Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tóò, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ́ lé e wọ̀nyí:
• Orí mélòó ni ìwé Míkà ní, ìgbà wo la kọ ọ́, báwo sì ni ipò nǹkan ṣe rí lákòókò yẹn?
Orí méje ni ìwé Míkà ní. Wòlíì Míkà kọ ìwé náà ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, lákòókò tí àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú pín sí orílẹ̀-èdè méjì, ìyẹn Ísírẹ́lì àti Júdà.—8/15, ojú ìwé 9.
• Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Míkà 6:8, kí ni Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe?
A gbọ́dọ̀ “ṣe ìdájọ́ òdodo.” Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣe nǹkan tirẹ̀ ni ọ̀pá tá a ó fi díwọ̀n ìdájọ́ òdodo, nítorí náà a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó gbé kalẹ̀, ìyẹn ni àìlábòsí àti pípa ìwà títọ́ mọ́. Ó sọ fún wa pé ká “nífẹ̀ẹ́ inú rere.” Àwọn Kristẹni ti fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn nípa bí wọ́n ṣe ń pèsè fún àìní àwọn ẹlòmíràn, bí irú ohun tí wọ́n máa ń ṣe lẹ́yìn tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀. Ká tó lè di “ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá” Jèhófà rìn, a gbọ́dọ̀ mọ ibi tí agbára wa mọ ká sì gbára lé Ọlọ́run.—8/15, ojú ìwé 20-22.
• Bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ Kristẹni kan, kí ló lè ṣe?
Yóò jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu kí irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ tún ọ̀nà tó ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ yẹ̀ wò. Ó lè dín bó ṣe ń náwó kù nípa kíkó lọ sí ilé tí owó rẹ̀ kò tó ti èyí tó ń gbé tẹ́lẹ̀ tàbí kó wa nǹkan ṣe sí àwọn dúkìá tí kò pọn dandan. Dájúdájú, ó ṣe pàtàkì láti dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa àwọn ohun tá a nílò lójoojúmọ́, gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run lè mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí. (Mátíù 6:33, 34)—9/1, ojú ìwé 14-15.
• Kí la gbọ́dọ̀ rántí nígbà tá a bá ń fúnni lẹ́bùn ìgbéyàwó tàbí nígbà tá a bá ń gbà á?
A ò ní láti ra ẹ̀bùn olówó gọbọi, bẹ́ẹ̀ làwa náà ò sì gbọ́dọ̀ retí pe káwọn èèyàn rà á fún wa. Ohun tí ẹni tó ń fúnni ní nǹkan náà ní lọ́kàn gan-an ló ṣeyebíye jù lọ. (Lúùkù 21:1-4) Kó dára ká máa dárúkọ ẹni tó mú ẹ̀bùn wá. Irú àṣà bẹ́ẹ̀ lè kó ìtìjú bá àwọn èèyàn. (Mátíù 6:3)—9/1, ojú ìwé 29.
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà láìdabọ̀?
Gbígbàdúrà déédéé lè jẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i kó sì mú wa gbára dì láti kojú àwọn àdánwò líle koko. A lè gbàdúrà tó ṣe ṣókí, a sì lè gba èyí tó gùn, ó sinmi lórí bí nǹkan ṣe rí àti ipò tá a bá wà. Àdúrà ń mú kí ìgbàgbọ́ lágbára sí i, ó sì ń ranni lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro.—9/15, ojú ìwé 15-18.
• Báwo ló ṣe yẹ ká lóye 1 Kọ́ríńtì 15:29, tí àwọn ẹ̀dà kan túmọ̀ sí “ṣíṣe batisí nítorí àwọn òkú”?
Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé a batisí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí a rì wọ́n bọmi sí ọ̀nà ìgbésí ayé tí yóò yọrí sí ikú tó dà bíi ti Kristi ní ti pé wọ́n á kú nítorí pé wọ́n pa ìwà títọ́ mọ́. Lẹ́yìn náà, à ó jí wọn dìde sí ìyè tẹ̀mí bíi ti Kristi.—10/1, ojú ìwé 29.
• Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹni tó fẹ́ di Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe kọjá wíwulẹ̀ máa yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a mẹ́nu kan nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9-11?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ sórí mímẹ́nukan kìkì irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bí àgbèrè, ìbọ̀rìṣà, àti ìmutípara nìkan. Láti fi hàn pé ó tún lè pọn dandan láti ṣe àwọn ìyípadà mìíràn, ó sọ ní ẹsẹ tí ó tẹ̀ lé e pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu fún mi; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní àǹfààní.”—10/15, ojú ìwé 18-19.
• Dárúkọ díẹ̀ nínú àwọn obìnrin ayé ìgbàanì tó múnú Ọlọ́run dùn?
Lára wọn ni Ṣífúrà àti Púà, ìyẹn àwọn agbẹ̀bí tí kò ṣègbọràn sí ohun tí Fáráò sọ pé kí wọ́n pa àwọn ọmọkùnrin jòjòló tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bí. (Ẹ́kísódù 1:15-20) Ráhábù, tó jẹ́ kárùwà ọmọ Kénáánì dáàbò bo àwọn amí méjì tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì. (Jóṣúà 2:1-13; 6:22, 23) Nítorí làákàyè tí Ábígẹ́lì lò, ó ṣèrànwọ́ láti gba ẹ̀mí là, kò sì jẹ́ kí Dáfídì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 25:2-35) Wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn obìnrin òde òní.—11/1, ojú ìwé 8-11.
• Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ pé “àwọn ìràwọ̀” bá Sísérà “jà láti ọ̀run,” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Àwọn Onídàájọ́ 5:20?
Àwọn kan wò ọ̀rọ̀ yìí bí ìrànlọ́wọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn mìíràn sọ pé ìrànlọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì ni, àwọn kan sọ pé ìpẹ́pẹ́ ìràwọ̀ ló já bọ́ látọ̀run tàbí kó jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ àwọn awòràwọ̀ tí Sísérà gbójú lé ni. Níwọ̀n ìgbà tí Bíbélì kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀, a lè lóye rẹ̀ sí pé Ọlọ́run sáà jà fún àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì lọ́nà kan ṣá.—11/15, ojú ìwé 30.
• Pẹ̀lú bí ẹ̀mí ìdágunlá àti àìka ìsìn sí ṣe gbòde kan, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì fi ń sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́?
Àwọn kan ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kí wọ́n lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Àwọn mìíràn ń lọ nítorí àtirí ìyè ayérayé gbà lẹ́yìn ikú, tàbí nítorí àtiní ìlera, ọlà, àti àṣeyọrí. Àwọn àgbègbè kan wà táwọn èèyàn ibẹ̀ ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nítorí àtipadà sí ipò tẹ̀mí tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ rí kí ìjọba oníṣòwò bòńbàtà tó rọ́pò ìjọba Àjùmọ̀ní. Mímọ àwọn ohun tó ń mú káwọn èèyàn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti mọ bí òun á ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó nítumọ̀ nígbà tó bá ń wàásù.—12/1, ojú ìwé 3.