Ẹ̀KỌ́ 36
Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo
Gbogbo wa la mọyì pé káwọn ọ̀rẹ́ wa jẹ́ olóòótọ́. Bákan náà, tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́, kò rọrùn rárá láti jẹ́ olóòótọ́, torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ aláìṣòótọ́ láyé tá a wà yìí. Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo?
1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká jẹ́ olóòótọ́?
Tá a bá ń ṣòótọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì bọ̀wọ̀ fún un. Rò ó wò ná: Jèhófà mọ gbogbo ohun tá à ń rò àtohun tá à ń ṣe. (Hébérù 4:13) Ó mọ àwọn ìgbà tá a bá jẹ́ olóòótọ́, ó sì mọyì rẹ̀ gan-an. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Jèhófà kórìíra oníbékebèke, ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.”—Òwe 3:32.
2. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́?
Jèhófà fẹ́ ká ‘máa bá ara wa sọ òtítọ́.’ (Sekaráyà 8:16, 17) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Bóyá àwọn ìdílé wa là ń bá sọ̀rọ̀, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, kò yẹ ká máa parọ́ tàbí ká fún wọn láwọn ìsọfúnni tó ń ṣini lọ́nà. Àwọn olóòótọ́ kì í ja àwọn míì lólè tàbí kí wọ́n lù wọ́n ní jìbìtì. (Ka Òwe 24:28 àti Éfésù 4:28.) Bákan náà, wọ́n máa ń san àwọn owó tó yẹ kí wọ́n san fún ìjọba. (Róòmù 13:5-7) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, tá a sì tún ń jẹ́ olóòótọ́ láwọn ọ̀nà míì, ńṣe là ń fi hàn pé a “jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
3. Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá jẹ́ olóòótọ́?
Táwọn èèyàn bá mọ̀ pé olóòótọ́ ni wá, wọ́n máa fọkàn tán wa. Ọkàn àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ á balẹ̀, a sì máa dà bí ọmọ ìyá. Àwa náà á sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Bákan náà, tá a bá jẹ́ olóòótọ́, ńṣe là ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́,” èyí sì máa jẹ́ káwọn míì dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn tòótọ́.—Títù 2:10.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo ìdí tí Jèhófà fi fẹ́ kó o jẹ́ olóòótọ́ àti àǹfààní tí wàá rí tó o bá jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tó ò ń ṣe.
4. Inú Jèhófà máa ń dùn sí àwọn olóòótọ́
Ka Sáàmù 44:21 àti Málákì 3:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu kẹ́nì kan rò pé òun lè fi òótọ́ pa mọ́ fún Ọlọ́run?
Báwo lo ṣe rò pé ó máa ń rí lára Jèhófà tá a bá ń sọ òótọ́, bí kò bá tiẹ̀ rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?
5. Jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé kò bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo nǹkan. Àmọ́, jẹ́ ká wo ìdí tó fi yẹ ká máa jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Wo FÍDÍÒ yìí.
Ka Hébérù 13:18, lẹ́yìn náà kó o sọ bá a ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ . . .
nínú ìdílé wa.
ní ibiṣẹ́ tàbí iléèwé.
nínú àwọn nǹkan míì.
6. A máa jàǹfààní púpọ̀ tá a bá jẹ́ olóòótọ́
Nígbà míì, ó lè dà bíi pé òótọ́ tá a sọ ló kó wa sí wàhálà. Àmọ́, nígbà tó bá yá àwa náà á rí i pé kò sóhun tó dáa tó kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. Ka Sáàmù 34:12-16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo?
A. Táwọn tọkọtaya bá jẹ́ olóòótọ́, wọ́n á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn
B. Táwọn òṣìṣẹ́ bá jẹ́ olóòótọ́, ọ̀gá wọn á fọkàn tán wọn
D. Táwọn aráàlú bá jẹ́ olóòótọ́, wọ́n á lórúkọ rere lọ́dọ̀ ìjọba
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò sóhun tó burú téèyàn bá ń pa irọ́ kéékèèké.”
Kí nìdí tó o fi gbà pé gbogbo irọ́ ni Jèhófà kórìíra?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn.
Kí lo rí kọ́?
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́?
Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu kẹ́nì kan ronú pé òun lè fi òótọ́ pa mọ́ fún Jèhófà?
Kí nìdí tó fi wù ẹ́ láti máa jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo?
ṢÈWÁDÌÍ
Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti jẹ́ olóòótọ́?
Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń mú ìlérí wa ṣẹ?
Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o máa sanwó orí, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ò fàwọn owó náà ṣohun tó yẹ kí wọ́n fi ṣe.
“Ṣé Dandan Ni Kéèyàn Máa San Owó Orí?” (Ilé Ìṣọ́, September 1, 2011)
Kí ló mú kí ọkùnrin oníjìbìtì kan yíwà pa dà tó sì di olóòótọ́?
“Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Pé Jèhófà Jẹ́ Aláàánú Ó sì Ń Dárí Jini” (Ilé Ìṣọ́, May 1, 2015)