‘Ẹ Dúró Gbọn-in Nínú Ìgbàgbọ́’
“Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, . . . ẹ di alágbára ńlá.”—1 KỌ́R. 16:13.
1. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pétérù nígbà tí ìjì ẹlẹ́fùúùfù kan jà lórí Òkun Gálílì? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ló fà á tí Pétérù fi bẹ̀rẹ̀ sí í rì?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn míì ń fi agbára wa ọkọ̀ ojú omi wọn lórí Òkun Gálílì lálẹ́ ọjọ́ kan tí ìjì ẹlẹ́fùúùfù ń jà. Ni wọ́n bá ṣàdédé rí Jésù tó ń rìn lórí òkun náà. Pétérù béèrè lọ́wọ́ Jésù tó jẹ́ Ọ̀gá rẹ̀ bóyá òun lè máa tọ̀ ọ́ bọ̀. Nígbà tí Jésù sọ fún Pétérù pé kó máa bọ̀, ó kúrò nínú ọkọ̀ náà, ó sì rìn tọ Jésù lọ lórí omi tó ń ru gùdù náà. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn yẹn tí Pétérù fi bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Kí ló fà á? Ó wo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà, ẹ̀rù sì bà á. Pétérù lọgun pé kí Jésù gba òun, Jésù yára gbá a mú ó sì sọ pé: “Ìwọ tí o ní ìgbàgbọ́ kíkéré, èé ṣe tí ìwọ fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì?”—Mát. 14:24-32.
2. Kí la máa jíròrò báyìí?
2 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́ta lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù, tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́: (1) bí Pétérù ṣe kọ́kọ́ fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run lè ran òun lọ́wọ́, (2) ìdí tí ìgbàgbọ́ Pétérù fi bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn àti (3) ohun tó mú kí Pétérù pa dà ní ìgbàgbọ́. Tá a bá jíròrò àwọn kókó yìí, àá rí báa ṣe lè ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.’—1 Kọ́r. 16:13.
Ó GBÀ GBỌ́ PÉ ỌLỌ́RUN LÈ RAN ÒUN LỌ́WỌ́
3. Kí nìdí tí Pétérù fi kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi? Báwo làwa náà ṣe ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀?
3 Ìgbàgbọ́ tí Pétérù ní ló mú kó kúrò nínú ọkọ̀ náà, kó lè rìn lórí omi. Jésù ló ní kí Pétérù máa bọ̀, Pétérù sì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run á fún òun lágbára láti rìn lórí omi bíi ti Jésù. Bí ọ̀rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi. Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run ló mú ká ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù ní ká wá di ọmọlẹ́yìn òun, ká sì máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ òun. A gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù àti Ọlọ́run, kó sì dá wa lójú pé wọ́n á máa tì wá lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà.—Jòh. 14:1; ka 1 Pétérù 2:21.
4, 5. Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ fi jẹ́ ohun ìní ṣíṣeyebíye?
4 Ká sòótọ́, ohun ìní tó ṣeyebíye ni ìgbàgbọ́. Bí ìgbàgbọ́ tí Pétérù ní ṣe mú kó rìn lórí omi, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ tá a ní lè mú ká ṣe ohun tó lè dà bí èyí tí kò ṣeé ṣe lójú èèyàn. (Mát. 21:21, 22) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ lára wa ti yí ìwà àti ìṣe wa pa dà débi pé àwọn tó mọ̀ wá tẹ́lẹ̀ á fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè gbà gbọ́ pé a ti ṣe ìyípadà tó tóyẹn nínú ìgbésí ayé wa. Jèhófà bù kún ìsapá wa torí pé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ ló mú ká ṣe irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀. (Ka Kólósè 3:5-10.) Níwọ̀n bí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà sì ti mú ká ya ara wa sí mímọ́ fún un, a di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni kò sí bá a ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Éfé. 2:8.
5 Ìgbàgbọ́ tá a ní túbọ̀ ń sọ wá di alágbára. Ìgbàgbọ́ yìí ń mú ká gbéjà ko Èṣù, alátakò tó lágbára ju ẹ̀dá lọ. (Éfé. 6:16) Ní àfikún síyẹn, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa máa ṣàníyàn jù nígbà ìṣòro. Jèhófà sọ pé tí ìgbàgbọ́ wa bá mú ká fi ire Ìjọba òun sípò àkọ́kọ́, òun á pèsè àwọn ohun tá a nílò nípa tara fún wa. (Mát. 6:30-34) Yàtọ̀ síyẹn, ìgbàgbọ́ tá a ní á mú kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀bùn tó jẹ́ pé òun nìkan ló lè fúnni, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 3:16.
TÁ Ò BÁ PỌKÀN PỌ̀, ỌKỌ̀ ÌGBÀGBỌ́ WA LÈ RÌ
6, 7. (a) Kí la lè fi wéra pẹ̀lú ìgbà tí Pétérù wà láàárín ìgbì òkun, tí ìjì sì ń jà? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ wa lè jó rẹ̀yìn?
6 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù nígbà tó ń rìn láàárín ìgbì òkun, tí ìjì sì ń jà la lè fi wé àwọn àdánwò àti ìdẹwò tá à ń dojú kọ torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Kódà bí ìdẹwò tàbí ìṣòro náà bá le koko, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè dúró gbọn-in. Rántí pé kì í ṣe ìró afẹ́fẹ́ tàbí ìjì líle ló mú kí Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé: “Ní wíwo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà, ó fòyà.” (Mát. 14:30) Pétérù ò pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ Jésù mọ́, ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í mì. Ìgbàgbọ́ tiwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í mì tá a bá ń wo àwọn ìṣòro wa bí ìgbà tá à ń ‘wo ìjì ẹlẹ́fùúùfù,’ tá à ń ronú lórí bó ṣe lágbára tó, tá a sì ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn.
7 Ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ wa lè jó rẹ̀yìn, torí pé Bíbélì pe ìgbàgbọ́ tó jó rẹ̀yìn tàbí àìnígbàgbọ́ ní “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” (Héb. 12:1) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù yìí fi hàn pé ìgbàgbọ́ wa lè tètè jó rẹ̀yìn tá a bá ń pọkàn pọ̀ sórí ohun tí kò tọ́. Báwo la ṣe lè mọ̀ bí ọ̀rọ̀ tiwa náà bá ti fẹ́ dà bíi ti Pétérù? Ronú lórí àwọn ìbéèrè díẹ̀ tó yẹ ká fi yẹ ara wa wò.
8. Kí ló lè mú kó máà dá wa lójú bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
8 Ǹjẹ́ ó ṣì dá mi lójú bíi ti tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa pa ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí run. Síbẹ̀, ṣé onírúurú eré ìnàjú tó wà nínú ayé ò ti máa fa ìpínyà ọkàn fún wa, nípa bẹ́ẹ̀, kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìlérí Ọlọ́run sì ti máa jó rẹ̀yìn? A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé bóyá ni òpin ti sún mọ́lé. (Háb. 2:3) Àpẹẹrẹ míì tún rèé. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun á máa dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. Àmọ́, tá a bá ń jẹ́ kí àṣìṣe tá a ti ṣe nígbà kan gbà wá lọ́kàn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé bóyá ni Jèhófà ti “pa” àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa “rẹ́.” (Ìṣe 3:19) A wá lè tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ayọ̀ tá à ń rí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ká sì di aláìṣiṣẹ́mọ́.
9. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ohun tó wù wá là ń lé?
9 Ṣé mo ṣì já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run bíi ti tẹ́lẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé a gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ kára fún Jèhófà ká bàa lè ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin.” Àmọ́, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ohun tó wù wá là ń lo gbogbo àkókò wa lé lórí, irú bíi ṣíṣe iṣẹ́ tó lówó lórí ṣùgbọ́n tó ń pa ìjọsìn wa lára? Ìgbàgbọ́ wa lè jó rẹ̀yìn ká sì “di onílọ̀ọ́ra,” ká wá máa fọwọ́ hẹ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lágbára láti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Héb. 6:10-12.
10. Báwo la ṣe ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà tá a bá ń dárí ji àwọn míì?
10 Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún mi láti dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ mí? Bí àwọn míì bá ṣẹ̀ wá tàbí tí wọ́n ṣe ohun tó dùn wá, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ro ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ní àròtúnrò, ká wá torí ìyẹn fìbínú sọ̀rọ̀ sí wọn tàbí ká máà bá wọn sọ̀rọ̀ mọ́. Àmọ́, tá a bá ń dárí jini, ìyẹn á fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Àwọn tó bá ṣẹ̀ wá jẹ wá ní gbèsè, bí ẹ̀ṣẹ̀ tiwa náà ṣe ń sọ wá di ajigbèsè lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Lúùkù 11:4) Tá a bá ń dárí ji àwọn èèyàn, a máa rí ojúure Ọlọ́run, ó sì gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé ìyẹn ṣe pàtàkì ju ká máa gbẹ̀san táwọn míì bá ṣẹ̀ wá. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ pé ó gba ìgbàgbọ́ kéèyàn tó lè dárí jini. Nígbà tí Jésù sọ fún wọn léraléra pé kí wọ́n máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wọ́n, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.”—Lúùkù 17:1-5.
11. Kí ló lè mú ká kọ̀ láti fara mọ́ ìbáwí tó bá Ìwé Mímọ́ mu?
11 Ṣé inú máa ń bí mi tí wọ́n bá fún mi ní ìbáwí tó bá Ìwé Mímọ́ mu? Dípò ká máa wá bá ó ṣe jàǹfààní látinú ìbáwí náà, a lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tá a rò pé kò dáa tó nínú ìbáwí náà tàbí ẹni tó fún wa ní ìbáwí. (Òwe 19:20) A lè wá tipa bẹ́ẹ̀ kùnà láti mú èrò wa bá ti Ọlọ́run mu.
12. Bó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ẹnì kan máa ń ráhùn nípa àwọn tí Jèhófà ń lò láti darí àwọn èèyàn rẹ̀, irú ẹni wo ni onítọ̀hún ń fi hàn pé òun jẹ́?
12 Ṣé mo máa ń ráhùn nípa àwọn arákùnrin tá a yàn sípò nínú ìjọ? Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọkàn pọ̀ sórí ìròyìn búburú tí àwọn amí mẹ́wàá tí kò nígbàgbọ́ náà mú wá fún wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn lòdì sí Mósè àti Áárónì. Jèhófà wá bi Mósè pé: “Yóò sì ti pẹ́ tó tí wọn kì yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi?” (Núm. 14:2-4, 11) Ó dájú pé bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ráhùn yẹn fi hàn pé wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tó yan Mósè àti Áárónì sípò. Bákan náà, tá a bá ń ráhùn ní gbogbo ìgbà nípa àwọn tí Ọlọ́run ń lò láti darí àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní fi hàn pé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn?
13. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tá a bá rí i pé ìgbàgbọ́ wa ti bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn?
13 Àmọ́ ṣá o, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì tí àyẹ̀wò tó o ṣe nípa ara rẹ bá fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn. Kódà, Pétérù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì bẹ̀rù, ó sì ṣiyè méjì. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jésù ní láti bá gbogbo àwọn àpọ́sítélì wí torí pé wọ́n ní “ìgbàgbọ́ kíkéré.” (Mát. 16:8) A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù. Ìyẹn sì jẹ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn tó ṣiyè méjì tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú òkun.
MÁA WO JÉSÙ KÓ O SÌ FÚN ÌGBÀGBỌ́ RẸ LÓKUN
14, 15. (a) Kí ni Pétérù ṣe nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í rì? (b) A ò lè fi ojúyòójú rí Jésù, báwo wá la ṣe lè “tẹjú mọ́” ọn?
14 Nígbà tí Pétérù wo ìjì òkun náà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì, ó lè wẹ̀ pa dà sídìí ọkọ̀ tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó mọ̀wẹ̀ dáadáa, torí náà ohun tí ì bá kọ́kọ́ fẹ́ láti ṣe nìyẹn. (Jòh. 21:7) Ṣùgbọ́n dípò kó gbára lé ara rẹ̀, ó yíjú pa dà sọ́dọ̀ Jésù, ó sì gbà kó ran òun lọ́wọ́. Bí àwa náà bá rí i pé ìgbàgbọ́ wa ti ń jó rẹ̀yìn, àpẹẹrẹ Pétérù ló yẹ ká tẹ̀ lé. Àmọ́, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
15 Bí Pétérù ṣe yíjú pa dà sọ́dọ̀ Jésù ni àwa náà ṣe gbọ́dọ̀ máa “tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù.” (Ka Hébérù 12:2, 3.) A ò lè fi ojúyòójú rí Jésù bíi ti Pétérù. Ṣùgbọ́n, à ń “tẹjú mọ́” ọn tá a bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtàwọn ohun tó ṣe, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìgbésẹ̀ tá a lè gbé ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, a máa rí ìrànlọ́wọ́ tá a nílò kí ìgbàgbọ́ wa lè dúró gbọn-in.
16. Báwo la ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà táá fi gbé ìgbàgbọ́ wa ró?
16 Mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Bíbélì túbọ̀ lágbára. Ó dá Jésù lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, ìtọ́sọ́nà inú rẹ̀ ló sì dára jù lọ. (Jòh. 17:17) Kó bàa lè dá àwa náà lójú bíi ti Jésù pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, a gbọ́dọ̀ máa kà á lójoojúmọ́, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a bá kọ́ nínú rẹ̀. Bá a ṣe ń ka Bíbélì, ó tún yẹ ká máa ṣèwádìí lórí àwọn nǹkan tá a bá rí pé kò yé wa. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé a ti ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn nínú Ìwé Mímọ́, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí ti sún mọ́lé ní tòótọ́. Tó o bá ń ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tó ti ṣẹ, ìgbẹ́kẹ̀lé tó o ní nínú àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ọjọ́ iwájú á lágbára sí i. Tó o bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Bíbélì máa ń yí ìgbésí ayé àwa èèyàn pa dà, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé ó wúlò.a—1 Tẹs. 2:13.
17. Kí ló mú kí Jésù jẹ́ olóòótọ́ bó tilẹ̀ dojú kọ ìdánwò líle koko? Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
17 Máa ronú lórí àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí. Torí pé Jésù tẹjú mọ́ “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀,” ó ṣeé ṣe fún un láti jẹ́ olóòótọ́ láìka àwọn ìdánwò líle koko sí. (Héb. 12:2) Kò jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà nínú ayé pín ọkàn òun níyà. (Mát. 4:8-10) O lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ. Máa wo ara rẹ bíi pé o ti wà nínú ayé tuntun nípa kíkọ ohun tó o máa fẹ́ ṣe lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá mú ètò búburú yìí kúrò tàbí kó o ya àwòrán rẹ̀. Kọ orúkọ àwọn èèyàn tó o máa fẹ́ kí káàbọ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá jí wọn dìde àtàwọn nǹkan tó o máa fẹ́ bá wọn sọ. Má wulẹ̀ wo àwọn ìlérí yìí bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún aráyé lápapọ̀, ṣùgbọ́n wò ó bíi pé ìwọ gan-an ni Ọlọ́run ṣe ìlérí náà fún.
18. Báwo ni àdúrà ṣe lè fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun?
18 Ní kí Ọlọ́run fún ẹ ní ìgbàgbọ́ sí i. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. (Lúùkù 11:9, 13) Bá a ṣe ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i. Ìgbàgbọ́ yìí jẹ́ apá kan lára èso tẹ̀mí. Sọ ohun pàtó tó ò ń fẹ́ fún Ọlọ́run, sọ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ohunkóhun tó o bá kíyè sí pé ó lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ jó rẹ̀yìn, lára irú ohun bẹ́ẹ̀ ni kéèyàn má máa dárí jini.
19. Kí ló yẹ kẹ́ni tá a fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́ ní?
19 Àwọn tó nígbàgbọ́ ni kó o máa bá ṣọ̀rẹ́. Jésù fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, pàápàá jù lọ àwọn tó ń bá a ṣe wọléwọ̀de. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù lọ, ìyẹn àwọn àpọ́sítélì, ti fi hàn nípa ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run pé àwọn nígbàgbọ́ àwọn sì jẹ́ adúróṣinṣin. (Ka Jòhánù 15:14, 15.) Torí náà, tó o bá ń yan àwọn tó o máa bá ṣọ̀rẹ́, rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù, tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́. Kó o sì máa rántí pé àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń bára wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, ara wọn kì í sì í kọ òótọ́ ọ̀rọ̀.—Òwe 27:9.
20. Tá a bá ń gbé ìgbàgbọ́ àwọn míì ró, báwo ló ṣe máa ṣe wá láǹfààní?
20 Máa fún ìgbàgbọ́ àwọn míì lókun. Jésù gbé ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ró nípasẹ̀ ohun tó sọ àti ohun tó ṣe. (Máàkù 11:20-24) Ó ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù torí pé bá a ṣe ń gbé ìgbàgbọ́ àwọn míì ró, bẹ́ẹ̀ la ó máa fún ìgbàgbọ́ tiwa náà lókun. (Òwe 11:25) Bó o ṣe ń wàásù tó o sì ń kọ́ni, jẹ́ káwọn èèyàn máa rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún àti pé Bíbélì ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí. Máa gbé ìgbàgbọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ ró. Bó o bá rí i pé àwọn kan fẹ́ máa ṣiyè méjì, bóyá tí wọ́n ń ráhùn nípa àwọn arákùnrin tá a yàn sípò, má ṣe tètè pa wọ́n tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, fọgbọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́, kó o sì wá bó o ṣe máa gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. (Júúdà 22, 23) Tó o bá wà níléèwé, tí wọ́n sì ń jíròrò ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, fìgboyà sọ ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá. Ipa tí ọ̀rọ̀ rẹ máa ní lórí olùkọ́ rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà ní kíláàsì lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ẹ.
21. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún olúkúlùkù wa nípa ìgbàgbọ́ wa?
21 Ọlọ́run àti Jésù ló ran Pétérù lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ó borí ìbẹ̀rù àti iyè méjì rẹ̀, ó sì di àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ fún àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ń ràn gbogbo wá lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. (Ka 1 Pétérù 5:9, 10.) Gbogbo ìsapá tá a bá ṣe láti gbé ìgbàgbọ́ wa ró tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ torí pé èrè tó máa tibẹ̀ wá ò láfiwé.
a Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń fi sóde.