Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù
Ipa Wo Làwọn Áńgẹ́lì Ń Ní Lórí Wa
Jésù gbé lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ní ibi táwọn áńgẹ́lì ń gbé “kí ayé tó wà.” (Jòhánù 17:5) Nítorí náà, ó kúnjú ìwọ̀n láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí.
Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì ń wá ire wa?
▪ Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn áńgẹ́lì ń wá ire àwọn èèyàn gan-an ni. Ó sọ pé: “Ìdùnnú . . . máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà.”—Lúùkù 15:10.
Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé, ara iṣẹ́ àwọn áńgẹ́lì ni láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run má bàa bà jẹ́. Nítorí náà, nígbà tí Jésù ń kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fa ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì, ó sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí; nítorí mo sọ fún yín pé nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 18:10) Ohun tí Jésù ń sọ níbí yìí kì í ṣe pé Ọlọ́run yan áńgẹ́lì kọ̀ọ̀kan fún àwọn ọmọlẹ́yìn kọ̀ọ̀kan láti máa dáàbò bò wọ́n. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, àwọn áńgẹ́lì tó ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ń wá ire àwọn Kristẹni tòótọ́.
Báwo ni Èṣù ṣe ń ṣini lọ́nà?
▪ Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé Sátánì ń sapá láti mú kí àwọn èèyàn ṣíwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Ó ní: “Níbi tí ẹnì kan bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba náà ṣùgbọ́n tí òye rẹ̀ kò yé e, ẹni burúkú náà a wá, a sì já ohun tí a ti gbìn sínú ọkàn-àyà rẹ̀ gbà lọ.”—Mátíù 13:19.
Jésù tú àṣírí ọ̀nà kan tí Sátánì máa ń gbà tan àwọn èèyàn jẹ nígbà tó sọ àpèjúwe nípa ọkùnrin kan tó gbin àlìkámà sínú oko rẹ̀. Jésù ni ọkùnrin olóko yìí dúró fún, àlìkámà náà sì dúró fún àwọn Kristẹni tòótọ́ tó máa bá Jésù jọba ní ọ̀run. Àmọ́ Jésù sọ pé, ọ̀tá kan wá, ó sì “fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà náà.” Àwọn èké Kristẹni làwọn èpò yìí dúró fún. “Ọ̀tá tí ó sì fún wọn ni Èṣù.” (Mátíù 13:25, 39) Bí èpò ṣe máa ń jọ àlìkámà, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn èké Kristẹni ṣe máa ń jọ àwọn Kristẹni tòótọ́. Ẹ̀sìn tó bá ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Sátánì ń lo ẹ̀sìn èké láti má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà.
Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí Sátánì ṣì wá lọ́nà?
▪ Jésù pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 14:30) Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run, ó jẹ́ ká mọ bí a kò ṣe ní kó sọ́wọ́ Sátánì. Jésù gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé. Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:15-17) Ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè dáàbò bò wá kúrò lábẹ́ ìdarí ayé tí Sátánì ń ṣàkóso.
Ipa wo làwọn áńgẹ́lì ń ní lórí wa lóde òní?
▪ Jésù sọ pé: “Ní ìparí ètò àwọn nǹkan: àwọn áńgẹ́lì yóò jáde lọ, wọn yóò sì ya àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn olódodo.” (Mátíù 13:49) Ní báyìí, à ń gbé “ní ìparí ètò àwọn nǹkan,” ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló sì ń fetí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 24:3, 14.
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ló rí ojú rere Ọlọ́run. Àwọn áńgẹ́lì ń darí iṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ìyàsọ́tọ̀ sì ń wáyé láàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn àtàwọn tí wọn kì í fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó rí ojú rere Ọlọ́run, ó ní: “Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹ́yìn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ọkàn-àyà àtàtà àti rere, wọ́n dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso pẹ̀lú ìfaradà.”—Lúùkù 8:15.
Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 10 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn áńgẹ́lì ń kó ipa nínú kíkó àwọn ọlọ́kàn títọ́ jọ sínú ìjọ Kristẹni