“Tẹ́ńpìlì Náà” Àti “Ìjòyè Náà” Lónìí
“Àti ní ti ìjòyè àárín wọn, nígbà tí wọ́n bá wọlé, ni kí ó wọlé; nígbà tí wọ́n bá sì jáde, ni kí ó jáde.”—ÌSÍKÍẸ́LÌ 46:10.
1, 2. Òtítọ́ pàtàkì wo ló ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí?
ÀWỌN kan lára àwọn Rábì ìgbàanì ni ìwé Ìsíkíẹ́lì kò tẹ́ lọ́rùn rárá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Talmud ti sọ, àwọn kan nínú wọn tilẹ̀ ronú pé ó yẹ kí wọ́n mú ìwé náà kúrò lára àwọn ìwé tí a tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí apá kan Ìwé Mímọ́. Ó ṣòro gidigidi fún wọn láti ṣàlàyé ìran tẹ́ńpìlì náà, wọ́n sì sọ pé ó kọjá ohun tí ènìyàn lè lóye. Ìran tẹ́ńpìlì Jèhófà tí Ìsíkíẹ́lì rí ti kó ṣìbáṣìbo bá àwọn mìíràn tí ó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bíbélì. Àwa náà ńkọ́?
2 Láti ìgbà tí a ti mú ìjọsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò, Jèhófà ti fi ìbùyẹ̀rì ìjìnlẹ̀ òye nípa tẹ̀mí bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kan òye ohun tí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí jẹ́—ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́ gaara tó dà bí tẹ́ńpìlì.a Òtítọ́ tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn yìí ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye púpọ̀ nínú ìtumọ̀ ìràn tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí. Ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò apá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin inú ìran yìí—tẹ́ńpìlì, àwọn àlùfáà, ìjòyè, àti ilẹ̀ náà. Kí ni ìwọ̀nyí túmọ̀ sí lónìí?
Tẹ́ńpìlì Náà àti Ìwọ Alára
3. Ẹ̀kọ́ wo lá rí kọ́ nínú àjà tẹ́ńpìlì náà tó ga fíofío àti iṣẹ́ ọ̀nà tó wà lára ògiri ẹnu ọ̀nà rẹ̀?
3 Fojú inú wò ó pé a ń ṣèbẹ̀wò sí tẹ́ńpìlì inú ìran yìí. A ti débẹ̀, a sì ń gun àtẹ̀gùn méje tó lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ẹnubodè ńlá náà. Bí a ṣe dúró ní ọ̀nà àbáwọlé yìí, a wòkè tìyanutìyanu. Àjà ilé náà mà ga ju ọgbọ̀n mítà sílẹ̀! A tipa báyìí rán wa létí pé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n fún wíwọnú ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn ga fíofío. Ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ láti ojú fèrèsé tàn sára àwọn igi ọ̀pẹ tí a yà sára ògiri, nínú Ìwé Mímọ́, igi ọ̀pẹ sì dúró fún ìdúróṣánṣán. (Sáàmù 92:12; Ìsíkíẹ́lì 40:14, 16, 22) Àwọn adúróṣánṣán ní ti ìwà rere àti nípa tẹ̀mí ni ibi ọ̀wọ̀ yìí wà fún. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú jẹ́ adúróṣánṣán kí Jèhófà lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.—Sáàmù 11:7.
4. Àwọn wo ni a kò yọ̀ǹda fún láti wọnú tẹ́ńpìlì náà, kí sì ni èyí kọ́ wa?
4 Ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ mẹ́ta wà níhà ìhín àti níhà ọ̀hún ọ̀nà àbákọjá náà. Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ yóò jẹ́ kí a wọnú tẹ́ńpìlì náà? Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kò sí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kankan tí ó jẹ́ “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà” tí ó gbọ́dọ̀ wọlé. (Ìsíkíẹ́lì 40:10; 44:9) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé kìkì àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ ni òun yóò tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí olùjọ́sìn rẹ̀. (Jeremáyà 4:4; Róòmù 2:29) Ó ń fi tayọ̀tayọ̀ gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sínú àgọ́ rẹ̀ tẹ̀mí, ìyẹn ni ilé ìjọsìn rẹ̀. (Sáàmù 15:1-5) Láti ìgbà tí a ti mú ìjọsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò ní ọdún 1919, ètò àjọ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé ti mú àwọn òfin rẹ̀ nípa ìwà rere ṣe kedere ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ó sì gbé e lárugẹ. Kò gba àwọn tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti ṣègbọràn láàyè mọ́ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀. Lónìí, ìlànà tí a gbé ka Bíbélì, ti yíyọ àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́, ti mú kí ìjọsìn wa wà ní mímọ́ gaara.—1 Kọ́ríńtì 5:13.
5. (a) Ìjọra wo ló wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí àti èyí tí Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Ìṣípayá 7:9-15? (b) Nínú ìran Ìsíkíẹ́lì, àwọn wo ni àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ń jọ́sìn ní àgbàlá òde ń ṣàpẹẹrẹ?
5 Ọ̀nà àbákọjá náà lọ sí àgbàlá òde, níbi tí àwọn ènìyàn ti ń jọ́sìn Jèhófà, tí wọ́n sì ń fìyìn fún un. Èyí rán wa létí ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, ìyẹn ni ti “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti ń jọ́sìn Jèhófà “tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” A fi àwọn igi ọ̀pẹ hàn nínú ìran méjèèjì. Nínú ìran Ìsíkíẹ́lì, a fi wọ́n ṣọ̀ṣọ́ sára ògiri ọ̀nà àbáwọlé. Nínú ìran Jòhánù, àwọn olùjọsìn náà mú imọ̀ ọ̀pẹ dání, èyí tí ó ṣàpẹẹrẹ pé wọ́n ń fi ìdùnnú yin Jèhófà, wọ́n sì fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn. (Ìṣípayá 7:9-15) Nínú àyíká ọ̀rọ̀ ti ìran Ìsíkíẹ́lì, ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá ṣàpẹẹrẹ “àwọn àgùntàn mìíràn.” (Jòhánù 10:16; fi wé Lúùkù 22:28-30.) Ṣé ìwọ náà wà lára àwọn tí ń rí ìdùnnú nínú yíyin Jèhófà nípa pípòkìkí Ìjọba rẹ̀?
6. Ète wo ni àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní àgbàlá òde wà fún, àǹfààní wo tí àwọn àgùntàn mìíràn ní ni èyí sì rán wa létí lónìí?
6 Nígbà tí a dé àgbàlá òde, a rí ọgbọ̀n yàrá ìjẹun níbi tí àwọn ènìyàn ti ń jẹ ọrẹ àtinúwá wọn. (Ìsíkíẹ́lì 40:17) Lónìí, àwọn tí wọ́n jẹ́ àgùntàn mìíràn kì í fi ẹran rúbọ, ṣùgbọ́n, wọn kì í ṣánwọ́ wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà. (Fi wé Ẹ́kísódù 23:15.) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ [Jésù], ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀. Ní àfikún, ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:15, 16; Hóséà 14:2) Àǹfààní ńláǹlà ló mà jẹ́ o láti máa rú irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ sí Jèhófà.—Òwe 3:9, 27.
7. Kí ni wíwọn tẹ́ńpìlì náà mú dá wa lójú?
7 Ìsíkíẹ́lì ń wo bí áńgẹ́lì kan ṣe ń wọn tẹ́ńpìlì inú ìran yìí. (Ìsíkíẹ́lì 40:3) Bákan náà, a sọ fún àpọ́sítélì Jòhánù pé: “Dìde, kí o sì wọn ibùjọsìn tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tí ń jọ́sìn nínú rẹ̀.” (Ìṣípayá 11:1) Kí ni wíwọ̀n yìí túmọ̀ sí? Nínú ọ̀ràn méjèèjì, ẹ̀rí fi hàn pé èyí jẹ́ àmì ìdánilójú pé kò sí ohunkóhun tí ó lè dá Jèhófà dúró pé kí ó má ṣe mú àwọn ète rẹ̀ nípa ìjọsìn mímọ́ gaara ṣẹ. Bákan náà lónìí, ẹ jẹ́ kí a ní ìdánilójú pé kò sí ohunkóhun—kódà inúnibíni gbígbóná janjan pàápàá láti ọ̀dọ̀ ìjọba—tó lè ṣe ìdènà mímú ìjọsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò.
8. Àwọn wo ni wọ́n ń gba ẹnubodè tó wọnú àgbàlá inú náà, kí sì ni àwọn ẹnubodè yìí mú wa rántí?
8 Bí a ṣe ń rìn gba inú àgbàlá òde kọjá, àwa yóò rí i pé àwọn ẹnubodè mẹ́ta ni ó wọ àgbàlá inú; àwọn ẹnubodè inú náà wà ní ọ̀gangan àwọn ẹnubodè òde, wọ́n kò sì tóbi jura lọ. (Ìsíkíẹ́lì 40:6, 20, 23, 24, 27) Àwọn àlùfáà nìkan ni ó lè wọ inú àgbàlá inú náà. Àwọn ẹnubodè inú náà rán wa létí pé àwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n àti òfin Ọlọ́run, àmọ́ ṣá o, ọ̀pá ìdiwọ̀n àti òfin kan náà yìí ni a ń retí pé kí gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ tẹ̀ lé. Ṣùgbọ́n, kí ni iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí ló sì túmọ̀ sí lónìí?
Ẹgbẹ́ Àlùfáà Olóòótọ́
9, 10. Báwo ni “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” ṣe pèsè ìtọ́ni nípa tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àlùfáà tí a rí nínú ìran Ìsíkíẹ́lì ti ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?
9 Ṣáájú ìgbà Kristẹni, àwọn àlùfáà máa ń ṣe iṣẹ́ àṣekára nínú tẹ́ńpìlì. Dídúnbú ẹran ìrúbọ, fífi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ, sísin àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn náà kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Ṣùgbọ́n wọ́n ní iṣẹ́ pàtàkì mìíràn tí wọ́n ń ṣe. Jèhófà pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé: “Kí wọ́n . . . fún àwọn ènìyàn mi ní ìtọ́ni nípa ìyàtọ̀ láàárín ohun mímọ́ àti ohun tí a ti sọ di àìmọ́; kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tí ó mọ́.”—Ìsíkíẹ́lì 44:23; Málákì 2:7.
10 Ìwọ ha mọrírì iṣẹ́ àṣekára àti iṣẹ́ ìsìn onírẹ̀lẹ̀ tí àwọn ẹni àmì òróró, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé,” ń ṣe nítorí ìjọsìn mímọ́ gaara? (1 Pétérù 2:9) Gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà ọmọ Léfì ìgbàanì, wọ́n ti mú ipò iwájú nínú fífúnni ní ìtọ́ni nípa tẹ̀mí, nípa ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ó mọ́, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run àti ohun tí kò ṣètẹ́wọ́gbà. (Mátíù 24:45) Irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀, tí ń wá láti inú àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì àti àwọn ìpàdé àti àpéjọpọ̀ Kristẹni, ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti di ẹni tí a mú padà bá Ọlọ́run rẹ́.—2 Kọ́ríńtì 5:20.
11. (a) Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwà tí àwọn àlùfáà gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́? (b) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, báwo ni a ti ṣe wẹ àwọn ẹni àmì òróró mọ́ nípa tẹ̀mí?
11 Ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà gbọ́dọ̀ ṣe ju kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn láti jẹ́ mímọ́; àwọn fúnra wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. Nípa báyìí, Ìsíkíẹ́lì rí àrítẹ́lẹ̀ ọ̀nà tí a óò gbà yọ́ àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì mọ́. (Ìsíkíẹ́lì 44:10-16) Bákan náà, ìtàn fi hàn pé ní ọdún 1918, Jèhófà jókòó gẹ́gẹ́ ‘bí ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́’ nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tẹ̀mí, ó ṣàyẹ̀wò ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ẹni àmì òróró. (Málákì 3:1-5) Àwọn tó rí i pé wọ́n mọ́ nípa tẹ̀mí tàbí tí wọ́n ti ronú pìwà dà nínú ìbọ̀rìṣà tí wọ́n ti lọ́wọ́ sí tẹ́lẹ̀, ni ó yọ̀ǹda fún láti máa bá àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wọn lọ nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tẹ̀mí. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni mìíràn, ẹnì kan nínú àwọn ẹni àmì òróró lè di aláìmọ́—nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà rere. (Ìsíkíẹ́lì 44:22, 25-27) Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti wà “láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27; fi wé Máàkù 7:20-23.
12. Èé ṣe tó fi yẹ kí a mọrírì iṣẹ́ àwọn ẹni àmì òróró?
12 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ mo mọrírì àpẹẹrẹ tí àwọn ẹni àmì òróró fi lélẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n fi òótọ́ ṣe? Ǹjẹ́ mo ń fara wé ìgbàgbọ́ wọn?’ Ó dára kí ogunlọ́gọ̀ ńlá máa rántí pé àwọn ẹni àmì òróró kì yóò wà pẹ̀lú wọn títí láé níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà sọ nípa àwọn àlùfáà inú ìran Ìsíkíẹ́lì pé: “Ẹ kò . . . gbọ́dọ̀ fún wọn ní ohun ìní [ilẹ̀] kankan ní Ísírẹ́lì: Èmi ni ohun ìní wọn.” (Ìsíkíẹ́lì 44:28) Bákan náà, àwọn ẹni àmì òróró kò ní ibi tí yóò jẹ́ tiwọn títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀run ni ogún wọn, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá sì kà á sí àǹfààní láti kọ́wọ́ tì wọ́n, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí nísinsìnyí tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 25:34-40; 1 Pétérù 1:3, 4.
Ìjòyè Náà—Ta Ló Dúró Fún?
13, 14. (a) Èé ṣe tí ìjòyè náà fi ní láti jẹ́ ara àwọn àgùntàn mìíràn? (b) Àwọn wo ni ìjòyè ń ṣàpẹẹrẹ?
13 Wàyí o, ìbéèrè kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra jẹyọ. Ta wá ni ìjòyè dúró fún? Níwọ̀n bí a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, a lè gbà pé ó dúró fún ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn kan. (Ìsíkíẹ́lì 44:3; 45:8, 9) Ṣùgbọ́n, ta ni òun í ṣe? Ó dájú pé kì í ṣe àwọn ẹni àmì òróró. Nínú ìran náà, ó ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn àlùfáà, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀kan lára wọn. Láìdàbí ẹgbẹ́ àlùfáà, a fún un ní ogún nínú ilẹ̀ náà, ó sì fojú sọ́nà láti wà lórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe ní ọ̀run. (Ìsíkíẹ́lì 48:21) Síwájú sí i, Ìsíkíẹ́lì 46:10 sọ pé: “Ní ti ìjòyè àárín wọn, nígbà tí wọ́n [àwọn ẹ̀yà tí kì í ṣe àlùfáà] bá wọlé [sí àgbàlá òde tẹ́ńpìlì], ni kí ó wọlé; nígbà tí wọ́n bá sì jáde, ni kí ó jáde.” Òun kì í wọ àgbàlá inú, àgbàlá òde ló ti máa ń jọ́sìn, ó máa ń bá àwọn ènìyàn wọnú tẹ́ńpìlì, ó sì ń bá wọn jáde. Láìsí àní-àní, àwọn kókó wọ̀nyí fi hàn pé ìjòyè náà jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn.
14 Ní kedere, ìjòyè yìí ní ẹrù iṣẹ́ mélòó kan láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ní àgbàlá òde, ó máa ń jókòó ní gọ̀bì Ẹnubodè Ìlà-Oòrùn. (Ìsíkíẹ́lì 44:2, 3) Èyí fi ipò àbójútó hàn, tí ó jọ ti àwọn àgbà ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, àwọn tí ó máa ń jókòó ní ẹnubodè ìlú ńlá náà, tí wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́. (Rúùtù 4:1-12; Òwe 22:22) Àwọn wo lára àwọn àgùntàn mìíràn ni a fún ní ipò àbójútó lónìí? Àwọn alàgbà tí a fi ẹ̀mí yàn tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé ni. (Ìṣe 20:28) Nítorí náà, a ti ń múra ẹgbẹ́ ìjòyè yìí sílẹ̀ pẹ̀lú ìrètí sísìn nínú ipò ìṣàbójútó nínú ayé tuntun lọ́jọ́ iwájú.
15. (a) Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe túbọ̀ jẹ́ kí a lóye ìbátan tó wà láàárín àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá àti ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró? (b) Ipò iwájú wo ni àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ti mú nínú ètò àjọ Ọlọ́run ti ilẹ̀ ayé?
15 Àmọ́, kí ni ìbátan tí ó wà láàárín ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn ẹni àmì òróró àti irú àwọn àgbà ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lónìí, àwọn àgbà wọ̀nyí tí í ṣe ara ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń sìn ní ipò àbójútó? Ìran Ìsíkíẹ́lì fi hàn pé àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ogunlọ́gọ̀ ńlá ń kó ipa ìtìlẹyìn àti ti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́, nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró ń mú ipò iwájú nípa tẹ̀mí. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀? Rántí pé, àwọn àlùfáà inú ìran yìí ni a fún ní ẹrù iṣẹ́ láti fún àwọn ènìyàn ní ìtọ́ni nínú àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. A tún sọ pé kí wọ́n jẹ́ onídàájọ́ nínú àwọn ọ̀ràn òfin. Ní àfikún sí èyí, a yan àwọn ọmọ Léfì sí ibi “iṣẹ́ àbójútó” ní àwọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì náà. (Ìsíkíẹ́lì 44:11, 23, 24) Ní kedere, ìjòyè náà yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ iṣẹ́ ìsìn nípa tẹ̀mí àti ipò aṣáájú àwọn àlùfáà. Nígbà náà, ó bá a mu ni àwọn àkókò òde òní pé àwọn ẹni àmì òróró ti mú ipò iwájú nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwọn ẹni àmì òróró ni a ti yan àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Irú àwọn alàgbà olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ti ń dá ẹgbẹ́ ìjòyè tí ń pọ̀ sí i lẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, wọ́n ń múra àwọn tí yóò jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ fún ọjọ́ náà nígbà tí a óò fún wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọlá àṣẹ wọn nínú ayé tuntun Ọlọ́run tí ń bọ̀.
16. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 32:1, 2, ti sọ, báwo ni gbogbo alàgbà ṣe gbọ́dọ̀ máa hùwà?
16 Irú alábòójútó wo ni àwọn tí yóò di mẹ́ńbà ẹgbẹ́ yìí yóò jẹ́, àwọn tí a óò fún ní ẹrù iṣẹ́ gbígbòòrò sí i gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ìjòyè? Àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Aísáyà 32:1, 2 sọ pé: “Wò ó! Ọba kan yóò jẹ fún òdodo; àti ní ti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo. Olúkúlùkù yóò sì wá dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ní ìmúṣẹ lónìí, ní ti pé gbogbo àwọn Kristẹni alàgbà—ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn mìíràn—ń ṣiṣẹ́ láti dáàbò bo agbo kúrò lọ́wọ́ irú ‘àwọn ìjì òjò’ bí inúnibíni àti ìrẹ̀wẹ̀sì.
17. Ojú wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn fi wo ara wọn, ojú wo ló sì yẹ kí agbo fi máa wò wọ́n?
17 Àwọn ọ̀rọ̀ náà, “ọmọ aládé” àti “ìjòyè,” tí ìtumọ̀ wọn jọra ní èdè Hébérù, ni a kò lò gẹ́gẹ́ bí àpèlé tí a yàn láti gbé àwọn ènìyàn ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣàpèjúwe ẹrù iṣẹ́ tí a retí pé kí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣe ní bíbójútó àwọn àgùntàn Ọlọ́run. Jèhófà kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ pé: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín, ẹ̀yin ìjòyè Ísírẹ́lì! Ẹ mú ìwà ipá àti ìfiṣèjẹ kúrò, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo pàápàá.” (Ìsíkíẹ́lì 45:9) Ó yẹ kí gbogbo alàgbà lónìí fi irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ sọ́kàn. (1 Pétérù 5:2, 3) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, agbo náà mọ̀ pé Jésù pèsè àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” (Éfésù 4:8) Àwọn ànímọ́ tó mú wọn tóótun ni a là sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí. (1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:5-9) Nítorí náà, àwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé ìdarí àwọn alàgbà.—Hébérù 13:7.
18. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹrù iṣẹ́ àwọn tí yóò di ẹgbẹ́ ìjòyè náà, kí sì ni yóò jẹ́ ẹrù iṣẹ́ wọn ní ọjọ́ iwájú?
18 Nígbà tí a kọ Bíbélì, àwọn ìjòyè kan ní ọlá àṣẹ tí ó pọ̀, ti àwọn mìíràn kò pọ̀. Lónìí, àwọn alàgbà nínú ogunlọ́gọ̀ ńlá ní àwọn ẹrù iṣẹ́ tí ó yàtọ̀ síra gan-an. Àwọn kan ń sìn nínú ìjọ kan ṣoṣo; àwọn mìíràn ń sin ìjọ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò; àwọn mìíràn ń sin odindi orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka; àwọn mìíràn ń ṣèrànwọ́ ní tààrà fún onírúurú ìgbìmọ̀ tí ó jẹ́ ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Nínú ayé tuntun, Jésù yóò yan àwọn “olórí ní gbogbo ilẹ̀ ayé” láti mú ipò iwájú láàárín àwọn olùjọsìn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 45:16) Láìsí àní-àní, lára àwọn alàgbà olùṣòtítọ́ tó wà lónìí ni Jésù yóò ti yan púpọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí. Nítorí pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń fi hàn nísinsìnyí pé àwọn kò kẹ̀rẹ̀, òun yóò fẹ́ láti fi àwọn ẹrù iṣẹ́ tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá lé ọ̀pọ̀ nínú wọn lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú nígbà tí ó bá ṣí ipa tí ẹgbẹ́ ìjòye náà yóò kó nínú ayé tuntun payá.
Ilẹ̀ Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run Lónìí
19. Kí ni ilẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran rẹ̀ dúró fún?
19 Ìran Ìsíkíẹ́lì tún fi ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí a mú padà bọ̀ sípò hàn. Kí ni apá yìí nínú ìran náà dúró fún? Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn nípa ìmúpadàbọ̀sípò sọ pé ilẹ̀ náà, Ísírẹ́lì, yóò di Párádísè gẹ́gẹ́ bí Édẹ́nì. (Ìsíkíẹ́lì 36:34, 35) Lónìí, a ń gbádùn ilẹ̀ tí a ti mú padà bọ̀ sípò, òun pẹ̀lú ni a lè sọ pé ó dà bí Édẹ́nì. Lọ́nà kan náà, a sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa párádísè wa nípa tẹ̀mí. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti túmọ̀ “ilẹ̀” wa gẹ́gẹ́ bí “ilẹ̀ àkóso ìgbòkègbodò” àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run yàn.b Ibi yòówù kí ìránṣẹ́ Jèhófà wà, ó wà nínú ilẹ̀ tí a mú padà bọ̀ sípò yẹn níwọ̀n ìgbà tí ó bá ń sapá láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ nípa títọpasẹ̀ Kristi Jésù.—1 Pétérù 2:21.
20. Ìlànà wo ni a lè rí kọ́ láti inú “ọrẹ mímọ́” tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran rẹ̀, báwo sì ni a ṣe lè fi ìlànà yìí sílò?
20 Apá kan ilẹ̀ náà tí a pè ní “ọrẹ mímọ́” ńkọ́? Èyí ni ọrẹ tí àwọn ènìyàn náà ṣe fún ìtìlẹ́yìn iṣẹ́ àlùfáà àti ìlú ńlá náà. Bákan náà, “gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà” yóò fi ìpín kan nínú ilẹ̀ wọn ta ìjòyè lọ́rẹ. Kí ni èyí túmọ̀ sí lónìí? Dájúdájú, kì í ṣe pé a óò fi ẹgbẹ́ àlùfáà tí ń gbowó oṣù dẹrù pa àwọn ènìyàn Ọlọ́run. (2 Tẹsalóníkà 3:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìtìlẹyìn tí a ń fún àwọn alàgbà lónìí ní pàtàkì jẹ́ tẹ̀mí. Ó ní nínú, ṣíṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ tí a ń ṣe lọ́wọ́ àti fífi ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ti ìtẹríba hàn. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ní ọjọ́ Ìsíkíẹ́lì, “Jèhófà,” ni a ń mú ọrẹ yìí wá fún, kì í ṣe ènìyàn èyíkéyìí.—Ìsíkíẹ́lì. 45:1, 7, 16.
21. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ láti inú bí a ṣe pín ilẹ̀ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí?
21 Kì í ṣe ìjòyè àti àwọn àlùfáà nìkan ni ó ní àyè tí a yàn fún wọn nínú ilẹ̀ tí a mú padà bọ̀ sípò yìí. Bí a ṣe pín ilẹ̀ náà fi hàn pé ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà méjèèjìlá ló ní ogún kan tí ó dájú. (Ìsíkíẹ́lì 47:13, 22, 23) Nítorí náà, kì í ṣe pé àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ní àyè kan nínú párádísè tẹ̀mí tòní nìkan ni, ṣùgbọ́n a óò tún yan ilẹ̀ fún wọn nígbà tí wọ́n bá jogún àyè kan nínú àgbègbè àkóso Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.
22. (a) Kí ni ìlú ńlá inú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí dúró fún? (b) Kí la lè rí kọ́ láti inú pé ìlú ńlá náà ní àwọn ẹnubodè ní gbogbo ìhà rẹ̀?
22 Lákòótán, kí ni ìlú ńlá tí ó wà nínú ìran náà dúró fún? Kì í ṣe ìlú ńlá kan tí ń bẹ ní ọ̀run, nítorí ó wà ní àárín ilẹ̀ “tí a sọ di àìmọ́.” (Ìsíkíẹ́lì 48:15-17) Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ ohun kan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé. Tóò, kí ni ìlú ńlá jẹ́? Kò ha fúnni ní èrò nípa àwọn ènìyàn tí ó kóra jọ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, tí wọ́n gbé ohun kan tí a wéwèé tí a sì ṣètò kalẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Nítorí náà, ó dà bí ẹni pé ìlú ńlá náà ń ṣàpẹẹrẹ ìṣètò lórí ilẹ̀ ayé, tí ó ń mú àǹfààní wá fún gbogbo àwọn tí ó para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn olódodo lórí ilẹ̀ ayé. Yóò ṣiṣẹ́ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú “ilẹ̀ ayé tuntun” tí ń bọ̀. (2 Pétérù 3:13) Àwọn ẹnubodè tó wà ní gbogbo ìhà ìlú ńlá náà, ọ̀kan fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, jẹ́ àkàwé tí ó ṣe kedere pé àyè wà fún ẹni tó bá fẹ́ wọ inú ìlú ńlá náà. Lónìí, àwọn ènìyàn Ọlọ́run kò sí lábẹ́ ètò ìmùlẹ̀ kan tí à ń yọ́ ṣe. Àwọn arákùnrin táa fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́; àwọn ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé sì hàn sí gbogbo gbòò. Òtítọ́ náà pé àwọn ènìyàn láti inú gbogbo ẹ̀yà ni ó ń ro ilẹ̀ tí a fi ń ṣètìlẹyìn fún ìlú ńlá náà rán wa létí pé àwọn àgùntàn mìíràn, àní nípa ohun ìní ti ara pàápàá, ń ṣètìlẹyìn fún àwọn ìṣètò tí ó wà fún ènìyàn Ọlọ́run kárí ayé.—Ìsíkíẹ́lì 48:19, 30-34.
23. Kí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
23 Ṣùgbọ́n, odò tí ń ṣàn láti inú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì náà ńkọ́? Ohun tí ìyẹn dúró fún lónìí àti ní ọjọ́ iwájú ni yóò jẹ́ kókó tí a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ kẹta, tí yóò jẹ́ èyí tó parí ọ̀wọ́ yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé náà Revelation—Its Grand Climax At Hand!, ojú ìwé 64, ìpínrọ̀ 22, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde
Àwọn Kókó Àtúnyẹ̀wò
◻ Kí ni tẹ́ńpìlì tó wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ń ṣàpẹẹrẹ?
◻ Àwọn wo ni àwọn àlùfáà tí wọ́n ń sìn nínú tẹ́ńpìlì náà ń ṣàpẹẹrẹ?
◻ Àwọn wo ni ẹgbẹ́ ìjòyè náà, kí sì ni díẹ̀ lára ẹrù iṣẹ́ wọn?
◻ Kí ni ilẹ̀ tó wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ọ̀nà wo sì ni a gbà pín in fún àwọn ẹ̀yà méjìlá?
◻ Kí ni ìlú ńlá náà ń ṣàpẹẹrẹ?
[Àwòrán/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Pípín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí
Ẹ̀YÀ MÉJÌLÁ
Òkun Ńlá
Òkun Gálílì
Odò Jọ́dánì
Òkun Iyọ̀
DÁNÌ
ÁṢÉRÌ
NÁFÚTÁLÌ
MÁNÁSÈ
ÉFÚRÁÍMÙ
RÚBẸ́NÌ
JÚDÀ
ÌJÒYÈ
BẸ́ŃJÁMÍNÌ
SÍMÉÓNÌ
ÍSÁKÁRÌ
SÉBÚLÓNÌ
GÁÀDÌ
[Àwòrán]
MÍMÚ ILẸ̀ ỌRẸ MÍMỌ́ GBÒÒRÒ SÍ I
A. “Jèhófà Alára Wà Níbẹ̀” (Jèhófà-Ṣamá); B. Ilẹ̀ ìlú ńlá náà tí ń méso jáde
Ìpín ti Àwọn Ọmọ Léfì
Ibùjọsìn Jèhófà
Ìpín ti Àwọn Àlùfáà
B A B