-
A Rí Ìtumọ̀ Àṣírí Ọlọ́wọ̀ KanÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
17. (a) Kí ni àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò sọ tẹ́lẹ̀? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ ní 1918, ìkọ̀sílẹ̀ wo ló yọrí sí, ìyannisípò wo ló sì wáyé?
17 Nínú àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà òkùnkùn kan tó máa wà nígbà tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì bá ń ṣe bó ṣe wù ú. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, jálẹ̀ gbogbo ọ̀rúndún ìpẹ̀yìndà, àwọn Kristẹni kọ̀ọ̀kan wà tí wọ́n dà bí àlìkámà, ìyẹn àwọn ojúlówó ẹni àmì òróró. (Mátíù 13:24-29, 36-43) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní oṣù October ọdún 1914. (Ìṣípayá 1:10) Ó jọ pé Jèhófà wá sínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tẹ̀mí fún ìdájọ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn ní 1918, Jésù “ońṣẹ́ májẹ̀mú” rẹ̀ sì bá a wá. (Málákì 3:1; Mátíù 13:47-50) Ìgbà yẹn jẹ́ àkókò fún Ọ̀gá náà láti kọ àwọn èké Kristẹni sílẹ̀ pátápátá kó sì yan ‘ẹrú olóòótọ́ àti olóye sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.’—Mátíù 7:22, 23; 24:45-47.
-
-
A Rí Ìtumọ̀ Àṣírí Ọlọ́wọ̀ KanÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 32]
Àkókò Ìdánwò àti Ìdájọ́
A ri Jésù bọmi, Ọlọ́run sì fẹ̀mí yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba Lọ́la ní Odò Jọ́dánì ní nǹkan bí oṣù October ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. Ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó wá sí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ó sì lé àwọn tí ń sọ ọ́ di hòrò ọlọ́ṣà jáde. Ó jọ pé ohun kan tó bá èyí dọ́gba wáyé ní sáà ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí Jésù ti gorí ìtẹ́ lọ́run ní October ọdún 1914 títí di ìgbà tó wá láti bẹ àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ wò nígbà tí ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run. (Mátíù 21:12, 13; 1 Pétérù 4:17) Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1918, ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Jèhófà nípa Ìjọba Ọlọ́run bá àtakò tó pọ̀ pàdé. Ó jẹ́ àkókò ìdánwò jákèjádò ilẹ̀ ayé, àwọn tí ẹ̀rù bà ni a sì sẹ́ kúrò, ìyẹn ni pé wọ́n kúrò láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní May 1918 ẹgbẹ́ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣokùnfà ìfisẹ́wọ̀n àwọn òṣìṣẹ́ Watch Tower Society, ṣùgbọ́n oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, a dá wọn sílẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n sọ pé wọn ò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn wọ́n. Láti ọdún 1919, ètò àwọn èèyàn Ọlọ́run tí a ti dán wò tí a sì ti yọ́ mọ́ ń fi ìtara tẹ̀ síwájú láti kéde Ìjọba Jèhófà tó wà lọ́wọ́ Kristi Jésù gẹ́gẹ́ bí ìrètí aráyé.—Málákì 3:1-3.
Kò sí àní-àní pé ìdájọ́ ẹ̀bi ni ẹgbẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì gbà nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ àbẹ̀wò rẹ̀ lọ́dún 1918. Yàtọ̀ sí pé àwọn àlùfáà náà ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run, wọ́n tún mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ńlá wá sórí ara wọn nípa ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń bára wọn jagun nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. (Ìṣípayá 18:21, 24) Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn fi ìrètí wọn sínú Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè téèyàn dá sílẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọdún 1919, ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti gbogbo ìsìn èké àgbáyé lápapọ̀ ti pàdánù ojú rere Ọlọ́run.
-