Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
JULY 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 11-14
“Ṣé O Ní Ọkàn-Àyà Ẹlẹ́ran Ara?”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
Lọ́dún 612 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ísíkíẹ́lì rí ìran kan tó ti bá ara rẹ̀ nílùú Jerúsálẹ́mù. Àwọn ohun ìríra tó rí tó ń ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run mà burú jáì o! Nígbà tí Jèhófà bá rán àwọn ọmọ ogun ọ̀run tó máa mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ (ìyẹn àwọn tí “ọkùnrin mẹ́fà” ṣàpẹẹrẹ wọn) láti mú ìbínú rẹ̀ wá sórí àwọn apẹ̀yìndà, kìkì àwọn tó ti gba ‘àmì sí iwájú orí wọn’ nìkan ló máa yè bọ́. (Ìsíkíẹ́lì 9:2-6) Àmọ́, lákọ̀ọ́kọ́ ná, “ẹyín iná,” ìyẹn ìkéde ìdájọ́ ìparun mímúná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wá sórí ìlú náà. (Ìsíkíẹ́lì 10:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘Jèhófà yóò mú ọ̀nà àwọn ẹni ibi wá sórí wọn,’ ó ṣèlérí pé òun yóò padà kó àwọn tó fọ́n káàkiri lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ.—Ìsíkíẹ́lì 11:17-21.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
12:26-28. Ní ti àwọn tó tiẹ̀ ń fi iṣẹ́ tí Ísíkíẹ́lì ń jẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ pàápàá, ó ní láti sọ fún wọn pé: “Kì yóò sí ìsúnsíwájú mọ́ rárá nípa èyíkéyìí nínú ọ̀rọ̀ [Jèhófà].” A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó tó di pé ó mú ètò nǹkan ìsinsìnyí wá sópin.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
14:12-23. Kálukú wa ló máa ṣiṣẹ́ tó máa fi rí ìgbàlà. Ẹlòmíràn kò lè bá wa ṣe é.—Róòmù 14:12.
JULY 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 15-17
“Ṣé O Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ Ṣẹ?”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
17:1-24— Àwọn wo ni idì ńlá méjì, báwo la ṣe já àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ orí ẹ̀ka igi kédárì kúrò, ta sì ni “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́” tí Jèhófà tún gbìn? Àwọn idì ńlá méjì yẹn dúró fún àwọn alákòóso Bábílónì àti Íjíbítì. Idì àkọ́kọ́ wá sórí téńté igi kédárì, ìyẹn ni pé ó wá sọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣàkóso nínú ìran Dáfídì ọba. Idì yìí wá já àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ orí igi náà kúrò nípa fífi Sedekáyà rọ́pò Jèhóákínì Ọba Júdà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sedekáyà búra pé òun ò ní dalẹ̀, síbẹ̀ ó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ idì mìíràn, ìyẹn alákòóso ilẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ pàbó ló já sí. Ńṣe ni wọ́n máa mú un nígbèkùn, Bábílónì ló sì máa kú sí. Jèhófà tún já “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́,” ìyẹn Mèsáyà Ọba. Ó wá tún èyí gbìn “sórí òkè ńlá gíga tí ó lọ sókè fíofío,” ìyẹn lórí Òkè Síónì, níbi tó ti máa di “kédárì ọlọ́lá ọba,” ìyẹn orísun ìbùkún àgbàyanu fún ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 14:1.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
17:1-24—Àwọn wo ni idì ńlá méjì, báwo la ṣe já àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ orí ẹ̀ka igi kédárì kúrò, ta sì ni “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́” tí Jèhófà tún gbìn? Àwọn idì ńlá méjì yẹn dúró fún àwọn alákòóso Bábílónì àti Íjíbítì. Idì àkọ́kọ́ wá sórí téńté igi kédárì, ìyẹn ni pé ó wá sọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣàkóso nínú ìran Dáfídì ọba. Idì yìí wá já àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ orí igi náà kúrò nípa fífi Sedekáyà rọ́pò Jèhóákínì Ọba Júdà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sedekáyà búra pé òun ò ní dalẹ̀, síbẹ̀ ó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ idì mìíràn, ìyẹn alákòóso ilẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ pàbó ló já sí. Ńṣe ni wọ́n máa mú un nígbèkùn, Bábílónì ló sì máa kú sí. Jèhófà tún já “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́,” ìyẹn Mèsáyà Ọba. Ó wá tún èyí gbìn “sórí òkè ńlá gíga tí ó lọ sókè fíofío,” ìyẹn lórí Òkè Síónì, níbi tó ti máa di “kédárì ọlọ́lá ọba,” ìyẹn orísun ìbùkún àgbàyanu fún ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 14:1.
Jẹ́ Kí Bẹ́ẹ̀ Ni Rẹ Jẹ́ Bẹ́ẹ̀ Ni
11 Kí nìdí tí Jèhófà fi mú kí a ṣàkọsílẹ̀ àwọn àpẹẹrẹ yìí fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀? Báwo ló sì ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wa jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni? Bíbélì kìlọ̀ fún wa lọ́nà tó ṣe kedere pé ẹni tó bá jẹ́ “olùyẹ àdéhùn” wà lára àwọn tó “yẹ fún ikú.” (Róòmù 1:31, 32) Fáráò ti ilẹ̀ Íjíbítì, Sedekáyà Ọba Jùdíà àti Ananíà àti Sáfírà wà lára àwọn àpẹẹrẹ burúkú tó wà nínú Bíbélì nípa àwọn tí kò jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wọn jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni. Láburú ló gbẹ̀yìn gbogbo wọn, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa.—Ẹ́kís. 9:27, 28, 34, 35; Ìsík. 17:13-15, 19, 20; Ìṣe 5:1-10.
w88 9/15 17 ¶8
Jèhófà Fa Idà Rẹ̀ Yọ Nínú Àkọ̀!
8 Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn olùṣàkóso Bábílónì àti Íjíbítì ni a fi wé àwọn idì ńlá. Okan gé téńté orí igi Kédárì kan sọ nù nípa fífi Sedekáyà rọ́pò Ọba Jèhóákínì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sedekáyà búra fún Nebukadinésárì pé òun máa jẹ́ adúróṣinsin sí i, ó dalẹ̀ nígbà tó wá ìrànlọ́wọ́ ológun lọ sọ́dọ̀ Íjíbítì, ìyẹn idì ńlá kejì. Bí Sedekáyà bá ti fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ké pe orúkọ Ọlọ́run nínú ṣíṣe ìbúrà rẹ̀, bíbà á jẹ́ yóò mú ẹ̀gàn wá sórí Jèhófà. Ìrònú náà gan-an tí mímú ẹ̀gàn wá sórí Ọlọ́run níláti kó wa níjàánu kúrò nínú sísẹ́ ọ̀rọ̀ wa nígbà kankan. Ẹ wo àǹfààní tí á ní tòótọ́ láti jẹ́ orúkọ àtọ̀runwá náà gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!—Ìsíkíẹ́lì 17:1-21.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
w88 9/15 17 ¶7
Jèhófà Fa Idà Rẹ̀ Yọ Nínú Àkọ̀!
7 Nítorí àwọn olùgbé rẹ̀, Júdà ni a fi wé àjàrà ijù tí kò ní èso dídára tí ó sì yẹ kìkì fún iná. (Ìsíkíẹ́lì 15:1-8) Òun pẹ̀lú ni a fi wé ọmọ-pàtàkì kan tí Ọlọ́run gbà là láti Íjíbítì tí ó sì tọ́ ọ dàgbà dé ipò-obìnrin. Jèhófà mú un gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, ṣùgbọ́n òun yídà sí àwọn èké Ọlọ́run, yóò sì jìyà ìparun fún ìwà panṣágà rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú àwọn olùṣòtítọ́ ni Ọlọ́run yóò ‘fìdí májẹ̀mú kan tí ó wà pẹ́ títí lọ gbére múlẹ̀’ májẹ̀mú tuntun pẹ̀lú Ísírẹ́lì tẹ̀mí náà.—Ìsíkíẹ́lì 16:1-63; Jeremáyà 31:31-34; Gálátíà 6:16.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
17:1-24—Àwọn wo ni idì ńlá méjì, báwo la ṣe já àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ orí ẹ̀ka igi kédárì kúrò, ta sì ni “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́” tí Jèhófà tún gbìn? Àwọn idì ńlá méjì yẹn dúró fún àwọn alákòóso Bábílónì àti Íjíbítì. Idì àkọ́kọ́ wá sórí téńté igi kédárì, ìyẹn ni pé ó wá sọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣàkóso nínú ìran Dáfídì ọba. Idì yìí wá já àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ orí igi náà kúrò nípa fífi Sedekáyà rọ́pò Jèhóákínì Ọba Júdà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sedekáyà búra pé òun ò ní dalẹ̀, síbẹ̀ ó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ idì mìíràn, ìyẹn alákòóso ilẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ pàbó ló já sí. Ńṣe ni wọ́n máa mú un nígbèkùn, Bábílónì ló sì máa kú sí. Jèhófà tún já “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́,” ìyẹn Mèsáyà Ọba. Ó wá tún èyí gbìn “sórí òkè ńlá gíga tí ó lọ sókè fíofío,” ìyẹn lórí Òkè Síónì, níbi tó ti máa di “kédárì ọlọ́lá ọba,” ìyẹn orísun ìbùkún àgbàyanu fún ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 14:1.
JULY 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 18-20
“Tí Ọlọ́run Bá Ti Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jini, Ṣé Ó Máa Ń Gbàgbé Rẹ̀?”
Tí Ọlọ́run Bá Ti Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jini, Ṣé Ó Máa Ń Gbàgbé Rẹ̀?
Jèhófà lo wòlíì Ísíkíẹ́lì bí agbọ̀rọ̀sọ láti kéde ìdájọ́ sórí ilẹ̀ Júdà àti ìlú Jerúsálẹ́mù nítorí àìṣòdodo wọn. Ilẹ̀ Júdà lápapọ̀ pa ìjọsìn Jèhófà tì, ìwà ipá sì gbòde kan níbẹ̀. Jèhófà wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì máa pa ìlú Jerúsálẹ́mù run. Àmọ́ bí Jèhófà ṣe kéde ìdájọ́ sorí wọn yìí, ó tún sọ̀rọ̀ tó fún wọn nírètí. Olúkúlùkù wọn ló ní òmìnira láti yan ohun tó wù ú; kálukú wọn ni yóò sì jíhìn ohun tó bá yàn láti ṣe.—Ẹsẹ 19, 20.
Tí Ọlọ́run Bá Ti Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jini, Ṣé Ó Máa Ń Gbàgbé Rẹ̀?
Bí èèyàn bá wá yí pa dà kúrò lọ́nà búburú tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere ńkọ́? Jèhófà sọ pé: “Ní ti ẹni burúkú, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó yí padà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá, tí ó sì pa gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́ ní ti tòótọ́, tí ó sì mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo ṣẹ ní kíkún, dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó. Òun kì yóò kú.” (Ẹsẹ 21) Jèhófà “ṣe tán láti dárí ji” ẹni tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tó sì yí pa dà kúrò ní ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—Sáàmù 86:5.
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹni náà ti wá dá ńkọ́? Jèhófà sọ pé: “Gbogbo ìrélànàkọjá rẹ̀ tí ó ti ṣe—a kì yóò rántí wọn lòdì sí i.” (Ẹsẹ 22) Kíyè sí i pé Ọlọ́run “kì yóò rántí” ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tó ronú pìwà dà yẹn “lòdì sí i.” Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì?
Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí a tú sí “rántí” ní ìtumọ̀ tó ju pé kéèyàn kàn rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Ohun tí ìwé ìwádìí kan sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí ni pé: “Ká sòótọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, [ó] máa ń túmọ̀ sí pé onítọ̀hún fẹ́ ṣe nǹkan kan nípa ohun tó rántí tàbí kí wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà pa pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ ìṣe tó máa fi hàn pé onítọ̀hún máa gbé ìgbésẹ̀ kan.” Torí náà, “kéèyàn rántí” nǹkan kan lè túmọ̀ sí “kéèyàn gbé ìgbésẹ̀.” Nípa báyìí, nígbà tí Jèhófà sọ nípa ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni òun “kì yóò rántí lòdì sí i,” ohun tó ń sọ ni pé òun kò ní tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ náà gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí ẹni náà, bóyá pé kí òun ka ẹ̀ṣẹ̀ sí onítọ̀hún lọ́rùn tàbí kí òun jẹ ẹ́ níyà.
Ọ̀rọ̀ inú Ìsíkíẹ́lì 18:21, 22 jẹ́ ká rí bí ìdáríjì Ọlọ́run ṣe máa ń jinlẹ̀ tó. Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini kò ní ka ẹ̀ṣẹ̀ yẹn sí wa lọ́rùn mọ́ lọ́jọ́ iwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó ronú pìwà dà sí ẹ̀yìn rẹ̀. (Aísáyà 38:17) Yóò ṣe é lọ́nà táá fi dà bíi pé ó pa àkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yẹn rẹ́.—Ìṣe 3:19.
Torí pé a jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, a nílò àánú Ọlọ́run. Ó ṣe tán ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń ṣẹ̀. (Róòmù 3:23) Àmọ́ Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé tí a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, òun ṣe tán láti dárí jì wá. Àti pé tó bá ti dárí jini, ó máa ń gbàgbé rẹ̀, ìyẹn ni pé kò ní máa ronú nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà láti lè kà wọ́n sí wa lọ́rùn tàbí láti torí rẹ̀ jẹ wá níyà. Ẹ ò rí i pé ìyẹn tuni nínú gan-an! Ǹjẹ́ àánú tí Ọlọ́run ní yìí kò mú kí ìwọ náà fẹ́ láti sún mọ́ ọn?
Amágẹ́dọ́nì Ogun Ọlọ́run Tó Máa Fòpin Sí Gbogbo Ogun
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Onídàájọ́, ó dájú pé ìdájọ́ tó tọ́ làwọn ẹni ibi máa gbà. Ábúráhámù béèrè pé: “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” Ohun tí Ábúráhámù wá mọ̀ ni pé, Jèhófà kì í ṣe àìtọ́ lọ́nàkọnà, gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe ohun tó tọ́! (Jẹ́nẹ́sísì 18:25) Síwájú sí i, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kì í dùn mọ́ Jèhófà nínú láti pa àwọn ẹni ibi run, ìgbà tó bá pọn dandan ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 18:32; 2 Pétérù 3:9.
Bá a Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọmọnìkejì Wa
11 Tá a bá fẹ́ máa fìfẹ́ hàn sáwọn tí kò sin Ọlọ́run, ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká fara wé Jèhófà fúnra rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kórìíra ìwà ibi, ó fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn nípa fífún wọn ní àǹfààní láti yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn kí wọ́n lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìsíkíẹ́lì 18:23) Jèhófà “fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Ohun tó wù ú ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi pa á láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù, kí wọ́n kọ́ni, kí wọ́n sì “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ yìí, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa, títí kan àwọn ọ̀tá wa pàápàá!
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Má Ṣe “Kún fún Ìhónú sí Jèhófà”
9 Tá ò bá mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an. Nígbà ayé Ísíkíẹ́lì, torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an, ńṣe ni wọ́n gbà pé ọ̀nà Jèhófà “kò gún.” (Ìsík. 18:29) Ṣe ló dà bíi pé wọ́n ń dá Ọlọ́run lẹ́jọ́, tí wọ́n sì ka ìlànà ìdájọ́ tiwọn sí ju ti Ọlọ́run lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lóye àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ń dá a lẹ́jọ́. Bákan náà, ó lè ṣẹlẹ̀ nígbà míì pé a ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wà nínú Bíbélì tàbí pé a ò mọ ìdí tí ohun kan fi ṣẹlẹ̀ sí wa. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé a kì í sọ nínú ọkàn wa pé ohun tí Jèhófà ṣe kò dára, pé ọ̀nà rẹ̀ “kò gún”?—Jóòbù 35:2.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
20:1, 49. Ohun táwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fi hàn pé wọn ò fi gbogbo ara gba ọ̀rọ̀ Ísíkíẹ́lì gbọ́. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣiyèméjì láé nípa ìkìlọ̀ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.
JULY 24-30
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 21-23
“Ẹni Tó Lẹ́tọ̀ọ́ Lábẹ́ Òfin Ni Ọba Tọ́ Sí”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
Lẹ́yìn ọdún méje táwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì ti wà nígbèkùn, ìyẹn ní ọdún 611 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n wá sọ́dọ̀ Ísíkíẹ́lì “láti wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.” Wọ́n gbọ́ ìtàn tó gùn gan-an nípa ọ̀tẹ̀ Ísírẹ́lì àti ìkìlọ̀ pé ‘Jèhófà yóò mú idà rẹ̀ wá’ sórí wọn. (Ìsíkíẹ́lì 20:1; 21:3) Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa olórí Ísírẹ́lì (ìyẹn Sedekáyà), Jèhófà sọ pé: “Mú láwàní kúrò, sì ṣí adé kúrò. Èyí kì yóò rí bákan náà. Gbé ohun tí ó rẹlẹ̀ pàápàá ga, kí o sì rẹ ẹni gíga pàápàá wálẹ̀. Rírun, rírun, rírun ni èmi yóò run ún. Ní ti èyí pẹ̀lú, dájúdájú, kì yóò jẹ́ ti ẹnì kankan títí di ìgbà tí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin [ìyẹn Jésù Kristi] yóò fi dé, èmi yóò sì fi í fún un.”—Ìsíkíẹ́lì 21:26, 27.
Wọ́n Retí Mèsáyà
6 Inú ẹ̀yà Júdà ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni wọ́n ti máa bí Mèsáyà. Nígbà tí Jékọ́bù ń súre fáwọn ọmọ rẹ̀ kó tó kú, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pá aládé kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ kì yóò yà kúrò ní àárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣílò yóò fi dé; ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.” (Jẹ́n. 49:10) Púpọ̀ lára àwọn ọ̀mọ̀wé Júù ìgbà yẹn ló gbà pé Mèsáyà ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa ṣẹ sí lára. Látìgbà tí Dáfídì Ọba tó wá látinú ẹ̀yà Júdà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ni ọ̀pá aládé (ipò àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọba) àti ọ̀pá àṣẹ (agbára láti pàṣẹ) kò ti kúrò nínú ẹ̀yà Júdà. “Ṣílò” túmọ̀ sí “Oní-nǹkan; Ẹni Tí Nǹkan Tọ́ Sí.” Ìlà ìdílé àwọn ọba látinú ẹ̀yà Júdà máa dópin nígbà tí “Ṣílò” tó jẹ́ Ajogún tí ipò ọba tọ́ sí títí gbére bá dé, torí Ọlọ́run sọ fún Sedekáyà tó jẹ́ ọba tó jẹ kẹ́yìn ní ìlà Júdà pé a óò fi ìṣàkóso fún ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin. (Ìsík. 21:26, 27) Lẹ́yìn Sedekáyà, Jésù nìkan ni àtọmọdọ́mọ Dáfídì tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa jọba. Ṣáájú ìbí Jésù, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Torí náà, Ṣílò ní láti jẹ́ Jésù Kristi tí í ṣe àtọmọdọ́mọ Júdà àti Dáfídì.—Mát. 1:1-3, 6; Lúùkù 3:23, 31-34.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
21:3—Kí ni “idà” tí Jèhófà mú jáde kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀? Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni “idà” tí Jèhófà lò láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Jerúsálẹ́mù àti Júdà. Apá tó jẹ́ ti òkè ọ̀run lára ètò Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ alágbára, tún lè wà lára ohun tí “ìdà” náà dúró fún.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
23:5-49. Lílẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Júdà lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ló mú kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké wọn. Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra fún níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé tí wọ́n lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́.—Jákọ́bù 4:4.
JULY 31–AUGUST 6
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 24-27
“Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Bí Ìlú Tírè Ṣe Máa Pa Run Mú Ká Fọkàn Tán Ọ̀rọ̀ Jèhófà”
si 133 ¶4
Ìwé Bíbélì Kẹrìndínlọ́gbọ̀n [26]—Ìsíkíẹ́lì
4 Àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa ìlú Tírè, Íjíbítì àti Édómù ní ìmúṣẹ, èyí sì túbọ̀ jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣeé fọkàn tán. Bí àpẹẹrẹ, Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìlú Tírè máa pa run, àsọtẹ́lẹ̀ náà ní ìmúṣẹ lápá kan nígbà tí Nebukadinésárì sàga tì í fún ọdún mẹ́tàlá, lẹ́yìn náà ló wá gbógun tì í. (Isk. 26:2-21) Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé ìlú Tírè ti pa run pátápátá. Torí ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe nípa rẹ̀ ni pé ó máa pa run pátápátá. Ó lo Ìsíkíẹ́lì láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èmi yóò ha ekuru rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di àpáta gàǹgà dídán borokoto. . . . Wọn yóò sì kó òkúta rẹ àti iṣẹ́ àfigiṣe rẹ àti ekuru rẹ sí àárín omi.” (26:4, 12) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ní ìmúṣẹ lẹ́yìn ohun tó lé ní 250 ọdún nígbà tí Alẹkisáńdà ńlá gbógun ti ìlú Tírè tó wà ní orí omi. Àwọn ọmọ ogun Alẹkisáńdà kó gbogbo àwókù láti orí ilẹ̀ dà sínú omi láti fi ṣe àtẹ̀gùn tí ó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800 m] mítà dé erékùṣù ìlú Tírè orí omi. Lẹ́yìn náà, wọ́n sàga ti ìlú náà, wọ́n gun ògiri rẹ̀ tó ga tó mítà mẹ́rìndínláàádọ́ta [46 m] wọnú ìlú, wọ́n sì mú ìlú náà balẹ̀ ní ọdún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Wọ́n pa ẹgbẹgbẹ̀rún èèyàn, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n sì kó lẹ́rú. Bí Ìsíkíẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìlú Tírè di ‘àpáta gàǹgà dídán borokoto tí a ń sá àwọ̀n ńlá sí.’ (26:14) Àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì ṣe nípa ìlú Édómù ní ìmúṣẹ nígbà tí wọ́n pa á run ní òdìkejì ilẹ̀ ìlérí. (25:12, 13; 35:2-9) Bákan náà, àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì ṣe nípa bí wọ́n ṣe máa pa Jerúsálẹ́mù run, tí wọ́n á sì tún mú Ísírẹ́lì pa dà bọ̀ sípò ṣẹ gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ.—17:12-21; 36:7-14.
ce 216 ¶3
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Mí Sí Bíbélì Lóòótọ́?
3 Ìlú Tírè jẹ́ ibùdókọ̀ òkun tó lọ́lá ní àgbègbè ilẹ̀ Fòníṣíà, àwọn ará ìlú náà sì máa ń ṣàìda sáwọn olùjọsìn Jèhófà, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní ìhà gúúsù ìlú Tírè. Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé wọ́n máa pa ìlú Tírè run, èyí sì ní ìmúṣẹ lẹ́yìn ọdún 250 tí wòlíì yẹn sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò sì gbé orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ . . . wọn yóò run ògiri Tírè, wọn yóò sì ya àwọn ilé gogoro rẹ̀ lulẹ̀, ṣe ni èmi yóò ha ekuru rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di àpáta gàǹgà dídán borokoto. Ilẹ̀ àgbàlá tí a ń sá àwọ̀n ńlá sí ni òun yóò dà láàárín òkun.” Tipẹ́tipẹ́ ni Ìsíkíẹ́lì ti sọ orúkọ ìlú tó máa sàga ti Tírè àti ẹni tó máa jẹ́ aṣáájú ìlú náà, ó ní: “Èmi yóò mú Nebukadirésárì ọba Bábílónì wá gbéjà ko Tírè.”—Ìsíkíẹ́lì 26:3-5, 7.
it-1 70
Alẹkisáńdà
Dípò tí Alẹkisáńdà ì bá fi lépa àwọn ará Páṣíà tó ń sá lọ lẹ́yìn tó ti ṣẹ́gun wọn ní ẹ̀ẹ̀mejì ní Éṣíà Kékeré (odò Granicus ló ti kọ́kọ́ ṣẹ́gun wọn; ó sì tún ṣẹ́gun wọn lẹ́ẹ̀kejì ní Issus, àwọn ọmọ ogun Páṣíà tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún ló ṣẹ́gun), ńṣe ló yíjú sí erékùṣù ìlú Tírè. Tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ya àwọn ògiri àti ilé gogoro rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n á sì kó àwọn àwókù rẹ̀ dà sí àárín omi. (Isk 26:4, 12) Torí náà, ó gbàfiyèsí pé nígbà tí Nebukadinésárì ṣẹ́gun ìlú Tírè orí ilẹ̀, Alẹkisáńdà kó gbogbo àwókù ìlú náà dà sínú omi láti fi ṣe àtẹ̀gùn tí ó gùn tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800 m] mítà dé erékùṣù ìlú Tírè orí omi. Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pa ìlú náà run ní oṣù July ọdún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
24:6-14—Kí ni ìpẹtà ìkòkò ìse-oúnjẹ dúró fún? Ipò tí Jerúsálẹ́mù wà lákòókò tí wọ́n sàga tì í ni Bíbélì fi wé ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀. Ìpẹtà rẹ̀ dúró fún ìwà ìbàjẹ́ ìlú náà, ìyẹn ìwà àìmọ́, ìwàkíwà, àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó ń lọ níbẹ̀. Ìwà àìmọ́ rẹ̀ pọ̀ débi pé gbígbé ìkòkò náà sórí ẹyín iná ní òfìfo kí wọ́n sì jẹ́ kó gbóná gan-an kò mú ìpẹtà náà kúrò.
w88 9/15 21 ¶24
Jèhófà Fa Idà Rẹ̀ Yọ Nínú Àkọ̀!
24 Lẹ́yìn ìyẹn, Ìsíkíẹ́lì ní láti gbégbèésẹ̀ ní ọ̀nà àràmàǹdà ọ̀tọ̀ kan. (Ka Ìsíkíẹ́lì 24:15-18.) Èéṣe tí wòlíì náà kò fi ní láti fi ẹ̀dùn ọkàn kankan hàn sóde nígbà tí aya rẹ̀ kú? Láti fi hàn bí àwọn Júù yóò ṣe díjìgbọ̀nrìrì tó nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù, àwọn olùgbé rẹ̀ àti tẹ́mpílì náà. Ìsíkíẹ́lì ṣáájú àkókò náà ti sọ ohun tí ó tó nípa irúfẹ́ àwọn kókó ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ òun kì yóò sì sọ ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run mọ́ títí di ìgbà tí a ó wá ròyìn ìṣubú Jerúsálẹ́mù fún un. Ní ìfarajọra, Kristẹ́ńdọ́mù àti àwọn onísìn alágàbàgebe rẹ̀ yóò díjìgbọ̀nrìrì ní àkókò ìparun wọn. Lẹ́yìn tí “ìpọ́njú ńlá” náà bá bẹ̀rẹ̀, ohun tí àwọn agbo ẹgbẹ́ èṣọ́kùnrin ẹni àmì òróró náà ti sọ ṣáájú àkókò náà nípa òpin rẹ̀ yóò ti tó. (Mátíù 24:21) Ṣùgbọ́n nígbà tí “idà” Ọlọ́run bá sọ̀kalẹ̀ sórí Kristẹ́ńdọ́mù, irúfẹ́ àwọn onísìn àti àwọn yòókù tí a mú díjìgbọ̀nrìrì ‘yóò ní láti mọ̀ pé òun ni Jèhófà.’—Ìsíkíẹ́lì 24:19-27.