“Ẹ Fẹ́ Òtítọ́ àti Àlàáfíà”!
“Ọ̀rọ̀ Oluwa àwọn ọmọ ogun sì tọ̀ mí wá wí pé, . . . ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”—SEKARIAH 8:18, 19.
1, 2. (a) Àkọsílẹ̀ wo ni aráyé ní, ní ti àlàáfíà? (b) Èé ṣe tí ayé ìsinsìnyí kò fi ní rí ojúlówó àlàáfíà láé?
“AYÉ kò lálàáfíà rí. Níbì kan—àti lọ́pọ̀ ìgbà, níbi púpọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà—ni ogun ti ń jà.” Ohun tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Milton Mayer ti Yunifásítì Massachusetts, U.S.A., sọ nìyẹn. Ẹ wo irú ọ̀rọ̀ bíbani nínú jẹ́ nípa aráyé, tí èyí jẹ́! Lóòótọ́, aráyé fẹ́ àlàáfíà. Àwọn òṣèlù ti gbìyànjú gbogbo ọ̀nà láti lè jẹ́ kí ó jọba, láti orí Pax Romana ti àkókò Romu dé orí ìlànà “Ìparun Àjùmọ̀pín Dídájú” nígbà Ogun Tútù. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, níkẹyìn pátápátá gbogbo ìsapá wọn já sí pàbó. Gẹ́gẹ́ bí Isaiah ti sọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ‘àwọn ikọ̀ àlàáfíà ti sọkún kíkorò.’ (Isaiah 33:7) Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀?
2 Ó jẹ́ nítorí pé, àlàáfíà wíwà pẹ́ títí ní láti wá láti ibi tí kò ti sí ìkórìíra àti ìwọra; a gbọ́dọ̀ gbé e karí òtítọ́. A kò lè gbé àlàáfíà karí irọ́. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jehofa fi sọ nígbà tí ó ń ṣèlérí ìmúpadàbọ̀sípò àti àlàáfíà fún Israeli ìgbàanì pé: “Èmi óò na àlàáfíà sí i bí odò, àti ògo àwọn Kèfèrí bí odò ṣíṣàn.” (Isaiah 66:12) “Apànìyàn,” amọ̀ọ́mọ̀pànìyàn, ni ọlọrun ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí, Satani Èṣù, “òpùrọ́ ati baba irọ́” sì ni. (Johannu 8:44; 2 Korinti 4:4) Báwo ni ayé tí ó ní irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ ṣe lè ní àlàáfíà?
3. Ẹ̀bùn pípẹtẹrí wo ni Jehofa ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀, láìka pé wọ́n ń gbé nínú ayé onídààmú sí?
3 Ṣùgbọ́n, lọ́nà tí ó pẹtẹrí, Jehofa ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àlàáfíà àní nígbà tí wọ́n ṣì ń gbé nínú ayé Satani tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ pàápàá. (Johannu 17:16) Ní ọ̀rúndún kẹfà Ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípasẹ̀ Jeremiah, ó sì fún orílẹ̀-èdè àkànṣe rẹ̀ ní “àlàáfíà àti òtítọ́” nígbà tí ó mú wọn padà sí ilẹ̀ wọn. (Jeremiah 33:6) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí pẹ̀lú, ó ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní “àlàáfíà àti òtítọ́” ní “ilẹ̀” wọn, tàbí ipò tẹ̀mí ti orí ilẹ̀ ayé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti wàláàyè la àwọn àkókò onídààmú tí ó burú jù lọ ti ayé yìí ti nírìírí rẹ̀ títí di ìsinsìnyí já. (Isaiah 66:8; Matteu 24:7-13; Ìṣípayá 6:1-8) Bí a ṣe ń bá ìjíròrò wa nìṣó nínú Sekariah orí 8, a óò ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ sí i, ti àlàáfíà àti òtítọ́ tí Ọlọrun ń fúnni yìí, a óò sì rí ohun tí a lè ṣe láti pa ìpín wa nínú rẹ̀ mọ́.
‘Ẹ Jẹ́ Kí Ọwọ́ Yin Le’
4. Báwo ni Sekariah ṣe ní kí Israeli gbégbèésẹ̀ bí wọn yóò bá nírìírí àlàáfíà?
4 Ní ìgbà kẹfà nínú Sekariah orí 8, a gbọ́ ìkéde amọ́kànyọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Jehofa pé: “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí pé, Jẹ́ kí ọwọ́ yin kí ó le, ẹ̀yin tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ní ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Oluwa àwọn ọmọ ogun lélẹ̀, kí a baà lè kọ́ tẹ́ḿpìlì. Nítorí pé ṣáájú ọjọ́ wọnnì [owó, NW] ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni [owó, NW] ọ̀yà ẹran pẹ̀lú; bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni tí ń jáde lọ, tàbí ẹni tí ń wọlé bọ̀, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀.”—Sekariah 8:9, 10.
5, 6. (a) Nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó dé bá Israeli, báwo ni ipò nǹkan ti rí ní Israeli? (b) Ìyípadà wo ni Jehofa ṣèlérí fún Israeli, bí ó bá fi ìjọsìn rẹ̀ sí ipò kíní?
5 Sekariah sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nígbà tí a ṣì ń tún tẹ́ḿpìlì náà kọ́ ní Jerusalemu. Ṣáájú, ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá àwọn ọmọ Israeli tí wọ́n padà wá láti Babiloni, wọ́n sì ti dáwọ́ kíkọ́ tẹ́ḿpìlì náà dúró. Nítorí pé, wọ́n yíjú sí ìtùnú ara wọn, wọn kò rí ìbùkún kankan àti àlàáfíà kankan gbà láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọ́n ń dáko lórí ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bójú tó ọgbà àjàrà wọn, wọn kò láásìkí. (Haggai 1:3-6) Ṣe ni ó dà bí pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ‘owó ọ̀yà tí kò tó nǹkan.’
6 Nísinsìnyí tí wọ́n ti tún tẹ́ḿpìlì náà kọ́, Sekariah fún àwọn Júù níṣìírí láti ‘mú ọwọ́ wọn le,’ kí wọ́n fi ìjọsìn Jehofa sí ipò kíní tìgboyàtìgboyà. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀? “Nísinsìnyí èmi kì yóò ṣe sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbà àtijọ́ wọnnì, ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí. Nítorí irúgbìn [àlàáfíà, NW] yóò gbilẹ̀: àjàrà yóò so èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mú ìrì wọn wá: èmi óò sì mú kí àwọn ìyókù ènìyàn yìí ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti jẹ́ ègún láàárín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israeli, bẹ́ẹ̀ ni èmi óò gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin óò sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọwọ́ yín kí ó le.” (Sekariah 8:11-13) Bí Israeli yóò bá gbégbèésẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu, yóò láásìkí. Ṣáájú, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá fẹ́ fúnni ní àpẹẹrẹ ẹni ègún, wọ́n lè nàka sí Israeli. Wàyí o, àpẹẹrẹ ẹni ìbùkún ni Israeli yóò jẹ́. Ẹ wo ìdí dídára ta yọ tí ó jẹ́ láti ‘jẹ́ kí ọwọ́ wọn kí ó le’!
7. (a) Àwọn ìyípadà amọ́kànyọ̀ wo ni àwọn ènìyàn Jehofa nírìírí rẹ̀, tí ó dé ìwọ̀n gíga ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1995? (b) Ní wíwo ìròyìn ọdọọdún, àwọn orílẹ̀-èdè wo ni o rí i pé, wọ́n ní àkọsílẹ̀ pípẹtẹrí ní ti àwọn akéde, aṣáájú ọ̀nà, ìpíndọ́gba wákàtí?
7 Lónìí ńkọ́? Tóò, ní àwọn ọdún tí ó ṣáájú 1919, lọ́nà kan ṣáá, àwọn ènìyàn Jehofa kò ní ìtara tó. Wọn kò di ìdúró aláìdásítọ̀túntòsì mú pátápátá nínú Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n sì ní ìtẹ̀sí láti tẹ̀ lé ènìyàn dípò Ọba wọn, Jesu Kristi. Ní ìyọrísí èyí, a kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan nípasẹ̀ àtakò láti inú àti ẹ̀yìn òde ètò àjọ náà. Nígbà náà, ní 1919, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa, wọ́n jẹ́ kí ọwọ́ wọn le. (Sekariah 4:6) Jehofa fún wọn ní àlàáfíà, wọ́n sì láásìkí lọ́nà bíbùáyà. A rí èyí nínú àkọsílẹ̀ ọdún 75 tí ó ti kọjá, tí ó dé ìwọ̀n gíga ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1995. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ta kété sí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀tanú, àti gbogbo orísun ìkórìíra mìíràn. (1 Johannu 3:14-18) Wọ́n ń ṣiṣẹ́ sin Jehofa pẹ̀lú ojúlówó ìtara nínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ tẹ̀mí. (Heberu 13:15; Ìṣípayá 7:15) Léṣìí níkan, wọ́n lo iye tí ó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Bàbá wọn ọ̀run! Lóṣooṣù, wọ́n ń darí 4,865,060 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ìpíndọ́gba àwọn bí 663,521 lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lóṣooṣù. Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù bá fúnni ní àpẹẹrẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ onítara tòótọ́ nínú ìjọsìn wọn, nígbà míràn, wọ́n máa ń tọ́ka sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
8. Báwo ni àwọn Kristian kọ̀ọ̀kan ṣe lè jàǹfààní nínú “irúgbìn [àlàáfíà, NW]”?
8 Nítorí ìtara wọn, Jehofa ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní “irúgbìn [àlàáfíà, NW].” Ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó bá mú irúgbìn yẹn dàgbà yóò rí i pé àlàáfíà ń dàgbà nínú ọkàn rẹ̀ àti nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Kristian onígbàgbọ́ kọ̀ọ̀kan tí ń lépa àlàáfíà pẹ̀lú Jehofa àti pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń nípìn-ín nínú òtítọ́ àti àlàáfíà àwọn ènìyàn tí ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jehofa. (1 Peteru 3:11; fi wé Jakọbu 3:18.) Ìyẹn kò ha jẹ́ ìyàlẹ́nu bí?
“Ẹ Má Bẹ̀rù”
9. Ìyípadà wo nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, ni Jehofa ṣèlérí?
9 Wàyí o, a óò ka ìkéde keje láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Kí ni? “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí; gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣẹ́ẹ yín níṣẹ̀ẹ́, nígbà tí àwọn bàbá yín mú mi bínú, ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí, tí èmi kò sì ronú pìwà dà. Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalemu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù.”—Sekariah 8:14, 15.
10. Àkọsílẹ̀ wo nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ó fi hàn pé wọn kò bẹ̀rù?
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn Jehofa fọ́n káàkiri lọ́nà tẹ̀mí nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, nínú ọkàn wọn, wọ́n fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́. Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó ti fún wọn ní ìbáwí díẹ̀, Jehofa yí ọ̀nà tí ó gbà ń bá wọn lò padà. (Malaki 3:2-4) Lónìí, a bojú wẹ̀yìn, a sì dúpẹ́ tọkàntọkàn lọ́wọ́ rẹ̀ fún ohun tí ó ti ṣe. Lóòótọ́, a ti jẹ́ “ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” (Matteu 24:9) A ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ sẹ́wọ̀n, àwọn kan tilẹ̀ ti kú pàápàá nítorí ìgbàgbọ́ wọn. A ń dojú kọ ìdágunlá tàbí ìkóguntini lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù kò bà wá. A mọ̀ pé Jehofa lágbára ju alátakò èyíkéyìí lọ, yálà èyí tí a lè fojú rí tàbí tí a kò lè fojú rí. (Isaiah 40:15; Efesu 6:10-13) A kò ní dẹ́kun láti máa kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ náà pé: “Dúró de Oluwa; kí o sì tújú ká, yóò sì mú ọ ní àyà le.”—Orin Dafidi 27:14.
“Ẹ Sọ̀rọ̀ Òtítọ́, Olúkúlùkù sí Ẹnì Kejì Rẹ̀”
11, 12. Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní láti fi sọ́kàn, bí a bá fẹ́ láti nípìn-ín ní kíkún nínú àwọn ìbùkún tí Jehofa ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀?
11 Láti nípìn-ín ní kíkún nínú àwọn ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Jehofa, àwọn ohun kan wà tí a ní láti rántí. Sekariah sọ pé: “Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin óò ṣe: Ẹ sọ̀rọ̀ òtítọ́, olúkúlùkù sí ẹnì kejì rẹ̀; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà níbodè yín wọnnì. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kan kí o ro ibi ní ọkàn rẹ̀ sí ẹnì kejì rẹ̀; ẹ máà fẹ́ ìbúra èké: nítorí gbogbo wọ̀nyí ni mo kórìíra, ni Oluwa wí.”—Sekariah 8:16, 17.
12 Jehofa ń rọ̀ wá láti máa sọ òtítọ́. (Efesu 4:15, 25) Kì í gbọ́ àdúrà àwọn tí ń gbèrò ibi, tí ń fi òtítọ́ pamọ́ nítorí èrè ara ẹni, tàbí tí ń búra èké. (Owe 28:9) Níwọ̀n bí ó ti kórìíra ìpẹ̀yìndà, ó fẹ́ kí a dìrọ̀ mọ́ òtítọ́ Bibeli. (Orin Dafidi 25:5; 2 Johannu 9-11) Síwájú sí i, bíi ti àwọn àgbà ọkùnrin ní àwọn ẹnubodè ìlú ńlá ní Israeli, àwọn alàgbà tí ń bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́ ní láti gbé ìmọ̀ràn àti ìpinnu wọn karí òtítọ́ Bibeli, kì í ṣe lórí èrò ara ẹni. (Johannu 17:17) Jehofa ń fẹ́ kí wọ́n wá “ìdájọ́ . . . àlàáfíà,” kí wọ́n gbìyànjú, gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristian olùṣọ́ àgùntàn, láti mú kí àlàáfíà padà wà láàárín àwọn tí aáwọ̀ wà láàárín wọn, kí wọ́n sì ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ti ronú pìwà dà lọ́wọ́ láti tún rí àlàáfíà Ọlọrun gbà. (Jakọbu 5:14, 15; Juda 23) Lọ́wọ́ kan náà, wọ́n ń pa àlàáfíà ìjọ mọ́, ní fífi tìgboyàtìgboyà lé àwọn tí wọ́n ń da àlàáfíà yẹn rú, nípa mímọ̀ọ́mọ̀ tẹpẹlẹ mọ́ híhùwà àìtọ́ jáde.—1 Korinti 6:9, 10.
“Ayọ̀, àti Dídùn Inú”
13. (a) Ìyípadà wo nípa ààwẹ̀ ni Sekariah sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀? (b) Ààwẹ̀ wo ni wọ́n máa ń gbà ní Israeli?
13 Wàyí o, a gbọ́ ìkéde kẹjọ tí ó jẹ́ ti aláyẹyẹ ìsìn pé: “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí pé; Ààwẹ̀ oṣù kẹrin, àti ti oṣù karùn-ún, àti ààwẹ̀ oṣù keje, àti ti ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀, àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.” (Sekariah 8:19) Lábẹ́ Òfin Mose, àwọn ọmọ Israeli máa ń gbààwẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù láti fi ẹ̀dùn ọkàn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn. (Lefitiku 16:29-31) Ààwẹ̀ mẹ́rin tí Sekariah mẹ́nu kàn ni ó hàn gbangba pé wọ́n gbà láti ṣọ̀fọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣẹ́gun àti ìparun Jerusalemu. (2 Awọn Ọba 25:1-4, 8, 9, 22-26) Ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, a ti tún tẹ́ḿpìlì náà kọ́, àwọn ènìyàn sì ti padà sí Jerusalemu. Ọ̀fọ̀ ti yí padà di inú dídùn, ààwẹ̀ sì lè di àpéjọ àríyá.
14, 15. (a) Báwo ní ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ṣe jẹ́ ìdí pàtàkì fún ayọ̀, kí sì ni èyí yẹ kí ó rán wa létí? (b) Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ìròyìn ọdọọdún, àwọn ilẹ̀ wo ni wọ́n ta yọ ní ti iye àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí?
14 Lónìí, a kì í gbààwẹ̀ tí Sekariah mẹ́nu kàn tàbí ààwẹ̀ tí a pà láṣẹ nínú Òfin. Níwọ̀n bí Jesu ti fi ara rẹ rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, a ń gbádùn àwọn ìbùkún Ọjọ́ Ètùtù kíkọyọyọ jù. Ẹ̀ṣẹ̀ wa di èyí tí a bá wa kájú rẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe lápá kan, ṣùgbọ́n délẹ̀délẹ̀. (Heberu 9:6-14) Ní títẹ̀ lé àṣẹ Àlùfáà Àgbà ti òkè ọ̀run náà, Jesu Kristi, a ń ṣe Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ayẹyẹ ìsìn kan ṣoṣo tí àwọn Kristian ń ṣe. (Luku 22:19, 20) A kò ha nírìírí “ayọ̀, dídùn inú” bí a ti ń péjọ pọ̀ lọ́dọọdún fún ayẹyẹ yìí bí?
15 Léṣìí, 13,147,201 pàdé pọ̀ láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí, ó fi 858,284 lé sí ti 1994. Ẹ wo irú ògìdìgbó ènìyàn tí ìyẹn jẹ́! Fọkàn yàwòrán ìnú dídùn náà nínú 78,620 ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà ṣíṣàjèjì, ṣe ń rọ́ wọ inú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn fún ayẹyẹ yìí. Dájúdájú, a sún gbogbo àwọn tí wọ́n pésẹ̀ láti “fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà” bí wọ́n ṣe ń rántí ikú Ẹni náà tí ó jẹ́ “ọ̀nà ati òtítọ́ ati ìyè,” tí ó sì ń ṣàkóso nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” títóbi lọ́lá ti Jehofa! (Johannu 14:6; Isaiah 9:6) Ayẹyẹ yẹn ní ìtumọ̀ àkànṣe fún àwọn tí ń ṣe é ní àwọn ilẹ̀ tí rúkèrúdò àti ogun ń pọ́n lójú. Ní 1995, díẹ̀ nínú àwọn ará wa fojú rí àwọn ohun ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ tí kò ṣe é fẹnu sọ. Síbẹ̀, ‘àlàáfíà Ọlọrun tí ó ta gbogbo ìrònú yọ ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà wọn àti agbára èrò orí wọn nípasẹ̀ Kristi Jesu.’—Filippi 4:7.
‘Ẹ Jẹ́ Kí A Tu Jehofa Lójú’
16, 17. Báwo ni àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè ṣe lè “tu Jehofa lójú”?
16 Ṣùgbọ́n, níbo ni gbogbo àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ̀n pésẹ̀ sí ibi Ìṣe Ìrántí yẹn ti wá? Ọ̀rọ̀ àsọjáde kẹsàn-án tí Jehofa sọ ṣàlàyé pé: “Báyìí ni Jehofa àwọn ọmọ ogun wí pé, ‘Yóò sì ṣe àwọn ènìyàn àti àwọn olùgbé ìlú ńlá púpọ̀ yóò wá; àwọn olùgbé ìlú ńlá kan yóò sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ti ibòmíràn, wọn yóò sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a tètè lọ tu Jehofa lójú kí a sì wá Jehofa àwọn ọmọ ogun. Èmi fúnra mi pẹ̀lú yóò lọ.” Ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára yóò wá Jehofa àwọn ọmọ ogun ní Jerusalemu àti láti tu Jehofa lójú.’”—Sekariah 8:20-22, NW.
17 Àwọn ènìyàn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí fẹ́ láti “wá Jehofa àwọn ọmọ ogun.” Ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ti ṣe ìyàsímímọ́, àti ìrìbọmi. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn tí wọ́n pésẹ̀ kò tí ì dé ipò yìí. Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn tí wọ́n pésẹ̀ sí Ìṣe Ìrántí ju iye àwọn akéde Ìjọba lọ ní ìlọ́po mẹ́rin tàbí márùn-ún. Ọ̀pọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn wọ̀nyí nílò ìrànlọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó láti tẹ̀ síwájú. Ẹ jẹ́ kí a kọ́ wọn láti máa yọ̀ nínú ìmọ̀ náà pé, Jesu kú fún ẹ̀sẹ̀ wa, pé ó sì ń ṣàkóso nísinsìnyí nínú Ìjọba Ọlọrun. (1 Korinti 5:7, 8; Ìṣípayá 11:15) Ẹ sì jẹ́ kí a fún wọn níṣìírí láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa Ọlọrun, kí wọ́n sì tẹrí ba fún Ọba rẹ̀ tí ó yàn sípò. Ní ọ̀nà yìí, wọn yóò “tu Jehofa lójú.”—Orin Dafidi 116:18, 19; Filippi 2:12, 13.
“Ọkùnrin Mẹ́wàá Láti Inú Gbogbo Èdè àti Orílẹ̀-Èdè”
18, 19. (a) Ní ìmúṣẹ Sekariah 8:23, ta ni “Júù” lónìí? (b) Ta ni “ọkùnrin mẹ́wàá” tí ń “di etí aṣọ ẹni tí í ṣe Júù mú” lónìí?
18 Fún ìgbà ìkẹyìn nínú Sekariah orí kẹjọ, a kà pé: “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí.” Kí ni ìkéde Jehofa tí ó kẹ́yìn? “Ní ọjọ́ wọnnì yóò ṣẹ̀, ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí í ṣe Júù mú, wí pé, A óò bá ọ lọ, nítorí àwa ti gbọ́ pé, Ọlọrun wà pẹ̀lú rẹ.” (Sekariah 8:23) Ní ọjọ́ Sekariah, Israeli àbínibí jẹ́ orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ Ọlọrun. Ṣùgbọ́n, ní ọ̀rúndún kìíní, Israeli ṣá Messia Jehofa tì. Nítorí náà, Ọlọrun wa yan “ẹni tí í ṣe Júù”—Israeli tuntun—gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ̀ pàtàkì, “Israeli Ọlọrun” tí ó para pọ̀ jẹ́ àwọn Júù nípa tẹ̀mí. (Galatia 6:16; Johannu 1:11; Romu 2:28, 29) Iye àwọn wọ̀nyí níkẹyìn yóò jẹ́ 144,000, tí a yàn láti inú aráyé láti ṣàkóso pẹ̀lú Jesu nínú Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run.—Ìṣípayá 14:1, 4.
19 Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn 144,000 wọ̀nyí ti kú gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́, wọ́n sì ti gba ère wọn ní ọ̀run. (1 Korinti 15:51, 52; Ìṣípayá 6:9-11) Ó ku àwọn kéréje lórí ilẹ̀ ayé, àwọn wọ̀nyí sì yọ̀ láti rí i pé, “ọkùnrin mẹ́wàá” tí wọ́n yàn láti bá “ẹni tí í ṣe Júù” náà lọ, ní tòótọ́ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n.”—Ìṣípayá 7:9; Isaiah 2:2, 3; 60:4-10, 22.
20, 21. Bí òpin ayé yìí ṣe ń sún mọ́lé, báwo ni a ṣe lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jehofa?
20 Bí òpin ayé yìí ṣe ń sún mọ́lé láìṣeéyẹ̀ sílẹ̀, Kirisẹ́ńdọ̀mù dà bí Jerusalemu ní ọjọ́ Jeremiah: “Àwa ń retí àlàáfíà, kò sì sí rere, àti fún ìgbà ìmúláradá, ṣùgbọ́n wò ó, ìdààmú!” (Jeremiah 14:19) Ìdààmú yẹn yóò dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá dojú kọ ìsìn èké, tí wọ́n sì mú un wá sí ìparun oníwà ipá. Kété lẹ́yìn náà, àwọn orílẹ̀-èdè fúnra wọn ni a óò parun nínú ogun àjàkẹyìn tí Ọlọrun yóò jà, Armageddoni. (Matteu 24:29, 30; Ìṣípayá 16:14, 16; 17:16-18; 19:11-21) Ẹ wo bí yóò ti jẹ̀ àkókò onírúkèrúdò tó!
21 Jálẹ̀ gbogbo rẹ̀, Jehofa yóò dáàbò bo àwọn tí wọ́n fẹ́ òtítọ́, tí wọ́n sì mú “irúgbìn [àlàáfíà, NW]” dàgbà. (Sekariah 8:12; Sefaniah 2:3) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wà láìséwu nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ní fífi tìtaratìtara yìn ín ní gbangba, kí a sì ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó lọ́wọ́ láti “tu Jehofa lójú.” Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa gbádùn àlàáfíà Jehofa nígbà gbogbo. Àní, “Oluwa yóò fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀; Oluwa yóò fi àlàáfíà bù sí i fún àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Orin Dafidi 29:11.
Ìwọ́ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Báwo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun ṣe ‘jẹ́ kí ọwọ́ wọn le’ ní ọjọ́ Sekariah? Lónìí ńkọ́?
◻ Báwo ni a ṣe ń hùwà padà sí inúnibíni, ìkóguntini àti ìdágunlá?
◻ Kí ni ‘sísọ̀rọ̀ òtítọ́, olúkúlùkù sí ẹnì kejì rẹ̀’ ní nínú?
◻ Báwo ni ẹnì kan ṣe lè “tu Jehofa lójú”?
◻ Ìdí pàtàkì wo ni a rí fún ayọ̀ nínú ìmúṣẹ Sekariah 8:23?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Léṣìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lo 1,150,353,444 wákàtí ní bíbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun