Ọpọ Yanturu Iwarere Iṣeun Jehofa
“Bawo ni iwarere iṣeun rẹ ti pọ yanturu tó, eyi ti o ti fipamọ bi iṣura fun awọn wọnni ti wọn nbẹru rẹ!”—SAAMU 31:19, NW.
1, 2. (a) Ki ni iṣẹ gigadabu ti Jehofa dawọle nigba kan ni akoko pipẹ sẹhin? (b) Bawo ni Jehofa ṣe ṣapejuwe iyọrisi awọn igbokegbodo iṣẹda rẹ̀?
AKOKO kan wà ti Ọlọrun bẹrẹ sí dá ‘awọn ọrun gẹgẹ bi itẹ rẹ ati ilẹ-aye gẹgẹ bi apoti itisẹ rẹ.’ (Aisaya 66:1) Akọsilẹ atọrunwa ko ṣipaya igba ti eyi ṣẹlẹ. O wulẹ sọ ni ṣoki pe: “Ni atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun oun aye.” (Jẹnẹsisi 1:1) Laaarin saa akoko iṣẹda, aimọye araadọta ọkẹ awọn iṣupọ irawọ ni a ṣe, ọpọlọpọ ńní ẹgbẹẹgbẹrun lọna araadọta ọkẹ irawọ ninu. Si iha ode ọkan lara iru iṣupọ irawọ bẹẹ ni irawọ mimọlẹ yòò kan ti iye awọn planẹti dudu, ti wọn kere ni ifiwera sii wà. Ọkan ninu wọn ni a wá npe ni ilẹ-aye. Ni fifiwe awọn irawọ titan yanranyanran, titobi nla, ilẹ-aye kò tó nǹkan. Sibẹ, eyi ni Jehofa pete lati jẹ apoti itisẹ rẹ̀.
2 Jehofa tipa bayii yiju agbara iṣẹda rẹ sí planẹti Ilẹ-aye. “Akọbi gbogbo ẹda” wà ni ẹba ọdọ rẹ gẹgẹ bi Ọga Oniṣẹ kan nigba ti a yi ilẹ dudu kekere yii pada, laaarin akoko “awọn ọjọ” iṣẹda gigun mẹfa. O di, lọna iṣapẹẹrẹ, ibi isinmi yiyẹ fun ẹsẹ Ọlọrun. (Kolose 1:15; Ẹkisodu 20:11; Owe 8:30) Nihin in ni ibi ti Ọlọrun pete lati fi iwalaaye ọlọgbọnloye ti a ṣẹṣẹ dá ni titun sí: araye. Eniyan meji akọkọ, ti a dá lati inu awọn eroja ti a rí lati inu ilẹ, ni a fi sinu awọn ayika ẹlẹwa, ti paradise. (Jẹnẹsisi 1:26, 27; 2:7, 8) Iyọrisi ikẹhin iṣẹ iṣẹda titayọ yii jẹ pipe gan an, ẹlẹwa gan an, debi pe Bibeli ṣipaya awọn imọlara Ọlọrun ni owurọ—apa ti o kẹhin—ọjọ iṣẹda kẹfa naa: “Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti ó dá, sì kiyesi i, daradara ni.”—Jẹnẹsisi 1:31.
Iwarere Iṣeun Ọlọrun
3. Animọ titayọ ti Ọlọrun wo ni a ṣipaya ninu iṣẹda?
3 Ẹgbẹẹgbẹrun ọdun lẹhin naa, ọmọ iran ẹni meji akọkọ yẹn wo ẹhin pada sí akoko iṣẹda o si kọwe pe: “Ohun [Ọlọrun] ti ó farasin lati igba dídá aye a rí wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a dá mọ ọn, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ ayeraye.” (Roomu 1:20) Bẹẹni, itayọ gigalọla ilẹ-aye ati awọn ẹda ti wọn wà ninu rẹ nitootọ jẹ́ ifarahan awọn animọ aiṣeefojuri ti Ọlọrun—eyi ti ko kere ju ninu wọn ni ọpọ yanturu iwarere iṣeun Ọlọrun. Bawo ni o ti ṣe rẹ́gí tó, nigba naa, pe Ọlọrun polongo pe ohun gbogbo ti oun ti dá jẹ daradara!—Saamu 31:19.
4, 5. Ki ni iwarere iṣeun?
4 Iwarere iṣeun ni ìhà kẹfa ti awọn eso ẹmi Ọlọrun ti apọsiteli Pọọlu ṣapejuwe ni Galatia 5:22. Awọn ikẹkọọ iṣaaju ninu iwe irohin Ilé-ìṣọ́nà ti jiroro awọn eso ẹmi marun un akọkọ, ni fifi ijẹpataki iwọnyi han ninu mimu animọ iwa Kristẹni ogboṣaṣa kan dagba.a Bi o ti wu ki o ri, bawo ni o ti ṣekoko tó, pe ki a ma gbagbe iwarere iṣeun! Lọna ti o ba a mu gẹ́ẹ́, a o yi afiyesi wa si animọ yii nisinsinyi.
5 Ki ni iwarere iṣeun? Ó jẹ́ animọ tabi ipo jijẹ ẹni rere. Ó jẹ́ itayọlọla iwarere, iwa mimọ. Fun idi yii, ó jẹ́ animọ amuni sunwọn sii ti ó maa nfi araarẹ han ninu ṣiṣe rere ati awọn ohun ti o ṣanfaani fun awọn ẹlomiran. Bawo ni a ṣe le fi animọ ti nfa ifẹ awọn ẹlomiran mọra han sode? Ni ipilẹ, nipa ṣiṣafarawe Jehofa. Fun idi yii, ṣaaju ki a tó jiroro siwaju sii ọna ti awa gẹgẹ bi Kristẹni kọọkan le gba fi iwarere iṣeun han, ẹ jẹ ki a ṣayẹwo iwarere iṣeun ti Ọlọrun wa onifẹẹ, Jehofa, ti fihan ninu pipese fun, ati biba idile eniyan lò.
Iwarere Iṣeun Ni A Fihan Kedere Ninu Iṣẹda
6. Ki ni o sun Jehofa lati da oniruuru awọn alaaye ọlọgbọnloye miiran?
6 Ki ni o sún Baba wa ọrun lakọọkọ lati ṣajọpin igbadun iwalaaye rẹ pẹlu awọn ẹda ọlọgbọnloye? Apọsiteli Johanu dahun ibeere yẹn nigba ti o wipe: “Ọlọrun jẹ ifẹ.” (1 Johanu 4:8, NW) Bẹẹni, ifẹ alainimọtara ẹni nikan sún Orisun iwalaaye titobi nla naa lati ṣeda iru awọn ẹda alaaye miiran, ni pipese ibugbe ti ọrun fun awọn kan ati ibugbe ori ilẹ-aye fun awọn miiran. Dajudaju, diẹ ni a mọ nipa bi ọrun tabi awọn ẹda ọrun ti rí. Wọn jẹ ẹmi—ti oju eniyan ko le rí—ibugbe wọn sì wa ni ilẹ-akoso ẹmi. Ṣugbọn wo ibugbe ilẹ-aye ti o yi ọ ka ti Jehofa pese fun awọn ọmọ rẹ ti wọn jẹ eniyan. Ki o si gbe araye funraarẹ yẹwo. Lẹhin naa iwọ yoo bẹrẹ sii ri ẹri alagbara iwarere iṣeun Ọlọrun funraarẹ.
7-9. Bawo ni a ṣe ri iwarere iṣeun Ọlọrun ninu ọna ti o gba dá ilẹ-aye ati eniyan sori rẹ̀?
7 Jehofa fun awọn obi wa akọkọ ni iwalaaye. Ju iyẹn lọ, o mu ki ó ṣeeṣe fun iwalaaye lati ladun, ki o gbadunmọni gan an. Lati bẹrẹ, o dá ibugbe wọn, ilẹ-aye, ti nlọyipo, pẹlu iwọn igbona ati itutu, ati oju ọjọ ti o yẹ gan an. Ó gbe awọn iyipo omi, afẹfẹ nitrogen, ati oxygen kalẹ ti wọn nṣiṣẹ lọna pipe fun anfaani ati itura eniyan. O fi ẹgbẹẹgbẹrun oniruuru awọn eweko tẹ oju ilẹ-aye, awọn kan fun eniyan gẹgẹ bi ounjẹ ati awọn kan ti o gbadun lati fojuri. O fi awọn ẹyẹ ti nfunni ni itẹlọrun pupọ pẹlu awọ wọn ati orin wọn kun oju ọrun. Ó fi ọpọlọpọ ẹja kun inu okun ati ilẹ pẹlu ọpọlọpọ oniruuru ẹranko, awọn kan yẹhànnà awọn kan sì ṣee tọ́. Iru iwa ọlawọ jaburata wo ni eyi! Ẹri ìjọ́lọ́kàn rere Ọlọrun wo sì niyii!—Saamu 104:24.
8 Nisinsinyi, wo ọna ti Ọlọrun gba dá eniyan. Awọn apa, ati ẹsẹ, jẹ ohun ti ó nilo gan an lati fun un lagbara lati duro laiṣubu ki o sì maa rin kiri pẹlu irọrun. Nipa bayii, lati inu awọn eroja ti a rí ni ọpọ yanturu lori ilẹ-aye ti o yi i ká, oun le rí ounjẹ ati awọn ohun koṣeemani miiran fun araarẹ. Ó pese sẹẹli itọwo lori ahọn ki jijẹ ati mimu ba maa jẹ awọn iṣe alafaraṣe mafọkanṣe lasan ti a nṣe lati ri okun gba—bii kiki okùn ohun eelo ile kan bọ oju ina manamana lonii. Bẹẹkọ, jijẹ ati mimu ni a pete lati fun wa ni igbadun, gẹgẹ bi wọn ko ti kun ikun wa nikan ṣugbọn ti wọn tun nru agbara itọwo wa soke. Jehofa fun eniyan ni eti bakan naa o sì mu ọpọlọpọ ìró ti o gbadun mọ eti wọnni yí i ká pẹlu. Bawo ni o ti gbadunmọni tó lati fetisilẹ sí ìṣàn térétéré atunilara ti odo kekere ti nṣan, didun ẹyẹle, tabi ẹrin púkẹ́púkẹ́ ọmọ ọwọ kan! Bẹẹni, ọpẹ ni fun iwarere iṣeun Ọlọrun, laika gbogbo ohun buburu ti o ti ṣẹlẹ lati igba iṣẹda sí, o ṣì jẹ ayọ lati walaaye.
9 Tun wo awọn agbara imọlara wa miiran. Iye oniruuru awọn àwọ̀ gbigbadunmọni wo ni wọn wa lati tẹ́ oju lọrun! Bawo ni o si ti tẹnilọrun tó lati gbóòórùn itasansan fẹẹrẹfẹ ti ododo kan! Abajọ ti onisaamu naa fi gbohun soke si Jehofa pe: “Emi yoo yìn ọ́; nitori tẹrutẹru ati tiyanutiyanu ni a dá mi: Iyanu ni iṣẹ rẹ”!—Saamu 139:14.
Iṣubu ati Igbasilẹ Araye
10. Bawo ni ọpọ julọ awọn eniyan ṣe dahunpada si iwarere iṣeun Ọlọrun, sibẹ bawo ni wọn ṣe nbaa lọ lati janfaani lati inu rẹ?
10 Lọna ti ó bani ninu jẹ́, bi akoko ti nlọ awọn obi wa akọkọ fi aini imọriri han fun gbogbo iwarere iṣeun Ọlọrun si wọn. Wọn fi eyi han nigba ti wọn ṣaigbọran si awọn aṣẹ Jehofa ti wọn si ré ìkálọ́wọ́kò kanṣoṣo ti o ti gbekari kọja. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ, awọn ati awọn ọmọ wọn wá mọ ibanujẹ, ijiya, ati iku. (Jẹnẹsisi 2:16, 17; 3:16-19; Roomu 5:12) Jakejado ọpọ ẹgbẹrun ọdun ti o ti kọja lati igba igbesẹ aigbọran yẹn, ọpọjulọ araye ti fi idagunla tabi aini imọriri han sí iwarere iṣeun Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, laika eyi si, awọn eniyan alailọpẹ ati alaini imọriri njanfaani lati inu iwarere iṣeun Ọlọrun sibẹ. Ni ọna wo? Apọsiteli Pọọlu ṣalaye fun awọn olugbe Lisira ni Aarin Ila-oorun aye: “[Ọlọrun] ko fi araarẹ silẹ ni ailẹrii, niti o nṣe rere, o nfun yin ni ojo lati ọrun wa, ati akoko eso, o nfi ounjẹ ati ayọ̀ kún ọkan yin.”—Iṣe 14:17.
11. Ni ọna wo ni iwarere iṣeun Ọlọrun gba nasẹ siwaju ju pipese ibugbe gbigbadunmọni kan fun araye?
11 Ṣugbọn iwarere iṣeun Ọlọrun ni a ko ti fimọ sí bibaa lọ lati pese awọn ipese gbigbadunmọni, ti ngbe iwalaaye ró eyi ti ilẹ-aye kún fun. Bẹẹkọ, oun lọ jinna sii. Jehofa fi araarẹ han ni ẹni ti o muratan lati dari ẹṣẹ awọn ọmọ Adamu ji wọn ati lati maa baa lọ lati mu ibatan dagba pẹlu awọn oluṣotitọ laaarin araye. Iha iwarere iṣeun Ọlọrun yii ni a mu wa si afiyesi Mose nigba ti Jehofa ṣeleri lati mu ki ‘gbogbo iwarere iṣeun rẹ kọja ni oju [Mose].’ Lẹhin naa Mose gbọ ipolongo naa pe: “Jehofa, Jehofa, Ọlọrun alaanu ati oloore ọfẹ, ti ó lọra lati binu ti o sì pọ ni iṣeun-ifẹ ati otitọ, ti npa iṣeun-ifẹ mọ́ fun ẹgbẹẹgbẹrun, ti ndari aṣiṣe ati aiṣedeedee ati ẹṣẹ jì.”—Ẹkisodu 33:19; 34:6, 7, NW.
12. Awọn ipese wo labẹ Ofin Mose ni wọn fi iwarere iṣeun Jehofa han?
12 Ni ọjọ Mose, Jehofa fidii eto-igbekalẹ olofin kan mulẹ fun orilẹ-ede titun ti Isirẹli ninu eyi ti awọn alaimọọmọ dẹṣẹ ti le ri idariji ẹṣẹ iṣapẹẹrẹ, tabi onigba diẹ gba. Nipasẹ Majẹmu Ofin ti Mose ṣe alarina rẹ, awọn ọmọ Isirẹli di orilẹ-ede akanṣe ti Ọlọrun a sì kọ́ wọn lati ṣe awọn irubọ ẹran oniruuru si Jehofa ti yoo bo awọn ẹṣẹ ati iṣe aimọ wọn. Nipa bayii, laika awọn ipo ẹda alaipe wọn sí, awọn ọmọ Isirẹli onironupiwada le maa baa lọ lati tọ Jehofa lọ lọna itẹwọgba ki wọn si mọ pe ijọsin wọn ńtẹ́ ẹ lọrun. Ọba Dafidi, mẹmba orilẹ-ede yẹn kan labẹ Ofin, sọ mímọ iwarere iṣeun Ọlọrun rẹ jade ni ọna yii: “Awọn ẹṣẹ igba ewe mi ati awọn iṣọtẹ mi ni ki iwọ jọwọ maṣe ranti. Gẹgẹ bi iṣeun-ifẹ rẹ ni ki iwọ funraarẹ ranti mi, nititori iwarere iṣeun rẹ, óò Jehofa.”—Saamu 25:7, NW.
13. Bawo ni Jehofa ṣe pese ọna kan ti o tubọ gbeṣẹ sii ju awọn ẹbọ ẹran lọ fun idariji awọn ẹṣẹ?
13 Laipẹ iwarere iṣeun Jehofa sún un lati pese ọna idariji ẹṣẹ ti o gbeṣẹ ju ti o si wà titilọ. Eyi jẹ́ nipasẹ ẹbọ Jesu, ẹni ti o jẹ́ atirandiran atẹle Ọba Dafidi. (Matiu 1:6-16; Luuku 3:23-31) Jesu ko dẹṣẹ. Fun idi yii, nigba ti o kú, iwalaaye rẹ ti o fifunni ninu irubọ ní itoye pupọ, Ọlọrun sì tẹwọgba a gẹgẹ bi irapada ti ó le ṣee lo fun gbogbo awọn ọmọ Adamu ẹlẹṣẹ. Apọsiteli Pọọlu kọwe pe: “Gbogbo eniyan ni o ṣa ti ṣẹ̀, ti wọn sì kuna ogo Ọlọrun; awọn ẹni ti a ndalare lọfẹẹ nipa ore-ọfẹ rẹ, nipa idande ti ó wa ninu Kristi Jesu: ẹni ti Ọlọrun ti gbekalẹ lati jẹ́ etutu nipa igbagbọ ninu ẹjẹ rẹ̀.”—Roomu 3:23-26.
14. Awọn ireti agbayanu wo ni a mu ki o ṣeeṣe fun eniyan nipasẹ ẹbọ irapada naa?
14 Igbagbọ ninu ẹbọ irapada Jesu ṣaṣepari ohun ti ó pọ fun awọn Kristẹni, ti ó pọ ju ohun ti awọn ẹbọ ẹran wọnni ṣe fun awọn ọmọ Isirẹli labẹ majẹmu Ofin. O ṣamọna sí pipolongo iye awọn Kristẹni ti ó ni ààlà gẹgẹ bi olododo ti ẹmi Ọlọrun si gbà wọn ṣọmọ lati di awọn ọmọkunrin rẹ̀. Wọn tipa bayii di arakunrin Jesu wọn si jere ireti didi awọn ti a jíǹde gẹgẹ bi ẹda ẹmi lati ṣajọpin pẹlu rẹ ninu Ijọba rẹ ọrun. (Luuku 22:29, 30; Roomu 8:14-17) Rò ó wò ná pe Ọlọrun yoo ṣí iru awọn ireti ti ọrun bẹẹ silẹ fun awọn ẹda ti ngbe lori planẹti kekere yii, ilẹ-aye! Awujọ kekere kan ti wọn nṣikẹ ireti yii ṣì wà. Ṣugbọn fun araadọta ọkẹ awọn Kristẹni miiran, mimu igbagbọ lo ninu irapada naa ṣí ọna silẹ lati gbadun ohun ti Adamu ati Efa sọnu—iye ayeraye lori paradise, ilẹ-aye ti o dabii ọgba kan. Majẹmu Ofin naa nikan ko pese yala ireti ọjọ iwaju ti ọrun tabi ti ilẹ-aye fun awọn ti wọn rọ̀ mọ ọn.
15. Ki ni ihinrere ní ninu?
15 Bawo ni o ti ba a mu tó pe ihin-iṣẹ nipa awọn iṣeto titun naa tí Ọlọrun ti gbekalẹ nipasẹ Jesu Kristi ni a pe ni “ihinrere,” nitori ti o gbe iwarere iṣeun Ọlọrun yọ. (2 Timoti 1:9, 10) Ninu Bibeli, ihinrere naa ni a maa npe ni “ihinrere ijọba naa” nigba miiran. Lonii o papọ sori otitọ naa pe Ijọba naa ni a ti fidii rẹ mulẹ labẹ iṣakoso Jesu ti a ti jí dide. (Matiu 24:14; Iṣipaya 11:15; 14:6, 7) Laika eyiini sí, ihinrere naa wémọ́ ohun ti ó ju bẹẹ lọ. Gẹgẹ bi a ti fihan ninu awọn ọrọ Pọọlu sí Timoti ti a ṣẹṣẹ ṣayọlo tan, ó papọ pẹlu imọ naa pe Jesu pese ẹbọ irapada kan nitori tiwa. Laisi ẹbọ yẹn, ipo ibatan wa pẹlu Ọlọrun, igbala wa gan an—ki a ma tilẹ sọ ti Ijọba Jesu ati 144,000 awọn alufaa ati ọba ti a mú lati inu aye—ni ko ni ṣeeṣe. Iru agbayanu ifihan ti iwarere iṣeun Ọlọrun wo ni irapada jẹ́!
Iwarere Iṣeun Ọlọrun Lonii
16, 17. Bawo ni Hosea 3:5 ṣe ni imuṣẹ (a) ni 537 B.C.E.? (b) ni 1919 C.E.?
16 Wiwo iwaju sí “awọn ọjọ ikẹhin,” apọsiteli Pọọlu kilọ pe: ‘Awọn eniyan yoo di . . . alainifẹẹ iwarere iṣeun.’ (2 Timoti 3:1-3, NW) Ani ifihan iwarere iṣeun ti ó yẹ paapaa, iru bi iwa ọlawọ ati ifẹ aladuugbo, ni a ki yoo mọriri. Bawo ni asọtẹlẹ amunilọkanyọ ti Hosea 3:5 ti funni niṣiiri tó, nigba naa pe: “Awọn ọmọ Isirẹli yoo pada, wọn o si wá Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; wọn o sì bẹru Oluwa [“Jehofa,” NW], ati ore [“iwarere iṣeun,” NW] rẹ̀ ni ọjọ ikẹhin.”
17 Asọtẹlẹ yii ni a muṣẹ ni 537 B.C.E. nigba ti awọn Juu pada si Ilẹ Ileri lati igbekun ni Babiloni. Ni awọn akoko ode oni, o bẹrẹ imuṣẹ rẹ ni ọdun 1919 nigba ti aṣẹku Isirẹli tẹmi jade lati inu eto-ajọ Satani ti ó sì bẹrẹ si wá Jehofa ati iwarere iṣeun rẹ tọkantọkan. Wọn rii pe “Dafidi ọba wọn” ẹni tii ṣe Jesu Kristi tí nbẹ ninu agbara Ijọba ti ọrun ti njọba lati 1914. Labẹ iṣabojuto rẹ lati ọrun, wọn fi titaratitara tẹwọgba ṣiṣefilọ ihinrere ijọba yii fun awọn orilẹ-ede. Nipa bayii wọn bẹrẹ sii mu iṣẹ ti a kọsilẹ ni Matiu 24:14 ṣẹ pe: “A o sì waasu ihinrere ijọba [ti a ti fidii rẹ̀ mulẹ] yii ni gbogbo aye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì dé.”
18. Awọn wo ni wọn ti darapọ mọ awọn aṣẹku Isirẹli tẹmi ninu pipolongo ihinrere naa?
18 Lonii, aṣẹku awọn ẹni ami ororo naa ni “ogunlọgọ nla” ti darapọ mọ, awọn ti wọn nkokiki iwarere iṣeun Jehofa bakan naa. (Iṣipaya 7:9, NW) Nisinsinyi, iye ti o ju aadọta ọkẹ mẹrin lọ nsọ asọtunsọ awọn ọrọ angẹli naa ti apọsiteli Johanu rí ninu iran gẹgẹ bi wọn ti nṣefilọ fun gbogbo awọn orilẹ-ede naa pe: “Ẹ bẹru Ọlọrun, ki ẹ sì fi ogo fun un; nitori ti wakati idajọ rẹ de: ẹ si foribalẹ fun ẹni ti o dá ọrun, oun aye, ati okun, ati awọn orisun omi.”—Iṣipaya 14:7.
19. Darukọ ọkan lara awọn ẹri titobi julọ ti iwarere iṣeun Ọlọrun.
19 Ọkan lara awọn ẹri titobi julọ ti iwarere iṣeun Ọlọrun ni pe ó yọnda fun wa lati jẹ alajumọ ṣiṣẹpọ pẹlu rẹ ninu iṣẹ aṣepari yii. Ẹ wo iru anfaani ti o ti jẹ pe a ti fi “ihinrere ologo ti Ọlọrun alayọ” lé wa lọwọ! (1 Timoti 1:11, NW) Nipa wiwaasu wa ati kikọ awọn ẹlomiran ni eyi, awa nfi iwarere iṣeun han, eso pataki ti ẹmi Ọlọrun yẹn, dé iwọn giga. Nipa bayii, a ni ẹmi-ironu ti Dafidi iranṣẹ Ọlọrun igbaani, ẹni ti o wipe: “Pẹlu mimẹnukan ọpọ yanturu iwarere iṣeun rẹ wọn yoo ma yọ̀ ṣinkin, ati nitori ododo rẹ wọn yoo kigbe jade pẹlu ayọ.”—Saamu 145:7, NW.
20. Isọfunni siwaju sii wo nipa iwarere iṣeun ni a o jiroro ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e?
20 Bi o ti wu ki o ri, njẹ ṣiṣajọpin ninu wiwaasu ihinrere naa ha ni ọna kanṣoṣo ti a le gbà fi iwarere iṣeun Ọlọrun han ninu igbesi-aye wa bi? Bẹẹkọ rara! A fun wa niṣiiri lati ṣe “afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n.” (Efesu 5:1) Iwarere iṣeun Ọlọrun ni a fihan ni oniruuru ọna. Fun idi yii, iwarere iṣeun wa pẹlu nilati nipa lori ọpọlọpọ awọn apa-iha igbesi-aye wa. Diẹ ninu iwọnyi ni a o gbé yẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọkọọkan awọn eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, inurere, iwarere iṣeun, igbagbọ, iwatutu, ati ikora-ẹni-nijaanu.
Iwọ Ha Le Dahun Bi?
◻ Ni ọna wo ni iṣẹda gba ṣagbeyọ iwarere iṣeun Ọlọrun?
◻ Awọn iṣeto wo ni Jehofa ṣe lati dárí ẹṣẹ awọn eniyan onironupiwada jì?
◻ Ni imuṣẹ Hosea 3:5, nigba wo ni awọn aṣẹku ẹni ami ororo wa sọdọ Jehofa ati iwarere iṣeun rẹ̀, ki ni eyi si ṣamọna sí?
◻ Ki ni ọkan lara awọn ẹri titobi julọ ti iwarere iṣeun Ọlọrun lonii?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Iṣẹda fi ẹri ọpọ yanturu iwarere iṣeun Ọlọrun funni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Yiyọnda ti a yọnda wa lati ṣajọpin ninu iṣẹ wiwaasu jẹ́ ẹri titayọ kan ti iwarere iṣeun Ọlọrun