-
Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀Ilé Ìṣọ́—2009 | January 1
-
-
Bó ṣe rí i pé kò sóun tóun lè ṣe sí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀, ó lọ wábì kan sùn sí nínú ọkọ̀ náà. Ó sì sùn lọ fọnfọn.b Ọ̀gákọ̀ náà rí i níbi tó sùn sí, ló bá jí i pé kóun náà gbàdúrà sí ọlọ́run tiẹ̀ náà. Àwọn atukọ̀ òkun náà ti wá rí i pé ìjì tó ń jà náà kì í ṣe ojú lásán, wọ́n bá ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè mọ ẹni tó fa ìṣòro náà. Ó dájú pé ọkàn Jónà á ti máa lù kìkì bí wọ́n ṣe ń dárúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kàn tó wà nínú ọkọ̀ náà. Nígbà tó yá, àṣírí tú. Torí Jónà ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí ìjì náà jà, òun náà sì ni kèké mú!—Jónà 1:5-7.
-
-
Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀Ilé Ìṣọ́—2009 | January 1
-
-
b Bíbélì Septuagint sọ pé Jónà hanrun, ìyẹn sì jẹ́ ká mọ bó ṣe sùn wọra tó. Àmọ́, kò ní dáa tá a bá rò pé torí kí Jónà má bàa dá sí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ló ṣe lọ wábi sùn sí, a lè rántí pé nígbà míì oorun máa ń kun àwọn tó bá rẹ̀wẹ̀sì. Nígbà tí Jésù wà lọ́gbà Gẹtisémánì lákòókò tí nǹkan ò rọrùn fún un, ńṣe ni Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù “ń tòògbé nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.”—Lúùkù 22:45.
-