Ẹ̀KỌ́ 47
Ṣé O Ti Múra Tán Láti Ṣèrìbọmi?
Ọ̀pọ̀ nǹkan lo ti kọ́ nípa Jèhófà látìgbà tó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kó o ti máa ṣe àwọn àyípadà kan kó o lè máa fi àwọn nǹkan tó ò ń kọ́ sílò. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan ṣì lè mú kó nira fún ẹ láti pinnu pé wàá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi. Nínú ẹ̀kọ́ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tó máa ń jẹ́ kó nira fáwọn kan láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, àá sì sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè borí àwọn nǹkan náà.
1. Báwo ló ṣe yẹ kí ìmọ̀ rẹ jinlẹ̀ tó kó o tó ṣèrìbọmi?
Kó o tó ṣèrìbọmi, ó yẹ kó o ní “ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ mọ bí wàá ṣe fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè táwọn èèyàn bá ń bi ẹ́. Ó ṣe tán, àwọn tó ti ṣèrìbọmi fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Kólósè 1:9, 10) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o lóye àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ nínú Bíbélì. Àwọn alàgbà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá o ti lóye àwọn ẹ̀kọ́ yìí.
2. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe kó o tó ṣèrìbọmi?
Kó o tó lè ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ ‘ronú pìwà dà, kó o sì yí pa dà.’ (Ka Ìṣe 3:19.) Èyí túmọ̀ sí pé o ní láti banú jẹ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó o ti dá, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó dárí jì ẹ́. O tún gbọ́dọ̀ kórìíra ohunkóhun tínú Ọlọ́run ò dùn sí, kó o sì pinnu pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni wàá máa ṣe ní gbogbo ìgbà. Bákan náà, wàá máa lọ sípàdé, wàá sì di akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi, kó o lè máa wàásù pẹ̀lú ìjọ.
3. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o bẹ̀rù láti ṣèrìbọmi?
Àwọn kan máa ń bẹ̀rù pé àwọn ò ní lè mú ìlérí tí wọ́n ṣe fún Jèhófà ṣẹ. Òótọ́ kan ni pé o lè ṣàṣìṣe, ó ṣe tán àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn náà ṣàṣìṣe. Rántí pé Jèhófà ò retí pé àwọn tó ń jọ́sìn òun ò ní ṣàṣìṣe rárá. (Ka Sáàmù 103:13, 14.) Inú Jèhófà máa dùn tó o bá ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kódà, Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé kò sí ohunkóhun tó “lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ [òun].”—Ka Róòmù 8:38, 39.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ mọ Jèhófà, kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó ń dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi.
4. Gbìyànjú láti túbọ̀ mọ Jèhófà
Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o mọ̀ nípa Jèhófà kó o tó lè ṣèrìbọmi? Ó yẹ kó o mọ Jèhófà débi tí wàá fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wàá sì fẹ́ máa ṣe àwọn nǹkan táá máa múnú ẹ̀ dùn. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, kí ló ran àwọn kan lọ́wọ́ kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti ṣèrìbọmi?
Ka Róòmù 12:2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé o gbà pé òótọ́ làwọn nǹkan tí Bíbélì fi kọ́ni, ṣé o sì gbà pé òótọ́ lohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ni?
Kí lo lè ṣe tí kò bá dá ẹ lójú?
5. Bó o ṣe lè borí àwọn ìṣòro tó lè mú kó nira fún ẹ láti ṣèrìbọmi
Gbogbo wa la máa kojú ìṣòro tá a bá ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, tá a sì ṣèrìbọmi. Kó o lè rí àpẹẹrẹ kan, wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, ìṣòro wo ni Narangerel ní láti borí kó lè sin Jèhófà?
Báwo ni ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́ láti borí ìṣòro náà?
Ka Òwe 29:25 àti 2 Tímótì 1:7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ló máa jẹ́ ká nígboyà ká lè borí àwọn ìṣòro wa?
6. Jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́
Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe ohun tó fẹ́. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, kí nìdí tẹ́rù fi ń ba akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn láti ṣèrìbọmi?
Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
Ka Àìsáyà 41:10, 13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèlérí pé wàá máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ló mú kó dá ẹ lójú pé wàá lè mú ìlérí náà ṣẹ?
7. Ronú lórí bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó
Tó o bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó, wàá túbọ̀ mọyì àwọn nǹkan tó ti ṣe fún ẹ, á sì wù ẹ́ gan-an pé kó o sìn ín títí láé. Ka Sáàmù 40:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Èwo lo fẹ́ràn jù nínú gbogbo àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ?
Wòlíì Jeremáyà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò sì fojú kéré àǹfààní tó ní láti jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ fún mi àti ìdùnnú ọkàn mi, nítorí wọ́n ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà Ọlọ́run.” (Jeremáyà 15:16) Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi jẹ́ àǹfààní tí ò lẹ́gbẹ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Ṣé wàá fẹ́ láti ṣèrìbọmi, kó o sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Ṣé ohun kan wà tó ń dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi?
Àwọn nǹkan wo lo rò pé ó yẹ kó o ṣe kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti ṣèrìbọmi?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò rò pé màá lè ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ kí n máa ṣe fún Jèhófà tí mo bá ṣèrìbọmi.”
Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi.
Kí lo rí kọ́?
Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o mọ̀ kó o tó ṣèrìbọmi?
Àwọn àtúnṣe wo ló yẹ kó o ṣe kó o tó lè ṣèrìbọmi?
Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o bẹ̀rù láti ṣèrìbọmi?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó yẹ kó mú kó o pinnu láti ṣèrìbọmi.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí wàá ṣe borí àwọn ìṣòro pàtó kan tó lè mú kó nira fún ẹ láti ṣèrìbọmi.
Wo fídíò yìí kó o lè rí bí ọkùnrin kan ṣe borí àwọn ìṣòro tó mú kó nira fún un láti ṣèrìbọmi.
Ataa ò kọ́kọ́ fẹ́ ṣèrìbọmi. Wo fídíò yìí kó o lè rí ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu pàtàkì yẹn nígbèésí ayé rẹ̀.