Báwo Lo Ṣe Lè Pa Kún Ìṣọ̀kan Tó Wà Láàárín Àwa Kristẹni?
‘Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara náà [ti wà pa] pọ̀ ní ìṣọ̀kan [tí a sì] mú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀.’—ÉFÉSÙ 4:16 4:16.
1. Kí ló fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀?
LÁTÌBẸ̀RẸ̀ ìṣẹ̀dá ni Jèhófà àti Jésù ti wà níṣọ̀kan. Kí Jèhófà tó dá gbogbo ohun mìíràn ló ti dá Jésù. Jésù bá Jèhófà ṣiṣẹ́, ó sì “wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà náà máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà bá ní kí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Nóà àti ìdílé ẹ̀ pawọ́ pọ̀ kan ọkọ̀ áàkì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà pawọ́ pọ̀ kọ́ àgọ́ ìjọsìn, wọ́n jọ máa ń tú u palẹ̀, wọ́n á sì tún jọ gbé e láti ibì kan sí ibòmíràn. Nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n máa ń jùmọ̀ lo àwọn ohun èlò ìkọrin, wọ́n sì máa ń pa ohùn pọ̀ kọrin aládùn sí Jèhófà. Torí pé àwọn èèyàn Jèhófà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ló jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan yìí láṣeyọrí.—Jẹ́nẹ́sísì 6:14-16, 22; Númérì 4:4-32; 1 Kíróníkà 25:1-8.
2. (a) Kí ló wúni lórí nípa àwọn Kristẹni tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?
2 Àwọn Kristẹni tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní, iṣẹ́ wọn ò sì dọ́gba, gbogbo wọn ṣera wọn lọ́kan. Àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ Aṣáájú wọn ni gbogbo wọn ń tẹ̀ lé. Pọ́ọ̀lù fi ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn wé bí àwọn ẹ̀yà ara ṣe máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. (Ka 1 Kọ́ríńtì 12:4-6, 12.) Àmọ́, àwa náà ńkọ́? Báwo la ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, nínú ìjọ àti nínú ìdílé?
MÁA FỌWỌ́ SOWỌ́ PỌ̀ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
3. Ìran wo ni àpọ́sítélì Jòhánù rí?
3 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àpọ́sítélì Jòhánù rí àwọn áńgẹ́lì méje kan nínú ìran tí wọ́n ń fun kàkàkí. Nígbà tí áńgẹ́lì karùn-ún fun kàkàkí rẹ̀, Jòhánù rí “ìràwọ̀ kan tí ó ti jábọ́ láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé.” “Ìràwọ̀” yẹn fi kọ́kọ́rọ́ kan ṣí kòtò jíjìn kan tó ṣókùnkùn biribiri. Èéfín ńlá kan ló kọ́kọ́ rú jáde látinú kòtò náà, lẹ́yìn náà ni ọ̀wọ́ àwọn eéṣú wá jáde wá látinú èéfín náà. Dípò tí àwọn eéṣú yìí ì bá fi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn igi tàbí àwọn ewéko run, àwọn èèyàn tí “kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn” ni wọ́n ya bò. (Ìṣípayá 9:1-4) Jòhánù mọ̀ pé ọṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn eéṣú máa ń ṣe; wọ́n ti pitú nílẹ̀ Íjíbítì nígbà ayé Mósè. (Ẹ́kísódù 10:12-15) Àwọn eéṣú tí Jòhánù rí dúró fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ń kéde ìdájọ́ Ọlọ́run sórí ìsìn èké. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé náà sì ti dara pọ̀ mọ́ wọn láti máa wàásù. Iṣẹ́ ìwàásù yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ìsìn èké sílẹ̀, ó sì ti dá wọn sílẹ̀ kúrò lóko ẹrú Sátánì.
Bá a ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wàásù jákèjádò ayé
4. Iṣẹ́ wo làwa èèyàn Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe, kí ló sì lè mú ká ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí?
4 Jèhófà ti gbé iṣẹ́ lé wa lọ́wọ́ pé ká wàásù “ìhìn rere” fún gbogbo èèyàn jákèjádò ayé kí òpin tó dé. Iṣẹ́ bàǹtà-banta lèyí! (Mátíù 24:14; 28:19, 20) A gbọ́dọ̀ ké sí àwọn “tí òùngbẹ ń gbẹ” pé kí wọ́n wá mu “omi ìyè,” ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ fi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ àwọn tó fẹ́ lóye rẹ̀. (Ìṣípayá 22:17) Àmọ́ tá a bá wà “ní ìṣọ̀kan,” tá a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nìkan la lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyọrí.—Éfésù 4:16.
5, 6. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó fi hàn pé a wà níṣọ̀kan?
5 Ká tó lè wàásù kárí ayé, àfi ká wà létòlétò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Àwọn ìtọ́ni tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé wa sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè wà létòlétò. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń pàdé pọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá ká tó jáde lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. A tún máa ń fáwọn èèyàn ní àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Kódà, ọ̀kẹ́ àìmọye ìtẹ̀jáde yìí la ti pín fáwọn èèyàn kárí ayé. Nígbà míì, a máa ń gba ìtọ́ni pé ká kópa nínú àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù. Bó o ṣe ń kópa nínú àkànṣe iṣẹ́ yìí, ohun kan náà tí ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà kárí ayé ń ṣe nìwọ náà ń ṣe! Yàtọ̀ síyẹn, o tún ń bá àwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́ torí pé àwọn ló ń ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere.—Ìṣípayá 14:6.
6 Kò sí àní-àní pé inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá ń ka ìròyìn nípa iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé nínú Ìwé Ọdọọdún wa. Tún ronú nípa bí gbogbo wa jákèjádò ayé ṣe máa ń ké sí àwọn èèyàn wá sí àwọn àpéjọ wa. Ìtọ́ni kan náà ni gbogbo wa jákèjádò ayé máa ń rí gbà láwọn àpéjọ yìí. Àwọn àsọyé tá à ń gbọ́, àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn àṣefihàn tá à ń wò láwọn àpéjọ yìí ń mú ká túbọ̀ máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, àwa àtàwọn ará wa jákèjádò ayé máa ń pàdé pọ̀ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún. (1 Kọ́ríńtì 11:23-26) A máa ń pàdé pọ̀ lọ́jọ́ kan náà, ìyẹn Nísàn 14, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀, ká lè pa àṣẹ Jésù mọ́ ká sì tún fi hàn pé a mọ rírì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa. Tó bá sì ku ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan ká ṣe Ìrántí Ikú Kristi, a jùmọ̀ máa ń ké sí àwọn èèyàn wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì náà.
7. Kí ni bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ti yọrí sí?
7 Eéṣú kan ṣoṣo ò lè dá pitú tí ọ̀wọ́ àwọn eéṣú lè pa. Ẹnì kan ṣoṣo ò sì lè dá wàásù fún gbogbo èèyàn. Àmọ́ torí pé gbogbo wa ń pawọ́ pọ̀ ṣe iṣẹ́ yìí, a ti sọ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn nípa Jèhófà káwọn náà lè máa fi ìyìn àti ọlá fún un.
MÁA FỌWỌ́ SOWỌ́ PỌ̀ NÍNÚ ÌJỌ
8, 9. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù fi ṣàpèjúwe bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn Kristẹni wà níṣọ̀kan? (b) Báwo la ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ìjọ?
8 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bá a ṣe ṣètò ìjọ fáwọn ará tó wà ní Éfésù, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n “dàgbà sókè nínú ohun gbogbo.” (Ka Éfésù 4:15, 16.) Pọ́ọ̀lù lo àwọn ẹ̀yà ara láti ṣe àpèjúwe pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan lè pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ kí gbogbo wọn lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ. Ó sọ pé gbogbo ẹ̀yà ara máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ “nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò.” Torí náà, kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe, yálà a jẹ́ ọmọdé àbí àgbàlagbà, yálà a ní ìlera tó dáa tàbí a jẹ́ aláìlera?
Báwo lo ṣe lè pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ?
9 Jésù yàn àwọn alàgbà láti máa múpò iwájú nínú ìjọ, ó sì fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa. (Hébérù 13:7, 17) Èyí kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Àmọ́, a lè bẹ Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́ni táwọn alàgbà ń fún wa. Tún ronú nípa àǹfààní tó máa ṣe ìjọ tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà. Ìjọ á wà ní ìṣọ̀kan, ìfẹ́ tá a ní síra wa nínú ìjọ á sì túbọ̀ lágbára.
10. Báwo làwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe ń pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
10 Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́, a sì mọyì gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń rí i dájú pé a ní àwọn ìtẹ̀jáde tó máa tó lò lóde ẹ̀rí, wọ́n sì máa ń fọ̀yàyà kí àwọn ẹni tuntun tó bá wá sípàdé. Wọ́n máa ń tún àwọn ohun tó bà jẹ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, wọ́n sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kó lè máa wà ní mímọ́ tónítóní. Bá a ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin yìí ń mú ká wà níṣọ̀kan, ó sì ń mú ká wà létòlétò bá a ṣe ń sin Jèhófà.—Fi wé Ìṣe 6:3-6.
11. Kí làwọn ọ̀dọ́ lè ṣe kí ìjọ lè wà níṣọ̀kan?
11 Ọjọ́ pẹ́ táwọn alàgbà kan ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun nínú ìjọ. Àmọ́, bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí i, wọ́n lè má lè ṣe tó bí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ lè ṣèrànwọ́. Tí wọ́n bá fún àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ yìí ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, wọ́n lè máa ṣe àwọn iṣẹ́ púpọ̀ sí i nínú ìjọ, tó bá sì yá, àwọn náà lè tóótun láti di alàgbà. (1 Tímótì 3:1, 10) Àwọn ọ̀dọ́ kan tó ti di alàgbà tiẹ̀ tún ti ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì. Àwọn kan lára wọn ti di alábòójútó àyíká, wọ́n sì ń ran ọ̀pọ̀ ìjọ lọ́wọ́. Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá rí àwọn ọ̀dọ́ tó ṣe tán láti máa ṣiṣẹ́ sin àwọn ará.—Ka Sáàmù 110:3; Oníwàásù 12:1.
MÁA FỌWỌ́ SOWỌ́ PỌ̀ NÍNÚ ÌDÍLÉ
12, 13. Kí ló lè mú kí ìdílé túbọ̀ ṣera wọn lọ́kan?
12 Kí ló lè mú ká túbọ̀ ṣera wa lọ́kan nínú ìdílé wa? Ìjọsìn Ìdílé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́. Táwọn òbí àtàwọn ọmọ bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn á máa lágbára sí i. Nígbà Ìjọsìn Ìdílé, wọ́n lè jọ múra ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa sọ lóde ẹ̀rí, èyí á sì jẹ́ kí gbogbo wọn wà ní ìmúrasílẹ̀ dáadáa. Bí wọ́n ṣe jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀, tí wọ́n sì rí i pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ló nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì fẹ́ máa múnú rẹ̀ dùn, wọ́n á túbọ̀ ṣera wọn lọ́kan.
Bí tọkọtaya bá jọ ń sin Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n á ṣera wọn lọ́kan, ayé wọn á sì dùn bí oyin
13 Báwo ni tọkọtaya ṣe lè ṣera wọn lọ́kan? (Mátíù 19:6) Táwọn méjèèjì bá jọ ń sin Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n á ṣera wọn lọ́kan, ayé wọn á sì dùn bí oyin. Ó tún yẹ kí wọ́n máa fìfẹ́ hàn síra wọn, kí wọ́n fìwà jọ àwọn tọkọtaya bí Ábúráhámù àti Sárà, Ísákì àti Rèbékà àti Ẹlikénà àti Hánà. (Jẹ́nẹ́sísì 26:8; 1 Sámúẹ́lì 1:5, 8; 1 Pétérù 3:5, 6) Bí tọkọtaya bá ń ṣe báyìí, wọ́n á ṣera wọn lọ́kan, wọ́n á sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—Ka Oníwàásù 4:12.
14. Bí ọkọ tàbí aya rẹ kì í bá ṣe Ẹlẹ́rìí, kí lo lè ṣe kí ìgbéyàwó yín má bàa tú ká?
14 Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé a kò gbọ́dọ̀ fẹ́ ẹni tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 6:14) Síbẹ̀, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan wà tí ọkọ tàbí aya wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn táwọn kan ti ṣègbéyàwó ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ọkọ tàbí aya wọn ò sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sì lè jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn kan fẹ́, àmọ́ kí ọkọ tàbí aya wọn fi ètò Jèhófà sílẹ̀ nígbà tó yá. Tọ́rọ̀ bá rí báyìí, irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, wọ́n sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti rí i dájú pé okùn ìfẹ́ tó wà láàárín wọn ò já. Èyí lè má fìgbà gbogbo rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, Mary àti ọkọ ẹ̀ David jọ ń sin Jèhófà ni. Àmọ́ nígbà tó yá, David ò lọ sípàdé mọ́. Síbẹ̀, Mary ṣì ń ṣe àwọn ohun tó yẹ kí aya rere máa ṣe, ó sì ń hùwà tó yẹ kí Kristẹni máa hù. Ó tún kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kì í sì í pa ìpàdé àtàwọn àpéjọ jẹ. Kódà, lẹ́yìn táwọn ọmọ náà dàgbà tí wọ́n sì kúrò nílé, Mary ṣì ń sin Jèhófà nìṣó, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan túbọ̀ nira fún un nígbà yẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, David bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé ìròyìn tí Mary ń fún un. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọmọ ọmọ ẹ̀ tí ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́fà lọ máa ń bá a gbàyè sílẹ̀ nípàdé, tí David ò bá sì wá, ó máa ń dun ọmọ náà gan-an, tó bá wá pa dà délé, á sọ fún David pé, “Ó dùn mí gan-an pé mi ò rí yín nípàdé lónìí.” Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lẹ́yìn tí David fi ètò sílẹ̀ ló tó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, inú òun àtìyàwó ẹ̀ sì wá ń dùn gan-an báyìí pé àwọn tún jọ ń sin Jèhófà báwọn ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.
15. Báwo làwọn tó ti ṣègbéyàwó tipẹ́ ṣe lè ran àwọn tí ò tíì pẹ́ tí wọ́n ṣègbéyàwó lọ́wọ́?
15 Ṣe ni Sátánì ń gbógun ti ìdílé lónìí. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwọn tọkọtaya tó ń sin Jèhófà ṣera wọn lọ́kan. Bó ti wù kó pẹ́ tó tẹ́ ẹ ti ṣègbéyàwó, máa ronú àwọn ọ̀rọ̀ tó o lè sọ tàbí àwọn ohun tó o lè ṣe táá mú kí ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní síra yín máa lágbára sí i. Tó bá ti pẹ́ tẹ́ ẹ ti ṣègbéyàwó, ẹ lè jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn tí ò tíì pẹ́ tí wọ́n ṣègbéyàwó. Ẹ lè pè wọ́n wá sílé yín nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín. Àpẹẹrẹ rere yín á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bó ti wù kó pẹ́ tó tí tọkọtaya kan ti ń bára wọn bọ̀, wọ́n ṣì gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn síra wọn, kí wọ́n sì ṣera wọn lọ́kan.—Títù 2:3-7.
‘Ẹ JẸ́ KÍ A GÒKÈ LỌ SÍ ÒKÈ ŃLÁ JÈHÓFÀ’
16, 17. Kí làwa èèyàn Jèhófà ń retí?
16 Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń lọ síbi àjọyọ̀ ọdọọdún tí wọ́n máa ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Wọ́n á kó gbogbo ohun tí wọ́n nílò dání, wọ́n á jọ gbéra ìrìn-àjò, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ títí tí wọ́n á fi débẹ̀. Tí wọ́n bá sì dé tẹ́ńpìlì, wọ́n á jọ sin Jèhófà, wọ́n á sì jùmọ̀ fìyìn fún un. (Lúùkù 2:41-44) Bí àwa náà ṣe ń retí àtigbé nínú ayé tuntun, a gbọ́dọ̀ ṣera wa lọ́kan ká sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa. Ǹjẹ́ o lè ronú ọ̀nà tó o lè gbà ṣe dáadáa sí i lórí kókó yìí?
17 Èrò àwọn èèyàn ò ṣọ̀kan láyé tá a wà yìí, àwọn ohun tí ò tó nǹkan ló sì máa ń dá ìjà sílẹ̀ láàárín wọn. Àmọ́ à ń dúpẹ́ pé Jèhófà ti jẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín wa, ó sì tún jẹ́ ká lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀! Àwọn èèyàn rẹ̀ jákèjádò ayé ń sìn ín lọ́nà tó fẹ́. Pàápàá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn èèyàn Jèhófà ti wá wà níṣọ̀kan ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Bí Aísáyà àti Míkà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ lọ̀rọ̀ náà rí, a jùmọ̀ ń gòkè lọ sí “òkè ńlá Jèhófà.” (Aísáyà 2:2-4; ka Míkà 4:2-4.) Ẹ sì wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tí gbogbo àwọn táá máa gbé lórí ilẹ̀ ayé á ‘so pọ̀ ní ìṣọ̀kan,’ tí gbogbo wọn á sì jọ máa sin Jèhófà!