“Ẹ Dúró Dè Mí”
“Nítorí náà ẹ dúró dè mí, ni Oluwa wí.”—SEFANIAH 3:8.
1. Ìkìlọ̀ wo ni wòlíì Sefaniah ṣe, báwo sì ni èyí ṣe jẹ́ ohun tí ó fa àwọn ènìyàn tí ń gbé lónìí lọ́kàn mọ́ra?
“ỌJỌ́ ńlá Oluwa kù sí dẹ̀dẹ̀.” Wòlíì Sefaniah ni ó kígbe ìkìlọ̀ yìí ní àárín ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Tiwa. (Sefaniah 1:14) Láàárín 40 tàbí 50 ọdún, àsọtẹ́lẹ̀ náà ní ìmúṣẹ nígbà tí ọjọ́ ìmúdàájọ́ṣẹ Jehofa dé sórí Jerusalemu àti sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti pe ipò ọba aláṣẹ Jehofa níjà nípa fífìyà jẹ àwọn ènìyàn rẹ̀. Èé ṣe tí èyí fi jẹ́ ohun tí ó fa àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ìparí ọ̀rúndún ogún lọ́kàn mọ́ra? A ń gbé ní àkókò náà, nígbà tí “ọjọ́ ńlá” ìkẹyìn ti Jehofa ń yára sún mọ́lé. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní àkókò Sefaniah, “ìbínú . . . gbígbóná” Jehofa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé sórí alábàádọ́gba Jerusalemu ti òde òní—Kirisẹ́ńdọ̀mù—àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ń fìyà jẹ àwọn ènìyàn Jehofa, tí wọ́n sì ń pe ipò ọba aláṣẹ àgbáyé rẹ̀ níjà.—Sefaniah 1:4; 2:4, 8, 12, 13; 3:8; 2 Peteru 3:12, 13.
Sefaniah—Ẹlẹ́rìí Onígboyà
2, 3. (a) Kí ni a mọ̀ nípa Sefaniah, kí sì ni ó fi hàn pé ó jẹ́ ẹlẹ́rìí onígboyà fún Jehofa? (b) Àwọn òkodoro òtítọ́ wo ni ó mú kí a mọ àkókò àti ibi tí Sefaniah ti sọ àsọtẹ́lẹ̀?
2 A kò mọ púpọ̀ nípa wòlíì Sefaniah, ẹni tí orúkọ rẹ̀ (ní èdè Heberu, Tsephan·yahʹ) túmọ̀ sí “Jehofa Ti Pa Á Mọ́ (Ti Tọ́jú Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ohun Iyebíye).” Ṣùgbọ́n, ní ìyàtọ̀ gédégbé sí àwọn wòlíì míràn, Sefaniah fúnni ní ìtàn ìran rẹ̀ títí dé ìran kẹrin, padà sí ọ̀dọ̀ “Hesekiah.” (Sefaniah 1:1; fi wé Isaiah 1:1; Jeremiah 1:1; Esekieli 1:3.) Èyí ṣàjèjì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn alálàyé fi mọ̀ pé, Ọba Hesekiah olùṣòtítọ́ ni baba ńlá rẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé òun ni, yóò jẹ̀ pé Sefaniah wá láti ìdílé ọba, èyí yóò sì ti mú kí ìdálẹ́bi mímúná tí ó ṣe fún àwọn olórí Juda túbọ̀ nítumọ̀, yóò sì ti fi hàn pé ó jẹ́ ẹlẹ́rìí onígboyà àti wòlíì Jehofa. Ìmọ̀ kíkún rẹ́rẹ́ tí ó ní nípa àwòrán ilẹ̀ Jerusalemu àti ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ààfin ọba fi hàn pé, ó ti lè pòkìkí ìdájọ́ Jehofa nínú olú ìlú náà gan-an.—Wo Sefaniah 1:8-11, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References.
3 Ohun tí ó yẹ fún àfiyèsí ni òkodoro òtítọ́ náà pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sefaniah pòkìkí ìdájọ́ àtọ̀runwá lòdì sí “àwọn olórí” elétò ìlú Juda (àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí àwọn ìjòyè ẹ̀yà) àti “àwọn ọmọkùnrin ọba,” nínú lámèyítọ́ rẹ̀, kò fìgbà kankan mẹ́nu kan ọba náà fúnra rẹ̀.a (Sefaniah 1:8; 3:3, NW) Èyí fi hàn pé Ọba Josiah ọ̀dọ́ ti fi ìfẹ́ hàn tẹ́lẹ̀ fún ìjọsìn mímọ́ gaara, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, ní ojú ìwòye ipò tí Sefaniah lòdì sí, ó hàn gbangba pé kò tí ì bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe ìsìn. Gbogbo èyí fi hàn pé, Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Juda ní kùtùkùtù àwọn ọdún Josiah, ẹni tí ó ṣàkóso láti ọdún 659 sí 629 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Láìṣiyèméjì, bí Sefaniah ṣe fi tagbáratagbára sọ àsọtẹ́lẹ̀ túbọ̀ mú kí Josiah ọ̀dọ́ wà lójúfò sí ìbọ̀rìṣà, ìwà ipá, àti ìwà ìbàjẹ́ tí ó gbalégbòde ní Juda ní àkókò náà, ó sì fún ìgbétásì rẹ̀ ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn lòdì sí ìbọ̀rìṣà níṣìírí.—2 Kronika 34:1-3.
Àwọn Ìdí fún Ìbínú Gbígbóná Jehofa
4. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jehofa lò láti sọ ìbínú rẹ̀ sí Juda àti Jerusalemu jáde?
4 Jehofa ní ìdí rere láti bínú sí àwọn aṣáájú Juda àti àwọn olùgbé rẹ̀ pẹ̀lú olú ìlú náà Jerusalemu. Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Sefaniah, ó wí pé: “Èmi óò na ọwọ́ mi pẹ̀lú sórí Juda, àti sórí gbogbo ará Jerusalemu; èmi óò sì ké ìyókù Baali kúrò níhìn-ín yìí, àti orúkọ Kemarimu pẹ̀lú àwọn àlùfáà; àti àwọn tí ń sin ogun ọ̀run lórí òrùlé: àwọn tí ń sìn, tí ń fi Oluwa búra, tí sì ń fi Malkomu búra.”—Sefaniah 1:4, 5.
5, 6. (a) Báwo ni ipò nǹkan ti rí ní ti ìsìn ní Juda ní àkókò Sefaniah? (b) Báwo ni ipò àwọn elétò ìlú Juda àti àwọn ọmọ abẹ wọn ti rí?
5 A fi ààtò ìsìn àtirọ́mọbí tí ó rẹni nípò wálẹ̀ ti ìjọsìn Baali, ìwòràwọ̀ ẹlẹ́mìí Èṣù, àti ìjọsìn Malkomu ọlọrun kèfèrí, ba Juda jẹ́. Bí ó bá jẹ́ pé Malkomu ni Moleki, bí àwọn kan ṣe sọ, nígbà náà, ìjọsìn èké Juda ní ohun ìríra ti fífi ọmọ rúbọ nínú. Irú àwọn ìṣe ìjọsìn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun ìríra ní ojú Jehofa. (1 Awọn Ọba 11:5, 7; 14:23, 24; 2 Awọn Ọba 17:16, 17) Wọ́n túbọ́ ń mú ìbínú rẹ̀ wá sórí ara wọn, níwọ̀n bí àwọn abọ̀rìṣà náà ṣì ń fi orúkọ Jehofa búra. Òun kì yóò fàyè gba irú ìwà àìmọ́ ní ti ìsìn bẹ́ẹ̀ mọ́, bákan náà ni yóò ké àwọn kèfèrí àti àlùfáà apẹ̀yìndà kúrò.
6 Ní àfikún sí i, àwọn elétò ìlú Juda bà jẹ́. Àwọn olórí rẹ̀ dà bí arebipa “kìnnìún tí ń ké ramúramù,” àwọn onídàájọ́ rẹ̀ ni a sì lè fi wé apanijẹ “ìkòokò.” (Sefaniah 3:3) A fi ẹ̀sùn ‘fífi ìwà ipá òun ẹ̀tàn kún ilé oluwa wọn’ kan àwọn òṣìṣẹ́ abẹ́ wọn. (Sefaniah 1:9) Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì wọ́pọ̀. Ọ̀pọ̀ ń lo àǹfààní ipò náà láti kó ọrọ̀ jọ.—Sefaniah 1:13.
Àwọn Iyè Méjì Nípa Ọjọ́ Jehofa
7. Báwo ni àkókò tí Sefaniah fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣáájú “ọjọ́ ńlá Oluwa” ṣe gùn tó, báwo sì ni ipò ọ̀pọ̀ àwọn Júù ṣe rí nípa tẹ̀mí?
7 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, ipò ìsìn oníjàm̀bá tí ó gbalégbòde ní ọjọ́ Sefaniah fi hàn pé, ó ṣe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí àti wòlíì ṣáájú kí Ọba Josiah tó bẹ̀rẹ̀ ìgbétásì rẹ̀ lòdì sí ìbọ̀rìṣà, ní nǹkan bí ọdún 648 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (2 Kronika 34:4, 5) Nígbà náà, ó ṣeé ṣe kí Sefaniah ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ó kéré tán 40 ọdún ṣáájú kí “ọjọ́ ńlá Oluwa” tó dé sórí ìjọba Juda. Ní àárín ìgbà náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ṣiyè méjì, wọ́n sì ‘fà sẹ́yìn’ kúrò nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa, wọ́n di ẹni tí ń dágunlá. Sefaniah sọ̀ nípa àwọn tí wọn “kò tí ì wá Oluwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.” (Sefaniah 1:6) Dájúdájú, olúkúlùkù tí ó wà ní Juda jẹ́ aláìbìkítà, wọn kò fi ọ̀ràn Ọlọrun yọ ara wọn lẹ́nu.
8, 9. (a) Èé ṣe tí Jehofa yóò fi bẹ “àwọn ènìyàn tí ó silẹ̀ sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn” wò? (b) Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa yóò gbà fún àwọn olùgbé Juda àti awọn elétò ìlú wọn pẹ̀lú àwọn aṣáájú ìsìn wọn ní àfiyèsí?
8 Jehofa sọ ète rẹ̀ láti bẹ àwọn tí ń sọ pé àwọn jẹ ènìyàn rẹ̀ wò di mímọ̀. Lára àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ olùjọsìn rẹ̀, òun yóò ṣàwárí àwọn tí ń ṣiyè méjì lọ́kàn wọn nípa agbára rẹ̀ tàbí èrò rẹ̀ láti dá sí àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn. Ó wí pé: “Yóò sì ṣe ní àkókò náà, ni èmi óò fi fìtílà wá Jerusalemu kiri, èmi óò sì bẹ àwọn ènìyàn tí ó silẹ̀ sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn wò: àwọn tí ń wí ní ọkàn wọn pé, Oluwa kì yóò ṣe rere, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣe búburú.” (Sefaniah 1:12) Gbólóhùn náà “àwọn ènìyàn tí ó silẹ̀ sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn” (tí ń tọ́ka sí ṣíṣe wáìnì) ń tọ́ka sí àwọn tí wọ́n ti silẹ̀, bíi gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ìkòkò ńlá, tí wọn kò sì fẹ́ ìyọlẹ́nu nípa ìpòkìkí èyíkéyìí ti bí Ọlọrun yóò ṣe dá sí àlámọ̀rí aráyé ṣe ń sún mọ́lé.
9 Jehofa yóò fún àwọn olùgbé Juda àti Jerusalemu pẹ̀lú àwọn àlùfáà wọn tí wọ́n ti da ìjọsìn rẹ̀ pọ̀ mọ́ ìbọ̀rìṣà ní àfiyèsí. Bí wọ́n bá rò pé kò séwu, bí ẹni pé wọ́n wà lábẹ́ òkùnkùn alẹ́ láàárín ògiri Jerusalemu, òun yóò wá wọn jáde bí ẹní gbé fìtílà tí ó mọ́lẹ̀ dání, tí yóò tàn sí òkùnkùn nípa tẹ̀mí níbi tí wọ́n fara pamọ́ sí. Òun yóò ru àìbìkítà wọn ní ti ìsìn sókè, lákọ̀ọ́kọ́ nípasẹ̀ àwọn ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, lẹ́yìn náà nípa mímú àwọn ìdájọ́ wọ̀nyẹn ṣẹ.
“Ọjọ́ Ńlá Oluwa Kù Sí Dẹ̀dẹ̀”
10. Báwo ni Sefaniah ṣe ṣàpèjúwe “ọjọ́ ńlá Oluwa”?
10 Jehofa mí sí Sefaniah láti pòkìkí pé: “Ọjọ́ ńlá Oluwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀, ó sì ń yára kánkán, [ohùn burúkú ni, NW] ohùn ọjọ́ Oluwa.” (Sefaniah 1:14) Ní tòótọ́ ọjọ́ burúkú wà níwájú fún olúkúlùkù—àwọn àlùfáà, àwọn olórí, àti àwọn ènìyàn—tí wọ́n kọ̀ láti kọbi ara sí ìkìlọ̀, kí wọ́n sì padà sí ìjọsìn mímọ́ gaara. Ní ṣíṣàpèjúwe ọjọ́ ìmúdàájọ́ṣẹ náà, àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Ọjọ́ náà ọjọ́ ìbínú ni, ọjọ́ ìyọnu, àti ìpọ́njú, ọjọ́ òfò àti ìdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti òkúdu, ọjọ́ kùukùu àti òkùnkùn biribiri, ọjọ́ ipè àti ìdágìrì sí ìlú olódi wọnnì àti sí ìṣọ́ gíga wọnnì.”—Sefaniah 1:15, 16.
11, 12. (a) Ìhìn ìṣẹ́ ìdájọ́ wo ni a kéde lòdì sí Jerusalemu? (b) Aásìkí ọrọ̀ àlùmọ́nì yóò ha gba àwọn Júù là bí?
11 Láàárín àwọn ẹ̀wádún díẹ̀, àwọn ọmọ ogun Babiloni yóò gbógun ti Juda. Jerusalemu kí yóò yè bọ́. A óò sọ agbègbè ibùgbé àti ti káràkátà rẹ̀ di ahoro. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ni Oluwa wí, ohùn ẹkún yóò ti ìhà bodè ẹja wá, àti híhu láti ìhà kejì wá, àti ìró ńlá láti òkè kéékèèké wọnnì wá. Hu, ẹ̀yin ara Maktẹsi [apá kan Jerusalemu], nítorí pé gbogbo ènìyàn oníṣòwò ni a ti ké lu ilẹ̀; gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ru fàdákà ni a ké kúrò.”—Sefaniah 1:10, 11, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References.
12 Ní kíkọ̀ láti gbà gbọ́ pé ọjọ́ Jehofa kù sí dẹ̀dẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Júù kó wọnú iṣẹ́ ajé tí ń mówó wọlé. Ṣùgbọ́n, nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ olùṣòtítọ́, Sefaniah, Jehofa sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, ọrọ̀ wọn yóò jẹ́ “ìkógun, àti ilẹ̀ wọn yóò di ahoro.” Wọn kì yóò mu wáìnì tí wọ́n pọn, bẹ́ẹ̀ sì ni “fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kì yóò lè gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú Oluwa.”—Sefaniah 1:13, 18.
A Ṣe Ìdájọ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Míràn
13. Ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ wo ni Sefaniah kéde lòdì sí Moabu, Ammoni, àti Assiria?
13 Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Sefaniah, Jehofa tún fi ìbínú rẹ̀ hàn sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fìyà jẹ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó polongo pé: “Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu, àti ẹlẹ́yà àwọn ọmọ Ammoni, nípa èyí tí wọn ti kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn. Nítorí náà bí èmi ti wà, ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí, Ọlọrun Israeli, Dájúdájú Moabu yóò dà bíi Sodomu, àti àwọn ọmọ Ammoni bíi Gomorra, bíi títàn wèrèpè, àti bí ihò iyọ̀, àti ìdahoro títí láé . . . Òun óò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí ìhà àríwá, yóò sì pa Assiria run; yóò sì sọ Ninefe di ahoro, àti di gbígbẹ bí aginjù.”—Sefaniah 2:8, 9, 13.
14. Ẹ̀rí wo ní ó wà pé, àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì “gbé ara wọn ga” sí àwọn ọmọ Israeli àti Ọlọrun wọn, Jehofa?
14 Moabu àti Ammoni ti jẹ́ ọ̀tá Israeli tipẹ́tipẹ́. (Fi wé Onidajọ 3:12-14.) Òkúta Moabu, tí ó wà ní Ilé Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé ti Louvre ní Paris, ní àkọlé kan tí ó ní ọ̀rọ̀ ìfọ́nnu tí Ọba Meṣa ará Moabu sọ nínú. Ó fi ìgbéraga sọ bí òún ṣe ṣẹ́gun àwọn ìlú ńlá Israeli mélòó kan pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọlọrun rẹ̀ Kemoṣi. (2 Awọn Ọba 1:1) Jeremiah, alájọgbáyé Sefaniah, sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ará Ammoni ṣe gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Israeli ti Gadi ní orúkọ Malkomu ọlọrun wọn. (Jeremiah 49:1) Ní ti Assiria, Ọba Ṣalamaneseri Karùn-ún ti dó ti Samaria, ó sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ ní nǹkan bí ọ̀rúndún kan ṣáájú ọjọ́ Sefaniah. (2 Awọn Ọba 17:1-6) Kó pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, Ọba Sennakaribi kọlu Juda, ó ṣẹ́gun púpọ̀ nínú àwọn ìlú ńlá olódi rẹ̀, àní ó tilẹ̀ halẹ̀ mọ́ Jerusalemu. (Isaiah 36:1, 2) Ní tòótọ́, agbẹnusọ fún ọba Assiria gbéra ga sí Jehofa nígbà tí ó ń fi dandan gbọ̀n béèrè pé kí Jerusalemu túúbá.—Isaiah 36:4-20.
15. Báwo ni Jehofa yóò ṣe tẹ́ àwọn ọlọrun àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gbéra ga sí àwọn ènìyàn rẹ̀ lógo?
15 Orin Dafidi 83 mẹ́nu kan àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan, tí ó ní Moabu, Ammoni, àti Assiria nínú, tí ó gbéraga sí Israeli, tí ó sì fi tìhàlẹ̀tìhàlẹ̀ sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a ké wọn kúrò láti máa wà ní orílẹ̀-èdè; kí orúkọ Israeli kí ó má ṣe sí ní ìrántí mọ́.” (Orin Dafidi 83:4) Wòlíì náà Sefaniah fi tìgboyàtìgboyà kéde pé, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́kàn gíga wọ̀nyí àti àwọn ọlọrun wọn ni Jehofa àwọn ọmọ ogun yóò tẹ́ lógo. “Èyí ni wọn óò ní nítorí ìgbéraga wọn, nítorí pé wọ́n ti kẹ́gàn, wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí ènìyàn Oluwa àwọn ọmọ ogun. Oluwa yoo jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn: nítorí òun óò mú kí gbogbo òrìṣà ilẹ̀ ayé kí ó rù; ènìyàn yóò sì máà sìn ín, olúkúlùkù láti ipò rẹ̀ wá, àní gbogbo erékùṣù àwọn kèfèrí.”—Sefaniah 2:10, 11.
“Ẹ Dúró Dè Mí”
16. (a) Àwọn wo ni ìsúnmọ́lé ọjọ́ Jehofa jẹ́ orísun ayọ̀ fún, èé sì ti ṣe? (b) Àṣẹ wo ni ó lọ sọ́dọ̀ àwọn àṣẹ́kù olùṣòtítọ́ wọ̀nyí?
16 Níwọ̀n bí títòògbé nípa tẹ̀mí, ṣíṣiyè méjì, ìbọ̀rìṣà, ìwà ìbàjẹ́, àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ti wọ́pọ̀ láàárín àwọn aṣáájú Juda àti Jerusalemu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ olùgbé wọn, ó hàn gbangba pé, àwọn Júù olùṣòtítọ́ kan fetí sílẹ̀ sí àwọn ìkìlọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tí Sefaniah ṣe. Àwọn iṣẹ́ ìríra tí àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, àti àwọn àlùfáà Juda ń ṣe bà wọ́n lọ́kàn jẹ́. Ìkéde tí Sefaniah ṣe jẹ́ orísun ìtùnú fún àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí. Kàkà tí yóò fi fa làásìgbò, ìsúnmọ́lé ọjọ́ Jehofa jẹ́ orísun ayọ̀ fún wọn, nítorí pé, yóò mú irú àwọn ìṣe tí ń múni ṣe họ́ọ̀ bẹ́ẹ̀ wá sí òpin. Àwọn àṣẹ́kù olùṣòtítọ́ wọ̀nyí kọbi ara sí àṣẹ Jehofa pé: “Nítorí náà ẹ dúró dè mí, ni Oluwa wí, títí di ọjọ́ náà tí èmi óò dìde sí ohun ọdẹ: nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ, kí èmi kí ó lè kó àwọn ilẹ̀ ọba jọ, láti da ìrunú mi sí orí wọn, àní gbogbo ìbínú mi gbígbóná.”—Sefaniah 3:8.
17. Nígbà wo àti báwo ni ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ ti Sefaniah jẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè?
17 Kò bá àwọn tí wọ́n kọbi ara sí ìkìlọ̀ yẹn lójijì. Ọ̀pọ̀ fojú rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah. Ní ọdún 632 ṣáájú Sànmánì Tiwa, a ṣẹ́gun Ninefe, a sì pa á run nípasẹ̀ ìfohùnṣọ̀kan àwọn ará Babiloni, Media, àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tí wọ́n wá láti ìhà àríwá, tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ àwọn Skitiani. Òpìtàn, Will Durant sọ pé: “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Babiloni lábẹ́ Nabopolassar dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Media lábẹ́ Cyaxares àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Skitiani láti Caucasus, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ibi ìsádi ìhà àríwá pẹ̀lú ìrọ̀rùn yíyani lẹ́nu àti ìyára kánkán. . . . Lójijì Assiria di àwátì nínú ìtàn.” Ohun tí Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ gan-an nìyí.—Sefaniah 2:13-15.
18. (a) Báwo ni a ṣe mú ìdájọ́ àtọ̀runwá ṣẹ sórí Jerusalemu, èé sì ti ṣe? (b) Báwo ni a ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah nípa Moabu àti Ammoni ṣẹ?
18 Ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí wọ́n dúró de Jehofa tún fojú rí bí a ṣe mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Juda àti Jerusalemu. Nípa Jerusalemu, Sefaniah ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ègbé ni fún ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́, fún ìlú aninilára nì. Òun kò fetí sí ohùn náà; òun kò gba ẹ̀kọ́; òun kò gbẹ́kẹ̀ lé Oluwa; òun kò sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọrun rẹ̀.” (Sefaniah 3:1, 2) Nítorí àìṣòótọ́ rẹ̀, ìgbà méjì ni àwọn ará Babiloni dó ti Jerusalemu, nígbẹ́yìngbẹ́yín, wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀, wọ́n sì pa á run ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (2 Kronika 36:5, 6, 11-21) Ní ti Moabu àti Ammoni, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Júù nì, Josephus, ti sọ, ní ọdún karùn-ún, lẹ́yìn ìṣubú Jerusalemu, àwọn ará Babiloni gbé ogun dìde sí wọn, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Àṣẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n di àwátì, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.
19, 20. (a) Báwo ni Jehofa ṣe san ère fún àwọn tí wọ́n dúró dè é? (b) Èé ṣe tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí fi kàn wá, kí sì ni a oò gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé é?
19 Ìmúṣẹ àwọn wọ̀nyí àti àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míràn nípa àsọtẹ́lẹ̀ tí Sefaniah sọ jẹ́ ìrírí afúngbàgbọ́lókun fún àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù tí wọ́n dúró de Jehofa. Jeremiah, Ebedmeleki ará Etiopia, àti ilé Jonadabu, àwọn ọmọ Rekabu, wà lára àwọn tí wọ́n la ìparun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Juda àti Jerusalemu já. (Jeremiah 35:18, 19; 39:11, 12, 16-18) Àwọn Júù olùṣòtítọ́ tí wọ́n wà ní ìgbèkùn àti àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n ń bá a nìṣó láti dúró de Jehofa, di apá kan àṣẹ́kù aláyọ̀ tí a dá nídè kúrò ní Babiloni ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa, tí wọ́n sì padà sí Juda láti tún fìdí ìjọsìn mímọ́ gaara múlẹ̀.—Esra 2:1; Sefaniah 3:14, 15, 20.
20 Kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí fún àkókò wa? Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, bí ipò nǹkan ti rí ní ọjọ́ Sefaniah bá àwọn ohun tí ń múni ṣe họ́ọ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ lónìí ní Kirisẹ́ńdọ̀mù mu. Ní àfikún sí i, onírúurú ìṣarasíhùwà àwọn Júù ní àkókò yẹn bá àwọn ìṣarasíhùwà tí a lè rí lónìí mu, àní nígbà míràn láàárín àwọn ènìyàn Jehofa pàápàá. Àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Yóò dà bíi pé gbólóhùn náà, “àwọn ọmọkùnrin ọba,” ń tọ́ka sí gbogbo àwọn ọmọ aládé, níwọ̀n bí àwọn ọmọ Josiah fúnra rẹ̀ ṣì kéré ní àkókò náà.
Ní Ṣíṣàtúnyẹ̀wò
◻ Báwo ni ipò Juda ti rí ní ti ìsìn ní ọjọ́ Sefaniah?
◻ Ipò wo ni ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn elétò ìlú, kí sì ni ìṣarasíhùwà púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn náà?
◻ Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè ṣe gbéra ga sí àwọn ènìyàn Jehofa?
◻ Ìkìlọ̀ wo ni Sefaniah fún Juda àti àwọn orílẹ̀-èdè míràn?
◻ Báwo ni a ṣe san èrè fún àwọn tí wọ́n dúró de Jehofa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Òkúta Moabu fi hàn gbangba pé Ọba Meṣa ti Moabu sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Israeli ìgbàanì
[Credit Line]
Òkúta Moabu: Musée du Louvre, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ní títi àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah lẹ́yìn, wàláà tí a gbẹ́ ọ̀rọ̀ sí, ti Ìtàn Àwọn Ará Babiloni ṣàkọsílẹ̀ ìparun Ninefe nípasẹ̀ ìfohùnṣọ̀kan àwọn ọmọ ogun
[Credit Line]
Wàláà tí a gbẹ́ ọ̀rọ̀ sí: Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da ónínúure ti The British Museum