Àwọn Ènìyàn “Tí Ó Ní Ìmọ̀lára Bí Tiwa”
ỌBA ni, wòlíì sì ni, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ bàbá onífẹ̀ẹ́. Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dàgbà di aláìníláárí àti agbéraga. Nínú ìpinnu láti gbapò lọ́wọ́ bàbá rẹ̀, ọmọ yìí gbé ogun abẹ́lé dìde, ó pète láti pa bàbá rẹ̀. Ṣùgbọ́n nínú ogun tí ó tẹ̀ lé e, ọmọ náà ni a pa. Nígbà tí bàbá náà gbọ́ nípa ikú ọmọ rẹ̀, ó dá lọ sórí ìyẹ̀wù òrùlé, ó sì sunkún pé: “Ọmọkùnrin mi Ábúsálómù, ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi Ábúsálómù! Áà ì bá ṣe pé mo ti kú, èmi fúnra mi, dípò ìwọ, Ábúsálómù ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi!” (2 Sámúẹ́lì 18:33) Ọba Dáfídì ni bàbá náà. Gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì Jèhófà yòókù, òun jẹ́ “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa.”—Jákọ́bù 5:17.
Ní àkókò tí a kọ Bíbélì, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún Jèhófà wá láti inú onírúurú ipò ìgbésí ayé, a sì rí wọn nínú gbogbo apá ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Bí tiwa, wọ́n ní ìṣòro, wọ́n sì jìyà lọ́wọ́ àìpé. Àwọn wo ni díẹ̀ lára àwọn wòlíì wọ̀nyí, báwo sì ni ìmọ̀lára wọn ṣe dà bí tiwa?
Mósè Fi Ìwà Ìjọra-Ẹni-Lójú Sílẹ̀, Ó Di Oníwà Tútù
Mósè jẹ́ wòlíì tí ó lókìkí ní ìgbà tí ó ṣáájú sànmánì ẹ̀sìn Kristẹni. Ṣùgbọ́n, ní ẹni 40 ọdún pàápàá, kò ṣe tán láti sìn gẹ́gẹ́ bi agbọ̀rọ̀sọ fún Jèhófà. Èé ṣe? Nígbà tí Fáráò ti Íjíbítì ń ni àwọn arákùnrin rẹ̀ lára, a tọ́ Mósè dàgbà nínú ilé Fáráò, ó sì “jẹ́ alágbára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀.” Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Ó rò pé àwọn arákùnrin òun yóò mòye pé Ọlọ́run ń fún wọn ní ìgbàlà láti ọwọ́ òun.” Nítorí tí ó jọ ara rẹ̀ lójú, ó fi ìbínú gbèjà ẹrú kan tí ó jẹ́ Hébérù, ó sì pa ará Íjíbítì kan.—Ìṣe 7:22-25; Ẹ́kísódù 2:11-14.
Wàyí o, ó di dandan fún Mósè láti sá lọ, ó sì lo ẹ̀wádún mẹ́rin tí ó tẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ní ilẹ̀ Mídíánì jíjìnnà réré. (Ẹ́kísódù 2:15) Ní òpin àkókò yẹn, Jèhófà yan Mósè, tí ó ti di ẹni 80 ọdún nísinsìnyí, gẹ́gẹ́ bí wòlíì. Ṣùgbọ́n Mósè kò jọ ara rẹ̀ lójú mọ́. O nímọ̀lára pé òun kò tóótun tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi béèrè lọ́wọ́ Jèhófà ìdí tí ó fi ní láti yan òun gẹ́gẹ́ bí wòlíì, ó lo àwọn gbólóhùn bí, “Ta ni èmi tí èmi yóò fi lọ bá Fáráò?” àti, “Kí ni èmi yóò sọ?” (Ẹ́kísódù 3:11, 13) Pẹ̀lú ìdánilójú àti ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fún un, Mósè kẹ́sẹ járí gidigidi nínú iṣẹ́ tí a yàn fún un.
Bí Mósè, ìwọ ha ti yọ̀ǹda kí ìjọra-ẹni-lójú sún ọ ṣe tàbí sọ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu bí? Bí ó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i. Àbí o ti nímọ̀lára pé o kò tóótun láti gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ Kristẹni kan pàtó bí? Kàkà tí ìwọ yóò fi kọ̀ láti ṣe é, tẹ́wọ́ gba ìrànwọ́ tí Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ ń fúnni. Ẹni náà tí ó ran Mósè lọ́wọ́ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú.
Èlíjà Ní Ìmọ̀lára Bí Tiwa ní Àkókò Ìbáwí
“Èlíjà jẹ́ ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa, síbẹ̀síbẹ̀ nínú àdúrà, ó gbàdúrà pé kí òjò má ṣe rọ̀; òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà.” (Jákọ́bù 5:17) Àdúrà Èlíjà wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà láti bá orílẹ̀-èdè kan tí ó ti kẹ̀yìn sí I wí. Síbẹ̀síbẹ̀, Èlíjà mọ̀ pé ọ̀dá tí òun ń gbàdúrà fún yóò mú ìjìyà bá ẹ̀dá ènìyàn. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ó wọ́pọ̀ jù lọ ní Ísírẹ́lì; ìrì àti òjò sì ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè àwọn ènìyàn náà. Ọ̀dá tí kò dáwọ́ dúró yóò mú ìpọ́njú lílégbákan wá. Ewéko yóò gbẹ; ohun ọ̀gbìn yóò sì kú. Àwọn ẹran agbéléjẹ̀ tí a ń lò fún iṣẹ́, tí a sì ń pa jẹ yóò kú, ebi yóò sì lu àwọn ìdílé kan pa. Ta ni yóò jìyà jù? Àwọn mẹ̀kúnnù ni. Lẹ́yìn náà, opó kan sọ fún Èlíjà pé òun kò ní ju ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun àti òróró kékeré lọ. Ó dá a lójú gidigidi pé ebi ni yóò lu òun pẹ̀lú ọmọ òun pa. (1 Àwọn Ọba 17:12) Kí Èlíjà tó lè gbàdúrà bí ó ti ṣe, ó ti ní láti ní ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ pé Jèhófà yóò tọ́jú àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀—ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì—tí wọn kò tí ì pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ náà ti fi hàn, a kò já Èlíjà kulẹ̀ rárá.—1 Àwọn Ọba 17:13-16; 18:3-5.
Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, nígbà tí Jèhófà fi hàn pé òun kò ní pẹ́ rọ̀jò, àdúrà Èlíjà tí ó gbóná janjan, tí ó gbà léraléra nígbà tí ó “ń bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, [tí] ó sì ń gbé ojú sáàárín eékún rẹ̀,” fi hàn pé ó fẹ́ lójú méjèèjì pé kí ọ̀dá náà wá sópin. (1 Àwọn Ọba 18:42) Léraléra, ó rọ ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, gòkè lọ. Wo ìhà òkun,” bóyá ó lè rí àmì pé Jèhófà ti gbọ́ àdúrà òun. (1 Àwọn Ọba 18:43) Ẹ wo bí inú rẹ̀ yóò ti dùn tó nígbà tí “ọ̀run . . . rọ òjò, [tí] ilẹ̀ sì mú èso rẹ̀ jáde wá,” ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀!—Jákọ́bù 5:18.
Bí o bá jẹ́ òbí tàbí alàgbà nínú ìjọ Kristẹni, o lè ní láti bá ìmọ̀lára rẹ jíjinlẹ̀ jìjàkadì nígbà tí o bá ń tọ́ni sọ́nà. Ṣùgbọ́n, a ní láti mú kí irú ìmọ̀lára ẹ̀dá ènìyàn bẹ́ẹ̀ wà déédéé pẹ̀lú ìdánilójú tí a ní pé nígbà mìíràn ìbáwí máa ń pọndandan àti pé nígbà tí a bá fi ìfẹ́ báni wí, “a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Ìyọrísí ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin Jèhófà máa ń ṣeni láǹfààní nígbà gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí Èlíjà, a ń gbàdúrà látọkàn wá pé kí a lè tẹ̀ lé wọn.
Jeremáyà Fi Ìgboyà Hán Láìfi Ìrẹ̀wẹ̀sì Pè
Nínú gbogbo àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé Jeremáyà ni ó kọ ohun tí ó pọ̀ jù lọ nípa ìmọ̀lára tí ó ní. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan, ó lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí a yàn fún un. (Jeremáyà 1:6) Síbẹ̀síbẹ̀, ó fi ìgboyà ńláǹlà polongo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kìkì láti wọnú àtakò gbígbóná janjan láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀—láti orí ọba dórí mẹ̀kúnnù. Nígbà mìíràn, àtakò yẹn mú kí inú bí i, kí ó sì sunkún. (Jeremáyà 9:3; 18:20-23; 20:7-18) Ní àwọn àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n kọ lù ú, wọ́n lù ú, a dè é mọ́ egìran, a fi í sẹ́wọ̀n, a fi ikú halẹ̀ mọ́ ọn, a sì fi í sílẹ̀ láti kú nínú ẹrẹ̀ nísàlẹ̀ ìkùdu tí kò ní omi. Nígbà mìíràn, ìhìn iṣẹ́ Jèhófà pàápàá pa Jeremáyà lára, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀nyí ti fi hàn, ó wí pé: “Ìwọ ìfun mi, ìfun mi! Mo wà nínú ìrora mímúná nínú ògiri ọkàn-àyà mi.”—Jeremáyà 4:19.
Síbẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ó wí pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ . . . di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi.” (Jeremáyà 15:16) Lọ́wọ́ kan náà, ìjákulẹ̀ mú kí ó kígbe sí Jèhófà pé: “Ó dájú hán-ún pé, ìwọ dà bí ohun ẹ̀tàn sí mi, bí omi tí ó jẹ́ aláìṣeégbẹ́kẹ̀lé,” bí ṣẹ́lẹ̀rú tí kì í pẹ́ gbẹ. (Jeremáyà 15:18) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà mọ onírúurú ìmọ̀lára tí ó ní, ó sì ń bá a nìṣó láti tì í lẹ́yìn, kí ó lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí.—Jeremáyà 15:20; tún wo 20:7-9.
Bí Jeremáyà, ìwọ ha ń dojú kọ ìjákulẹ̀ tàbí àtakò ní ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ bí? Yíjú sí Jèhófà. Máa bá a nìṣó láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, Jèhófà yóò sì san èrè ìsapá rẹ fún ọ pẹ̀lú.
Jésù Ní Ìmọ̀lára Bí Tiwa
Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ni wòlíì títóbilọ́lá jù lọ tí ó tíì wà rí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni pípé, kò bo ìmọ̀lára rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a kà nípa ìmọ̀lára rẹ̀ inú lọ́hùn-ún, tí ó ti gbọ́dọ̀ hàn ní ojú rẹ̀ àti nínú ìhùwàpadà rẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn. “Àánú ṣe” Jésù ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó sì lo gbólóhùn kan náà láti ṣàpèjúwe ìṣarasíhùwà àwọn ẹ̀dá inú àkàwé rẹ̀.—Máàkù 1:41; 6:34; Lúùkù 10:33.
Ó gbọ́dọ̀ ti gbé ohùn rẹ̀ sókè nígbà tí ó lé àwọn òǹtàjà àti ẹran kúrò nínú tẹ́ńpìlì pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà pé: “Ẹ kó nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín!” (Jòhánù 2:14-16) Ìmọ̀ràn Pétérù pé, “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa,” fa èsì lílágbára náà pé, “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì!”—Mátíù 16:22, 23.
Jésù ní ìfẹ́ni àrà ọ̀tọ̀ fún àwọn kan pàtó tí wọ́n sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí. A ṣàpèjúwe àpọ́sítélì Jòhánù gẹ́gẹ́ bí “ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ti máa ń nífẹ̀ẹ́.” (Jòhánù 21:7, 20) A sì kà pé: “Wàyí o, Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.”—Jòhánù 11:5.
A lè pa ìmọ̀lára Jésù pẹ̀lú lára. Nígbà tí ikú Lásárù ń bà á nínú jẹ́, “Jésù bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” (Jòhánù 11:32-36) Bí ó ti ń ṣí ìrora ọkàn tí ó ní fún dídà tí Júdásì Ísíkáríótù dà á payá, Jésù ṣàyọlò ọ̀rọ̀ arò kan láti inú Sáàmù pé: “Ẹni tí ó ti ń fi oúnjẹ mi ṣe oúnjẹ jẹ, ti gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.”—Jòhánù 13:18; Sáàmù 41:9.
Àní nígbà tí ara ń ro Jésù gógó lórí òpó igi pàápàá, ó fi bí ìmọ̀lára òun ti jinlẹ̀ tó hàn. Ó fi jẹ̀lẹ́ńkẹ́ fi ìyá rẹ̀ síkàáwọ́ “ọmọ ẹ̀yìn tí ó nífẹ̀ẹ́.” (Jòhánù 19:26, 27) Nígbà tí ó rí ẹ̀rí ìrònúpìwàdà tí ọ̀kan nínú àwọn aṣebi tí a kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ fi hàn, Jésù fi ìyọ́nú wí pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) A lè nímọ̀lára bí ìrora rẹ̀ ti pọ̀ tó nínú igbe rẹ̀ pé: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?” (Mátíù 27:46) Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nígbà tí ó ń kú lọ sì fi ìfẹ́ àtọkànwá àti ìgbẹ́kẹ̀lé hàn: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.”—Lúùkù 23:46.
Ẹ wo irú ìdánilójú tí gbogbo èyí fún wa! “Nítorí àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni [Jésù] tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.”—Hébérù 4:15.
Ìfọkàntán Tí Jèhófà Ní
Jèhófà kò fìgbà kan rí kábàámọ̀ nípa àwọn tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ. Ó mọ ìdúróṣinṣin tí wọ́n ní sí òun, ó sì fi ìyọ́nú gbójú fo ìkù-díẹ̀-káàtó àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìpé. Síbẹ̀, ó retí pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn parí. Pẹ̀lú ìrànwọ́ rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí a fi sùúrù fọkàn tán àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa adúróṣinṣin. Wọn yóò fìgbà gbogbo jẹ́ aláìpé nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, gẹ́gẹ́ bí àwa náà yóò ti fìgbà gbogbo jẹ́. Síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ ka àwọn arákùnrin wa sí àwọn ẹni tí kò yẹ fún ìfẹ́ àti àfiyèsí wa láé. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àmọ́ ṣáá o, ó yẹ kí àwa tí a ní okun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun, kí a má sì máa ṣe bí ó ti wù wá.”—Róòmù 15:1; Kólósè 3:13, 14.
Àwọn wòlíì Jèhófà nírìírí gbogbo ìmọ̀lára tí a ń nírìírí. Síbẹ̀, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Jèhófà sì mú wọn dúró. Ìyẹn nìkan kọ́, Jèhófà fún wọn ní ìdí láti ní ayọ̀—ẹ̀rí ọkàn rere, mímọ̀ pé wọ́n ní ojú rere òun, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n mú wọn dúró, àti ìdánilójú ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. (Hébérù 12:1-3) Ẹ jẹ́ kí a dìrọ̀ mọ́ Jèhófà pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún bí a ti ń fara wé ìgbàgbọ́ àwọn wòlíì ìgbàanì, àwọn ènìyàn “tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa.”