Orí Kẹjọ
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jeremáyà Kó o Lè “Máa Wà Láàyè Nìṣó”
1, 2. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ti ìdílé?
LẸ́YÌN tí Jóṣúà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n yan ẹni tí wọ́n á máa sìn, ó sọ pé: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” (Jóṣ. 24:15) Jóṣúà pinnu pé òun yóò jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, ó sì dá a lójú pé ìdílé rẹ̀ náà yóò dúró ṣinṣin. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, bí ìparun Jerúsálẹ́mù ṣe ń sún mọ́lé, Jeremáyà sọ fún Sedekáyà Ọba pé kó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn ará Bábílónì, pé, “Dájúdájú ìwọ fúnra rẹ àti agbo ilé rẹ yóò . . . máa wà láàyè nìṣó.” (Jer. 38:17) Kíkọ̀ tí ọba yẹn kọ̀ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí ṣàkóbá fún òun, àwọn aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n kọ́kọ́ pa àwọn ọmọ rẹ̀ níṣojú rẹ̀, wọ́n wá fọ́ ọ lójú, wọ́n sì mú un lọ sígbèkùn ní Bábílónì.—Jer. 38:18-23; 39:6, 7.
2 Lóòótọ́, ẹnì kan ṣoṣo ló ní ojúṣe pàtàkì tó yẹ kó ṣe nínú gbólóhùn tá a fi lẹ́tà tó dagun kọ ní Jóṣúà 24:15 àti Jeremáyà 38:17 tá a tọ́ka sí lókè yìí. Ṣùgbọ́n wọ́n tún mẹ́nu kan ìdílé ẹni náà pẹ̀lú. Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu. Nítorí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé olúkúlùkù ẹni tó ti tójúúbọ́ ló máa jíhìn fún Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ń gbé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ọwọ́ pàtàkì làwa Kristẹni náà fi mú ọ̀rọ̀ ìdílé. Èyí hàn gbangba látinú àwọn ohun tá à ń kà nínú Bíbélì àtàwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ láwọn ìpàdé ìjọ nípa ìgbéyàwó, títọ́ ọmọ àti bíbọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé wa.—1 Kọ́r. 7:36-39; 1 Tím. 5:8.
ÀṢẸ KAN TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀
3, 4. Àwọn ọ̀nà wo ni ipò Jeremáyà gbà yàtọ̀ sì ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù, báwo nìyẹn sì ṣe pé e?
3 Ẹ̀mí Jeremáyà kò bá ìparun Jerúsálẹ́mù ti ìgbà ayé rẹ̀ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lòun ń “wà láàyè nìṣó” bó tiẹ̀ jẹ́ pé ipò tirẹ̀ yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ìgbà ayé rẹ̀. (Jer. 21:9; 40:1-4) Ọlọ́run sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ fẹ́ aya, kò gbọ́dọ̀ bímọ, kò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀ máa ń ṣe.—Ka Jeremáyà 16:1-4.
4 Láyé ìgbà Jeremáyà, àwọn èèyàn máa ń wò ó pé ó pọn dandan kéèyàn fẹ́ ẹnì kan kó sì bímọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọkùnrin Júù ló sì ṣe bẹ́ẹ̀ láti má pàdánù ilẹ̀ ìdílé wọn àti ti ìran wọn.a (Diu. 7:14) Kí wá nìdí tí Jeremáyà ò fi gbọ́dọ̀ láya kó sì bímọ? Torí àjálù tí ń bẹ níwájú ni Ọlọ́run fi sọ pé kò gbọ́dọ̀ bá àwọn Júù ṣọ̀fọ̀ lákòókò ọ̀fọ̀ wọn, kó sì gbọ́dọ̀ bá wọn yọ̀ nígbà àjọyọ̀ wọn. Kò gbọ́dọ̀ tu ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú tàbí kó jẹun níbi ìsìnkú, kò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn. Ìdí ni pé gbogbo àríyá àti ayọ̀ yíyọ̀ bẹ́ẹ̀ máa tó dópin. (Jer. 7:33; 16:5-9) Àwọn ohun tí Jeremáyà ṣe yìí á jẹ́ kí wọ́n rí i pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ló ń bá àwọn sọ, á sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ rí bí ìdájọ́ tó ń bọ̀ ṣe máa gbóná tó. Àjálù yẹn sì dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ìpọ́njú náà ṣe pọ̀ tó fáwọn tí ìyàn mú débi pé ẹran ara èèyàn ló kù tí wọ́n ń jẹ tàbí bí nǹkan ṣe máa rí lára àwọn tí wọ́n ń pa èèyàn wọn jẹ? (Ka Jeremáyà 14:16; Ìdárò 2:20.) Gbogbo èyí fi hàn pé ó pé Jeremáyà o bí kò ṣe láya. Torí kò ní ṣòfò aya tàbí àwọn ọmọ nígbà tí ọ̀pọ̀ ìdílé ń run dà nù lásìkò táwọn ọ̀tá sàga tì wọ́n fún ọdún kan àtààbọ̀, tí wọ́n sì ń pa wọ́n nípakúpa.
5. Ẹ̀kọ́ wo làwa Kristẹni lè rí kọ́ nínú ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Jeremáyà 16:5-9?
5 Ṣùgbọ́n ṣé a lè sọ pé ohun tó wà nínú Jeremáyà 16:5-9 kan àwa náà? Ó tì o. Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé ká “tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú,” ká sì “máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀.” (2 Kọ́r. 1:4; Róòmù 12:15) Jésù pàápàá lọ síbi ìgbéyàwó, ó sì ṣe ohun tó mú kí ìgbéyàwó yẹn túbọ̀ lárinrin. Àmọ́ o, ohun tó ń bọ̀ wá dé bá ètò nǹkan burúkú tá a wà yìí kúrò ní kèrémí. Lákòókò yẹn, nǹkan lè má fara rọ fáwa Kristẹni, káwọn nǹkan kan sì wọ́n wa. Jésù ti sọ ọ́ lásọtúnsọ pé ká múra tán láti fara da ipòkípò tó bá yọjú, ká sì jẹ́ olóòótọ́, àní bí àwọn ará wa ti ọ̀rúndún kìíní tó sá kúrò ní Jùdíà ti ṣe. Torí náà, ó gba pé ká ronú jinlẹ̀ dáadáa lórí ọ̀ràn wíwà láìláya tàbí láìlọ́kọ, lórí ọ̀ràn ṣíṣe ìgbéyàwó àti ti ọmọ bíbí.—Ka Mátíù 24:17, 18.
6. Àwọn wo ló lè jàǹfààní nínú àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún Jeremáyà tí wọ́n bá ronú jinlẹ̀ lé e lórí?
6 Kí la lè rí kọ́ nínú àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún Jeremáyà pé kò gbọ́dọ̀ láya tàbí kó bímọ? Lónìí, àwọn Kristẹni olóòótọ́ míì kò lọ́kọ, àwọn míì kò sì láya tàbí kí wọ́n jẹ́ tọkọtaya tí kò bímọ. Ẹ̀kọ́ wo ni wọ́n lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ ti Jeremáyà? Kí sì nìdí tó fi yẹ káwọn tọkọtaya tó bímọ pàápàá ronú lórí bí Jeremáyà kò ṣe láya tí kò sì bímọ yìí?
7. Lóde òní, kí nìdí tó fi yẹ ká ronú lórí àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún Jeremáyà pé kó má ṣe bímọ?
7 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún Jeremáyà pé kó má ṣe bímọ ná. Jésù ò sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò gbọ́dọ̀ bímọ. Síbẹ̀ má gbàgbé pé ó ké “ègbé” lórí àwọn tó bá jẹ́ aboyún àtàwọn tó bá ṣì ń fún ọmọ ọwọ́ lọ́mú nígbà tí ìpọ́njú dé bá Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Kristẹni. Àkókò yẹn máa nira fún wọn ju àwọn tó kù lọ, torí ipò tí wọ́n wà. (Mát. 24:19) Ìpọ́njú tó ju tìgbà yẹn lọ la dojú kọ báyìí. Ó yẹ káwọn tọkọtaya Kristẹni tó ń ronú lórí bóyá káwọn bímọ ṣírò ìyẹn náà mọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ìwọ náà ò gbà pé ńṣe ni nǹkan túbọ̀ ń nira sí i lákòókò líle koko tá à ń gbé yìí? Àwọn òbí pàápàá máa ń gbà pé kò rọrùn láti tọ́ àwọn ọmọ lọ́nà tí wọn ò fi ní kúrò lọ́nà ìyè, kí wọ́n lè máa “wà láàyè nìṣó” nígbà òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí. Lóòótọ́, tọkọtaya kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá àwọn máa bímọ tàbí àwọn ò ní bí, síbẹ̀, ó yẹ kí wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ti Jeremáyà yìí. Ní ti àṣẹ tí Ọlọ́run wá pa fún un pé kó má ṣe láya ńkọ́?
Àṣẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ni Ọlọ́run pa fún Jeremáyà, kí ló sì yẹ kíyẹn mú wa ronú lé lórí?
KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ BÍ JEREMÁYÀ KÒ ṢE NÍ AYA
8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé kò dìgbà téèyàn bá lọ́kọ tàbí láya kó tó lè múnú Ọlọ́run dùn?
8 Nígbà tí Ọlọ́run ní kí Jeremáyà má ṣe láya, kò sọ ìyẹn di ìlànà tí gbogbo ìránṣẹ́ òun gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Nǹkan dáadáa ni ètò ìgbéyàwó jẹ́. Ṣe ni Jèhófà dá a sílẹ̀ kí èèyàn lè tipa bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé àti pé kó jẹ́ ọ̀nà kan táwọn tọkọtaya lè gbà máa tẹ́ ara wọn lọ́rùn kí wọ́n sì máa múnú ara wọn dùn. (Òwe 5:18) Síbẹ̀ gbogbo ọkùnrin kọ́ ló láya, gbogbo obìnrin kọ́ ló sì lọ́kọ nígbà ayé Jeremáyà. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe káwọn ìwẹ̀fà wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà tí Jeremáyà jẹ́ wòlíì.b Ó sì dájú pé àwọn opó àtàwọn tí aya wọn ti kú náà máa wà níbẹ̀. Nítorí náà, Jeremáyà nìkan kọ́ ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí kò ní alábàáṣègbéyàwó. Ṣùgbọ́n, ó nídìí tóun ò fi láya, àní báwọn Kristẹni kan lóde òní náà ṣe nídìí tí wọn ò fi wá ẹnì kan fẹ́.
9. Ìtọ́ni lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, èyí tí Ọlọ́run mí sí, wo ló yẹ ká ronú jinlẹ̀ lé lórí?
9 Ọ̀pọ̀ nínú àwa Kristẹni máa ń lọ́kọ, ọ̀pọ̀ sì máa ń láya, àmọ́ kì í ṣe gbogbo Kristẹni ló ń ní. O mọ̀ pé Jésù ò láya, ó sì sọ pé àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa wà láìlọ́kọ, àwọn míì yóò sì wà láìláya, pé wọ́n á “wá àyè fún” ẹ̀bùn yẹn látinú ọkàn wọn wá. Ó wá rọ àwọn tó bá lè wáyè fún un pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Mátíù 19:11, 12.) Torí náà, ohun tó máa dáa ni pé ká máa yin àwọn tó pinnu láti wà láìláya tàbí láti wà láìlọ́kọ nítorí pé kí wọ́n lè túbọ̀ ráyè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, dípò ká máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Nígbà míì ṣá o, nǹkan kan ló máa ń fà á táwọn Kristẹni míì fi wà láìlọ́kọ tàbí tí wọ́n fi wà láìláya, ì báà jẹ́ fúngbà díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọn ò tíì rí Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn tí wọ́n lè fẹ́, síbẹ̀ tí wọ́n ti pinnu pé àwọn ò ní ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run tó sọ pé ká ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” Ìyẹn sì dáa gan-an. (1 Kọ́r. 7:39) Bákan náà, àwọn míì lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́ opó tàbí kí aya wọn ti kú, tí wọ́n sì dẹni tí kò lẹ́nì kejì.c Kí wọ́n má gbàgbé pé àtayébáyé lọ̀rọ̀ irú àwọn tó wà láìlọ́kọ tàbí àwọn tó wà láìláya bẹ́ẹ̀ ti ń jẹ Ọlọ́run (àti Jésù náà) lógún.—Jer. 22:3; ka 1 Kọ́ríńtì 7:8, 9.
10, 11. (a) Kí ló jẹ́ kí Jeremáyà lè gbé ìgbé ayé àpọ́n lọ́nà tó dára? (b) Báwo ni ìrírí àwọn èèyàn lóde òní ṣe fi hàn pé àwọn tó wà láìlọ́kọ tàbí àwọn tó wà láìláya lè gbé ìgbé ayé rere?
10 Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, bí Jeremáyà ṣe jẹ́ àpọ́n, ojú Ọlọ́run ló ń wò fún ìrànlọ́wọ́. Báwo? Ṣó o rántí pé ọ̀rọ̀ Jèhófà máa ń dùn mọ́ Jeremáyà gan-an? Èyí ní láti jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń fún Jeremáyà lókun, tó sì ń fi í lọ́kàn balẹ̀ ní gbogbo ọdún tó fi gbájú mọ́ iṣẹ́ wòlíì tí Ọlọ́run yàn fún un. Bákan náà, ṣe ló ń fọgbọ́n yẹra fáwọn tó lè máa fi ṣẹlẹ́yà torí pé ó jẹ́ àpọ́n. Ó tẹ́ ẹ lọ́rùn kó dá ‘jókòó ní òun nìkan’ ju kó lọ máa jókòó sáàárín irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.—Ka Jeremáyà 15:17.
11 Ọ̀pọ̀ Kristẹni tí kò lọ́kọ tàbí àwọn tí kò láya ni wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere Jeremáyà, yálà wọ́n ṣì wà ní ọ̀dọ́ tàbí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí ló ti fi hàn pé èrè ńlá wà nínú kéèyàn tara bọ iṣẹ́ Ọlọ́run gan-an, kéèyàn máa kópa tó jọjú nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, Ẹlẹ́rìí kan tó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Ṣáínà sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ kí n máa rí i pé mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe nǹkan gidi. Níwọ̀n bí mi ò ti lọ́kọ, ṣe ni mo tara bọ iṣẹ́ náà ní pẹrẹu, èyí kò sì jẹ́ kí n mọ̀ ọ́n lára pé mo dá nìkan wà. Inú mi máa ń dùn lópin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan torí mo ń rí i pé iṣẹ́ ìsìn mi ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní gan-an. Èyí sì máa ń jẹ́ kí n láyọ̀ púpọ̀.” Arábìnrin ẹni ọdún méjìdínlógójì kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ pé: “Tó o bá fẹ́ máa láyọ̀, máa wo àǹfààní tó wà nínú ipò tó o bá bá ara rẹ, kó o sì máa lò ó lọ́nà tí wàá fi lè gbádùn rẹ̀.” Arábìnrin kan tí kò lọ́kọ ní gúúsù ilẹ̀ Yúróòpù sọ gbangba pé: “Lóòótọ́, ó lè máà jẹ́ bí mo ṣe fẹ́ gan-an ni mo wà yìí, àmọ́ mo ń láyọ̀, mi ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun já ayọ̀ mi gbà mọ́ mi lọ́wọ́.”
12, 13. (a) Kí ni òótọ́ ọ̀rọ̀ tó dájú nípa àwọn tó lọ́kọ tàbí àwọn tó láya àtàwọn tí kò ní? (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nípa wíwà láìlọ́kọ àti wíwà láìláya látinú ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù àti ìmọ̀ràn rẹ̀?
12 Bóyá Jeremáyà tiẹ̀ lè wá rí i pé ìgbésí ayé òun kò rí bóun ṣe rò pé ó máa rí tóun bá dàgbà. Àmọ́ ó ṣeé ṣe kó tún rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣègbéyàwó tí wọ́n sì bímọ. Òótọ́ ọ̀rọ̀ tí arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Sípéènì náà sọ nìyí, ó ní: “Mo mọ àwọn tọkọtaya tó láyọ̀, mo sì mọ àwọn míì tí kò láyọ̀. Èyí jẹ́ kó dá mi lójú pé ayọ̀ mi nígbèésí ayé kò sinmi lórí bóyá màá lọ́kọ tàbí mi ò ní lọ́kọ.” Láìsí àníàní, àpẹẹrẹ Jeremáyà wulẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí kan ṣoṣo nínú àìmọye ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹni tó wà láìlọ́kọ àti ẹni tó wà láìláya lè gbé ìgbésí ayé rere, tó jẹ́ aláyọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà tún jẹ́rìí sí èyí, ó ní: “Èmi sọ fún àwọn ènìyàn tí kò gbéyàwó àti àwọn opó pé, ó dára kí wọ́n wà, àní bí èmi ti wà.” (1 Kọ́r. 7:8) Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù láya rí, àmọ́ kí aya rẹ̀ ti kú. Ohun tó ṣáà dájú ni pé, kò láya nígbà tó ń ṣe gudugudu méje lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. (1 Kọ́r. 9:5) Ǹjẹ́ a wá jayò pa tá a bá sọ pé wíwà tó wà láìláya jẹ́ ara ohun tó mú kó lè ṣiṣẹ́ ribiribi bẹ́ẹ̀? Ipò yẹn jẹ́ kó lè máa ‘ṣiṣẹ́ sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn,’ débi tó fi lè gbé iṣẹ́ ńlá wọ̀nyẹn ṣe.—1 Kọ́r. 7:35.
13 Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù kó fi kún un pé: “Àwọn tí wọ́n [ṣègbéyàwó] yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” Ó sì jẹ́ kó tún fi kókó pàtàkì yìí kún un pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu tán nínú ọkàn-àyà rẹ̀. . . láti pa ipò wúńdíá tirẹ̀ mọ́, òun yóò ṣe dáadáa. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹni náà tí ó fi ipò wúńdíá rẹ̀ fúnni nínú ìgbéyàwó ṣe dáadáa, ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi í fúnni nínú ìgbéyàwó yóò ṣe dáadáa jù.” (1 Kọ́r. 7:28, 37, 38) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí kò tíì wáyé lákòókò ti Jeremáyà, ṣùgbọ́n ìgbé ayé Jeremáyà fún ọ̀pọ̀ ọdún jẹ́ kó hàn pé àìní aya tàbí ọkọ kò ní kéèyàn má lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run láṣetẹ́rùn. Ṣe lá tiẹ̀ jẹ́ kéèyàn lè túbọ̀ tara bọ iṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn sì ni ìgbésí ayé tó dára jù. Sedekáyà Ọba ṣáà ní aya, àmọ́ nítorí pé kó gba ìmọ̀ràn tí Jeremáyà fún un, kò ṣeé ṣe fún un láti “máa wà láàyè nìṣó.” Àmọ́ wòlíì Jeremáyà tí kò láya gbé ìgbé ayé tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ó sì la ìparun Jerúsálẹ́mù já.
Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ látinú bí Jeremáyà ṣe gbé ìgbé ayé àpọ́n fún ọ̀pọ̀ ọdún?
Ẹ MÚNÚ WỌN DÙN KÍNÚ Ẹ̀YIN NÁÀ SÌ DÙN
14. Kí ni àjọṣe tó wà láàárín Pọ́ọ̀lù àti ìdílé Ákúílà fi hàn?
14 Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbà ayé Jeremáyà ló ṣègbéyàwó tí wọ́n sì ní ìdílé. Bó ṣe rí náà nìyẹn nígbà ayé Pọ́ọ̀lù. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ Kristẹni tó ní ìdílé ni kò lè lọ ṣiṣẹ́ Ọlọ́run nílẹ̀ òkèèrè bíi ti Pọ́ọ̀lù, àmọ́ àwọn náà ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu níbi tí wọ́n wà. Lára ohun tí wọ́n ń ṣe ni pé wọ́n jẹ́ orísun ìṣírí fáwọn tí kò lọ́kọ tàbí àwọn tí kò láya. Rántí pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé sílùú Kọ́ríńtì, ṣe ni Ákúílà àti Pírísílà gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀ sílé wọn, wọ́n sì jẹ́ kó máa bá àwọn ṣe iṣẹ́ ajé pọ̀. Àmọ́ òwò ṣíṣe nìkan kọ́ ló dà wọ́n pọ̀. Ó dájú pé inú Pọ́ọ̀lù máa dùn gan-an bí ìdílé Ákúílà ṣe gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀. Ìwọ wo bí wọ́n á ṣe máa gbádùn oúnjẹ wọn àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n jọ ń ṣe pa pọ̀. Ǹjẹ́ Jeremáyà náà nírú àjọṣe tó lárinrin bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jeremáyà ń lo ìgbà àpọ́n rẹ̀ láti fi ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn kò sọ ọ́ dẹni tó ń ya ara rẹ̀ láṣo. Ó ṣeé ṣe kóun àti ìdílé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ onítara bíi Bárúkù, Ebedi-mélékì àtàwọn míì jọ máa ní ìfararora tó lárinrin.—Róòmù 16:3; ka Ìṣe 18:1-3.
15. Ọ̀nà wo làwọn ará lè gbà máa ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn Kristẹni tí kò lọ́kọ àtàwọn tí kò láya?
15 Àwọn Kristẹni tí kò lọ́kọ àtàwọn tí kò láya lónìí náà máa ń jàǹfààní látinú irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ alárinrin tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìdílé Ákúílà. Tó o bá ní ìdílé, ǹjẹ́ ìdílé yín máa ń rí i pé ẹ fa àwọn tí kò lọ́kọ àtàwọn tí kò láya mọ́ra kẹ́ ẹ lè jọ máa ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ alárinrin? Arábìnrin kan sọ ohun tó ń dùn ún lọ́kàn, ó ní: “Mo ti fi ayé yìí sílẹ̀ pátápátá, mi ò sì ní pa dà síbẹ̀ mọ́. Àmọ́ ìyẹn ò fi hàn pé mo lè dá wà láìrí àwọn ará táá máa fà mí mọ́ra táá sì máa ṣaájò mi. Lóòótọ́, àdúrà mi ni pé kí Jèhófà máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí àti ọ̀rọ̀ ìṣírí púpọ̀ sí i fáwa Kristẹni tá ò lọ́kọ àtàwọn tí kò láya. Síbẹ̀síbẹ̀, kò yẹ káwọn ará máa ṣe bíi pé àwọn ò rí wa, gbogbo wa ṣáà kọ́ ló ṣe tán láti fẹ́ ẹnì kan. Àmọ́, ó fẹ́ dà bíi pé àwọn ará ò ráyè tiwa. Òótọ́ ni pé Jèhófà wà níbẹ̀ fún wa lọ́jọ́kọ́jọ́, àmọ́ láwọn ìgbà tó bá ṣe wá bíi pé ká rẹ́ni fọ̀ràn lọ̀, ǹjẹ́ ẹ̀yin ìdílé wa nípa tẹ̀mí máa wà níbẹ̀ fún wa?” Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin tí kò láya àtàwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ ló máa sọ tinútinú pé àwọn ará máa ń wà níbẹ̀ fáwọn. Wọ́n máa ń rí àwọn ará bá ṣe nǹkan pa pọ̀ nínú ìjọ wọn. Àtọmọdé àtàgbà ni wọ́n ń bá ṣọ̀rẹ́. Níwọ̀n bí ara wọn ti yá mọ́ọ̀yàn, gbogbo ará ìjọ ni wọ́n ń kó mọ́ra.
16. Àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ wo lẹ lè ṣe láti fi múnú àwọn ará tí kò lọ́kọ àtàwọn tí kò láya tó wà nínú ìjọ yín dùn?
16 Tẹ́ ẹ bá ń fara balẹ̀ ronú ohun tẹ́ ẹ máa ṣe ṣáájú, ẹ lè múnú àwọn tí kò lọ́kọ tàbí àwọn tí kò láya dùn tẹ́ ẹ bá ń pè wọ́n mọ́ra lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà àwọn ìgbòkègbodò ìdílé yín, irú bíi nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín nírọ̀lẹ́. Tẹ́ ẹ bá pe àwọn tí kò lọ́kọ tàbí àwọn tí kò láya wá bá yín jẹun pa pọ̀ nínú ìdílé yín, ó lè ṣe wọ́n láǹfààní ju pé kẹ́ ẹ kàn lọ gbé oúnjẹ aládùn fún wọn. Ǹjẹ́ ẹ lè lo ìdánúṣe kẹ́ ẹ ṣètò pé kẹ́ ẹ jọ jáde òde ẹ̀rí pa pọ̀? Tàbí ǹjẹ́ ẹ lè pe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́ra nígbà tí ìdílé yín bá ń lọ ṣe iṣẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí kẹ́ ẹ jọ lọ sí ọjà lọ ra nǹkan nígbà míì? Àwọn ìdílé míì sì ń pe opó tàbí ẹni tí aya rẹ̀ ti kú tàbí aṣáájú-ọ̀nà kan tó jẹ́ àpọ́n mọ́ra, pé kí wọ́n bá àwọn wọ ọkọ̀ pọ̀ lọ sí àpéjọ àgbègbè tàbí kí wọ́n jọ gbafẹ́ lọ síbì kan. Irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń gbádùn mọ́ni gan-an ni.
17-19. (a) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ máa gba tẹ́nì kìíní kejì rò nígbà tí wọ́n bá ń ṣètò àbójútó òbí wọn tó ti dàgbà tàbí èyí tára rẹ̀ ò le? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ látinú ohun tí Jésù ṣe láti fi bójú tó ìyá rẹ̀?
17 Ohun míì tá a tún fẹ́ gbé yẹ̀ wò nípa àwọn arákùnrin tí kò láya àtàwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ ni ti ọ̀rọ̀ àbójútó àwọn òbí tó ti dàgbà. Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn ẹni ńlá kan láàárín àwọn Júù máa ń fọgbọ́n yẹ àbójútó bàbá àti ìyá wọn sílẹ̀. Wọ́n á ní àwọn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ bójú tó àwọn ààtò ìsìn kan táwọn ti pinnu láti ṣe káwọn tó dá sí ọ̀rọ̀ àbójútó òbí, èyí tó jẹ́ ojúṣe wọn lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Máàkù 7:9-13) Kò yẹ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé rárá nínú ìdílé Kristẹni.—1 Tím. 5:3-8.
18 Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé òbí tó ti dàgbà ní àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ńkọ́? Tí ọ̀kan lára ọmọ òbí yìí ò bá lọ́kọ tàbí tí kò bá láya, ṣé ó wá di dandan pé ọrùn rẹ̀ ni kí àbójútó òbí yìí já lé? Arábìnrin kan nílẹ̀ Japan kọ̀wé pé: “Ó wù mí kí n lọ́kọ àmọ́ kò sáyè ọkọ fún mi nítorí ọrùn mi ni ìtọ́jú àwọn òbí mi já lé. Ó dá mi lójú pé Jèhófà mọ iṣẹ́ ńlá tó wà nínú kéèyàn tọ́jú òbí, ó sì tún mọ ẹ̀dùn ọkàn àwọn tí kò lọ́kọ tàbí àwọn tí kò láya pẹ̀lú.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé arábìnrin náà ní àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ti ní ìdílé tiwọn, àmọ́ tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n sọ pé òun ni kó wá máa tọ́jú òbí àwọn láìkọ́kọ́ fọ̀rọ̀ náà lọ̀ ọ́ ṣáájú. Tírú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jeremáyà náà láwọn arákùnrin tó hùwà àìdáa sóun náà.—Ka Jeremáyà 12:6.
19 Jèhófà mọ gbogbo bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn tí kò lọ́kọ àtàwọn tí kò láya, àánú àwọn tó sì ń fojú winá ipò tó le koko máa ń ṣe é. (Sm. 103:11-14) Àmọ́ ṣá o, òbí kan tó ti dàgbà tàbí èyí tó ń ṣàìsàn ló ṣáà bí gbogbo ọmọ rẹ̀, torí náà ọrùn èyí tí kò lọ́kọ tàbí tí kò láya nìkan kọ́ ló yẹ kí ìtọ́jú rẹ̀ já lé. Òótọ́ ni pé àwọn míì nínú wọn lè ti ṣègbéyàwó kí wọ́n sì ti bímọ. Àmọ́, ìyẹn ò yẹ kó já okùn ìfẹ́ ọmọ sí òbí tó yẹ kí wọ́n ní, kò sì sọ pé kí wọ́n má máa ṣe ojúṣe ọmọ sí òbí tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe. Ká rántí pé nígbà tí Jésù ń kú lọ lórí igi oró pàápàá, ó fa ìtọ́jú ìyá rẹ̀ lé ẹnì kan lọ́wọ́, tó fi hàn pé kò gbàgbé ojúṣe rẹ̀. (Jòh. 19:25-27) Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ lórí báwọn ọmọ tí wọ́n ní òbí tó ti dàgbà tàbí òbí tára rẹ̀ ò le yóò ṣe máa bójú tó o láàárín ara wọn, kò sì sọ pé tọ́mọ wọn kan ò bá lọ́kọ tàbí kò láya, ọrùn rẹ̀ ni àbójútó òbí náà gbọ́dọ̀ já lé. Lórí ọ̀ràn tó gbẹgẹ́ yìí, ṣe ni kí àwọn tọ́ràn náà kàn fi ọgbọ́n àti ìgbatẹnirò ṣètò bí wọ́n ṣe máa bójú tó o, kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní ti bó ṣe bójú tó ìyá rẹ̀.
20. Ojú wo lo fi ń wo ọ̀rọ̀ ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kò lọ́kọ àtàwọn tí kò láya nínú ìjọ yín?
20 Ọlọ́run mí sí Jeremáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Olúkúlùkù wọn kì yóò sì tún máa kọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, àti olúkúlùkù wọn arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí.” (Jer. 31:34) Ní ti ọ̀rọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ tí ibí yìí mẹ́nu kàn, a lè sọ pé, lọ́nà kan, à ń gbádùn irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àrà ọ̀tọ̀ yìí nínú ìjọ Kristẹni, títí kan ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará tí kò láya àtàwọn tí kò lọ́kọ. Kò sí àní-àní pé gbogbo wa ló yẹ kó máa wọ́nà láti múnú irú àwọn bẹ́ẹ̀ dùn káwọn náà lè máa ṣe ohun kan náà fún wa, kí wọ́n lè dẹni táá “máa wà láàyè nìṣó.”
Kí ló tún ń béèrè pé kó o ṣe síwájú sí i láti lè rí i dájú pé ò ń múnú àwọn ará kan tí kò láya àtàwọn tí kò lọ́kọ dùn káwọn náà lè múnú rẹ dùn?
a Kò sí ọ̀rọ̀ Hébérù tó dúró fún gbólóhùn náà “àpọ́n” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀.
b Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn tí wọ́n bí ní ìwẹ̀fà àtàwọn tí wọ́n sọ di ìwẹ̀fà, tó jẹ́ pé wọ́n ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kópa nínú ìjọsìn déwọ̀n àyè kan nígbà ayé rẹ̀. Ó ní tí wọ́n bá jẹ́ onígbọràn, wọ́n máa jèrè “ohun tí ó sàn ju àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin” lọ, ìyẹn ni pé wọ́n á ní “orúkọ tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” ní ilé Ọlọ́run.—Aísá. 56:4, 5.
c Àwọn míì lè dá wà nítorí pé alábàáṣègbéyàwó wọn, bóyá tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, pínyà kúrò lọ́dọ̀ wọn tàbí pé ó jáwèé fún wọn.