Kò Sí Ohun Ìjà Tí a Ṣe Sí Yín Tí Yóò Ṣàṣeyọrí
“Ohun ìjà . . . tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.”—AÍSÁYÀ 54:17.
1, 2. Báwo ni ìrírí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Alibéníà ṣe fi hàn pé òótọ́ lohun tó wà nínú Aísáyà 54:17?
NÍ Ọ̀PỌ̀ ọdún sẹ́yìn àwùjọ àwọn Kristẹni onígboyà kan wà ní Alibéníà, orílẹ̀-èdè kékeré kan tó jẹ́ ilẹ̀ olókè ní gúúsù ìlà oòrùn Yúróòpù. Ìjọba Kọ́múníìsì kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rẹ́yìn àwọn Kristẹni yìí. Wọ́n fìyà jẹ wọ́n, wọ́n fi wọ́n sí àgọ́ tí wọ́n ti ń fi àwọn èèyàn ṣiṣẹ́ àṣekú, wọ́n bà wọ́n lórúkọ jẹ́ lórí rédíò, nínú ìwé ìròyìn àtàwọn ọ̀nà míì. Síbẹ̀, mìmì kan ò mì wọ́n. Ta làwọn Kristẹni yìí? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn rárá láti máa ṣèpàdé àti láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù nígbà yẹn, ìforítì wọn láàárín ọdún wọ̀nyẹn gbé ìsìn Kristẹni ga, ó sì mú káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún un, èyí sì ti mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà. Lọ́dún 2006, nígbà tí wọ́n ń ṣe ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn tuntun lórílẹ̀-èdè Alibéníà, arákùnrin kan tó ti ń sin Jèhófà bọ̀ tipẹ́ sọ pé: “Kò sí bí Sátánì ṣe lè gbógun tó, ńṣe ni yóò máa pòfo tí Jèhófà á sì máa ṣẹ́gun!”
2 Irú àwọn ìrírí báyìí fi hàn pé òótọ́ ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Aísáyà 54:17, ó kà pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi.” Àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn fi hàn pé kò sóhun tí ayé Sátánì lè ṣe tó máa mú káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ jáwọ́ nínú sísin Jèhófà Ọlọ́run.
Àwọn Ìsapá Sátánì Tó Ń Já sí Pàbó
3, 4. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun ìjà tí Sátánì ń lò? (b) Ọ̀nà wo lohun ìjà tí Èṣù ń lò kò fi borí?
3 Lára àwọn ohun ìjà tí Sátánì fi ń gbógun ti àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ni pé, ó ń mú kí ìjọba fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, ó ń lo àwọn jàǹdùkú láti gbéjà kò wá, ó ń mú kí ìjọba fàwọn kan sẹ́wọ̀n, ó sì ń mú káwọn èèyàn ‘fi òfin dáná ìjàngbọ̀n.’ (Sáàmù 94:20) Kódà, báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́lọ́wọ́, Èṣù ń “dán” àwọn kan nínú wọn “wò” láwọn orílẹ̀-èdè kan, kó lè ba ìwà títọ́ wọn sí Ọlọ́run jẹ́.—Ìṣípayá 2:10.
4 Bí àpẹẹrẹ, ohun tá a gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ni pé, láàárín ọdún kan péré, ìgbà méjìlélọ́gbọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn lu àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà lóde ẹ̀rí. Bákan náà, ìgbà mọ́kàndínlọ́gọ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ọlọ́pàá mú àwọn Ẹlẹ́rìí, lọ́mọdé, lágbà, lọ́kùnrin, lóbìnrin nígbà tí wọ́n ń wàásù fáwọn èèyàn lóde ẹ̀rí. Wọ́n ní káwọn míì tẹ̀ka, wọ́n ya fọ́tò wọn, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn. Wọ́n tiẹ̀ láwọn máa ṣe àwọn míì lára wọn léṣe. Ní orílẹ̀-èdè míì, àkọsílẹ̀ fi hàn pé ó tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún [1,100] ìgbà tí wọ́n ti fàṣẹ ọba mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ní kí wọ́n sanwó ìtanràn, tàbí tí wọ́n lù wọ́n. Àní, èyí tó ju igba [200] nínú rẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ táwọn ará péjọ láti ṣèrántí ikú Jésù! Láìka àwọn ìṣòro kíkàmàmà yẹn sí, ẹ̀mí Jèhófà ń mú káwọn èèyàn rẹ̀ borí àwọn ìṣòro wọ̀nyí láwọn orílẹ̀-èdè tá a sọ nípa wọn yìí àtàwọn orílẹ̀-èdè míì. (Sekaráyà 4:6) Bó ti wù káwọn ọ̀tá gbógun tó, wọn ò lè mú káwọn èèyàn Jèhófà ṣíwọ́ yíyìn ín. Ó dá wa lójú hán-ún pé, kò sóhun ìjà tí Sátánì lè lò tó lè mú kóhun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe yẹ̀.
A Dá Àwọn Ahọ́n Èké Lẹ́bi
5. Àwọn ahọ́n èké wo ló dìde sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ọ̀rúndún kìíní?
5 Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò dá ahọ́n èyíkéyìí tó bá dìde sí wọn lẹ́bi. Ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn parọ́ mọ́ àwọn Kristẹni, tí wọ́n sọ pé ẹni ibi ni wọ́n. Àpẹẹrẹ kan wà nínú Ìṣe 16:20, 21 nípa irú àwọn ẹ̀sùn èké bẹ́ẹ̀. Ó kà pé: “Àwọn ọkùnrin yìí ń yọ ìlú ńlá wa lẹ́nu gan-an ni, . . . wọ́n sì ń kéde àwọn àṣà tí kò bófin mu fún wa láti tẹ́wọ́ gbà tàbí láti sọ dàṣà, nítorí pé a jẹ́ ará Róòmù.” Ó tún ṣẹlẹ̀ nígbà míì pé àwọn tó ń ṣàtakò ẹ̀sìn fẹ́ ti àwọn aláṣẹ ìlú láti gbéjà ko àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, wọ́n sọ pé: “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí wọ́n ti sojú ilẹ̀ ayé tí a ń gbé dé ti dé síhìn-ín pẹ̀lú, wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ ní ìlòdìsí àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ Késárì.” (Ìṣe 17:6, 7) Wọ́n tiẹ̀ sọ pé “alákòóbá” ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n tún ní òun ni olórí àwọn ẹ̀ya ìsìn kan tó ń ru ìdìtẹ̀ sókè “jákèjádò ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—Ìṣe 24:2-5.
6, 7. Ọ̀nà wo làwa Kristẹni tòótọ́ gbà ń “dá” irọ́ táwọn èèyàn ń pa mọ́ wa àti bí wọ́n ṣe ń bà wá lórúkọ jẹ́ “lẹ́bi”?
6 Kò yà wá lẹ́nu pé àwọn èèyàn ń parọ́ mọ́ àwa Kristẹni lóde òní, wọ́n sì ń bà wá lórúkọ jẹ́. Ọ̀nà wo là ń gbà “dá” irọ́ táwọn èèyàn ń pa mọ́ wa àti bí wọ́n ṣe ń bà wá lórúkọ jẹ́ “lẹ́bi”?—Aísáyà 54:17.
7 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń dá irọ́ àti ìbanilórúkọjẹ́ bẹ́ẹ̀ lẹ́bi nípa ìwà rere wa. (1 Pétérù 2:12) Báwa Kristẹni bá ń pa àwọn òfin ìlú mọ́, tá a jẹ́ ọmọlúwàbí tí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ lógún, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé irọ́ gbuu làwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi ń kàn wá. Ìwà rere tá à ń hù máa ń dá wa láre. Báwọn èèyàn ṣe ń rí i tá à ń tẹra mọ́ ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àtàtà, èyí ń mú kí wọ́n fògo fún Bàbá wa ọ̀run, wọ́n sì gbà lóòótọ́ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń gbé ìgbésí ayé tó dára jù.—Aísáyà 60:14; Mátíù 5:14-16.
8. (a) Kí ló lè gbà pé ká ṣe nígbà míì láti fi gbèjà ohun tá a gbà gbọ́? (b) Bíi ti Kristi, báwo la ṣe ń dá àwọn ahọ́n tó bá dìde sí wa lẹ́bi?
8 Láfikún sí ìwà Kristẹni tá a ní, nígbà míì ó lè gba pé ká fìgboyà gbèjà ohun tá a gbà gbọ́. Ọ̀nà kan tá à ń gbà ṣe èyí ni pé ká ké gbàjarè sáwọn ìjọba àtàwọn ilé ẹjọ́. (Ẹ́sítérì 8:3; Ìṣe 22:25-29; 25:10-12) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, láwọn ìgbà míì, gbangba gbàǹgbà ló máa ń já àwọn alátakò rẹ̀ nírọ́. (Mátíù 12:34-37; 15:1-11) Ẹ jẹ́ ká máa fara wé Jésù, nípa mímúratán láti fi ìdánilójú ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn nígbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ. (1 Pétérù 3:15) Ẹ má ṣe jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ tí wọ́n bá fi wá ṣe níléèwé, níbi iṣẹ́ tàbí èyí táwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bá fi wá ṣe mú ká má ṣe sọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn.—2 Pétérù 3:3, 4.
“Òkúta Ẹrù Ìnira” Ni Jerúsálẹ́mù
9. Jerúsálẹ́mù wo ló ṣàpẹẹrẹ “òkúta ẹrù ìnira” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Sekaráyà 12:3, àwọn wo ló sì jẹ́ aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
9 Àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà jẹ́ ká mọ ìdí táwọn orílẹ̀-èdè fi lòdì sáwa Kristẹni tòótọ́. Kíyè sí ohun tí Sekaráyà 12:3 sọ, ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di òkúta ẹrù ìnira sí gbogbo ènìyàn.” Jerúsálẹ́mù wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ? “Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run” ni Sekaráyà sàsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn Ìjọba ti ọ̀run, èyí tí Ọlọ́run pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sí. (Hébérù 12:22) Díẹ̀ lára àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró yìí tí wọ́n máa bá Mèsáyà náà jọba ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn yìí àtàwọn “àgùntàn mìíràn” ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nígbà tí àkókò ṣì wà. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 11:15) Ìhà wo làwọn orílẹ̀-èdè kọ sí ìpè yìí? Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ olóòótọ́ lẹ́yìn lóde òní? Láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Sekaráyà orí kejìlá túmọ̀ sí. Èyí á jẹ́ kó lè dá wa lójú pé ‘kò sí ohun ìjà’ tí wọ́n lè fi bá àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n ti yara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run jà tí “yóò ṣe àṣeyọrí.”
10. (a) Kí nìdí táwọn orílẹ̀-èdè fi ń gbógun ti àwa èèyàn Ọlọ́run? (b) Kí ló gbẹ̀yìn àwọn tó gbìyànjú láti gbé “òkúta ẹrù ìnira” náà kúrò lọ́nà?
10 Sekaráyà orí kejìlá ẹsẹ kẹta sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè yóò “fara bó yánnayànna.” Báwo lèyí ṣe ṣẹlẹ̀? Àṣẹ Ọlọ́run ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Ọwọ́ pàtàkì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere yìí torí pé ojúṣe wa ni. Àmọ́, kíkéde tá à ń kéde Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé jẹ́ “òkúta ẹrù ìnira” fáwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n ń gbìyànjú láti gbé òkúta yìí kúrò lọ́nà nípa ṣíṣèdíwọ́ fáwọn tó ń wàásù Ìjọba náà. Báwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń ṣèdíwọ́ yìí, wọ́n ti “fara bó yánnayànna.” Kódà, orúkọ wọn ti dèyí tó bà jẹ́ nítorí pé ńṣe ni gbogbo ètekéte wọn máa ń dà lé àwọn fúnra wọn lórí. Àwọn orílẹ̀-èdè kò lè pa àwọn tí ń fi òtítọ́ inú jọ́sìn Jèhófà lẹ́nu mọ́ nítorí àwọn olùjọsìn Jèhófà mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa kéde “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” ti Ìjọba Ọlọ́run kí ètò àwọn nǹkan yìí tó dópin. (Ìṣípayá 14:6) Nígbà tí ọkùnrin kan tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà rí bí wọn ṣe ń hùwà ìkà sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ó sọ fáwọn tó ń hùwà ìkà náà pé: ‘Ẹ kàn ń dara yín láàmù lásán ni pẹ̀lú bẹ́ ẹ ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn aráabí yìí. Wọn ò ní ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn láéláé. Ńṣe ni wọ́n á máa pọ̀ sí i ṣáá.’
11. Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú ìlérí tó ṣe nínú Sekaráyà 12:4 ṣẹ?
11 Ka Sekaráyà 12:4. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa mú kí àwọn tó kọjúùjà sáwọn tó ń fìgboyà kéde Ìjọba náà pàdánù agbára ìríran wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, òun yóò sì fi “ìdàrúdàpọ̀-ọkàn” kọ lù wọ́n. Ǹjẹ́ Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ yìí ṣẹ? Bẹ́ẹ̀ ni o. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan tí ìjọba ti fòfin de ìjọsìn tòótọ́, àwọn alátakò ò lè ṣèdíwọ́ fáwọn èèyàn Ọlọ́run kí wọ́n máà rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà. Ìwé ìròyìn kan tiẹ̀ sọ pé fèrè tí wọ́n fẹ́ afẹ́fẹ́ kún inú rẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọlé sí orílẹ̀-èdè náà! Òótọ́ pọ́ńbélé ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin pé: “Èmi yóò sì la ojú mi . . . gbogbo ẹṣin àwọn ènìyàn náà ni èmi yóò sì fi ìpàdánù agbára ìríran kọlù.” Ìbínú tó ru bo àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run lójú ò jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tí wọ́n máa ṣe. Ó dá wa lójú hán-ún pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀ lápapọ̀, yóò sì bójú tó wa.—2 Àwọn Ọba 6:15-19.
12. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà dá iná nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? (b) Báwo làwọn àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń mú kí iná ràn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
12 Ka Sekaráyà 12:5, 6. “Àwọn séríkí Júdà” tí ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu kàn tọ́ka sí àwọn tó jẹ́ alábòójútó láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Jèhófà mú kí ìtara àwọn alábòójútó tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró yìí máa jó bí iná, kí wọ́n lè bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà kan, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi wá láti dá iná kan sórí ilẹ̀ ayé.” (Lúùkù 12:49) Lóòótọ́, Jésù sì dáná sórí ilẹ̀ ayé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ìjọba Ọlọ́run ni olórí ohun tí Jésù ń fi ìtara wàásù fáwọn èèyàn. Àríyànjiyàn ńlá ni èyí sì dá sílẹ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè àwọn Júù. (Mátíù 4:17, 25; 10:5-7, 17-20) Lọ́nà kan náà, “bí ìkòkò tí a kóná sí láàárín igi àti bí ògùṣọ̀ oníná nínú ẹsẹ ọkà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gé,” làwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí ṣe ń mú kí iná ràn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ lóde òní. Ìwé kan tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1917, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní The Finished Mysterya tú àṣírí gbogbo àgàbàgebè àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Èyí sì múnú bí àwọn olórí ìsìn burúkú burúkú. Bákan náà, Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 37, tá a pín lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, “Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!” ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn yàn láti fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí láti kẹ̀yìn sí i.
Jèhófà Gba “Àgọ́ Júdà” Là
13. Kí ni gbólóhùn náà, “àgọ́ Júdà” túmọ̀ sí, kí sì nìdí tí Jèhófà fi máa gbà wọ́n là?
13 Ka Sekaráyà 12:7, 8. Ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, àwọn èèyàn máa ń lo àgọ́ dáadáa, pàápàá àwọn darandaran àtàwọn àgbẹ̀. Àwọn wọ̀nyí á sì nílò ààbò gan-an táwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá bá wá gbógun ja ìlú Jerúsálẹ́mù, nítorí pé àwọn ni wọ́n á kọ́kọ́ kàn. Ohun tí gbólóhùn náà “àgọ́ Júdà” túmọ̀ sí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ni pé, pápá gbalasa ni àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró wà lóde òní, kì í ṣe inú àwọn ìlú ńlá olódi. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń fi ìgboyà gbèjà àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Mèsáyà náà. “Àgọ́ Júdà” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun máa “kọ́kọ́” gbà là, torí pé àwọn ni Sátánì dìídì dojú ìjà kọ.
14. Báwo ni Jèhófà ṣe ń gbèjà àwọn tó wà nínú “àgọ́ Júdà” tí kò sì jẹ́ kí wọ́n kọsẹ̀?
14 Ká sòótọ́, àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn fi hàn pé Jèhófà ń gbèjà àwọn ikọ̀ tó ń ṣojú fún Ìjọba Ọlọ́run nínú “àgọ́” wọn, ní pápá gbalasa.b Jèhófà ò jẹ́ kí wọ́n “kọsẹ̀” ní ti pé ó ń fún wọn lágbára, ó sì ń mú kí wọ́n nígboyà bíi Dáfídì, ọba tó jẹ́ jagunjagun.
15. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń “wá ọ̀nà láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ́,” ìgbà wo ló sì máa ṣe èyí?
15 Ka Sekaráyà 12:9. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń “wá ọ̀nà láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ́”? Ìdí ni pé wọ́n ò yéé ta ko Ìjọba Mèsáyà náà. Nítorí pé wọ́n ń fòòró àwọn èèyàn Ọlọ́run, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wọn, ìdájọ́ Ọlọ́run tọ́ sí wọn. Àwọn aṣojú Sátánì lórí ilẹ̀ ayé máa tó gbógun àjàkẹ́yìn ja àwọn olùjọsìn Jèhófà tòótọ́, ohun tí èyí sì máa yọrí sí ni ogun ńlá kan tí Bíbélì pè ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:13-16) Ogun yìí ni Onídàájọ́ Gíga jù lọ náà máa fi gbèjà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, yóò sì sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.—Ìsíkíẹ́lì 38:14-18, 22, 23.
16, 17. (a) Kí ni ‘ohun ìní àjogúnbá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà’? (b) Bá a ṣe ń fara da àtakò Sátánì jẹ́ ẹ̀rí pé a ní kí ni?
16 Sátánì ò ní ohun ìjà tó lè fi sọ ìgbàgbọ́ àwa èèyàn Ọlọ́run jákèjádò ayé di aláìlágbára tàbí èyí tó lè fi paná ìtara wa. A ní àlááfíà, nítorí a mọ̀ pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn pẹ̀lú agbára rẹ̀ tó ń gbani là, èyí sì ni ‘ohun ìní àjogúnbá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà.’ (Aísáyà 54:17) Kò sẹ́ni tó lè gba àlááfíà àti aásìkí tẹ̀mí tá a ní. (Sáàmù 118:6) Sátánì kò ní yéé mú káwọn èèyàn máa ṣàtakò sí wa láti lè kó ìpọ́njú bá wa. Àmọ́, bá a ṣe ń dúró ṣinṣin tá a sì ń fara da ẹ̀gàn jẹ́ ẹ̀rí pé a ní ẹ̀mí Ọlọ́run. (1 Pétérù 4:14) À ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Jèhófà kárí ayé. Bí ohun ìjà téèyàn fi ń kó ṣìbáṣìbo bá ọ̀tá, ọ̀pọ̀ “òkúta kànnàkànnà” làwọn èèyàn ti jù lu àwa èèyàn Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Àmọ́, agbára Jèhófà ń mú ká borí irú àwọn òkúta bẹ́ẹ̀, a sì ń sọ agbára wọn dòfo. (Sekaráyà 9:15) Kò sẹ́ni tó lè pa àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó dúró ṣinṣin tì wọ́n lẹ́nu mọ́!
17 À ń retí ìgbà tá a máa bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àtakò Èṣù. Ó mà tù wá nínú gan-an o láti mọ̀ pé ‘ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí wa kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí wa nínú ìdájọ́ ni a óò dá lẹ́bi’!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.
b Tó o bá fẹ́ àlàyé kíkún sí i, wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 675 àti 676. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ló fi hàn pé ohun ìjà tí Sátánì ń lò kò borí?
• Báwo ni Jerúsálẹ́mù tọ̀run ṣe di “òkúta ẹrù ìnira”?
• Báwo ni Jèhófà ṣe gba “àgọ́ Júdà” là?
• Kí ló dá ẹ lójú bí Amágẹ́dọ́nì ṣe ń sún mọ́lé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Pẹ̀lú bí Sátánì ṣe gbógun tó, ìṣòtítọ́ àwọn èèyàn Jèhófà lórílẹ̀-èdè Alibéníà ò yingin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jésù já àwọn alátakò rẹ̀ nírọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Kò sóhun ìjà kankan táwọn èèyàn lè ṣe sáwọn tó ń wàásù ìhìn rere tí yóò ṣàṣeyọrí