-
Ṣé Póòpù Ló “Rọ́pò Pétérù Mímọ́”?Ilé Ìṣọ́—2011 | August 1
-
-
Ṣé Pétérù ni Póòpù Àkọ́kọ́?
Láti jẹ́rìí sí i pé Pétérù ni ìpìlẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, tipẹ́tipẹ́ ni ẹ̀sìn Kátólíìkì ti ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 16:18 pé: “Ìwọ ni Pétérù, orí àpáta ràbàtà yìí sì ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi sí dájúdájú.” Kódà, wọ́n tiẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ yìí lédè Látìn sí abẹ́ òrùlé ribiti ti ilé ìjọsìn St. Peter’s Basilica tó wà ní Róòmù.
Ọ̀gbẹ́ni Augustine táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún dáadáa, tó jẹ́ Bàbá Ìjọ sọ nígbà kan pé, Pétérù ni ìpìlẹ̀ ìjọ. Àmọ́ kí ọ̀gbẹ́ni yìí tó kú, ó yí èrò rẹ̀ nípa ohun tí Jésù sọ yìí pa dà. Nínú ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Retractations, Augustine jẹ́ kó yé àwọn èèyàn pé Jésù ni ìpìlẹ̀ Ìjọ Kristẹni kì í ṣe Pétérù.a
Òótọ́ ni pé, àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nǹkan tó pọ̀ gan-an nípa Pétérù. Àwọn ìgbà kan wà tí Jésù pe àpọ́sítélì Jòhánù, Jákọ́bù àti Pétérù pé kí wọ́n wà pẹ̀lú òun láwọn ibi tí nǹkan pàtàkì ti ṣẹlẹ̀. (Máàkù 5:37, 38; 9:2; 14:33) Jésù fún Pétérù ní “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run,” èyí tí Pétérù lò láti fi ṣí ọ̀nà Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù, lẹ́yìn náà fún àwọn ará Samáríà àti ní ìkẹyìn fún àwọn kèfèrí. (Mátíù 16:19; Ìṣe 2:5, 41; 8:14-17; 10:45) Nítorí pé ara Pétérù yá mọ́ èèyàn, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé òun ló máa ń gbẹ́nu sọ fún àwọn àpọ́sítélì yòókù. (Ìṣe 1:15; 2:14) Àmọ́, ṣé àwọn nǹkan yìí wá fi hàn pé Pétérù ni orí ìjọ Kristẹni lákòókò yẹn?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kọ̀wé pé Pétérù ni Jésù yàn pé kó máa ṣe “iṣẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn tí ó dádọ̀dọ́.” (Gálátíà 2:8) Àmọ́, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí kò fi hàn pé Pétérù ló ń darí ìjọ. Ipa tí Pétérù máa kó nínú wíwàásù fún àwọn Júù ni Pọ́ọ̀lù ń sọ.
Òótọ́ ni pé wọ́n fún Pétérù ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti máa bójú tó, àmọ́ kò sí ibì kankan tó ti sọ nínú Bíbélì pé òun ni orí ìjọ Kristẹni, pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣe ìpinnu fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn. Ohun tó sọ nípa ara rẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ ni pé, òun jẹ́ “àpọ́sítélì” àti “àgbà ọkùnrin,” kò sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ.—1 Pétérù 1:1; 5:1.
-
-
Ṣé Póòpù Ló “Rọ́pò Pétérù Mímọ́”?Ilé Ìṣọ́—2011 | August 1
-
-
a Báwọn èèyàn ṣe máa dá Kristi àti ipa tó ń kó mọ̀ ni Jésù ń bá Pétérù sọ, kì í ṣe ipò tí Pétérù máa wà nínú ìjọ Kristẹni. (Mátíù 16:13-17) Nígbà tó yá, Pétérù pàápàá sọ pé Jésù ni àpáta tó jẹ́ ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni. (1 Pétérù 2:4-8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí sí i pé, Jésù ni “òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé” ìjọ Kristẹni kì í ṣe Pétérù.—Éfésù 2:20.
-