Ẹ Ṣọra fun Gbogbo Oniruuru Ibọriṣa
“Irẹpọ ki ni tẹmpili Ọlọrun sì ni pẹlu oriṣa?”—2 KORINTI 6:16.
1. Ki ni ohun ti agọ-isin ati awọn tẹmpili Israeli jẹ́ apẹẹrẹ fun?
JEHOFA ní tẹmpili kan ti kìí ṣe ile awọn oriṣa. Eyi ni agọ-isin Israeli ti Mose kọ́ ati awọn tẹmpili ti a kọ́ lẹhin naa ni Jerusalemu jẹ́ apẹẹrẹ fun. Awọn ile ti a gbekalẹ wọnyẹn ṣoju fun “agọ tootọ,” tẹmpili tẹmi nla ti Jehofa. (Heberu 8:1-5) Tẹmpili yẹn ni iṣeto fun títọ Ọlọrun lọ ninu ijọsin lori ipilẹ ẹbọ irapada Jesu Kristi.—Heberu 9:2-10, 23.
2. Ta ni o di ọwọ̀n ninu tẹmpili nla tẹmi Ọlọrun, ipo wo sì ni awọn ogunlọgọ nla ń gbadun?
2 Awọn Kristian ẹni-ami-ororo kọọkan di “ọwọ̀n ninu tẹmpili [Ọlọrun],” ni gbigba aaye ninu ọrun. “Awọn ogunlọgọ nla” (NW) ti awọn olujọsin Jehofa miiran ń “sin [Ọlọrun]” ninu ohun ti agbala awọn Keferi ṣoju fun ninu tẹmpili ti Herodu tún kọ́. Nitori igbagbọ ninu ẹbọ Jesu, wọn ni iduro ododo eyi ti ń yọrisi ipamọ la “ipọnju nla” já.—Ìfihàn 3:12; 7:9-15.
3, 4. Ki ni a fi ijọ awọn Kristian ẹni-ami-ororo lori ilẹ̀-ayé wé, isọdẹgbin wo ni kò sì gbọdọ si ninu rẹ̀?
3 Ijọ awọn Kristian ẹni-ami-ororo lori ilẹ̀-ayé lọna iṣapẹẹrẹ ni a fiwe tẹmpili miiran ti o wà laisi ibọriṣa. Si iru awọn ẹni bẹẹ ‘ti a fi ẹmi mimọ ṣe edidi wọn,’ aposteli Paulu sọ wi pe: “A sì ń gbe yin ró lori ipilẹ awọn aposteli, ati awọn wolii, Jesu Kristi tikaraarẹ jẹ pataki okuta igun ile; ninu ẹni ti gbogbo ile naa, ti a ń kọ́ ṣọ̀kan pọ̀, ń dagba soke ni tẹmpili mimọ ninu Oluwa: ninu ẹni ti a ń gbe yin ró pọ pẹlu fun ibujokoo Ọlọrun ninu ẹmi.” (Efesu 1:13; 2:20-22) Awọn 144,000 ti a fi edidi di wọnyi jẹ́ “okuta ààyè” ti a “kọ́ ni ile ẹmi, alufaa mimọ.”—1 Peteru 2:5; Ìfihàn 7:4; 14:1.
4 Niwọn bi awọn alufaa ọmọ-abẹ wọnyi ti jẹ “ile Ọlọrun,” oun kò fààyè gba tẹmpili yii lati di eyi ti a sọ di alaimọ. (1 Korinti 3:9, 16, 17) “Ẹ maṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ,” ni Paulu kilọ. “Nitori idapọ ki ni ododo ni pẹlu aiṣododo? Idapọ ki ni ìmọ́lẹ̀ sì ni pẹlu òkùnkùn? Irẹpọ ki ni Kristi sì ni pẹlu Beliali? Tabi ipin wo ni ẹni ti o gbagbọ ni pẹlu alaigbagbọ? Irẹpọ ki ni tẹmpili Ọlọrun sì ni pẹlu oriṣa?” Awọn Kristian ẹni-ami-ororo, ti wọn jẹ ti “Oluwa Olodumare,” gbọdọ wà lominira kuro ninu ibọriṣa. (2 Korinti 6:14-18) Awọn wọnni ti wọn jẹ́ ti ogunlọgọ nla bakan naa gbọdọ yẹra fun gbogbo oniruuru ibọriṣa.
5. Ni mímọ̀ pe Jehofa lẹtọọ si ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé, ki ni awọn Kristian tootọ ń ṣe?
5 Iru-oriṣi ibọriṣa paraku ati ti ọlọgbọn-ẹwẹ ni o wà. Bẹẹkọ, ibọriṣa ni a kò fimọ si jijọsin awọn ọlọrun ati abo-ọlọrun èké nikan. O jẹ́ ijọsin ohunkohun tabi ẹnikẹni yatọ si Jehofa. Gẹgẹ bi Ọba-alaṣẹ Agbaye, oun fi ẹ̀tọ́ beere o sì lẹtọọ si ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé. (Deuteronomi 4:24) Ni mímọ eyi, awọn Kristian tootọ ń ṣegbọran si ikilọ Iwe Mimọ lodisi gbogbo ibọriṣa. (1 Korinti 10:7) Ẹ jẹ ki a ṣayẹwo irú awọn ibọriṣa pato kan ti awọn iranṣẹ Jehofa nilati yẹra fun.
Ibọriṣa Kristẹndọm Ní Apẹẹrẹ Iṣaaju
6. Awọn ohun irira wo ni Esekieli ri ninu iran?
6 Nigba ti o wà ni igbekun awọn ara Babiloni ni 612 B.C.E., wolii Esekieli ri iran awọn nǹkan ẹlẹgbin tí awọn Ju apẹhinda ń ṣe bi àṣà ni tẹmpili Jehofa ni Jerusalemu. Esekieli ri “ère owú” kan. Awọn 70 àgbà [ọkunrin] ni a ṣakiyesi ti wọn ń rubọ turari ninu tẹmpili naa. Awọn obinrin ni a ri ti wọn ń sunkun lori ọlọrun èké. Awọn ọkunrin 25 sì ń jọsin oòrùn. Ijẹpataki wo ni awọn àṣà ipẹhinda wọnyi ni?
7, 8. “Ère owú” naa lè ti jẹ́ ki ni, eesitiṣe ti o fi ru Jehofa soke si owú?
7 Ibọriṣa Kristẹndọm ni awọn nǹkan ẹlẹgbin ti Esekieli ri ninu iran jẹ́ apẹẹrẹ iṣaaju fun. Fun apẹẹrẹ, o sọ pe: “Sì kiyesi i, ère owú yii niha ariwa ní atiwọle ọ̀nà pẹpẹ. Pẹlupẹlu [Jehofa Ọlọrun] wi fun mi pe, Ọmọ eniyan, iwọ ri ohun ti wọn ń ṣe? Àní irira nla ti ile Israeli ń ṣe nihin-in yii, ki emi baà lè lọ jinna kuro ni ibi mimọ mi?”—Esekieli 8:1-6.
8 Ère owú ibọriṣa naa ti lè jẹ́ òpó mímọ́ kan ti ń ṣoju fun abo-ọlọrun èké ti awọn ara Kenaani wò gẹgẹ bi aya Baali ọlọrun wọn. Ohun yoowu ki ère naa jẹ́, o ru Jehofa si owú nitori pe o pín ifọkansin Israeli ti a yasọtọ gédégbé si i níyà ni rírú awọn ofin rẹ̀ pe: “Emi ni OLUWA Ọlọrun rẹ . . . Iwọ kò gbọdọ ni Ọlọrun miiran pẹlu mi. Iwọ kò gbọdọ yá ère fun araarẹ, tabi aworan ohun kan ti ń bẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti ń bẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti ń bẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ. Iwọ kò gbọdọ tẹ ori araarẹ ba fun wọn, bẹẹ ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi.”—Eksodu 20:2-5.
9. Bawo ni Kristẹndọm ṣe ru Ọlọrun si owú?
9 Jijọsin ère owú ninu tẹmpili Ọlọrun jẹ ọ̀kan ninu awọn ohun irira titobi ti awọn ọmọ Israeli apẹhinda ṣe. Bakan naa, awọn ṣọọṣi Kristẹndọm ni a sọdẹlẹgbin pẹlu awọn ami iṣapẹẹrẹ ati ère alaibọla fun Ọlọrun ti o pín ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé ti wọn jẹwọ pe awọn ń fun Ẹni naa ti wọn jẹwọ pe awọn ń sin niya. Ọlọrun ni a rusoke si owú bakan naa nitori pe awọn alufaa kọ Ijọba rẹ̀ silẹ gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun iran eniyan ti wọn sì sọ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede di oriṣa.—‘ohun irira ti o duro ni ibi mimọ,’ nibi ti kò ti yẹ ki o duro.—Matteu 24:15, 16; Marku 13:14.
10. Ki ni Esekieli ri ninu tẹmpili, bawo sì ni eyi ṣe jọra pẹlu ohun ti a ṣakiyesi ninu Kristẹndọm?
10 Ni wiwọ tẹmpili naa, Esekieli rohin pe: “Si kiyesi i, gbogbo aworan ohun ti ń rako, ati ẹranko irira, ati gbogbo oriṣa ile Israeli ni a yà ni aworan lara ogiri yikaakiri. Aadọrin ọkunrin ninu awọn agba ile Israeli sì duro niwaju wọn . . . olukuluku pẹlu àwo turari lọwọ rẹ̀; eefin ṣiṣududu ti turari sì goke lọ.” Ṣáà rò ó wò na! Awọn agbaagba Israeli ninu tẹmpili Jehofa ń sun turari si awọn ọlọrun èké, eyi ti awọn ère fínfín ara ogiri ṣoju fun. (Esekieli 8:10-12) Ni ifiwera, ẹyẹ ati awọn ẹranko ẹhanna ni a ń lò lati ṣapẹẹrẹ awọn orilẹ-ede Kristẹndọm, eyi ti awọn eniyan ń fun ni ifọkansin. Siwaju sii, ọpọ ninu awọn alufaa ni wọn jẹbi ṣiṣeranwọ lati ṣi awọn eniyan lọna nipa ṣiṣe agbẹnusọ fun aba-ero-ori òdì ti ẹfoluṣọn pé eniyan wá lati ara ẹ̀yà oriṣiriṣi ẹranko, ti ó rẹlẹ si ẹ̀dá eniyan dipo didi akọsilẹ Bibeli tootọ nipa iṣẹda lati ọwọ Jehofa Ọlọrun mú.—Iṣe 17:24-28.
11. Eeṣe ti awọn apẹhinda obinrin Israeli fi ń sọkun lé Tamusi lori?
11 Ni abawọle ẹnu-ọna ile Jehofa, Esekieli rí awọn apẹhinda obinrin Israeli ti wọn ń sunkun lé Tamusi lori. (Esekieli 8:13, 14) Awọn ará Babiloni ati Siria wo Tamusi gẹgẹ bi ọlọrun eweko eyi ti ń hù ni akoko ojo ti o sì ń kú ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Iku eweko naa ṣapẹẹrẹ iku Tamusi, eyi ti awọn olujọsin rẹ̀ ń pohùnréré ẹkún lé lori ni akoko ooru ti o ga julọ. Pẹlu ipadafarahan eweko ni ìgbà ojo, Tamusi ni awọn kan tànmọ́ọ̀ pe o pada lati ayé abẹ ilẹ. Oun ni wọn fi lẹta ibẹrẹ orukọ rẹ̀ ṣoju fun, tau igbaani eyi ti o jẹ́ iru-oriṣi agbelebuu kan. Eyi lè rán wa leti daradara ọ̀wọ̀ ńlá onibọriṣa ti Kristẹndọm ni fun agbelebuu.
12. Ki ni Esekieli ri ti awọn apẹhinda ọkunrin Israeli 25 ń ṣe, iru igbesẹ ti o jọra wo ni o si ń ṣẹlẹ ninu Kristẹndọm?
12 Tẹle eyi, ninu agbala tẹmpili ti o wà ninu, Esekieli rí awọn ọkunrin apẹhinda ọmọ Israeli 25 ti wọn ń jọsin oòrùn—itapa si àṣẹ Jehofa lodisi iru ibọriṣa bẹẹ. (Deuteronomi 4:15-19) Awọn abọriṣa wọnyẹn tun na ẹ̀ka igi iṣaata kan, boya ti ń ṣoju fun ẹya ara ọkunrin, si imu Ọlọrun. Abajọ ti Ọlọrun kò fi ni dahun adura wọn, àní bi Kristẹndọm paapaa yoo ṣe wá iranlọwọ rẹ̀ lori asán nigba “ipọnju nla.” (Matteu 24:21) Bi awọn apẹhinda ọmọ Israeli wọnyẹn ṣe jọsin oòrùn afunni ni ìmọ́lẹ̀ ni dídẹ̀hìn wọn kọ tẹmpili Jehofa, bẹẹ ni Kristẹndọm ṣe kọ ẹhin rẹ̀ si ìmọ́lẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, ti ó ń kọni ni awọn ẹkọ isin èké, ti ó sì ń sọ ọgbọn ayé di oriṣa, ti ó sì ń foju pa iwapalapala rẹ́.—Esekieli 8:15-18.
13. Ni awọn ọ̀nà wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbà ń yẹra fun iru-oriṣi ibọriṣa ti a ri ninu iran Esekieli?
13 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń yẹra fun iru awọn ibọriṣa ti a ń ṣe ni Kristẹndọm, tabi Jerusalemu amapẹẹrẹṣẹ, gẹgẹ bi Esekieli ti ri i tẹlẹ. A kò sọ awọn ère alaibọla fun Ọlọrun doriṣa. Bi o tilẹ jẹ pe a fi ọ̀wọ̀ fun awọn ‘alaṣẹ giga’ ti ijọba, itẹriba wa fun wọn ni ààlà. (Romu 13:1-7; Marku 12:17; Iṣe 5:29) Gbogbo ọkan-aya wa patapata ni a ń fifun Ọlọrun ati Ijọba rẹ̀. A kìí fi abá-èrò-orí ẹfoluṣọn rọpo Ẹlẹdaa ati iṣẹda rẹ̀. (Ìfihàn 4:11) Awa ko jẹ juba agbelebuu tabi ki a sọ ọgbọn ironu wọnyẹn, imọ-ọran, tabi iru awọn ọgbọn ayé miiran bẹẹ doriṣa lae. (1 Timoteu 6:20, 21) A tun ń ṣọra fun iru-oriṣi ibọriṣa miiran pẹlu. Ki ni diẹ ninu awọn wọnyi?
Iru Awọn Ibọriṣa Miiran
14. Ipo wo ni awọn iranṣẹ Jehofa mú ni ibamu pẹlu “ẹranko ẹhanna” inu Ìfihàn 13:1?
14 Awọn Kristian kìí bá awọn eniyan ṣajọpin ninu sisọ “ẹranko ẹhanna” iṣapẹẹrẹ doriṣa. Aposteli Johannu sọ pe: “Mo sì rí ẹranko kan ń ti inu òkun jade wá, o ni ori meje ati ìwo mẹwaa . . . Gbogbo awọn ti ń gbe ori ilẹ̀-ayé yoo sì maa sin in.” (Ìfihàn 13:1, 8) Awọn ẹranko ìgbẹ́ lè ṣapẹẹrẹ “awọn ọba,” tabi awọn agbara oṣelu. (Danieli 7:17; 8:3-8, 20-25) Nitori naa awọn ori meje tí ẹranko ẹhanna iṣapẹẹrẹ naa ní duro fun awọn agbara ayé—Egipti, Assiria, Babiloni, Medo-Persia, Griki, Romu, ati Anglo-American eyi ti o ni ninu Britain ati United States of America. Awọn alufaa Kristẹndọm fi àìlọ́wọ̀ ti o pẹtẹri hàn fun Ọlọrun ati Kristi nipa ṣiṣamọna araye ninu sisọ eto-igbekalẹ oṣelu Satani, “alade ayé yii” doriṣa kan. (Johannu 12:31) Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi Kristian alaidasitọtuntosi ati alágbàwí Ijọba, awọn iranṣẹ Jehofa kọ iru ibọriṣa bẹẹ silẹ.—Jakọbu 1:27.
15. Bawo ni awọn eniyan Jehofa ṣe ń wo awọn ogbontarigi ayé, ki si ni Ẹlẹ́rìí kan sọ nipa eyi?
15 Awọn eniyan Ọlọrun tun yẹra kuro ninu sisọ awọn ogbontarigi eré-ìnàjú ati ere-idaraya ayé doriṣa. Lẹhin didi Ẹlẹ́rìí Jehofa, olorin kan sọ pe: “Orin fun eré-ìnàjú ati fun jíjó lè ru ìfẹ́-ọkàn ti kò tọ́ soke . . . Oṣere naa ń kọrin nipa ayọ ati iṣepẹlẹ ti ọpọ olùgbọ́ lè nimọlara pe kò si ninu alabaagbeyawo wọn. Eléré naa ni a sábà maa ń damọyatọ pẹlu ohun ti oun ń kọrin nipa rẹ̀. Awọn akọṣẹmọṣẹ akọrin diẹ kan ti mo mọ̀ jẹ́ ààyò gidi fun awọn obinrin nitori idi yii. Gbàrà ti ẹnikan bá ti rì sinu ironu-asan ti ayé yii, ó lè ṣamọna si sisọ oṣere naa di oriṣa. Ó lè bẹrẹ lọna alaile panilara kan ṣáá nipa bibeere ti ẹnikan ń beere fun iwe ìtàn igbesi-aye kan gẹgẹ bi ohun iranti. Ṣugbọn awọn diẹ wá di ẹni ti ń wo awọn eléré naa gẹgẹ bi apẹẹrẹ pipe wọn, ati nipa fifun un ni iyì ara-ẹni ti kò tọ́ si i yii, wọn sọ ọ di oriṣa kan. Wọn lè gbé aworan eléré naa kọ́ sara ogiri ki wọn sì bẹrẹ sii maa mura ki wọn sì maa tunraṣe gẹgẹ bi oun ti ń ṣe. Awọn Kristian nilati fi si ọkàn pe ijuba jẹ ti Ọlọrun nikanṣoṣo.”
16. Ki ni o fihàn pe awọn angẹli olododo kọ ibọriṣa silẹ?
16 Bẹẹni, Ọlọrun nikanṣoṣo ni o lẹtọọ si ijuba tabi ijọsin. Nigba ti Johannu “wólẹ̀ lati foribalẹ niwaju ẹsẹ angẹli naa” ti o fi awọn nǹkan yiyanilẹnu hàn án, ẹ̀dá ẹmi yẹn kọ̀ jalẹ lati jẹ́ ẹni ti a sọ doriṣa lọna eyikeyii ṣugbọn o sọ pe: “Wò ó, ma ṣe bẹẹ: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ ni emi, ati ti awọn arakunrin rẹ wolii, ati ti awọn ti ń pa ọ̀rọ̀ inu iwe yii mọ́: foribalẹ fun Ọlọrun.” (Ìfihàn 22:8, 9) Ibẹru Jehofa, tabi ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun un, ń mú wa jọsin oun nikanṣoṣo. (Ìfihàn 14:7) Nipa bayii, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun tootọ ń pa wá mọ́ kuro ninu ibọriṣa.—1 Timoteu 4:8.
17. Bawo ni a ṣe lè ṣọra fun iwa-palapala ibalopọ takọtabo onibọriṣa?
17 Iwa palapala ti ibalopọ takọtabo jẹ́ iru-oriṣi ibọriṣa miiran ti awọn iranṣẹ Jehofa kọsilẹ. Wọn mọ̀ pe “kò si panṣaga, tabi alaimọ eniyan, tabi olojukokoro, tii ṣe olubọriṣa, ti yoo ni ìní kan ni ijọba Kristi ati ti Ọlọrun.” (Efesu 5:5) Eyi ní ibọriṣa ninu nitori pe iyanhanhan fun itẹlọrun alaibofinmu di ohun ifọkansin kan. Awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun ni a wu lewu nipa ìfẹ́-ọkàn ibalopọ takọtabo ti kò yẹ. Nipa títẹ oju ati etí rẹ̀ mọ́ aworan onibaalopọ takọtabo, ẹnikan fi ipo-ibatan eyikeyii ti oun lè ni pẹlu Ọlọrun mímọ́, Jehofa, sinu ewu. (Isaiah 6:3) Lati ṣọra fun iru ibọriṣa bẹẹ, nigba naa, awọn iranṣẹ Ọlọrun gbọdọ yẹra fun aworan ibalopọ takọtabo ati orin idibajẹ. Wọn nilati rọ̀ mọ́ iniyelori ti ẹmi lilagbara ti a gbekari Iwe Mimọ, wọn si gbọdọ maa baa lọ ni gbigbe “ọkunrin titun nì . . . eyi ti a dá nipa ti Ọlọrun ni òdodo ati ni iwa mimọ otitọ” wọ̀.—Efesu 4:22-24.
Yẹra fun Ìwọra ati Ojukokoro
18, 19. (a) Ki ni ìwọra ati ojukokoro jẹ́? (b) Bawo ni a ṣe lè ṣọra fun ìwọra ati ojukokoro onibọriṣa?
18 Awọn Kristian tun ń ṣọra fun ìwọra ati ojukokoro, ti wọn jẹ iru-oriṣi ibọriṣa ti wọn tanmọra pẹkipẹki. Ìwọra jẹ ìfẹ́-ọkàn alailaala tabi ti ọlọkanjuwa, ojukokoro sì jẹ ìwọra fun ohunkohun ti o jẹ ti ẹlomiran. Jesu kilọ lodisi ojukokoro ó sì sọ nipa ọkunrin ọlọ́rọ̀ olojukokoro kan ẹni ti kò lè janfaani lati inu ọlá rẹ̀ nigba iku ti ó sì wà ninu ipo onibanujẹ ti ṣiṣaini “ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun.” (Luku 12:15-21) Paulu lọna ti o baa mu fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ nimọran pe: “Ẹ maa pa ẹya ara yin ti ń bẹ ni ayé run . . . ati ojukokoro, tii ṣe ibọriṣa.”—Kolosse 3:5.
19 Awọn ti ifẹ fun owó gbà lọ́kàn, pẹlu ìwọra fun ounjẹ ati ohun mimu, tabi pẹlu ilepa fun agbara ṣe iru awọn ìfẹ́-ọkàn bẹẹ ni oriṣa wọn. Gẹgẹ bi Paulu ṣe ṣalaye, oniwọra eniyan kan jẹ́ abọriṣa kì yoo sì jogun Ijọba Ọlọrun. (1 Korinti 6:9, 10; Efesu 5:5) Bi o bá ri bẹẹ, awọn eniyan lẹnikọọkan ti wọn ti ṣe iribọmi ti wọn ń ṣe ibọriṣa gẹgẹ bi aṣa ni jíjẹ́ oniwọra eniyan ni a lè yọ lẹ́gbẹ́ kuro ninu ijọ Kristian. Nipa fifi Iwe Mimọ silo ati gbigbadura tọkantọkan, bi o ti wu ki o ri, a lè yẹra fun ìwọra. Owe 30:7-9 wi pe: “Ohun meji ni mo tọrọ lọdọ rẹ [Jehofa Ọlọrun]; maṣe fi wọn dù mi ki emi tó kú. Mu asan ati èké jinna si mi: maṣe fun mi ni òṣì, maṣe fun mi ni ọrọ̀; fi ounjẹ ti o tó fun mi bọ́ mi. Ki emi ki ó ma baà yó jù, ki emi ki o ma sì sẹ́ ọ, pe ta ni Oluwa? Tabi ki emi ma baà tòṣì, ki emi si jale, ki emi sì ṣẹ̀ si orukọ Ọlọrun mi.” Iru ẹmi bẹẹ lè ràn wá lọwọ lati ṣọra fun ìwọra ati ojukokoro onibọriṣa.
Ṣọra fun Isọra-ẹni Di Oriṣa
20, 21. Bawo ni awọn eniyan Jehofa ṣe ń ṣọra fun isọra-ẹni di oriṣa?
20 Awọn eniyan Jehofa tun ń ṣọra fun isọra-ẹni di oriṣa. Ninu ayé yii o wọpọ lati sọ ara-ẹni ati ifẹ-inu ẹni funra-ẹni di oriṣa. Ìfẹ́-ọkàn fun okiki ati ògo ń mu ọpọ lati gbegbeesẹ ni awọn ọ̀nà wiwọ. Wọn fẹ ki ifẹ-inu wọn di ṣiṣe, kìí ṣe ti Ọlọrun. Ṣugbọn a kò lè ni ipo-ibatan kankan pẹlu Ọlọrun ti a bá ń juwọsilẹ fun isọra-ẹni di oriṣa nipa wiwa ki ifẹ-inu tiwa funraawa di ṣiṣe lọna wíwọ́ ati gbigbiyanju lati jẹgaba lori awọn ẹlomiran. (Owe 3:32; Matteu 20:20-28; 1 Peteru 5:2, 3) Gẹgẹ bi awọn ọmọlẹhin Jesu, a ti kọ awọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ ayé silẹ.—2 Korinti 4:1, 2.
21 Dipo wiwa okiki, awọn eniyan Ọlọrun ń rìn ni ibamu pẹlu iṣinileti Paulu pe: “Nitori naa bi ẹyin ba ń jẹ, tabi bi ẹyin bá ń mu, tabi ohunkohun ti ẹyin bá ń ṣe, ẹ maa ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun.” (1 Korinti 10:31) Niwọn bi a ti jẹ́ iranṣẹ Jehofa, a kìí taku lori ọ̀nà tiwa funraawa lọna onibọriṣa ṣugbọn a ń fi tayọtayọ ṣe ifẹ-inu atọrunwa, ni titẹwọgba idari lati ọwọ́ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa” ti a si ń fọwọsowọpọ ni kikun pẹlu eto-ajọ Jehofa.—Matteu 24:45-47, NW.
Ẹ Maa Ṣọra!
22, 23. Ni ọ̀nà wo ni a lè gbà ṣọra fun gbogbo oniruuru ibọriṣa?
22 Gẹgẹ bi awọn eniyan Jehofa, a kìí tẹriba niwaju oriṣa afọwọṣe eyikeyii. A tun ń ṣọra fun iru-oriṣi ibọriṣa ọlọgbọn-ẹwẹ pẹlu. Nitootọ, a gbọdọ maa baa lọ lati yẹra fun gbogbo oniruuru ibọriṣa. A tipa bẹẹ fohunṣọkan pẹlu imọran Johannu pe: “Ẹyin ọmọ mi, ẹ pa ara yin mọ́ kuro ninu oriṣa.”—1 Johannu 5:21.
23 Bi iwọ bá jẹ ọ̀kan ninu awọn iranṣẹ Jehofa, maa lo ẹ̀rí-ọkàn ati awọn agbara imoye rẹ ti a ti kọlẹkọọ nigba gbogbo. (Heberu 5:14) Nigba naa iwọ ni a kì yoo sọ deleeeri nipa ẹmi onibọriṣa ti ayé ṣugbọn iwọ yoo dabi awọn Heberu olùṣòtítọ́ mẹta naa ati awọn Kristian aduroṣinṣin akọkọbẹrẹ. Iwọ yoo fun Jehofa ni ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé, oun yoo sì ràn ọ́ lọwọ lati maa ṣọra fun gbogbo oniruuru ibọriṣa.
Ki ni Èrò Rẹ?
◻ Bawo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ń yẹra fun iru-oriṣi ibọriṣa ti a ri ninu iran Esekieli?
◻ Ki ni “ẹranko ẹhanna” inu Ìfihàn 13:1, ipo wo sì ni awọn iranṣẹ Jehofa mú nipa rẹ̀?
◻ Eeṣe ti a fi nilati ṣọra fun sisọ awọn ogbontarigi eré-ìnàjú ati ere-idaraya di oriṣa?
◻ Bawo ni a ṣe lè ṣọra fun isọra-ẹni di oriṣa?
◻ Eeṣe ti a fi nilati maa ṣọra fun gbogbo oniruuru ibọriṣa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Iwọ ha mọ bi awọn ohun irira ti a ri ninu iran Esekieli ṣe jẹ apẹẹrẹ iṣaaju fun ibọriṣa Kristẹndọm bi?
[Credit Line]
Ọnà-àwòrán (apá-òsì loke) ni a gbekari fọto Ralph Crane/Bardo Museum