun ilẹ̀ Íjíbítì fi ń lo àwọn àwókù Mémúfísì tó pọ̀ bí nǹkan míì gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ti ń kó àwọn òkúta tí wọ́n fi ń kọ́ [Cairo] tó jẹ́ olú ìlú wọn ní apá kejì odò náà. Àpapọ̀ òkúta odò Náílì àti iṣẹ́ táwọn kọ́lékọ́lé ará Arébíà ṣe dára gan-an débi pé kò sí òkúta kan tó yọ gọnbu ju ilẹ̀ dúdú náà lọ láwọn ilé tí wọ́n kọ́ sí ọ̀pọ̀ kìlómítà láàárín ìlú ìgbàanì náà.” Ní ti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, Mémúfísì di ‘ohun ìyàlẹ́nu lásán . . . láìní olùgbé kankan.’—Jeremáyà 46:19.
AUGUST 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 32-34
“Iṣẹ́ Ńlá Ni Iṣẹ́ Olùṣọ́”
it-2 1172 ¶2
Olùṣọ́
Ohun tó ṣàpẹẹrẹ. Jèhófà yan àwọn wòlíì rẹ̀ láti ṣe olùṣọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì (Jer 6:17), àwọn wòlíì náà sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa olùṣọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tí wọ́n bá ń jíṣẹ́. (Ais 21:6, 8; 52:8; 62:6; Ho 9:8) Ojúṣe àwọn wòlíì tó dà bí olùṣọ́ yìí ni láti máa kìlọ̀ fún àwọn ẹni ibi nípa ìparun tó ń bọ̀, bí wọ́n bá sì kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa dá wọn lẹ́bi. Àmọ́ tí wọ́n bá kìlọ̀ tí àwọn èèyàn náà sì kọ̀ láti ṣègbọràn, orí ara wọn ni wọ́n máa fi ru ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn. (Isk 3:17-21; 33:1-9) Bí wòlíì kan bá wá jẹ́ aláìṣòótọ́, tí kò ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́, ńṣe ló dà bí afọ́jú olùṣọ́ tàbí ajá tí kò lè fọhùn.—Ais 56:10.
w88 1/1 28 ¶13
Ẹ Máa Bá a Nìṣó Ní Wíwàásù Ìjọba Náà
Yíyẹra fún Ẹbi-Ẹ̀jẹ̀
13 Ẹrù iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà olùyàsímímọ́ láti kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń bò ni a lè fi wé èyí tí Ìsíkíẹ́lì ṣe nígbà tirẹ̀. A yàn án gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì. Iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un ni pé kó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọn kò bá yí pa dà nínú ìwà búburú wọn, wọ́n máa jìyà, wọ́n á sì kú. Bí òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sọ́ bá kúnà láti kìlọ̀ fún wọn, àwọn èèyàn búburú á ṣì jìyà ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí ẹ̀ṣọ́ náà nítorí ìwà àìnání rẹ̀. Nínú èyí Jèhófà fi ẹ̀mí ìrònú rẹ̀ hàn lórí ọ̀rọ̀ ìdájọ́ pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí padà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó ní tòótọ́. Ẹ yí padà, ẹ yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú yín, nítorí kí ni ẹ ó ṣe kú, ilé Ísírẹ́lì?”—Ìsíkíẹ́lì 33:1-11.
Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú
KÍ NÌDÍ TÍ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ WA FI JẸ́ KÁNJÚKÁNJÚ?
3 Tó o bá ronú pé iṣẹ́ ìwàásù wa lè mú kí àwọn èèyàn rí ìgbàlà tàbí kí wọ́n pa run bí a kò bá wàásù fún wọn, wàá rí i pé wíwàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn jẹ́ kánjúkánjú. (Róòmù 10:13, 14) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nígbà tí mo bá sì sọ fún ẹni burúkú pé: ‘Dájúdájú ìwọ yóò kú,’ tí ó sì yí padà ní tòótọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo, . . . òun yóò máa wà láàyè nìṣó. Òun kì yóò kú. Kò sí ìkankan nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ tí a óò rántí lòdì sí i.” (Ìsík. 33:14-16) Bíbélì sọ fún àwọn tó ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run pé: “Ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 Tím. 4:16; Ìsík. 3:17-21.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Maa Ṣísẹ̀rìn ní Ìyára kan naa Pẹlu Kẹkẹ-Ẹṣin Òkè Ọ̀run Ti Jehofa
Idagunla Kò Dá A Lọ́wọ́kọ́
16 Esekiẹli tun fi apẹẹrẹ rere lelẹ nipa jijẹ onigbọran ati laiyọnda ara rẹ̀ lati di ẹni ti a dálọ́wọ́kọ́ nipasẹ idagunla tabi ipẹgan. Lọna ti o farajọra, nipa wiwa ni iyara kan naa pẹlu èdè mimọgaara ti ńgbèrú, awa ti wà ni imuratan lati tẹle ọna ti Olùgùn Kẹkẹ-ẹṣin ọlọba naa ba gbà. Nipa bayii a ti mura wa silẹ lati dahunpada si awọn àṣẹ rẹ̀, a fun wa lokun lati jẹ ẹni ti a kò dáláwọ́kọ́ nipasẹ idagunla tabi ìpẹ̀gàn awọn wọnni ti a nsọ ihin-iṣẹ idajọ Jehofa fun. Gẹgẹ bi o ti ri pẹlu Esekiẹli, Ọlọrun ti kilọ fun wa ṣaaju pe awọn eniyan kan yoo ṣe atako lọna mimuna, ni jijẹ olorikunkun ati ọlọkan lile. Awọn miiran ki yoo gbọ́ nitori pe wọn kò fẹ lati fetisilẹ si Jehofa. (Esekiẹli 3:7-9) Sibẹ awọn miiran yoo jẹ agabagebe, gẹgẹ bi Esekiẹli 33:31, 32 ti wi pe: “Wọn sì tọ̀ ọ́ wa, bi eniyan ti nwa, wọn sì jokoo niwaju rẹ bi eniyan mi, wọn sì gbọ ọ̀rọ̀ rẹ, ṣugbọn wọn kì yoo ṣe wọn: nitori ẹnu wọn ni wọn fi nfi ifẹ pupọ hàn, ṣugbọn ọkan wọn tẹle ojukokoro wọn. Si kiyesi i, iwọ jẹ orin ti o dùn pupọ fun wọn, ti ẹnikan ti o ni ohùn daradara, ti o sì lè fun ohun-eelo orin daradara: nitori wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ṣugbọn wọn kò ṣe wọn.”
17 Ki ni yoo jẹ abajade? Ẹsẹ 33 fikun un pe: “Ati nigba ti eyi ba ṣẹ, (kiyesi i, yoo dé,) nigba naa ni wọn yoo mọ̀ pe wolii kan ti wà laaarin wọn.” Awọn ọ̀rọ̀ wọnni fihan pe Esekiẹli kò juwọsilẹ nitori aisi idahunpada. Agunla awọn miiran kò mú un jọ̀gọ̀nù. Yala awọn eniyan fetisilẹ tabi bẹẹkọ, oun ṣegbọran si Ọlọrun o sì mu iṣẹ ti a fun un ṣẹ.
Ẹ Máa Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Tẹrí Ba Fáwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Onífẹ̀ẹ́
3 Àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 40:10, 11 jẹ́ ká rí i pé tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn rẹ̀. (Sáàmù 23:1-6) Nígbà tí Jésù wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, òun náà fìfẹ́ bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò àtàwọn èèyàn lápapọ̀. (Mátíù 11:28-30; Máàkù 6:34) Jèhófà àti Jésù kórìíra ìwà àìláàánú àwọn olùṣọ́ àgùntàn, ìyẹn àwọn aṣáájú Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń hùwà lọ́nà tó tini lójú nípa pípa àgbò wọn tì, tí wọ́n sì máa ń yàn wọ́n jẹ. (Ìsíkíẹ́lì 34:2-10; Mátíù 23:3, 4, 15) Jèhófà ṣèlérí pé: “Èmi yóò gba àwọn àgùntàn mi là, wọn kì yóò di ohun ìpiyẹ́ mọ́; ṣe ni èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ láàárín àgùntàn àti àgùntàn. Ṣe ni èmi yóò gbé olùṣọ́ àgùntàn kan dìde sórí wọn, òun yóò sì máa bọ́ wọn, àní ìránṣẹ́ mi Dáfídì. Òun fúnra rẹ̀ yóò máa bọ́ wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì di olùṣọ́ àgùntàn wọn.” (Ìsíkíẹ́lì 34:22, 23) Ní àkókò òpin yìí, Jésù Kristi, tó jẹ́ Dáfídì Títóbi Jù, ni “olùṣọ́ àgùntàn” tí Jèhófà ti yàn sórí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn àtàwọn “àgùntàn mìíràn.”—Jòhánù 10:16.
AUGUST 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 35-38
“Gọ́ọ̀gù Ti Ilẹ̀ Mágọ́gù Máa Tó Pa Run”
Bí Ayé Yìí Ṣe Máa Dópin
8 Lẹ́yìn tí ìsìn èké bá ti pa run, àwọn orílẹ̀-èdè máa rí i pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣì ń “gbé ní ààbò” àti “láìsí ògiri.” (Ìsík. 38:11, 14) Kí ló wá máa ṣẹlẹ̀ sí àwùjọ èèyàn tó dà bíi pé wọn kò ní ààbò kankan tí wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà yìí? Ó jọ pé ńṣe ni “ọ̀pọ̀ ènìyàn” máa fi gbogbo agbára wọn kọ lù wọ́n. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pè ní ìkọlù tàbí ìgbéjàkò láti ọ̀dọ̀ “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:2, 15, 16.) Ojú wo ló yẹ ká fi wo ìkọlù yẹn?
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ nípa ìkọlù tó ń bọ̀ wá bá àwa èèyàn Ọlọ́run yìí, ìyẹn ò mú ká máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, dípò tá a ó fi máa ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa rí ìgbàlà, ohun tó jẹ wá lógún jù lọ ni bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́ tó sì máa dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre. Kódà, nínú Bíbélì, ó ju ọgọ́ta [60] ìgbà lọ tí Jèhófà sọ pé: “Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsík. 6:7) Nípa bẹ́ẹ̀, à ń fi ìháragàgà retí ìmúṣẹ apá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì yìí, ọkàn wa sì balẹ̀ pé “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” (2 Pét. 2:9) Àmọ́ ní báyìí, a fẹ́ máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti máa ṣe àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti pa ìwà títọ́ wa sí Jèhófà mọ́ láìka àdánwò tá a lè dojú kọ sí. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe? A gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tí à ń kọ́, ká sì máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyè àìnípẹ̀kun tí à ń retí á túbọ̀ fìdí múlẹ̀ lọ́kàn wa bí “ìdákọ̀ró.”—Héb. 6:19; Sm. 25:21.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Máa Fi Ìwà Rere Kristẹni Kọ́ Ara Rẹ Àtàwọn Ẹlòmíràn
12 Àpọ́sítélì náà tẹnu mọ́ ìdí pàtàkì tó fi yẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ ìlànà ìwà rere inú Bíbélì, kó o sì máa fi sílò. Ìwà búburú àwọn Júù mú ẹ̀gàn bá Jèhófà, ìyẹn ni Bíbélì fi sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí ń yangàn nínú òfin, ǹjẹ́ ìwọ nípasẹ̀ ríré tí o ń ré Òfin kọjá ha ń tàbùkù sí Ọlọ́run bí? Nítorí ‘orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.’ ” (Róòmù 2:23, 24) Bákan náà ló rí lónìí. Bá a bá tàpá sí ìwà rere Kristẹni, a ó tàbùkù sí Ẹni tó gbé ìlànà ìwà rere náà kalẹ̀. Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, bá a bá rọ̀ mọ́ ìlànà Ọlọ́run, yóò mú iyì àti ọlá wá bá a. (Aísáyà 52:5; Ìsíkíẹ́lì 36:20) Ríronú lórí èyí lè jẹ́ kí o túbọ̀ dúró ṣinṣin bó o bá dojú kọ àdánwò tàbí àwọn ipò tó lè mú kó rọrùn gan-an láti fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìwà rere Kristẹni. Nǹkan mìíràn tún wà tí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù kọ́ wa. Yàtọ̀ sí pé ìwọ alára mọ̀ pé ìwà rẹ lè nípa lórí orúkọ Ọlọ́run, bó o ṣe ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, jẹ́ kí wọ́n rí i pé bí wọ́n ṣe ń fi ìlànà ìwà rere tí wọ́n ń kọ́ sílò yóò nípa lórí orúkọ Jèhófà. Kì í wulẹ̀ ṣe kìkì pé ìwà rere Kristẹni ń mú ìtẹ́lọ́rùn àti ìlera wá nìkan ni. Ó tún ń nípa lórí orúkọ Ẹni tó gbé ìlànà ìwà rere náà kalẹ̀, tó sì fẹ́ ká máa tẹ̀ lé e.—Sáàmù 74:10; Jákọ́bù 3:17.
w88 9/15 24 ¶11
“Wọn Yóò Níláti Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”
11 Lẹ́yìn tí àwọn àṣẹ́kù kan pa dà sí Júdà, ilẹ̀ tí ó ti dahoro náà yí pa dà sí “ọgbà Édénì” eléso kan (Ka Ìsíkíẹ́lì 36:33-36.) Ní ìfiwéra, láti 1919 Jèhófà ti yí dúkìá ìní àṣẹ́kù ẹni àmì òróró tí ó dahoro nígbà kan rí pa dà sí Párádísè eléso kan tí à ń ṣàjọpín nísinsìnyí pẹ̀lú “ogunlọ́gọ̀ ńlá èèyàn.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Párádísè tẹ̀mí yìí kún fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kàn ṣiṣẹ́ láti pa á mọ́ tónítóní.—Ìsíkíẹ́lì 36:37, 38.
AUGUST 28–SEPTEMBER 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 39-41
“Bí Ìran Tẹ́ńpìlì Tí Ìsíkíẹ́lì Rí Ṣe Kàn Ọ́”
“Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
16 Láti rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ kí a padà lọ sínú ìran náà fúnra rẹ̀. Ìsíkíẹ́lì kọ̀wé pé: “Nínú àwọn ìran ti Ọlọ́run, ó mú mi wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó gbé mi kalẹ̀ sórí òkè ńlá kan tí ó ga gan-an, lórí èyí tí ohun kan wà tí ó ní ìrísí ìlú ńlá níhà gúúsù.” (Ìsíkíẹ́lì 40:2) Orí “òkè ńlá kan tí ó ga gan-an,” tí a ti rí ìran yìí, rán wa létí ohun tí ó wà nínú Míkà 4:1, tí ó sọ pé: “Yóò . . . ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀.” Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ? Míkà 4:5 fi hàn pé èyí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè ṣì ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké. Ní tòótọ́, ní àkókò tiwa ni, ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ni a gbé ìjọsìn mímọ́ gaara ga, tí a dá a padà sí àyè tí ó yẹ ẹ́ nínú ìgbésí ayé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kejì
40:3–43:17— Kí ni wíwọ̀n tí wọ́n wọn tẹ́ńpìlì náà túmọ̀ sí? Wíwọ̀n tí wọ́n wọn tẹ́ńpìlì yìí jẹ́ àmì pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nípa ìjọsìn mímọ́ yóò nímùúṣẹ dájúdájú.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kejì
40:14, 16, 22, 26. Àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri tó wà láwọn ibi àbáwọlé tẹ́ńpìlì náà fi hàn pé kìkì àwọn tí ìwà wọn bá dára nìkan ló lè wọbẹ̀. (Sáàmù 92:12) Èyí kọ́ wa pé tá a bá ń hùwà tó dára nìkan ni Jèhófà á fi tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yóò Ní Láti Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”
“Jèhófà sọ pé: “Èmi kì yóò sì jẹ́ kí a sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ mọ́.” Nígbà tí àwọn èèyàn bá ń sọ pé Ọlọ́run kì í ṣe ìdájọ́ òdodo, ṣe ni wọ́n ń sọ orúkọ rẹ̀ di aláìmọ́. Lọ́nà wo? Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “orúkọ” sábà máa ń tọ́ka sí irú ẹni tí èèyàn jẹ́. Ìwé ìwádìí kan sọ pé orúkọ Ọlọ́run dúró fún “ohun tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ohun tó ṣí payá nípa ara rẹ̀; ó sì tún dúró fún ògo rẹ̀, àti iyì rẹ̀.” Orúkọ Jèhófà wé mọ́ irú ẹni tó jẹ́. Wàyí o, irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìwà àìṣe ìdájọ́ òdodo? Ó kórìíra rẹ̀ gan-an ni! Àánú àwọn tí wọ́n bá hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí sì máa ń ṣe é gan-an. (Ẹ́kísódù 22:22-24) Torí náà tí àwọn èèyàn bá ń fi ẹ̀sùn àwọn ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kórìíra kan Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n ń bà á lórúkọ jẹ́. Wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ “hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ” rẹ̀.—Sáàmù 74:10.
w89 8/15 14 ¶20
Bí Ọlọ́run Ṣe Mú Párádísè Pa Dà Bọ̀ Sípò
20 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ohun èlò ogun tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi sílẹ̀ sẹ́yìn? Ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ohun èlò náà máa pọ̀ gan-an, torí ó sọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé àkókò tí a máa lò láti kó àwọn ohun èlò náà jọ máa gùn gan-an. (Ìsíkíẹ́lì 39:8-10) Àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já máa fi àwọn ohun èlò náà rọ àwọn irinṣẹ́ tó máa wúlò fún wa láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan.—Aísáyà 2:2-4.