-
“Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
6. (a) Ohun méjì wo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe lásìkò kan náà nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀? (b) Kí ni àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé kí ó ‘wọn irun náà, kó sì pín in’ jẹ́ ká mọ̀?
6 Ìparun Jerúsálẹ́mù àtàwọn èèyàn rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, ohun méjì ni Ìsíkíẹ́lì ṣe lásìkò kan náà nínú àṣefihàn tó fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn. Ó kọ́kọ́ ṣàṣefihàn ohun tí Jèhófà máa ṣe. Jèhófà sọ fún un pé: “Mú idà kan tó mú kí o lè lò ó bí abẹ ìfárí.” (Ka Ìsíkíẹ́lì 5:1, 2.) Ọwọ́ tí Ìsíkíẹ́lì fi mú idà ṣàpẹẹrẹ ọwọ́ Jèhófà, ìyẹn ìdájọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun Bábílónì. Lẹ́yìn náà ni Ìsíkíẹ́lì wá ṣàṣefihàn ohun kejì, ìyẹn ohun tí ojú àwọn Júù máa rí. Jèhófà sọ fún un pé: “Fá orí rẹ àti irùngbọ̀n rẹ.” Orí tí Ìsíkíẹ́lì fá yìí ṣàpẹẹrẹ bí wọ́n ṣe máa gbógun ti àwọn Júù, tí wọ́n á sì pa wọ́n rẹ́. Bákan náà, bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un pé, “mú òṣùwọ̀n kí o lè wọn irun náà, kí o sì pín in” fi hàn pé Jèhófà máa dìídì mú ìdájọ́ wá sórí Jerúsálẹ́mù, ìdájọ́ náà kò ní yẹ̀ àti pé ó máa délé dóko.
-
-
“Fá Orí Rẹ àti Irùngbọ̀n Rẹ”Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
‘Fá Orí àti Irùngbọ̀n’
Wọ́n máa gbógun ti àwọn Júù, wọ́n sì máa pa wọ́n rẹ́
‘Wọ̀n Ọ́n, Kí O sì Pín In’
Ọlọ́run máa dìídì mú ìdájọ́ náà wá, ó sì máa délé dóko
-