Ọjọ́ Tí Ń “Jó Bí Iná Ìléru”
“Kíyèsí i, ọjọ́ náà ń bọ̀, tí yóò máa jó bí iná ìléru.”—MALAKI 4:1.
1. Àwọn ìbéèrè wo ni ó dìde ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Malaki 4:1?
NÍ ÀWỌN ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí Jehofa yàn láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé ìrántí rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ni nípa ti àwọn tí wọn kò tóótun fún àǹfààní yẹn? Yálà wọ́n jẹ́ alákòóso tàbí gbáàtúù ènìyàn, báwo ni nǹkan yóò ti rí fún wọn bí wọ́n bá fi ojú ẹ̀gàn wo àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọrun àti ìhìn-iṣẹ́ wọn? Malaki sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìjíhìn kan. Ní orí 4, ẹsẹ̀ 1, a kà pé: “Sáà kíyèsí i, ọjọ́ náà ń bọ̀, tí yóò máa jó bí iná ìléru; àti gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àkékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò sì jó wọn run, ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí kì yóò fi ku gbòǹgbò tàbí ẹ̀ka fún wọn.”
2. Àpèjúwe ṣíṣe tààràtà wo nípa ìdájọ́ Jehofa ni a fúnni nínú Esekieli?
2 Àwọn wòlíì mìíràn pẹ̀lú fi ìdájọ́ Jehofa lórí àwọn orílẹ̀-èdè wé ooru gbígbóná iná ìléru. Ẹ wo bí Esekieli 22:19-22 ti bá ìdájọ́ Ọlọrun lórí àwọn ẹgbẹ́ ìyapa Kristẹndọm apẹ̀yìndà mu lọ́nà yíyẹ tó! Ó kà pé: “Báyìí ni Oluwa Ọlọrun wí; Nítorí tí gbogbo yín di ìdàrọ́, kíyèsí i, nítorí náà èmi óò kó yín jọ . . . Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa kó fàdákà, àti idẹ, àti irin, àti òjé, àti táńganran jọ sí àárín ìléru, láti fín iná sí i, kí á lè yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi óò kó yín ní ìbínú mi, àti ìrunú mi, èmi óò sì fi yín síbẹ̀ èmi óò yọ́ yín. Nítòótọ́, èmi óò kó yín jọ, èmi óò sì fín iná ìbínú mi sí yín lára, ẹ óò sì di yíyọ́ láàárín rẹ̀. Bí a ti í yọ́ fàdákà láàárín ìléru, bẹ́ẹ̀ ni a óò yọ́ yín láàárín rẹ̀; ẹ̀yin óò sì mọ̀ pé èmi Oluwa ni ó ti da ìrunú mi sí yín lórí.”
3, 4. (a) Ìjẹ́wọ́ alágàbàgebè wo ni ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ti ṣe? (b) Àkọsílẹ̀ ẹlẹ́gbin wo ni ìsìn ní?
3 Àpèjúwe kíkàmàmà ní èyí nítòótọ́! Ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n ti kọ̀ láti lo orúkọ Jehofa, tí wọ́n tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ mímọ́ yẹn pàápàá, yóò dojúkọ ọjọ́ ìjíhìn yẹn. Nínú ìwà ọ̀yájú wọn, wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn àti àwọn olóṣèlú ẹlẹgbẹ́ wọn yóò fìdí Ìjọba Ọlọrun múlẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, tàbí ó kérétán mú kí ilẹ̀-ayé jẹ́ ibi tí ó bójúmu fún Ìjọba náà.
4 Kristẹndọm apẹ̀yìndà ti darapọ̀ mọ́ àwọn alákòóso òṣèlú láti jagun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀. Ìtàn ṣàkọsílẹ̀ àwọn Ogun Ìsìn ní sànmánnì agbedeméjì, ìfipá múni yípadà ti Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ní Spania, Ogun Ọlọ́gbọ̀n Ọdún tí ó run apá ilẹ̀ Europe tí ó pọ̀ jùlọ ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, àti Ogun Abẹ́lé ní Spania ní àwọn ọdún 1930, tí wọ́n jà láti mú kí Spania jẹ́ ibi aláìléwu fún Ìsìn Katoliki. Ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ wáyé pẹ̀lú ogun àgbáyé méjèèjì ti ọ̀rúndún wa, nígbà tí àwọn Katoliki àti Protẹstanti kópa nínú ogun àjàkú akátá, ní pípa àwọn onígbàgbọ́ ìsìn tiwọn àti ti àwọn ìsìn mìíràn láìfi ìyàtọ̀ síi. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìjà aṣekúpani ti wà láàárín àwọn Katoliki ati Protẹstanti ní Ireland, láàárín ẹgbẹ́ ìyapa ìsìn ní India, àti láàárín àwùjọ ìsìn ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀rí. Ojú-ewé ìwé ìtàn ìsìn rin gbingbin pẹ̀lú fún ẹ̀jẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ sí Jehofa tí wọ́n ṣekúpa.—Ìṣípayá 6:9, 10.
5. Ìdájọ́ wo ni ó ń dúró dé ìsìn èké?
5 Ó yẹ kí á fi ìmọrírì hàn fún ìdájọ́-òdodo Jehofa tí ó súnmọ́lé ti fífìyà ikú jẹ Babiloni Ńlá, ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé, papọ̀ pẹ̀lú àwọn alátìlẹyìn rẹ̀. Ìyà ikú yìí ni a ṣàpèjúwe nínú Ìṣípayá 18:21, 24 pé: “Áńgẹ́lì alókunlágbára kan sì gbé òkúta kan tí ó dàbí ọlọ ńlá sókè ó sì fi í sọ̀kò sínú òkun, ó wí pé: ‘Lọ́nà yii pẹlu ìgbésọnù yíyára ni a óò fi Babiloni ìlú-ńlá títóbi naa sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yoo sì tún rí i mọ́ láé. Bẹ́ẹ̀ ni, ninu rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ awọn wòlíì ati ti awọn ẹni mímọ́ ati ti gbogbo awọn wọnnì tí a ti fikúpa lórí ilẹ̀-ayé.’”
6. (a) Àwọn wo ni yóò di àkékù koríko, èésìtiṣe? (b) Ìdánilójú wo ni ó wà fún àwọn wọnnì tí wọ́n bẹ̀rù Jehofa?
6 Nígbà tí ó bá tó àkókò, gbogbo àwọn ọ̀tá òdodo, àti àwọn tí wọ́n ń gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, “yóò dàbí àkékù koríko.” Ọjọ́ Jehofa yóò jó láàárín wọn bí iná ìléru. “Kì yóò . . . ku gbòǹgbò tàbí ẹ̀ka fún wọn.” Ní ọjọ́ ìjíhìn yẹn, àwọn ọmọ kéékèèké, tàbí ẹ̀ka, ni a fi ìdájọ́-òdodo bálò ní ìbámu pẹ̀lú bí Jehofa bá ṣe díwọ̀n àwọn gbòǹgbò, àwọn òbí wọn, tí wọ́n ní àbójútó lórí àwọn ọmọ wọn. Àwọn òbí burúkú kì yóò ní àtọmọdọ́mọ láti mú àwọn ọ̀nà ibi wọn wà títí lọ. Ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ìjọba Ọlọrun kì yóò mikàn. Nípa báyìí Heberu 12:28, 29 gbani níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ lati máa ní inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, nípasẹ̀ èyí tí a fi lè ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún Ọlọrun lọ́nà tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun ati ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀. Nitori Ọlọrun wa jẹ́ iná tí ń jónirun pẹlu.”
Jehofa Ha Jẹ́ Ọlọrun Oníkà?
7. Báwo ni ìfẹ́ Jehofa ṣe wọnú ìdájọ́ rẹ̀?
7 Èyí ha túmọ̀ sí pé Jehofa jẹ́ ìkà, Ọlọrun ẹlẹ́mìí ìgbẹ̀san bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ní 1 Johannu 4:8, aposteli náà sọ òtítọ́ tí ó ṣe pàtàkì kan: “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́.” Lẹ́yìn náà, ní ẹsẹ̀ 16 ó fi ìtẹnumọ́ kún un, ní sísọ pé: “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́, ẹni tí ó bá sì dúró ninu ìfẹ́ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun sì dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀.” Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ fún aráyé ni Jehofa ṣe pète láti gbá ìwà burúkú kúrò lórí ilẹ̀-ayé. Ọlọrun wa aláàánú, onífẹ̀ẹ́ polongo pé: “Bí èmi ti wà, . . . èmi kò ní inú-dídùn ní ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n kí ènìyàn búburú yípadà kúrò nínú ọ̀nà rẹ kí ó sì yè: ẹ yípadà, ẹ yípadà kúrò nínú ọ̀nà búburú yín; nítorí kí ni ẹ̀yin óò ṣe kú?”—Esekieli 33:11.
8. Báwo ni Johannu ṣe tẹnumọ́ ìfẹ́, síbẹ̀ tí ó fi ara rẹ̀ hàn bí Ọmọkùnrin Ààrá?
8 Johannu ń tọ́ka sí a·gaʹpe, ìfẹ́ tí a gbékarí ìlànà, lọ́pọ̀ ìgbà ju bí àwọn òǹkọ̀wé Ìhìnrere mẹ́ta yòókù ti ṣe, síbẹ̀ ní Marku 3:17, Johannu fúnra rẹ̀ ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “Ọmọkùnrin Ààrá.” Nípasẹ̀ ìmísí Jehofa ni Ọmọkùnrin Ààrá yìí fi ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìhìn-iṣẹ́ tí ń kìlọ̀ ohun tí ń bẹ níwájú nínú ìwé tí ó gbẹ̀yìn Bibeli, Ìṣípayá, tí ó fi Jehofa hàn bí Ọlọrun tí ń mú ìdájọ́-òdodo ṣẹ. Ìwé yìí kún fún àwọn àsọjáde onídàájọ́, bí “ìfúntí-wáìnì ńlá ti ìbínú Ọlọrun,” “àwokòtò méje ìbínú Ọlọrun,” àti “ìbínú ìrunú Ọlọrun Olódùmarè.”—Ìṣípayá 14:19; 16:1; 19:15.
9. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jesu sọ nípa àwọn ìdájọ́ Jehofa, báwo ni a sì ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ?
9 Jesu Kristi Oluwa wa, ẹni tí ó jẹ́ “àwòrán Ọlọrun tí a kò lè rí,” fi tìgboyà tìgboyà polongo ìdájọ́ Jehofa nígbà tí ó wà níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé. (Kolosse 1:15) Fún àpẹẹrẹ, àwọn ègbé méje ti Matteu orí 23 wà tí òun kéde láìfibọpobọyọ̀ lórí àwọn onísìn alágàbàgebè ọjọ́ rẹ̀. Òun parí ìdájọ́ ìdálẹ́bi yẹn pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Jerusalemu, Jerusalemu, olùpa awọn wòlíì ati olùsọ awọn wọnnì tí a rán sí i lókùúta,—iye ìgbà tí mo fẹ́ lati kó awọn ọmọ rẹ jọ papọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó awọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọ papọ̀ lábẹ́ awọn ìyẹ́-apá rẹ̀! Ṣugbọn ẹ̀yin kò fẹ́ ẹ. Wò ó! A ti pa ilé yín tì fún yín.” Ní ọdún 37 lẹ́yìn náà, ìdájọ́ ni a múṣẹ láti ọwọ́ ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Romu lábẹ́ Ọ̀gágun Titus. Ó jẹ́ ọjọ́ abanilẹ́rù kan, èyí tí ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóò jẹ́ ọjọ́ tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù jùlọ nínú ìrírí ẹ̀dá ènìyàn—ọjọ́ Jehofa, tí yóò tú jáde láìpẹ́.
“Oòrùn” Là
10. Báwo ni “oòrùn òdodo” ṣe mú ìdùnnú-ayọ̀ wá fún àwọn ènìyàn Ọlọrun?
10 Jehofa jẹ́ kí a mọ̀ pé àwọn tí yóò la ọjọ́ òun já yóò wà. Ó tọ́ka sí àwọn wọ̀nyí ní Malaki 4:2, ní sísọ pé: “Oòrùn òdodo yóò là, ti òun ti ìmúláradá ní ìyẹ́-apá rẹ̀, fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi.” Jesu Kristi fúnra rẹ̀ ni oòrùn òdodo yẹn. Òun ni “ìmọ́lẹ̀ ayé” nípa tẹ̀mí. (Johannu 8:12) Báwo ni òun ṣe là? Òun yọ pẹ̀lú ìmúláradá ní ìyẹ́-apá rẹ̀—lákọ̀ọ́kọ́ ìmúláradá nípa tẹ̀mí, èyí tí a lè ní ìrírí rẹ̀ àní lónìí pàápàá, àti lẹ́yìn náà, nínú ayé titun tí ń bọ̀, ìwòsàn nípa ti ara fún gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè. (Matteu 4:23; Ìṣípayá 22:1, 2) Ní ọ̀nà àpèjúwe, bí Malaki ti sọ, àwọn ẹni tí a mú láradá yoo ‘jáde lọ, wọ́n óò sì máa dàgbà bí àwọn ẹgbọrọ màlúù inú agbo’ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀ láti gàá. Ẹ wo irú ìdùnnú-ayọ̀ tí àwọn tí a óò jí dìde pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún jíjèrè ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn yóò tún ní ìrírí rẹ̀!
11, 12. (a) Ìpín wo ni ó ń dúró dé awọn ẹni burúkú? (b) Báwo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun ṣe “tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀”?
11 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ẹni burúkú ńkọ́? Ní Malaki 4:3, a kà pé: “Ẹ̀yin óò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀: nítorí wọn óò jásí eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi óò dá, ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun wí.” Bí ó ti ń dáàbò bo àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, Ọlọrun wa Ajagun yóò ti gbá àwọn ọ̀tá òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ mọ́ tefétefé kúrò lórí ilẹ̀-ayé, ní pípa wọ́n rẹ́ ráúráú. Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni a óò sì ti ká lọ́wọ́ kò.—Orin Dafidi 145:20; Ìṣípayá 20:1-3.
12 Àwọn ènìyàn Ọlọrun kì í kó ipa kankan ní pípa àwọn ẹni burúkú. Nígbà náà, báwo ni wọ́n ṣe “tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀”? Èyí ni wọ́n ṣe lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nípa ṣíṣàjọpín nínú ayẹyẹ ìṣẹ́gun ńlá. Eksodu 15:1-21 ṣàpèjúwe irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. Ó tẹ̀lé ìparun Farao àti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ̀ ní Òkun Pupa. Ní ìmúṣẹ Isaiah 25:3-9, tẹ̀lé ìmúkúrò “àwọn òṣìkà agbonimọ́lẹ̀” (NW), ni àsè ìṣẹ́gun tí ó sopọ̀ mọ́ ìlérí Ọlọrun pé: “Òun óò gbé ikú mì láéláé; Oluwa Jehofa yóò nu omijé nù kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn; yóò sì mú ẹ̀gàn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ayé: nítorí Oluwa ti wí i. A óò sì sọ ní ọjọ́ náà pé, Wò ó, Ọlọrun wa ní èyí. . . . Oluwa ni èyí: àwa ti dúró dè é, àwa óò máa yọ̀, inú wa óò sì máa dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.” Kò sí ẹ̀mí ìgbẹ̀san tàbí ẹ̀mí ọwọ́-bà-wọ́n nínú ayọ̀ yìí, ṣùgbọ́n yíyọ ayọ̀ àṣeyọrí nínú rírí bí a ti ya orúkọ Jehofa sí mímọ́ tí a sì gbá ilẹ̀-ayé mọ́ fún aráyé tí a sopọ̀ṣọ̀kan láti gbé ní àlàáfíà.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Kíkàmàmà Kan
13. Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo ni yóò ṣẹlẹ̀ nínú “ayé titun”?
13 Ní Malaki 4:4, a ṣí àwọn Júù létí láti “rántí òfin Mose.” Bákan náà lónìí ó yẹ kí á tẹ̀lé “òfin Kristi,” gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nubà á nínú Galatia 6:2. Kò sí iyèméjì pé àwọn olùla Armageddoni já ni a óò fún ní ìsọfúnni síwájú síi tí a gbékarí èyí, ìwọ̀nyí ni ó sì ṣeé ṣe kí a kọ sínú “awọn àkájọ ìwé” ti inú Ìṣípayá 20:12 tí a óò ṣí sílẹ̀ nígbà àjíǹde. Ọjọ́ kíkàmàmà ni ìyẹn yóò mà jẹ́ o bí a ti ń kọ́ àwọn tí a jí dìde kúrò nínú òkú láti fi ọ̀nà ìgbésí-ayé ti “ayé titun” náà ṣèwàhù!—Ìṣípayá 21:1.
14, 15. (a) Báwo ni a ṣe dá Elijah òde-òní mọ̀? (b) Ẹrù-iṣẹ́ wo ni ẹgbẹ́ Elijah ń múṣẹ?
14 Ìyẹn yóò jẹ́ ìmúgbòòrò iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Jehofa tọ́ka sí, bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Malaki 4:5: “Wò ó, èmi óò rán wòlíì Elijah sí yín, kí ọjọ́ ńlá-ǹlà Oluwa, àti ọjọ́ tí ó ní ẹ̀rù tó dé.” Ta ni Elijah òde-òní yẹn? Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn ní Matteu 16:27, 28, ní títọ́ka sí ‘bíbọ̀ ninu ìjọba rẹ̀,’ Jesu sọ pé: “A ti yan Ọmọkùnrin ènìyàn tẹ́lẹ̀ lati wá ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu awọn áńgẹ́lì rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo sì san èrè-iṣẹ́ fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹlu ìhùwàsí rẹ̀.” Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, lórí òkè kan pẹ̀lú Peteru, Jakọbu, àti Johannu, “a . . . yí i padà di ológo níwájú wọn, ojú rẹ̀ sì tàn bí oòrùn, awọn ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sì wá tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀.” Òun nìkan ni ó ha wà nínú ìran yìí bí? Ó tì o, “sì wò ó! Mose ati Elijah sì fara hàn wọ́n níbẹ̀, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀.”—Matteu 17:2, 3.
15 Kí ni èyí lè túmọ̀ sí? Ó tọ́ka sí Jesu gẹ́gẹ́ bíi Mose Títóbi Jù náà tí a sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò bíbọ̀ rẹ̀ fún ìdájọ́. (Deuteronomi 18:18, 19; Ìṣe 3:19-23) Nígbà náà Elijah òde-òní yóò darapọ̀ mọ́ ọn láti baà lè ṣàṣeparí iṣẹ́ ṣíṣekókó kan, ìyẹn ni ti wíwàásù ìhìnrere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀-ayé ṣáájú kí ọjọ́ ńlá Jehofa tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù tó dé. Ní ṣíṣàpèjúwe iṣẹ́ “Elijah” yìí, Malaki 4:6 sọ pé: “Yóò sì pa ọkàn àwọn bàbá dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sí ti àwọn bàbá wọn, kí èmi kí ó má baà wá fi ayé gégùn-ún.” Nípa bẹ́ẹ̀, “Elijah” ni a dámọ̀ bí ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n-inú ẹrú ti àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró lórí ilẹ̀-ayé, ẹni tí Ọ̀gá náà, Jesu, ti fi gbogbo ohun-ìní Rẹ̀ sí àbójútó rẹ̀. Èyí ní nínú pípèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu,” nípa tẹ̀mí fún agbo-ilé ìgbàgbọ́.—Matteu 24:45, 46.
16. Àbájáde aláyọ̀ wo ni ó ti jẹ́ ìyọrísí iṣẹ́ ẹgbẹ́ Elijah?
16 Jákèjádò ayé lónìí, a lè rí àbájáde aláyọ̀ tí ètò bíbọ́ni yẹn ní. Ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà, pẹ̀lú iye títẹ̀ tí ó jẹ́ 16,100,000 ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ní 120 èdè, 97 nínú ìwọ̀nyí tí a ń tẹ̀jáde ní ìgbà kan náà, ń kún ilẹ̀-ayé fọ́fọ́ pẹ̀lú “ìhìnrere ìjọba yii.” (Matteu 24:14) Àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn ní ọ̀pọ̀ èdè ni a ń lò nínú onírúurú apá ìhà iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ẹgbẹ́ Elijah náà, olùṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n-inú ẹrú, wà lójúfò sí pípèsè lọ́pọ̀ yanturu fún gbogbo “awọn wọnnì tí àìní wọn nipa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Matteu 5:3) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ́wọ́gba ìrètí Ìjọba náà tí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ lé e lórí ni a sopọ̀ nínú àgbàyanu ìṣọ̀kan kárí ayé. Ó ní nínú ogunlọ́gọ̀ ńlá “lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí iṣẹ́ yìí débi tí Jehofa fẹ́, nígbà náà ni òpin yóò dé ní ọjọ́ ńlá Jehofa tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù.
17. Ìgbà wo ni ọjọ́ Jehofa tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù yóò tú jáde?
17 Nígbà wo gan-an ni ilẹ̀ ọjọ́ tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù yẹn yóò mọ́ níṣojú wa? Aposteli Paulu dáhùn pé: “Ọjọ́ Jehofa ń bọ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí [bóyá lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀ kan] pé: ‘Àlàáfíà ati ààbò!’ nígbà naa ni ìparun òjijì yoo dé lọ́gán sórí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí aboyún; wọn kì yoo sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 Tessalonika 5:2, 3.
18, 19. (a) Báwo ni a ṣe polongo “àlàáfíà ati ààbò”? (b) Nígbà wo ni àwọn ènìyàn Jehofa yóò rí ìtura?
18 Àwọn wo ni “wọ́n” nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí? Wọ́n jẹ́ àwọn aṣáájú òṣèlú tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn lè gbé ètò titun tí ó wà ní ìṣọ̀kan kalẹ̀ láti inú apá tí ó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ti ayé oníwà-ipá yìí. Èso-iṣẹ́ wọn títóbi kàbìtì, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè àti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ti kùnà nínú èyí. Bí wòlíì Jehofa ti sọtẹ́lẹ̀, nísinsìnyí wọ́n tilẹ̀ ń “wí pé, Àlàáfíà! Àlàáfíà! nígbà tí kò sí àlàáfíà.”—Jeremiah 6:14; 8:11; 14:13-16.
19 Ní báyìí ná, àwọn ènìyàn Jehofa ń farada àwọn ìkìmọ́lẹ̀ àti inúnibíni ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọrun yìí. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ ní 2 Tessalonika 1:7, 8, wọ́n yóò rí ìtura “nígbà ìṣípayá Jesu Oluwa lati ọ̀run pẹlu awọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára ninu iná tí ń jófòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí awọn wọnnì tí kò mọ Ọlọrun ati awọn wọnnì tí kò ṣègbọràn sí ìhìnrere nipa Jesu Oluwa wa.”
20. (a) Kí ni Sefaniah àti Habakkuku sọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ náà ‘tí ń jó bí iná ìléru’? (b) Ìmọ̀ràn àti ìṣírí wo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí fúnni?
20 Báwo ni ìyẹn yóò ti jẹ́ kíákíá tó? Ọ̀pọ̀ nínú wa ti ń dúró fún ìgbà pípẹ́. Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́kàn tútù tí yóò làájá ń dáhùn sí ìpè tí ó wà nínú Sefaniah 2:2, 3 pé: “Ẹ wá Oluwa . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìwà-pẹ̀lẹ́: bóyá a óò pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Oluwa.” Lẹ́yìn náà, Sefaniah 3:8 ní ọ̀rọ̀-ìyànjú yìí: “Nítorí náà ẹ dúró dè mí, ni Oluwa wí, títí di ọjọ́ náà tí èmi óò dìde sí ohun-ọdẹ: nítorí ìpinnu mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, kí èmi kí ó lè kó àwọn ilẹ̀-ọba jọ, láti da ìrunú mi sí orí wọn, àní gbogbo ìbínú mi gbígbóná: nítorí a óò fi iná owú mi jẹ gbogbo ayé run.” Òpin ti dé tán! Jehofa mọ ọjọ́ àti wákàtí yẹn kí yóò sì yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò rẹ̀ padà. Ẹ jẹ́ kí a fi sùúrù faradà á. “Nítorí ìran náà jẹ́ ti ìgbà kan tí a yàn, yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn, kì yóò sì ṣèké, bí ó tilẹ̀ pẹ́, dúró dè é, nítorí ní dídé, yóò dé, kì yóò pẹ́.” (Habakkuku 2:3) Ọjọ́ Jehofa tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù ń yára kánkán súnmọ́lé. Rántí pé, ọjọ́ yẹn kì yóò pẹ́!
Bí Àtúnyẹ̀wò:
◻ Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn alákòóso àti àwọn tí a ń ṣàkóso ní ọjọ́ Jehofa tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù?
◻ Irú Ọlọrun wo ni Jehofa?
◻ Irú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo ni a ṣàpèjúwe fún àwọn ènìyàn Ọlọrun?
◻ Báwo ni àwọn wòlíì Ọlọrun ṣe gbà wá níyànjú lójú ìwòye ìsúnmọ́lé òpin náà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Lákòókò Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ní Spania ọ̀pọ̀ ni a fagbára mú láti yípadà sí ìsìn Katoliki
[Credit Line]
The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck