Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe
◼ Awọn angẹli jẹ ẹ̀mí, laini ara iyara, nitori naa eeṣe ti ẹyin fi nfi wọn hàn ninu aworan gẹgẹ bi awọn ẹni ti o ni ìyẹ́? Eyi ha wulẹ jẹ àṣà atọwọdọwọ isin bi?
Niye igba a maa nfi awọn angẹli hàn ninu aworan pẹlu ìyẹ́ nitori awọn apejuwe iṣapẹẹrẹ ti a ri ninu Bibeli.
O tọna lati sọ pe awọn ẹda ẹmi kò ni ara ìyára pẹlu awọn ìyẹ́ gidi—bẹẹ ni ko si oju, ọwọ́, ẹsẹ̀, tabi awọn apa ara miiran. Sibẹ, nigba ti angẹli farahan awọn iranṣẹ Ọlọrun, irisi wọn ti gbọdọ dabi ti eniyan gidi, nitori a ṣì wọn mọ̀ si eniyan.—Jẹnẹsisi 18:2, 22; 19:1; Onidaajọ 6:11-22.
Bi o ti wu ki o ri, nigba miiran, awọn ẹda eniyan ri iran awọn angẹli wọn sì ṣapejuwe wọn. Wolii Esekiẹli ri “ẹda alaaye mẹrin,” ati ninu iran miiran lẹhin naa oun da awọn wọnyi mọ gẹgẹ bi angẹli ti wọn wà ni ipo ẹgbẹ ti a mọ̀ si ti kerubu. (Esekiẹli 1:5; 9:3; 10:3) Ọkọọkan awọn angẹli wọnyi ni ìyẹ́ apá mẹrin, eyi ti o fi agbara wọn lati dahunpada pẹlu ìyára ni ìhà eyikeyii si àṣẹ Ọlọrun han. “Wọn kò yipada nigba ti wọn lọ; olukuluku wọn lọ ni ọkankan gan-an-ran . . . nibi ti ẹ̀mí ìbáà lọ, wọn lọ; wọn kò si yipada nigba ti wọn lọ.”—Esekiẹli 1:6, 9, 12.
Ṣugbọn awọn angẹli ti a ri ninu ìran kii ri bakannaa nigba gbogbo. Awọn ẹ̀dá angẹli tí Aisaya ri ti a pe ni serafu ni ìyẹ́ apa mẹfa. (Aisaya 6:1, 2) Awọn iyatọ wà laaarin awọn iran ti Esekiẹli ri. Ninu ti akọkọ, awọn angẹli naa ni ẹsẹ̀, ọwọ́ labẹ ọkọọkan iyẹ apa mẹrẹẹrin, ati oju mẹrin (bii oju ti eniyan, kinniun, akọmaluu, ati idì). Ninu iran rẹ̀ ti o tẹle e, ọkan lara awọn oju naa dabi ti kerubu dipo bii ti akọmaluu kan, boya lati fi agbara nla awọn kerubu hàn. Ninu iran ti ìṣelọ́ṣọ̀ọ́ tẹmpili iṣapẹẹrẹ kan ti o tẹle e, Esekiẹli ri awọn kerubu ti wọn ni oju meji, ọkan ti eniyan ekeji ti kinniun. (Esekiẹli 1:5-11; 10:7-17; 41:18, 19) Ninu Ibi Mimọ Julọ ninu agọ isin ati pẹlu ninu tẹmpili ti Solomoni kọ́ ni Jerusalẹmu, awọn kerubu wà nibẹ ti wọn ni iyẹ apá meji. Awọn wọnyi wà lori ìdérí oniwura ti apoti ti a npe ni áàkì majẹmu. Awọn kerubu oniwura meji naa dojukọ araawọn, awọn mejeeji sì ní ìyẹ́ apa meji ti o nàbo ori Áàkì naa. (Ẹkisodu 25:10-22; 37:6-9) Lori Áàkì naa (ati ìdérí rẹ̀) ninu tẹmpili Solomoni ni kerubu meji titobi nla ti a fi wura bò lara duro si, ti ọkọọkan ni ìyẹ́ apa meji ti a na jade.—1 Ọba 8:6-8; 1 Kironika 28:18; 2 Kironika 5:7, 8.
Josephus kọwe pe: “Niti kerubu [wọnni] funraawọn, ko si ẹni ti o le sọ tabi woye bi wọn ti ṣe ri.” Nipa bayii, awọn ọmọwe akẹkọọjinlẹ ati awọn ayàwòrán gbe aworan apẹẹrẹ awọn angẹli (ni pataki awọn kerubu) wọn kari awọn ohun ti a npe ni awọn apẹẹrẹ ọlọrun akọkọ ti Near Eastern [Itosi Ila-oorun] igbaani ti wọn ri bii awọn ẹran ti o ni ìyẹ́. Ṣugbọn atọ́nisọ́nà ti o ṣeegbarale ju ni ọrọ Esekiẹli pe awọn wọnni ti oun ri “ni aworan eniyan.” (Esekiẹli 1:5) Nitori naa nigba ti a ba nyaworan awọn angeli ọrun ninu awọn itẹjade wa, awa nyaworan wọn nitootọ gan-an ni ìrí ẹda eniyan. Awa fi wọn hàn pẹlu ìyẹ́ apa nitori ọgọọrọ awọn apejuwe Bibeli nipa oniruuru angẹli ti wọn ni iyẹ apa ati nitori ọ̀rọ̀ nipa awọn angẹli ti “nfo.”—Iṣipaya 14:6; Saamu 18:10.
Nikẹhin, oju iwe 288 ti Revelation—Its Grand Climax At Hand! yaworan ẹ̀dá ti ọrun oniyẹ apa kan, ti o ni adé ni ori rẹ̀ ati kọkọrọ ni ọwọ́ rẹ̀. Eyi jẹ iṣapejuwe alaworan ti Iṣipaya 20:1: “Mo si ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wa, ti oun ti kọkọrọ ọ̀gbun nì, ati ẹ̀wọ̀n nla kan ni ọwọ́ rẹ̀.” Awa loye angẹli ti o ni kọkọrọ yii pe o jẹ Jesu Kristi ti a ti ṣelogo. Apejuwe naa fi i han pẹlu iyẹ apa lati fohunṣọkan pẹlu otitọ naa pe awọn angẹli ti a ri ninu iran saba maa nni awọn ìyẹ́ apa.