-
Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Wà Nínú ÌjọGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Wà Nínú Ìjọ
Inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ará wa. Bó sì ṣe rí lára Ọba Dáfídì nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Ó mà dára o, ó mà dùn o pé kí àwọn ará máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” (Sáàmù 133:1) Ohun kékeré kọ́ ló máa ń ná àwa èèyàn Jèhófà láti wà níṣọ̀kan. Torí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ní ohun tó yẹ kó ṣe ká lè túbọ̀ máa wà níṣọ̀kan.
1. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ láàárín àwa èèyàn Jèhófà?
Tó o bá lọ sípàdé lórílẹ̀-èdè míì, ó ṣeé ṣe kó o má gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ. Àmọ́ ó dájú pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ò ní ṣàjèjì sí ẹ, ara á tù ẹ́, ọkàn ẹ á sì balẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwé kan náà la fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé. A sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa fìfẹ́ hàn síra wa. Orílẹ̀-èdè yòówù ká máa gbé, gbogbo wa là ń ‘pe orúkọ Jèhófà, ká lè máa sìn ín ní ìṣọ̀kan.’—Sefanáyà 3:9.
2. Kí lo lè ṣe kí àlàáfíà lè wà nínú ìjọ?
“Ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara yín látọkàn wá.” (1 Pétérù 1:22) Báwo lo ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò? Dípò tí wàá fi máa wá ibi táwọn èèyàn kù sí, ibi tí wọ́n dáa sí ni kó o máa wò. Dípò tí wàá fi mú àwọn tẹ́ ẹ jọ mọwọ́ ara yín nìkan lọ́rẹ̀ẹ́, gbìyànjú láti túbọ̀ mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí èdè tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tìẹ. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò ara wa kó má lọ di pé a ti ń kórìíra àwọn tí ẹ̀yà tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa. Tá a bá sì rí i pé a ti ń kórìíra wọn, ká ṣàtúnṣe ní kíá.—Ka 1 Pétérù 2:17.a
3. Kí lo lè ṣe tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ìwọ àti Kristẹni míì?
Òótọ́ ni pé a wà níṣọ̀kan, síbẹ̀ ó yẹ ká máa rántí pé aláìpé ni gbogbo wa. Nígbà míì, a lè ṣẹ ara wa tàbí ká ṣe ohun tó dun àwọn ẹlòmíì. Torí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé “ẹ . . . máa dárí ji ara yín,” ó fi kún un pé: “Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.” (Ka Kólósè 3:13.) Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti ṣẹ Jèhófà tó sì ti dárí jì wá. Torí náà, ó fẹ́ káwa náà máa dárí ji ara wa. Tó o bá rí i pé o ti ṣẹ ẹnì kan, gbìyànjú láti lọ bá ẹni náà kẹ́ ẹ lè yanjú ọ̀rọ̀ náà.—Ka Mátíù 5:23, 24.b
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó o lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè túbọ̀ wà nínú ìjọ.
4. Gbìyànjú láti borí ẹ̀tanú
Ó máa ń wù wá láti nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Àmọ́, ó lè má rọrùn fún wa láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan tí èdè tàbí àṣà ẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́? Ka Ìṣe 10:34, 35, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Onírúurú èèyàn ni Jèhófà fún láǹfààní láti di Ẹlẹ́rìí òun. Kí ni àpẹẹrẹ Jèhófà kọ́ ẹ nípa bó ṣe yẹ kó o máa ṣe sí àwọn tí àṣà tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tìẹ?
Kí làwọn èèyàn tó wà ládùúgbò ẹ sábà máa ń ṣe láti fi hàn pé wọ́n kórìíra àwọn tí àṣà tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tiwọn? Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o máa hu irú ìwà bẹ́ẹ̀?
Ka 2 Kọ́ríńtì 6:11-13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn nǹkan wo lo rò pé o lè ṣe tó o bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará tí àṣà tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tìẹ?
5. Máa dárí jini ní fàlàlà, kó o sì máa wá àlàáfíà
Jèhófà kì í ṣẹ̀ wá, torí náà a ò nílò láti máa dárí jì í, síbẹ̀ ó máa ń dárí jì wá ní fàlàlà. Ka Sáàmù 86:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jini?
Báwo ló ṣe rí lára rẹ láti mọ̀ pé Jèhófà múra tán láti dárí jini?
Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó nira fún wa láti máa wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn?
Báwo la ṣe lè máa fara wé Jèhófà kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè máa wà láàárín àwa àtàwọn ará? Ka Òwe 19:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tí ẹnì kan bá múnú bí ẹ, kí ló yẹ kó o ṣe kó o lè yanjú ọ̀rọ̀ náà?
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń ṣẹ àwọn míì. Kí ló yẹ ká ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, àwọn nǹkan wo ni arábìnrin yẹn ṣe kó lè wá àlàáfíà?
6. Ibi táwọn ará dáa sí ni kó o máa wò
Bá a bá ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ àwọn ará, bẹ́ẹ̀ làá máa mọ ibi tí wọ́n dáa sí àti ibi tí wọ́n kù sí. Kí láá jẹ́ ká máa wo ibi táwọn ara dáa sí dípò ibi tí wọ́n kù sí? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí ló lè mú kó rọrùn fún ẹ láti máa wo ibi táwọn ará dáa sí?
Ibi tá a dáa sí ni Jèhófà máa ń wò. Ka 2 Kíróníkà 16:9a, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ló ṣe rí lára rẹ bó o ṣe mọ̀ pé ibi tó o dáa sí ni Jèhófà máa ń wò?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ẹni tó bá ṣẹ̀ mí gbọ́dọ̀ bẹ̀bẹ̀ kí n tó lè dárí jì í.”
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dárí ji àwọn èèyàn tí wọn ò bá tiẹ̀ tọrọ àforíjì?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tó o bá ń dárí ji àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tó o sì ń fìfẹ́ hàn sí wọn, ìyẹn á jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.
Kí lo rí kọ́?
Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa máa kórìíra àwọn èèyàn torí pé àṣà àti èdè wọn yàtọ̀ sí tìẹ?
Kí ni wàá ṣe tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ìwọ àti arákùnrin tàbí arábìnrin kan?
Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa dárí ji àwọn èèyàn ní fàlàlà bíi ti Jèhófà?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo fídíò yìí kó o lè rí àpèjúwe tí Jésù ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa máa dá àwọn míì lẹ́jọ́.
Tá a bá gbà pé a ò ṣẹ ẹnì kan, ṣé ó pọn dandan ká tọrọ àforíjì lọ́wọ́ onítọ̀hún?
“Títọrọ Àforíjì Ọ̀nà Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ Láti Wá Àlàáfíà” (Ilé Ìṣọ́, November 1, 2002)
Wo fídíò yìí kó o lè rí ohun tó ran àwọn kan lọ́wọ́ tí wọn ò fi ń ṣojúsàájú.
Ka ìwé yìí kó o lè rí àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti yanjú èdèkòyédè kó má bàa da àlàáfíà ìjọ rú.
a Àlàyé Ìparí 6 sọ ohun tá a lè ṣe ká má bàa kó àrùn ran àwọn míì, ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.
b Àlàyé Ìparí 7 jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè yanjú ọ̀rọ̀ nípa ìṣòwò àtàwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ òfin.
-
-
Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Wà Nínú ÌjọGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
1. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ láàárín àwa èèyàn Jèhófà?
Tó o bá lọ sípàdé lórílẹ̀-èdè míì, ó ṣeé ṣe kó o má gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ. Àmọ́ ó dájú pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ò ní ṣàjèjì sí ẹ, ara á tù ẹ́, ọkàn ẹ á sì balẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwé kan náà la fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé. A sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa fìfẹ́ hàn síra wa. Orílẹ̀-èdè yòówù ká máa gbé, gbogbo wa là ń ‘pe orúkọ Jèhófà, ká lè máa sìn ín ní ìṣọ̀kan.’—Sefanáyà 3:9.
-