Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
KÒ SÍ àní-àní pé bí ìsọkúsọ ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà ṣe máa rí lójú àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tó sàsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa kàgbákò! Ó sọ pé àwọn ọ̀tá yóò finá sun tẹ́ńpìlì wọn ẹlẹ́wà tí wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn látohun tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún [300] sẹ́yìn. Ó ní àwọn ọ̀tá máa sọ Jerúsálẹ́mù àti Júdà dahoro, wọ́n á kó àwọn tó ń gbébẹ̀ nígbèkùn. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àtàwọn ọ̀rọ̀ ìdájọ́ mìíràn ló wà nínú ìwé Jeremáyà tí í ṣe ìwé tó tóbi ṣìkejì nínú Bíbélì. Ìwé náà tún ròyìn ohun tí Jeremáyà fojú winá rẹ̀ ní gbogbo ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] tó fi jẹ́ wòlíì tó sì ṣiṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́. Kì í ṣe bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra wọn ni Jeremáyà ṣe kọ wọ́n sínú ìwé náà. Ńṣe ló kọ wọ́n níbàámu pẹ̀lú bí kókó tó wà níbẹ̀ ṣe tẹ̀ léra wọn.
Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tó wà nínú ìwé Jeremáyà? Ìdí kan ni pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé náà tó nímùúṣẹ jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà pé ó jẹ́ Ẹni tó máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Aísáyà 55:10, 11) Ìdí mìíràn ni pé, láyé ìsinsìnyí, àwọn kan wà tó ń ṣe irú iṣẹ́ tí wòlíì Jeremáyà ṣe, ìhà táwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ sì kọ sí ọ̀rọ̀ tó ń sọ jọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Yàtọ̀ síyẹn, ìtàn bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ rẹ̀ kedere, ó sì yẹ kí èyí ní ipa tó lágbára lórí wa.—Hébérù 4:12.
“OHUN BÚBURÚ MÉJÌ NI ÀWỌN ÈNÌYÀN MI ṢE”
Ọdún kẹtàlá ìjọba Jòsáyà, ọba Júdà, ni Ọlọ́run yan Jeremáyà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Ìyẹn jẹ́ ní ogójì ọdún ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù, èyí tó wáyé lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Jeremáyà 1:1, 2) Àwọn ohun tí Jeremáyà kéde, pàápàá àwọn tó kéde láàárín ọdún méjìdínlógún tó gbẹ̀yìn ìjọba Jòsáyà, jẹ́ láti fi tú àṣírí ìwà ibi táwọn ará Júdà hù àti láti kéde ìdájọ́ Jèhófà lórí ìlú náà. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò sì sọ Jerúsálẹ́mù di ìtòjọpelemọ òkúta, . . . èmi yóò sì sọ ìlú ńlá Júdà di ahoro, láìní olùgbé.” (Jeremáyà 9:11) Kí nìdí tí Jèhófà fi lóun máa ṣe bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Nítorí ohun búburú méjì ni àwọn ènìyàn mi ṣe.”—Jeremáyà 2:13.
Jeremáyà tún kéde pé àwọn tó bá ronú pìwà dà lára àṣẹ́kù wọn tó wà nígbèkùn yóò padà sí ilẹ̀ wọn. (Jeremáyà 3:14-18; 12:14, 15; 16:14-21) Àmọ́, inú àwọn èèyàn náà ò dùn sí Jeremáyà pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ tó ń jẹ́. Ẹni “tí ó tún jẹ́ kọmíṣọ́nnà tí ó ń mú ipò iwájú nínú ilé Jèhófà” lu Jeremáyà, ó sì fi í sínú àbà mọ́jú ọjọ́ kejì.—Jeremáyà 20:1-3.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:11, 12—Kí nìdí tí ẹsẹ yìí fi fi wíwà tí Jèhófà wà lójúfò nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀ wé “èéhù igi álímọ́ńdì”? Igi álímọ́ńdì wà lára àwọn igi tó máa ń kọ́kọ́ yọ ìtànná nígbà ìrúwé. Ńṣe ló dà bí ẹni pé Jèhófà “ń dìde lójoojúmọ́ ní kùtùkùtù [tó] sì ń rán [àwọn wòlíì rẹ̀]” jáde láti lọ kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ nípa ìdájọ́ rẹ̀, tó sì tún ń “wà lójúfò” títí àwọn ìdájọ́ náà á fi ṣẹ.—Jeremáyà 7:25.
2:10, 11—Kí ló mú kí nǹkan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ṣe dà bí ohun tí kò ṣẹlẹ̀ rí? Báwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Kítímù àtàwọn tó wà lápá ìlà oòrùn ilẹ̀ Kídárì bá tiẹ̀ mú òrìṣà wá láti ilẹ̀ ibòmíràn tí wọ́n sì fi kún òrìṣà tí wọ́n ń bọ, wọn ò ní jẹ́ tìtorí òrìṣà tí wọ́n mú wá láti ilẹ̀ ibòmíràn yìí pa tiwọn tì láé. Àmọ́ ní tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ńṣe ni wọ́n kọ Jèhófà sílẹ̀, wọ́n wá ń fi ògo fún òrìṣà lásánlàsàn dípò Ọlọ́run.
3:11-22; 11:10-12, 17—Níwọ̀n bí àwọn ọ̀tá ti ṣẹ́gun Samáríà tí í ṣe olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kí nìdí tí Jeremáyà fi fi ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà kún àwọn tó kéde ìdájọ́ lé lórí? Ìdí ni pé ìparun tó wá sórí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni jẹ́ ìdájọ́ Jèhófà lórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀, kì í wulẹ̀ ṣe lórí Júdà nìkan. (Ìsíkíẹ́lì 9:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn táwọn ọ̀tá ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà, wọ́n ò gbàgbé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù nítorí pé àwọn wòlíì Ọlọ́run ṣì máa ń sọ̀rọ̀ wọn nínú iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́.
4:3, 4—Kí ni àṣẹ yìí túmọ̀ sí? Àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ ní láti yí ọkàn wọn padà, kí wọ́n mú kí ọkàn wọn rọ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kó wà ní mímọ́. Wọ́n ní láti gé “adọ̀dọ́” ọkàn wọn kúrò, ìyẹn ni pé kí wọ́n mú èrò tí kò tọ́ kúrò lọ́kàn wọn. (Jeremáyà 9:25, 26; Ìṣe 7:51) Èyí gba pé kí wọ́n ṣe àyípadà nínú ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n ṣíwọ́ híhu ìwà búburú kí wọ́n sì máa ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí.
4:10; 15:18—Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà tan àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀dàlẹ̀? Nígbà ayé Jeremáyà, àwọn wòlíì kan wà tí wọ́n máa ń sọ “àsọtẹ́lẹ̀ èké.” (Jeremáyà 5:31; 20:6; 23:16, 17, 25-28, 32) Jèhófà ò dá àwọn wòlíì wọ̀nyí dúró kí wọ́n má kéde àwọn ọ̀rọ̀ tó lè ṣi èèyàn lọ́nà.
16:16—Nígbà tí Jèhófà sọ pé òun “yóò ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ apẹja” àti “ọ̀pọ̀ ọdẹ,” kí ló túmọ̀ sí? Ó ṣeé ṣe kí èyí tọ́ka sí rírán àwọn ọmọ ogun ọ̀tá pé kí wọ́n lọ wá àwọn Júù aláìṣòótọ́ tí ìdájọ́ Jèhófà máa dé sórí wọn kàn. Tá a bá sì fojú ohun tí Jeremáyà 16:15 sọ wò ó, ọ̀rọ̀ náà tún lè tọ́ka sí wíwá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ronú pìwà dà jáde.
20:7—Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ‘lo okun rẹ̀’ lórí Jeremáyà, tó sì tàn án? Bí àwọn èèyàn tí Jeremáyà ń kéde ìdájọ́ Jèhófà fún ò ṣe fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí i, ó ṣeé ṣe kó ronú pé òun ò lókun láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. Àmọ́, Jèhófà lo okun rẹ̀ láti fi mú kí Jeremáyà mú irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn, ó fún Jeremáyà lókun kó lè máa bá iṣẹ́ náà lọ. Báyìí ni Jèhófà ṣe tan wòlíì Jeremáyà nípa mímú kó ṣe ohun tó ronú pé òun ò ní lè ṣe.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:8. Jèhófà máa ń lo onírúurú ọ̀nà láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ inúnibíni. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ńṣe ló máa lo adájọ́ tí kì í ṣe ojúsàájú, tàbí kó fi aláṣẹ tó ń gba tẹlòmíràn rò rọ́pò èyí tó jẹ́ òǹrorò tàbí kó fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lókun tí wọ́n á fi lè fara da inúnibíni.—1 Kọ́ríńtì 10:13.
2:13, 18. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ ṣe ohun méjì tó burú jáì. Wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, ẹni tó jẹ́ pé òun ni orísun ìbùkún, ìtọ́sọ́nà, àti ààbò. Wọ́n wá lọ gbẹ́ ìkùdu tiwọn fúnra wọn, tó túmọ̀ sí pé wọ́n lọ bá àwọn ọmọ ogún Íjíbítì àti Ásíríà pé kí wọ́n gba àwọn. Ní àkókò tiwa yìí, tẹ́nì kan bá fi Ọlọ́run tòótọ́ sílẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀kọ́ àti èrò ọmọ aráyé àti nítorí ìṣèlú ayé, ńṣe lonítọ̀hún fi “àwọn ìkùdu fífọ́” rọ́pò “orísun omi ààyè.”
6:16. Jèhófà gba àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ti ya ọlọ̀tẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò ara wọn kí wọ́n sì padà sí “àwọn òpópónà” àwọn baba ńlá wọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa ṣàyẹ̀wò ara wa látìgbàdégbà láti mọ̀ bóyá ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́ ká máa rìn la ti ń rìn?
7:1-15. Àwọn Júù gbẹ́kẹ̀ lé tẹ́ńpìlì, wọ́n ń wò ó bíi pé òun ló máa dáàbò bo àwọn, àmọ́ ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Torí náà, nípa ìgbàgbọ́ ló yẹ ká máa rìn kì í ṣe nípa ohun tá a lè fojú rí.—2 Kọ́ríńtì 5:7.
15:16, 17. A lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí Jeremáyà ti ṣe. A lè ṣe èyí nípa ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó mọ́yán lórí, èyí tí yóò máa fún wa láyọ̀, nípa lílọ sóde ẹ̀rí láti gbé orúkọ Jèhófà ga, àti nípa yíyẹra fún ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́.
17:1, 2. Ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn Júdà dá mú kí Jèhófà kọ ẹbọ wọn. Táwa náà bá ń hu ìwà tí kò mọ́, asán ni ẹbọ ìyìn wa yóò já sí.
17:5-8. Ìgbà téèyàn tàbí àjọ tí ẹ̀dá èèyàn gbé kálẹ̀ bá ń ṣe ohun tó wà níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀ nìkan la lè fọkàn tán an. Àmọ́, tó bá dọ̀rọ̀ ẹni tá a lè gbẹ́kẹ̀ lé fún ìgbàlà, àlàáfíà àti ojúlówó ààbò, ẹnì kan ṣoṣo tó bọ́gbọ́n mu pé ká gbẹ́kẹ̀ lé ni Jèhófà.—Sáàmù 146:3.
20:8-11. Kò yẹ ká jẹ́ kí ẹ̀tanú, àtakò àti inúnibíni táwọn èèyàn ń ṣe sí wa mú wa dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.—Jákọ́bù 5:10, 11.
“MÚ ỌRÙN RẸ WÁ SÁBẸ́ ÀJÀGÀ ỌBA BÁBÍLÓNÌ”
Jeremáyà kéde ìdájọ́ sórí àwọn ọba mẹ́rin tó jẹ gbẹ̀yìn ní Júdà àti sórí àwọn wòlíì èké, àti sórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ò wúlò fún ohunkóhun àtàwọn àlùfáà tó ń hùwà ìbàjẹ́. Jèhófà fi àwọn olóòótọ́ èèyàn tó ṣẹ́ kù wé ọ̀pọ̀tọ́ dáradára, ó ní: “Èmi yóò sì gbé ojú mi lé wọn lọ́nà rere.” (Jeremáyà 24:5, 6) Àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́ta nínú Jeremáyà orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣe àkópọ̀ ìdájọ́ táwọn orí tó tẹ̀ lé e ṣàlàyé rẹ̀ ní kíkún.
Àwọn àlùfáà àtàwọn wòlíì kan gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jeremáyà. Iṣẹ́ tí Jeremáyà jẹ́ fún wọn ni pé wọ́n máa sìnrú fún ọba Bábílónì, ó ní kò sí bí wọ́n ṣe lè yẹ̀ ẹ́. Jeremáyà sọ fún Sedekáyà Ọba pé: “Mú ọrùn rẹ wá sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.” (Jeremáyà 27:12) Ṣùgbọ́n “Ẹni tí ó tú Ísírẹ́lì ká ni yóò fúnra rẹ̀ kó [Ísírẹ́lì] jọpọ̀.” (Jeremáyà 31:10) Ọlọ́run ṣe ìlérí kan fáwọn ọmọ Rékábù nítorí ìdí pàtàkì kan. Ọba pàṣẹ fáwọn kan pé kí wọ́n fi Jeremáyà “sínú ìhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.” (Jeremáyà 37:21) Àwọn ọ̀tá pa Jerúsálẹ́mù run, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo àwọn tó ń gbé nílùú náà lọ sígbèkùn tán. Lára àwọn díẹ̀ tí wọn ò kó lọ ni Jeremáyà àti Bárúkù akọ̀wé rẹ̀. Jeremáyà kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n má ṣe lọ sí Íjíbítì, àmọ́ nítorí ìbẹ̀rù, wọ́n lọ. Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè wà ní orí kẹrìndínláàádọ́ta sí kọkànléláàádọ́ta.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
22:30—Ǹjẹ́ àṣẹ yìí fagi lé ẹ̀tọ́ tí Jésù Kristi ní láti gorí ìtẹ́ Dáfídì? (Mátíù 1:1, 11) Rárá o, kò fagi lé e. Àwọn àtọmọdọ́mọ Jèhóákínì lòfin náà dè. Kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí yóò ‘jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì ní Júdà.’ Ní ti Jésù, ọ̀run ni ìtẹ́ rẹ̀ wà, ibẹ̀ ni yóò sì ti máa ṣàkóso, kì í ṣe láti ilẹ̀ Júdà.
23:33—Kí ni “ẹrù ìnira Jèhófà” tí ibí yìí ń sọ? Nígbà tí Jeremáyà kéde ìdájọ́ alágbára nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, ẹrù ìnira ló jẹ́ fáwọn èèyàn olóríkunkun tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Àwọn pẹ̀lú sì jẹ́ ẹrù ìnira fún Jèhófà débi pé Jèhófà kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Bákan náà, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa ìparun àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ ẹrù ìnira fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, àwọn tí wọn ò sì kọbi ara sí ọ̀rọ̀ yìí náà jẹ́ ẹrù ìnira ńlá fún Ọlọ́run.
31:33—Báwo ni òfin Ọlọ́run ṣe lè di ohun tí wọ́n kọ sí ọkàn? A lè sọ pé wọ́n kọ òfin Ọlọ́run sọ́kàn ẹnì kan tó bá jẹ́ pé ńṣe lẹni náà nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run gan-an débi pé ìfẹ́ láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ń jó lala lọ́kàn rẹ̀ bí iná.
32:10-15—Kí ni ìwé àdéhùn méjì tí Jeremáyà ṣe nítorí ọjà kan ṣoṣo tó rà wà fún? Wọ́n ò fi èdìdì di ọ̀kan nínú àwọn ìwé àdéhùn méjì náà nítorí kí wọ́n lè máa yẹ̀ ẹ́ wò tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Wọ́n sì fi èdìdì di ìkejì kí wọ́n bàa lè máa fi jẹ́rìí sí tàkọ́kọ́ nígbà tó bá gba pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Jeremáyà tẹ̀ lé ìgbésẹ̀ tó bófin mu tó sì bọ́gbọ́n mu bó tilẹ̀ jẹ́ pé onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ tó tún jẹ́ ìbátan rẹ̀ ló bá dòwò pọ̀. Àpẹẹrẹ lèyí jẹ́ fún wa lónìí.
33:23, 24—Ìdílé wo ni “ìdílé méjì” tí ẹsẹ yìí mẹ́nu kàn? Ọ̀kan ni ìdílé ọlọ́ba tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba, ìkejì sì ni ìdílé àlùfáà tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Áárónì. Báwọn ọ̀tá ṣe pa Jerúsálẹ́mù run tí wọ́n sì dáná sun tẹ́ńpìlì Jèhófà mú kó dà bíi pé Jèhófà ti kọ ìdílé méjèèjì, pé Jèhófà ò ní ní ìjọba kankan mọ́ tí yóò ṣàkóso lé ayé lórí, ó sì tún mú kó dà bíi pé Jèhófà ò ní jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ padà máa ṣe ìjọsìn rẹ̀ mọ́.
46:22—Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fi ohùn Íjíbítì wé ti ejò? Ó lè jẹ́ nítorí bí orílẹ̀-èdè náà yóò ṣe rọra máa ké nítorí àjálù tó dé bá a bí ìgbà tí ejò rọra ń dún nígbà tó bá ń fi ìbẹ̀rù sá lọ, ó sì lè jẹ́ nítorí ẹ̀tẹ́ tó bá orílẹ̀-èdè náà. Àfiwé yìí tún fi hàn pé asán lórí asán ni fífi táwọn ọba Fáráò nílẹ̀ Íjíbítì máa ń fi ère ejò mímọ́ sára ìbòrí wọn. Ìgbàgbọ́ àwọn ọba wọ̀nyí ni pé òrìṣà tí wọ́n ń pè ní Uatchit tí í ṣe abo-òrìṣà ejò máa dáàbò bo àwọn.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
21:8, 9; 38:19. Àní nígbà tó kù ṣíún káwọn ọ̀tá pa Jerúsálẹ́mù run, Jèhófà ṣì pàpà jẹ́ káwọn èèyàn ìlú náà tí wọn ò lẹ́mìí ìrònúpìwàdà mọ ìgbésẹ̀ tí wọ́n lè gbé láti rí ìgbàlà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú tọ́ sí wọn. Kò sí àní-àní pé “àánú [Ọlọ́run] pọ̀.”—2 Sámúẹ́lì 24:14; Sáàmù 119:156.
31:34. Ìtùnú ńlá gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé tí Jèhófà bá ti dárí ji èèyàn, ó ti darí jì í náà nìyẹn, kì í tún rántí ẹ̀ṣẹ̀ onítọ̀hún láti fìyà jẹ ẹ́ lọ́jọ́ iwájú!
38:7-13; 39:15-18. Jèhófà kì í gbàgbé iṣẹ́ ìsìn wa tá à ń fi tọkàntọkàn ṣe. Lára iṣẹ́ ìsìn náà ni ‘ṣíṣe ìránṣẹ́ fáwọn ẹni mímọ́.’—Hébérù 6:10.
45:4, 5. Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn nílẹ̀ Júdà ayé ọjọ́un kì í ṣe àkókò láti máa lépa “àwọn ohun ńláńlá,” bákan náà, kì í ṣe àkókò nìyí fún àwa tá à ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí láti máa lépa “àwọn ohun ńláńlá,” irú bí ọrọ̀, òkìkí, tàbí àwọn nǹkan ìní tara.—2 Tímótì 3:1; 1 Jòhánù 2:17.
WỌ́N DÁNÁ SUN JERÚSÁLÉMÙ
Nígbà tó fi máa di ọdún kọkànlá ìjọba Sedekáyà, ìyẹn lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti fi àwọn ológún rẹ̀ yí Jerúsálẹ́mù ká fún ọdún kan ààbọ̀. Lọ́jọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún kọkàndínlógún ìjọba Nebukadinésárì, Nebusarádánì tí í ṣe olórí ẹ̀ṣọ́, “wá sí” itòsí Jerúsálẹ́mù. (2 Àwọn Ọba 25:8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibi tí Nebusarádánì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí lẹ́yìn odi ìlú Jerúsálẹ́mù ló ti wo gbogbo bí nǹkan ṣe rí tó sì ti gbèrò nǹkan tó máa ṣe. Lọ́jọ́ kẹta, ìyẹn lọ́jọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebusarádánì “wá sí” ìlú Jerúsálẹ́mù. Ó sì dáná sun ìlú ńlá náà.—Jeremáyà 52:7, 12.
Jeremáyà ṣe àkọsílẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa bí àwọn ọ̀tá ṣe ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù. Àwọn ohun tó wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ yìí mú kó kédàárò. Ìwé Bíbélì tá à ń pè ní Ìdárò ni ìdárò Jeremáyà yìí wà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìdájọ́ Jèhófà lórí Jerúsálẹ́mù wà lára àwọn ohun tí Jeremáyà kéde rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Báwo ni Jèhófà ṣe ‘lo okun rẹ̀’ lórí Jeremáyà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
“Bí ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì fi ojú rere wo àwọn ìgbèkùn Júdà.”—Jeremáyà 24:5