-
A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
-
-
7. Àbá wo ni àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ dá fún ọba, ọ̀nà wo sì ni wọ́n gbà gbé e kalẹ̀?
7 Àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ para pọ̀ lọ bá Dáríúsì, wọ́n wọlé wá “bí àgbájọ ènìyàn kan.” Ní èdè Árámáíkì, gbólóhùn tí a lò níhìn-ín ní èrò ti ìró bí ààrá. Ó jọ pé ṣe ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú kí ó dà bí pé ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ kánjúkánjú gidi gan-an ni wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Dáríúsì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti rò ó pé kò ní lè béèrè ìbéèrè kankan lórí ìwéwèé wọn bí wọ́n bá fi ìdánilójú sọ ọ́ tí wọ́n sì mú kí ó dà bí pé ó ń fẹ́ ìgbésẹ̀ kánjúkánjú. Nítorí náà, wọ́n tẹnu bọ̀rọ̀ pé: “Gbogbo àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga nínú ìjọba náà, àwọn aṣíwájú àti baálẹ̀, àwọn olóyè onípò gíga àti àwọn gómìnà, ti gbìmọ̀ pọ̀ láti fìdí ìlànà àgbékalẹ̀ ọba múlẹ̀ àti láti mú kí àṣẹ ìkàléèwọ̀ kan rinlẹ̀, pé ẹnì yòówù tí ó bá ṣe ìtọrọ lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe lọ́wọ́ rẹ, ọba, ni kí a sọ sínú ihò kìnnìún.”a—Dáníẹ́lì 6:6, 7.
8. (a) Èé ṣe tí òfin tí a dá lábàá yìí yóò fi wu Dáríúsì? (b) Kí ni ète àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ náà ní ti gidi?
8 Àkọsílẹ̀ inú ìtàn jẹ́rìí sí i pé ó wọ́pọ̀ pé kí a ka àwọn ọba Mesopotámíà sí ọlọ́run, kí a sì máa jọ́sìn wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìwéwèé yìí wú Dáríúsì lórí. Ó sì ṣeé ṣe kí ó tún rí ìhà kan tí ó wúlò níbẹ̀. Rántí pé Dáríúsì jẹ́ àjèjì àti ẹni tuntun sí àwọn tí ń gbé ní Bábílónì. Ṣe ni òfin tuntun yìí yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba, yóò sì jẹ́ kí àwọn ògìdìgbó tí ń gbé ní Bábílónì lè jẹ́jẹ̀ẹ́ ìdúróṣinṣin àti ìtìlẹyìn fún ìjọba tuntun yìí. Àmọ́ ṣá, kì í ṣe ire ọba ló jẹ àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ lọ́kàn tí wọ́n fi wéwèé òfin yìí. Èrò ọkàn wọn ní ti gidi ni láti kẹ́dẹ mú Dáníẹ́lì, nítorí wọ́n mọ̀ pé ó jẹ́ àṣà rẹ̀ láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹ́ta lóòjọ́ ní ìdojúkọ fèrèsé tí ó wà ní ṣíṣí ní ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀.
9. Èé ṣe tí òfin tuntun yìí kò fi ní jẹ́ ìṣòro fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí kì í ṣe Júù?
9 Ìkálọ́wọ́kò tí a gbé karí àdúrà gbígbà yìí yóò ha dá ìṣòro sílẹ̀ fún àwùjọ àwọn ẹlẹ́sìn tí ń gbé ní Bábílónì bí? Ó lè máa rí bẹ́ẹ̀, pàápàá bí ó ti jẹ́ pé ìfòfindè náà kò ju oṣù kan péré lọ. Síwájú sí i, díẹ̀ nínú àwọn tí kì í ṣe Júù ni yóò ka dídarí ìjọsìn wọn sí ènìyàn kan fún àkókò kan sí ṣíṣe ohun tí ó lódì sí ìjọsìn ẹni. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bíbélì kan sọ pé: “Jíjọ́sìn ọba kì í ṣe ohun àjèjì rárá lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà jù lọ; nítorí náà, nígbà tí a ní kí àwọn ará Bábílónì fi ìjúbà tí ó tọ́ sí ọlọ́run kan fún ẹni tí ó ṣẹ́gun wọn—Dáríúsì ará Mídíà—wọ́n gbà bẹ́ẹ̀ láìjanpata. Júù yẹn nìkan ni kò fara mọ́ ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.”
-
-
A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
-
-
a Ẹ̀rí láti inú àwọn àkọsílẹ̀ ìgbàanì, tí ó fi hàn pé àwọn ọba ìhà Ìlà Oòrùn sábà máa ń sin àwọn ẹranko ẹhànnà bí ohun ọ̀sìn, ṣètìlẹ́yìn fún ọ̀rọ̀ náà pé “ihò kìnnìún” wà ní Bábílónì.
-