“Máà Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Kí Ó Dẹ̀”
“Máà jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀. Oluwa Ọlọrun rẹ ni agbára ní àárín rẹ; yóò gbani là.”—SEFANIAH 3:16, 17.
1. Kí ni ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú Bibeli sọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah?
À SỌTẸ́LẸ̀ Sefaniah nasẹ̀ kọjá ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní àwọn ọ̀rúndún ìkeje àti ìkẹfà ṣáájú Sańmánì Tiwa. Nínú àlàyé rẹ̀ lórí Sefaniah, Ọ̀jọ̀gbọ́n C. F. Keil kọ̀wé pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah . . . kò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kìkì ìkéde ìdájọ́ gbogbogbòò lórí gbogbo ayé, nínú èyí tí ìdájọ́ náà tí yóò ṣẹlẹ̀ sórí Juda nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti jẹ yọ, àti sórí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè nítorí ìwà ibi rẹ̀ sí àwọn ènìyàn Jehofa; ṣùgbọ́n ó ṣàlàyé ọjọ́ ńlá bíbani lẹ́rù ti Jehofa láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.”
2. Àwọn ìjọra wo ni ó wà láàárín ipò tí ó wà ní ọjọ́ Sefaniah àti ipò tí ó wà nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù lónìí?
2 Lónìí, ìpinnu ìdájọ́ Jehofa ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ fún ìparun ní ìwọ̀n tí ó ga ju ti ọjọ́ Sefaniah lọ. (Sefaniah 3:8) Ní pàtàkì, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ Kristian jẹ̀bi lójú Ọlọrun. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jerusalemu ṣe jìyà tí ó sì jewé iyá nítorí àìṣòótọ́ rẹ̀ sí Jehofa, bẹ́ẹ̀ náà ni Kirisẹ́ńdọ̀mù yóò ṣe dáhùn níwájú Ọlọrun fún àwọn ọ̀nà àìbìkítà rẹ̀ fún ìlànà títọ́. Ìdájọ́ àtọ̀runwá tí a kéde lòdì sí Juda àti Jerusalemu ní ọjọ́ Sefaniah bá àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti ẹ̀ya ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù mu lọ́nà tí ó túbọ̀ lágbára. Àwọn pẹ̀lú ti kó àbàwọ́n bá ìjọsìn mímọ́ gaara nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ wọn tí kò bọlá fún Ọlọrun, èyí tí púpọ̀ nínú rẹ̀ pilẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí. Wọ́n ti fi àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn onílera rúbọ lórí pẹpẹ ogun ti òde òní. Síwájú sí i, àwọn olùgbé Jerusalemu amápẹẹrẹṣẹ da ohun tí a fẹnu lásán pè ní ìsìn Kristian pọ̀ mọ́ ìwòràwọ̀, àṣà ìbẹ́mìílò, àti ìwà pálapàla takọtabo tí ń rẹni nípò wálẹ̀, tí ń ránni létí ìjọsìn Baali.—Sefaniah 1:4, 5.
3. Kí ni a lè sọ nípa àwọn aṣáájú ayé àti ìjọba olóṣèlú lónìí, kí sì ni Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?
3 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn aṣáájú òṣèlú Kirisẹ́ńdọ̀mù ń fẹ́ ipò ọlá nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ṣùgbọ́n bí “àwọn olórí” Juda, púpọ̀ lára wọn ń kò àwọn ènìyàn nífà bíi “kìnnìún tí ń ké ramúramù” àti apanijẹ “ìkòokò.” (Sefaniah 3:1-3) Àwọn ẹrú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ti òṣèlú “ń fi ìwà ipá òun ẹ̀tàn kún ilé oluwa wọn.” (Sefaniah 1:9) Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ìwà ìpá wọ́pọ̀. Ní ti ìjọba òṣèlú nínú àti lẹ́yìn òde Kirisẹ́ńdọ̀mù, iye tí ń pọ̀ sí i nínú wọn ‘ń gbé ara wọn ga’ sí àwọn ènìyàn Jehofa àwọn ọmọ ogun, àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, ní bíbá wọn lò gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀ya ìsìn” tí a tẹ́ḿbẹ́lú. (Sefaniah 2:8; Ìṣe 24:5, 14) Ní ti gbogbo irú àwọn aṣáájú òṣèlú bẹ́ẹ̀ àti àwọn ọmọlẹ́yìn wọn, Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kì yóò lè gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú Oluwa: ṣùgbọ́n gbogbo ilẹ̀ náà ni a óò fi iná ìjowú rẹ̀ pa run: nítorí òun oò fi ìyára mú gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà kúrò.”—Sefaniah 1:18.
“A Óò Pa Yin Mọ́ Ní Ọjọ́ Ìbínú Oluwa”
4. Kí ni ó fi hàn pé àwọn olùlàájá yóò wà ní ọjọ́ ńlá Jehofa, ṣùgbọ́n kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe?
4 Kì í ṣe gbogbo olùgbé Juda ni a pa run ní ọ̀rúndún keje ṣáájú Sańmánì Tiwa. Bákan náà, àwọn olùla ọjọ́ ńlá Jehofa já yóò wà. Jehofa tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Sefaniah sọ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Kí a tó pa àṣẹ náà, kí ọjọ́ náà tó kọjá bí ìyàngbò, kí gbígbóná ìbínú Oluwa tó dé bá a yín, kí ọjọ́ ìbínú Oluwa kí ó tó dé bá a yín. Ẹ wá Oluwa, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ayé, tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ẹ wá òdodo, ẹ wá ìwà pẹ̀lẹ́: bóyá a óò pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Oluwa.”—Sefaniah 2:2, 3.
5. Ní àkókò òpin yìí, àwọn wo ni wọ́n kọ́kọ́ kọbi ara sí ìkìlọ̀ Sefaniah, báwo sì ni Jehofa ṣe lò wọ́n?
5 Ní àkókò òpin ayé yìí, àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ kọbi ara sí ìkésíni alásọtẹ́lẹ̀ náà ni àṣẹ́kù àwọn ọmọ Israeli tẹ̀mí, àwọn Kristian ẹni àmì òróró. (Romu 2:28, 29; 9:6; Galatia 6:16) Níwọ̀n bí wọ́n ti wá òdodo àti ìwà tútù, tí wọ́n sì ti fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìpinnu ìdájọ́ Jehofa, a dá wọn nídè kúrò nínú Babiloni Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, a sì mú wọn padà bọ̀ sí ojú rere Ọlọrun ní 1919. Láti ìgbà náà, àti ní pàtàkì láti 1922, àṣẹ́kù olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ti ń fi àìbẹ̀rù pòkìkí ìdájọ́ Jehofa lòdì sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti ẹ̀ya ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù àti lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè òṣèlú.
6. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Sefaniah sọ nípa àṣẹ́kù olùṣòtítọ́ náà? (b) Báwo ni a ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ?
6 Nípa àṣẹ́kù olùṣòtítọ́ yìí, Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Èmi óò fi àwọn òtòṣì àti tálákà ènìyàn sílẹ̀ pẹ̀lú láàárín rẹ̀, wọn óò sì gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Oluwa. Àwọn ìyókù Israeli kì yóò hùwà ibi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ni ẹnu wọn: ṣùgbọ́n wọn óò jẹun wọn óò sì dùbúlẹ̀, ẹnì kan kì yóò sì dẹ́rù bà wọ́n.” (Sefaniah 3:12, 13) Àwọn Kristian ẹni àmì òróró wọ̀nyí ti fìgbà gbogbo fi orúkọ Jehofa sí ipò kíní, ṣùgbọ́n, wọ́n tí ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì láti 1931, nígbà tí wọ́n tẹ́wọ́ gba orúkọ náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. (Isaiah 43:10-12) Nípa títẹnu mọ́ ọ̀ràn àríyànjiyàn ti ipò ọba aláṣẹ Jehofa, wọ́n ti bọlá fún orúkọ àtọ̀runwá náà, èyí sì ti jẹ́ ibi ìsádi fún wọn. (Owe 18:10) Jehofa ti bọ́ wọn ní àbọ́yó nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ń gbé nínú paradise tẹ̀mí láìsí ìbẹ̀rù.—Sefaniah 3:16, 17.
“Orúkọ àti Ìyìn Láàárín Gbogbo Ènìyàn”
7, 8. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ míràn wo ni o tí ní ìmúṣẹ sórí àṣẹ́kù Israeli tẹ̀mí? (b) Kí ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti wá mọ̀, kí sì ni èrò rẹ nípa èyí?
7 A kò ṣàìkíyèsí ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ tí àṣẹ́kù náà ní pẹ̀lú orúkọ Jehofa àti pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ènìyàn olóòótọ́ ọkàn ti wá rí ìyàtọ̀ láàárín ìwà àsẹ́kù náà àti ìwà ìbàjẹ́ àti àgàbàgebè àwọn aṣáájú òṣèlú àti ti ìsìn ayé yìí. Jehofa ti bù kún “àwọn ìyókù Israeli [tẹ̀mí].” Ó ti fi àǹfààní jíjẹ́ orúkọ rẹ̀ dá wọn lọ́lá, ó sì ti mú kí wọ́n ní orúkọ rere láàárín àwọn ènìyàn orí ilẹ̀ ayé. Èyí rí gẹ́gẹ́ bí wòlíì Sefaniah ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé: “Nígbà náà ni èmi óò mú yin padà wá, àní ní àkókò náà ni èmi óò ṣà yín jọ: nítorí èmi óò fi orúkọ àti ìyìn fún yín láàárín gbogbo ènìyàn àgbáyé, nígbà tí èmi óò yí ìgbèkùn yín padà ní ojú yín, ni Oluwa wí.”—Sefaniah 3:20.
8 Láti 1935, ní ti gidi, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti wá mọ̀ pé ìbùkún Jehofa wà lórí àṣẹ́kù náà. Wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ tẹ̀ lé àwọn Júù, tàbí Israeli tẹ̀mí wọ̀nyí, ní sísọ pé: “A óò bá ọ lọ, nítorí àwa ti gbọ́ pé, Ọlọrun wà pẹ̀lú rẹ.” (Sekariah 8:23) “Awọn àgùtàn mìíràn” wọ̀nyí tẹ́wọ́ gba àṣẹ́kù ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” tí Kristi yàn sípò “lórí gbogbo awọn nǹkan ìní rẹ̀ [ti orí ilẹ̀ ayé].” Wọ́n fi tìmooretìmoore ṣàjọpín oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹgbẹ́ ẹrú náà ń pèsè “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu.”—Johannu 10:16; Matteu 24:45-47.
9. “Èdè” wo ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti kọ́ láti sọ, inú iṣẹ́ ńláǹlà wo sì ni àwọn àgùntàn míràn ti ń ṣiṣẹ́ sìn “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú àṣẹ́kù ẹni àmì òróró?
9 Ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àṣẹ́kù náà, àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti àwọn àgùntàn míràn wọ̀nyí ń kọ́ láti gbé ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú “èdè mímọ́ gaara” náà, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀.a Jehofa tipasẹ̀ Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Nígbà náà ni èmi óò yí èdè mímọ́ gaara sí àwọn ènìyàn, kí gbogbo wọn lè máa ké pe orúkọ Jehofa, láti lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sefaniah 3:9, NW) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn àgùntàn míràn ń fi ìṣọ̀kan ṣiṣẹ́ sin Jehofa “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà ẹni àmì òróró ti “agbo kékeré” nínú iṣẹ́ kánjúkánjú ti wíwàásù “ìhìnrere ìjọba yii . . . lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.”—Luku 12:32; Matteu 24:14.
“Ọjọ́ Jehofa Yóò Dé”
10. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, kí ni a ti mú dá àṣẹ́kù ẹni àmì òróró lójú, kì sì ni wọn yóò wà láàyè láti rí?
10 Àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti fìgbà gbogbo fi ọ̀rọ̀ onímìísí tí aposteli Peteru sọ sọ́kàn pé: “Jehofa kò fi nǹkan falẹ̀ níti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí awọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fún yín nitori pé oun kò ní ìfẹ́-ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni parun ṣugbọn ó ní ìfẹ́-ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà. Síbẹ̀ ọjọ́ Jehofa yoo dé gẹ́gẹ́ bí olè.” (2 Peteru 3:9, 10) Àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ẹrú olùṣòtítọ́ kò tí ì fìgbà kankan ṣiyè méjì nípa dídé ọjọ́ Jehofa ní àkókò wa. Ọjọ́ ńlá yẹn yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọrun lòdì sí Kirisẹ́ńdọ̀mù, Jerusalemu amápẹẹrẹṣẹ, àti ìyókù Babiloni Ńlá.—Sefaniah 1:2-4; Ìṣípayá 17:1, 5; 19:1, 2.
11, 12. (a) Apá mìíràn wo nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah ni ó ti ní ìmúṣẹ sórí àṣẹ́kù náà? (b) Báwo ni àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti ṣe kọbi ara sí ipè náà pé, “Máà jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀”?
11 Inú àṣẹ́kù olùṣòtítọ́ náà dùn láti rì ìdáǹdè gbà kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí ti Babiloni Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, ní 1919. Wọ́n ti ní ìrírí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah pé: “Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni; kígbe, ìwọ Israeli; fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalemu. Oluwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọnnì kúrò, ó ti ti ọ̀tá rẹ̀ jáde: ọba Israeli, àní Oluwa, ń bẹ láàárín rẹ: ìwọ kì yóò sì rí ibi mọ́. Ní ọjọ́ náà a óò wí fún Jerusalemu pé, Ìwọ má bẹ̀rù: àti fún Sioni pé, Máà jẹ̀ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀. Oluwa Ọlọrun rẹ ni agbara ní àárín rẹ; yóò gbani là.”—Sefaniah 3:14-17.
12 Pẹ̀lú ìdánilójú àti ẹ̀rí jáǹtírẹrẹ pé Jehofa wà pẹ̀lú wọn, àṣẹ́kù ẹni àmì òróró náà ti tẹ̀ síwájú láìbẹ̀rù ní ṣíṣe iṣẹ́ àṣẹ tí Ọlọrun yàn fún wọn. Wọ́n ti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, wọ́n sì ti sọ ìdájọ́ Jehofa lòdì sí Kirisẹ́ńdọ̀mù, ìyókù Babiloni Ńlá, àti gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí ti Satani di mímọ̀. Láìka gbogbo ìṣòro sí, jálẹ̀ àwọn ẹ̀wádún láti 1919, wọ́n ti ṣègbọràn sí àṣẹ àtọ̀runwá náà pé: “Ìwọ má bẹ̀rù: àti fún Sioni pé, Máà jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dẹ̀.” Wọ́n kò dẹwọ́ wọn nínú pípín ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìwé àṣàrò kúkurú, ìwé ìròyìn, ìwé ńlá, àti ìwé pẹlẹbẹ tí ń kéde Ìjọba Jehofa. Wọ́n ti jẹ́ àpẹẹrẹ tí ń gbé ìgbàgbọ́ ró fún àwọn àgùntàn míràn, àwọn tí wọ́n ti ń rọ́ wá sí ọ̀dọ̀ wọn láti 1935.
“Máà Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Kí Ó Dẹ̀”
13, 14. (a) Èé ṣe tí àwọn Júù kan fi fà sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa, báwo sì ni èyí ṣe fara hàn? (b) Kí ni kì yóò bọ́gbọ́n mu fún wa láti ṣe, nínú iṣẹ́ wo sì ni kò yẹ kí a jẹ́ kí ọwọ́ wa dẹ̀?
13 Bí a ti ń “dúró de” ọjọ́ ńlá Jehofa, báwo ni a ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ gbígbéṣẹ́ gbà láti inú àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a ní láti ṣọ́ra kí a má ṣe dà bí àwọn Júù ọjọ́ Sefaniah tí wọ́n fà sẹ́yìn kúrò nínú títẹ̀ lé Jehofa nítorí pé, wọ́n ṣiyè méjì nípa ìsúnmọ́lé ọjọ́ Jehofa. Kò pọn dandan pé irú àwọn Júù bẹ́ẹ̀ fi iyè méjì wọn hàn ní gbangba, ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ wọn ṣí i payá pé wọn kò gbà gbọ́ ní tòótọ́ pé, ọjọ́ Jehofa kù sí dẹ̀dẹ̀. Wọ́n pọkàn pọ̀ sórí kíkó ọrọ̀ jọ dípò dídúró de Jehofa.—Sefaniah 1:12, 13; 3:8.
14 Kí í ṣe àkókò nìyí láti yọ̀ọ̀da fún iyè méjì láti ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà wa. Yóò jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu láti máa sún dídé ọjọ́ Jehofa síwájú nínú ọkàn-àyà wa. (2 Peteru 3:1-4, 10) A ní láti yẹra fún fífà sẹ́yìn kúrò nínú títẹ̀ lé Jehofa tàbí ‘jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dẹ̀’ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Èyí kan kí a má ṣe “dẹ ọwọ́” nínú bí a ṣe ń wàásù “ìhìnrere naa.”—Owe 10:4; Marku 13:10.
Gbígbógun ti Ìdágunlá
15. Kí ni ó lè mú kí a dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa, báwo sì ni a ṣe sọ èyí tẹ́lẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah?
15 Èkejì ni pé, a ní láti wà lójúfò sí ipa ìdarí tí ń sọni di aláìlágbára tí ìdágunlá ní. Ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé, àìbìkítà nípa ọ̀ràn tẹ̀mí lè di okùnfà ìrẹ̀wẹ̀sì láàárín àwọn kan nínú àwọn oníwàásù ìhìn rere náà. Irú ìdágunlá bẹ́ẹ̀ wáyé ní ọjọ́ Sefaniah. Jehofa tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ sọ pé: “Èmi óò . . . bẹ àwọn ènìyàn . . . tí ń wí ní ọkàn wọn pé, Oluwa kì yóò ṣe rere, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣe búburú [wò].” (Sefaniah 1:12) Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí àyọkà yìí nínú ìwé Cambridge Bible for Schools and Colleges, A. B. Davidson sọ pé, ó tọ́ka sí àwọn ènìyàn tí wọ́n ti “rì wọnú níní ìdágunlá tàbí kódà sínú àìnígbàgbọ́ pé agbára ajẹ̀dálọ kankan lè dá sí àlámọ̀rí aráyé.”
16. Báwo ni ipò ọkàn ọ̀pọ̀ mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe rí, ṣùgbọ́n ìṣírí wo ni Jehofa fún wa?
16 Ìdágunlá ni ìṣarasíhùwà tì ó gbalégbòde lónìí ní ibi púpọ̀ ní orí ilẹ̀ ayé, ní pàtàkì, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún. Àwọn mẹ́ḿbà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù pàápàá kò tilẹ̀ gbà gbọ́ pé, Jehofa Ọlọrun yóò dá sí àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn ní ọjọ́ wa. Wọ́n ṣá àwọn ìsapá wa láti mú ìhìn rere Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ wọn tì, yálà nípa rírẹ́rìn-ín tí ń fi iyè méjì hàn tàbí fífèsì gán-ín pé “N kò fẹ́ gbọ́!” Lábẹ́ irú àwọn ipò wọ̀nyí, lílo ìforítì nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà lè jẹ́ ìpènijà gidi. Ó ń dán ìfaradà wa wò. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah, Jehofa fún àwọn ènìyàn rẹ̀ olùṣòtítọ́ lókun, ní sísọ pé: “Máà jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀. Oluwa Ọlọrun rẹ ni agbára ní àárín rẹ; yóò gbani là, yóò yọ̀ ní orí rẹ fún ayọ̀; yóò sinmi nínú ìfẹ́ rẹ̀, yóò fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”—Sefaniah 3:16, 17.
17. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni ó yẹ kí àwọn ẹni tuntun láàárín àwọn àgùntàn míràn tẹ̀ lé, báwo sì ni?
17 Ó jẹ́ òkodoro òtítọ́ nínú ìtàn òde òní ti àwọn ènìyàn Jehofa pé, àṣẹ́kù náà, àti àwọn àgbàlagbà láàárín àwọn àgùntàn míràn, ti ṣàṣeparí ìṣẹ́ bàǹtàbanta ti kíkóni jọ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Gbogbo àwọn Kristian olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ti lo ìfaradà jálẹ̀ àwọn ẹ̀wádún. Wọn kò yọ̀ọ̀da kí ìdágunlá níhà ọ̀dọ̀ àwọn tí ó pọ̀ jù lọ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Nítorí náà, ǹjẹ́ kí àwọn ẹni tuntun láàárín àwọn àgùntàn míràn náà má ṣe jẹ́ kí ìdágunlá sí ọ̀ràn tẹ̀mí tí ó gbalégbòde lónìí ní ilẹ̀ púpọ̀ mú wọn sọ̀rètí nù. Ǹjẹ́ kí wọn má ṣe yọ̀ọ̀da fún ‘ọwọ́ wọn láti dẹ̀,’ tàbí kí ó rọ. Ǹjẹ́ kí wọn lo gbogbo àǹfààní láti fi Ilé-Ìṣọ́nà, Jí!, àti àwọn ìtẹ̀jáde pípinminrin mìíràn lọni, èyí tí a mọ̀ọ́mọ̀ ṣe láti ran àwọn ẹni bí àgùntàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa ọjọ́ Jehofa àti àwọn ìbùkún tí yóò tẹ̀ lé e.
Ẹ Máa Tẹ̀ Síwájú Bí Ẹ Ti Ń Retí Ọjọ Ńlá Náà!
18, 19. (a) Ìṣírí wo láti lo ìfaradà ni a rí nínú Matteu 24:13 àti Isaiah 35:3, 4? (b) Báwo ni a óò ṣe bù kún wa bí a bá ń tẹ̀ síwájú níṣọ̀kan nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa?
18 Jesu sọ pé: “Ẹni tí ó bá faradà á dé òpin ni ẹni tí a óò gbàlà.” (Matteu 24:13) Nítorí náà, ẹ má ṣe fàyè gba “ọwọ́ aláìlera” tàbí “eékún àìlera” bí a ṣe ń retí ọjọ́ ńlá Jehofa! (Isaiah 35:3, 4) Lọ́nà tí ó fini lọ́kàn balẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah sọ nípa Jehofa pé: “Gẹ́gẹ́ bí Ẹni alágbára, yóò gbani là.” (Sefaniah 3:17, NW) Bẹ́ẹ̀ ni, Jehofa yóò gba “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà là, la apá ìkẹyìn “ìpọ́njú ńlá naa” jà, nígbà tí ó bá pàṣẹ fún Ọmọkùnrin rẹ̀ láti fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè òṣèlú tí wọ́n ń “gbe ara wọn ga sí” àwọn ènìyàn rẹ̀ túútúú.—Ìṣípayá 7:9, 14; Sefaniah 2:10, 11; Orin Dafidi 2:7-9.
19 Bí ọjọ́ ńlá Jehofa ti ń sún mọ́lé, ǹjẹ́ kí a máa tẹ̀ síwájú tìtaratìtara, ní ṣíṣiṣẹ́ sìn ín “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́”! (Sefaniah 3:9, NW) Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwa fúnra wa àti àwọn míràn tí kò níye yóò wà ní ipò àwọn tí a ‘óò pa mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Oluwa,’ tí a óò sì lè fojú rí ìsọdimímọ́ orúkọ mímọ́ rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìjíròrò lórí “èdè mímọ́gaara,” wo Ilé-Ìsọ́nà, April 1, 1991, ojú ìwé 20 sí 25, àti ti May 1, 1991, ojú ìwé 10 sí 20.
Ní Ṣíṣàtúnyẹ̀wò
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni ipò ìsìn láàárín Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ba ti ọjọ́ Sefaniah mu?
◻ Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú òṣèlú lónìí ṣe dà bí “àwọn olórí” ayé ní àkókò Sefaniah?
◻ Àwọn ìlérí wo nínú Sefaniah ni ó ti ní ìmúṣẹ lórí àṣẹ́kù náà?
◻ Kí ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti wá mọ̀?
◻ Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a jẹ́ kí ọwọ́ wa dẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gẹ́gẹ́ bíi Sefaniah, àṣẹ́kù olùṣòtítọ́ ti àwọn Kristian ẹni àmì òróró ti ń pòkìkí ìdájọ́ Jehofa láìbẹ̀rù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Awọn àgùtàn mìíràn” kò yọ̀ọ̀da fún ìdágunlá àwọn ènìyàn láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn