Ori 19
“Ogun Ọjọ Nla Ọlọrun Olodumare” Tí Ó Rọ̀dẹ̀dẹ̀
1. (a) Ki ni awọn orilẹ-ede laipẹ yoo mu ki o pọndandan fun Ọlọrun Olodumare lati kọ sinu “iwe Ogun OLUWA,” ki ni iwe naa si jẹ? (b) Pẹlu ogun wo ni iwe yẹn yoo fi dé otente atobilọla rẹ̀?
AWỌN orilẹ-ede nigbẹhin-gbẹhin ti wa dé akoko naa ti wọn ń mu ki o pọndandan fun Ọlọrun Olodumare lati kọ ipari titobilọla sinu “iwe Ogun OLUWA.” (Numeri 21:14) Iwe gidi yẹn jẹ́ akọsilẹ awọn ogun ti Jehofa jà nititori awọn eniyan rẹ̀. Dajudaju Mose kà á. O si ṣeeṣe ki iwe naa ti ní ibẹrẹ rẹ̀ pẹlu ija ogun alaṣeyọri si rere ti Abrahamu lodisi awọn ọba ti wọn di Loti ní igbekun, ti Jehofa si ja fun Abrahamu. (Genesisi 14:1-16, 20) Laipẹ si isinsinyi, a o mu “iwe Ogun OLUWA” wa si otente atobilọla rẹ̀ pẹlu ori titun kan ti a fi kun un—akọsilẹ iṣẹgun ologo julọ rẹ̀. Eyi yoo jẹ́ “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” ní Armageddoni, ipari patapata kan niti eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi. (Ìfihàn 16:14, 16) Gbogbo “iwe” naa latokedelẹ yoo fihan pe Ọlọrun Olodumare kò tii figbakanri padanu ninu ija, tabi ogun eyikeyii.
2, 3. (a) Lati igba ibẹrẹ isin Kristian, ki ni o ti jẹ́ otitọ nipa Jehofa niti jija “ogun” ti awọn ologun? (b) Ki ni yoo ru Jehofa soke sinu jija fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ní akoko wa?
2 Nitootọ, lati igba ibẹrẹ isin Kristian titi di isinsinyi, Jehofa ti daabobo awọn eniyan rẹ̀ nipasẹ awọn ohun-eelo miiran yatọ si ogun ti awọn ologun. Kò tii si igba kan rí ti Jehofa ti jà fun awọn Kristian Ẹlẹ́rìí rẹ̀ bi ó ti ṣe fun Israeli labẹ Ofin Mose. Ṣugbọn akoko yoo de ní ọjọ iwaju ti ó sunmọle nigba ti oun yoo jà lọna ti ologun fun awọn iranṣẹ rẹ̀ olufọkansin ti ode-oni. Ki ni ohun ti yoo ru ogun naa ní Armageddoni soke?
3 Ṣaaju ibẹsilẹ ogun Ọlọrun, Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye, ni a ó ti parun. Satani Eṣu ati awọn oṣelu aláìlẹ́sìn olupa Babiloni Nla run yoo binu si otitọ naa pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nikan ni yoo jẹ́ ẹgbẹ ti o laaja. Ọwọ́ awọn alaṣẹ ayé ki yoo lè tẹ gongo wọn ti nini ayé ti kò ní ọlọrun kan. Nitori naa, nisinsinyi, wọn tẹsiwaju si ikọluni àfi gbogbo-okun-ṣe si awọn olujọsin Jehofa, ipo ọba-alaṣẹ agbaye ẹni ti wọn sẹ́ ti wọn si ṣayagbangba si! Nipa bayii, wọn yoo maa bá Ọlọrun jà niti gidi.—Ìfihàn 17:14, 16; fiwe Iṣe 5:39.
“Jehofa Awọn Ọmọ Ogun” Tun Bẹrẹ Awọn Igbokegbodo Ologun Rẹ̀
4. (a) Bawo ni Jehofa ṣe huwapada si ikọluni Gogu? (b) Ki ni idahunpada yẹn yoo jẹwọ rẹ̀, ní ibamu pẹlu orukọ naa “Jehofa awọn ọmọ ogun”?
4 Satani Eṣu, Gogu ara Magogu iṣapẹẹrẹ naa, ni yoo wewee ikọluni yii si awọn eniyan Jehofa. Nigba ti Gogu ba lo agbo ẹgbaagbeje awọn alaigba Ọlọrun gbọ rẹ̀ lati kọlu awọn eniyan Jehofa, lati piyẹ wọn ati lati pa wọn run, Jehofa yoo wa dasi ọran naa yoo si jà fun awọn eniyan rẹ̀, bi a ti sọ tẹ́lẹ̀ ninu Esekieli 38:2, 12, 18-20. Idahunpada Jehofa ni a tun sọ tẹ́lẹ̀ ninu Sekariah 14:3 pe: “Nigba naa ni Oluwa yoo jade lọ, yoo si ba awọn orilẹ-ede wọnni jà, gẹgẹ bi o ti ń ja ní ọjọ ogun.” Ní ọna yii Ọlọrun Bibeli yoo fun gbogbo awọn orilẹ-ede ode-oni ní ẹri pe Ọlọrun Ajagun ni oun ṣi jẹ́, gan-an gẹgẹ bi o ti ṣe jẹ́ ní awọn ọjọ Israeli igbaani, bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Iwe Mímọ́ Lede Heberu, nigba ti a ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi “Jehofa awọn ọmọ ogun” ní 260 igba.—Orin Dafidi 24:10; 84:12, NW.
5, 6. (a) Ogun wo ni o wa bẹsilẹ nisinsinyi, ta si ni o ṣaaju awọn ẹgbẹ ogun ọ̀run naa lọ sinu ogun? (b) Akọsilẹ wo ni aposteli Johannu funni nipa awọn ẹgbẹ ogun ọ̀run ti ń lọ sinu ogun?
5 Nigba ti “ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” ba dé, yoo jẹ́ akoko fun “ogun” ti yoo samisi ọjọ naa. Jehofa yoo fun Ọgagun Agba Julọ rẹ̀, Jesu Kristi, ní àmì. Ní orukọ Jehofa, oun ati ẹgbẹ ogun ọ̀run ti ẹgbaagbeje awọn angẹli rọ́ wọ inu ija ogun naa, bi pe wọn gun awọn ẹṣin ogun. (Juda 14, 15) Gẹgẹ bi akọrohin ogun kan, aposteli Johannu fun wa ní irohin iṣaaju nipa iṣẹgun àṣẹ́tán yán-án-yán ti Ọgagun Agba Julọ tí Jehofa yoo jere ninu “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare”:
6 “Mo si ri ọ̀run ṣisilẹ, si wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni ti ó si jokoo lori rẹ̀ ni a ń pe ní Olododo ati Oloootọ, ninu ododo ni o si ń ṣe idajọ, ti o si ń jagun. Oju rẹ̀ dabi ọwọ́ ina, ati ní ori rẹ̀ ni ade pupọ wà . . . Awọn ogun ti ń bẹ ní ọ̀run ti a wọ̀ ní aṣọ ọgbọ wiwẹ, funfun ati mímọ́, si ń tọ̀ ọ́ lẹhin lori ẹṣin funfun. Ati lati ẹnu rẹ̀ ni ida mimu ti ń jade lọ, ki o lè maa fi ṣá awọn orilẹ-ede: oun o si maa fi ọpa irin ṣe akoso wọn: o sì ń tẹ ifunti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare. O si ní lara aṣọ rẹ̀ ati ní itan rẹ̀ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA.”—Ìfihàn 19:11-16.
7. Ki ni titẹ ifunti iṣapẹẹrẹ ibinu Ọlọrun tumọsi fun awọn orilẹ-ede?
7 Ọgagun Agba Julọ ọlọla ọba naa, Jesu Kristi, ṣaaju ẹgbẹ ogun ọ̀run ninu ikọluni ajaṣẹgun lodisi apapọ gbogbo awọn ọta ní Armageddoni. O yí pápá ogun naa pada si ifunti nla ràgàjì kan! Niwọn igba ti Ọba awọn ọba ti “ń tẹ ifunti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare,” eyi fihan pe awọn orilẹ-ede ni a o tẹ̀ ni àtẹ̀rẹ́ patapata. A o rọ wọn dà sinu “ifunti” titobi gìrìwò naa bi eso ajara pipọn, nibi ti a o ti da “irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare” si wọn lori pẹlu iyọrisi titẹ wọn rẹ́. Ẹgbẹ ogun ọ̀run yoo darapọ ninu titẹ “ifunti nla ibinu Ọlọrun.”—Ìfihàn 14:18-20.
8. Bawo ni Jehofa ṣe ṣapejuwe awọn ọgbọn ẹ̀wẹ́ ogun rẹ̀?
8 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lori ilẹ̀-ayé kò gbe “ida” soke lodisi agbo ẹgbaagbeje Gogu, ṣugbọn Jehofa ṣe bẹẹ. Ija tirẹ ni eyi! Ati nisinsinyi nigbẹhin-gbẹhin, awọn orilẹ-ede ayé yii ti ó ti goke agba ninu imọ ijinlẹ yoo ri i ti ń jà! Fetisilẹ bi o ti ń ṣapejuwe awọn ọgbọn ẹ̀wẹ́ ogun rẹ̀: “Emi o si pe ida si i [Gogu] lori gbogbo oke mi, ni Oluwa Ọlọrun wi: ida olukuluku yoo si dojukọ arakunrin rẹ̀. Emi o si fi ajakalẹ arun ati ẹjẹ bá a wijọ; emi o si rọ ojo pupọ, ati yinyin nla, ina ati brimstone [imi ọjọ], si i lori ati sori awọn ẹgbẹ rẹ̀, ati sori ọpọlọpọ eniyan ti ó wà pẹlu rẹ̀. Emi o si gbe araami leke, emi o si ya araami si mímọ́; emi o si di mímọ̀ loju ọpọlọpọ orilẹ-ede, wọn o si mọ̀ pe emi ni [Jehofa, NW].”—Esekieli 38:21-23.
A Lo Awọn Ohun Ija Ogun Ọrun Lodisi Awọn Ọta
9. Awọn ohun ija ogun wo ni Jehofa yoo lo lodisi awọn ọta rẹ̀?
9 Bi awọn ohun ija ogun, Jehofa yoo lo awọn ipá ìṣẹ̀dá: ejiwọwọ ojo ti ń yalulẹ di àgbàrá akúnlé-kúnnà, okuta yìnyín bàǹtìbàǹtì aṣekupani, ìyalulẹ̀ ina ati imi-ọjọ ajáṣòòròṣò, omi ti ń bú jade lati inu ọgbun ilẹ̀-ayé, ati manamana aara ti ń sán gààrà. Pẹlu kikọ yẹ̀rì-yẹ̀rì awọn ohun-eelo Ọlọrun fun iku awọn ọta rẹ̀, imọlẹ naa yoo tàn yanranyanran lọsan-an ati loru debi pe oorun ati oṣupa ti àdánidá yoo farahan bi eyi ti kò wulo mọ́ fun titanmọlẹ. Yoo dabi ẹni pe wọn duro jẹẹ, ti wọn kò ṣiṣẹ mọ bi atànmọ́lẹ̀ ṣugbọn ti wọn ń jẹ ki awọn ohun ija agbokeere-ṣọṣẹ ti ń tan yanranyanran ti Jehofa maa dárà pẹlu agbara itanmọlẹ. (Habakkuku 3:10, 11) Jehofa ní akunwọsilẹ awọn ohun abàmì àdánidá ní ìkáwọ́ rẹ̀ fun jíja ija.—Joṣua 10:11; Jobu 38:22, 23, 29.
10. Ní ibamu pẹlu Sekariah 14:12, awọn ohun miiran wo ni Jehofa yoo lo ní “ọjọ ija” naa ti ń bọ?
10 Ní “ọjọ ija” naa ti ń bọ, Jehofa bakan naa yoo lo ajakalẹ arun ati “arun.” Wolii naa Sekariah kọwe nipa eyi pe: “Eyi ni yoo si jẹ́ arun ti Oluwa yoo fi kọlu gbogbo awọn eniyan ti ó ti bá Jerusalemu jà; ẹran ara wọn yoo rù nigba ti wọn duro ni ẹsẹ wọn, oju wọn yoo sì rà ní iho wọn, ahọn wọn yoo si sọ́kì ní ẹnu wọn.”—Sekariah 14:12.
11. Ki ni yoo ṣẹlẹ nigba ti “arun” naa ba kọlu awọn ọmọ ogun ti wọn ń gbejako awọn eniyan Jehofa?
11 Boya “arun” naa yoo jẹ́ niti gidi tabi bẹẹkọ, yoo pa awọn ẹnu ti wọn là silẹ lati sọ awọn idayafoni bibanilẹru jade mọ́! Awọn ahọn ti rà danu! Agbara iriran yoo dẹkun, ki o baa lè ṣẹlẹ pe awọn akọluni oloju riroro naa yoo wulẹ kan maa lu afẹfẹ ni lairiran. Awọn oju ti rà danu! Awọn iṣan ara awọn akikanju ologun nla yoo padanu okun wọn nigba ti wọn duro lori ẹsẹ wọn—kii ṣe nigba ti wọn nà gbalaja silẹ bi oku. Ẹran ara ti ó bo igbekalẹ egungun wọn ti rà danu!—Fiwe Habakkuku 3:5.
12. Bawo ni “arun” naa yoo ṣe nipa lori awọn ibudo ologun ati ohun-eelo awọn ọta naa?
12 “Arun” naa kọlu awọn ibudo ologun wọn lojiji. Awọn ohun-eelo àgbékiri fun ṣiṣe ikọluni naa ni a sọ di alaiwulo ti kò lè ta pútú! (Sekariah 14:15; fiwe Eksodu 14:24, 25.) Awọn ọ̀rọ̀ Sekariah 14:6 (NW) fihan bi awọn ohun-eelo ologun wọn yoo ṣe di alaiwulo tó pe: “O si gbọdọ ṣẹlẹ ni ọjọ naa pe ki yoo sì si imọlẹ iyebiye—awọn nǹkan yoo dì gbagidi.” Ko si imọlẹ ojurere atọrunwa kankan ti yoo tàn sori wọn. Imọlẹ atọwọda ti imọ ijinlẹ ode-oni ki yoo mu okunkun ti airojurere atọrunwa kuro. Awọn ohun-eelo ti a lè mú ṣiṣẹ ní yoo di alaigbeṣẹ bi eyi ti otutu mu di lilegbangidi—ni dídì gbagidi.
13. Ki ni yoo fikun ipaya ti Jehofa yoo ru soke laaarin awọn akọluni naa?
13 Gbogbo eyi ti panilaya to! Ṣugbọn ní afikun si ipaya naa ni idarudapọ ti Ọlọrun yoo ru soke laaarin awọn akọluni naa. Iṣọkan wọn ní gbigbe igbesẹ lodisi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a o fọ́ yanga. Bi awọn elere ija iku ti wọn fi aṣibori ti ń boniloju bo ori wọn ninu gbọngan ere ilẹ Romu, wọn yoo maa kọlu ẹnikinni keji wọn lairiran. Idarudapọ aṣekupani naa yoo tankalẹ bi wọn ti ń lọwọ ninu jijumọ pa araawọn.—Sekariah 14:13.
14. (a) Bawo ni ipakupa naa yoo ti gbooro to ní akoko naa, bawo si ni awọn ẹyẹ ati ẹranko igbẹ yoo ṣe nipin-in ninu anfaani ijagunmolu Jehofa? (b) Ki ni yoo jẹ́ iṣarasihuwa awọn olulaaja si “awọn ti Oluwa pa”?
14 Ipakupa alapalu ọjọ ti o ju gbogbo ọjọ lọ naa yoo gadabu, nitori awọn ẹgbẹ ogun ti wọn tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ niha ọdọ Gogu ninu ija ogun naa yoo pọ̀ rẹpẹtẹ. (Ìfihàn 19:19-21) Iyẹn nitootọ yoo jẹ́ ìwàyá ija kárí-ayé kan, nitori ko si iha kankan lori ilẹ̀-ayé ti yoo yèbọ́ ninu iparun naa. Siwaju sii, awọn wọnni ti a pa ní Armageddoni ni a kò ní tẹ sinu awọn iboji pẹlu awọn ami akọle lati fi ṣeranti wọn. Oniruuru awọn ẹyẹ ati ẹranko igbẹ yoo nipin-in ninu anfaani iṣẹgun Ọlọrun ati, lẹsẹkan naa, ṣeranwọ lati palẹ ọpọlọpọ oku mọ́ ti wọn yoo fọn kaakiri sori ilẹ̀ bi ajilẹ, ti awọn olulaaja yoo koriira, ti wọn ki yoo kedaro fun tabi sin. (Esekieli 39:1-5, 17-20; Ìfihàn 19:17, 18) “Awọn ti Oluwa pa” yoo ti gba ẹ̀gàn ayeraye fun araawọn.—Jeremiah 25:32, 33; Isaiah 66:23, 24.
A Ṣe Orukọ Jehofa Lọ́ṣọ̀ọ́
15. Iṣẹlẹ alailẹgbẹ wo ni a o ti ṣe aṣepari rẹ̀ nigba naa, ati pẹlu iyọrisi wo lori orukọ Jehofa?
15 Nipa bayii, “Jehofa awọn ọmọ ogun” nipasẹ Ọgagun Agba Julọ rẹ̀, Jesu Kristi, yoo jere ogo ti kii ṣa fun araarẹ̀. Iṣẹlẹ ti ó ga julọ ninu itan agbaye ni a o ti ṣe aṣepari rẹ̀—idalare ipo ọba-alaṣẹ agbaye Jehofa ati yiya orukọ mímọ́ rẹ̀ si mímọ́. (Esekieli 38:23; 39:6, 7) Jehofa yoo ṣe orukọ kan fun araarẹ̀ eyi ti yoo tayọ rekọja ohunkohun miiran ti a tii ṣapejuwe rẹ̀ ri ninu “iwe Ogun OLUWA” ati ninu Iwe Mímọ́ Lede Heberu ti Bibeli Mímọ́. (Fiwe Isaiah 63:12-14.) Ẹ wo bi orukọ ti Jehofa yoo ṣe fun araarẹ̀ nipasẹ iṣẹgun onibẹru ọlọwọ rẹ̀ ninu “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” yoo ti lẹ̀wá to! Pẹlu iho ayọ̀ iṣẹgun, gbogbo ololufẹ orukọ yẹn ni yoo yin in titi ayeraye, ti wọn yoo maa kọrin iyin rẹ̀ jade!
16. Loju iwoye “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” ti o rọ̀dẹ̀dẹ̀, adura wo ni a gba nitori “ogunlọgọ nla” naa?
16 Óò Jehofa awọn ọmọ ogun, maa tẹsiwaju, nigba naa, sinu igbesẹ ija ogun, pẹlu Ọmọkunrin rẹ ọba, Jesu Kristi ní ẹgbẹ rẹ! (Orin Dafidi 110:5, 6) Jẹ ki awọn ẹlẹ́rìí oloootọ rẹ lori ilẹ̀-ayé di awọn ẹlẹ́rìí alayọ ti iṣẹgun alailẹgbẹ rẹ nipasẹ Ọba rẹ Jesu Kristi ninu “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare.” Jẹ ki “ogunlọgọ nla” naa fi pẹlu ayọ̀ “jade lati inu ipọnju nla” lati jẹ́ awọn ẹlẹ́rìí rẹ ori ilẹ̀-ayé titilae. (Ìfihàn 7:14) Labẹ itọju onifẹẹ rẹ, jẹ́ ki wọn laaja bọ sinu Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” rẹ aṣẹgun nibi ti ogun ki yoo ti si. Jẹ ki wọn jẹ́ ẹri ṣiṣeefojuri fun awọn oku ti a ji dide ní idalare ipo ọba-alaṣẹ naa ti ó jẹ́ tirẹ pẹlu ẹtọ lori gbogbo agbaye. O ṣeun pupọ fun kíkọ apa ipari titobilọla sinu “iwe Ogun OLUWA.” Titi ayeraye, jẹ́ ki akọsilẹ iṣẹlẹ iṣẹgun alailafiwe rẹ yii wa ninu akojọpọ itan agbaye!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 156, 157]
“Jehofa awọn ọmọ ogun” yoo gbogunti awọn orilẹ-ede