Orí Kẹtàlá
“Ẹ Pòkìkí Èyí Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè”
1. Kí nìdí tá a fi lè fi ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì rẹ̀ wé ìbúramúramù kìnnìún?
ǸJẸ́ o ti gbọ́ ìbúramúramù kìnnìún rí? Wọ́n sọ pé igbe rẹ̀ máa ń rinlẹ̀ ju ariwo ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń fọ́ òkúta tàbí tí wọ́n fi ń fọ́ kọnkéré lọ. Tó o bá gbọ́ igbe kìnnìún nítòsí ilé rẹ láàjìn òru, kí ni wàá ṣe? Ó dájú pé ojú ẹsẹ̀ ni wàá ṣe ohun tó yẹ. Ámósì, ọ̀kan lára àwọn wòlíì méjìlá tá à ń gbé ọ̀rọ̀ wọn yẹ̀ wò, lo àfiwé kan bí èyí, ó ní: “Kìnnìún kan wà tí ó ti ké ramúramù! Ta ni kì yóò fòyà? Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kì yóò sọ tẹ́lẹ̀?” (Ámósì 3:3-8) Tó o bá gbọ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ o ò ní ṣe bíi ti Ámósì? Ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
2. (a) Báwo lo ṣe lè fara wé Ámósì nínú bó ṣe ṣe iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́? (b) Kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò ní orí yìí?
2 Ó ṣeé ṣe kó o sọ pé, ‘Àmọ́ èmi kì í ṣe wòlíì!’ Ó lè ṣe ọ́ bíi pé o ò kúnjú òṣùwọ̀n nítorí pé o ò tíì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wàá fi lè jẹ́ wòlíì. Àmọ́ ṣé o rántí Ámósì? Nígbà tí Amasááyà tó jẹ́ àlùfáà lẹ́nu ìjọsìn ọmọ màlúù ko Ámósì lójú, Ámósì sọ pé: “Èmi kì í ṣe wòlíì tẹ́lẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì í ṣe ọmọ wòlíì; ṣùgbọ́n olùṣọ́ agbo ẹran ni mí àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè.” (Ámósì 7:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe inú ìdílé àwọn ọ̀tọ̀kùlú ló ti wá, ó múra tán láti ṣe iṣẹ́ wòlíì tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́. Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Jèhófà gbé iṣẹ́ kan lé ọ lọ́wọ́ tó fi àwọn nǹkan kan jọ tàwọn wòlíì méjìlá náà? Iṣẹ́ náà ni pé kó o kéde ìhìn Ọlọ́run tó wà fún àkókò tá a wà yìí, kó o kọ́ni, kó o sì sọni dọmọ ẹ̀yìn. Ojú wo lo fi ń wo iṣẹ́ bàǹtà-banta yẹn? Ìhìn wo lo ní láti polongo láàárín àwọn orílẹ̀-èdè? Báwo ló ṣe ń ṣe é kúnnákúnná tó? Kí ló máa pinnu bóyá o kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ náà? Jẹ́ ká wá ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí.
‘ẸGBỌRỌ AKỌ MÀLÙÚ ÈTÈ RẸ’
3. Báwo lo ṣe lè ṣe iṣẹ́ tó jọ tàwọn wòlíì tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé wọn?
3 Ǹjẹ́ òótọ́ lò ń ṣe iṣẹ́ kan tó jọ tàwọn wòlíì náà? O lè máà gbọ́ ìbúramúramù kìnnìún ní ti pé kí Jèhófà mí sí ọ ní tààràtà. Àmọ́, nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, o tí gbọ́ ìhìn kánjúkánjú nípa ọjọ́ Jèhófà tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe mẹ́nu kàn án ní Orí Kìíní ìwé yìí, ọ̀rọ̀ náà “wòlíì” ní ìtumọ̀ tó pọ̀ díẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè máà jẹ́ wòlíì lọ́nà tí Ámósì àtàwọn mìíràn láyé ọjọ́un gbà jẹ́ wòlíì, o lè sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Lọ́nà wo? O lè kéde àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, èyí tí ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà jẹ́ ara rẹ̀. Ìsinsìnyí gan-an ló sì yẹ kó o kéde rẹ̀.
4. Ọ̀nà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì 2:28-32 gbà ń nímùúṣẹ lónìí?
4 Gba ìhà mìíràn wo ọ̀rọ̀ yìí. Jèhófà Ọlọ́run sọ fún wòlíì Jóẹ́lì pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà yóò máa sọ tẹ́lẹ̀, ó ní: “Lẹ́yìn ìyẹn, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, èmi yóò tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ dájúdájú. Ní ti àwọn àgbà ọkùnrin yín, wọn yóò máa lá àlá. Ní ti àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín, wọn yóò máa rí ìran.” (Jóẹ́lì 2:28-32) Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ẹsẹ Bíbélì yìí ló ṣẹ nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn tí wọ́n pé jọ ní yàrá kan lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ní Jerúsálẹ́mù àti ìwàásù tí wọ́n ṣe “nípa àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” lẹ́yìn náà. (Ìṣe 1:12-14; 2:1-4, 11, 14-21) Wá gbé ìgbà tiwa yìí yẹ̀ wò. Àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ti ń ní ìmúṣẹ pípabanbarì láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún. Àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn, lọ́kùnrin lóbìnrin, lọ́mọdé lágbà, bẹ̀rẹ̀ sí í “sọ tẹ́lẹ̀,” ìyẹn ni pé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kéde “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run,” tó fi mọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ti fìdí múlẹ̀ ní ọ̀run báyìí.
5. (a) Àǹfààní ńlá wo ni gbogbo wa ní? (b) Kí ló túmọ̀ sí pé kó o fi “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè [rẹ]” rúbọ, kí sì nìdí tó fi jẹ́ àǹfààní ńlá?
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò fẹ̀mí yan àwọn tó para pọ̀ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó jẹ́ ara “àgùntàn mìíràn” láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, wọ́n ń sọ fáwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.” (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16; Sekaráyà 8:23) Yálà ìrètí rẹ jẹ́ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé, o láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti máa fi “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè [rẹ]” rúbọ. (Hóséà 14:2) Kí ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà yìí túmọ̀ sí? Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ C. F. Keil sọ pé: “Ọ̀dọ́ akọ màlúù . . . ni ẹran tó dára jù lọ láti fi rú ẹbọ ọpẹ́.” Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé, ó mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ Hóséà 14:2, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Bẹ́ẹ̀ ni, gbólóhùn náà, “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa” túmọ̀ sí ohun tó dáa jù lọ tá a lè fẹnu wa sọ, ìyẹn ọ̀rọ̀ tá à ń sọ láti fi yin Jèhófà.
6. Kí nìdí to fi yẹ ká ṣàyẹ̀wò bí ẹbọ ìyìn tá à ń rú ṣe dára sí?
6 Tó o bá ń gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, tó ò ń dáhùn ní ìpàdé ìjọ lọ́nà tó fi hàn pé o moore rẹ̀, tó o sì ń fi ìtara bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí, ẹbọ ìyìn lò ń rú sí Jèhófà yẹn. Àmọ́, kálukú wa lè bi ara rẹ̀ pé: ‘Nígbà tí mo bá ń ṣe àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn yìí, báwo ni ẹbọ ìyìn mi ṣe máa ń dára tó?’ Nítorí ohun tó o ti kẹ́kọ̀ọ́, ó dájú pé wàá ti fojú ẹ̀tẹ́ wo àwọn àlùfáà ìgbà ayé Míkà tó jẹ́ pé gbangba-gbàǹgbà ni wọ́n ń mú ẹran tó lábùkù lára wá sórí pẹpẹ Ọlọ́run. Ìgbà tí Jèhófà tipasẹ̀ Málákì tẹnu mọ́ ọn fún wọn pé ẹbọkẹ́bọ ni wọ́n ń rú ni wọ́n tó mọ̀ pé ẹbọ táwọn ń rú ò dáa, wọn ò tiẹ̀ rò ó rárá pé ńṣe làwọn ń tẹ́ńbẹ́lú tábìlì Jèhófà. (Málákì 1:8) Ó yẹ káwa náà yẹ ẹbọ ìyìn tá à ń rú wò láti mọ bó ṣe dára sí, ká rí i dájú pé ẹbọ tó dára jù lọ tí kò sì ní àbùkù kankan là ń rú.
ÌHÌN TÁ A NÍ LÁTI POLONGO
7. Èwo ló gba ìgboyà nínú apá méjì tí ìhìn tá à ń kéde pín sí?
7 Fífi “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa” rúbọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gba ìgboyà, nítorí pé apá méjì ni ìhìn tá à ń mú tọ àwọn èèyàn lọ pín sí, ó sì dájú pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀kan nínú apá méjì náà. Wòlíì Jóẹ́lì sọ fáwọn èèyàn Ọlọ́run pé: “Ẹ pòkìkí èyí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ‘Ẹ sọ ogun di mímọ́! Ẹ ru àwọn ọkùnrin alágbára dìde! Ẹ jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ tòsí! Ẹ jẹ́ kí wọ́n gòkè wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun!’” (Jóẹ́lì 3:9) Ìkéde yìí kan àkókò tá a wà yìí o. Ẹ ò rí i pé ìpèníjà ńláǹlà lèyí jẹ́ fáwọn orílẹ̀-èdè! Ó jẹ́ ìkéde ogun òdodo tí Ọlọ́run yóò bá àwọn tó ń ṣàyàgbàǹgbà sí i jà. Nígbà tí Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, kí wọ́n sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn,’ ńṣe ló sọ fáwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá pé kí wọ́n ‘fi àwọn abẹ ohun ìtúlẹ̀ wọn rọ idà, kí wọ́n sì fi àwọn ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn wọn rọ aṣóró.’ (Míkà 4:3; Jóẹ́lì 3:10) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọ̀tá Ọlọ́run gbọ́dọ̀ múra láti pàdé Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run lójú ogun. Dájúdájú, ìkéde yìí ò lè bá àwọn tó kórìíra rẹ̀ lára mu.
8. Kí nìdí tí Míkà fi fi “àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù” wé kìnnìún?
8 Nínú iṣẹ́ tí wòlíì Míkà jẹ́, ó fi àwọn tó fi ‘ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wọn’ rúbọ wé kìnnìún. Ó kọ̀wé pé: “Nínú àwọn orílẹ̀-èdè . . . àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù yóò sì dà bí kìnnìún láàárín àwọn ẹranko igbó, bí ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ láàárín agbo àgùntàn, èyí tí, nígbà tí ó bá kọjá lọ ní ti tòótọ́, yóò tẹ̀ mọ́lẹ̀, yóò sì fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ dájúdájú; kò sì sí olùdáǹdè.” (Míkà 5:8) Kí nìdí tó fi lo àpèjúwe yìí? Ìdí ni pé ní ọjọ́ wa lónìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run tí àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ń mú ipò iwájú láàárín wọn, gbọ́dọ̀ ní ìgboyà bíi kìnnìún bí wọ́n ṣe ń jíṣẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.a
9. (a) Ìgbà wo ni wàá ní láti ní ìgboyà bíi kìnnìún? (b) Báwo lo ṣe lè ní ìgboyà táwọn èèyàn bá ta kò ọ́ tàbí tí wọ́n dágunlá?
9 Ǹjẹ́ o ní ìgboyà bíi kìnnìún bó o ṣe ń kéde apá tó jẹ́ ìkìlọ̀ nínú ìhìn tá à ń polongo? Kì í ṣe ìgbà tó o bá dúró níwájú àwọn aláṣẹ nìkan lo máa nílò ìgboyà yìí o, àmọ́ o tún máa nílò rẹ̀ nígbà tó o bá ń bá àwọn ojúgbà rẹ sọ̀rọ̀ níléèwé tàbí níbi iṣẹ́, tàbí nígbà tó o bá ń bá àwọn ìbátan rẹ tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀. (Míkà 7:5-7; Mátíù 10:17-21) Báwo lo ṣe lè ní ìgboyà táwọn èèyàn bá ta kò ọ́ tàbí tí wọ́n dágunlá? Gbọ́ bí Míkà ṣe sọ ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún un láti ṣe iṣẹ́ bàǹtà-banta tí Ọlọ́run fi rán an pé kó kìlọ̀ nípa ìparun Samáríà àti Jerúsálẹ́mù. Ó ní: “Èmi alára . . . ti kún fún agbára, nípa ẹ̀mí Jèhófà, àti ti ìdájọ́ òdodo àti agbára ńlá, kí n bàa lè sọ ìdìtẹ̀ Jékọ́bù fún un, kí n sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fún un.” (Míkà 1:1, 6; 3:8) Ìwọ náà lè “kún fún agbára” nítorí pé Ọlọ́run lè fún ìwọ náà ní ìwọ̀n tó pọ̀ lára ẹ̀mí rẹ̀ tí ń fúnni lágbára. (Sekaráyà 4:6) Tó o bá ń gbára lé Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti máa kéde ọ̀rọ̀ tó lè mú etí hó yee.—2 Àwọn Ọba 21:10-15.
10. Báwo la ṣe lè fara wé Sefanáyà bá a ṣe ń polongo “ọjọ́ Jèhófà”?
10 O ní láti ní ìgboyà bó o ṣe ń jíṣẹ́ ìkìlọ̀ fáwọn èèyàn, àmọ́ ó tún yẹ kó o máa fòye bá àwọn èèyàn lò. A gbọ́dọ̀ jẹ́ “ẹni pẹ̀lẹ́ [tàbí “afòyebánilò”] sí gbogbo ènìyàn,” ì báà tiẹ̀ jẹ́ ìhìn nípa “ọjọ́ Jèhófà” tó máa tó dé là ń kéde. (2 Tímótì 2:24; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; Jóẹ́lì 2:1, 11; Sefanáyà 1:14) Ẹ̀kọ́ míì tá a tún rí kọ́ lára àwọn wòlíì méjìlá náà nìyẹn. Wọn fìgboyà kéde ìdájọ́ Jèhófà, síbẹ̀, wọ́n gba tàwọn tó tẹ́tí sí wọn rò. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Sefanáyà ò fọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ aládé (ìyẹn àwọn ọ̀tọ̀kùlú) ìgbà ayé rẹ̀ tí wọ́n ti jingíri sínú ìwà ìbàjẹ́, àmọ́ kò bẹnu àtẹ́ lu Jòsáyà Ọba tó jẹ́ olóòótọ́. (Sefanáyà 1:8) Bá a ṣe ń jíṣẹ́ ìkìlọ̀ fáwọn èèyàn, ǹjẹ́ a lè mú kó túbọ̀ rọrùn nípa wíwò wọ́n bí ẹni tó lè di àgùntàn lọ́la, dípò ká máa wò wọ́n bí ẹni tí kò lè yí padà?—Mátíù 25:32-34.
11. (a) Kí ni apá kejì ìhìn alápá-méjì tá à ń polongo? (b) Báwo lo ṣe lè fara wé àwọn wòlíì méjìlá náà nígbà tó o bá ń kéde ọjọ́ Jèhófà?
11 Kí ni apá kejì ìhìn alápá-méjì tá à ń polongo? Míkà orí 5 la ti rí apá kejì náà. Ẹsẹ kan ní orí yẹn sọ pé: “Àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù yóò sì dà bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò lórí ewéko, tí kì í retí ènìyàn tàbí kí ó dúró de àwọn ọmọ ará ayé.” (Míkà 4:1; 5:7) Nítorí ìhìn rere tí “àwọn tí ó ṣẹ́ kù” nínú Jákọ́bù, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń mú tọ “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” lọ lónìí, wọ́n dà bí ‘ìrì tí ń tuni lára láti ọ̀dọ̀ Jèhófà’ àti “ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò lórí ewéko.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìparun nìkan kọ́ làwọn wòlíì náà kéde, àmọ́ tí wọ́n tún kéde ìmúbọ̀sípò, ó yẹ ká lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn ìwé méjìlá tó gbẹ̀yìn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nípa apá kejì yìí nínú ìhìn tá à ń kéde. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, ǹjẹ́ o máa ń tẹnu mọ́ apá tó ń múnú ẹni dùn yìí nínú ìhìn nípa ọjọ́ Jèhófà?
BÁWO LO ṢE Ń POLONGO ÌHÌN YÌÍ?
12, 13. (a) Kí ni ìtumọ̀ pàtàkì fífi tá a fi àwọn èèyàn Ọlọ́run wé ogunlọ́gọ̀ àwọn kòkòrò tó ń gbá yìn-ìn? (b) Kí lèrò rẹ nípa ohun tó o kà nínú Jóẹ́lì 2:7, 8?
12 Báwo lo ṣe ń polongo ìhìn alápá-méjì yìí? Wòlíì Jóẹ́lì fi iṣẹ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe wé oríṣiríṣi ìyọnu táwọn kòkòrò máa ń fà. Eéṣú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kòkòrò ọ̀hún. (Jóẹ́lì 1:4) Àmọ́, kí nìdí tí a ò fi rí nǹkan míì fi àwọn èèyàn Jèhófà wé, àfi ogunlọ́gọ̀ àwọn kòkòrò tó ń gbá yìn-ìn? Ìdí ni pé bí Jóẹ́lì 2:11 ṣe sọ, Ọlọ́run sọ pé àwọn kòkòrò yìí jẹ́ “ẹgbẹ́ ológun rẹ̀.” (Bákan náà, ìwé Ìṣípayá fi àwọn èèyàn Ọlọ́run wé eéṣú. Wo Ìṣípayá 9:3, 4.) Àwọn kòkòrò tí Jóẹ́lì ṣàpèjúwe dà bí iná tí ń jẹ gbogbo nǹkan run, ohun kan tó sì dà bí “ọgbà Édẹ́nì” ní ọ̀nà tí wọ́n ń tọ̀ di “aginjù tí ó di ahoro.” (Jóẹ́lì 2:2, 3) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọ ìtumọ̀ pàtàkì tí àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ní?
13 Ronú nípa bí àwọn kòkòrò kéékèèké wọ̀nyí ṣe ṣe iṣẹ́ wọn kúnnákúnná tó. Jóẹ́lì sọ pé: “Wọ́n sáré bí àwọn ọkùnrin alágbára. Wọ́n gun ògiri gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin ogun. Wọ́n sì ń lọ, olúkúlùkù ní ọ̀nà tirẹ̀, wọn kò sì yí ipa ọ̀nà wọn padà. Wọn kò sì ti ara wọn. Gẹ́gẹ́ bí abarapá ọkùnrin ní ipa ọ̀nà rẹ̀, wọ́n ń lọ ṣáá; ká ní àwọn kan lára wọn ṣubú sáàárín àwọn ohun ọṣẹ́ pàápàá, àwọn yòókù kì yóò yà kúrò ní ipa ọ̀nà.” (Jóẹ́lì 2:7, 8) Kò sí “ògiri” àtakò tó lè dí wọn lọ́wọ́ tàbí tó lè dínà àgbákò tí wọ́n ń fà. ‘Kódà bí àwọn kan lára wọn tiẹ̀ ṣubú sáàárín àwọn ohun ọṣẹ́,’ bíi tàwọn Kristẹni olóòótọ́ táwọn òǹrorò ọ̀tá pa, àwọn míì á máa bá iṣẹ́ tí wọ́n fi sílẹ̀ lọ, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe. Ǹjẹ́ o ti pinnu láti máa bá iṣẹ́ pípòkìkí ọjọ́ Jèhófà lọ títí tí Ọlọ́run á fi sọ pé ó tó? O tiẹ̀ lè máa bá iṣẹ́ náà lọ ní ipò àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó ti kú.
14. Báwo lo ṣe lè ṣe ipa tìrẹ nínú iṣẹ́ wíwàásù kúnnákúnná?
14 Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni pé a ní láti máa ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ kúnnákúnná. Báwo ni kálukú wa ṣe lè máa ṣe ipa tirẹ̀ kí iṣẹ́ ìwàásù lè jẹ́ èyí tá à ń ṣe kúnnákúnná bí àpèjúwe tí àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ṣe? Ìwọ lè ṣe ipa tìrẹ kúnnákúnná nípa wíwàásù láti ilé dé ilé kó o sì tún padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn àtàwọn tí o ò bá nílé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á hàn pé o mọ ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì nípa àwọn kòkòrò túmọ̀ sí. Bákan náà, tó o bá ń jẹ́rìí fáwọn èèyàn ní òpópónà, o lè rí àwọn tó jẹ́ pé ó lè má ṣeé ṣe fún ọ láti bá pàdé níbòmíràn. Ọ̀nà mìíràn wà tó o lè gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ kúnnákúnná: Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ran àwọn tó kó wá sí àdúgbò rẹ láti orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́.b Ṣé o máa ń wà lójúfò kó o lè mọ̀ nígbàkigbà táwọn àǹfààní tó o lè fi jẹ́rìí wọ̀nyí bá ṣí sílẹ̀, ṣé o sì máa ń lo àwọn àǹfààní náà láti ṣe ipa tìrẹ nínú ohun tí gbogbo wa ń para pọ̀ lépa lónìí, ìyẹn ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù kúnnákúnná?
KÍ LÓ MÁA PINNU BÓYÁ O KẸ́SẸ JÁRÍ NÍNÚ IṢẸ́ NÁÀ?
15. Kí ni nǹkan pàtàkì tó yẹ ká kíyè sí nínú bí àwọn èèyàn ṣe ṣe sí ìkéde àwọn wòlíì méjìlá náà?
15 Báwo làwọn èèyàn ṣe ń ṣe sí ìhìn tá à ń polongo nípa ọjọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ Jèhófà? Kò yẹ kó yà ọ́ lẹ́nu táwọn èèyàn bá ń ta kò ọ́ tàbí tí wọ́n ń dágunlá. Láyé ọjọ́un, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ṣe sí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì tó jẹ́ pé ìhìn ìkìlọ̀ tó lágbára ni Ọlọ́run ní kí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn kéde. (Jeremáyà 1:17-19; 7:27; 29:19) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn kan lára àwọn wòlíì náà rí àbájáde rere! Ó kéré tán, márùn-ún lára wọn ló sọ̀rọ̀ tó wọ àwọn èèyàn lọ́kàn débi pé àwọn kan ronú pìwà dà tí wọ́n sì yíwà padà. Àwọn wòlíì márùn-ún náà ni: Jónà, Míkà, Sefanáyà, Hágáì àti Sekaráyà.
16. Èso wo ni ìsapá wòlíì Míkà so?
16 Ó hàn gbangba pé ìkéde Sefanáyà ló mú kí Jòsáyà Ọba ṣètò bí wọ́n á ṣe padà sínú ìjọsìn tòótọ́. Nígbà tí Míkà fìgboyà kéde ìdájọ́ Ọlọ́run lòdì sí àwọn olórí ní Júdà, ohun tí Hesekáyà Ọba ṣe wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Míkà. (Míkà 3:1-3) Lẹ́yìn náà, nígbà táwọn àgbà ọkùnrin kan nígbà ayé Jeremáyà sọ pé Hesekáyà Ọba ‘bẹ̀rù Jèhófà tó sì tu Jèhófà lójú,’ ohun tí wọ́n ń sọ ni pé àpẹẹrẹ rere ni Hesekáyà fi lélẹ̀. (Jeremáyà 26:18, 19; 2 Àwọn Ọba 18:1-4) Lábẹ́ ipò aṣáájú Hesekáyà, àwọn èèyàn Júdà àtàwọn kan láti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá àti Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú, kódà wọ́n fi ọ̀sẹ̀ kan kún àkókò àjọyọ̀ náà. Kí ni àbájáde pípadà tí wọ́n padà sínú ìjọsìn tòótọ́? Bíbélì sọ àbájáde rẹ̀, ó ní: “Ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà sì wá wà ní Jerúsálẹ́mù.” (2 Kíróníkà 30:23-26) Àtìgbà ayé Áhásì Ọba ni Míkà ti ń kéde ìhìn àjálù tí Ọlọ́run fi rán an sí orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà náà. Míkà sì wá rí i pé ìsapá òun so èso rere nígbà tí Hesekáyà ọmọ Áhásì ṣe ohun tó tọ́.
17. Àṣeyọrí wo ló ṣeé ṣe fún Hágáì àti Sekaráyà láti ṣe?
17 Tún ronú nípa wòlíì Hágáì àti Sekaráyà. Wọ́n jíṣẹ́ Ọlọ́run fáwọn Júù tó padà dé láti ìgbèkùn. Àwọn Júù wọ̀nyẹn di onímọtara-ẹni-nìkan wọ́n sì ń dágunlá. (Hágáì 1:1, 2; Sekaráyà 1:1-3) Nígbà táwọn wòlíì náà fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í sọ tẹ́lẹ̀, ó ti ju ọdún mẹ́rìndínlógún lọ táwọn Júù ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀. Ńṣe ni wọ́n “ń sá kiri, olúkúlùkù nítorí ilé tirẹ̀,” nígbà tí ilé Jèhófà “wà ní ipò ahoro.” Hágáì wá gbà wọ́n níyànjú pé: “‘Kí ẹ sì jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́.’” Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Jèhófà ‘ru ẹ̀mí Gómìnà Serubábélì sókè,’ àti ẹ̀mí Jóṣúà Àlùfáà Àgbà àti “gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn náà.” Ìyẹn mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí.—Hágáì 1:9, 12, 14; 2:4.
18, 19. (a) Báwo làwọn èèyàn láwọn ilẹ̀ kan ṣe ń ṣe sí ìkéde ọjọ́ Jèhófà tí wọ́n ń gbọ́? (b) Bó ṣe jẹ́ pé a ní láti kéde ìhìn ìkìlọ̀ fún gbogbo èèyàn, kí ni wàá ṣe?
18 Orílẹ̀-èdè tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tẹ́lẹ̀ ni ọ̀pọ̀ lára àwọn wòlíì méjìlá náà jíṣẹ́ Ọlọ́run fún. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn èèyàn tí ò gbọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ rí làwa ń wàásù fún, àmọ́, a ṣì lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àbájáde ìgbòkègbodò àwọn wòlíì náà. Lónìí, bíi tìgbà yẹn, àwọn èèyàn ń gbọ́ ìhìn kánjúkánjú tá à ń kéde nípa ọjọ́ Jèhófà wọ́n sì ń ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. À ń rí irú àbájáde tí Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀, pé: “Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò sì dara pọ̀ mọ́ Jèhófà ní ọjọ́ náà dájúdájú, ní ti tòótọ́, wọn yóò sì di ènìyàn mi; dájúdájú, èmi yóò sì máa gbé ní àárín rẹ.” (Sekaráyà 2:11) Lákòókò wa yìí, àwa èèyàn Ọlọ́run ń rí i táwọn èèyàn láti “ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè” ń tẹ́wọ́ gba ìhìn tá à ń kéde. (Ìṣípayá 7:9) Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá yóò sì wá ní ti tòótọ́ láti wá Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Jerúsálẹ́mù àti láti tu Jèhófà lójú.” Ó ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè,” tí wọ́n á di etí aṣọ ẹnì kan tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí mú tí wọ́n á sì sọ pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”—Sekaráyà 8:20-23.
19 Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé “gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè.” À ń túmọ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì sí ọ̀pọ̀ èdè, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ń dá àwọn òjíṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa kọ́ àwọn èèyàn “gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti kọ́ èdè mìíràn kó o lè máa ran àwọn tó ń sọ èdè náà ní àdúgbò rẹ lọ́wọ́. Àwọn kan ti múra tán láti kọ́ èdè kan tàbí méjì kí wọ́n sì kó lọ sí orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ti ń fi ìháragàgà tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà. Ṣé á ṣeé ṣe fún ọ láti kó lọ sí irú àwọn ìpínlẹ̀ tó ń sèso bẹ́ẹ̀ kó o lè “pòkìkí èyí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè”? O ò ṣe gbé e yẹ̀ wò tàdúrà-tàdúrà? Tó bá jẹ́ pé o ní ìdílé, ṣètò pé kí ẹ máa gbé bó ṣe lè ṣeé ṣe fún yín láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn yẹ̀ wò léraléra bẹ́ ẹ bá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, kó o máa fi èyí síwájú àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun tẹ̀mí tọ́wọ́ wọn lè tẹ̀.
20. Irú ẹ̀mí wo ni Jèhófà fẹ́ ká kíyè sí nínú ohun tó sọ nípa àwọn ará Nínéfè?
20 Jónà ni wòlíì mìíràn táwọn èèyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ará Nínéfè táwọn èèyàn ò retí pé wọ́n á gbọ́ ló sì gbọ́ ọ. Wọ́n gbọ́ ìkéde Jónà, wọ́n ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe, wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, kódà ọba Nínéfè alára ṣe bẹ́ẹ̀. Abájọ tí Ọlọ́run fi béèrè pé: “Kò ha . . . yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà, tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn?” (Jónà 4:11) Ronú nípa ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí, kó o tún ronú nípa ohun tó sún ọ tó o fi ń pòkìkí ọjọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn, kó o wá wo méjèèjì pọ̀. Ǹjẹ́ o rí i pé o jẹ Jèhófà ní gbèsè nítorí fífi tó fi ẹbọ ìràpadà gbà ọ́ là? Ǹjẹ́ o rí i pé o wà lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti ṣe ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣèyàsímímọ́? (1 Kọ́ríńtì 9:16, 17) Ìwọ̀nyí jẹ́ ìdí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tó fi yẹ kó o máa pòkìkí ọjọ́ Jèhófà. Àmọ́, kókó kan tún rèé o: Ǹjẹ́ o máa ń “káàánú” àwọn èèyàn tó ò ń kéde ọjọ́ Jèhófà fún? O ò rí i pé ayọ̀ rẹ á kún nígbà tí àánú bíi ti Ọlọ́run bá sún ọ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà!
21. Kí lo rí kọ́ nínú bí Ámósì ṣe ṣe nígbà tí Amasááyà halẹ̀ mọ́ ọn?
21 A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí àwọn èèyàn ṣe ṣe sí Jóẹ́lì, Ọbadáyà, Náhúmù, Hábákúkù, àti Málákì. Ṣùgbọ́n ó kéré tán, a mọ bí ẹnì kan ṣe ṣe sí Ámósì. Amasááyà ta ko wòlíì Ámósì gidigidi, ó fẹ̀sùn kàn án pé ó ń di rìkíṣí sí ọba, ó sì gbìyànjú láti fòfin de Ámósì pé kò gbọ́dọ̀ wàásù ní Bẹ́tẹ́lì. (Ámósì 7:10-13) Ámósì fi ìgboyà kojú àtakò yẹn. Lóde òní pẹ̀lú, àwọn onísìn lè gbìyànjú láti mú kí àwọn alákòóso òṣèlú ṣenúnibíni sí àwa èèyàn Jèhófà tàbí kí wọ́n gbìyànjú láti mú kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa tó ṣàǹfààní. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ǹjẹ́ wàá fara wé Ámósì tí wàá sì máa fi ìgboyà kéde ìhìn rere láìfi àtakò pè?
22. Kí nìdí tó o fi lè sọ pé iṣẹ́ ìjẹ́rìí ń kẹ́sẹ járí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ rẹ?
22 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú nǹkan làwọn èèyàn ṣe sáwọn wòlíì méjìlá náà, gbogbo wọn ló jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn. Pé àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gba ìhìn alápá-méjì tá à ń polongo kọ́ ló jà jù, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jà jù ni pé à ń fi “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa” rúbọ sí Jèhófà, ìyẹn “ẹbọ ìyìn” wa tó dára jù lọ. (Hóséà 14:2; Hébérù 13:15) Tá a bá ti ṣe ìyẹn, ẹ jẹ́ ká fi èyí tó kù sílẹ̀ fún Ọlọ́run. Yóò fa àwọn tó jẹ́ àgùntàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jòhánù 6:44) Yálà àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gba ìhìn tó ò ń kéde tàbí wọn ò tẹ́wọ́ gbà á, o lè ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí ìhìn Ọlọ́run. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé ‘ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá tó sì ń kéde àlàáfíà’ dára rèǹtè-rente lójú àwọn tó mọyì ìhìn rere tí wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gbà á. Èyí tó tiẹ̀ wá dáa jù lọ ni pé ó dára lójú Jèhófà. (Náhúmù 1:15; Aísáyà 52:7) Bí ọjọ́ ńlá Jèhófà ṣe sún mọ́lé gan-an yìí, pinnu pé wàá máa bá a lọ láti ṣe ohun tí Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé á máa wáyé ní àkókò wa yìí, ìyẹn kíkéde ogun tí Ọlọ́run yóò bá àwọn orílẹ̀-èdè jà. Jóẹ́lì kéde pé: “Ẹ pòkìkí èyí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ‘Ẹ sọ ogun di mímọ́! Ẹ ru àwọn ọkùnrin alágbára dìde!’” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run yóò bá àwọn orílẹ̀-èdè jagun.—Jóẹ́lì 3:9.
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́ lákòókò àwọn Mákábì. Nígbà yẹn, àwọn Júù lábẹ́ àwọn Mákábì lé àwọn ọ̀tá wọn kúrò ní Júdà wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì yà sí mímọ́. Ìyẹn ló mú kó ṣeé ṣe fún àṣẹ́kù àwọn Júù láti kí Mèsáyà káàbọ̀ nígbà tó fara hàn.—Dáníẹ́lì 9:25; Lúùkù 3:15-22.
b Àwọn kan ti lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Good News for People of All Nations, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, láti fi ran àwọn tí kì í sọ èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ ní àdúgbò wọn lọ́wọ́.