Ríran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Sún Mọ́ Jèhófà
“Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.”—JÒHÁNÙ 14:6.
1. Kí ni àṣẹ tí Jésù tí a jíǹde fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí ló sì ti jẹ́ àbájáde ìgbọràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àṣẹ náà?
JÉSÙ KRISTI pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ‘máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọn máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.’ (Mátíù 28:19) Lẹ́nu ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì batisí wọn láti fi ẹ̀rí hàn pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. A mà láyọ̀ pé a láǹfààní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run o!—Jákọ́bù 4:8.
2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ni a ń batisí, kí ló ń ṣẹlẹ̀?
2 Àmọ́, iye àwọn akéde Ìjọba kò fí bẹ́ẹ̀ lọ sókè ní àwọn orílẹ̀-èdè kan táa ti batisí ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn tuntun. Bí ìṣirò wa yóò bá pé dáadáa, a gbọ́dọ̀ yọ àwọn tó ti kú kúrò, nítorí pé ẹnì kan nínú ọgọ́rùn-ún ló ń kú lọ́dún. Àmọ́ ṣá o, ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ti ṣáko lọ nítorí àwọn ìdí kan. Èé ṣe? Àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e yóò gbé bí a ṣe ń mú kí àwọn èèyàn sún mọ́ Jèhófà yẹ̀ wò àti àwọn ohun tó fà á tí àwọn kan fi ṣáko lọ.
Ète Tí A Fi Ń Wàásù
3. (a) Báwo ni iṣẹ́ pàtàkì tí a fi síkàáwọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe bá ti áńgẹ́lì tí a mẹ́nu kan nínú Ìṣípayá 14:6 mu? (b) Ọ̀nà wo ló gbéṣẹ́ jù lọ láti ta ọkàn-ìfẹ́ àwọn ènìyàn jí sí iṣẹ́ Ìjọba náà, ṣùgbọ́n ìṣòro wo ló wà níbẹ̀?
3 Ní “àkókò òpin” yìí, iṣẹ́ pàtàkì tí a gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ́wọ́ ni láti tan “ìmọ̀ tòótọ́” nípa “ìhìn rere ìjọba yìí” kálẹ̀. (Dáníẹ́lì 12:4; Mátíù 24:14) Iṣẹ́ wọ́n ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ti áńgẹ́lì tó “ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣípayá 14:6) Nínú ayé tó jẹ́ pé ọ̀ràn nípa àwọn nǹkan asán ló kún inú rẹ̀ yìí, ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù láti mú kí àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí Ìjọba Ọlọ́run àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà ni pé, kí a sọ nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé fún wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táà ń ṣe yé wa, ó yẹ ká mọ̀ pé àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run nítorí kí wọ́n ṣáà lè wọnú Párádísè kò tí ì mú ìdúró wọn dáadáa lójú ọ̀nà tóóró náà tó lọ sí ìyè.—Mátíù 7:13, 14.
4. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jésù àti áńgẹ́lì tó ń fò ní agbedeméjì ọ̀run sọ, kí ni ète iṣẹ́ ìwàásù wa?
4 Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Áńgẹ́lì tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run ń polongo “ìhìn rere àìnípẹ̀kun,” ó sì ń sọ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” (Ìṣípayá 14:7) Ohun tó wá túmọ̀ sí ni pé, ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ Kristi Jésù ni olórí ète tí a fi ń wàásù ìhìn rere.
Ipa Tiwa Nínú Iṣẹ́ Jèhófà
5. Ọ̀rọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù àti Jésù sọ tó fi hàn pé iṣẹ́ Jèhófà ni a ń ṣe, kì í ṣe iṣẹ́ ara wa?
5 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bíi tirẹ̀, ó sọ̀rọ̀ nípa “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,” ó sì sọ pé Ọlọ́run mú àwọn ènìyàn padà bá ara rẹ̀ rẹ́ nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Pọ́ọ̀lù sọ pé ó dà “bí ẹni pé Ọlọ́run ń pàrọwà nípasẹ̀ wa,” àti pé “gẹ́gẹ́ bí àwọn adípò fún Kristi, àwa bẹ̀bẹ̀ pé: ‘Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.’” Ẹ wo bí èyí ṣe jẹ́ èrò tí ń múni lọ́kàn yọ̀ tó! Yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi” tàbí a jẹ́ aṣojú tó ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé iṣẹ́ Jèhófà niṣẹ́ yìí, kì í ṣe iṣẹ́ wa. (2 Kọ́ríńtì 5:18-20) Ní gidi, Ọlọ́run ló ń fa ènìyàn, òun ló sì ń kọ́ àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ Kristi. Jésù la ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á; dájúdájú, èmi yóò sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. A kọ̀wé rẹ̀ nínú àwọn Wòlíì pé, ‘Gbogbo wọn yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’ Gbogbo ẹni tí ó bá ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó sì ti kẹ́kọ̀ọ́, ń wá sọ́dọ̀ mi.”—Jòhánù 6:44, 45.
6. Ìgbésẹ̀ ìṣáájú wo ni Jèhófà fi ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn wo ló sì ń rí ààbò nínú “ilé” ìjọsìn rẹ̀ ní àkókò kan náà?
6 Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, báwo ni Jèhófà ṣe ń fa àwọn ènìyàn, tó sì ń ṣí “ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́” sílẹ̀ fún wọn? (Ìṣe 14:27, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; 2 Tímótì 3:1) Ọ̀nà pàtàkì tó ń lò jù ni mímú kí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ pòkìkí iṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀ àti ìdájọ́ lórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (Aísáyà 43:12; 61:1, 2) Ìkéde jákèjádò ayé yìí ń mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì—àmì ìdájọ́ kan láìpẹ́ tí yóò mú ìparun lọ́wọ́ ni èyí jẹ́. Ní àkókò kan náà tí ìkéde yìí ń lọ lọ́wọ́, a ń fa àwọn èèyàn tó “ṣeyebíye” lójú Ọlọ́run jáde kúrò nínú ètò àwọn nǹkan yìí, wọ́n sì ń rí ààbò nínú “ilé” ìjọsìn tòótọ́ rẹ̀. Jèhófà ń tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí Hágáì kọ sílẹ̀ ṣẹ pé: “Èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.”—Hágáì 2:6, 7, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; Ìṣípayá 7:9, 15.
7. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn sílẹ̀, tó sì ń fà wọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àtọ̀dọ̀ Ọmọ rẹ̀?
7 Jèhófà ń ṣí ọkàn-àyà àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run wọ̀nyí sílẹ̀—ìyẹn “àwọn ohun tí a yàn láàyò ní gbogbo orílẹ̀-èdè”—pé kí wọn lè “fiyè sí àwọn ohun tí” àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ “ń sọ.” (Hágáì 2:7, Jewish Publication Society; Ìṣe 16:14) Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní, nígbà mí-ìn, Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti darí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn olóòótọ́ ọkàn tó ti ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. (Ìṣe 8:26-31) Bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìpèsè àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe fún wọn nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Jèhófà ń fà wọ́n mọ́ ọn. (1 Jòhánù 4:9, 10) Dájúdájú, Ọlọ́run ń fi “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” tàbí “ìfẹ́ dídúró-ṣinṣin” Rẹ̀ fa àwọn ènìyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àtọ̀dọ̀ Ọmọ rẹ̀.—Jeremáyà 31:3, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
Àwọn Wo Ni Jèhófà Ń Fà?
8. Irú àwọn ènìyàn wo ni Jèhófà ń fà?
8 Àwọn tó ń wá Jèhófà ló máa ń fà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àtọ̀dọ̀ Ọmọ rẹ̀. (Ìṣe 17:27) Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe” nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù àti èyí tí a ń ṣe jákèjádò ayé pàápàá. (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Àwọn làwọn èèyàn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Láìsí àní-àní, àwọn ni “ọlọ́kàn tútù [“onírẹ̀lẹ̀,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW] ilẹ̀ ayé,” tí yóò gbé inú párádísè orí ilẹ̀ ayé títí láé.—Sefanáyà 2:3.
9. Báwo ni Jèhófà ṣe lè mọ̀ bí àwọn ènìyàn bá “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun,” báwo ló sì ṣe ń fa àwọn wọ̀nyí?
9 Jèhófà lè mọ ọkàn-àyà ènìyàn. Ọba Dáfídì sọ fún ọmọ rẹ̀ Sólómọ́nì pé: “Gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀. Bí ìwọ bá wá a, yóò jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíróníkà 28:9) Nípa wíwo bí ọkàn-àyà ẹnì kan ṣe rí àti irú ẹ̀mí tí onítọ̀hún ní, tàbí ìṣarasíhùwà rẹ̀, Jèhófà lè mọ̀ bóyá irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gba ìpèsè àtọ̀runwá náà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò tuntun òdodo ti Ọlọ́run. (2 Pétérù 3:13) Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ń wàásù tí wọ́n sì fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ló fi ń fa ‘gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun’ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àtọ̀dọ̀ Ọmọ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí sì ‘ń di onígbàgbọ́.’—Ìṣe 13:48.
10. Kí ló fi hàn pé bí Jèhófà ṣe ń fa àwọn kan, tí kì í fa àwọn mìíràn kò ní í ṣe pẹ̀lú àyànmọ́?
10 Bí Jèhófà ṣe ń fa àwọn kan, tí kò sì fa àwọn mìíràn ha ní í ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ bí? Dájúdájú, kò rí bẹ́ẹ̀! Ìfẹ́-ọkàn àwọn èèyàn fúnra wọn ló ń pinnu bóyá Ọlọ́run yóò fà wọ́n tàbí kò ní fà wọ́n. Kì í fagbára mú wọn láti ṣe ohun tí wọn kò bá fẹ́ ṣe. Irú ohun tí Jèhófà fi síwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn náà ló tún fi síwájú àwọn èèyàn lónìí, nígbà tó tẹnu Mósè sọ pé: “Mo fi ìyè àti ire, àti ikú àti ibi, sí iwájú rẹ lónìí. . . . Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn; nítorí òun ni ìyè rẹ àti gígùn ọjọ́ rẹ.”—Diutarónómì 30:15-20.
11. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa yan ìyè?
11 Kíyè sí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa yan ìyè ‘nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀, àti nípa fífà mọ́ ọn.’ Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kò tí ì gba Ilẹ̀ Ìlérí náà nígbà tí a sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn o. Wọ́n ṣì ń gbára dì ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, wọ́n ń múra láti rékọjá Odò Jọ́dánì, kí wọ́n sì wọ Kénáánì. Gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, wọ́n á ti máa ronú gan-an nípa ilẹ̀ náà “tí ó dára tí ó sì ní àyè gbígbòòrò,” ilẹ̀ tó “ń ṣàn fún wàrà àti oyin” tí yóò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ láìpẹ́, àmọ́ ṣá o, ìfẹ́ wọn fún Jèhófà, fífetí sí ohùn rẹ̀, àti fífà mọ́ ọn, la óò fi mọ̀ bóyá àlá wọn yìí yóò ṣẹ. (Ẹ́kísódù 3:8) Mósè mú èyí ṣe kedere, ó la ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀ pé: “Bí ìwọ yóò bá fetí sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, èyí tí èmi ń pa fún ọ lónìí, kí o bàa lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, nígbà náà, a óò mú kí o máa wà láàyè nìṣó, a ó sì sọ ọ́ di púpọ̀ sí i, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì bù kún ọ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ láti gbà.”—Diutarónómì 30:16.
12. Ẹ̀kọ́ wo ló yẹ kí àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ wa nípa iṣẹ́ ìwàásù wa àti iṣẹ́ ìkọ́ni tí a ń ṣe?
12 Ǹjẹ́ kò yẹ kí ohun táa ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ kan nípa ìwàásù wa àti iṣẹ́ ìkọ́ni tí a ń ṣe ní àkókò ìkẹyìn yìí? A máa ń ronú nípa Párádísè tí ń bọ̀ náà, bẹ́ẹ̀ sì ni a kì í yé sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí èyí tí yóò rí ìmúṣẹ ìlérí náà nínú àwa àti àwọn tí a ń sọ di ọmọ ẹ̀yìn bó bá jẹ́ pé nítorí ẹ̀mí tara wa nìkan ni àwa tàbí àwọn táa sọ di ọmọ ẹ̀yìn fi ń sin Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwa àti àwọn tí a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ kọ́ bí a ṣe ń ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, báa ṣe lè fetí sí ohùn rẹ̀, àti báa ṣe ń fà mọ́ ọn.’ Bí a bá ń rántí èyí nígbà tí a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó dájú pé a óò máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run láti fa àwọn ènìyàn sọ́dọ̀ rẹ̀.
Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run
13, 14. (a) Ní ìbámu pẹ̀lú 1 Kọ́ríńtì 3:5-9, báwo la ṣe lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run? (b) Ọ̀dọ̀ ta ló yẹ kí ìyìn fún ìbísí èyíkéyìí lọ, èé sì ti ṣe?
13 Pọ́ọ̀lù fi fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run wé iṣẹ́ oko ríro. Ó kọ̀wé pé: “Kí wá ni Àpólò jẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, kí ni Pọ́ọ̀lù jẹ́? Àwọn òjíṣẹ́ tí ẹ tipasẹ̀ wọn di onígbàgbọ́, àní gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti yọ̀ǹda fún olúkúlùkù. Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà; tí ó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tí ń gbìn ni ó jẹ́ nǹkan kan tàbí ẹni tí ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń mú kí ó dàgbà. Wàyí o, ẹni tí ń gbìn àti ẹni tí ń bomi rin jẹ́ ọ̀kan, ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò gba èrè tirẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òpò tirẹ̀. Nítorí àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ̀yin jẹ́ pápá Ọlọ́run tí a ń ro lọ́wọ́.”—1 Kọ́ríńtì 3:5-9.
14 Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí ìgbàgbọ́ gbin “ọ̀rọ̀ ìjọba náà” sí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn, lẹ́yìn náà kí a bomi rin ọkàn-ìfẹ́ tí wọ́n bá fi hàn nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a múra sílẹ̀ dáadáa. Bí ilẹ̀ náà, ìyẹn ọkàn-àyà wọ́n bá dára, Jèhófà yóò ṣe ipa tirẹ̀ láti mú kí òtítọ́ Bíbélì dàgbà di irúgbìn tí yóò so èso rere. (Mátíù 13:19, 23) Yóò fa ẹni náà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àtọ̀dọ̀ Ọmọ rẹ̀. Ní àbárèbábọ̀, ìbísí èyíkéyìí tí a bá ní nínú iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba yóò jẹ́ nítorí iṣẹ́ tí Jèhófà ṣe lórí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn, nípa mímú kí irúgbìn òtítọ́ dàgbà, tó sì ń fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àtọ̀dọ̀ Ọmọ rẹ̀.
Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tí Yóò Wà Títí
15. Àpèjúwe wo ni Pọ́ọ̀lù lò láti fi hàn bí a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú ìgbàgbọ́ dàgbà?
15 Bí a ti ń yọ̀ pé a ń ní ìbísí, a fi tọkàntọkàn fẹ́ láti máa rí àwọn ènìyàn tí ìfẹ́ wọn fún Jèhófà kò dín kù, tí wọ́n ń fetí sí ohùn rẹ̀, tí wọ́n sì ń fà mọ́ ọn. Ó máa ń bà wá nínú jẹ́ nígbà tí a bá rí àwọn kan tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, tí wọ́n sì ṣáko lọ. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí a lè ṣe kí èyí má bàa ṣẹlẹ̀? Nínú àpèjúwe mìíràn, Pọ́ọ̀lù fi bí a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú ìgbàgbọ́ wọn dàgbà hàn. Ó kọ̀wé pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè fi ìpìlẹ̀ èyíkéyìí mìíràn lélẹ̀ ju ohun tí a ti fi lélẹ̀ lọ, èyí tí í ṣe Jésù Kristi. Wàyí o, bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ wúrà, fàdákà, àwọn òkúta ṣíṣeyebíye, àwọn ohun èlò igi, koríko gbígbẹ, àgékù pòròpórò sórí ìpìlẹ̀ náà, iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò fara hàn kedere, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí a óò ṣí i payá nípasẹ̀ iná; iná náà fúnra rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀rí irú ohun tí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ hàn.”—1 Kọ́ríńtì 3:11-13.
16. (a) Báwo ni ète àwọn àpèjúwe méjèèjì tí Pọ́ọ̀lù lò ṣe yàtọ̀ síra? (b) Báwo ni iṣẹ́ ìkọ́lé wa ṣe lè di èyí tí kò tẹ́rùn, tí kò sì lè la iná já?
16 Nínú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa pápá oko, dídàgbà sinmi lórí fífi ìṣọ́ra gbin nǹkan, bíbomi rin ín déédéé, àti ìbùkún Ọlọ́run. Àpèjúwe mìíràn tí àpọ́sítélì náà ṣe tẹnu mọ́ apá tí ó kan Kristẹni òjíṣẹ́ kan nínú ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí iṣẹ́ ìkọ́lé tó ṣe. Òun ha fi ojúlówó ohun èlò kọ́lé sórí ìpìlẹ̀ tó dájú bí? Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Kí olúkúlùkù máa ṣọ́ bí ó ti ń kọ́lé sórí rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 3:10) Lẹ́yìn tí a bá ti ta ìfẹ́-ọkàn ẹnì kan jí nípa sísọ̀rọ̀ nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè fún un, ṣé lórí ohun ìpìlẹ̀ nípa ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ ni ẹ̀kọ́ wa yóò wulẹ̀ dá lé tí a óò wá máa tẹnu mọ́ kìkì ohun tí ẹni náà gbọ́dọ̀ ṣe láti ní ìyè ayérayé? Ǹjẹ́ ó yẹ kí ẹ̀kọ́ wa dá lórí kìkì pé: ‘Bí o bá fẹ́ wà láàyè títí láé nínú Párádísè, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́, kí o máa lọ sí ìpàdé, kí o sì máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù’? Bó bá jẹ́ ìyẹn là ń ṣe, a jẹ́ pé a ò kọ́ ìgbàgbọ́ ẹni náà sórí ìpìlẹ̀ tó lágbára, ohun tí a sì kọ́ lè má lè kojú iná àdánwò tàbí kó má lè fara da ìṣòro fún ìgbà pípẹ́. Gbígbìyànjú láti fa àwọn ènìyàn sọ́dọ̀ Jèhófà nípa wíwulẹ̀ jẹ́ kí wọ́n rò pé tí wọ́n bá ti lè fi ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ sìn ín, ìrètí ìyè wọn nínú Párádísè ti dájú dà bíi fífi “àwọn ohun èlò igi, koríko gbígbẹ, àgékù pòròpórò” kọ́lé.
Gbígbé Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti Kristi Ró
17, 18. (a) Kí ni kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn bí ìgbàgbọ́ ẹnì kan yóò bá wà pẹ́ títí? (b) Báwo la ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn-àyà rẹ̀?
17 Kí ìgbàgbọ́ tó lè wà pẹ́ títí, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a gbé karí ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn aláìpé, a lè ní irú ìbátan alálàáfíà bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. (Róòmù 5:10) Rántí pé Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” Láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ wọn ró, “kò sí ènìyàn kankan tí ó lè fi ìpìlẹ̀ èyíkéyìí mìíràn lélẹ̀ ju ohun tí a ti fi lélẹ̀ lọ, èyí tí í ṣe Jésù Kristi.” Kí ni èyí túmọ̀ sí?—Jòhánù 14:6; 1 Kọ́ríńtì 3:11.
18 Kíkọ́lé sórí Kristi gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ túmọ̀ sí kíkọ́ni lọ́nà tó jẹ́ pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà yóò mú ìfẹ́ tó jinlẹ̀ dàgbà fún Jésù nípasẹ̀ níní ìmọ̀ kíkún rẹ́rẹ́ nípa ipò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùdáǹdè, Orí ìjọ, Àlùfáà Àgbà tó nífẹ̀ẹ́ ẹni, àti Ọba tí ń jọba. (Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 20:28; Kólósè 1:18-20; Hébérù 4:14-16) Ó túmọ̀ sí mímú kí Jésù jẹ́ ẹni gidi sí wọn débi pé ó wá jọ pé ó ń gbé inú ọkàn-àyà wọn. Ṣe ló yẹ kí àdúrà táà ń gbà nítorí wọn dà bí ẹ̀bẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ń bẹ̀ nítorí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù. Ó kọ̀wé pé: “Mo tẹ eékún mi ba fún Baba, . . . kí ó bàa lè yọ̀ǹda fún yín . . . láti mú kí Kristi máa gbé inú ọkàn-àyà yín pẹ̀lú ìfẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín; kí ẹ lè ta gbòǹgbò, kí ẹ sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà.”—Éfésù 3:14-17.
19. Kí ni gbígbé ìfẹ́ fún Kristi ró nínú ọkàn-àyà àwọn tí a ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò yọrí sí, ṣùgbọ́n kí la gbọ́dọ̀ kọ́ wọn?
19 Bí a bá kọ́lé ní irú ọ̀nà tó lè mú kí ìfẹ́ fún Kristi dàgbà nínú ọkàn-àyà akẹ́kọ̀ọ́ wa, lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, èyí yóò yọrí sí gbígbé ìfẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run ró. Ìfẹ́ tí Jésù ní, ìmọ̀lára rẹ̀, àti ìyọ́nú rẹ̀ fi àwọn ànímọ́ Jèhófà hàn láìkù síbì kan. (Mátíù 11:28-30; Máàkù 6:30-34; Jòhánù 15:13, 14; Kólósè 1:15; Hébérù 1:3) Báwọn ènìyàn bá ṣe ń mọ Jésù tí wọ́n sì ń nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn óò mọ Jèhófà, tí wọn óò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.a (1 Jòhánù 4:14, 16, 19) A gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn tí a ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé Jèhófà ló mú kí Kristi ṣe gbogbo ohun tó ṣe fún aráyé àti pé a tipa bẹ́ẹ̀ jẹ Ẹ́ ní ọpẹ́, ìyìn, àti ìjọsìn gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run ìgbàlà wa.”—Sáàmù 68:19, 20; Aísáyà 12:2-5; Jòhánù 3:16; 5:19.
20. (a) Báwo la ṣe lè ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?
20 Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ ọn àti láti sún mọ́ Ọmọ rẹ̀, kí a ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ dàgbà nínú ọkàn-àyà wọn. Jèhófà yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹni gidi sí wọn. (Jòhánù 7:28) Nípasẹ̀ Kristi, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti fìdí ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run múlẹ̀, wọn óò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọn óò sì fà mọ́ ọn. Wọn ò ní máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àkókò kan pàtó lọ́kàn, wọn óò gbà gbọ́ pé àwọn ìlérí àgbàyanu Jèhófà yóò ní ìmúṣẹ ní àkókò tí òun yàn. (Ìdárò 3:24-26; Hébérù 11:6) Àmọ́ ṣá o, bí a ti ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ dàgbà, a gbọ́dọ̀ gbé ìgbàgbọ́ tiwa náà ró kí ó lè da bí ọkọ̀ òkun tó dáńgájíá tó lè la ìjì líle já. Èyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àrànṣe títayọ tí a fi lè túbọ̀ mọ Jésù sí i kí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ mọ Bàbá rẹ̀, Jèhófà, ni ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Àtúnyẹ̀wò
◻ Báwo ní a ṣe sábà ń ta ìfẹ́-ọkàn àwọn ènìyàn jí sí iṣẹ́ Ìjọba náà, ṣùgbọ́n ìṣòro wo ló wà níbẹ̀?
◻ Irú àwọn ènìyàn wo ni Jèhófà ń fà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àtọ̀dọ̀ Ọmọ rẹ̀?
◻ Orí kí ni a gbé wíwọ inú Ilẹ̀ Ìlérí náà kà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí?
◻ Ipa wo là ń kó nínú ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń nawọ́ ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè sí àwọn ènìyàn, olórí ète wa ní láti fà wọ́n sọ́dọ̀ Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìpadàbẹ̀wò wa lè gbéṣẹ́ gan-an bí a bá múra sílẹ̀ dáadáa