ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 20
Ta Ni “Ọba Àríwá” Lónìí?
“Ó máa . . . pa run, kò sì ní sẹ́ni tó máa ràn án lọ́wọ́.”—DÁN. 11:45.
ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÀWỌN nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ti túbọ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé apá tó kẹ́yìn lára àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé burúkú yìí là ń gbé. Láìpẹ́, Jèhófà àti Jésù Kristi máa pa gbogbo ìṣàkóso tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run run. Àmọ́ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, ọba àríwá àti ọba gúúsù á ṣì máa bára wọn jà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n á máa bá àwọn èèyàn Ọlọ́run jà.
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:40–12:1. A máa sọ ẹni tó jẹ́ ọba àríwá lónìí, àá sì jíròrò ìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dá wa nídè láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí.
ỌBA ÀRÍWÁ TUNTUN
3-4. Ta ni ọba àríwá lónìí? Ṣàlàyé.
3 Lẹ́yìn tí ìjọba Soviet Union wá sópin tó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lọ́dún 1991, àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní ilẹ̀ yẹn rí ‘ìrànlọ́wọ́ díẹ̀’ gbà ní ti pé wọ́n lómìnira. (Dán. 11:34) Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti wàásù fàlàlà, ká tó ṣẹ́jú pẹ́ àwọn akéde tó wà lábẹ́ ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́ ti tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di ọba àríwá. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ká tó lè sọ pé ẹnì kan ni ọba àríwá tàbí ọba gúúsù, ó gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta yìí: (1) ó máa ṣàkóso àwọn èèyàn Ọlọ́run tàbí kó ṣenúnibíni sí wọn, (2) ó máa ṣe ohun tó fi hàn pé ó kórìíra Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ àti (3) ó máa bá ọba kejì jà.
4 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìdí tá a fi gbà pé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ọba àríwá. (1) Wọ́n ń fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà lábẹ́ àkóso wọn. (2) Ohun tí wọ́n ń ṣe fi hàn pé wọ́n kórìíra Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. (3) Wọ́n ń bá Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó jẹ́ ọba gúúsù jà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ṣe tó fi hàn pé àwọn ni ọba àríwá lóòótọ́.
ỌBA ÀRÍWÁ ÀTI ỌBA GÚÚSÙ Á MÁA KỌ LU ARA WỌN
5. Àsìkò wo ni Dáníẹ́lì 11:40-43 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn?
5 Ka Dáníẹ́lì 11:40-43. Apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ó jẹ́ ká mọ bí ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣe máa bára wọn jà. Bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọba gúúsù ‘máa kọ lu’ ọba àríwá tàbí kó “fi ìwo kàn án.”—Dán. 11:40; àlàyé ìsàlẹ̀.
6. Kí ló fi hàn pé àwọn ọba méjèèjì náà ti ń kọ lu ara wọn?
6 Ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣì ń bára wọn jà kí wọ́n lè mọ ìjọba tó lágbára jù láyé. Bí àpẹẹrẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìjọba Soviet Union àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso èyí tó pọ̀ jù lára ilẹ̀ Yúróòpù. Ohun tó ṣe náà mú kí ọba gúúsù dá ẹgbẹ́ apawọ́pọ̀jagun tó lágbára sílẹ̀, ìyẹn àjọ NATO. Ohun míì ni pé ọba àríwá àti ọba gúúsù ń ná òbítíbitì owó kí wọ́n lè kó ohun ìjà jọ kí wọ́n sì ní ẹgbẹ́ ológún tó lágbára jù lọ. Ọba àríwá bá ọ̀tá rẹ̀ yìí jà nínú àwọn ogun tí tọ̀tún tòsì wọn ti pọ̀n sẹ́yìn àwọn orílẹ̀-èdè ní Áfíríkà, Éṣíà àti Látìn Amẹ́ríkà. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ńṣe ni orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ túbọ̀ ń lo agbára wọn lọ́pọ̀ ibi láyé. Bákan náà, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé fimú fínlẹ̀ kí wọ́n lè jí ìsọfúnni ara wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọba yìí ń fi kọ̀ǹpútà gbéjà ko ara wọn kí wọ́n lè ba ètò ìṣòwò àti ìṣèlú ara wọn jẹ́. Láfikún sí èyí, Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ọba àríwá ò ní ṣíwọ́ àtimáa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ohun tó sì ń ṣe nìyẹn.—Dán. 11:41.
ỌBA ÀRÍWÁ WỌ “ILẸ̀ ÌṢELỌ́ṢỌ̀Ọ́”
7. Kí ni “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́”?
7 Dáníẹ́lì 11:41 sọ pé ọba àríwá máa wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.” Ilẹ̀ wo nibí yìí ń sọ? Lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni “ibi tó rẹwà jù ní gbogbo ilẹ̀.” (Ìsík. 20:6) Àmọ́ ohun tó jẹ́ kí ilẹ̀ náà ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé ibẹ̀ ni àwọn èèyàn ti máa ń ṣe ìjọsìn tòótọ́. Látìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni, “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” náà kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan pàtó. Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu torí pé ibi gbogbo láyé làwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà wà. Lónìí, “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” náà ni Párádísè tẹ̀mí táwọn èèyàn Ọlọ́run wà. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú Párádísè tẹ̀mí yìí ni pé wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà láwọn ìpàdé wọn, wọ́n sì ń wàásù nípa Jèhófà fáwọn èèyàn.
8. Báwo ni ọba àríwá ṣe wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́”?
8 Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọba àríwá ti wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.” Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì jẹ́ ọba àríwá, pàápàá nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọba yìí wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” ní ti pé ó ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì pa ọ̀pọ̀ lára wọn. Bákan náà, lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì nígbà tí ìjọba Soviet Union di ọba àríwá, ọba náà wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” ní ti pé òun náà ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì kó ọ̀pọ̀ lára wọn lọ sí ìgbèkùn.
9. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, báwo ni orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ṣe wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́”?
9 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ti wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.” Kí ló fi hàn bẹ́ẹ̀? Lọ́dún 2017, ọba àríwá tuntun yìí fòfin de iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó sì ju àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kan sẹ́wọ̀n. Ó tún fòfin de àwọn ìtẹ̀jáde wa títí kan Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ohun míì tó tún ṣe ni pé, ó gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà títí kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa. Pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ṣe yìí, lọ́dún 2018 Ìgbìmọ̀ Olùdarí jẹ́ kó ṣe kedere pé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ọba àríwá. Àmọ́ láìka gbogbo bó ṣe ń fojú pọ́n àwọn èèyàn Jèhófà tó sì ń ṣenúnibíni sí wọn, àwọn èèyàn Jèhófà kò bá ìjọba jà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò wá bí wọ́n ṣe máa dojú ìjọba dé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n ń ṣe pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún “gbogbo àwọn tó wà ní ipò gíga,” ní pàtàkì táwọn ìjọba bá fẹ́ pinnu bóyá kí wọ́n fún wa lómìnira láti jọ́sìn.—1 Tím. 2:1, 2.
ṢÉ ỌBA ÀRÍWÁ MÁA ṢẸ́GUN ỌBA GÚÚSÙ?
10. Ṣé ọba àríwá máa ṣẹ́gun ọba gúúsù? Ṣàlàyé.
10 Ohun tí ọba àríwá máa ṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:40-45 dìídì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ọba àríwá máa borí ọba gúúsù ni? Rárá o. Ọba gúúsù ṣì máa wà “láàyè” nígbà tí Jèhófà àti Jésù máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 19:20) Kí ló mú kíyẹn dá wa lójú? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti Ìfihàn sọ.
11. Kí lohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:43-45 jẹ́ ká mọ̀? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
11 Ka Dáníẹ́lì 2:43-45. Wòlíì Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ìjọba tó mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó fi ère gìrìwò kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ṣàpèjúwe àwọn ìjọba náà. Ó fi èyí tó gbẹ̀yìn nínú àwọn ìjọba náà wé àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà, èyí tó jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà á ṣì máa ṣàkóso nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa kọ lu gbogbo ìjọba ayé yìí tó sì máa pa wọ́n run.
12. Kí ni ìkeje lára orí ẹranko náà ṣàpẹẹrẹ, kí sì nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu?
12 Àpọ́sítélì Jòhánù náà sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ìjọba tó mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Jòhánù fi àwọn ìjọba yìí wé ẹranko kan tó ní orí méje. Ìkeje lára orí ẹranko náà ṣàpẹẹrẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Èyí bọ́gbọ́n mu torí pé ẹranko náà kò ní ju orí méje lọ. Torí náà, ìkeje lára orí ẹranko náà á ṣì máa ṣàkóso nígbà tí Kristi àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa pa ẹranko náà run ráúráú.b—Ìfi. 13:1, 2; 17:13, 14.
KÍ NI ỌBA ÀRÍWÁ MÁA ṢE LÁÌPẸ́?
13-14. Ta ni “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,” kí ló sì máa mú kó gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run?
13 Wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá kù díẹ̀ kí ọba àríwá àti ọba gúúsù pa run. Ó jọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà ni Ìsíkíẹ́lì 38:10-23; Dáníẹ́lì 2:43-45; 11:44–12:1 àti Ìfihàn 16:13-16, 21 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tá a máa jíròrò tẹ̀ lé e yìí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀.
14 Lásìkò díẹ̀ lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” máa kóra jọ, wọ́n á sì fìmọ̀ ṣọ̀kan láti ṣe ohun kan. (Ìfi. 16:13, 14; 19:19) Ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ni Bíbélì pè ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” (Ìsík. 38:2) Wọ́n máa fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run láti pa wá rẹ́ ráúráú. Kí ló máa mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Nígbà tí Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn, ó sọ pé àwọn òkúta yìnyín ńlá máa já bọ́ lu àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí òkúta yìnyín ìṣàpẹẹrẹ yìí dúró fún àwọn gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ táwa èèyàn Jèhófà máa kéde. Ìkéde yìí lè múnú bí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, kíyẹn sì mú kó gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run pẹ̀lú èrò àtipa wá run pátápátá.—Ìfi. 16:21.
15-16. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì 11:44, 45 máa tọ́ka sí? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ọba àríwá àti ìyókù Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù?
15 Ó jọ pé àwọn gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ táwa èèyàn Jèhófà máa kéde àti báwọn ọ̀tá ṣe máa gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:44, 45 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Kà á.) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Dáníẹ́lì sọ pé “ìròyìn láti ìlà oòrùn àti àríwá” máa yọ ọba àríwá lẹ́nu, ìyẹn sì máa mú kó lọ pẹ̀lú “ìbínú tó le gan-an.” Ohun tó wà lọ́kàn ọba àríwá ni bó ṣe máa “pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run.” Ó ṣeé ṣe kí “ọ̀pọ̀lọpọ̀” yìí tọ́ka sí àwa èèyàn Jèhófà.c Torí náà, ó jọ pé ohun tí Dáníẹ́lì ń sọ ni bí àwọn ọ̀tá ṣe máa fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run láti pa wá rẹ́ ráúráú.
16 Nígbà tí ọba àríwá àtàwọn ìjọba ayé yòókù bá gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, inú máa bí Ọlọ́run Olódùmarè, ìyẹn ló sì máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:14, 16) Lásìkò yẹn, Jèhófà máa pa ọba àríwá run, kò sì “sẹ́ni tó máa ràn án lọ́wọ́.” Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìjọba tó para pọ̀ jẹ́ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.—Dán. 11:45.
17. Ta ni Máíkẹ́lì “ọmọ aládé ńlá” tí Dáníẹ́lì 12:1 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kí sì lohun tó ṣe?
17 Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ọba àríwá àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ṣe máa pa run àti bí Jèhófà ṣe máa dá àwa èèyàn rẹ̀ nídè. (Ka Dáníẹ́lì 12:1.) Kí ni ẹsẹ yìí túmọ̀ sí? Máíkẹ́lì ni orúkọ míì tí Jésù Kristi Ọba wa ń jẹ́. Àtọdún 1914 tí Ọlọ́run ti fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lọ́run ni Máíkẹ́lì ti ń “dúró nítorí” àwa èèyàn Jèhófà. Láìpẹ́, ó “máa dìde” tàbí lédè míì á gbèjà àwa èèyàn Jèhófà, á sì pa àwọn ọ̀tá run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Ogun yẹn ló máa kẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Dáníẹ́lì sọ pé ó máa wáyé ní “àkókò wàhálà” tó burú jù nínú ìtàn ẹ̀dá. Bákan náà, àsọtẹ́lẹ̀ Jòhánù tó wà nínú ìwé Ìfihàn pe àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ogun Amágẹ́dọ́nì ní “ìpọ́njú ńlá.”—Ìfi. 6:2; 7:14.
ṢÉ O MÁA WÀ LÁRA ÀWỌN “TÍ ORÚKỌ WỌN WÀ NÍNÚ ÌWÉ”?
18. Kí nìdí tá ò fi bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
18 Ọkàn wa balẹ̀, a ò sì bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú torí pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti ti Jòhánù jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn tó bá sin Jèhófà àti Jésù máa là á já nígbà ìpọ́njú ńlá. Dáníẹ́lì sọ pé orúkọ àwọn tó máa là á já máa “wà nínú ìwé.” (Dán. 12:1) Kí la lè ṣe kí orúkọ wa lè wà nínú ìwé náà? A gbọ́dọ̀ fi hàn láìsí tàbí ṣùgbọ́n pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù tó jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run. (Jòh. 1:29) A gbọ́dọ̀ ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ká sì ṣèrìbọmi. (1 Pét. 3:21) Bákan náà, ó ṣe pàtàkì ká máa kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà ká lè fi hàn pé à ń ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn.
19. Kí ló yẹ ká ṣe nísinsìnyí, kí sì nìdí?
19 Ìsinsìnyí ló yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì fọkàn tán ètò rẹ̀ pátápátá. Ìsinsìnyí ló yẹ ká ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá là á já nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá pa ọba àríwá àti ọba gúúsù run.
ORIN 149 Orin Ìṣẹ́gun
a Ta ni “ọba àríwá” lónìí, báwo ló sì ṣe máa pa run? Tá a bá mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára, èyí á sì jẹ́ ká múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tá a máa tó kojú.
b Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i lórí Dáníẹ́lì 2:36-45 àti Ìfihàn 13:1, 2, wo Ilé Ìṣọ́ June 15, 2012, ojú ìwé 7 sí 19.
c Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo Ilé Ìṣọ́ May 15, 2015, ojú ìwé 29 sí 30.