“Ẹ Mú Gbogbo Idamẹwaa Wá Sí Ile-Iṣura”
“Ẹ sì fi eyi dán mi wò nisinsinyi, bi emi kì yoo bá ṣí ferese ọrun fun yin, ki ń sì tú ibukun jade fun yin.”—MALAKI 3:10.
1. (a) Ni ọrundun karun-un B.C.E., ikesini wo ni Jehofa fun awọn eniyan rẹ̀? (b) Ni ọrundun kìn-ín-ní C.E., ki ni o jẹ iyọrisi wíwá ti Jehofa wa sinu tẹmpili fun idajọ?
NI ỌRUNDUN karun-un B.C.E., awọn ọmọ Israeli ti di alaiṣootọ si Jehofa. Wọn ti fawọ idamẹwaa sẹhin wọn sì ti mu awọn ẹran alaiyẹ wá si tẹmpili bi irubọ. Bi eyi tilẹ ri bẹẹ, Jehofa ṣeleri pe bi wọn yoo bá mú gbogbo idamẹwaa wa sinu ile iṣura, oun yoo rọjo ibukun tobẹẹ ti ààyè kì yoo fi gbà á. (Malaki 3:8-10) Ni nǹkan bii 500 ọdun lẹhin naa, Jehofa, ti Jesu ṣoju fun gẹgẹ bii onṣẹ majẹmu Rẹ̀, wá sinu tẹmpili ni Jerusalemu fun idajọ. (Malaki 3:1) Israeli gẹgẹ bi orilẹ-ede ni a ri bi alaikunju oṣuwọn, ṣugbọn awọn ẹnikọọkan ti wọn pada sọdọ Jehofa ni a bukun ni jingbinni. (Malaki 3:7) A fi ororo yàn wọn lati di awọn ọmọkunrin Jehofa nipa ti ẹmi, iṣẹda titun kan, “Israeli Ọlọrun.”—Galatia 6:16; Romu 3:25, 26.
2. Nigba wo ni Malaki 3:1-10 yoo ni imuṣẹ ẹlẹẹkeji, ki sì ni a késí wa lati ṣe ni isopọ pẹlu eyi?
2 Ni nǹkan bii 1,900 ọdun lẹhin eyi, ni 1914, Jesu ni a gbé gorí ìtẹ́ bi Ọba Ijọba ọrun ti Ọlọrun, tí akoko sì tó fun awọn ọ̀rọ̀ onimiisi atọrunwa naa ni Malaki 3:1-10 lati ni imuṣẹ ẹlẹẹkeji. Ni isopọ pẹlu iṣẹlẹ ti ń ru imọlara soke yii, awọn Kristian lonii ni a késí lati mú gbogbo idamẹwaa wa sinu ile iṣura. Bi a ba ṣe bẹẹ, awa pẹlu yoo gbadun awọn ibukun tobẹẹ ti ààyè kì yoo fi gbà á.
3. Ta ni onṣẹ naa ti ń tun ọ̀nà ṣe niwaju Jehofa (a) ni ọrundun kìn-ín-ní? (b) ṣaaju ogun agbaye kìn-ín-ní?
3 Niti wíwá rẹ̀ sinu tẹmpili naa, Jehofa sọ pe: “Kiyesi i, Emi ó rán onṣẹ mi, yoo si tun ọ̀nà ṣe niwaju mi.” (Malaki 3:1) Gẹgẹ bi imuṣẹ ọrundun kìn-ín-ní fun eyi, Johannu Arinibọmi wá si Israeli ó sì ń waasu ironupiwada awọn ẹ̀ṣẹ̀. (Marku 1:2, 3) Iṣẹ́ imurasilẹ kankan ha wà ni isopọ pẹlu wíwá Jehofa sinu tẹmpili rẹ̀ lẹẹkeji bi? Bẹẹni. Ni awọn ẹwadun ṣaaju ogun agbaye kìn-ín-ní, awọn Akẹkọọ Bibeli farahan lori ibi-iran ayé ní kíkọ́ni ni ẹkọ Bibeli mimọ gaara ti wọn sì ń tudii awọn irọ alaibọla fun Ọlọrun, iru bii Mẹtalọkan ati ẹkọ iná ọ̀run-àpáàdì. Wọn tún ṣekilọ nipa opin Akoko awọn Keferi tí ń bọwa ni 1914. Ọpọlọpọ dahunpada si awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ otitọ wọnyi.—Orin Dafidi 43:3; Matteu 5:14, 16.
4. Ibeere wo ni a nilati yanju lakooko ọjọ Oluwa?
4 Ọdun 1914 bẹrẹ ohun ti Bibeli pe ni “ọjọ Oluwa.” (Ìfihàn 1:10) Awọn iṣẹlẹ ṣiṣe pataki gidigidi ni yoo wáyé lakooko ọjọ yẹn, o ni ninu dídá “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọ-inu naa” mọ yatọ ati yíyan iyẹn lati “ṣe olori gbogbo ohun ti [Ọ̀gá naa] ní.” (Matteu 24:45-47) Nigba naa lọ́hùn-ún ni 1914, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ṣọọṣi jẹwọ pe awọn jẹ Kristian. Awujọ wo ni Ọga naa, Jesu Kristi, yoo gba gẹgẹ bi ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa? Ibeere yẹn ni a reti pe ki o yanju nigba ti Jehofa wa sinu tẹmpili naa.
Wíwá Sinu Tẹmpili Tẹmi Naa
5, 6. (a) Si tẹmpili wo ni Jehofa wa fun idajọ? (b) Iru idajọ wo ni Kristẹndọm gbà lati ọ̀dọ̀ Jehofa?
5 Bi o ti wu ki o ri, sinu tẹmpili wo ni ó wá? Ni kedere kìí ṣe sinu tẹmpili gidi kan ni Jerusalemu. Eyi ti o kẹhin lara awọn tẹmpili wọnyẹn ni a parun nigba naa lọ́hùn-ún ni 70 C.E. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa ní tẹmpili titobi ju kan tí eyi ti o wà ni Jerusalemu jẹ ojiji iṣaaju fun. Paulu sọrọ nipa tẹmpili titobi ju yii o si fihàn bi itobilọla rẹ̀ ti ri nitootọ, pẹlu ibi mimọ kan ni ọrun ati agbala kan nihin-in lori ilẹ̀-ayé. (Heberu 9:11, 12, 24; 10:19, 20) Sinu tẹmpili tẹmi titobi yii ni Jehofa wá fun iṣẹ́ idajọ kan.—Fiwe Ìfihàn 11:1; 15:8.
6 Nigba wo ni iyẹn ṣẹlẹ? Ni ibamu pẹlu ẹ̀rí rẹpẹtẹ ti o wà larọọwọto, ni 1918 ni.a Ki ni iyọrisi rẹ̀? Niti Kristẹndọm, Jehofa rí eto-ajọ kan ti ọwọ́ rẹ̀ kun fun ẹ̀jẹ̀, eto-igbekalẹ isin ẹlẹgbin kan ti o ti fi iwakiwa gbé araarẹ̀ tà fun ayé yii, ni siso araarẹ̀ pọ̀ pẹlu awọn alaasiki ti o si ń ni awọn otoṣi lara, ni kíkọ́ wọn ni awọn ẹkọ oloriṣa dipo ki o sọ ijọsin mimọgaara dàṣà. (Jakọbu 1:27; 4:4) Nipasẹ Malaki, Jehofa ti kilọ pe: “Emi o sì ṣe ẹlẹ́rìí yiyara si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn abura èké, ati awọn ti o ni alágbàṣe lara ninu ọ̀yà rẹ̀, ati opó, ati alainibaba.” (Malaki 3:5) Kristẹndọm ti ṣe gbogbo eyi ati eyi ti o buru ju. Nigba ti o fi maa di 1919 o ti wá hàn kedere pe Jehofa ti dá a lẹbi iparun papọ pẹlu iyoku Babiloni Nla, isin eke agbaye ràgàjì naa. Lati ìgbà naa lọ, ipe naa ti jade lọ sọdọ awọn ẹni ọlọkantitọ pe: “Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹyin eniyan mi.”—Ìfihàn 18:1, 4.
7. Ta ni Jesu fihàn gẹgẹ bi ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa?
7 Nigba naa, ta ni ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa? Ni ọrundun kìn-ín-ní, o bẹrẹ pẹlu awujọ kereje naa ti wọn dahunpada si iṣẹ́ ijẹrii ti Johannu Arinibọmi ati ti Jesu, onṣẹ majẹmu naa. Ni ọrundun tiwa, ó jẹ́ awọn ẹgbẹrun diẹ ti wọn dahunpada si iṣẹ imurasilẹ awọn Akẹkọọ Bibeli lakooko awọn ọdun ti wọn ṣaaju Ogun Agbaye Kìn-ín-ní. Awọn wọnyi farada awọn adanwo lilekoko lakooko ogun agbaye kìn-ín-ní naa, ṣugbọn wọn fihàn pe ọkan-aya wọn wà pẹlu Jehofa.
Iṣẹ́ Iwẹnumọ Kan
8, 9. Nigba naa lọ́hùn-ún ni 1918, awọn ọ̀nà wo ni ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọ-inu naa fi nilo iwẹnumọ, ileri wo sì ni Jehofa ti ṣe nipa eyi?
8 Bi o ti wu ki o ri, awujọ yii paapaa nilo iwẹnumọ. Awọn kan ti wọn ti so araawọn pọ̀ mọ́ wọn yipada lati jẹ awọn ọ̀tá igbagbọ naa ti a sì nilati gbá wọn da sode. (Filippi 3:18) Awọn miiran kò muratan lati tẹwọgba awọn ẹrù-iṣẹ́ tí ṣiṣiṣẹsin Jehofa ni ninu ti wọn si tipa bẹẹ sú lọ. (Heberu 2:1) Yatọ si iyẹn, awọn aṣa Babiloni kan ṣi ṣẹku ti o yẹ ki wọn mú kuro. Niti eto-ajọ pẹlu ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa nilo iwẹnumọ. Ipo titọ niti aidasi tọtuntosi ayé yii ni wọn nilo lati mọ ki wọn si fisilo. Bi ayé naa sì ti tubọ ń di ẹlẹgbin sii, wọn nilati ja ija lile lati mú iwa aimọ niti iwarere ati tẹmi kuro ninu awọn ijọ.—Fiwe Juda 3, 4.
9 Bẹẹni, iwẹnumọ ni a nilo, ṣugbọn Jehofa ti fi tifẹtifẹ ṣeleri niti Jesu ti a ti gbé gorí ìtẹ́ naa pe: “Oun gbọdọ jokoo gẹgẹ bi olùyọ́mọ́ ati olùwẹ̀mọ́ fadaka kan oun sì gbọdọ yọ́ awọn ọmọ Lefi mọ́; oun sì gbọdọ mú wọn ṣe kedere bii wura ati bii fadaka, dajudaju wọn yoo sì jẹ si Jehofa awọn eniyan ti ń mú ọrẹ-ẹbọ ẹbun kan wa ninu ododo.” (Malaki 3:3, NW) Bẹrẹ ni 1918, Jehofa, nipasẹ onṣẹ majẹmu yii, ti mú ileri yii ṣẹ o si ti wẹ awọn eniyan rẹ̀ mọ́.
10. Iru irubọ wo ni awọn eniyan Ọlọrun mú wa, ikesini wo si ni Jehofa fun wọn?
10 Awọn ẹni-ami-ororo arakunrin Kristi naa ati ogunlọgọ nla ti wọn darapọ mọ wọn lẹhin naa ninu iṣẹ-isin Jehofa gbogbo wọn ni wọn janfaani lati inu igbesẹ Jehofa gẹgẹ bi olùyọ́mọ́ ati olùwẹ̀mọ́ fadaka. (Ìfihàn 7:9, 14, 15) Gẹgẹ bi eto-ajọ kan, wọn wá, wọn si ń wá sibẹ, ni mímú ọrẹ-ẹbọ ẹbun kan wa ninu ododo. Ọrẹ-ẹbọ wọn si “wu Oluwa, gẹgẹ bii ti ọjọ igbaani, ati gẹgẹ bii ọdun atijọ.” (Malaki 3:4) Awọn wọnyi ni Jehofa késí lọna asọtẹlẹ pe: “Ẹ mú gbogbo idamẹwaa wá si ile iṣura, ki ounjẹ baa lè wà ni ile mi, ẹ sì fi eyi dán mi wò nisinsinyi, bi emi kì yoo bá ṣi awọn ferese ọrun fun yin, ki ń sì tú ibukun jade fun yin.”—Malaki 3:10.
Awọn Irubọ ati Idamẹwaa
11. Eeṣe ti a kò fi beere fun awọn irubọ ni ibamu pẹlu eto-igbekalẹ Ofin Mose mọ́?
11 Ni ọjọ Malaki awọn eniyan Ọlọrun mú awọn irubọ ati idamẹwaa gidi, bii ọkà, èso, ati ẹran ọsin wa. Koda ni ọjọ Jesu, awọn ọmọ Israeli oluṣotitọ ṣe awọn irubọ gidi ni tẹmpili. Bi o ti wu ki o ri, lẹhin iku Jesu gbogbo iyẹn yipada. Ofin naa ni a mú wá sopin, ti o ni ninu àṣẹ naa lati mú awọn irubọ ohun ti ara ati awọn idamẹwaa gidi pato wa. (Efesu 2:15) Jesu mú iru awọn irubọ ohun ti ara ati awọn idamẹwaa gidi pato wa. (Efesu 2:15) Jesu mú iru awọn irubọ alasọtẹlẹ naa labẹ Ofin ṣẹ. (Efesu 5:2; Heberu 10:1, 2, 10) Ni ọ̀nà wo, nigba naa, ni awọn Kristian lè gbà mú awọn irubọ ati awọn idamẹwaa wọlé?
12. Iru awọn irubọ ati ẹbọ nipa tẹmi wo ni awọn Kristian ń ṣe?
12 Fun wọn, awọn irubọ lọna ti o tayọ jẹ́ iru ti ẹmi kan. (Fiwe Filippi 2:17; 2 Timoti 4:6.) Fun apẹẹrẹ, Paulu sọrọ nipa iṣẹ́ iwaasu gẹgẹ bi irubọ kan nigba ti o sọ pe: “Ǹjẹ́ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ́ ki a maa rú ẹbọ iyin si Ọlọrun nigbagbogbo, eyiini ni eso ètè wa, ti ń jẹwọ orukọ rẹ̀.” O tọkasi iru ẹbọ nipa tẹmi miiran nigba ti o rọ̀ wa pe: “Ṣugbọn ati maa ṣoore oun ati maa pin funni ẹ maṣe gbagbe: nitori iru ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ.” (Heberu 13:15, 16) Nigba ti awọn òbí ba ń fun awọn ọmọ wọn niṣiiri lati kowọnu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna, a le sọ pe wọn ń fi wọn rubọ si Jehofa, gan-an gẹgẹ bi Jefta ti fi ọmọbinrin rẹ̀ rubọ gẹgẹ bi “ẹbọ sisun” si Ọlọrun, ẹni ti o ti fun un ni ijagunmolu.—Awọn Onidajọ 11:30, 31, 39.
13. Eeṣe ti a kò fi beere lọwọ awọn Kristian lati funni ni idamẹwaa gidi kan ninu ohun ti ń wọle fun wọn?
13 Bi o ti wu ki o ri, ọ̀ràn ti idamẹwaa ń kọ́? Awọn Kristian ha wà labẹ aigbọdọmaṣe lati ya idamẹwaa kan lara ohun-ìní ti ara ti ń wọle fun wọn sọtọ ki wọn sì fi fun eto-ajọ Jehofa, ni ifiwera pẹlu ohun ti wọn ń ṣe ninu awọn ṣọọṣi Kristẹndọm kan bi? Rara, a kò beere fun iyẹn. Kò si iwe mimọ kankan ti o sọ iru ofin bẹẹ fun awọn Kristian. Nigba ti Paulu ń gba ọrẹ fun awọn alaini ni Judea, kò mẹnukan iye kan pato ti a nilati fifunni. Kaka bẹẹ, o sọ pe: “Ki olukuluku eniyan ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu ni ọkàn rẹ̀; kìí ṣe afekunṣe, tabi ti alaigbọdọmaṣe: nitori Ọlọrun fẹ́ oninudidun ọlọ́rẹ.” (2 Korinti 9:7) Ni sisọrọ nipa awọn ti wọn wà ninu akanṣe iṣẹ-ojiṣẹ, Paulu fihàn pe nigba ti o jẹ pe a ń ṣetilẹhin fun awọn kan lọna titọ nipasẹ awọn ọrẹ atinuwa, oun muratan lati ṣiṣẹ lati ṣetilẹhin fun ara oun. (Iṣe 18:3, 4; 1 Korinti 9:13-15) Kò si awọn idamẹwaa kankan ti a yàn fun ète yii.
14. (a) Eeṣe ti mimu idamẹwaa wá kò fi duro fun fifun Jehofa ni gbogbo araawa? (b) Ki ni idamẹwaa duro fun?
14 Ni kedere, fun awọn Kristian idamẹwaa ṣapẹẹrẹ, tabi duro fun, ohun kan. Niwọn bi o ti jẹ idamẹwaa tí nọmba naa, mẹwaa, ninu Bibeli sì sábà maa ń ṣapẹẹrẹ ijẹpipe ori ilẹ̀-ayé, ǹjẹ́ idamẹwaa ha ṣapẹẹrẹ fifun Jehofa ni gbogbo araawa? Bẹẹkọ. Nigba ti a ya araawa si mimọ fun Jehofa ti a sì fi apẹẹrẹ eyi hàn nipasẹ baptism ninu omi, ìgbà yẹn ni a fi gbogbo araawa fun un. Lati ìgbà iyasimimọ wa, kò si ohunkohun ti a ní ti kò figba kan jẹ́ ti Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa yọnda ẹnikọọkan lati ṣepinfunni ohun ti o jẹ tiwọn. Nitori naa idamẹwaa duro fun apá naa ti o jẹ tiwa ti a mú wá fun Jehofa, tabi lo ninu iṣẹ-isin Jehofa, gẹgẹ bi àmì apẹẹrẹ ifẹ wa fun un ati mimọ otitọ naa pé a jẹ tirẹ̀. Idamẹwaa ti ode-oni ko wulẹ nilati jẹ ipin kan ninu mẹwaa. Ninu awọn ọ̀ràn kan yoo kere ju iyẹn lọ. Ninu omiran yoo ju bẹẹ lọ. Ẹnikọọkan ń mu ohun ti ọkan-aya rẹ̀ bá sún un lati múwá wa ati ohun ti ayika ipo rẹ̀ bá yọnda.
15, 16. Ki ni idamẹwaa wa nipa tẹmi ni ninu?
15 Ki ni ohun ti idamẹwaa nipa tẹmi yii ni ninu? Fun ohun kan, a fun Jehofa ni akoko ati okun wa. Akoko ti a ń lo ni awọn ipade, ni pipesẹ si awọn apejọ ati awọn apejọpọ, ninu iṣẹ-isin papa, gbogbo iwọnyi jẹ ohun kan ti a ń fi fun Jehofa—apakan idamẹwaa wa. Akoko ati okun ti a ń lo lati ṣebẹwo sọdọ awọn alaisan ti a sì fi ń ran awọn ẹlomiran lọwọ—bakan naa, iwọnyi jẹ apakan idamẹwaa wa. Ṣiṣe iranlọwọ ninu kikọ awọn Gbọngan Ijọba ati kikopa ninu iṣẹ́ iṣatunṣe ati isọdimimọ gbọngan bakan naa tun jẹ apakan ninu rẹ̀.
16 Idamẹwaa wa tún ni ninu itilẹhin niti ọ̀ràn inawo. Pẹlu ibisi ara-ọtọ ti eto-ajọ Jehofa ní awọn ọdun aipẹ yii, awọn iṣẹ́ aigbọdọmaṣe ti ọ̀ràn inawo ti di pupọ sii. Awọn Gbọngan Ijọba titun ni a nilo, ni isopọ pẹlu awọn ile lilo ẹka ati awọn Gbọngan Apejọ titun, papọ pẹlu iṣatunṣe awọn wọnni ti a ti kọ́ tẹlẹ. Kíkájú awọn inawo awọn wọnni ti wọn ti mú araawọn wà larọọwọto fun akanṣe iṣẹ-isin—ni ṣiṣe awọn irubọ ara-ẹni titobi lọpọ ìgbà lati ṣe bẹẹ—tun pilẹ jẹ ipenija kíkàmàmà kan. Ni 1991 iye owo ti a lò lati gbọ́ bukata awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun, awọn alaboojuto arinrin-ajo, ati awọn aṣaaju-ọna akanṣe nikan jásí iye ti o ju 40 million dollar lọ, gbogbo eyi ni a ti pese nipasẹ awọn ọrẹ afinnufindọṣe.
17. Ki ni ohun naa gan-an ti a nilati fifunni gẹgẹ bii idamẹwaa wa nipa tẹmi?
17 Ki ni ohun naa gan-an ti a nilati funni gẹgẹ bi idamẹwaa wa nipa tẹmi? Jehofa kò fi iye ìpín pato kan lélẹ̀. Bi eyi tilẹ ri bẹẹ, imọlara naa pe a ń fọkan ṣiṣẹsin, ojulowo ifẹ fun Jehofa ati awọn arakunrin wa, ati pẹlu imọlara ijẹkanjukanju lati inu mímọ̀ pe awọn ẹmi wà lati gbala, ń fun wa ni iṣiri lati mú gbogbo idamẹwaa wa nipa tẹmi wá. A nimọlara isunniṣe lati ṣiṣẹsin Jehofa de ààyè ti o ga julọ ti o ṣeeṣe. Bi a ba nilati fawọsẹhin tabi fi araawa tabi awọn ohun àmúṣọrọ̀ wa funni pẹlu kunrungbun, eyi yoo dọgba pẹlu jíja Ọlọrun lólè.—Fiwe Luku 21:1-4.
A Bukun Wọn Tobẹẹ Ti Kò Fi Sí Ààyè Tó Lati Gbà Á
18, 19. Bawo ni a ṣe bukun awọn eniyan Jehofa fun mimu gbogbo idamẹwaa wọn wá?
18 Láti 1919, awọn eniyan Jehofa ti fi iwa-ọlawọ dahunpada niti akoko, okun, ati awọn ohun àmúṣọrọ̀ inawo wọn si aini iṣẹ́ iwaasu naa. Nitootọ wọn ti mú gbogbo idamẹwaa wa sinu ile iṣura. Gẹgẹ bi iyọrisi eyi, Jehofa ti mu ileri rẹ̀ ṣẹ ó si ti tú ibukun jade tobẹẹ ti kò fi sí ààyè tó lati gbà á. Eyi ni a ti ri lọna ti ń múnijígìrì julọ ninu idagbasoke wọn ni iye. Lati iwọnba ẹgbẹrun diẹ awọn ẹni-ami-ororo ti wọn ń ṣiṣẹsin Jehofa nigba ti o wá sinu tẹmpili rẹ̀ ni 1918, wọn ti dagba titi di oni yii ti awọn ẹni-ami-ororo naa papọ pẹlu awọn alabaakẹgbẹ wọn, awọn agutan miiran, fi tó iye ti ó rekọja million mẹrin ni awọn ilẹ ọtọọtọ ti wọn jẹ́ 211. (Isaiah 60:22) Awọn wọnyi ni a tun ti fi idagbasoke ti ń baa lọ ninu òye otitọ naa bukun. Ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ naa ni a ti tubọ mu daju fun wọn. Igbọkanle wọn ninu imuṣẹ awọn ète Jehofa ni a ti tubọ fidi rẹ̀ mulẹ. (2 Peteru 1:19) Nitootọ wọn jẹ awọn eniyan kan “ti Jehofa kọlẹkọọ.”—Isaiah 54:13, NW.
19 Nipasẹ Malaki, Jehofa sọ asọtẹlẹ ibukun siwaju sii: “Nigba naa ni awọn ti ó bẹru Oluwa ń ba araawọn sọrọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, ó sì gbọ́, a sì kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹru Oluwa, ti wọn sì ń ṣe aṣaro orukọ rẹ̀.” (Malaki 3:16) Ninu gbogbo awọn eto-ajọ ti wọn ń fidaniloju sọ pe awọn jẹ́ Kristian, kìkì awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nikanṣoṣo ni wọn ń ṣe aṣaro orukọ rẹ̀ ti wọn sì ń gbe e ga laaarin awọn orilẹ-ede. (Orin Dafidi 34:3) Ẹ wo bi wọn ti layọ tó lati ni idaniloju naa pe Jehofa ranti iṣotitọ wọn!
20, 21. (a) Ibatan onibukun wo ni awọn Kristian tootọ ń gbadun? (b) Niti isin Kristian, iyasọtọọtọ wo ni o tubọ ń ṣe kedere siwaju ati siwaju sii?
20 Awọn aṣẹku ẹni-ami-ororo jẹ awọn eniyan akanṣe fun Jehofa, ti awọn ogunlọgọ nla, ti wọn ń rọ́ wọle lati ba wọn kẹgbẹpọ, si ń karugbin awọn ibukun ijọsin mimọgaara pẹlu wọn. (Sekariah 8:23) Nipasẹ Malaki, Jehofa ṣeleri pe: “’Wọn yoo jẹ temi dajudaju,’ ni Jehofa awọn ọmọ-ogun wi, ‘ni ọjọ naa nigba ti emi ń mu akanṣe dukia kan jade. Emi yoo si fi ìyọ́nu hàn fun wọn, gẹgẹ bi ọkunrin kan ti ń fi ìyọ́nú hàn fun ọmọkunrin rẹ̀ ti o ń ṣiṣẹsin in.’” (Malaki 3:17, NW) Ẹ wo iru ibukun kan ti o jẹ lati mọ pe Jehofa ni iru aniyan onijẹlẹnkẹ bẹẹ fun wọn!
21 Nitootọ, siwaju ati siwaju sii ni iyatọ naa laaarin awọn Kristian tootọ ati ti èké tubọ ń farahan sii. Bi awọn eniyan Jehofa ti ń làkàkà lati pa awọn ọpa-idiwọn rẹ̀ mọ́, Kristẹndọm ń rì siwaju ati siwaju sii sinu àfọ̀ iwa-aimọ. Loootọ, awọn ọ̀rọ̀ Jehofa ti jasi otitọ pe: “Nigba naa ni ẹyin ó yipada, ẹ o si mọ iyatọ laaarin olododo ati ẹni buburu, laaarin ẹni ti ń sin Ọlọrun, ati ẹni ti kò sìn ín.”—Malaki 3:18.
22. Awọn ibukun wo ni a lè ni igbọkanle pe a o gbadun bi awa bá ń baa lọ lati mú gbogbo idamẹwaa wa wá?
22 Laipẹ laijinna, ọjọ iṣeṣiro yoo de fun awọn èké Kristian. “Kiyesi i, ọjọ naa ń bọ̀, ti yoo maa jo bi ina ileru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yoo dabii àkékù koriko: ọjọ naa ti ń bọ̀ yoo si jó wọn run, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi.” (Malaki 4:1) Awọn eniyan Jehofa mọ̀ pe yoo daabobo wọn ni akoko yẹn, gẹgẹ bi o ti daabobo orilẹ-ede tẹmi rẹ̀ nigba naa lọ́hùn-ún ni 70 C.E. (Malaki 4:2) Ẹ wo bi wọn ti layọ tó lati ni idaniloju yẹn! Nipa bayii, titi di akoko yẹn ẹ jẹ ki ẹnikọọkan wa fi imọriri wa ati ifẹ wa hàn fun Jehofa nipa mimu gbogbo idamẹwaa wá sinu ile-iṣura. Nigba naa, a le ni igbọkanle pe yoo maa baa lọ lati maa bukun wa tobẹẹ ti kì yoo fi sí ààyè tó lati gbà á.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun isọfunni siwaju sii, wo Ilé-Ìsọ́nà June 15, 1987, oju-iwe 14 si 20.
Iwọ Ha Le Ṣalaye Bi?
◻ Ni awọn akoko ode-oni, nigba wo ni Jehofa wá sinu tẹmpili pẹlu onṣẹ majẹmu rẹ̀?
◻ Ta ni ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa, iru iwẹnumọ wo sì ni wọn nilo lẹhin 1918?
◻ Iru awọn irubọ nipa tẹmi wo ni awọn Kristian tootọ mú wá fun Jehofa?
◻ Ki ni idamẹwaa ti a késí awọn Kristian lati mú wá sinu ile iṣura?
◻ Awọn ibukun wo ni awọn eniyan Ọlọrun gbadun nipa fifi idamẹwaa wọn nipa tẹmi rubọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Idamẹwaa wa nipa tẹmi ni ninu fifi agbara ati ohun àmúṣọrọ̀ rubọ lati kọ́ awọn Gbọngan Ijọba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nitori ibukun Jehofa lori awọn eniyan rẹ̀, ètò ìkọ́lé ti ó pọ̀ ni a ti nílò, eyi ti o ní ninu awọn Gbọngan Ijọba ati Gbọngan Apejọ