-
‘Wo Iṣẹ́ Ibi Tó Ń Ríni Lára Tí Wọ́n Ń Ṣe’Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
Ohun Kẹta: “Àwọn Obìnrin . . . Tí Wọ́n Ń Sunkún Torí Ọlọ́run Tí Wọ́n Ń Pè Ní Támúsì”
13. Kí ni Ìsíkíẹ́lì rí tí àwọn obìnrin tó di apẹ̀yìndà ń ṣe ní ọ̀kan lára àwọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì?
13 Ka Ìsíkíẹ́lì 8:13, 14. Lẹ́yìn ohun méjì tó ń kóni nírìíra tí Ìsíkíẹ́lì rí yẹn, Jèhófà tún sọ fún un pé: “Wàá rí àwọn ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ń ṣe tó tún burú ju èyí lọ.” Kí ni wòlíì yẹn wá rí lẹ́yìn náà? Ní ‘ẹnubodè àríwá ilé Jèhófà,’ ó rí ‘àwọn obìnrin tí wọ́n jókòó, tí wọ́n ń sunkún torí ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Támúsì.’ Òrìṣà ilẹ̀ Mesopotámíà ni Támúsì, wọ́n sì tún pè é ní Dúmúsì nínú ìwé àwọn ará ilẹ̀ Súmà. Wọ́n gbà pé òun ni olólùfẹ́ abo òrìṣà ìbímọlémọ tí wọ́n ń pè ní Íṣítà.d Ó ṣe kedere pé ẹkún tí àwọn obìnrin Ísírẹ́lì ń sun yìí wà lára àwọn ààtò ìbọ̀rìṣà tó jẹ mọ́ ikú Támúsì. Bí àwọn obìnrin yìí ṣe ń sunkún nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà torí Támúsì, ààtò ìbọ̀rìṣà àwọn kèfèrí ni wọ́n ń ṣe níbi tó yẹ kí wọ́n ti máa ṣe ìjọsìn mímọ́. Ti pé wọ́n ń ṣe ìjọsìn èké nínú tẹ́ńpìlì Ọlọrun ò sọ pé kí Ọlọ́run fọwọ́ sí ìjọsìn wọn. Ẹ ò rí i pé ohun “tó ń ríni lára” làwọn obìnrin tí wọ́n di apẹ̀yìndà yìí ń ṣe lójú Jèhófà!
14. Kí la rí kọ́ látinú ojú tí Jèhófà fi wo ohun táwọn obìnrin tó di apẹ̀yìndà yẹn ń ṣe?
14 Kí la rí kọ́ látinú ojú tí Jèhófà fi wo ohun táwọn obìnrin yẹn ń ṣe? Kí ìjọsìn wa lè máa wà ní mímọ́, a ò gbọ́dọ̀ dà á pọ̀ mọ́ àwọn àṣà kèfèrí tó ń kóni nírìíra. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ayẹyẹ tó wá látinú ẹ̀sìn èké. Ṣé ibi tí nǹkan ti pilẹ̀ tiẹ̀ ṣe pàtàkì rárá? Bẹ́ẹ̀ ni! Lóde òní, àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe nígbà àwọn ayẹyẹ bíi Kérésìmesì àti Ọdún Àjíǹde lè dà bí ohun tí kò burú. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ rí àwọn àṣà ẹ̀sìn èké tí wọ́n sọ di àwọn ayẹyẹ òde òní. Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gba àwọn àṣà ẹ̀sìn èké kìkì nítorí pé àwọn èèyàn ti ń ṣe é tipẹ́ tàbí torí pé wọ́n ń gbìyànjú láti dà á pọ̀ mọ́ ìjọsìn mímọ́.—2 Kọ́r. 6:17; Ìfi. 18:2, 4.
-