-
‘Ìbùkún Títí Kì Yóò Fi Sí Àìní Mọ́’Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
-
-
1, 2. (a) Àwọn ohun tó ṣàǹfààní wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè yàn? (b) Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ní í ṣe pẹ̀lú ìbùkún tá a lè rí gbà?
ÀKÒKÓ ìdájọ́ àti ìbùkún la wà yìí. Ó jẹ́ àkókò táwọn ìsìn ń bà jẹ́ bàlùmọ̀ àti àkókò tá a mú ìjọsìn tòótọ́ bọ̀ sípò. Ó dájú pé wàá yàn láti rí ìbùkún ìmúbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́, tó fi mọ́ àwọn àbájáde rere tó ń wá látinú ìmúbọ̀sípò yìí nísinsìnyí àtàwọn èyí tó máa wá lọ́jọ́ iwájú! Àmọ́ báwo lo ṣe lè rí i dájú pé àwọn ohun rere yìí kàn ọ́? Ìdáhùn ìbéèrè yìí ní í ṣe pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ní ìmúṣẹ rẹ̀ tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ láìpẹ́ lẹ́yìn tí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. (2 Tímótì 3:1) Bí Málákì ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà rèé: “‘Olúwa tòótọ́ [Jèhófà] yóò sì wá sí tẹ́ńpìlì Rẹ̀, . . . ẹni tí ẹ ń wá, àti ońṣẹ́ májẹ̀mú náà, ẹni tí ẹ ní inú dídùn sí. Wò ó! Dájúdájú, òun yóò wá,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.”—Málákì 3:1.
-
-
‘Ìbùkún Títí Kì Yóò Fi Sí Àìní Mọ́’Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
-
-
ÀKÓKÒ ÌFỌ̀MỌ́ TẸ̀MÍ
3. Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run ayé ọjọ́un ṣe tí Ọlọ́run fi pa wọ́n tì tó sì yan “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”?
3 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún lẹ́yìn tí Málákì gbé ayé, Jèhófà, tí Kristi (ẹni tí í ṣe “ońṣẹ́ májẹ̀mú [Ábúráhámù]”) ṣojú fún, wá sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn Rẹ̀ tó bá dá májẹ̀mú. Orílẹ̀-èdè náà lódindi fi hàn pé òun ò lẹ́tọ̀ọ́ sí ojú rere Ọlọ́run mọ́, ni Jèhófà bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Mátíù 23:37, 38) O lè rí ẹ̀rí ìyẹn nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Dípò orílẹ̀-èdè náà, ẹ̀rí àrídájú wà pé Jèhófà yan “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, ìyẹn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn tá a mú láti gbogbo orílẹ̀-èdè. (Gálátíà 6:16; Róòmù 3:25, 26) Àmọ́, kì í ṣe ibi tí ìmúṣe àsọtẹ́lẹ̀ Málákì parí sí nìyẹn. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún tọ́ka sí ìgbà tiwa yìí ó sì ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ò ń retí láti rí gbà lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn ‘ìbùkún títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’
4. Ìbéèrè wo ló ń fẹ́ ìdáhùn lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914?
4 Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ní ọdún 1914, Jèhófà fi Jésù Kristi jẹ Ọba Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. Ni àkókò bá tó fún Jésù láti fi àwùjọ àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà hàn. Ta ló máa yege ìdánwò yẹn, èyí tó máa fi àwùjọ àwọn Kristẹni tó mọ́ nípa tẹ̀mí hàn? Wàá rí i pé ọ̀rọ̀ tí Málákì sọ fi ìdáhùn hàn, ó ní: “Ta ni ó lè fara da ọjọ́ dídé rẹ̀, ta sì ni ẹni tí yóò dúró nígbà tí ó bá fara hàn? Nítorí òun yóò dà bí iná ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́.” (Málákì 3:2) Ìgbà wo ni Jèhófà wá sí “tẹ́ńpìlì” rẹ̀ fún ìdájọ́, báwo ló sì ṣe wá?
5, 6. (a) Nígbà tí Jèhófà wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ láti ṣe àbẹ̀wò, kí ló rí láàárín ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó sọ pé olùjọsìn rẹ̀ làwọn? (b) Kí làwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run nílò?
5 Ó hàn gbangba pé kì í ṣe inú tẹ́ńpìlì téèyàn fi ọwọ́ kọ́ ni Ọlọ́run wá. Ọdún 70 Sànmánì Kristẹni ni èyí tó kẹ́yìn lára irú tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́ bẹ́ẹ̀ tó wà fún ìjọsìn tòótọ́ pa run. Nítorí náà, inú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni Jèhófà wá, tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà sì ni ètò tí Ọlọ́run ṣe kí èèyàn fi lè sún mọ́ Ọlọ́run kó sì jọ́sìn rẹ̀ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. (Hébérù 9:2-10, 23-28) Ó dájú pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kọ́ ló para pọ̀ di tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yẹn, nítorí pé gbogbo wọn lápapọ̀ jẹ́ ètò ẹ̀sìn tó jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó sì ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó tẹ̀mí, tó jẹ́ pé ẹ̀kọ́ èké ló ń gbé lárugẹ dípò ìjọsìn tòótọ́. Jèhófà di “ẹlẹ́rìí yíyára kánkán lòdì sí” irú ètò ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀, kò sì sí àní-àní pé ó dá ọ lójú pé ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe fún wọn bá òdodo mu. (Málákì 3:5) Àmọ́, lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀, àwùjọ àwọn Kristẹni tòótọ́ kan wà tí wọ́n ń sin Ọlọ́run nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. Àwọn Kristẹni tòótọ́ náà fi hàn pé ti Ọlọ́run làwọn nípa fífara da àdánwò láìfi Ọlọ́run sílẹ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn ṣì nílò ìfọ̀mọ́ díẹ̀. Àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà tọ́ka sí ìyẹn, nítorí pé nínú wọn, a rí àwọn ìlérí amọ́kànyọ̀ nípa ìmúbọ̀sípò tara àti tẹ̀mí láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Málákì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn kan á wà tí Jèhófà yóò ‘sọ di mímọ́ kedere bíi wúrà àti bíi fàdákà, dájúdájú, wọn yóò di àwọn ènìyàn tí ń mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà nínú òdodo.’—Málákì 3:3.
6 Bí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ṣe fi hàn, àtọdún 1918 ni Jèhófà ti ń ṣe ìfọ̀mọ́ tó pọn dandan, ó ṣe àfọ̀mọ́ ìjọsìn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àṣà wọn àti ẹ̀kọ́ wọn.a Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó dara pọ̀ mọ́ wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ti jàǹfààní tó pọ̀. (Ìṣípayá 7:9) Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tó wà níṣọ̀kan, wọ́n ń bá a nìṣó láti máa mú ‘ọrẹ ẹbọ wá nínú òdodo,’ ọrẹ náà sì ń “mú inú Jèhófà dùn.”—Málákì 3:3, 4.
7. Kí ló yẹ ká bi ara wa nípa bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sí?
7 Ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn Ọlọ́run lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ńkọ́? Ó dáa, o lè béèrè pé: ‘Ṣé mi ò ní àwọn ìwà àti ìṣe kan tó ṣì nílò àtúnṣe? Ṣé mo ṣì ní láti ṣe àfọ̀mọ́ ìwà mi, bí Jèhófà ṣe ṣe àfọ̀mọ́ àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀?’ A ti rí i tẹ́lẹ̀ nínú ìwé yìí pé àwọn wòlíì méjìlá náà mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ àti ìṣe tó dára, àti àwọn èrò àti ìwà tí kò dára. Sísọ tí wọ́n sọ èyí mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti mọ ohun tí Jèhófà “ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ.” (Míkà 6:8) Kíyè sí awẹ́ gbólóhùn náà, “láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Ìyẹn tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ kí kálukú wa yẹ ara rẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá ó yẹ kóun ṣe àwọn ìfọ̀mọ́ kan.
-