ORÍ KẸJỌ
“Tìtorí Èyí Ni A Ṣe Rán Mi Jáde”
1-4. (a) Báwo ni Jésù ṣe fọgbọ́n kọ́ obìnrin ará Samáríà kan lẹ́kọ̀ọ́, kí ló sì yọrí sí? (b) Báwo lọ̀ràn ọ̀hún ṣe rí lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
Ó TI tó wákàtí mélòó kan báyìí tí wọ́n ti wà lórí ìrìn. Jùdíà ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti ń fẹsẹ̀ rìn bọ̀ wá sí Gálílì tó wà ní apá àríwá. Ọ̀nà àárín ìlú Samáríà tó yá jù ni wọ́n gbà, síbẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta gbáko ló gbà wọ́n. Nǹkan bí ọjọ́kanrí ni wọ́n wọ ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Síkárì, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti dúró láti wá nǹkan panu.
2 Jésù ń sinmi lẹ́bàá kànga kan nípẹ̀kun ìlú náà ní gbogbo àkókò táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ ra oúnjẹ. Obìnrin kan wá síbẹ̀ láti pọnmi. Nítorí pé ó ti rẹ Jésù “láti inú ìrìn àjò náà,” bó bá fẹ́, ó lè sọ pé òun ò ní dá sí obìnrin náà. (Jòhánù 4:6) Kò sẹ́ni tó máa dá a lẹ́bi ká sọ pé ńṣe ló ṣe bí ẹni tí ò rí obìnrin ará Samáríà yẹn tó sì jẹ́ kó bá tiẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i ní Orí 4 nínú ìwé yìí, obìnrin yẹn ti ní láti mọ̀ pé kò sí Júù tó máa fojúure wo òun. Àmọ́ Jésù bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú obìnrin yìí.
3 Àpèjúwe kan ni Jésù fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò náà, èyí tó dá lórí ohun tí obìnrin náà máa ń rí ní gbogbo ìgbà, kódà, nǹkan ọ̀hún ló gbé e débẹ̀ lásìkò náà. Omi ló wá pọn; Jésù sì sọ̀rọ̀ nípa omi ìyè tí ò ní jẹ́ kí òùngbẹ tẹ̀mí gbẹ ẹ́. Ó tó bí ìgbà mélòó kan tí obìnrin náà ṣáà ń mẹ́nu ba àwọn ọ̀rọ̀ kan tó lè fa ìjiyàn.a Àmọ́ ṣe ni Jésù ń fọgbọ́n pẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ tó sì pọkàn pọ̀ sórí ẹ̀kọ́ tó fẹ́ kọ́ obìnrin yẹn. Àwọn nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn ìjọsìn mímọ́ àti ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ló gbájú mọ́. Ọ̀rọ̀ tó bá obìnrin yẹn sọ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, torí pé obìnrin yẹn padà sọ ọ́ fáwọn ọkùnrin ìlú náà, èyí tó mú káwọn náà fẹ́ láti gbọ́rọ̀ lẹ́nu Jésù.—Jòhánù 4:3-42.
4 Nígbà táwọn àpọ́sítélì dé, báwo ni wọ́n ṣe rí wíwàásù tí Jésù ń wàásù fún obìnrin náà sí? Kò dà bíi pé ó dùn mọ́ wọn nínú. Ẹnu yà wọ́n pé Jésù tiẹ̀ lè máa bá obìnrin yẹn sọ̀rọ̀, ó sì dájú pé wọn ò bá obìnrin yẹn sọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan. Lẹ́yìn tí obìnrin yẹn ti lọ, wọ́n wá ń rọ Jésù pé kó jẹ oúnjẹ táwọn bá a rà wá. Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Mo ní oúnjẹ láti jẹ tí ẹ kò mọ̀ nípa rẹ̀.” Ẹnu yà wọ́n, torí wọ́n rò pé oúnjẹ téèyàn ń jẹ sẹ́nu ni Jésù ń sọ. Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé fún wọn pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:32, 34) Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ wọn pé olórí iṣẹ́ tóun wáyé wá ṣe ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ. Ọwọ́ tó fẹ́ káwọn náà fi mú un nìyẹn. Iṣẹ́ wo niṣẹ́ ọ̀hún?
5. Iṣẹ́ wo ni Jésù wáyé wá ṣe, kí la sì máa jíròrò nínú orí yìí?
5 Jésù ti sọ nígbà kan rí pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Bó ṣe rí gan-an nìyẹn o, torí kí Jésù bàa lè wàásù kó sì kọ́ni ní ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni Ọlọ́run ṣe rán an wá sáyé.b Iṣẹ́ yìí kan náà làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ máa ṣe lónìí. Ó wá ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká mọ ìdí tí Jésù fi ń wàásù, ohun tó ń wàásù rẹ̀ àti bí ìwàásù ọ̀hún ṣe máa ń rí lára rẹ̀.
Ìdí Tí Jésù Fi Ń Wàásù
6, 7. Èrò wo ni Jésù fẹ́ kí “olúkúlùkù olùkọ́ni ní gbangba” ní nípa wíwàásù ìhìn rere fáwọn ẹlòmíì? Ṣe àpèjúwe.
6 Ẹ jẹ́ ká wo ọwọ́ tí Jésù fi mú òtítọ́ tó fi kọ́ àwọn èèyàn; lẹ́yìn náà, a óò jíròrò bó ṣe ń ṣe sáwọn tó ń kọ́. Jésù sọ àpèjúwe kan tó ṣe kedere láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ bó ṣe máa ń wu òun láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ tí òun kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà. Ó ní: “Olúkúlùkù olùkọ́ni ní gbangba, nígbà tí a bá ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọba ọ̀run, dà bí ọkùnrin kan, baálé ilé kan, tí ń mú àwọn ohun tuntun àti ògbólógbòó jáde láti inú ibi ìtọ́jú ìṣúra pa mọ́ rẹ̀.” (Mátíù 13:52) Kí nìdí tí baálé ilé inú àpèjúwe yìí ṣe mú lára ohun tó wà nínú ibi tó ń tọ́jú ìṣúra pa mọ́ sí jáde?
7 Kì í ṣe pé baálé ilé yẹn kàn ń ṣe àṣehàn àwọn dúkìá tó ní bíi ti irú èyí tí Hesekáyà Ọba àtijọ́ ṣe, èyí tó kó bá a. (2 Àwọn Ọba 20:13-20) Kí wá nìdí tí baálé ilé yẹn fi ṣe bẹ́ẹ̀? Àpèjúwe kan rèé: Ká sọ pé o lọ sọ́dọ̀ olùkọ́ kan tó o gba tiẹ̀. Ó ṣí ibi ìkóǹkansí tó wà nínú tábìlì rẹ̀ ó sì kó lẹ́tà méjì jáde, ọ̀kan ti pọ́n torí pé ó ti pẹ́ gan-an, èkejì sì tuntun. Bàbá rẹ̀ ló fi àwọn lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí i, ó gba ọ̀kan nígbà tó wà lọ́mọdé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àmọ́ kò tíì pẹ́ tó gba ìkejì. Ìdùnnú hàn lójú rẹ̀ bó ṣe ń sọ báwọn lẹ́tà náà ti ṣe pàtàkì sóun tó àti báwọn ìmọ̀ràn inú wọn ti ṣe yí ìgbésí ayé òun padà, tó sì ń sọ fún ọ pé àwọn ìmọ̀ràn náà lè ran ìwọ náà lọ́wọ́. Olùkọ́ yìí ka àwọn lẹ́tà náà sí ìṣúra ṣíṣeyebíye gan-an, kò sì jẹ́ gbàgbé àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀. (Lúùkù 6:45) Kì í ṣe torí àtifi gbéra ga, kì í sì í ṣe torí èrè kan tó lè rí lórí rẹ̀ ló ṣe fi àwọn lẹ́tà náà hàn ọ́ bí kò ṣe torí kó lè ṣe ọ́ láǹfààní kó o sì lè mọ báwọn lẹ́tà náà ṣe ṣe pàtàkì tó.
8. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ka gbogbo ohun tá a ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ìṣúra ṣíṣeyebíye?
8 Ohun kan náà ló ń sún Jésù, Olùkọ́ Ńlá Náà, láti máa kọ́ àwọn ẹlòmíì láwọn ẹ̀kọ́ tó ti kọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Lójú tiẹ̀, ìṣúra iyebíye tí kò ṣeé fowó rà làwọn ẹ̀kọ́ yẹn. Ó fẹ́ràn àwọn ohun tó kọ́, ó sì máa ń wù ú láti fáwọn ẹlòmíì gbọ́. Bó ṣe fẹ́ kó rí lọ́kàn gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ “olùkọ́ni ní gbangba” nìyẹn. Ṣé bó ṣe rí lọ́kàn àwa náà nìyẹn? Ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wà fún wa láti fẹ́ràn gbogbo òtítọ́ tá a bá kọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A ka àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye wọ̀nyẹn sí pàtàkì, wọn ì báà jẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti mọ̀ tipẹ́ tàbí àtúnṣe tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí gbà. Bá a bá ń fi ìtara àtọkànwá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tá a sì rí i pé ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ohun tí Jèhófà kọ́ wa ò di tútù, ó túmọ̀ sí pé àwa náà ti ní irú ìfẹ́ tí Jésù ní nìyẹn.
9. (a) Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú àwọn èèyàn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ọ̀nà tá a gbà ń bá àwọn èèyàn lò?
9 Jésù tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa jíròrò rẹ̀ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ ní Ìsọ̀rí 3. Àsọtẹ́lẹ̀ ti wà pé Mèsáyà máa “káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì.” (Sáàmù 72:13) Ká sòótọ́, Jésù bójú tó àwọn èèyàn. Ó máa ń kọbi ara sí èrò tó wà lọ́kàn wọn tí wọ́n fi ṣe ohun kan; ó máa ń fẹ́ mọ ìṣòro tó wọ̀ wọ́n lọ́rùn àti ohun tó dà bí ìdènà tí kò jẹ́ kí wọ́n gba òtítọ́. (Mátíù 11:28; 16:13; 23:13, 15) Bí àpẹẹrẹ, rántí obìnrin ará Samáríà yẹn. Kò síyè méjì pé inú rẹ̀ dùn sí bí Jésù ṣe kà á sí. Bí Jésù ṣe fòye mọ ìṣòro ìgbésí ayé rẹ̀ mú kó rọrùn fún un láti gbà gbọ́ pé wòlíì ni, ìyẹn ló sì jẹ́ kó lè sọ fáwọn ẹlòmíì nípa Jésù. (Jòhánù 4:16-19, 39) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwa ọmọlẹ́yìn Jésù òde òní ò lè mọ ohun tí àwọn èèyàn tá à ń wàásù fún ń rò lọ́kàn. Síbẹ̀ a lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún bíi ti Jésù; a lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé à ń ro tiwọn mọ́ tiwa; a lè sọ̀rọ̀ kan ohun tó jẹ́ àníyàn wọn, ìṣòro wọn àti ohun tí wọ́n ń fẹ́.
Ohun Tí Jésù Wàásù
10, 11. (a) Kí ni Jésù wàásù? (b) Kí nìdí tá a fi nílò Ìjọba Ọlọ́run?
10 Kí ni Jésù wàásù? Bó bá jẹ́ pé inú àwọn ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ àwọn èèyàn lónìí lo ti fẹ́ mú ìdáhùn jáde, ó ṣeé ṣe kó o rò pé irú àwọn oníwàásù tó ń fi ìwàásù wọn polongo bó ṣe yẹ kárá ìlú máa ṣe ni Jésù jẹ́. O sì lè rò pé ṣe ló ń wàásù nípa àtúntò ètò òṣèlú tàbí kó o rò pé ṣe ló ń wàásù pé ìgbàlà ara tiẹ̀ ló ṣe pàtàkì ju gbogbo nǹkan míì lọ. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, Jésù sojú abẹ níkòó pé: “Mo gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
11 Má gbàgbé pé ọ̀run ni Jésù wà nígbà tí Sátánì kọ́kọ́ jiyàn pé Jèhófà ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba láyé àti lọ́run. Ẹ wo bó ṣe máa dun Jésù tó bó ṣe ń wò ó tí wọ́n ń ba Bàbá rẹ̀ lórúkọ jẹ́ tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé Olùṣàkóso tí kì í ṣẹ̀tọ́ ni, àti pé kò fẹ́ àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ fẹ́re! Kò ní ṣàìdun Ọmọ Ọlọ́run nígbà tí Ádámù àti Éfà, àwọn tó máa di òbí fún ìràn èèyàn, gba ìbàjẹ́ tí Sátánì ṣe gbọ́! Ọmọ yìí rí i bí ọmọ aráyé ṣe jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú gẹ́gẹ́ bí èrè ìwà àìgbọràn táwọn òbí wọn hù. (Róòmù 5:12) Àmọ́, ẹ ò rí i bí ara rẹ̀ á ṣe yá gágá tó bó ṣe rí i pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Bàbá òun á yanjú gbogbo wàhálà tó wà nílẹ̀ náà!
12, 13. Àwọn ohun tí kò tọ́ wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa mú kó tọ́, báwo sì ni Jésù ṣe fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe lájorí ìwàásù rẹ̀?
12 Lékè gbogbo rẹ̀, wàhálà wo ló ń fẹ́ ìyanjú? Orúkọ mímọ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ di mímọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gàn tí Sátanì àtàwọn tó wà lẹ́yìn rẹ̀ ti kó bá a. Aráyé ní láti mọ̀ pé Jèhófà ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àti ọ̀run, wọ́n ní láti mọ̀ pé ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso yẹn nìkan ló dáa jù. Kò sí ẹlòmíì tó mọ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí tó Jésù. Nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àdúrà àwòkọ́ṣe, ó ní kí wọ́n kọ́kọ́ máa gbàdúrà pé kí Orúkọ Bàbá òun di mímọ́, lẹ́yìn náà, kí wọ́n wá gbàdúrà pé kí Ìjọbà Bàbá òun dé, àti pé kí ìfẹ́ Ọlórun ṣẹ lorí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9, 10) Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi Jésù máa jẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ máa tó pa ètò àwọn nǹkan Sátánì tó ti díbàjẹ́ yìí run, Ìjọba náà sì máa fìdí ìṣàkóso òdodo Jèhófà múlẹ̀ títí ayé.—Dáníẹ̀lì 2:44.
13 Ìjọba Ọlọ́run yìí ni lájorí ìwàásù Jésù. Gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ àtàwọn ohun tó ṣe jẹ́ ká rí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àti bí Ìjọba náà ṣe máa mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Jésù kò jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ òun, ìyẹn ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó wà láyé, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ló ń fẹ́ àtúnṣe láàárín ìlú, bẹ́ẹ̀ sì ni àìṣẹ̀tọ́ pọ̀ lọ bíi rẹ́rẹ, síbẹ̀ ìhìn rere tí Jésù fẹ́ kéde fáráyé àti iṣẹ́ tó ń ṣe ló gbájú mọ́. Ǹjẹ́ bí Jésù ṣe gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run nìkan fi hàn pé kò láròjinlẹ̀, pé ìwàásù rẹ̀ kò tani jí àti pé ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ló tẹnu mọ́? Rárá o!
14, 15. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé “ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ” ni òun? (b) Ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ohun tá à ń wàásù?
14 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i nínú ìsọ̀rí yìí, Jésù mú kí ọ̀nà tó gbà ń kọ́ àwọn èèyàn tù wọ́n lára, oríṣiríṣi nǹkan ló sì máa ń kọ́ wọn. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó fi máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Èyí máa rán wa létí Ọba Sólómọ́nì, tó jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ tó dùn létí tó sì jẹ́ òtítọ́ tó péye ló ṣà jọ láti fi ṣàlàyé èrò tí Jèhófà mí sí i láti kọ sílẹ̀. (Oníwàásù 12:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni ọkùnrin yẹn, Jèhófà fún un ní “fífẹ̀ ọkàn-àyà,” ìyẹn òye gbígbòòrò, èyí tó jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó pọ̀, látorí àwọn ẹyẹ dórí àwọn ẹja, dórí àwọn igi títí dórí àwọn ẹranko ẹhànnà. Àwọn èèyàn máa ń wá gbọ́ ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì látibi tó jìnnà réré. (1 Àwọn Ọba 4:29-34) Síbẹ̀ “ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ” ni Jésù. (Mátíù 12:42) Ọgbọ́n rẹ̀ kọjá ti Sólómọ́nì, “fífẹ̀ ọkàn-àyà” rẹ̀, ìyẹn òye rẹ̀ gbígbòòrò ju ti Sólómọ́nì lọ. Ìmọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Jésù ní jinlẹ̀ ju ti ẹnikẹ́ni lọ, ó sì máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ látinú ìmọ̀ yìí. Ó tún máa ń fi àwọn ẹyẹ, àwọn ẹranko, àwọn ẹja, iṣẹ́ ọ̀gbìn, oju ọjọ́, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́, ìtàn àtàwọn ohun tó ń lọ láwùjọ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀, Jésù kì í fi ìmọ̀ tó ní yangàn lójú àwọn ẹlòmíì. Ìwàásù rẹ̀ máa ń ṣe ṣókí, ó sì máa ń ṣe kedere. Abájọ táwọn èèyàn fi máa ń fẹ́ láti gbọ́rọ̀ rẹ̀!—Máàkù 12:37; Lúùkù 19:48.
15 Lóde òní, àwọn Kristẹni máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Bá ò tiẹ̀ ní ibú ọgbọ́n àti àká ìmọ̀ tó ní, gbogbo wa la ní ìwọ̀n ìmọ̀ àti ìrírí tá a lè lò láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí wọ́n jẹ́ òbí lè lo ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń tọ́ àwọn ọmọ láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíì nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Àwọn míì lè mú àpèjúwe tàbí àpẹẹrẹ látinú ìrírí wọn lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ní ilé ìwé tàbí látinú òye tí wọ́n ní nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Síbẹ̀ a máa ń ṣọ́ra kí ohunkóhun má bàa gba àfiyèsí wa kúrò lórí ohun tá à ń wàásù, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—1 Tímótì 4:16.
Ọwọ́ Tí Jésù Fi Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀
16, 17. (a) Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? (b) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi hàn pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ lòun gbájú mọ́ nígbèésí ayé?
16 Lójú Jésù, ìṣúra ṣíṣeyebíye ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Inú rẹ̀ máa ń dùn láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́ gan-an, pé kì í ṣe irú ẹni tí kò ṣeé mọ̀ táwọn ẹlẹkọ̀ọ́ ìsìn àtọwọ́dá àtàwọn tó ń tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó díjú ń sọ pó jẹ́. Jésù nífẹ̀ẹ́ àtimáa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófa kí wọ́n sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Inú rẹ̀ máa ń dùn láti jẹ́ kí ìhìn rere tu àwọn èèyàn lára kó sì fún wọn láyọ̀. Ọ̀nà wo ló gbà fi hàn pé ó máa ń wu òun láti ṣe bẹ́ẹ̀? Wo ọ̀nà mẹ́ta yìí tó gbà ṣe é.
17 Àkọ́kọ́, iṣẹ́ ìwàásù ni Jésù fi ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀. Sísọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló yàn bí iṣẹ́, òun ló fi ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé, òun ló sì jọba lọ́kàn rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jésù ò fi walé ayé máyà gẹ́gẹ́ bí àlàyé tá a ṣe ní Orí 5 ìwé yìí. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ló gbájú mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tó máa ń gba àwọn èèyàn. Kò jẹ́ kí àwọn nǹkan táá máa sanwó fún, àwọn nǹkan táá máa tún ṣe tàbí àwọn táá máa tún rà lóòrèkóòrè gbà á lọ́kàn. Kò walé ayé máyà kí ohunkóhun má bàa pín ọkàn rẹ̀ níyà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.—Mátíù 6:22; 8:20.
18. Láwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà lo ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
18 Ìkejì, Jésù lo ara rẹ̀ tokunratokunra lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Gbogbo agbára rẹ̀ ló fi ṣiṣẹ́ náà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà ló rìn yí gbogbo ẹkùn Palẹ́sínì ká, tó ń wá àwọn èèyàn tó máa wàásù ìhìn rere fún. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ilé wọn, ní gbàgede ìlú, nínú ọjà àti ní gbangba. Kódà, ó bá wọn sọ̀rọ̀ lákòókò tó yẹ kó máa rẹjú, lákòókò tó yẹ kó máa jẹ́un, lákòókò tó yẹ kó máa mumi tàbí níbi tó ti yẹ kó máa sinmi pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Àní nígbà tó tiẹ̀ ń kú lọ, ó ṣì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíì!—Lúùkù 23:39-43.
19, 20. Báwo ni Jésù ṣe fi àpèjúwe sọ bí a ò ṣe gbọ́dọ̀ fi àkókò falẹ̀ láti wàásù?
19 Ìkẹta, Jésù kò fi àkókò falẹ̀ láti wàásù. Má gbàgbé ìjíròrò tó wáyé láàárín òun àti obìnrin ará Samáríà yẹn nídìí kànga nílùú Síkárì. Lákòókò yẹn, àwọn àpọ́sítélì Jésù ò rí wíwàásù ìhìn rere fáwọn ẹlòmíì bí ohun tó jẹ́ kánjúkánjú. Ìyẹn ni Jésù ṣe sọ fún wọn pé: “Ẹ kò ha sọ pé ó ṣì ku oṣù mẹ́rin kí ìkórè tó dé? Wò ó! Mo wí fún yín: Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.”—Jòhánù 4:35.
20 Jésù mú àpèjúwe yẹn látinú àkókò tí wọ́n wà nígbà náà. Ẹ̀rí wà pé oṣù Kísíléfì (láàárín oṣù November sí December) ni. Ó ṣì ku oṣù mẹ́rin kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kórè ọkà báàlì, èyí tó máa ṣe déédéé pẹ̀lú àkókò Ìrékọjá ní Nísàn 14. Nírú àkókò yẹn, àwọn àgbẹ̀ ò tíì ní máa kánjú. Lójú wọn, ọ̀nà ṣì jìn. Ṣùgbọ́n ti kíkórè àwọn èèyàn ńkọ́? Ibi tọ́rọ̀ wà gan-an nìyí, ọ̀pọ̀ ni ara wọn wà lọ́nà láti gbọ́, wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, kí wọ́n bàa lè ní ìrètí àgbàyanu tí Jèhófà nawọ́ rẹ̀ sí wọn. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jésù wo inú pápá ìṣàpẹẹrẹ yẹn lọ tó sì rí i tó funfun lọ gbòò, bí afẹ́fẹ́ ṣe ń gbé e sọ́tùn-ún-sósì, èyí tó túmọ̀ sí pé àkókò ìkórè ti tó.c Àkókò ti tó, iṣẹ́ náà ò sì ṣeé fi falẹ̀! Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà táwọn aráàlú kan fẹ́ dá Jésù dúró sọ́dọ̀ wọn ju bó ṣe yẹ lọ, ó yáa sọ fún wọn pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.”—Lúùkù 4:43.
21. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
21 Nínú gbogbo ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a jíròrò tán yìí la ti lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. A lè fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé wa. Àní bá a bá tiẹ̀ ní ìdílé tá à ń bójú tó tàbí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tá à ń ṣe, a lè fi hàn pé ipò àkọ́kọ́ la fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sí nípa fífi tìtaratìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù déédéé gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Mátíù 6:33; 1 Tímótì 5:8) A lè lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà nípa fífi èyí tó pọ̀ nínú àkókò wa àti agbára wa àti ohun ìní wa ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn. (Lúùkù 13:24) A sì gbọ́dọ̀ máa rántí pé iṣẹ́ yìí kì í ṣe iṣẹ́ tá a lè fi falẹ̀. (2 Tímótì 4:2) Gbogbo àǹfààní tó bá yọjú la gbọ́dọ̀ fi wàásù!
22. Kí la máa jíròrò ní orí tó kàn?
22 Jésù tún jẹ́ ká mọ̀ pé òun mọ bí iṣẹ́ náà ti ṣe pàtàkì tó nípa bó ṣe ṣe gbogbo ohun tó yẹ, kí iṣẹ́ náà bàa lè máa tẹ̀ síwájú lẹ́yìn ikú rẹ̀. Ó gbé iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ kíkọ́ni lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa ṣe é lọ. Iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́ yìí la máa jíròrò ní orí tó kàn.
a Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí obìnrin yìí ń béèrè ìdí tí Jésù tó jẹ́ Júù fi ń bá ará Samáríà sọ̀rọ̀, ó mẹ́nu ba ìkórìíra tó ti wà láàárín àwọn ẹ̀yà méjèèjì látọdúnmọdún. (Jòhánù 4:9) Ó sì tún sọ pé àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù làwọn èèyàn òun, èyí táwọn Júù kì í fẹ́ gbọ́ sétí. (Jòhánù 4:12) Káwọn èèyàn bàa lè mọ̀ pé ọmọ àtọ̀húnrìnwá làwọn ará Samáríà ní Jerúsálẹ́mù, ọmọ Kútà ni wọ́n máa ń pè wọ́n.
b Láti wàásù túmọ̀ sí láti kéde tàbí láti polongo ìhìn kan. Ó jọra pẹ̀lú kíkọ́ni àmọ́ kíkọ́ni jinlẹ̀ ju wíwàásù lọ ó sì gba pé kéèyàn ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé. Ká tó lè sọ pé a kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan bó ṣe yẹ, ẹ̀kọ́ náà gbọ́dọ̀ dénú ọkàn rẹ̀ kó bàa lè máa fi ohun tó kọ́ sílò.
c Ìwé kan sọ nípa ẹsẹ yìí pé: “Bí ọkà bá ti tó kórè, àwọ̀ rẹ̀ á yí padà láti àwọ̀ ewé sí àwọ̀ òféfèé tàbí òféfèé tó ti ń funfun, èyí tó jẹ́ àmì pé àkókò àtikórè rẹ̀ ti tó.”