Orí Kẹwàá
Ta ní lè Dìde sí Olórí Àwọn Ọmọ Aládé?
1, 2. Èé ṣe tí ìran tí Dáníẹ́lì rí ní ọdún kẹta ìṣàkóso Bẹliṣásárì fi ṣe pàtàkì fún wa?
NÍ BÁYÌÍ, ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ti kọjá lẹ́yìn tí a pa tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù run. Bẹliṣásárì àti Nábónídọ́sì baba rẹ̀ sì jùmọ̀ ń ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì, agbára ayé kẹta nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.a Dáníẹ́lì wòlíì Ọlọ́run wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì. “Ní ọdún kẹta ìgbà àkóso Bẹliṣásárì Ọba,” Jèhófà fi ìran kan ránṣẹ́ sí Dáníẹ́lì, èyí tí ó ṣí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa bí a óò ṣe mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò payá.—Dáníẹ́lì 8:1.
2 Ìran alásọtẹ́lẹ̀ tí Dáníẹ́lì rí ní ipa tí ó lágbára gidigidi lórí rẹ̀, ó sì gbàfiyèsí àwa tí a ń gbé ní “àkókò òpin” gidigidi. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Kíyè sí i, mo ń jẹ́ kí o mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ìdálẹ́bi náà, nítorí ó wà fún àkókò òpin tí a yàn kalẹ̀.” (Dáníẹ́lì 8:16, 17, 19, 27) Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a fi ìháragàgà gbé ohun tí Dáníẹ́lì rí àti ohun tí ó túmọ̀ sí fún wa lónìí yẹ̀ wò.
ÀGBÒ TÍ Ó NÍ ÌWO MÉJÌ
3, 4. Ẹranko wo ni Dáníẹ́lì rí tí ó dúró síwájú ipadò, kí ló sì dúró fún?
3 Dáníẹ́lì kọ̀wé pé: “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí lójú ìran; ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí mo ti rí i, mo wà ní Ṣúṣánì, ilé aláruru, èyí tí ó wà ní Élámù, àgbègbè abẹ́ àṣẹ; mo sì ń bá a lọ láti rí i lójú ìran, èmi fúnra mi sì wà ní ipadò Úláì.” (Dáníẹ́lì 8:2) Bóyá ní ti gidi ni Dáníẹ́lì wà ní Ṣúṣánì (Súsà)—olú ìlú ilẹ̀ Élámù tí ó wà ní ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín mẹ́wàá [350] kìlómítà níhà ìlà oòrùn Bábílónì—tàbí bóyá ojú ìran ni ó gbà wà níbẹ̀ ni o, a kò sọ fún wa.
4 Dáníẹ́lì ń bá a lọ pé: “Nígbà tí mo gbé ojú mi sókè, mo wá rí i, sì wò ó! àgbò kan dúró níwájú ipadò, ó sì ní ìwo méjì.” (Dáníẹ́lì 8:3a) Bí àgbò náà ṣe jẹ́ kò jẹ́ àdììtú títí lọ gbére fún Dáníẹ́lì. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣàlàyé lẹ́yìn náà pé: “Àgbò tí ìwọ rí tí ó ní ìwo méjì dúró fún àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà.” (Dáníẹ́lì 8:20) Ibi àwọn òkè ńláńlá, olórí títẹ́jú, tí ó wà níhà ìlà oòrùn Ásíríà, ni àwọn ará Mídíà ti wá, ní ti àwọn ará Páṣíà, ìgbésí ayé aṣíkiri ni wọ́n sábà máa ń gbé látilẹ̀wá ní ẹkùn àríwá Ìyawọlẹ̀ Omi Páṣíà. Àmọ́, bí Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà ṣe ń gbilẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn ibẹ̀ wá di ẹni tí ó fẹ́ràn afẹ́ gidi gan-an.
5. Báwo ni ìwo tí ó “jáde wá lẹ́yìn náà” ṣe di èyí tí ó ga ju èkejì lọ?
5 Dáníẹ́lì ròyìn pé: “Ìwo méjèèjì náà sì ga, ṣùgbọ́n ọ̀kan ga ju èkejì lọ, èyí tí ó ga jù ni ó sì jáde wá lẹ́yìn náà.” (Dáníẹ́lì 8:3b) Ìwo tí ó ga jù, tí ó jáde wá lẹ́yìn náà, dúró fún àwọn ará Páṣíà, nígbà tí ìwo kejì dúró fún àwọn ará Mídíà. Àwọn ará Mídíà ni wọ́n kọ́kọ́ mókè. Ṣùgbọ́n ní ọdún 550 ṣááju Sànmánì Tiwa, wẹ́rẹ́ ni Kírúsì alákòóso ilẹ̀ Páṣíà ṣẹ́gun Asítíyágè ọba Mídíà. Kírúsì wá pa àṣà àti òfin ilẹ̀ méjèèjì pọ̀ ṣọ̀kan, ó mú kí ìjọba wọn para pọ̀, ó sì mú kí ibi tí wọ́n ń ṣẹ́gun túbọ̀ pọ̀ sí i. Láti ìgbà náà lọ, ilẹ̀ ọba wọn wá di agbára ayé aláwẹ́ méjì.
ÀGBÒ NÁÀ GBÉ ÀGBÉRÉ ŃLÁǸLÀ
6, 7. Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé ‘kò sí ẹranko ìgbẹ́ kankan tí ó lè dúró níwájú’ àgbò náà?
6 Dáníẹ́lì ń ṣàpèjúwe àgbò náà lọ, ó wí pé: “Mo rí tí àgbò náà ń ṣe ìkọlù síhà ìwọ̀-oòrùn àti síhà àríwá àti síhà gúúsù, kò sì sí ẹranko ìgbẹ́ kankan tí ó dúró níwájú rẹ̀, kò sì sí ẹni tí ó ń ṣe ìdáǹdè kankan kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì ṣe bí ìfẹ́ rẹ̀, ó sì gbé àgbéré ńláǹlà.”—Dáníẹ́lì 8:4.
7 Nínú ìran tí a fi han Dáníẹ́lì níṣàájú, ẹranko ìgbẹ́ tí ó ti inú òkun jáde wá, tí ó sì dà bí kìnnìún tí ó níyẹ̀ẹ́ idì lápá ni a fi ṣàpẹẹrẹ Bábílónì. (Dáníẹ́lì 7:4, 17) Ẹranko ìṣàpẹẹrẹ náà kò lè dúró níwájú “àgbò” inú ìran tuntun yìí. Bábílónì ṣubú sọ́wọ́ Kírúsì Ńlá ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, kò sí “ẹranko ìgbẹ́,” tàbí ìjọba ìṣèlú kankan tí ó lè dúró láti gbéjà ko Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà—agbára ayé kẹrin nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.
8, 9. (a) Báwo ni “àgbò náà” ṣe “ń ṣe ìkọlù síhà ìwọ̀-oòrùn, àti síhà àríwá àti síhà gúúsù”? (b) Kí ni ìwé Ẹ́sítérì sọ nípa ẹni tí ó rọ́pò Dáríúsì Kìíní ọba Páṣíà?
8 Bí Agbára Ayé Mídíà òun Páṣíà ṣe wá “láti yíyọ oòrùn”—ìlà oòrùn—ńṣe ni ó ń ṣe bó ṣe wù ú, tí ó “ń ṣe ìkọlù síhà ìwọ̀-oòrùn àti síhà àríwá àti síhà gúúsù.” (Aísáyà 46:11) Kanbáísísì Ọba Kejì, tí ó rọ́pò Kírúsì Ńlá, ṣẹ́gun ilẹ̀ Íjíbítì. Dáríúsì Kìíní ọba Páṣíà ni ó rọ́pò rẹ̀, ó sì gba ti ojú ọ̀nà òkun Bósípórù sọdá sí ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ọdún 513 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó wá gbógun ti àwọn ẹkùn ilẹ̀ Tírésì ní Yúróòpù, tí olú ìlú rẹ̀ jẹ́ Baisáńtíọ́mù (Istanbul nísinsìnyí). Lọ́dún 508 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó tẹ Tírésì lórí ba, ó sì ṣẹ́gun Makedóníà ní ọdún 496 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nípa báyìí, nígbà tí ó fi máa di àkókò Dáríúsì, “àgbò” ti ilẹ̀ Mídíà òun Páṣíà ti gba ìpínlẹ̀ níhà ibi mẹ́ta: ìhà àríwá títí wọ ilẹ̀ ọba Bábílónì àti Ásíríà, ìwọ̀-oòrùn títí la Éṣíà Kékeré já, àti ìhà gúúsù títí wọ Íjíbítì.
9 Nígbà tí Bíbélì ń sọ nípa bí Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà ṣe tóbi tó, ó sọ nípa Sásítà Kìíní, arọ́pò Dáríúsì, pé: “Ahasuwérúsì tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba láti Íńdíà títí dé Etiópíà, lórí ẹ̀tà-dín-láàádóje àgbègbè abẹ́ àṣẹ.” (Ẹ́sítérì 1:1) Àmọ́, ilẹ̀ ọba títóbi yìí máa tó bọ́ sí abẹ́ òmíràn, ìran Dáníẹ́lì sì ṣí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra payá nípa èyí, tí ó yẹ kí ó mú kí ìgbàgbọ́ tí a ní nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ti Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i.
AKỌ EWÚRẸ́ NÁÀ ṢÁ ÀGBÒ NÁÀ BALẸ̀
10. Nínú ìran Dáníẹ́lì, ẹranko wo ni ó ṣá “àgbò náà” balẹ̀?
10 Fojú inú wo bí ohun tí Dáníẹ́lì wá rí ti máa ṣe é ní kàyéfì tó. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ní tèmi, mo ń gbé e yẹ̀ wò nìṣó, sì wò ó! akọ ewúrẹ́ kan wà tí ń bọ̀ láti wíwọ̀-oòrùn sórí gbogbo ilẹ̀ ayé, kò sì kanlẹ̀. Àti ní ti òbúkọ náà, ìwo kan tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà wà láàárín àwọn ojú rẹ̀. Ó sì ń bọ̀ tààrà sọ́dọ̀ àgbò tí ó ní ìwo méjì náà, èyí tí mo ti rí tí ó dúró níwájú ipadò; ó sì ń sáré bọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ìhónú rẹ̀ tí ó lágbára. Mo sì rí i tí ó ń sún mọ́ àgbò náà pẹ́kípẹ́kí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìkorò hàn sí i, ó sì ń bá a lọ láti ṣá àgbò náà balẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì, kò sì sí agbára kankan nínú àgbò náà láti dúró níwájú rẹ̀. Nítorí náà, ó là á mọ́lẹ̀, ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àgbò náà kò sì ní olùdáǹdè kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 8:5-7) Kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí?
11. (a) Báwo ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣe ṣàlàyé “òbúkọ onírun” náà àti “ìwo ńlá” tí ó ní? (b) Ta ni ìwo tí ó hàn gbangba-gbàǹgbà náà dúró fún?
11 A kò jẹ́ kí Dáníẹ́lì àti àwa náà wulẹ̀ máa méfòó lórí ohun tí ìtumọ̀ àlá yìí jẹ́. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Òbúkọ onírun náà sì dúró fún ọba ilẹ̀ Gíríìsì; àti ní ti ìwo ńlá tí ó wà láàárín àwọn ojú rẹ̀, ó dúró fún ọba àkọ́kọ́.” (Dáníẹ́lì 8:21) Ní ọdún 336 ṣááju Sànmánì Tiwa, a fi adé dé Dáríúsì Kẹta (Kodománọ́sì), òun ni ọba tí ó jẹ kẹ́yìn ní Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà. Ní ọdún kan náà, Alẹkisáńdà di ọba ní Makedóníà. Ìtàn fi hàn pé Alẹkisáńdà Ńlá ni “ọba ilẹ̀ Gíríìsì” àkọ́kọ́ tí a sọ tẹ́lẹ̀. Bí Alẹkisáńdà ṣe bẹ̀rẹ̀ “láti wíwọ̀-oòrùn,” ìyẹn ìwọ̀-oòrùn, ní ọdún 334 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó tẹ̀ síwájú kánkán. Bí ẹni tí ‘kò kanlẹ̀’ ló ṣe ń ṣẹ́gun àwọn ìpínlẹ̀ lọ tí ó sì ṣá “àgbò” náà balẹ̀. Bí Gíríìsì ṣe fòpin sí ìṣàkóso Mídíà òun Páṣíà tí ó ti wà láti nǹkan bí ọ̀rúndún méjì, ló bá di agbára ayé karùn-ún tí ó ṣe pàtàkì nínú Bíbélì. Ẹ wo bí àsọtẹ́lẹ̀ àtọ̀runwá yìí ṣe ní ìmúṣẹ lọ́nà tí ó pẹtẹrí!
12. Báwo ni a ṣe “ṣẹ́ ìwo ńlá” ewúrẹ́ ìṣàpẹẹrẹ náà, kí sì ni àwọn ìwo mẹ́rin tí ó jáde wá dípò rẹ̀?
12 Ṣùgbọ́n agbára Alẹkisáńdà kò wà pẹ́. Ìran náà ṣí i payá síwájú sí i pé: “Akọ ewúrẹ́ náà, ní tirẹ̀, gbé àgbéré ńláǹlà dé góńgó; ṣùgbọ́n gbàrà tí ó di alágbára ńlá, a ṣẹ́ ìwo ńlá náà, mẹ́rin tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá dípò rẹ̀, síhà ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ojú ọ̀run.” (Dáníẹ́lì 8:8) Ní ṣíṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Gébúrẹ́lì sọ pé: “Bí ìyẹn sì ti ṣẹ́, tí ó fi jẹ́ pé mẹ́rin dìde dúró dípò rẹ̀, ìjọba mẹ́rin ni yóò dìde láti orílẹ̀-èdè rẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú agbára rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 8:22) Bí a ṣe ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, nígbà tí Alẹkisáńdà ti ja àjàṣẹ́gun dé ipò tí ó ga gidigidi, ló bá “ṣẹ́,” ìyẹn ni pé ó kú, láìju ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n péré. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mẹ́rin nínú àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bá pín ilẹ̀ ọba rẹ̀ ńlá mọ́ ara wọn lọ́wọ́.
ÌWO KÉKERÉ KAN TÍ Ó JẸ́ ÀRÀMÀǸDÀ
13. Kí ní hù láti inú ọ̀kan lára ìwo mẹ́rin náà, báwo ni ó sì ṣe gbé ìgbésẹ̀?
13 Ìmúṣẹ apá tí ó tẹ̀ le nínú ìran náà gbà ju ẹgbọ̀kànlá [2,200] ọdún lọ, ó nasẹ̀ dé àkókò òde òní. Dáníẹ́lì kọ̀wé pé: “Láti inú ọ̀kan lára wọn [ìwo mẹ́rin náà] . . . ni ìwo mìíràn ti jáde wá, ọ̀kan tí ó kéré, ó sì ń tóbi sí i gidigidi síhà gúúsù àti síhà yíyọ oòrùn àti síhà Ìṣelóge. Ó sì tóbi sí i dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, tí ó fi mú àwọn kan lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn kan lára ìràwọ̀ já bọ́ sí ilẹ̀, ó sì ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Àti dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ Olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni ó gbé àgbéré ńláǹlà, a sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wó ibi àfìdímúlẹ̀ ibùjọsìn rẹ̀ lulẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan ni a fi léni lọ́wọ́, pa pọ̀ pẹ̀lú apá pàtàkì ìgbà gbogbo, nítorí ìrélànàkọjá; ó sì ń bá a lọ láti wó òtítọ́ mọ́lẹ̀, ó gbé ìgbésẹ̀, ó sì kẹ́sẹ járí.”—Dáníẹ́lì 8:9-12.
14. Kí ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ nípa ìgbòkègbodò ìwo kékeré ìṣàpẹẹrẹ náà, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ sí ìwo náà?
14 Kí a tó lè lóye àwọn ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fà yọ yìí, a ní láti fetí sí áńgẹ́lì Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ti tọ́ka sí bí ìjọba mẹ́rin ṣe dé ipò agbára láti inú ilẹ̀ ọba Alẹkisáńdà, ó wá sọ pé: “Ní apá ìgbẹ̀yìn ìjọba wọn, bí àwọn olùrélànàkọjá ti ń gbé ìgbésẹ̀ lọ dé ìparí, ọba kan yóò dìde, tí ó rorò ní ojú, tí ó sì lóye àwọn ọ̀rọ̀ onítumọ̀ púpọ̀. Agbára rẹ̀ yóò sì di ńlá, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ti òun fúnra rẹ̀. Yóò sì fa ìparun ní ọ̀nà àgbàyanu, dájúdájú yóò kẹ́sẹ járí, yóò sì gbéṣẹ́. Ní ti tòótọ́, òun yóò run àwọn alágbára ńlá, àti àwọn tí í ṣe ẹni mímọ́. Àti gẹ́gẹ́ bí ìjìnlẹ̀ òye rẹ̀, dájúdájú, yóò mú kí ẹ̀tàn kẹ́sẹ járí ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Yóò sì gbé àgbéré ńláǹlà ní ọkàn-àyà rẹ̀, àti lákòókò òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn, yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀. Yóò sì dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé, ṣùgbọ́n a óò ṣẹ́ ẹ láìsí ọwọ́.”—Dáníẹ́lì 8:23-25.
15. Kí ni áńgẹ́lì náà sọ pé kí Dáníẹ́lì ṣe nípa ìran náà?
15 Áńgẹ́lì náà wá sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ìwọ, ní tìrẹ, pa ìran náà mọ́ láṣìírí, nítorí tí ó ṣì wà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.” (Dáníẹ́lì 8:26) Ìmúṣẹ apá yìí nínú ìran náà kò tíì ní ṣẹlẹ̀ títí di “ọ̀pọ̀ ọjọ́,” Dáníẹ́lì sì ní láti “pa ìran náà mọ́ láṣìírí.” Ó dájú pé ìtumọ̀ rẹ̀ pa mọ́ fún Dáníẹ́lì. Ṣùgbọ́n, ní báyìí, ó dájú pé “ọ̀pọ̀ ọjọ́” náà yóò ti kọjá lọ. Nítorí náà, ìbéèrè wa ni pé: ‘Kí ni ìtàn ayé fi hàn nípa ìmúṣẹ ìran alásọtẹ́lẹ̀ yìí?’
ÌWO KÉKERÉ NÁÀ DI ALÁGBÁRA ŃLÁ
16. (a) Inú ìwo ìṣàpẹẹrẹ wo ni ìwo kékeré náà ti jáde wá? (b) Báwo ni Róòmù ṣe di agbára ayé kẹfà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ṣùgbọ́n èé ṣe tí òun kì í fi í ṣe ìwo ìṣàpẹẹrẹ kékeré náà?
16 Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe fi hàn, ìwo kékeré náà jáde wá láti inú ọ̀kan lára ìwo ìṣàpẹẹrẹ mẹ́rin náà—èyí tí ó sún mọ́ ìpẹ̀kun ìwọ̀-oòrùn jù lọ. Èyíinì ni àkóso ìjọba Hélénì ti Ọ̀gágun Kasáńdà lórí Makedóníà àti Gíríìsì. Nígbà tí ó yá, ìjọba Ọ̀gágun Lisimákù ọba Tírésì àti Éṣíà Kékeré wá gbé ìjọba yìí mì. Ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, ilẹ̀ Róòmù ṣẹ́gun àwọn ẹ̀ka ìwọ̀-oòrùn àgbègbè ìṣàkóso àwọn Hélénì yìí. Ìgbà tí ó sì fi máa di ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa, Róòmù gba gbogbo ìjọba àwọn Hélénì, ó sì sọ ara rẹ̀ di agbára ayé kẹfà ti inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Àmọ́, Ilẹ̀ Ọba Róòmù kọ́ ni ìwo kékeré inú ìran Dáníẹ́lì, nítorí pé ilẹ̀ ọba yẹn kò wà títí di “àkókò òpin tí a yàn kalẹ̀.”—Dáníẹ́lì 8:19.
17. (a) Kí ni ìbátan tí ó wà láàárín ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù? (b) Báwo ni Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ṣe tan mọ́ ìjọba Hélénì ti Makedóníà àti Gíríìsì?
17 Nígbà náà, kí wá ni ìtàn fi hàn pé ó jẹ́ “ọba kan” yẹn “tí ó rorò ní ojú”? Ní ti gidi, ìhà àríwá ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti yọ jáde. Títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Tiwa, àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù wà ní ibi tí ó di ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì báyìí. Nígbà tí ó ṣe, ìfàsẹ́yìn bá Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ṣùgbọ́n ayé ọ̀làjú ti àwọn Gíríìkì àti Róòmù ṣì ń bá a lọ láti nípa lórí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn apá yòókù Yúróòpù tí ó ti fìgbà kan rí wà lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù. Octavio Paz, ará Mexico kan tí ó jẹ́ akéwì àti òǹkọ̀wé tí ó ti gba Ẹ̀bùn Nobel, kọ̀wé pé: “Nígbà tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣubú, Ṣọ́ọ̀ṣì gbapò rẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Àwọn Baba Ṣọ́ọ̀ṣì, àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ẹ̀yìn ìgbà náà, gbé ẹ̀kọ́ ọgbọ́n èrò orí àwọn Gíríìkì wọnú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni.” Bertrand Russell, tí ó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ọgbọ́n èrò orí àti onímọ̀ ìṣirò ní ọ̀rúndún ogún, ṣàkíyèsí pé: “Ọ̀làjú ìhà Ìwọ̀-Oòrùn, tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn Gíríìkì wá, ni a gbé karí àṣà ọgbọ́n èrò orí àti sáyẹ́ǹsì tí ó bẹ̀rẹ̀ ní Mílétù [ìlú Gíríìsì kan tí ó wà ní Éṣíà Kékeré] ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ààbọ̀ sẹ́yìn.” Nípa báyìí, a lè sọ pé inú ìjọba Hélénì ti Makedóníà àti Gíríìsì ni àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ti Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ti wá.
18. Kí ni ìwo kékeré tí ó di ‘ọba tí ó rorò ní ojú’ ní “àkókò òpin”? Ṣàlàyé.
18 Nígbà tí ó fi máa di ọdún 1763, Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ti ṣẹ́gun Sípéènì àti Faransé tí wọ́n jẹ́ ilẹ̀ alágbára tí ń bá a figẹ̀ wọngẹ̀. Láti ìgbà náà lọ ni Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ti di aláṣẹ lórí àwọn òkun àti agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Kódà lẹ́yìn tí àwọn ilẹ̀ mẹ́tàlá ní Àríwá Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ya kúrò lára ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1776, tí wọ́n sì dá Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sílẹ̀, Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì gbòòrò débi tí ó fi kó ìdá mẹ́rin ilẹ̀ ayé àti ìdá mẹ́rin àwọn ènìyàn inú rẹ̀ sábẹ́. Agbára ayé keje yìí tún lágbára sí i nígbà tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n fi pa pọ̀ di agbára ayé aláwẹ́ méjì ti Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Lóòótọ́, agbára ayé yìí di “ọba kan . . . tí ó rorò ní ojú” nínú ọ̀ràn ọrọ̀ ajé àti agbára ológun. Nígbà náà, ìwo kékeré náà tí ó di agbára ìṣèlú tí ó rorò ní “àkókò òpin” ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà.
19. Kí ni “Ìṣelóge” tí a mẹ́nu kàn nínú ìran náà?
19 Dáníẹ́lì rí i pé ìwo kékeré náà “ń tóbi sí i gidigidi . . . síhà Ìṣelóge.” (Dáníẹ́lì 8:9) Ilẹ̀ Ìlérí tí Jèhófà fi fún àwọn ènìyàn àyànfẹ́ rẹ̀ dára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi pè é ní “ìṣelóge ilẹ̀ gbogbo,” èyíinì ni gbogbo ilẹ̀ ayé. (Ìsíkíẹ́lì 20:6, 15) Lóòótọ́, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gba Jerúsálẹ́mù ní December 9, 1917, nígbà tí ó sì di ọdún 1920, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní àṣẹ láti máa bójú tó ilẹ̀ Palẹ́sìnì, èyí tí ó ń bá a lọ títí di May 14, 1948. Ṣùgbọ́n ìran náà jẹ́ alásọtẹ́lẹ̀, tí ọ̀pọ̀ nǹkan inú rẹ̀ sì jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ. Ohun tí “Ìṣelóge” tí a mẹ́nu kàn nínú ìran náà sì ṣàpẹẹrẹ kì í ṣe Jerúsálẹ́mù bí kò ṣe ipò kan tí àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run kà sí mímọ́ wà lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò agbára ayé keje. Ẹ jẹ́ kí a wo bí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣe gbìyànjú láti halẹ̀ mọ́ àwọn ẹni mímọ́.
A WÓ ‘IBI IBÙJỌSÌN RẸ̀’ LULẸ̀
20. Àwọn wo ni “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” àti “àwọn ìràwọ̀” tí ìwo kékeré náà gbìyànjú láti já bọ́ sílẹ̀?
20 Ìwo kékeré náà “tóbi sí i dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, tí ó fi mú àwọn kan lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn kan lára ìràwọ̀ já bọ́ sí ilẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí àlàyé áńgẹ́lì náà, “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” àti àwọn “ìràwọ̀” tí ìwo kékeré náà gbìyànjú láti já sí ilẹ̀ ni “àwọn tí í ṣe ẹni mímọ́.” (Dáníẹ́lì 8:10, 24) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni àwọn “ẹni mímọ́” wọ̀nyí. Nítorí pé májẹ̀mú tuntun, tí ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi tí a ta sílẹ̀ mú kí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu, mú àwọn àti Ọlọ́run wọnú àjọṣe kan, a sọ wọ́n di mímọ́, a wẹ̀ wọ́n mọ́, a sì yà wọ́n sọ́tọ̀ gedegbe fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. (Hébérù 10:10; 13:20) Níwọ̀n bí Jèhófà ti yàn wọ́n kí wọ́n bá Ọmọ òun jẹ́ ajogún nínú ogún ti ọ̀run, ó kà wọ́n sí ẹni mímọ́. (Éfésù 1:3, 11, 18-20) Nígbà náà, nínú ìran Dáníẹ́lì, “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” tọ́ka sí àṣẹ́kù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì “ẹni mímọ́” tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, tí yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣàkóso ní ọ̀run.—Ìṣípayá 14:1-5.
21. Ta ní wà ní “ibi mímọ́” tí agbára ayé keje gbìyànjú láti sọ di ahoro?
21 Lónìí, àwọn àṣẹ́kù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́ aṣojú ti orí ilẹ̀ ayé fún “Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run”—Ìjọba Ọlọ́run tí ó dà bí ìlú ńlá—àti ìṣètò tẹ́ńpìlì rẹ̀. (Hébérù 12:22, 28; 13:14) Lójú ìwòye yìí, “ibi mímọ́” ni wọ́n wà, èyí tí agbára ayé keje gbìyànjú láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó sì sọ di ahoro. (Dáníẹ́lì 8:13) Dáníẹ́lì tún sọ̀rọ̀ ibi mímọ́ yẹn gẹ́gẹ́ bí “ibi àfìdímúlẹ̀ ibùjọsìn [Jèhófà],” ó sọ pé: “A sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ [Jèhófà], a sì wó ibi àfìdímúlẹ̀ ibùjọsìn rẹ̀ lulẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan ni a fi léni lọ́wọ́, pa pọ̀ pẹ̀lú apá pàtàkì ìgbà gbogbo, nítorí ìrélànàkọjá; ó sì ń bá a lọ láti wó òtítọ́ mọ́lẹ̀, ó gbé ìgbésẹ̀, ó sì kẹ́sẹ járí.” (Dáníẹ́lì 8:11, 12) Báwo ni a ṣe mú èyí ṣẹ?
22. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, báwo ni “ìrélànàkọjá” kan tí ó gbàfiyèsí ṣe wáyé láti ọ̀dọ̀ agbára ayé keje?
22 Kí ní jẹ́ ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì? Inúnibíni tí ó le koko ni a ṣe sí wọn! Ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè elétò ìjọba Násì àti ti Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ni ó ti bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́, a “wó òtítọ́ mọ́lẹ̀” jákèjádò àgbègbè ìṣàkóso gbígbòòrò ti ‘ìwo kékeré náà tí agbára rẹ̀ ti di ńlá.’ Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú Àjọ Kájọlà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni a ti fòfin de “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” olùpòkìkí Ìjọba náà àti iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere” tí wọ́n ń ṣe. (Máàkù 13:10) Nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ń fi tipátipá kó àwọn ènìyàn sínú iṣẹ́ ológun, wọ́n kọ̀ láti yọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ nínú iṣẹ́ yìí, ní ṣíṣàìbọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run tí a yàn wọ́n sẹ́nu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Ìwọ́jọpọ̀ kọluni àti onírúurú àbùkù ni àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fara gbá. Nípa báyìí, ńṣe ni agbára ayé keje gbìyànjú láti mú ẹbọ ìyìn—“èso ètè”—tí àwọn ènìyàn Jèhófà ń rú sí i déédéé gẹ́gẹ́ bí “apá pàtàkì ìgbà gbogbo” nínú ìjọsìn wọn kúrò. (Hébérù 13:15) Bí “ìrélànàkọjá” agbára ayé yẹn ṣe wáyé nìyẹn ní ti pé ó gbógun ti àgbègbè ìṣàkóso tí ó tọ́ sí Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ—“ibi àfìdímúlẹ̀ ibùjọsìn rẹ̀.”
23. (a) Láàárín Ogun Àgbáyé Kejì, báwo ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣe “dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé”? (b) Ta ni “Olórí àwọn ọmọ aládé”?
23 Ìwo kékeré náà gbé àgbéré ńláǹlà “dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ Olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun” nípa pé ó ṣe inúnibíni sí àwọn “ẹni mímọ́” nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Tàbí gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣe ṣàlàyé, ó “dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé.” (Dáníẹ́lì 8:11, 25) Oyè náà “Olórí àwọn ọmọ aládé” jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Ọ̀rọ̀ Hébérù náà, sar, tí a tú sí “aládé,” ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tí ó túmọ̀ sí “ṣàkóso lórí.” Ní àfikún sí pé ó tọ́ka sí ọmọ ọba tàbí ẹnì kan tí ó wá láti ìdílé ọba, ọ̀rọ̀ náà tún ṣeé lò fún ẹni tí ó jẹ́ olórí. Ìwé Dáníẹ́lì mẹ́nu kan àwọn áńgẹ́lì mìíràn tí ó jẹ́ ọmọ aládé—Máíkẹ́lì jẹ́ àpẹẹrẹ kan. Ọlọ́run ni Olórí gbogbo irúfẹ́ àwọn ọmọ aládé bẹ́ẹ̀. (Dáníẹ́lì 10:13, 21; fi wé Sáàmù 83:18.) Ǹjẹ́ a lè ronú kàn án pé ẹnikẹ́ni lè dìde sí Jèhófà—Olórí àwọn ọmọ aládé?
A MÚ “IBI MÍMỌ́” WÁ SÍ IPÒ TÍ Ó TỌ́
24. Kí ni Dáníẹ́lì 8:14 mú dá wa lójú?
24 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé—kódà ọba “tí ó rorò ní ojú,” Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà, kò tó bẹ́ẹ̀! Ìgbìyànjú ọba yìí láti sọ ibùjọsìn Ọlọ́run di ahoro kò kẹ́sẹ járí. Áńgẹ́lì òjíṣẹ́ náà sọ pé lẹ́yìn sáà “ẹ̀ẹ́dégbèjìlá alẹ́ àti òwúrọ̀ . . . a óò mú ibi mímọ́ náà wá sí ipò rẹ̀ tí ó tọ́,” tàbí pé “yóò ṣẹ́gun.”—Dáníẹ́lì 8:13, 14; The New English Bible.
25. Báwo ni sáà àkókò alásọtẹ́lẹ̀ ti ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ náà ṣe gùn tó, ìṣẹ̀lẹ̀ wo sì ni ó yẹ kí a so ó pọ̀ mọ́?
25 Ẹ̀ẹ́dégbèjìlá [2,300] ọjọ́ náà jẹ́ sáà àkókò alásọtẹ́lẹ̀ kan. Nípa bẹ́ẹ̀, ọdún alásọtẹ́lẹ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ òjìdín-nírínwó ọjọ́ ni èyí jẹ́. (Ìṣípayá 11:2, 3; 12:6, 14) Nígbà náà, ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọdún mẹ́fà, oṣù mẹ́rin, àti ogúnjọ́. Ìgbà wo ni sáà yìí jẹ́? Ó dára, ní ọdún 1930 sí 1939, inúnibíni tí a ń ṣe sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní onírúurú orílẹ̀-èdè. Àti pé, lákòókò Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti agbára ayé aláwẹ́ méjì ti Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣe inúnibíni lọ́nà rírorò sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èé ṣe? Nítorí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi dandan lé ‘ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.’ (Ìṣe 5:29) Nítorí náà, ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ náà ní láti so pọ̀ mọ́ ogun náà.b Ṣùgbọ́n kí ni a lè sọ nípa ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin sáà àkókò alásọtẹ́lẹ̀ yìí?
26. (a) Ó yá, a ò rírú ẹ̀ rí, ìgbà wo ni ó yẹ kí a bẹ̀rẹ̀ sí ka ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ náà? (b) Ìgbà wo ni ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ náà parí?
26 Kí “ibi mímọ́” tó lè jẹ́ èyí tí a “mú” tàbí tí a dá padà sí ipò tí ó yẹ kí ó wà, ó ní láti jẹ́ pé ìgbà tí ó fi wà ní “ipò rẹ̀ tí ó tọ́” lójú Ọlọ́run nígbà ìṣáájú ni ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ náà bẹ̀rẹ̀. Ó yá, a ò rírú ẹ̀ rí, èyí jẹ́ ní June 1, 1938, nígbà tí Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) tẹ apá àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ètò,” jáde. Apá kejì jáde nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) June 15, 1938. Tí a bá ka ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ (ọdún mẹ́fà àti oṣù mẹ́rin àti ogúnjọ́ lórí kàlẹ́ńdà àwọn Hébérù) láti June 1 tàbí 15, 1938, yóò mú wa dé October 8 tàbí 22, 1944. Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ ìpàdé tí a ṣe ní ìlú Pittsburgh, Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ní September 30 àti October 1, 1944, ààrẹ Watch Tower Society sọ̀rọ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà “Ìtògúnrégé Ìṣàkóso Ọlọ́run Lónìí.” Ní October 2, nígbà ìpàdé ẹgbẹ́ tí a ń ṣe lọ́dọọdún, a ṣàtúnṣe àkọsílẹ̀ ète ẹgbẹ́ nínú akitiyan láti mú kí ó bá ìṣètò ìṣàkóso Ọlọ́run mu bí ó bá ti ṣeé ṣe tó lábẹ́ òfin. Pẹ̀lú ìtẹ̀jáde tí ó mú kí àwọn ohun tí Bíbélì béèrè túbọ̀ ṣe kedere, kò pẹ́ tí a fi túbọ̀ gbé ìṣètò lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run kalẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
27. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé a ṣèdíwọ́ fún “apá pàtàkì ìgbà gbogbo” láàárín àwọn ọdún tí ó kún fún inúnibíni gidigidi nígbà Ogun Àgbáyé Kejì?
27 Nígbà tí ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ náà ń bá a lọ lọ́wọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1939, rírú ẹbọ “apá pàtàkì ìgbà gbogbo,” nínú ibùjọsìn Ọlọ́run ni a ṣèdíwọ́ fún gidigidi nítorí inúnibíni. Lọ́dún 1938, ẹ̀ka ilé iṣẹ́ mọ́kàndínlógójì ni Watch Tower Society ní, tí ń bójú tó iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí kárí ayé, ṣùgbọ́n nígbà tí ó fi máa di ọdún 1943, mọ́kànlélógún péré ni ó wà. Ìbísí nínú iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba sì kéré pẹ̀lú láàárín àkókò yẹn.
28, 29. (a) Bí òpin Ogun Àgbáyé Kejì ṣe ń sún mọ́lé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó ṣẹlẹ̀ nínú ètò àjọ Jèhófà? (b) Kí ni a lè sọ nípa ìsapá kíkankíkan tí ọ̀tá náà ṣe láti sọ “ibi mímọ́” náà di ahoro kí ó sì pa á run?
28 Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe sọ ṣáájú, nínú àwọn oṣù tí ó kẹ́yìn ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún tẹnu mọ́ ìpinnu wọn láti gbé ìṣàkóso Ọlọ́run lárugẹ nípa sísìn ín gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ kan tí a gbé kalẹ̀ lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Ète yìí ni wọ́n ní lọ́kàn tí ó fi jẹ́ pé ní ọdún 1944, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lórí ṣíṣe àtúntò iṣẹ́ wọn àti ọ̀nà tí a ń gbà ṣàkóso wọn. Kódà Ilé Ìṣọ́ October 15, 1944, (Gẹ̀ẹ́sì) gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tí a pè ní “A Ṣètò Wọn fún Iṣẹ́ Ìkẹyìn.” Èyí àti ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ mìíràn tí ó dá lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láàárín sáà kan náà yìí fi hàn pé ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́ náà ti dópin àti pé “ibi mímọ́” náà tún ti padà sí “ipò rẹ̀ tí ó tọ́.”
29 Àwọn ìsapá kíkankíkan tí ọ̀tá náà ṣe láti sọ “ibi mímọ́” di ahoro kí ó sì pa á run ti kùnà pátápátá. Ní ti tòótọ́, àṣẹ́kù àwọn “ẹni mímọ́” lórí ilẹ̀ ayé, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” ti ṣẹ́gun. (Ìṣípayá 7:9) Ibùjọsìn, tí ó ti wà ní ipò rẹ̀ tí ó tọ́ lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run, wá ń bá a lọ wàyí láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ sí Jèhófà.
30. Kí ni ó máa tó ṣẹlẹ̀ sí ‘ọba tí ó rorò ní ojú’ náà?
30 Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣì wà ní ipò rẹ̀. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ pé: “Ṣùgbọ́n a óò ṣẹ́ ẹ láìsí ọwọ́.” (Dáníẹ́lì 8:25) Láìpẹ́, agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì—‘ọba tí ó rorò ní ojú’ yìí—ni a óò ṣẹ́, láìjẹ́ láti ọwọ́ ènìyàn bí kò ṣe láti ọwọ́ agbára tí ó tayọ ti ènìyàn ní Amágẹ́dọ́nì. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 16:14, 16) Ó mà wúni lórí o, láti mọ̀ pé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà Ọlọ́run, Olórí àwọn ọmọ aládé, ní a óò wá dá láre ní ìgbà yẹn!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn agbára ayé méje tí ó ṣe pàtàkì lọ́nà àkànṣe nínú Bíbélì ni Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, Róòmù àti agbára ayé aláwẹ́ méjì náà, Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Gbogbo ìwọ̀nyí gba àfiyèsí nítorí pé wọ́n ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn Jèhófà.
b Dáníẹ́lì 7:25 tún sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tí a ń “bá a lọ ní fífòòró àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ.” Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú àkòrí tí ó ṣáájú èyí, a so èyí pọ̀ mọ́ ogun àgbáyé kìíní.
KÍ LO LÓYE?
• Kí ni
“àgbò” tí ó ní “ìwo méjì” ṣàpẹẹrẹ?
“òbúkọ onírun” àti “ìwo ńlá” tí ó ní ṣàpẹẹrẹ?
ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó jáde wá dípò “ìwo ńlá” náà ṣàpẹẹrẹ?
ìwo kékeré tí ó hù jáde láti inú ọ̀kan lára ìwo mẹ́rin náà ṣàpẹẹrẹ?
• Láàárín Ogun Àgbáyé Kejì, báwo ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣe gbìyànjú láti sọ “ibi mímọ́” náà di ahoro, ó ha sì kẹ́sẹ járí bí?
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 166]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ilẹ̀ Ọba Mídíà Òun Páṣíà
MAKEDÓNÍÀ
ÍJÍBÍTÌ
Mémúfísì
ETIÓPÍÀ
Jerúsálẹ́mù
Bábílónì
Ekibátánà
Súsà
Persepolis
ÍŃDÍÀ
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 169]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì
MAKEDÓNÍÀ
ÍJÍBÍTÌ
Bábílónì
Odò Indus
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 172]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ilẹ́ Ọba Róòmù
ILẸ̀ BRITANNIA
ÍTÁLÌ
Róòmù
Jerúsálẹ́mù
ÍJÍBÍTÌ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 164]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 174]
Àwọn ẹni pàtàkì pàtàkì nínú Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà:
1. George Washington, ààrẹ àkọ́kọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà (ọdún 1789 sí 1797)
2. Ọbabìnrin Victoria ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (ọdún 1837 sí 1901)
3. Woodrow Wilson, ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà (ọdún 1913 sí 1921)
4. David Lloyd George, olórí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (ọdún 1916 sí 1922)
5. Winston Churchill, olórí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (ọdún 1940 sí 1945, 1951 sí 1955)
6. Franklin D. Roosevelt, ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà (ọdún 1933 sí 1945)