ORÍ KỌKÀNLÁ
“Ènìyàn Mìíràn Kò Tíì Sọ̀rọ̀ Báyìí Rí”
1, 2. (a) Kí nìdí táwọn ọlọ́pàá tí wọ́n rán pé kí wọ́n lọ mú Jésù wá fi padà lọ́wọ́ òfo? (b) Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ olùkọ́ tó ju olùkọ́ lọ?
INÚ ń bí àwọn Farisí burúkú burúkú. Jésù sì wà nínú tẹ́ńpìlì tó ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Bàbá rẹ̀. Èrò àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù yàtọ̀ síra; èyí tó pọ̀ lára wọn ló gba Jésù gbọ́, àwọn míì sì ń fẹ́ kí wọ́n fi àṣẹ ọba mú un. Nítorí pé àwọn aṣáájú ìsìn ò lè mú ìbínú wọn mọ́ra mọ́, wọ́n ní káwọn ọlọ́pàá lọ mú Jésù wá. Àmọ́ ọwọ́ òfo làwọn ọlọ́pàá náà padà dé. Olórí àlùfáà àtàwọn Farisí bi wọ́n pé: “Èé ṣe tí ẹ kò fi mú un wá?” Èsì àwọn ọlọ́pàá náà ni pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” Ọ̀rọ̀ Jésù wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi pé kò wù wọ́n láti fi àṣẹ ọba mú un.a—Jòhánù 7:45, 46.
2 Àwọn ọlọ́pàá yẹn nìkan kọ́ ni ẹ̀kọ́ Jésù wọ̀ lọ́kàn. Ńṣe làwọn èèyàn máa ń pé jọ bìbà nítorí kí Jésù lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Máàkù 3:7, 9; 4:1; Lúùkù 5:1-3) Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ olùkọ́ tó ju olùkọ́ lọ? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ní Orí 8, ó fẹ́ràn òtítọ́ tó ń kọ́ni, ó sì fẹ́ràn àwọn tó ń kọ́ pẹ̀lú. Àti pé olùkọ́ tó mọṣẹ́ dunjú lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ni ni. Ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́ta yẹ̀ wò lára àwọn ọ̀nà tó máa ń gbà kọ́ni lọ́nà tó já fáfá, ká sì wo bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.
Ó Máa Ń Lo Ọ̀rọ̀ Tó Lè Tètè Yéni
3, 4. (a) Kí nìdí tí Jésù fi lo gbólóhùn tó lè tètè yéni nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? (b) Ọ̀nà wo ni Ìwàásù Lórí Òkè fi jẹ́ àpẹẹrẹ kan nípa bí Jésù ṣe máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ tó lè tètè yé gbogbo èèyàn?
3 Wo bí àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì tí Jésù lè lò ṣe ti ní láti pọ̀ tó. Síbẹ̀, nígbà tó bá ń kọ́ni, kì í lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣòroó lóye fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ tó jẹ́ pé “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù,” lọ̀pọ̀ nínú wọn. (Ìṣe 4:13) Ó mọ ibi tí agbára wọn mọ, kì í rọ̀jò àlàyé lé wọn lórí. (Jòhánù 16:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kéékèèké tó lè tètè yé gbogbo èèyàn ló máa ń lò, òtítọ́ tó máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ náà gbé jáde kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ.
4 Bí àpẹẹrẹ, wo Ìwàásù Lórí Òkè tó wà nínú Mátíù 5:3 sí 7:27. Ìmọ̀ràn tí Jésù fúnni nínú ìwàásù náà wọni lọ́kàn, ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Àwọn èrò àti gbólóhùn tó ń gbé jáde kì í lọ́jú pọ̀. Kódà, kò séyìí tí kò lè tètè yé ọmọdé nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ! Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” Àfàìmọ̀ kó má sì jẹ́ pé àgbẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn àti apẹja ló pọ̀ nínú àwọn ogunlọ́gọ̀ náà.—Mátíù 7:28.
5. Mẹ́nu ba àpẹẹrẹ àwọn gbólóhùn tí Jésù sọ tó lè tètè yé gbogbo èèyàn tó sì ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀.
5 Bí Jésù bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, àwọn gbólóhùn ṣókíṣókí tí kò lọ́jú pọ̀, ló fi máa ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ jáde. Láyé ìgbà tí wọn ò tíì máa tẹ ọ̀rọ̀ sínú ìwé, ọgbọ́n yìí ló lò láti rí i pé ohun tóun ń kọ́ àwọn olùgbọ́ òun wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi tí wọn ò fi ní gbàgbé. Àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan rèé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.” “Ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.” “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”b (Mátíù 7:1; 9:12; 26:41; Máàkù 12:17; Ìṣe 20:35) Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn tí Jésù ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé ṣì ni wọ́n.
6, 7. (a) Bá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa yé gbogbo èèyàn, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká lo èdè tí kò lọ́jú pọ̀? (b) Báwo la ṣe lè yẹra fún kíkó àlàyé tó pọ̀ pá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí?
6 Báwo la ṣe lè kọ́ni lọ́nà tó lè tètè yé gbogbo èèyàn? Ọ̀nà kan tó ṣe pàtàkì ni pé ká lo èdè tó ṣe kedere tí èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn lè tètè lóye. Àwọn ìpìlẹ̀ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò lọ́jú pọ̀. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti olóòótọ́ ọkàn ni Jèhófà sọ ohun tó fẹ́ ṣe fún. (1 Kọ́ríńtì 1:26-28) Bá a bá fara balẹ̀ wá àwọn ọ̀rọ̀ tí kò lọ́jú pọ̀, òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá à ń sọ á lè yé ẹni tá a fẹ́ sọ ọ́ fún.
7 Bá ò bá fẹ́ kí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́jú pọ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ máa kó àlàyé tó pọ̀ jù pá a lórí. Nítorí náà, bá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò pọn dandan ká ṣàlàyé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀; kò sídìí tá a fi ní láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní sáré-n-bájà bí ìgbà tó jẹ́ pé iye ojú ìwé tá a bá kà ló ṣe pàtàkì jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká máa ro ti òye àti ipò akẹ́kọ̀ọ́ náà ká tó pinnu bá a ṣe máa jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yára tó. Ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà di ọmọlẹ́yìn Kristi kó sì di olùjọsìn Jèhófà. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, a ní láti lo àkókò tó bá gbà láti jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè lóye ohun tó ń kọ́ débí tó yẹ. Ìgbà yẹn ni òtítọ́ Bíbélì tó ń kọ́ máa tó lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn, tó sì máa lè fi ohun tó ń kọ́ sílò.—Róòmù 12:2.
Ìbéèrè Tó Bá A Mu Ló Máa Ń Béèrè
8, 9. (a) Kí nìdí tí Jésù fi máa ń lo ìbéèrè? (b) Báwo ni Jésù ṣe lo ìbéèrè láti ran Pétérù lọ́wọ́ kó bàa lè lóye ọ̀rọ̀ sísan owó orí inú tẹ́ńpìlì?
8 Jésù máa ń lo ìbéèrè dáadáa, kódà nígbà tóhun tó fẹ́ bá àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sọ ò ní gbà á lákòókò púpọ̀. Kí wá nìdí tó fi máa ń béèrè ìbéèrè? Nígbà míì, ó máa ń lo ìbéèrè tó ṣe ṣàkó láti túdìí èròkerò tó wà lọ́kàn àwọn alátakò rẹ̀, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ pa wọ́n lẹ́nu mọ́. (Mátíù 21:23-27; 22:41-46) Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, Jésù máa ń lo ìbéèrè láti jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde kó sì mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀, kó tún jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà ronú. Ìdí nìyẹn tó fi lo irú àwọn ìbéèrè bíi, “Kí ni ẹ̀yin rò?” àti “Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” (Mátíù 18:12; Jòhánù 11:26) Ọ̀nà tí Jésù máa ń gbà lo ìbéèrè yìí ti mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn. Àpẹẹrẹ kan rèé.
9 Lákòókò kan, àwọn agbowó orí bi Pétérù bóyá Jésù máa ń sanwó orí.c Pétérù ò tiẹ̀ ṣòpò rò ó jinlẹ̀ kó tó dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Àmọ́ lẹ́yìn náà, Jésù ràn án lọ́wọ́ láti ronú, ó ní: “Kí ni ìwọ rò, Símónì? Lọ́wọ́ ta ni àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn ni tàbí lọ́wọ́ àwọn àjèjì?” Pétérù fèsì pé: “Lọ́wọ́ àwọn àjèjì.” Jésù wá sọ fún un pé: “Ní ti gidi, nígbà náà, àwọn ọmọ bọ́ lọ́wọ́ owó orí.” (Mátíù 17:24-27) Ó dájú pé yékéyéké ni ìbéèrè yẹn jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ kí Pétérù kọ́ yé e, torí kò ṣàìmọ̀ pé kò yẹ káwọn ará ilé ọba máa san owó orí. Nítorí náà, kò yẹ kí Jésù, tó jẹ́ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo fún Ọba ọ̀run táwọn èèyàn ń jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì, san owó orí. Kíyè sí i pé dípò kí Jésù kàn sọ bó ṣe yẹ kí ọ̀ràn rí fún Pétérù, ṣe ló fọgbọ́n lo ìbéèrè láti ran Pétérù lọ́wọ́ kó bàa lè lóye ọ̀ràn náà, tàbí kó bàa lè mọ̀ pé ó máa dáa nígbà míì kó máa ronú jinlẹ̀ kó tó máa fèsì ọ̀rọ̀.
10. Bá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, báwo la ṣe lè lo ìbéèrè lọ́nà tó múná dóko?
10 Báwo la ṣe lè lo ìbéèrè lọ́nà tó múná dóko lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, a lè lo ìbéèrè láti mú kí ọkàn àwọn èèyàn fà sí ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ bá wọn sọ, èyí tó ṣeé ṣe kó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti sọ ìhìn rere náà fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé àgbàlagbà la bá nílé, a lè béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé, “Báwo layé ṣe rí nígbà tiyín?” Lẹ́yìn tá a bá ti jẹ́ kó fèsì, a ‘tún lè bi í pé, “Kí lẹ rò pé ó lè jẹ́ kí ayé túbọ̀ rọrùn-ún gbé?” (Mátíù 6:9, 10) Bó bá jẹ́ pé ẹni tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ ló jáde sí wa, a lè bi í pé, “Ǹjẹ́ ẹ ti ronú rí nípa bí ayé yìí ṣe máa rí nígbà táwọn ọmọ yín bá fi máa dàgbà?” (Sáàmù 37:10, 11) Bá a bá ní àkíyèsí nígbà tá a bá ti ń sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé kan, ó máa rọrùn fún wa láti mọ ìbéèrè tó máa bá ẹni tó wà nínú ilé náà mu.
11. Nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, báwo la ṣe lè máa lo ìbéèrè lọ́nà tó dára?
11 Nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, báwo la ṣe lè máa lo ìbéèrè lọ́nà tó dára? Bá a bá fara balẹ̀ ronú dáadáa lórí ìbéèrè tá a fẹ́ bi akẹ́kọ̀ọ́ náà, ó máa jẹ́ kó lè sọ èrò rẹ̀ jáde. (Òwe 20:5) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé orí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn,” là ń jíròrò nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?d Orí náà jíròrò ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìṣekúṣe, ìmutípara àti irọ́ pípa. Ìdáhùn akẹ́kọ̀ọ́ náà lè fi hàn pé ó lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó gba ohun tó ń kọ́ yẹn gbọ́? A lè bi í pé “Ǹjẹ́ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ mọ́gbọ́n dání?” A tún lè bi í pé, “Báwo lo ṣe lè fi ohun tó o ń kọ́ yìí sílò nígbèésí ayé rẹ?” Ṣá, ká má gbàgbé pé a ní láti fọgbọ́n ṣe é, ká sì fọ̀wọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ náà wọ̀ ọ́. A ò kàn ní fẹ́ bi akẹ́kọ̀ọ́ ní ìbéèrè tó máa kàn án lábùkù.—Òwe 12:18.
Ó Ń Lo Ìfèròwérò Tó Mọ́gbọ́n Dání Lọ́nà Tó Ta Yọ
12-14. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà lo ìfèròwérò lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání? (b) Báwo ni Jésù ṣe lo ìfèròwérò tó mọ́gbọ́n dání lọ́nà tó ta yọ nígbà táwọn Farisí sọ pé agbára Sátánì ló ń lò?
12 Kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Jésù nínú ká fèrò wérò nítorí pé ẹni pípé ni. Nígbà míì, ó máa ń lo ìfèròwérò lọ́nà tó ta yọ láti lè túdìí àṣírí ẹ̀sùn èké àwọn alátakò rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń lo ọgbọ́n ìyíniléròpadà táá mú kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ronú jinlẹ̀ láti lè kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára wọn.
13 Lẹ́yìn tí Jésù ṣèwòsàn fún ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù wà nínú rẹ̀ tó fọ́jú tó sì tún yadi, àwọn Farisí fẹ̀sùn kàn án pé: “Àwé yìí kò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde bí kò ṣe nípasẹ̀ Béélísébúbù [ìyẹn Sátánì], olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí fi hàn pé wọ́n gbà tipátipá pé agbára tó ju agbára lọ lèèyàn lè fi lé ẹ̀mí èṣù jáde. Àmọ́ agbára Sátánì ni wọ́n ní Jésù ń lò. Yàtọ̀ sí pé irọ́ lẹ̀sùn yẹn, kò tiẹ̀ tún mọ́gbọ́n dání. Láti lè fi hàn pé ìrònú wọn ò jinlẹ̀, Jésù dá wọn lóhùn pé: “Gbogbo ìjọba tí ó bá pínyà sí ara rẹ̀ a máa wá sí ìsọdahoro, gbogbo ìlú ńlá tàbí ilé tí ó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. Ní ọ̀nà kan náà, bí Sátánì bá ń lé Sátánì jáde, ó ti pínyà sí ara rẹ̀; báwo wá ni ìjọba rẹ̀ yóò ṣe dúró?” (Mátíù 12:22-26) Ohun tí Jésù fìyẹn sọ fún wọn ni pé: “Bí mo bá jẹ́ ìránṣẹ́ Sátánì, tí mo wá ń ba iṣẹ́ Sátánì jẹ́, a jẹ́ pé Sátánì ń ta ko ara rẹ̀ nìyẹn, kò ní pẹ́ ṣubú.” Ǹjẹ́ wọ́n lè sọ pé ìfèròwérò tó mọ́gbọ́n dání yẹn kì í ṣòọ́tọ́?
14 Jésù ò fi ìfèròwérò yẹn mọ síbẹ̀. Torí ó mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí kan ti lé ẹ̀mí èṣù jáde rí, ó bi wọ́n ní ìbéèrè gbankọgbì kan, ó ní: “Bí mo bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípasẹ̀ Béélísébúbù, ta ni àwọn ọmọ yín [lédè mìíràn, ọmọ ẹ̀yìn yín] fi ń lé wọn jáde?” (Mátíù 12:27) Ìtúmọ̀ ohun tí Jésù ń sọ fún wọn rèé: “Bó bá jẹ́ pé agbára Sátánì ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé agbára Sátánì ọ̀hún kan náà làwọn ọmọ yín fi ń lé e jáde.” Kí làwọn Farisí máa tún rí wí? Láé, wọn ò jẹ́ gbà pé agbára Sátánì làwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn fi ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. Nípa báyìí, Jésù mú kí wọ́n gbà tipátipá pé ìrònú wọn ò jinlẹ̀. Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ ẹ bó o kàn ṣe kà nípa ọ̀nà tí Jésù gbà fèrò wérò pẹ̀lú wọn yẹn? Wá ronú nípa bó ṣe rí lára àwọn èrò tó fetí ara wọn gbọ́rọ̀ Jésù, ó dájú pé bí wọ́n ṣe ń wò ó àti ohùn rẹ̀ tí wọ́n ń gbọ́ á túbọ̀ mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lágbára lọ́kàn wọn.
15-17. Mẹ́nu ba àpẹẹrẹ kan tí Jésù ti fèrò wérò nípa lílò gbólóhùn náà “mélòómélòó ni” láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ tó ń mọ́kàn yọ̀ nípa Bàbá rẹ̀.
15 Tí Jésù bá fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ tó ń gbéni ró tó sì ń mọ́kàn yọ̀ nípa Bàbá rẹ̀, ó máa ń lo ìfèròwérò àti ìyíniléròpadà tó mọ́gbọ́n dání. Ó sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa lílo gbólóhùn náà, “mélòómélòó ni,” èyí tó ń jẹ́ káwọn olùgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ ní òye tó jinlẹ̀ nípa àwọn òtítọ́ kan tí wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀, ó sì ń mú kó dá wọn lójú sí i. eTéèyàn bá fi irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ ṣe ìfèròwérò, ó máa ń jẹ́ kí òye jinlẹ̀ nínú ẹni téèyàn ń kọ́, torí pé á rí ìyàtọ̀ láàárín ohun tó mọ̀ àti ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì péré yẹ̀ wò.
16 Nígbà tí Jésù ń fèsì ìbéèrè àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kó kọ́ àwọn bó ṣe yẹ láti máa gbàdúrà, ńṣe ló ṣàlàyé bó ṣe máa ń wu àwọn òbí tó jẹ́ aláìpé láti “fi ẹ̀bùn rere fún” àwọn ọmọ wọn. Ó wá parí rẹ̀ báyìí pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:1-13) Ohun tí Jésù ṣe níbí ni pé ó fi nǹkan méjì wéra. Báwọn òbí tí wọ́n jẹ́ èèyàn aláìpé bá lè máa ṣe ohun tí ọmọ wọn nílò, mélòómélòó ni Bàbá wa ọ̀run, tó jẹ́ ẹni pípé tó sì jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà, á fi fún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ láìyẹsẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ bí wọ́n ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà!
17 Irú ọ̀nà ìfèròwérò yìí kan náà ni Jésù lò nígbà tó ń gbani nímọ̀ràn nípa àníyàn. Ó ní: “Àwọn ẹyẹ ìwò kì í fún irúgbìn tàbí kárúgbìn, wọn kò sì ní yálà abà tàbí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Mélòómélòó ni ẹ fi níye lórí ju àwọn ẹyẹ? Ẹ ṣàkíyèsí dáadáa bí àwọn òdòdó lílì ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá tàbí rànwú . . . Wàyí o, bí Ọlọ́run bá ṣe báyìí wọ ewéko tí ń bẹ nínú pápá ní aṣọ, èyí tí ó wà lónìí, tí a sì jù sínú ààrò lọ́la, mélòómélòó ni òun yóò kúkú wọ̀ yín ní aṣọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré!” (Lúùkù 12:24, 27, 28) Bí Jèhófà bá ń bójú tó àwọn ẹyẹ àtàwọn òdòdó, mélòómélòó ni kò fi ní bójú tó àwọn èèyàn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ tí wọ́n sì ń sìn ín! Ó dájú pé lílò tí Jésù lo irú ọ̀nà ìfèròwérò yẹn jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn tó gbọ́ ọ lọ́kàn.
18, 19. Báwo la ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú ẹni tó sọ pé òun ò lè gbà pé Ọlọ́run tóun ò fojú rí wà?
18 Bá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó yẹ ká máa lo ìfèròwérò tó mọ́gbọ́n dání láti járọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké. A sì tún lè lo ọgbọ́n ìyíniléròpadà láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Jèhófà. (Ìṣe 19:8; 28:23, 24) Ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé ká lọ kọ́ ìfèròwérò tó lọ́jú pọ̀? Rárá o. Ẹ̀kọ́ tá a kọ́ lára Jésù ni pé ìfèròwérò tó mọ́gbọ́n dání tó sì tètè ń yé èèyàn ló máa ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tá a bá fi kọ́ni wọni lọ́kàn jù lọ.
19 Bí àpẹẹrẹ, èsì wo la lè fẹ́ni tó sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà torí pé òun ò lè rí i sójú? A lè bá a fèrò wérò nípa lílo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí òfin àdánidá kan pé bí kò bá sí ohun tó ṣe ẹ̀ṣẹ́, ẹ̀ṣẹ́ kì í ṣẹ́ lásán. Tá a bá rí nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀, a mọ̀ pé ohun kan ló fà á. A lè sọ pé: “Ká ló o wà níbì kan tó jẹ́ àdádó, tó o sì dédé yọ sí ilé mèremère kan tí oúnjẹ kúnnú rẹ̀, ṣó dìgbà tẹ́nì kan bá sọ fún ọ kó o tó mọ̀ pé ilé náà ò ṣàdédé débẹ̀, àti pé ẹnì kan ló gbọ́dọ̀ ti kó oúnjẹ náà síbẹ̀? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bá a bá wá rí àwọn iṣẹ́ ọnà tó wà nínú ìṣẹ̀dá àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ṣé kò bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ẹnì kan ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀? Ohun tí Bíbélì tiẹ̀ sọ ni pé: ‘Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.’” (Hébérù 3:4) Àmọ́ ṣá, bó ti wù kí ìfèròwérò wa gún régé tó, gbogbo èèyàn kọ́ ló máa gba ohun tá a bá sọ.—2 Tẹsalóníkà 3:2.
20, 21. (a) Báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn èèyàn ronú nípa lílo gbólóhùn náà “mélòómélòó ni” láti fi tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ Jèhófà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò ní orí tó kàn?
20 Bá a bá ń kọ́ni, ì báà jẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí nínú ìjọ, àwa náà lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ronú nípa lílo gbólóhùn náà “mélòómélòó ni” láti fi ṣàlàyé àwọn ànímọ́ Jèhófà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé, ẹ̀kọ́ tó sọ pé àwọn èèyàn ń joró nínú iná ọ̀run àpáàdì títí ayé ń tàbùkù sí Jèhófà, a lè sọ pé: “Bàbá wo tó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ló máa kiwọ́ ọmọ rẹ̀ bọnú iná torí pé ọmọ náà ṣe ohun tó ní kò gbọ́dọ̀ ṣe? Mélòómélòó wá ni èrò iná ọ̀run àpáàdì á ṣe jẹ́ ohun ìríra fún Bàbá wa ọ̀run tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́!” (Jeremáyà 7:31) Bá a bá fẹ́ fún onígbàgbọ́ bíi tiwa tí ìrònú ti dorí rẹ̀ kodò níṣìírí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a lè sọ pé: “Bí Jèhófà bá lè ka àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ kéékèèké sí pàtàkì, mélòómélòó wá ni ti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwa tá à ń sìn ín lórí ilẹ̀ ayé títí kan ìwọ alára, ó dájú pé ó kà wá sí, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa!” (Mátíù 10:29-31) Irú ìfèròwérò bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn ẹlòmíì lọ́kàn.
21 Mẹ́ta lára àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jésù tá a gbé yẹ̀ wò yìí ti jẹ́ ká rí ìdí tó fi jẹ́ pé àsọdùn kọ́ làwọn ọlọ́pàá tí wọ́n rán pé kí wọ́n lọ gbé Jésù sọ nígbà tí wọ́n sọ pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” Ní orí tó kàn, a máa jíròrò àwọn ọ̀nà ìkọ́ni míì táwọn èèyàn mọ̀ mọ Jésù, ìyẹn ni lílo àpèjúwe.
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn Sànhẹ́dírìn àtàwọn olórí àlùfáà làwọn ọlọ́pàá náà ń ṣiṣẹ́ fún.
b Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nìkan ló fa gbólóhùn tó wà nínú Ìṣe 20:35 yìí yọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó fetí ara rẹ̀ gbọ́ ọ (lẹ́nu ẹnì kan tó gbọ́ ọ lẹ́nu Jésù fúnra rẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù jí dìde ló sọ ọ́), ó sì lè jẹ́ nípasẹ̀ ìṣípayá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
c Wọ́n máa ń gba owó dírákímà méjì, èyí tó jẹ́ déédéé owó iṣẹ́ ọjọ́ méjì, lọ́wọ́ àwọn Júù lọ́dọọdún gẹ́gẹ́ bí owó orí tẹ́ńpìlì. Ìwé kan sọ pé: “Olórí ohun tí wọ́n ń lo owó orí yìí fún ni láti fi bójú tó ìnáwó ìrúbọ àtàwọn ètùtù míì tí wọ́n ń ṣe nítorí àwọn aráàlú.”
d Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
e This type of reasoning is sometimes termed “a fortiori,” a Latin expression meaning “for a still stronger reason; even more certain; all the more.”