ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Jẹ́ Adúróṣinṣin Nígbà Ìdánwò
    Ilé Ìṣọ́—2010 | January 1
    • Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Tí Wọ́n Tọ́ Ọ Sọ́nà

      Lákòókò díẹ̀ lẹ́yìn tí ọwọ́ wọn dí gan-an yìí, Jésù mú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn kan lọ sí ìrìn-àjò jíjìn kan lápá àríwá. Nígbà míì láti orí Òkun Gálílì tó mọ́ roro, wọ́n máa ń rí ṣóńṣó orí Òkè Hámónì tí yìnyín bò, tó wà ní ìkángun àríwá Ilẹ̀ Ìlérí. Díẹ̀díẹ̀ ló ń dà bíi pé òkè yìí ń ga sí i, bí wọ́n ti ń sún mọ́ ọn, tí wọ́n sì ń gbà àwọn ọ̀nà olókè tó lọ sáwọn abúlé tó wà ní agbègbè Kesaréà nílùú Fílípì.c Ní àgbègbè tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí, níbi tí wọ́n ti lè rí èyí tó pọ̀ jù nínú Ilẹ̀ Ìlérí láti apá gúúsù, Jésù béèrè ìbéèrè pàtàkì kan lọ́wọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.

      Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ta ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” A lè fojú inú wo bí Pétérù á ṣe máa wojú Jésù, tó sì ń ronú nípa bí Ọ̀gá rẹ̀ yìí ṣe jẹ́ aláàánú àti bó ṣe ní ìmọ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Jésù fẹ́ mọ èrò àwọn èèyàn náà lẹ́yìn tí wọ́n ti rí òun, tí wọ́n sì ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òun. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn máa fèsì, àwọn èrò tí kò tọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa Jésù láwọn náà tún sọ. Àmọ́ Jésù tún fẹ́ mọ̀ síwájú sí i. Ó fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ọmọlẹ́yìn tí wọ́n sún mọ́ òun dáadáa ń ṣe irú àṣìṣe kan náà. Torí náà, ó bi wọ́n pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?”—Lúùkù 9:18-22.

  • Ó Jẹ́ Adúróṣinṣin Nígbà Ìdánwò
    Ilé Ìṣọ́—2010 | January 1
    • c Etí Òkun Gálílì tí wọ́n wà jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó lọọlẹ̀ gan-an ní nǹkan bí igba-ó-lé-mẹ́wàá [210] mítà, wọ́n wá rìnrìn àjò kìlómítà méjìdínláàádọ́ta [48] lọ sáwọn ibi gíga tó ga tó àádọ́ta-dín-nírinwó [350] mítà. Ẹwà àrímáleèlọ ló wà ní gbogbo àgbègbè olókè náà.

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́