Jèhófà Kórìíra Ìwà Àdàkàdekè
‘Ẹ má ṣe àdàkàdekè sí ara yín.’—MÁLÁKÌ 2:10.
1. Kí ni Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ wa tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun?
ṢÉ O fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun? Tó o bá nígbàgbọ́ nínú ìrètí yẹn bí Bíbélì ṣe ṣèlérí rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni o.’ Àmọ́ tó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run fún ọ ní ìyè ayérayé nínú ayé tuntun rẹ̀, o ní láti kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tó béèrè. (Oníwàásù 12:13; Jòhánù 17:3) Ṣé ó pọ̀ jù láti retí pé káwọn ẹ̀dá aláìpé ṣe bẹ́ẹ̀? Rárá o, nítorí pé Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí pé: “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni mo ní inú dídùn sí, kì í sì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun.” (Hóséà 6:6) Nítorí náà, àwọn ẹ̀dá aláìpé pàápàá lè kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọlọ́run béèrè.
2. Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣe àdàkàdekè sí Jèhófà?
2 Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo èèyàn ló fẹ́ ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Hóséà sọ pé kódà ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ti gbà láti wọnú májẹ̀mú, ìyẹn àdéhùn, láti ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 24:1-8) Àmọ́, kò pẹ́ rárá tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ‘tẹ májẹ̀mú náà lójú’ nípa rírú àwọn òfin rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn “ṣe àdàkàdekè” sí òun. (Hóséà 6:7) Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe látìgbà yẹn. Àmọ́ Jèhófà kórìíra ìwà àdàkàdekè, yálà sí òun fúnra rẹ̀ tàbí sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín.
3. Ìfọ́síwẹ́wẹ́ wo la ó ṣe nínú ẹ̀kọ́ yìí?
3 Hóséà nìkan kọ́ ni wòlíì tó sọ̀rọ̀ nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àdàkàdekè. Irú ojú tó sì yẹ kí àwa náà máa fi wò ó nìyẹn, tá a bá fẹ́ gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ apá púpọ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Málákì, bẹ̀rẹ̀ láti orí kìíní ìwé rẹ̀. Wàyí o, ẹ jẹ́ ká yíjú sí orí kejì ìwé náà, ká sì rí i bá a ṣe túbọ̀ pe àfiyèsí sórí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àdàkàdekè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lẹ́yìn tí wọ́n padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì ni Málákì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, síbẹ̀ orí kejì yìí kàn wá lónìí.
Àwọn Àlùfáà Tí Ìbáwí Tọ́ Sí
4. Ìkìlọ̀ wo ni Jèhófà fún àwọn àlùfáà?
4 Orí kejì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú bí Jèhófà ṣe bá àwọn àlùfáà Júù wí nítorí pé wọ́n yà kúrò lójú ọ̀nà òdodo rẹ̀. Bí àwọn àlùfáà náà kò bá kọbi ara sí ìmọ̀ràn rẹ̀, kí wọ́n sì tún ọ̀nà wọn ṣe, ó dájú pé ohun búburú jáì ni yóò tẹ̀yìn rẹ̀ jáde. Kíyè sí ẹsẹ méjì àkọ́kọ́: “‘Àṣẹ yìí wà fún yín, ẹ̀yin àlùfáà. Bí ẹ kò bá ní fetí sílẹ̀, bí ẹ kò bá sì ní fi ọkàn-àyà yín sí i láti fi ògo fún orúkọ mi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘dájúdájú, èmi yóò rán ègún sórí yín, èmi yóò sì gégùn-ún fún ìbùkún yín.’” Ká ní àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn ti fi òfin Ọlọ́run kọ́ àwọn ènìyàn náà ni, tí wọ́n sì ti pa á mọ́, ìbùkún ì bá jẹ́ tiwọn. Àmọ́ nítorí pé wọn ò bìkítà nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ègún, ìyẹn ìfiré, ni yóò wá sórí wọn. Kódà ègún ni ìre tó bá ń tẹnu àwọn àlùfáà jáde yóò jẹ́.
5, 6. (a) Èé ṣe tó fi jẹ́ pé àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn gan-an ni ìbáwí tọ́ sí? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé ojú ẹni àbùkù lòun fi ń wo àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn?
5 Èé ṣe tó fi jẹ́ pé àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn gan-an ni ìbáwí tọ́ sí? Ẹsẹ keje sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ètè àlùfáà ni èyí tí ó yẹ kí ó pa ìmọ̀ mọ́, òfin sì ni ohun tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn máa wá ní ẹnu rẹ̀; nítorí pé òun ni ońṣẹ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú àkókò yẹn, òfin Ọlọ́run tá a fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè sọ pé iṣẹ́ àwọn àlùfáà ni “láti kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìlànà tí Jèhófà ti sọ.” (Léfítíkù 10:11) Ó ṣeni láàánú pé, bí ọdún ti ń gorí ọdún, ẹni tó kọ 2 Kíróníkà 15:3 ròyìn pé: “Ọjọ́ púpọ̀ sì ni Ísírẹ́lì fi wà láìní Ọlọ́run tòótọ́ àti láìní àlùfáà tí ń kọ́ni àti láìní Òfin.”
6 Ipò kan náà làwọn àlùfáà wà nígbà ayé Málákì, ní ọ̀rúndún kárùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa. Wọ́n ń kùnà láti fi Òfin Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn náà. Nítorí náà, ìbáwí tọ́ sí àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn. Kíyè sí ọ̀rọ̀ líle tí Jèhófà sọ sí wọn. Málákì 2:3 là á mọ́lẹ̀ pé: “Èmi yóò sì fọ́n imí sójú yín, imí àwọn àjọyọ̀ yín.” Ìbáwí ńlá mà lèyí o! Òde ibùdó ló yẹ kí wọ́n kó imí àwọn ẹran tá a fi rúbọ lọ, kí wọ́n sì lọ sun wọ́n níbẹ̀. (Léfítíkù 16:27) Àmọ́, nígbà tí Jèhófà sọ fún wọn pé ojú wọn lòun máa fọ́n ìmí náà sí, ó hàn gbangba pé ojú àbùkù ló fi ń wo àti ẹbọ àtàwọn tó ń rú wọn.
7. Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú sí àwọn olùkọ́ Òfin?
7 Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò Málákì, Jèhófà ní kí àwọn ọmọ Léfì máa bójú tó àgọ́ ìjọsìn àti lẹ́yìn náà tẹ́ńpìlì àti àwọn iṣẹ́ òjíṣẹ́ mímọ́ rẹ̀. Àwọn ni olùkọ́ ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ká ní wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ ni, ìyẹn ì bá túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà fún àwọn àti orílẹ̀-èdè náà. (Númérì 3:5-8) Àmọ́ àwọn ọmọ Léfì kò bẹ̀rù Ọlọ́run mọ́. Abájọ tí Jèhófà fi sọ fún wọn pé: “Ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà. Ẹ ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀ nínú òfin. Ẹ ti da májẹ̀mú Léfì . . . Ẹ kò . . . pa àwọn ọ̀nà mi mọ́.” (Málákì 2:8, 9) Nítorí pé àwọn àlùfáà wọ̀nyí kò fi òtítọ́ kọ́ni àti nítorí àpẹẹrẹ búburú wọn, wọ́n ṣi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà. Nítorí náà, ó tọ̀nà bí Jèhófà ṣe bínú sí wọn yẹn.
Pípa Ìlànà Ọlọ́run Mọ́
8. Ṣé ohun tó pọ̀ jù ni láti máa retí pé káwọn èèyàn pa ìlànà Ọlọ́run mọ́? Ṣàlàyé.
8 Ẹ má ṣe jẹ́ ká ronú pé àánú àti ìdáríjì tọ́ sí àwọn àlùfáà yẹn nítorí pé èèyàn aláìpé lásán ni wọ́n àti pé a ò lè retí pé kí wọ́n pa ìlànà Ọlọ́run mọ́. Kókó tó wà níbẹ̀ ni pé, ó ṣeé ṣe fún èèyàn láti pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́, nítorí pé Jèhófà kò retí pé kí wọ́n ṣe ohun tí agbára wọn ò gbé. A ò lè sọ bóyá àwọn àlùfáà kọ̀ọ̀kan pa ìlànà Ọlọ́run mọ́ nígbà yẹn, àmọ́ kò sí iyèméjì kankan nípa ẹnì kan tó wá ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn náà—ìyẹn Jésù, “àlùfáà àgbà” títóbi náà. (Hébérù 3:1) Ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ sí lára ní ti tòótọ́ pé: “Àní òfin òtítọ́ sì wà ní ẹnu rẹ̀, a kò sì rí àìṣòdodo kankan ní ètè rẹ̀. Ó bá mi rìn ní àlàáfíà àti ní ìdúróṣánṣán, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ padà kúrò nínú ìṣìnà.”—Málákì 2:6.
9. Àwọn wo ló ń fi ìṣòtítọ́ kéde ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà ní àkókò tiwa?
9 Ní ìfiwéra, ó ti lé ní ọ̀rúndún báyìí tí àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi, ìyẹn àwọn tí wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run, ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà mímọ́, láti máa rú àwọn ẹbọ ti ẹ̀mí tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:5) Wọ́n ti mú ipò iwájú nínú kíkéde òtítọ́ Bíbélì dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì tí wọ́n fi ń kọ́ni, ǹjẹ́ àwọn ohun tó o ti rí kò ti fi hàn pé òfin òtítọ́ wà lẹ́nu wọn? Wọ́n ti ṣèrànwọ́ láti yí ọ̀pọ̀ èèyàn padà kúrò nínú ìgbàgbọ́ èké, tó fi jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti wà jákèjádò ayé nísinsìnyí tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Àwọn wọ̀nyí tún ní àǹfààní láti kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn ní òfin òtítọ́ náà.—Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:9.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Ṣọ́ra
10. Èé ṣe tó fi yẹ ká ṣọ́ra?
10 Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká ṣọ́ra. Ojú wa lè fo àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Málákì 2:1-9. Ǹjẹ́ àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan wà lójúfò, kí a má bà a rí àìṣòdodo kankan ní ètè wa? Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ àwọn aráalé wa lè fi gbogbo ara gba ohun tá a bá sọ gbọ́? Ṣé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú ìjọ lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú? Ó rọrùn gan-an láti ní àṣà fífi agbárí gbé ọ̀rọ̀ wa jókòó, tí yóò fi dà bíi pé bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an la sọ ọ́, síbẹ̀ kó jẹ́ pé ńṣe là ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Tàbí kẹ̀, èèyàn lè jẹ́ alásọdùn, tàbí kó máa fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan pa mọ́ nínú ọ̀ràn ìṣòwò. Ṣé Jèhófà ò wá ní mọ ìyẹn ni? Tá a bá sì ń lo irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀, ṣé yóò gba àwọn ẹbọ ìyìn tó ń ti ètè wa jáde?
11. Àwọn wo ló yẹ kó máa ṣọ́ra jù?
11 Ní ti àwọn tó láǹfààní kíkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ìjọ lónìí, Málákì 2:7 gbọ́dọ̀ jẹ́ ìkìlọ̀ ńlá fún wọn. Ó sọ pé ètè wọn “ni èyí tí ó yẹ kí ó pa ìmọ̀ mọ́, òfin sì ni ohun tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn máa wá” ní ẹnu wọn. Ẹrù iṣẹ́ ńlá ló já lé irú àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ léjìká, nítorí pé Jákọ́bù 3:1 là á mọ́lẹ̀ pé àwọn ni “yóò gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbọ́dọ̀ fi tokuntokun àti tìtaratìtara kọ́ni, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tá a gbé ka ìwé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtọ́ni tó ń wá nípasẹ̀ ètò àjọ Jèhófà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” Ìdí nìyẹn tá a fi gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tímótì 2:2, 15.
12. Kí ló yẹ kí àwọn tó jẹ́ olùkọ́ni ṣọ́ra fún?
12 Bí a kò bá ṣọ́ra, ó lè ṣe wá bíi pé ká fi àwọn ọ̀rọ̀ tara wa tàbí àwọn èrò tiwa kún ẹ̀kọ́ wa nígbà mìíràn. Ìyẹn lè jẹ́ ewu ńlá, àgàgà fún ẹnì kan tó máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí òun bá sọ labẹ́ gé, kódà bí ohun tó ń sọ tiẹ̀ lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ètò àjọ Jèhófà fi ń kọ́ni. Àmọ́ Málákì orí kejì fi hàn pé ó yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pé àwọn olùkọ́ nínú ìjọ yóò tẹ̀ lé ìmọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe èrò ti ara wọn tó lè mú àwọn àgùntàn kọsẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú mi kọsẹ̀, ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún un kí a so ọlọ kọ́ ọrùn rẹ̀, irúfẹ́ èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí, kí a sì rì í sínú òkun gbalasa, tí ó lọ salalu.”—Mátíù 18:6.
Gbígbé Aláìgbàgbọ́ Níyàwó
13, 14. Kí ni ìwà àdàkàdekè kan tí Málákì mẹ́nu kàn?
13 Láti ẹsẹ kẹwàá lọ ni Málákì orí kejì ti tẹnu mọ́ ìwà àdàkàdekè láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Málákì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà méjì tó tan mọ́ra wọn, tó pè ní “àdàkàdekè” léraléra. Lákọ̀ọ́kọ́, ṣàkíyèsí pé Málákì bẹ̀rẹ̀ ìmọ̀ràn rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: “Baba kan ha kọ́ ni gbogbo wa ní? Ọlọ́run kan ha kọ́ ni ó dá wa? Èé ṣe tí a fi ń ṣe àdàkàdekè sí ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní sísọ májẹ̀mú àwọn baba ńlá wa di aláìmọ́?” Lẹ́yìn náà, ẹsẹ kọkànlá fi kún un pé ìwà àdàkàdekè wọn ló sọ “ìjẹ́mímọ́ Jèhófà” di aláìmọ́. Kí ni wọ́n ń ṣe tó burú tó bẹ́ẹ̀? Ẹsẹ náà mẹ́nu kan ọ̀kan lára àwọn ìwà búburú náà, ó ní: Wọ́n ti “fi ọmọbìnrin ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè ṣe ìyàwó.”
14 Lọ́rọ̀ mìíràn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan, tí wọ́n jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tí a yà sí mímọ́ fún Jèhófà, ti fi àwọn tí kò jọ́sìn Jèhófà ṣe aya. Àyíká ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ká rí ìdí tíyẹn fi burú jáì. Ẹsẹ kẹwàá sọ pé baba kan náà ni gbogbo wọ́n ní. Èyí kì í ṣe Jékọ́bù (tá a yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ísírẹ́lì), bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe Ábúráhámù, kì í ṣe Ádámù pàápàá. Málákì 1:6 fi hàn pé Jèhófà ni “baba kan” náà. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀, nítorí májẹ̀mú tó bá àwọn baba ńlá wọn dá. Ọ̀kan lára òfin tí ń bẹ nínú májẹ̀mú yẹn ni pé: “Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ bá wọn dána. Ọmọbìnrin rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi fún ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú fún ọmọkùnrin rẹ.”—Diutarónómì 7:3.
15. (a) Báwo làwọn kan ṣe lè gbìyànjú láti sọ pé kò sóhun tó burú nínú fífẹ́ aláìgbàgbọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ ojú tí òun fi ń wo ọ̀ràn ìgbéyàwó?
15 Àwọn kan lóde òní lè máa ronú pé: ‘Ẹni tí mo fẹ́ẹ́ fẹ́ ṣèèyàn gan-an. Ó ṣeé ṣe kó tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́ láìpẹ́.’ Irú ìrònú bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òótọ́ ni ìkìlọ̀ onímìísí náà pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Ojú tí Ọlọ́run fi wo ọ̀ràn fífẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́ la fi hàn nínú Málákì 2:12, pé: “Jèhófà yóò ké olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe é kúrò.” Ìdí nìyẹn tá a fi rọ̀ àwa Kristẹni pé ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Nínú ètò Kristẹni, a kì í “ké” onígbàgbọ́ “kúrò” nítorí pé ó fẹ́ aláìgbàgbọ́. Àmọ́ bí aláìgbàgbọ́ náà bá kọ̀ láti yí padà, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sírú ẹni bẹ́ẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá mú ètò búburú yìí wá sópin láìpẹ́?—Sáàmù 37:37, 38.
Ṣíṣe Àìdáa sí Ọkọ Tàbí Aya Ẹni
16, 17. Ìwà àdàkàdekè wo làwọn kan hù?
16 Málákì lọ sórí àdàkàdekè kejì: ìyẹn ni ṣíṣe àìdáa sí ọkọ tàbí aya ẹni, àgàgà nípasẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ tí kò yẹ. Orí kejì ẹsẹ ìkẹrìnlá sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti jẹ́rìí láàárín ìwọ àti aya ìgbà èwe rẹ, ẹni tí ìwọ alára ti ṣe àdàkàdekè sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ẹnì kejì rẹ àti aya májẹ̀mú rẹ.” Nípa ṣíṣe àdàkàdekè sí àwọn aya wọn, àwọn ọkọ tó jẹ́ Júù ti mú kí pẹpẹ Jèhófà di èyí tó ‘kún fún omijé.’ (Málákì 2:13) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn ń jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ lórí onírúurú àṣìṣe tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọ́n ń fi àwọn aya ìgbà èwe wọn sílẹ̀ lọ́nà àìtọ́, bóyá kí wọ́n lè lọ fẹ́ àwọn tó kéré lọ́jọ́ orí tàbí àwọn obìnrin kèfèrí. Àwọn àlùfáà oníwà ìbàjẹ́ yẹn sì fàyè gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Àmọ́, Málákì 2:16 là á mọ́lẹ̀ pé: “‘Òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,’ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí.” Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jésù wá sọ pé ìwà pálapàla takọtabo ni ohun kan ṣoṣo tó lè mú ìkọ̀sílẹ̀ wá, èyí tó lè jẹ́ kí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ fẹ́ ẹlòmíràn.—Mátíù 19:9.
17 Ronú nípa ọ̀rọ̀ Málákì, kí o sì rí i bó ti wọni lọ́kàn tó, tó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà ìkà kò pé. Ó tọ́ka sí “ẹnì kejì rẹ àti aya májẹ̀mú rẹ.” Olúkúlùkù àwọn ọkùnrin tí à ń sọ̀rọ̀ wọn yìí ló ti fẹ́ olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ìyẹn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, tó ti yàn án gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ ọ̀wọ́n, tí wọ́n máa jọ bára wọn kalẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà táwọn méjèèjì ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ ni wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó yẹn. Kò wá yẹ kí májẹ̀mú tí wọ́n bá ara wọn dá, ìyẹn ìdè ìgbéyàwó di èyí tí kò gbéṣẹ́ mọ́ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, tí wọ́n sì ń dàgbà.
18. Ọ̀nà wo ni ìmọ̀ràn Málákì nípa àdàkàdekè gbà kàn wá lónìí?
18 Ìmọ̀ràn lórí àwọn kókó wọ̀nyẹn kàn wá bákan náà lóde òní. Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ò ka ìlànà Ọlọ́run lórí gbígbéyàwó kìkì nínú Olúwa sí. Bẹ́ẹ̀ náà ló tún bani nínú jẹ́ pé àwọn kan ò sapá láti mú kí ìdè ìgbéyàwó wọn lágbára sí i. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n ń ṣàwáwí, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run kórìíra, nípa jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, kí wọ́n lè fẹ́ ẹlòmíràn. Nípa ṣíṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, wọ́n ti “dá Jèhófà lágara.” Nígbà ayé Málákì, àwọn tó kọ ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílẹ̀ tiẹ̀ gbójúgbóyà láti sọ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan ni kò tọ̀nà. Ohun tí wọ́n kúkú ń sọ ni pé: “Ibo ni Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo wà?” Ìsọkúsọ gbáà ni! Ẹ má ṣe jẹ́ ká kó sínú pańpẹ́ yẹn o.—Málákì 2:17.
19. Báwo làwọn ọkọ àtàwọn aya ṣe lè rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà?
19 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Málákì fi hàn pé àwọn ọkọ kan wà tí wọn kò ṣe àdàkàdekè sí àwọn aya wọn. Àwọn wọ̀nyí ‘ní èyí tí ó ṣẹ́ kù lára ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.’ (Ẹsẹ ìkẹẹ̀ẹ́dógún) Inú wa dùn pé irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ń ‘fi ọlá fún àwọn aya wọn’ kún inú ìjọ Ọlọ́run lóde òní. (1 Pétérù 3:7) Àwọn ọkọ wọ̀nyí kì í fìyà jẹ àwọn aya wọn. Wọ́n kórìíra àṣà ìbálòpọ̀ tí ń tẹ́ni lógo. Wọn kì í tàbùkù sí àwọn aya wọn nípa bíbá àwọn obìnrin mìíràn tage tàbí nípa wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn olóòótọ́ aya Kristẹni tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run àtàwọn òfin rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ètò àjọ Jèhófà. Irú àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ mọ ohun tí Ọlọ́run kórìíra. Wọ́n ń ronú, wọ́n sì ń gbégbèésẹ̀ tó fi hàn pé àwọn náà kórìíra nǹkan bẹ́ẹ̀. Máa fara wé wọn, máa “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso,” wàá sì rí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ gbà lọ́pọ̀ yanturu.—Ìṣe 5:29.
20. Àkókò wo ló ń sún mọ́lé fún gbogbo aráyé?
20 Láìpẹ́, Jèhófà yóò dá gbogbo ayé yìí lẹ́jọ́. Olúkúlùkù ni yóò jíhìn ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ fún un. “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Nítorí náà, ìbéèrè tó wá gbèrò níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí ni pé: Àwọn wo ni yóò la ọjọ́ Jèhófà já? Inú àpilẹ̀kọ kẹta tó jẹ́ èyí tó gbẹ̀yìn nínú ọ̀wọ́ yìí la ó ti jíròrò kókó yẹn.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí pàtàkì tí Jèhófà fi dẹ́bi fún àwọn àlùfáà ní Ísírẹ́lì?
• Èé ṣe tí ìlànà Ọlọ́run kò kọjá ohun tí èèyàn lè pa mọ́?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká ṣọ́ra nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lóde òní?
• Àwọn àṣà méjì wo ni Jèhófà dìídì sọ pé kò dára?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ní ọjọ́ Málákì, a bá àwọn àlùfáà wí nítorí pé wọn ò pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ó gba ìṣọ́ra láti rí i pé àwọn ọ̀nà Jèhófà la fi ń kọ́ni, kì í ṣe ìfẹ́ inú tiwa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà dẹ́bi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kọ àwọn aya wọn sílẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí wọ́n sì fi àwọn obìnrin kèfèrí ṣaya
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Kristẹni òde òní kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú májẹ̀mú ìgbéyàwó wọn