Ìjagunmólú Ìkẹyìn ti Mikaeli, Balógun Ńlá Náà
“Ní àkókò náà ni Mikaeli, balógun ńlá nì, tí yóò gbèjà àwọn ọmọ àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò dìde.”—DANIELI 12:1.
1. Irú ìṣarasíhùwà wo ni ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ayé ti fihàn sí ipò ọba-aláṣẹ Jehofa, báwo sì ni èyí kò ṣe yọ ọba àríwá sílẹ̀?
“TA NI [Jehofa, NW], tí èmi ó fi gba ohùn rẹ̀ gbọ́ láti jẹ́ kí Israeli kí ó lọ?” (Eksodu 5:2) Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn Farao sí Mose. Ní kíkọ̀ láti mọ ipò-àjùlọ jíjẹ́ Ọlọrun Jehofa ní àmọ̀jẹ́wọ́, Farao pinnu láti mú kí Israeli wà nínú ìsìnrú. Àwọn olùṣàkóso mìíràn ti fi ìkẹ́gàn kan-náà hàn fún Jehofa, èyí kò si yọ àwọn ọba inú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli sílẹ̀. (Isaiah 36:13-20) Nítòótọ́, ọba àríwá ti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Angeli náà sọ pé: “Òun ó sì gbé ara rẹ̀ ga, yóò sì gbéra rẹ̀ ga ju gbogbo ọlọrun lọ, yóò sì máa sọ̀rọ̀ ohun ìyanu sí Ọlọrun àwọn ọlọrun. . . . Bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò sì ka Ọlọrun àwọn baba rẹ̀ sí, tàbí ìfẹ́ àwọn obìnrin, òun kì yóò sì ka ọlọrun kan sí: nítorí tí yóò gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni gbogbo lọ.”—Danieli 11:36, 37.
2, 3. Ní ọ̀nà wo ni ọba àríwá gba kọ “Ọlọrun àwọn baba rẹ̀” sílẹ̀ láti fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú jíjọ́sìn “ọlọrun” mìíràn?
2 Ní mímú àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ, ọba àríwá kọ “Ọlọrun àwọn baba rẹ̀” (tàbí, “àwọn ọlọrun àwọn babańlá rẹ̀,” The New English Bible), sílẹ̀ ìbáà jẹ́ àwọn ọlọrun òrìṣà ti Romu tàbí ọlọrun Mẹ́talọ́kan ti Kristẹndọm. Hitler lo Kristẹndọm fún àwọn ète tirẹ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fihàn pé ó wéwèé láti fi ṣọ́ọ̀ṣì titun, ti Germany rọ́pò rẹ̀. Ọba tí ó gbapò rẹ̀ gbé ẹ̀kọ́ àìgbàgbọ́-nínú-wíwà-Ọlọrun lárugẹ ní gbangba wálíà. Ọba àríwá tipa báyìí sọ ara rẹ̀ di ọlọrun, ‘ní gbígbé ara rẹ̀ ga ju ẹni gbogbo lọ.’
3 Àsọtẹ́lẹ̀ náà ń báa lọ pé: “Ní ipò rẹ̀, yóò máa bu ọlá fún ọlọrun àwọn ìlú olódi, àní ọlọrun kan tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ rí ni yóò máa fi wúrà, àti fàdákà, àti òkúta iyebíye, àti ohun dáradára bu ọlá fún.” (Danieli 11:38) Níti tòótọ́, ọba àríwá gbé ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ rẹ̀ karí ìgbàgbọ́ nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ìlànà ológun ti òde-òní, “ọlọrun àwọn ìlú olódi.” Jálẹ̀ gbogbo àkókò òpin, ó ti wá ìgbàlà nípasẹ̀ “ọlọrun” yìí, ní fífi ọrọ̀ tabua rúbọ lórí pẹpẹ rẹ̀.
4. Àṣeyọrí wo ni ọba àríwá ti ní?
4 “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò ṣe [lọ́nà gbígbéṣẹ́, NW] nínú ìlú olódi wọnnì tí ó lágbára jùlọ nípa ìrànlọ́wọ́ ọlọrun àjèjì, ẹni tí ó jẹ́wọ́ rẹ̀ ni yóò fi ògo fún, tí yóò sì mú ṣe alákòóso ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò sì pín ilẹ̀ fún un ní èrè.” (Danieli 11:39) Ní gbígbẹ́kẹ̀lé “ọlọrun àjèjì” ti ológun rẹ̀, ọba àríwá ti gbégbèésẹ̀ “lọ́nà gbígbéṣẹ́” jùlọ, ní fífẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ àkòtagìrì agbára ológun ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Timoteu 3:1, NW) Àwọn wọnnì tí wọ́n ti ìjẹ́wọ́-èrò rẹ̀ lẹ́yìn ni ó fi ìtìlẹ́yìn ti òṣèlú, ìsúnná-owó, àti nígbà mìíràn ti ológun san èrè fún.
“Ní Àkókò Òpin”
5, 6. Báwo ni ọba gúúsù ti ṣe ‘kàn,’ báwo sì ni ọba àríwá ti ṣe hùwàpadà?
5 Danieli 11:40a kà pé: “Ní àkókò òpin, ọba gúúsù yóò kàn án.” Ẹsẹ yìí àti àwọn tí ó tẹ̀lé e ni a ti wò gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó máa ní ìmúṣẹ rẹ̀ ní ọjọ́-ọ̀la wa. Bí ó ti wù kí ó rí, bí “àkókò òpin” níhìn-ín bá túmọ̀sí ohun kan-náà bí ó ti rí ní Daniel 12:4, 9, a níláti wọ̀nà fún ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ọba gúúsù ha ti “kan” ọba àríwá ní àkókò yìí bí? Bẹ́ẹ̀ni, nítòótọ́. Lẹ́yìn ogun àgbáyé kìn-ín-ní, ìmùlẹ̀-àdéhùn àlàáfíà ti ìfìyàjẹni náà dájúdájú jẹ́ ‘kíkàn’ kan, ìrunilọ́kànsókè sí ìránró. Lẹ́yìn ìjagunmólú rẹ̀ nínú ogun àgbáyé kejì, ọba gúúsù dojú àwọn ohun-ìjà alágbára átọ́míìkì bíbanilẹ́rù kọ alábàádíje rẹ̀, tí ó sì ṣètò àjọṣepọ̀ ológun lílágbára, NATO, lòdì sí i. Bí ọdún tí ń gorí ọdún, ‘kíkàn’ rẹ̀ wémọ́ ìfimúfínlẹ̀ ṣe amí ọlọ́gbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga àti ìgbéjàkoni lọ́nà ti ìṣèlú àti ti ológun.
6 Báwo ni ọba àríwá ṣe hùwàpadà? “Ọba àríwá yóò sì fi kẹ̀kẹ́, àti ẹlẹ́ṣin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀, kọlù ú bí àfẹ́yíká-ìjì: òun ó sì wọ ilẹ̀ wọnnì yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, yóò sì rékọjá.” (Danieli 11:40b) Ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ti gbé ìlànà-ètò ìmúgbòòrò ààlà-ìpínlẹ̀ ti ọba àríwá jáde lákànṣe. Nígbà ogun àgbáyé kejì, “ọba” Nazi yabo àwọn ààlà-ìpínlẹ̀ rẹ̀ kọjá sínú àwọn ilẹ̀ tí ó wà láyìíká. Ní òpin ogun yẹn, “ọba” olùgbapò rẹ̀ kọ́ ilẹ̀-ọba lílágbára kan sẹ́yìn òde àwọn ààlà-ìpínlẹ̀ tirẹ̀. Nígbà Ogun Tútù, ọba àríwá bá alábàádíje rẹ̀ jà nípasẹ̀ àwọn ogun tí tọ̀tún-tòsì wọn tìlẹ́yìn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn àti àwọn ọmọ-ogun ọlọ̀tẹ̀ ní Africa, Asia, àti Latin America. Ó ṣenúnibíni sí àwọn ojúlówó Kristian, ní pípààlà sí ìgbòkègbodò wọn (ṣùgbọ́n láìdá a dúró lọ́nàkọnà). Àwọn ìgbéjàkoni lọ́nà ti ìṣèlú àti ti ológun rẹ̀ mú iye awọn ilẹ̀ kan wá sábẹ́ àkóso rẹ̀. Èyí rí gẹ́lẹ́ bí angeli náà ti sọtẹ́lẹ̀: “Yóò sì wọ ilẹ̀ ológo nì [dúkìá-ìní tẹ̀mí àwọn ènìyàn Ọlọrun] pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó sì bì ṣubú.”—Danieli 11:41a.
7. Àwọn ààlà wo ni ó wà fún ìlànà-ètò ìmúgbòòrò ààlà-ìpínlẹ̀ ti ọba àríwá?
7 Síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé—láti inú ojú-ìwòye alábàádíje rẹ̀—ọba àríwá ti farahàn bí ewu tí ń yọnilẹ́nu, ìṣẹ́gun ayé kò tíì tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. “Àwọn wọ̀nyí ni yóò sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àní Edomu, àti Moabu, àti olórí àwọn ọmọ Ammoni.” (Danieli 11:41b) Ní àwọn ìgbà àtijọ́, Edomu, Moabu, àti Ammoni ni wọ́n wà ní ibi tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ agbedeméjì Egipti àti Siria. A lè sọ pé wọ́n dúró lónìí fún àwọn orílẹ̀-èdè àti ètò-àjọ tí ọba àríwá yànsọjú ṣùgbọ́n tí kò lè mú wá sábẹ́ agbára ìdarí rẹ̀.
‘Egipti Kì Yóò Là Á’
8, 9. Báwo ni agbára-ìdarí ọba àríwá ṣe di èyí tí a mọ̀lára, àní nípasẹ̀ olórí alábàádíje rẹ̀ pàápàá?
8 Angeli náà ń báa lọ láti sọ pé: “Òun ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí ilẹ̀ wọnnì pẹ̀lú, ilẹ̀ Egipti kì yóò sì là á. Ṣùgbọ́n òun óò lágbára lórí ìṣúra wúrà, àti ti fàdákà, àti lórí gbogbo ohun dáradára ní ilẹ̀ Egipti: àti àwọn ará Libia, àwọn ará Etiopia yóò sì wà lẹ́yìn rẹ̀.” (Danieli 11:42, 43) Àní ọba gúúsù pàápàá, “Egipti,” kò la àwọn àbáyọrí ìlànà-elétò ìmúgbòòrò ààlà-ìpínlẹ̀ ti ọba àríwá já. Fún àpẹẹrẹ, ó jìyà ìṣẹ́gun pípẹtẹrí ní Vietnam. Kí sì ni nípa ti “àwọn ará Libia, àwọn ará Etiopia”? Àwọn aládùúgbò Egipti ìgbàanì wọ̀nyí lọ́nà yíyẹ lè jẹ́ òjìji ìṣáájú fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ alámùúlégbè “Egipti” òde-òní, bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ibi tí wọ́n wà sí i, tí wọ́n sì ti jẹ́ ọmọlẹ́yìn, ‘tí wọ́n wà lẹ́yìn,’ ọba àríwá ní àwọn ìgbà mìíràn.
9 Ọba àríwá ha ti ṣàkóso lórí ‘ìṣúra Egipti’ tí ó farasin bí? Ó dára, ó dájú pé òun kò tíì ṣẹ́gun ọba gúúsù, títí tí ó sì fi di 1993 ipò ayé mú kí ó dàbí ohun tí kò ṣeéṣe pé yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ti ní agbára-ìdarí lílágbára lórí ọ̀nà tí ọba gúúsù ń gba lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ níti ọ̀ràn ìnáwó. Nítorí ìbẹ̀rù alábàádíje rẹ̀, ọba gúúsù ti ya àròpọ̀ iye púpọ̀ jaburata sọ́tọ̀ lọ́dọọdún fún pípa àwọn àkòtagìrì ọmọ-ogun orí ilẹ̀, ti ojú-omi, àti ti òfuurufú mọ́. Dé ìwọ̀n-ààyè yìí ni a lè sọ pé ọba àríwá ti ‘lágbára lórí,’ darí, ìṣètò ọrọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọba gúúsù.
Ìgbétáásì Àṣekẹ́yìn ti Ọba Àríwá
10. Ní ọ̀nà wo ni angeli náà gbà ṣàpèjúwe òpin ìdíje tí ó wà láàárín àwọn ọba méjèèjì náà?
10 Ìbáradíje tí ó wà láàárín àwọn ọba méjèèjì náà ha ń bá a lọ títí gbére bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Angeli náà sọ fún Danieli pé: “Ìhìn láti ìlà-oòrùn, àti láti ìwọ̀-oòrùn wá yóò dààmú rẹ̀ [ọba àríwá]: nítorí náà ni yóò ṣe fi ìbínú ńlá jáde lọ láti máa parun, àti láti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò pátápátá. Òun ó sì pàgọ́ ààfin rẹ̀ láàárín omi kọjú sí òkè mímọ́ ológo nì; ṣùgbọ́n òun ó sì dé òpin rẹ̀, kì yóò sì sí ẹni tí yóò ràn án lọ́wọ́.”—Danieli 11:44, 45.
11, 12. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òṣèlú ẹnu àìpẹ́ yìí wo ni wọ́n níí ṣe pẹ̀lú ìbáradíje láàárín ọba àríwá àti ọba gúúsù, kí ni a sì níláti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ síbẹ̀?
11 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣì jẹ́ ti ọjọ́ iwájú, nítorí náà a kò lè sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò ṣe ní ìmúṣẹ. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ipò òṣèlú nípa àwọn ọba méjèèjì ti yípadà. Ìbáradíje kíkorò tí ó wà láàárín United States àti àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà-Oòrùn Europe ti rọlẹ̀. Síwájú síi, Soviet Union ni a túká ní 1991 tí kò sì sí mọ́.—Wo ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti March 1, 1992, ojú-ìwé 4 àti 5.
12 Nítorí náà ta ni ọba àríwá nísinsìnyí? A ha níláti dá a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tí jẹ́ apákan Soviet Union rí bí? Tàbí ó ha ń yí ìdánimọ̀ rẹ̀ padà pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní iye ìgbà ṣáájú ni bí? Àwa kò lè sọ. Ta ni yóò jẹ́ ọba àríwá nígbà tí Danieli 11:44, 45 bá ní ìmúṣẹ? Ìbáradíje tí ó wà láàárín àwọn ọba méjèèjì náà yóò ha tún buná làù lẹ́ẹ̀kan síi bí? Kí sì ni nípa ìkójọ gègèrè ti àwọn ohun ìjà alágbára átọ́míìkì tí ó ṣì wà síbẹ̀ ní iye àwọn ilẹ̀ kan? Àkókò nìkan ni yóò pèsè ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
13, 14. Kí ni a mọ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la àwọn ọba méjèèjì náà?
13 Ohun kan ni a mọ̀. Láìpẹ́, ọba àríwá yóò darí ìgbétáásì ìgbéjàkoni tí yóò bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ ‘ìhìn láti ìlà-oòrùn, àti láti ìwọ̀-oòrùn wá tí yóò dààmú rẹ.’ Kété ṣáájú “òpin” rẹ̀ ni ìgbétáásì yìí yóò wáyé. A lè kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ síi nípa àwọn “ìhìn” yìí bí a bá gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli mìíràn yẹ̀wò.
14 Bí ó ti wù kí ó rí, lákọ̀ọ́kọ́ ná, ṣàkíyèsí pé àwọn ìṣesí ọba àríwá wọ̀nyí ni a kò sọ pé ó jẹ́ ní ìlòdìsí ọba gúúsù. Kò wá sí òpin rẹ̀ láti ọwọ́ alábàádíje rẹ̀ ńlá. Bákan-náà, ọba gúúsù ni a kò ti ọwọ́ ọba àríwá parun. Ọba gúúsù (tí a fi ìwo ìkẹyìn tí yóò farahàn lórí ẹranko ẹhànnà kan ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn) ni a parun “láìsí ọwọ́ [ènìyàn]” nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọrun. (Danieli 7:26; 8:25) Níti tòótọ́, gbogbo àwọn ọba ilẹ̀-ayé ni a ti ọwọ́ Ìjọba Ọlọrun parun níkẹyìn nínú ìja ogun Armageddoni, ó sì dájú pé èyí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba àríwá. (Danieli 2:44; 12:1; Ìfihàn 16:14, 16) Danieli 11:44, 45 ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó lọ jálẹ̀ sí ìjà ogun àjàkẹ́yìn yẹn. Abájọ tí ‘kì yóò fi sí ẹni tí yóò ràn án lọ́wọ́’ nígbà tí ọba àríwá bá ṣalábàápàdé ìparun rẹ̀!
15. Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ni wọ́n ṣẹ́kù tí a óò jíròrò?
15 Nígbà náà, kí ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn náà tí ó tànmọ́lẹ̀ sórí àwọn “ìhìn” tí ó sún ọba àríwá láti jáde láti “mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò pátápátá”? Àwọn wo sì ni “ọ̀pọ̀lọpọ̀” náà tí ohun yóò fẹ́ láti parun?
Ìhìn kan Láti Ìlà-Oòrùn Wá
16. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ títayọ wo ni ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ ṣáájú Armageddoni? (b) Àwọn wo ni “àwọn ọba àti ìlà-oòrùn wá”?
16 Ṣáájú ìjà ogun àjàkẹ́yín náà, Armageddoni, ọ̀tá ńlá kan fún ìjọsìn tòótọ́ ni a gbọ́dọ̀ parun—Babiloni Nlá tí ó dàbí aṣẹ́wó, ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìfihàn 18:3-8) Ìtújáde àwokòtò kẹfà ti ìbínú Ọlọrun sórí odò Eufrate ìṣàpẹẹrẹ jẹ́ òjìji ìṣáájú fún ìparun rẹ̀. Odò náà gbẹ “kí a lè pèsè ọ̀nà fún àwọn ọba àti ìlà-oòrùn wá.” (Ìfihàn 16:12) Àwọn wo ni àwọn ọba wọ̀nyí? Wọn kìí ṣe ẹlòmíràn yàtọ̀ sí Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi!a
17. (a) Kí ni Bibeli sọ fún wa nípa ìparun Babiloni Ńlá? (b) Kí ni ẹ̀rí lè fihàn pé ìhìn “láti ìlà-oòrùn” jẹ́?
17 Ìparun Babiloni Ńlá ni a ṣàpèjúwe kedere nínú ìwé Ìfihàn: “Àwọn ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí [àwọn ‘ọba’ tí ń ṣàkóso ní àkókò òpin], àti ẹranko ẹhànnà náà [ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, tí ó dúró fún ètò-àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè], àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparun-dahoro àti ìhòòhò, wọn yóó sì jẹ àwọn ibi ẹran-ara rẹ̀ wọn yóó sì fi iná sun ún pátápátá.” (Ìfihàn 17:16, NW) Nítòótọ́, àwọn orílẹ̀-èdè ‘pa ẹran-ara púpọ̀ run’! (Danieli 7:5, NW) Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwọn alákòóso, títíkan ọba àríwá, yóò fi pa Babiloni Ńlá run? Nítorí pé ‘Ọlọrun fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ sẹ.’ (Ìfihàn 17:17) Ìhìn náà tí ó wá láti “ìlà oòrun” lọ́nà yíyẹ lè tọ́ka sí ìgbésẹ̀ Jehofa yìí, nígbà tí, ní ọ̀nà kan tí òun yàn, ó fi sínú ọkàn àwọn ènìyan tí wọ́n jẹ́ aṣáájú láti pa aṣẹ́wó ìsìn ńlá náà rẹ́ ráúráú.—Danieli 11:44.
Ìhìn kan Láti Àríwá Wá
18. Àyànsọjú mìíràn wo ni ọba àríwá ní, níbo sì ni èyí fi í sí nígbà tí ó wá sí òpin rẹ̀?
18 Ṣùgbọ́n àyànsọjú mìíràn wà fún ìrunú ọba àríwá. Angeli náà sọ pé yóò “sì pàgọ́ ààfin rẹ̀ láàárín omi [“òkun títóbilọ́lá,” NW] kọjú sí òkè mímọ́ ológo nì.” (Danieli 11:45) Ní àkókò Danieli, òkun títóbilọ́lá náà ni Meditareniani, òkè kanṣoṣo náà sì ni Sioni, níbi ti tẹ́ḿpìlì Ọlọrun wà nígbà kan rí. Fún ìdí yìí, nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà, ọba àríwá tí inú rẹ̀ ru náà dárí ìgbétáásì ológun lòdìsí àwọn ènìyàn Ọlọrun! Ni èrò ìtúmọ̀ tẹ̀mí lónìí, ‘láàárín òkun títóbilọ́lá àti òkè mímọ́’ fi í sínú ọrọ̀-ìní tẹ̀mí ti àwọn ẹni-àmì-òróró ìránṣẹ́ Ọlọrun, tí wọ́n ti jáde wá láti inú “òkun” aráyé tí a sọ dàjèjì tí wọ́n sì nírètí ṣíṣàkóso pẹ̀lú Jesu Kristi lórí Òkè Sioni ti ọ̀run.—Isaiah 57:20; Heberu 12:22; Ìfihàn 14:1.
19. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Esekieli ṣe fihàn, báwo ni a ṣe lè dá ìròyìn náà tí ó ru ìgbéjàkó Gogu sókè mọ̀? (Wo àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé.)
19 Esekieli, alájọgbáyé Danieli, tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìgbéjàko àwọn ènìyàn Ọlọrun “níkẹyìn ọjọ́.” Ó sọ pé Gogu ti Magogu, tí ó dúró fún Satani Eṣu, ni yóò kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkóguntini náà. (Esekieli 38:16) Láti apá ìhà wo, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ni Gogu ti wá? Nípasẹ̀ Esekieli, Jehofa sọ pe: “Ìwọ ó sì ti ipò rẹ wá láti ìhà àríwá.” (Esekieli 38:15) Fún ìdí yìí, ìhìn “láti ìlà-oòrùn” lọ́nà yíyẹ lè jẹ́ ìgbékèéyíde Satani tí ń ru ọba àríwá àti gbogbo àwọn ọba yòókù lọ́kàn sókè làti gbéjàko àwọn ènìyàn Jehofa.b—Fiwé Ìfihàn 16:13, 14; 17:14.
20, 21. (a) Èéṣe ti Gogu yóò fi ru àwọn orílẹ̀-èdè lọ́kàn sókè, títíkan ọba àríwá, láti gbéjàko àwọn ènìyàn Ọlọrun? (b) Ìgbéjàkò rẹ̀ yóò ha kẹ́sẹjárí bí?
20 Gogu ṣètò ìkọlunilójijì àrúnpárúnsẹ̀sí yìí nítorí aásìkí “Israeli Ọlọrun,” tí, pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àgùtàn mìíràn, wọ́n kìí ṣe apákan ayé rẹ̀ mọ́. (Galatia 6:16; Johannu 10:16; 17:15, 16; 1 Johannu 5:19) Gogu fojú àbùkù wo “àwọn ènìyàn kan tí a kójọ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè wá, ọ̀kan tí ń kó ọrọ̀ àti dúkìá [tẹ̀mí] jọ.” (Esekieli 38:12, NW; Ìfihàn 5:9; 7:9) Ní ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àwọn ènìyàn Jehofa ń láásìkí lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ní ọ̀pọ̀ àwọn ilẹ̀ ní Europe, Africa, àti Asia níbi tí a ti fòfindè wọ́n tẹ́lẹ̀rí, wọ́n ń jọ́sìn fàlàlà nísinsìnyí. Láàárín 1987 àti 1992, iye tí ó fi púpọ̀ rékọjá mílíọ̀nù kan “àwọn ohun fífanilọ́kànmọ́ra” ti inú àwọn orílẹ̀-èdè jáde wá sí ilé ìjọsìn tòótọ́ ti Jehofa. Nípa tẹ̀mí, wọ́n lọ́rọ̀ wọ́n sì wà ní àlááfíà.—Haggai 2:7, NW; Isaiah 2:2-4; 2 Korinti 8:9.
21 Ní wíwo dúkìá-ìní àwọn Kristian gẹ́gẹ́ bíi “ilẹ̀ ìletò tí kò ní odi” tí ó rọrùn láti ṣẹ́gun, Gogu lo ìsapá gíga jùlọ láti pa ohun yìí tí ń dí i lọ́wọ́ láti darí aráyé pátápátá rẹ́ kúrò. (Esekieli 38:11) Ṣùgbọ́n ó kùnà. Nígbà tí àwọn ọba ayé bá gbéjàko àwọn ènìyàn Jehofa, wọ́n ‘yóò wá sí ìparun wọn.’ Báwo?
Ọba Kẹta
22, 23. Nígbà tí Gogu ṣe ìgbéjàkò, ta ni ó dúró fún àwọn ènìyàn Ọlọrun, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?
22 Esekieli sọ pé ìgbéjàkoni Gogu ni àmì fún Jehofa Ọlọrun láti dìde nítìtorí àwọn ènìyàn rẹ̀ kí ó sì pa àwọn agbo-ọmọ-ogun Gogu run “lórí òkè gíga Israeli.” (Esekieli 38:18; 39:4) Èyí rán wa létí ohun tí angeli náà sọ fún Danieli: “Ní àkókò náà ni Mikaeli, balógun ńlá nì, tí yóò gbèjà àwọn ọmọ àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò dìde, àkókò wàhálà yóò sì wà, irú èyí tí kò tíì sí rí, láti ìgbà tí orílẹ̀-èdè ti wà títí fi di ìgbà àkókò yìí, àti ní ìgbà àkókò náà ni a ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là, àní gbogbo àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sínú ìwé.”—Danieli 12:1.
23 Ní 1914, Jesu—jagunjagun ti ọ̀run náà Mikaeli—di Ọba Ìjọba Ọlọrun ní ọ̀run. (Ìfihàn 11:15; 12:7-9) Láti ìgbà náà wá, ni òun ti ń dúró ‘nítìtorí àwọn ọmọkùnrin àwọn ènìyàn Danieli.’ Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́, òun yóò “dìde” ní orúkọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọba-Ajagun tí kò ṣeé ṣẹ́gun, tí ń “san ẹ̀san fún àwọn tí kò mọ Ọlọrun, tí wọn kò sì gba ìhìnrere Jesu Oluwa wa gbọ́.” (2 Tessalonika 1:8) Gbogbo orílẹ̀-èdè ayé pátá, títíkan àwọn ọba inú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli yóò “káàánú.” (Matteu 24:30) Pẹ̀lú èrò ibi síbẹ̀ nínú ọkàn-àyà wọn sí ‘àwọn ènìyàn Danieli,’ wọn yóò ti ọwọ́ ‘Mikaeli, balógun ńlá náà,’ ṣègbé títíláé.—Ìfihàn 19:11-21.
24. Ipa wo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ asọtẹ́lẹ̀ Danieli yìí níláti ní lórí wa?
24 Àwa kò ha yánhànhàn láti ṣẹlẹ́rìí ayọ̀-ìṣẹ́gun títóbilọ́lá ti Mikaeli yẹn àti ti Ọlọrun rẹ̀, Jehofa bí? Nítorí pé ìjagunmólú yẹn yóò túmọ̀sí “àsálà,” lílàájá, fún àwọn Kristain tòótọ́. (Fiwé Malaki 4:1-3.) Fún ìdí yìí, ní wíwo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà, àwa fi àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu sọ́kàn pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà; ṣe àìsinmi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò tí kò wọ̀.” (2 Timoteu 4:2) Ẹ jẹ́ ki a di Ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin kí a sì fi taápọn-taápọn wá àwọn àgùtàn Jehofa rí nígbà tí àkókò wíwọ̀ náà ṣì ń baá lọ. Nínú apá tí ó gbẹ̀yìn nínú eré-ìje fún ìyè ni a wà báyìí. Èrè náà wà ní ọ̀kánkán iwájú. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu làti faradà á títí dé òpin kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn wọnnì tí a ó gbàlà.—Matteu 24:13; Heberu 12:1.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Revelation—Its Grand Climax At Hand! tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ojú-ìwé 229 sí 230.
b Ní ọ̀nà mìíràn, ìhìn “láti ìhà àríwá” ni ẹ̀rí lè fihàn pé ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jehofa, lójú-ìwòye àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Gogu: “Èmi ó . . . fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, èmi ó sì mú ọ jáde wá.” “Èmi ó sì mú ọ gòkè wá láti ìhà àríwá, èmi ó sì mú ọ wá sórí òkè gíga Israeli.”—Esekieli 38:4; 39:2; fiwé Orin Dafidi 48:2.
Ìwọ Ha Lóye Bí?
◻ Báwo ni ọba gúúsù ṣe kan ọba àríwá jálẹ̀ gbogbo àkókò òpin?
◻ Kì ni a ṣì ní láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nípa àbájáde ìbáradíje láàárín àwọn ọba méjèèjì?
◻ Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjì wo ṣáájú Armageddoni ni ó dájú pe wọn yóò ni ọba àríwá nínú?
◻ Báwo ni ‘Mikaeli, balógun ńlá náà,’ yóò ṣe dáàbòbo àwọn ènìyàn Ọlọrun?
◻ Báwo ni a ṣe níláti hùwàpadà sí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nípa àsọtẹ́lẹ̀ Danieli?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ọba àríwá ti jọ́sìn ọlọrun kan tí ó yàtọ̀ sí àwọn ọlọrun àwọn tí ó ṣaájú rẹ̀
[Credit Line]
Òkè lápá òsì àti àárín: UPI/Bettmann; ìsàlẹ̀ lápá òsì: Reuters/Bettmann; ìsàlẹ̀ lápá ọ̀tún: Jasmin/Gamma Liaison