Ki ni Àwọ̀n-Ìpẹja ati Ẹja Tumọsi Fun Ọ?
“Ẹyin ni a fifun lati loye awọn àṣírí mimọ ti ijọba awọn ọ̀run.”—MATTEU 13:11, NW.
1, 2. Eeṣe ti a fi lè ni ọkàn-ìfẹ́ ninu awọn àkàwé Jesu?
IWỌ HA gbadun mímọ àṣírí kan tabi wíwá ojutuu si àdìtú kan bi? Ki ni bi ṣiṣe bẹẹ yoo bá ràn ọ lọwọ lati tubọ rí ipa tirẹ kedere sii ninu ète Ọlọrun? Ó mú ni layọ pe iwọ lè jere iru ijinlẹ òye alanfaani bẹẹ nipasẹ àkàwé ti Jesu fi funni. Ó ti daamu ọpọlọpọ ti wọn gbọ́ ọ ó sì ti tojúsú àìlóǹkà awọn miiran lati ìgbà naa wá, ṣugbọn iwọ lè loye rẹ̀.
2 Ṣakiyesi ohun ti Jesu sọ ni Matteu ori 13 nipa lilo ti o lo awọn àkàwé. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ beere pe: “Eeṣe ti o fi ń sọrọ fun wọn nipa lilo awọn àkàwé?” (Matteu 13:10, NW) Bẹẹni, eeṣe ti Jesu fi lo awọn àkàwé ti ọpọ julọ awọn eniyan ki yoo loye? Ó fèsì pada ni ẹsẹ 11 si 13 pe: “Ẹyin ni a fi fun lati loye awọn àṣírí mímọ́ ti ijọba awọn ọ̀run, ṣugbọn awọn eniyan wọnni ni a kò fifun. . . . Eyi ni idi ti mo fi ń sọrọ fun wọn nipa lilo awọn àkàwé, nitori pe, ni wíwò, wọn ń wò lasan, ati ni gbígbọ́, wọn ń gbọ́ lasan, bẹẹ ni òye rẹ̀ kò yé wọn.”
3. Bawo ni liloye awọn àkàwé Jesu ṣe lè mú anfaani wá fun wa?
3 Jesu lẹhin naa fi ọrọ Isaiah 6:9, 10 silo, eyi ti o ṣapejuwe awọn eniyan kan ti wọn dití ti wọn sì fọ́jú nipa tẹmi. Bi o ti wu ki o ri, awa, kò nilati rí bẹẹ. Bi a bá lóye ti a sì huwa lori awọn àkàwé rẹ̀, a lè jẹ́ alayọ gan-an—nisinsinyi ati wọnu ọjọ-ọla alailopin. Jesu pese idaniloju amárayágágá yii fun wa pe: “Alayọ ni oju yin nitori wọn rí, ati etí yin nitori wọn gbọ́.” (Matteu 13:16, NW) Idaniloju yẹn kárí gbogbo awọn apejuwe Jesu, ṣugbọn ẹ jẹ ki a kó afiyesi jọ sori owe àkàwé ṣoki ti àwọ̀n-ìpẹja, ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Matteu 13:47-50.
Apejuwe Kan Ti Ó Ní Itumọ Jijinlẹ
4. Ki ni Jesu fi àkàwé sọ, gẹgẹ bi a ti ṣe akọsilẹ rẹ̀ ní Matteu 13:47-50?
4 “Ijọba awọn ọ̀run dabii àwọ̀n-ìpẹja kan ti a dà sinu òkun ti o sì kó gbogbo oniruuru ẹja. Nigba ti ó kún wọn fà á wá si etíkun ati, ni jijokoo wọn ṣa awọn ti o dara sinu awọn ohun eelo, ṣugbọn awọn alaiyẹ ni wọn danu. Bi yoo ti ri niyẹn ni ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan: awọn angẹli yoo jade lọ wọn o sì ya awọn eniyan buruku sọtọ kuro lara awọn olododo wọn ó sì ju wọn sinu ìléru oníná. Nibẹ ni sisunkun wọn ati pipahinkeke wọn yoo wà.”
5. Iru awọn ibeere wo ni o dide niti itumọ owe àkàwé àwọ̀n-ìpẹja?
5 Boya iwọ ti rí i ki awọn eniyan maa fi àwọ̀n pẹja rí, ó keretan lori aworan sinima tabi lori tẹlifiṣọn, nitori naa owe àkàwé Jesu kò ṣoro lati foju inu wò. Ṣugbọn ki ni nipa awọn kulẹkulẹ ati itumọ rẹ̀? Fun apẹẹrẹ, Jesu sọ pe apejuwe yii dá lori “ijọba awọn ọ̀run.” Sibẹ, o daju pe oun kò ní i lọkan pe “gbogbo oniruuru” eniyan, awọn ti wọn dara ati awọn alaiyẹ, tabi ẹni buburu, yoo wà ninu Ijọba naa. Pẹlupẹlu, ta ni o ń pa ẹja naa? Ẹja pípa ati iyasọtọ yii ha wáyé ni ọjọ Jesu bi, tabi a ha lè fi mọ si akoko tiwa, “ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan” bi? Iwọ ha rí araarẹ ninu owe àkàwé yii bi? Bawo ni o ṣe lè yẹra fun pipari rẹ̀ sí wíwà lara awọn wọnni ti wọn sunkun ti wọn sì pa ehin wọn keke?
6. (a) Eeṣe ti a fi nilati ni ọkàn-ìfẹ́ mimuna ninu liloye owe àkàwé àwọ̀n-ìpẹja? (b) Ki ni kọkọrọ kan si ìlóye rẹ̀?
6 A gbọdọ ranti pe, iru awọn ibeere bẹẹ fihan pe àkàwé yii kò kúkú fi bẹẹ rọrun. Bi o ti wu ki o ri, maṣe gbagbe pe: “Alayọ ni oju yin nitori ti wọn rí, ati etí yin nitori ti wọn gbọ́.” Ẹ jẹ ki a wò ó bi a bá lè walẹ̀jìn sinu itumọ rẹ̀ ki awọn etí wa ma baa yigbì ati ki oju wa ma baa padé si ijẹpataki rẹ̀. Niti gasikiya, a ti ní kọkọrọ ṣiṣe kókó fun ṣíṣí itumọ rẹ̀. Ọrọ-ẹkọ ti o ṣaaju sọ nipa bi Jesu ṣe késí awọn ọkunrin apẹja ara Galili lati fi iṣẹ àjókòótì yẹn silẹ ki wọn sì nawọ́gán iṣẹ tẹmi gẹgẹ bi “apẹja eniyan.” (Marku 1:17) Ó sọ fun wọn pe: “Lati isinsinyi lọ iwọ yoo maa mú awọn eniyan lóòyẹ̀.”—Luku 5:10, NW.
7. Ki ni Jesu ń ṣàkàwé nigba ti o sọrọ nipa ẹja?
7 Ni ibamu pẹlu iyẹn, ẹja naa ninu owe àkàwé yii duro fun awọn eniyan. Fun idi yii, nigba ti ẹsẹ 49 sọ nipa yiya awọn ẹni buburu sọtọ kuro lara awọn olododo, ó ń tọkasi, kì í ṣe awọn ohun alaaye olododo tabi buburu ti ń gbé inu agbami òkun, ṣugbọn si awọn olododo ati eniyan buburu. Lọna kan naa, ẹsẹ 50 kò gbọdọ mú wa ronu nipa awọn ẹran omi tí ń sunkun tabi pa ehín wọn keke. Bẹẹkọ. Owe àkàwé yii dá lori kiko awọn eniyan jọpọ ati ìyàsọ́tọ̀ wọn lẹhin naa, eyi ti ó se pataki gan-an, gẹgẹ bi abajade ti fihan.
8. (a) Ki ni a lè kẹkọọ rẹ̀ niti abajade fun awọn ẹja ti kò yẹ? (b) Ni oju-iwoye ohun ti a sọ nipa awọn ẹja ti kò yẹ, ki ni a lè pari ero sí nipa Ijọba naa?
8 Ṣakiyesi pe awọn ẹja alaiyẹ, iyẹn ni, awọn ẹni buburu, ni a o gbé sọ sinu ìléru oníná, nibi ti wọn yoo ti sunkun ti wọn yoo sì pa ehín wọn keke. Nibomiran Jesu so iru ẹkún sísun ati ìpahínkeke bẹẹ mọ wíwà lẹhin ode Ijọba naa. (Matteu 8:12; 13:41, 42) Ni Matteu 5:22 ati 18:9, ó tilẹ mẹnukan “Gehenna oníná,” ti ń tọka si iparun titilae. Iyẹn kò ha fi bi o ti ṣe pataki tó lati lóye itumọ àkàwé yii ki a sì huwa lọna ti ó baa mu hàn bi? Gbogbo wa mọ pe kò sí bẹẹ ni ki yoo sí awọn ẹni buburu ninu Ijọba Ọlọrun. Fun idi yii, nigba ti Jesu sọ pe “ijọba awọn ọ̀run dabi àwọ̀n-ìpẹja,” oun ti lè ní in lọ́kàn pe ni isopọ pẹlu Ijọba Ọlọrun, ohun kan ti ó dabi àwọ̀n ti a dà silẹ lati kó oniruuru gbogbo ẹja wà.
9. Bawo ni àkàwé àwọ̀n-ìpẹja ṣe kan awọn angẹli?
9 Lẹhin ti a ba ti da àwọ̀n-ìpẹja silẹ ti a sì ti kó awọn ẹja tan, iṣẹ ìyàsọ́tọ̀ yoo wà. Awọn wo ni Jesu sọ pe ọ̀ràn kàn? Matteu 13:49 fi awọn ọkunrin apẹja aṣeyasọtọ wọnyi hàn gẹgẹ bi awọn angẹli. Nitori naa Jesu ń sọ fun wa nipa abojuto awọn angẹli lori ohun eelo kan lori ilẹ̀-ayé eyi ti a lò lati dá awọn eniyan mọ̀—awọn kan dara wọn sì yẹ fun Ijọba ọ̀run, awọn miiran jásí alaiyẹ fun ìpè yẹn.
Ẹja Pípa Naa—Nigba Wo?
10. Nipasẹ ọ̀nà ìgbàronú wo ni a fi le pinnu pe ẹja pipa naa gbooro la akoko pupọ gan-an já?
10 Àyíká ọrọ naa ràn wa lọwọ lati ṣawari ìgbà ti eyi ṣee fisilo. Ni gẹlẹ ṣaaju eyi, Jesu funni ni àkàwé kan nipa gbigbin irugbin rere, ṣugbọn nigba naa a gbin awọn èpò saaarin rẹ̀ ninu pápá naa, eyi ti o duro fun ayé. Ó ṣalaye ni Matteu 13:38 pe irugbin rere duro fun “awọn ọmọkunrin ijọba naa; ṣugbọn èpò ni awọn ọmọkunrin ẹni buburu naa.” Iwọnyi dagba ni ifẹgbẹkẹgbẹ fun ọpọ awọn ọrundun, titi di akoko ikore ni ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan. Nigba naa ni a ya èpò sọtọ ti a sì jó o dànù lẹhin ìgbà naa. Ni mímú eyi baradọgba rẹ́gí pẹlu apejuwe àwọ̀n-ìpẹja, a rí i pe fífa awọn eniyan wọnu àwọ̀n naa ni o nilati gbooro kọja akoko gigun kan.—Matteu 13:36-43.
11. Bawo ni iṣẹ ẹja pípa jakejado awọn orilẹ-ede ṣe bẹrẹ ni ọrundun kìn-ín-ní?
11 Ni ibamu pẹlu owe àkàwé Jesu, awọn ẹja ni a o kojọpọ ni wọ̀ǹdùrùkù, iyẹn ni pe, àwọ̀n ẹja kó ati ẹja rere ati ẹja ti kò yẹ mọra. Nigba ti awọn aposteli wà laaye, awọn angẹli ti wọn ń daabobo iṣẹ ẹja pípa naa lo eto-ajọ Kristian ti Ọlọrun lati mú “awọn ẹja” ti wọn di awọn Kristian ẹni-ami-ororo. Iwọ le sọ pe ṣaaju Pentekosti 33 C.E., iṣẹ apẹja eniyan ti Jesu ṣe fi àwọ̀n kó nǹkan bii 120 ọmọ-ẹhin. (Iṣe 1:15) Ṣugbọn gbàrà ti ijọ awọn Kristian ẹni-ami-ororo ti fidi mulẹ, ẹja pípa naa pẹlu ohun eelo àwọ̀n-ìpẹja bẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ẹja rere ni a sì mú. Lati 36 C.E., ẹja pípa naa tankalẹ yika wọnu awọn omi jakejado awọn orilẹ-ede, gẹgẹ bi a ti fa awọn Keferi mọ́ isin Kristian ti wọn sì di mẹmba ijọ ẹni-ami-ororo ti Kristi.—Iṣe 10:1, 2, 23-48.
12. Ki ni ó gbèrú lẹhin iku awọn aposteli?
12 Ni awọn ọrundun lẹhin ti awọn aposteli ti kuro lójú iran, awọn Kristian diẹ wà ti wọn ń baa lọ lati sakun lati rí ki wọn sì dìrọ̀ mọ́ otitọ atọrunwa. Ó keretan diẹ ninu iwọnyi ní itẹwọgba Ọlọrun, ó sì fami ororo yan wọn pẹlu ẹmi mimọ. Sibẹ, iku awọn aposteli mú agbara idari aṣediwọ naa kuro, ni fifaayegba itankalẹ rẹ́kẹrẹ̀kẹ ipẹhinda lati gbèrú. (2 Tessalonika 2:7, 8) Eto-ajọ kan dagba soke ti ó ń fi àìyẹ jẹwọ jíjẹ́ ijọ Ọlọrun. Ó fi èrú sọ pe oun jẹ́ orilẹ-ede mimọ ti a fi ẹmi Ọlọrun yan lati ṣakoso pẹlu Jesu.
13. Eeṣe ti a fi lè sọ pe Kristendom ni ipa kan ninu igbeṣẹṣe àwọ̀n-ìpẹja?
13 Iwọ ha ronu pe awọn alaiṣootọ olufẹnu lasan jẹwọ isin Kristian ní apá kankan ninu àkàwé naa nipa àwọ̀n-ìpẹja bi? Ó dara, idi wà lati dahun pe, bẹẹni, wọn ní. Àwọ̀n-ìpẹja iṣapẹẹrẹ naa ní Kristendom ninu. Loootọ, fun ọpọ sanmani Ṣọọṣi Katoliki ti gbiyanju lati tọju Bibeli pamọ fun awọn eniyan gbáàtúù. Bi o tilẹ ri bẹẹ, la ọpọ ọrundun ja awọn mẹmba Kristendom kó ipa pataki ninu titumọ, ṣíṣẹ̀dà, ati pípín Ọrọ Ọlọrun kiri. Awọn ṣọọṣi lẹhin naa dá ẹgbẹ awujọ Bibeli, eyi ti ó tumọ Bibeli si èdè awọn ilẹ jijinna réré silẹ tabi ṣetilẹhin fun un. Wọn tun rán awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun oniṣegun ati olukọ jade, awọn ti wọn sọ awọn eniyan di Kristian onírẹsì. Eyi kó ọpọ jaburata awọn ẹja ti kò yẹ jọ, awọn ti kò ni itẹwọgba Ọlọrun. Ṣugbọn ó keretan ó sọ araadọta-ọkẹ awọn ti wọn kì í ṣe Kristian di ojulumọ Bibeli ati si oriṣi isin Kristian kan, bi o tilẹ jẹ pe o dibajẹ.
14. Bawo ni a ṣe ṣetilẹhin fun pípa awọn ẹja ti o dara nipasẹ iṣẹ tí awọn ṣọọṣi Kristendom ṣe?
14 Ni gbogbo àfo akoko naa, awọn oluṣotitọ ti wọn wà kaakiri ti wọn ń dìrọ̀ mọ́ Ọrọ Ọlọrun lo araawọn tokunratokunra bi wọn ti lè ṣe daradara julọ tó. Ni akoko eyikeyii kan, wọn parapọ jẹ ijọ ẹni ami ororo tootọ ti Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé. A sì lè ni idaniloju pe awọn pẹlu ń mú ẹja, tabi awọn eniyan, ọpọ ninu awọn ẹni ti Ọlọrun yoo wò gẹgẹ bi ẹni rere awọn ẹni ti yoo sì fami ororo yàn pẹlu ẹmi rẹ̀. (Romu 8:14-17) Ó ṣeeṣe fun awọn olufẹnujẹwọ isin Kristian rere wọnyi lati mú otitọ Bibeli wá fun ọpọlọpọ ti wọn ti di Kristian onírẹsì tabi ti wọn ti jere ìmọ̀ Bibeli diẹ lati inu Iwe Mimọ ti a tumọ si èdè ahọ́n wọn lati ọwọ́ awọn ẹgbẹ awujọ Bibeli ti Kristendom. Loootọ, kiko awọn ẹja rere jọ ń baa lọ, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ julọ tí awọn Kristendom kójọ kò yẹ ni oju-iwoye Ọlọrun.
15. Ní ṣàkó, ki ni àwọ̀n-ìpẹja duro fun ninu owe àkàwé naa?
15 Nitori naa àwọ̀n-ìpẹja duro fun ohun eelo ti ilẹ̀-ayé ti o fẹnujẹwọ jijẹ́ ijọ Ọlọrun ti ó sì ń kó awọn ẹja wọle. Ó ti ní Kristendom ati ijọ awọn Kristian ẹni ami ororo ninu, eyi ti a sọ kẹhin yii si ti ń baa lọ lati kó awọn ẹja rere jọ, labẹ idari awọn angẹli ti a kò lè fojuri, ní ìlà pẹlu Matteu 13:49.
Akoko Tiwa Jẹ Akanṣe
16, 17. Eeṣe ti akoko ti a ń gbé ninu rẹ̀ fi ṣe pataki tobẹẹ ninu iṣiṣẹyọri àkàwé àwọ̀n-ìpẹja ti Jesu?
16 Ẹ jẹ ki a wá gbé apá pataki ti akoko yẹwo nisinsinyi. Fun ọpọ ọrundun ohun eelo àwọ̀n-ìpẹja ṣe ikojọpọ awọn ẹja rere ati ọpọlọpọ awọn ti kò yẹ, tabi awọn ẹni buburu, pẹlu. Lẹhin naa akoko dé nigba ti awọn angẹli dásí ṣiṣe iṣẹ ìyàsọ́tọ̀ kan ti ó ṣe kókó. Nigba wo? Ó dara, ẹsẹ 49 sọ ni kedere pe ó jẹ́ ni “ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan.” Eyi bá ohun ti Jesu sọ ninu apejuwe ti awọn agutan ati ewurẹ mu: “Nigba ti Ọmọkunrin eniyan bá dé ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli pẹlu rẹ̀, nigba naa ni yoo jokoo lori ìtẹ́ ogo rẹ̀. A o sì kó gbogbo awọn orilẹ-ede jọ si iwaju rẹ̀, oun yoo sì ya awọn eniyan sọ́tọ̀ kuro ninu ara wọn, gan-an gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti ń ya agutan sọ́tọ̀ kuro ninu ewurẹ.”—Matteu 25:31, 32, NW.
17 Fun idi yii, ni ibamu pẹlu Matteu 13:47-50, iṣẹ ìyàsọ́tọ̀ kan ti ó ṣe kókó labẹ idari awọn angẹli ti ń tẹsiwaju lati ìgbà ti “ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan” ti bẹrẹ ni 1914. Eyi ṣe kedere ni pataki lẹhin 1919, nigba ti a dá awọn aṣẹku ẹni-ami-ororo silẹ lominira kuro ninu ìdè-ìsìnrú, tabi ìgbèkùn tẹmi onigba kukuru, ti wọn sì tubọ di ohun eelo jijafafa fun ṣiṣaṣepari iṣẹ ẹja pípa naa.
18. Bawo ni a ti ṣe kó awọn ẹja ti o dara sinu awọn ohun eelo?
18 Ki ni ó nilati ṣẹlẹ si awọn ẹja rere ti a ti yasọtọ naa? Ẹsẹ 48 sọ pe awọn angẹli ọkunrin apẹja ti ń ṣe ìyàsọ́tọ̀ “ṣa awọn [ẹja] ti o dara sinu awọn ohun eelo, ṣugbọn awọn alaiyẹ ni wọn dànù.” Awọn ohun eelo naa jẹ ìkóhunsí tí ó ni ààbò ninu eyi ti a kó awọn ẹja ti o dara sí. Eyi ha ti ṣẹlẹ ni akoko wa bi? Dajudaju. Gẹgẹ bi a ti mú awọn ẹja iṣapẹẹrẹ ti o dara lóòyẹ̀, a ti kó wọn jọ sinu ijọ awọn Kristian tootọ. Awọn ijọ ti o dabi ohun eelo wọnyi ti ṣeranwọ lati daabobo ki ó sì fi wọn ṣura fun iṣẹ-isin atọrunwa, iwọ kò ha gbà bi? Sibẹ, ẹnikan lè ronu pe, ‘Gbogbo eyi dara ó sì bojumu, ṣugbọn ki ni ó nii ṣe pẹlu igbesi-aye mi isinsinyi ati ọjọ-ọla?’
19, 20. (a) Eeṣe ti o fi ṣekókó lonii lati ní òye owe àkàwé yii? (b) Iṣẹ ẹja pípa pataki wo ni a ti ṣe lati 1919?
19 Iṣiṣẹyọri ohun ti a ṣapejuwe nihin-in ni a kò fi mọ si awọn ọrundun ti o wà laaarin akoko awọn aposteli ati 1914. Ni akoko yẹn, ohun eelo àwọ̀n-ìpẹja wá kó awọn olùfẹnujẹ́wọ́ Kristian ti wọn jẹ́ eke ati otitọ papọ. Bẹẹni, o ń kó ati ẹja ti kò yẹ ati ẹja ti o dara jọ. Siwaju sii pẹlu, iṣẹ ìyàsọ́tọ̀ tí awọn angẹli ń ṣe kò dopin lẹhin lọhun-un ni nǹkan bii 1919. Bẹẹkọ, rárá. Ni awọn apa-iha diẹ àkàwé ti àwọ̀n-ìpẹja yii ni ó ṣee fisilo jalẹ titi di akoko wa. Ó ní wa ninu bẹẹ sì ni ọjọ-ọla wa ti ó wọle dé tán. Ó jẹ́ kanjukanju fun wa lati loye ọ̀nà ati idi ti iyẹn fi rí bẹẹ bi a bá fẹ́ ki awọn ọrọ wọnyi ṣapejuwe wa: “Alayọ ni oju yin nitori ti wọn rí, ati etí yin nitori ti wọn gbọ́” pẹlu òye.—Matteu 13:16.
20 Ó ṣeeṣe ki o mọ pe lẹhin 1919 awọn aṣẹku ẹni-ami-ororo ni ọwọ́ wọn dí ninu iṣẹ iwaasu ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn angẹli, ti wọn ń baa lọ lati lo àwọ̀n-ìpẹja iṣapẹẹrẹ lati kó awọn ẹja sókè ẹ̀bá etikun, lati ya awọn ti wọn dara kuro lara awọn ti kò yẹ. Akọsilẹ iṣiro lati akoko yẹn fihan pe mímú awọn ẹja ti o dara fun fifami ororo yan pẹlu ẹmi Ọlọrun ń baa lọ gẹgẹ bi a ti kó awọn ti o kẹhin ninu awọn 144,000 jọpọ nipasẹ àwọ̀n iṣapẹẹrẹ naa. (Ifihan 7:1-4) Ṣugbọn nigba ti ó fi maa di agbedemeji awọn ọdun 1930, ṣíṣa awọn ẹja ti o dara jọ fun fifami ororo yan pẹlu ẹmi mimọ ni o dopin ni pataki. Ǹjẹ́ ijọ awọn aṣẹku ẹni-ami-ororo yoo ha pa àwọ̀n naa tì, gẹgẹ bi a ti lè sọ ọ́, ki wọn sì wulẹ jokoo gẹlẹtẹ, ni diduro de èrè wọn ti ọ̀run bi? Ki a má ri!
Bi Ọ̀ràn Ẹja Pípa naa Ṣe Kàn Ọ
21. Ẹja pípa miiran wo ni ó ti ṣẹlẹ ni akoko wa? (Luku 23:43)
21 Àkàwé Jesu nipa àwọ̀n-ìpẹja kó afiyesi jọ sori awọn ẹja ti o dara ti a o san èrè fun pẹlu àyè kan ninu Ijọba awọn ọ̀run. Sibẹ, yatọ si apejuwe yẹn, ẹja pípa iṣapẹẹrẹ miiran ń ṣẹlẹ ni ìwọn gigadabu, ani gẹgẹ bi a ti ṣakawe rẹ̀ ninu ọrọ-ẹkọ ti o ṣaaju. Ẹja pípa yii, kì í ṣe fun awọn ẹja didara ti a fami ororo yàn ti a mẹnukan ninu àkàwé Jesu, ṣugbọn fun awọn ẹja iṣapẹẹrẹ ti a o mú lóòyẹ̀ ti a o sì fun ni ireti agbayanu ti ìyè lori paradise ilẹ̀-ayé.—Ifihan 7:9, 10; fiwe Matteu 25:31-46.
22. Abajade alayọ wo ni a lè niriiri rẹ̀, ki sì ni afidipo naa?
22 Bi iwọ bá fọkan ṣikẹ ireti yẹn, nigba naa iwọ lè yọ̀ pe Jehofa ti fààyè gba iṣẹ ẹja pípa agbẹmila kan lati maa baa lọ titi di isinsinyi. Eyi ti mu ki o ṣeeṣe fun ọ lati jere ifojusọna agbayanu kan. Ifojusọna kẹ̀? Bẹẹni, iyẹn ni ọrọ ti o ba a mu lati lò, niwọn bi iyọrisi yoo ti wà ni ibamu pẹlu iṣotitọ wa ti ń baa lọ si Ẹni naa ti ń dari isapa ẹja pípa ti ń lọ lọwọ. (Sefaniah 2:3) Sọyeranti lati inu àkàwé naa pe kì í ṣe gbogbo awọn ẹja ti a kó sókè nipasẹ àwọ̀n-ìpẹja ni o niriiri abajade olojurere. Jesu sọ pe awọn ti kò yẹ, tabi awọn buburu, ni a o yasọtọ kuro lara awọn olododo. Fun ki ni? Ni Matteu 13:50, Jesu ṣapejuwe abajade wiwuwo naa fun awọn ẹja ti kò yẹ, tabi buburu. Awọn wọnyi ni a o dà sinu ìléru oníná, ti o tumọsi iparun ayeraye.—Ifihan 21:8.
23. Ki ni ó mú iṣẹ ẹja pípa naa ṣe pataki tobẹẹ lonii?
23 Fun awọn ẹja didara ti a fami ororo yan, ati bakan naa fun awọn ẹja iṣapẹẹrẹ ti wọn lè walaaye titilae lori ilẹ̀-ayé, ọjọ-ọla ologo wà. Pẹlu idi rere, nigba naa, awọn angẹli ń rí sí i pe nisinsinyi gan-an iṣẹ́ ẹja pípa alaṣeyọrisirere ni a ń bá lọ yika ayé. Ẹ sì wo iru awọn ẹja iṣapẹẹrẹ ti a ti mú! Iwọ yoo tọna ni sisọ iyẹn ni ọ̀nà tirẹ̀, pe ó wulẹ jẹ́ẹja kíkó agbayanu bii ti ẹja gidi ti awọn aposteli gbadun nigba ti wọn da àwọ̀n wọn sódò tẹle idari Jesu.
24. Ki ni a gbọdọ fẹ́ lati ṣe nipa ẹja pípa tẹmi?
24 Iwọ ha ń ní ipin alaapọn gẹgẹ bi o ti ṣeeṣe tó ninu iṣẹ agbẹmila ti ẹja pípa tẹmi yii bi? Laika bi ipin wa lẹnikọọkan ti lè gbooro tó titi di akoko yii, ẹnikọọkan wa lè wo ohun ti a ń ṣaṣepari rẹ̀ yika ayé ninu iṣẹ ẹja pípa ńláǹlà ati iṣẹ agbẹmila ti ń lọ lọwọ nisinsinyi lọna ti ń mú anfaani wá. Ṣiṣe bẹẹ gbọdọ ru wa soke sí itara giga sii ninu dída àwọ̀n sódò fun ẹja kíkó ni awọn ọjọ ti ó wa ni iwaju gan-an!—Fiwe Matteu 13:23; 1 Tessalonika 4:1.
Iwọ Ha Sọyeranti Awọn Kókó Wọnyi Bi?
◻ Ki ni iru oriṣi ẹja meji ninu owe àkàwé Jesu nipa àwọ̀n ẹja duro fun?
◻ Ni ero itumọ wo ni igbeṣẹṣe àwọ̀n-ìpẹja naa gbà ní awọn ṣọọṣi Kristendom ninu?
◻ Eeṣe ti ẹja pípa ti ń ṣẹlẹ ni akoko wa fi lekoko tobẹẹ?
◻ Owe àkàwé nipa àwọ̀n-ìpẹja gbọdọ ṣamọna ẹnikọọkan wa lati ṣe iru iṣayẹwo ara-ẹni wo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Iṣẹ́ ẹja pípa ti ṣẹlẹ loju Okun Galili fun ọpọ ọrundun
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.