“Má Bẹ̀rù, Agbo Kékeré”
“Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nitori pé Baba yín ti fi ojúrere tẹ́wọ́gba fífi ìjọba naa fún yín.”—LUKU 12:32, NW.
1. Kí ni ìdí náà fún ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré”?
“ẸMÁA wá ìjọba [Ọlọrun] nígbà gbogbo.” (Luku 12:31, NW) Nígbà tí Jesu sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ̀rọ̀ nípa ìlànà kan tí ó ti ń darí ìrònú àwọn Kristian láti ọjọ́ rẹ̀ títí di ọjọ́ tiwa. Ìjọba Ọlọrun ni ó gbọ́dọ̀ gba ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí-ayé wa. (Matteu 6:33) Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àkọsílẹ̀ Luku, Jesu ń bá a nìṣó láti máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ fífanimọ́ra àti èyí tí ń múni lọ́kàn le fún àkànṣe àwùjọ àwọn Kristian kan. Ó wí pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nitori pé Baba yín ti fi ojúrere tẹ́wọ́gba fífi ìjọba naa fún yín.” (Luku 12:32, NW) Gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùtàn Àtàtà náà, Jesu mọ̀ pé àwọn àkókò onírúkèrúdò wà níwájú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ṣùgbọ́n kò sí ìdí fún wọn láti bẹ̀rù bí wọ́n bá ń bá a nìṣó láti máa wá Ìjọba Ọlọrun. Nítorí ìdí èyí, ọ̀rọ̀-ìyànjú Jesu kì í ṣe àṣẹ lílekoko. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìlérí onífẹ̀ẹ́ tí ó ṣiṣẹ́ láti fúnni ní ìgbọ́kànlé àti ìgboyà.
2. Àwọn wo ni wọ́n parapọ̀ di agbo kékeré náà, èésìtiṣe tí àwọn ní pàtàkì fi ní àǹfààní àrà-ọ̀tọ̀?
2 Jesu ń bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì pè wọ́n ní “agbo kékeré.” Ó tún ń bá àwọn wọnnì tí Jehofa yóò ‘fi ìjọba náà fún’ sọ̀rọ̀. Bí a bá fi wọ́n wéra pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ rẹpẹtẹ tí yóò tẹ́wọ́gba Jesu lẹ́yìn àkókò yẹn, àwùjọ yìí kéré níye níti gidi. A sì tún kà wọ́n sí iyebíye nítorí pé a yàn wọ́n fún ọjọ́-ọ̀la pípẹtẹrí kan, kí a lè lò wọ́n nínú iṣẹ́-ìsìn ọlọ́ba. Bàbá wọn, Olùṣọ́ Àgùtàn Ńlá náà, Jehofa, pe agbo kékeré náà pẹ̀lú èrò pé wọn yóò gba ogún-ìní ti ọ̀run ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba Messia ti Kristi.
Agbo Kékeré
3. Ìran ológo wo ni Johannu rí nípa agbo kékeré?
3 Nígbà náà, àwọn wo ni wọ́n parapọ̀ di agbo kékeré yìí tí wọ́n ní irú ìfojúsọ́nà àgbàyanu bẹ́ẹ̀? Àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ni. (Iṣe 2:1-4) Nígbà tí ó rí wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn akọrin tí háàpù wà ní ọwọ́ wọn, aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa dúró lórí Òkè-Ńlá Sioni, ati pẹlu rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. Awọn wọnyi ni awọn tí kò fi obìnrin sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin; níti tòótọ́, wúńdíá ni wọ́n. Awọn wọnyi ni awọn tí ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ. Awọn wọnyi ni a rà lati àárín aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọrun ati fún Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa, a kò sì rí èké kankan ní ẹnu wọn; wọ́n wà láìní àbààwọ́n.”—Ìṣípayá 14:1, 4, 5, NW.
4. Ipò wo ni agbo kékeré ní lórí ilẹ̀-ayé lónìí?
4 Láti Pentekosti 33 C.E., àwọn ẹni-àmì-òróró, tí a fi ẹ̀mí bí wọ̀nyí ti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ fún Kristi lórí ilẹ̀-ayé. (2 Korinti 5:20) Lónìí, ó ṣẹ́ku kìkì àṣẹ́kù kan lára wọn, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú. (Matteu 24:45; Ìṣípayá 12:17) Ní pàtàkì láti ọdún 1935, “awọn àgùtàn mìíràn,” àwọn Kristian tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀-ayé, tí iye wọn ti wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí, ti darapọ̀ mọ́ wọn. Àwọn wọ̀nyí ń ṣèrànwọ́ láti wàásù ìhìnrere náà ní gbogbo ayé.—Johannu 10:16, NW.
5. Kí ni ìṣarasíhùwà àṣẹ́kù agbo kékeré náà, èésìtiṣe tí kò fi sí ìdí fún wọn láti bẹ̀rù?
5 Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn tí ó ṣẹ́kù lára agbo kékeré yìí tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé? Bí wọ́n ti mọ̀ pé àwọn yóò gba ‘Ìjọba kan tí kò ṣeé mì,’ wọ́n ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wọn pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọrun àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. (Heberu 12:28, NW) Wọ́n fi tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ mọ̀ pé àwọn ní àǹfààní tí kò ṣeé díwọ̀n tí ń yọrí sí ìdùnnú-ayọ̀ tí kò ní ààlà. Wọ́n ti rí “péàlì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga” tí Jesu tọ́ka sí nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà. (Matteu 13:46, NW) Bí ìpọ́njú ńlá ti ń súnmọ́lé, àwọn ẹni-àmì-òróró Ọlọrun dúró láìbẹ̀rù. Láìka ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹ sórí ayé aráyé sí ní “ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ alókìkíkáyé ti Jehofa,” wọn kò ní ìbẹ̀rù oníjìnnìjìnnì nípa ọjọ́-ọ̀la. (Iṣe 2:19-21, NW) Ìdí ha wà tí wọ́n fi níláti bẹ̀rù bí?
Iye Wọn Ń Dínkù
6, 7. (a) Èéṣe tí iye àṣẹ́kù agbo kékeré tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé fi kéré jọjọ? (b) Ojú wo ni ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan fi wo ìrètí tí òun dìmú?
6 Ní àwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí iye agbo kékeré tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé ti dínkù gidigidi. Èyí ṣe kedere láti inú ìròyìn Ìṣe-Ìrántí ti 1994. Nínú nǹkan bíi 75,000 ìjọ àwọn ènìyàn Jehofa kárí-ayé, 8,617 péré ni ó fi ìjẹ́wọ́ wọn hàn pé àwọn jẹ́ mẹ́ḿbà àṣẹ́kù náà nípa jíjẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ. (Matteu 26:26-30) Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àròpọ̀ iye àwọn tí ó pésẹ̀ jẹ́ 12,288,917. Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn retí èyí. Jehofa ti fìdí iye pàtó kan, tí í ṣe 144,000 múlẹ̀, láti parapọ̀ di agbo kékeré náà, ó sì ti ń kó o jọ láti Pentekosti 33 C.E. wá. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n-ìrònú mu, ìpè agbo kékeré náà yóò wá sí ìparí nígbà tí iye náà bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé, ẹ̀rí tí ó wà sì ni pé ìkójọpọ̀ gbogbogbòò ti àwọn ẹni tí a bùkún lọ́nà àkànṣe yìí parí ní 1935. Bí ó ti wù kí ó rí, a sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn àgùtàn mìíràn ní àkókò òpin yóò pọ̀ sí i tí wọn yóò fi di “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹni kankan kò lè kà, lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n.” Láti 1935 ni Jehofa ti ń ṣe ìkójọpọ̀ gbogbogbòò ti ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí, tí ìrètí wọn jẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun lórí paradise ilẹ̀-ayé.—Ìṣípayá 7:9, NW; 14:15, 16; Orin Dafidi 37:29.
7 Ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti agbo kékeré tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé síbẹ̀ ni ọjọ-orí wọn ti rékọjà 70, 80, àti 90 ọdún. Àwọn díẹ̀ tilẹ̀ ti rékọjá ọgọ́rùn-ún ọdún ìwàláàyè wọn. Àwọn wọ̀nyí pátá, ohun yòówù kí ọjọ́-orí wọn jẹ́, mọ̀ pé nípasẹ̀ àjíǹde sí ọ̀run, wọn yóò sopọ̀ṣọ̀kan ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ pẹ̀lú Jesu Kristi wọn yóò sì ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀ ológo. Àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá yóò jẹ́ ọmọ-abẹ́ orí ilẹ̀-ayé fún Kristi Ọba. Ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù yọ̀ lórí ohun tí Jehofa ní ní ìpamọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀. Kì í ṣe tiwa láti yan ìrètí tí a níláti ní. Jehofa ni ó níláti pinnu ìyẹn. Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì lè yọ̀ nínú ìrètí wọn fún ọjọ́-ọ̀la aláyọ̀, yálà ó jẹ́ nínú Ìjọba ti òkè ọ̀run tàbí lórí paradise ilẹ̀-ayé lábẹ́ Ìjọba yẹn.—Johannu 6:44, 65; Efesu 1:17, 18.
8. Báwo ni fífi èdìdì dì 144,000 náà ti lọ jìnnà tó, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó bá parí?
8 Agbo kékeré náà tí wọ́n jẹ́ 144,000 oníye kan pàtó ni “Israeli Ọlọrun,” èyí tí ó ti rọ́pò Israeli àbínibí nínú àwọn ète Ọlọrun. (Galatia 6:16, NW) Nítorí náà, àṣẹ́kù náà ni ó parapọ̀ jẹ́ apá tí ó ṣẹ́kù nínú orílẹ̀-èdè Israeli tẹ̀mí tí ó ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé. Irú àwọn àṣẹ́kù bẹ́ẹ̀ ni a ń fi èdìdì dì fún ìtẹ́wọ́gbà Jehofa tí kò ṣeé yípadà. Nínú ìran kan, aposteli Johannu rí i tí èyí ń ṣẹlẹ̀, ó sì ròyìn pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń gòkè lati ibi yíyọ-oòrùn, ó ní èdìdì Ọlọrun alààyè; ó sì ké pẹlu ohùn rara sí awọn áńgẹ́lì mẹ́rin naa tí a yọ̀ǹda fún lati pa ilẹ̀-ayé ati òkun lára, wí pé: ‘Ẹ máṣe pa ilẹ̀-ayé tabi òkun tabi awọn igi lára, títí di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì di awọn ẹrú Ọlọrun wa ní iwájú orí wọn.’ Mo sì gbọ́ iye awọn wọnnì tí a fi èdìdì dì, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí a fi èdìdì dì lati inú gbogbo ẹ̀yà awọn ọmọ Israeli [nípa tẹ̀mí].” (Ìṣípayá 7:2-4) Níwọ̀n bí ó ti ṣe kedere pé iṣẹ́ fífi èdìdì dì Israeli tẹ̀mí yìí ti ń lọ sí ìparí rẹ̀, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń runisókè tí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ ni a tọ́ka sí. Ohun kan ni pé “ìpọ́njú ńlá naa,” tí yóò wáyé lẹ́yìn tí a bá ti tú afẹ́fẹ́ apanirun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sórí ilẹ̀-ayé, ti gbọ́dọ̀ súnmọ́lé gidigidi.—Ìṣípayá 7:14, NW.
9. Ojú wo ni agbo kékeré fi ń wo iye ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń pọ̀ sí i?
9 Àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti ogunlọ́gọ̀ ńlá náà tí a ti kójọpọ̀ báyìí ti wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ní iye. Ẹ wo bí èyí ti mú ọkàn-àyà àwọn àṣẹ́kù yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ tó! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbo kékeré tí wọ́n ṣì ṣẹ́kù lórí ilẹ̀-ayé ń báa lọ láti máa dínkù síi, wọ́n ti dá àwọn ọkùnrin tí wọ́n tóótun lára ogunlọ́gọ̀ ńlá náà lẹ́kọ̀ọ́ wọ́n sì ti múra wọn sílẹ̀ láti tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ètò-àjọ Ọlọrun ti orí ilẹ̀-ayé tí ń gbòòrò síi. (Isaiah 61:5) Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ, àwọn olùla ìpọ́njú ńlá náà já yóò wà.—Matteu 24:22.
“Má Bẹ̀rù”
10. (a) Àtakò wo ni a máa tó gbé dìde sí àwọn ènìyàn Ọlọrun, kí ni yóò sì yọrí sí? (b) Ìbéèrè wo ni a bi ẹnìkọ̀ọ̀kan wa?
10 Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni a ti rẹ̀nípòsílẹ̀ sí sàkáání ilẹ̀-ayé. Òun àti agbo alátìlẹ́yìn rẹ̀ ni a ti ń dárí láti fi gbogbo ìsapá wọn gbéjàko àwọn ènìyàn Jehofa. Ìgbéjàkò yìí, tí a ti sọtẹ́lẹ̀ nínú Bibeli, ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ìgbéjàkò láti ọ̀dọ̀ Gogu ti Magogu. Àwọn wo ní pàtàkì ni Èṣù darí ìkọlù rẹ̀ sí? Kì í ha ṣe àwọn mẹ́ḿbà tí ó kẹ́yìn lára agbo kékeré, Israeli tẹ̀mí Ọlọrun, tí wọ́n ń gbé ní àlàáfíà ní “àárín gbùngbùn ilẹ̀-ayé” ni bí? (Esekieli 38:1-12, NW) Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n àṣẹ́kù ẹgbẹ́ ẹni-àmì-òróró olùṣòtítọ́, papọ̀ pẹ̀lú àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn adúróṣinṣin, àwọn àgùtàn mìíràn, yóò ṣẹlẹ́rìí bí ìgbéjàkò Satani yóò ṣe mú kí Jehofa Ọlọrun hùwà sí i lọ́nà tí ń múnijígìrì. Yóò dásí i láti lè gbèjà àwọn ènìyàn rẹ̀, èyí yóò sì súnná sí ìbẹ́sílẹ̀ “ọjọ́ ńlá àti ẹ̀rù Oluwa.” (Joeli 2:31) Lónìí, olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà ń ṣàṣeparí iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà kan, tí ó ṣekókó, tí ń kininílọ̀ nípa ìdásí Jehofa tí ń bọ̀wá yìí. (Malaki 4:5; 1 Timoteu 4:16) Ìwọ ha ń fi taápọn taápọn ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́-ìsìn yẹn, tí o sì ń kópa nínú ìwàásù ìhìnrere Ìjọba Jehofa bí? Ìwọ yóò ha máa bá a lọ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba tí kì í bẹ̀rù bí?
11. Èéṣe ti ìṣarasíhùwà onígboyà fi ṣekókó lónìí?
11 Lójú ìwòye bí ipò ayé ṣe rí ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, ẹ wo bí ó ti bá àkókò mu tó fún agbo kékeré náà láti kọbiara sí ọ̀rọ̀ tí Jesu darí rẹ̀ sí wọn pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré”! Irú ìṣarasíhùwà onígboyà bẹ́ẹ̀ ṣekókó lójú ìwòye gbogbo ohun tí a ń ṣe àṣeparí rẹ̀ nísinsìnyí ní ìbámu pẹ̀lú ète Jehofa. Lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan lára agbo kékeré náà mọrírì àìní náà láti lo ìfaradà títí dé òpin. (Luku 21:19) Gẹ́gẹ́ bí Jesu Kristi, Oluwa àti Ọ̀gá agbo kékeré náà, ti lo ìfaradà tí ó sì fi ẹ̀rí jíjẹ́ olùṣòtítọ́ hàn títí dé òpin ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àṣẹ́kù náà gbọ́dọ̀ lo ìfaradà kí wọ́n sì fi ẹ̀rí jíjẹ́ olùṣòtítọ́ hàn.—Heberu 12:1, 2.
12. Gẹ́gẹ́ bíi ti Jesu, báwo ni Paulu ṣe gba àwọn Kristian níyànjú láti máṣe bẹ̀rù?
12 Gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró gbọ́dọ̀ ní ojú-ìwòye kan náà gẹ́gẹ́ bíi ti aposteli Paulu. Kíyèsí i bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni-àmì-òróró olùpòkìkí àjíǹde ní gbangba ṣe wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú Jesu láti máṣe bẹ̀rù. Paulu kọ̀wé pé: “Rántí pé a gbé Jesu Kristi dìde kúrò ninu òkú ati pé irú-ọmọ Dafidi ni oun jẹ́, ní ìbámu pẹlu ìhìnrere tí mo ń wàásù; ní ìsopọ̀ pẹlu èyí tí mo ń jìyà ibi títí dé orí awọn ìdè ẹ̀wọ̀n bí aṣebi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítìtorí èyí mo ń bá a lọ ní fífarada ohun gbogbo nitori awọn àyànfẹ́, kí awọn pẹlu lè rí ìgbàlà naa gbà tí ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Kristi Jesu papọ̀ pẹlu ògo àìnípẹ̀kun. Àsọjáde naa ṣe é gbíyèlé: Dájúdájú bí a bá kú papọ̀, a óò wà láàyè papọ̀ pẹlu; bí a bá ń bá a lọ ní fífaradà, a óò ṣàkóso papọ̀ pẹlu gẹ́gẹ́ bí ọba; bí a bá sẹ́, oun pẹlu yoo sẹ́ wa; bí a bá jẹ́ aláìṣòótọ́, oun dúró ní olùṣòtítọ́, nitori oun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.”—2 Timoteu 2:8-13, NW.
13. Ìdálójú jíjinlẹ̀ wo ni àwọn mẹ́ḿbà agbo kékeré náà dìmú, kí sì ni èyí sún wọn láti ṣe?
13 Bíi ti aposteli Paulu, àwọn mẹ́ḿbà tí ó ṣẹ́kù lára agbo kékeré ẹni-àmì-òróró múratán láti farada ìjìyà bí wọ́n ti ń polongo ìhìn-iṣẹ́ alágbára tí a gbékalẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìdálójú ìgbàgbọ́ wọn fìdímúlẹ̀ ṣinṣin bí wọ́n ti ń fìgbà gbogbo gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìlérí Ọlọrun fún ìgbàlà àti ti fífi tí a óò fi “adé ìyè” fún wọn bí wọ́n bá jẹ́ olùṣòtítọ́ títí dé ojú ikú. (Ìṣípayá 2:10, NW) Nípa níní ìrírí ìyípadà àti àjíǹde ojú-ẹsẹ̀, a óò mú wọn wá sínú ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, láti ṣàkóso papọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ẹ wo irú ayọ̀ ìṣẹ́gun tí èyí jẹ́ fún ipa-ọ̀nà ìpàwàtítọ́mọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun ayé!—1 Johannu 5:3, 4.
Ìrètí Tí Kò Lẹ́gbẹ́
14, 15. Ní ọ̀nà wo ni ìrètí àjíǹde agbo kékeré gbà jẹ́ èyí tí kò lẹ́gbẹ́?
14 Ìrètí àjíǹde tí agbo kékeré náà ní kò lẹ́gbẹ́. Ní àwọn ọ̀nà wo? Ohun kan ni pé, ó ṣáájú àjíǹde gbogbogbòò ti “awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo.” (Iṣe 24:15, NW) Níti gidi, àjíǹde àwọn ẹni-àmì-òróró jẹ́ ọ̀kan tí ó tẹ̀léra lọ́nà pàtàkì kan, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ tí a rí nínú 1 Korinti 15:20, 23 (NW) wọ̀nyí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ kedere pé: “A ti gbé Kristi dìde kúrò ninu òkú, àkọ́so ninu awọn wọnnì tí wọ́n ti sùn ninu ikú. Ṣugbọn olúkúlùkù ní ìlà-ipò tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn naa awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.” Nípa níní irú ìfaradà àti ìgbàgbọ́ tí Jesu fihàn, agbo kékeré náà mọ ohun tí ń bẹ ní ìpamọ́ fún wọn bí wọ́n ti ń parí ipa-ọ̀nà wọn lórí ilẹ̀-ayé, ní pàtàkì láti ìgbà tí Oluwa tòótọ́ náà ti wá sínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ fún ìdájọ́ ní 1918.—Malaki 3:1.
15 Paulu fún wa ní ìdí mìíràn láti wo àjíǹde yìí gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò lẹ́gbẹ́. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ní 1 Korinti 15:51-53 (NW), ó kọ̀wé pé: “Wò ó! Àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ ni mo ń sọ fún yín: Kì í ṣe gbogbo wa ni yoo sùn ninu ikú, ṣugbọn a óò yí gbogbo wa padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn. . . . Nitori èyí tí ó lè díbàjẹ́ yii gbọ́dọ̀ gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ati èyí tí ó jẹ́ kíkú yii gbọ́dọ̀ gbé àìkú wọ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìfisílò fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti agbo kékeré tí wọ́n kú nígbà wíwàníhìn-ín Kristi. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ níláti sùn fún àkókò gígùn nínú ikú, àìlèkú ni a gbé wọ̀ wọ́n, “ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́.”
16, 17. Nípa ìrètí àjíǹde tí wọ́n ní, ni ọ̀nà pàtàkì wo ni a gbà bùkún àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró lónìí?
16 Pẹ̀lú òye yìí, a lè lóye ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Johannu tí a rí nínú Ìṣípayá 14:12, 13 (NW). Ó kọ̀wé pé: “‘Níhìn-ín ni ibi tí ó ti túmọ̀ sí ìfaradà fún awọn ẹni mímọ́, awọn wọnnì tí ń pa awọn àṣẹ Ọlọrun ati ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.’ Mo sì gbọ́ tí ohùn kan lati ọ̀run wá wí pé: ‘Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni awọn òkú tí wọ́n kú ní [ìrẹ́pọ̀] pẹlu Oluwa lati àkókò yii lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, ni ẹ̀mí wí, kí wọ́n sinmi kúrò ninu awọn òpò wọn, nitori awọn ohun tí wọ́n ṣe ń bá wọn lọ ní tààràtà.’”
17 Ẹ wo èrè-ẹ̀san tí kò lẹ́gbẹ́ tí ń bẹ ní ìpamọ́ fún àṣẹ́kù agbo kékeré náà! Àjíǹde wọn yóò wáyé ní kíákíá, ní kété lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sùn nínú ikú. Ẹ wo ìyípadà pípẹtẹrí tí wọn yóò ní ìrírí rẹ̀ bí wọ́n ti ń gba iṣẹ́ àyànfúnni wọn ní ilẹ̀-ọba ẹ̀mí! Bí ìṣelógo agbo kékeré náà ti ń lọ lọ́wọ́ nísinsìnyí tí ìmúṣẹ àwọn lájorí àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli sì ń súnmọ́ ìparí wọn, àwọn àṣẹ́kù mẹ́ḿbà tí ó kẹ́yìn lára agbo kékeré náà kò níláti “bẹ̀rù” nítòótọ́. Àìbẹ̀rù wọn sì ṣiṣẹ́ láti fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n gbọ́dọ̀ mú irú ìwà àìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ dàgbà ní ìṣírí bí wọ́n ti ń wọ̀nà fún ìdáǹdè ní àkókò oníwàhálà jùlọ tí ayé tí ì ní ìrírí rẹ̀ rí.
18, 19. (a) Èéṣe tí àkókò tí a ń gbé nínú rẹ̀ fi jẹ́ àkókò kánjúkánjú? (b) Èéṣe tí àwọn ẹni-àmì-òróró àti àwọn àgùtàn mìíràn kò fi níláti bẹ̀rù?
18 Sísọ̀rọ̀ nípa ìgbòkègbodò agbo kékeré mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn àti ogunlọ́gọ̀ ńlá láti máa bá a nìṣó ní bíbẹ̀rù Ọlọrun òtítọ́. Wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, àkókò ojúrere tí ó ṣẹ́kù sì ṣeyebíye. Níti gidi, àkókò tí ó ṣẹ́kù fún àwọn ẹlòmíràn láti gbégbèésẹ̀ kéré jọjọ. Ṣùgbọ́n, àwa kò bẹ̀rù pé ète Ọlọrun yóò kùnà. Ó dájú pé yóò kẹ́sẹjárí!
19 Ní báyìí ná, a ti gbọ́ tí àwọn ohùn tí ń kérara ní ọ̀run ń wí pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Oluwa wa ati ti Kristi rẹ̀, oun yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé ati láéláé.” (Ìṣípayá 11:15, NW) Dájúdájú, Olùṣọ́ Àgùtàn Ńlá náà, Jehofa, ń ṣamọ̀nà gbogbo àwọn àgùtàn rẹ̀ ‘sí ipa-ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.’ (Orin Dafidi 23:3) Agbo kékeré náà ni a ń ṣamọ̀nà lọ sí èrè-ẹ̀san wọn ní ọ̀run láìsí ìṣìnà. Àwọn àgùtàn mìíràn ni a óò sì dánídè láàyè la ìpọ́njú ńlá náà já láti gbádùn ìyè ayérayé nínú pápá-àkóso Ìjọba ológo tí ó jẹ́ ti Ọlọrun lábẹ́ ìṣàkóso Kristi Jesu. Nítorí ìdí èyí, nígbà tí a darí ọ̀rọ̀ Jesu sí agbo kékeré, ó dájú pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé ní ìdí láti fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Má bẹ̀rù.”
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Èéṣe tí a fi níláti retí pé kí iye tí ó ṣẹ́kù lára agbo kékeré náà dínkù?
◻ Kí ni ipò àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró lónìí?
◻ Èéṣe tí àwọn Kristian kò fi níláti bẹ̀rù, láìka àtakò Gogu ti Magogu tí ń bọ̀wá sí?
◻ Èéṣe tí ìrètí àjíǹde àwọn 144,000 fi jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, pàápàá jùlọ lónìí?