Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Kọ́ Ìdáríjì Lọ́dọ̀ Ọ̀gá Rẹ̀
PÉTÉRÙ kò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ tí nǹkan ò rọgbọ yẹn, nígbà tójú òun àti Jésù ṣe mẹ́rin. Ǹjẹ́ Pétérù rí i lójú Jésù pé kò fọkàn tán òun mọ́ tàbí pé ó pẹ̀gàn òun? A kò lè sọ, àmọ́ ohun tí àkọsílẹ̀ onímìísí sọ ni pé “Olúwa sì yí padà, ó sì bojú wo Pétérù.” (Lúùkù 22:61) Ṣùgbọ́n Pétérù rí bí àṣìṣe òun ṣe pọ̀ tó nínú bí Jésù ṣe wo òun yẹn. Ó gbà pé ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ni òun ṣe yìí, ìyẹn ohun tí Pétérù sọ pé òun kò ní ṣe láéláé, pé kí òun sẹ́ Ọ̀gá òun àtàtà. Ìgbà yẹn, gbogbo nǹkan tojú sú Pétérù pátápátá, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọjọ́ yìí lọjọ́ tó tíì le jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀.
Àmọ́ ṣá o, ó bà ni, kò tíì bà jẹ́. Ìdí ni pé Pétérù ní ìgbàgbọ́ gan-an, ó ṣì ní àǹfààní láti borí àṣìṣe náà, kí ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ ńlá kan lọ́dọ̀ Jésù. Ìdáríjì ni ẹ̀kọ́ náà. Gbogbo wa ló yẹ ka kọ́ irú ẹ̀kọ́ yìí, nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo bí Pétérù ṣe kọ́ ẹ̀kọ́ náà.
Ọkùnrin Tó Lè Kọ́ni Lóhun Púpọ̀
Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn ní Kápánáúmù, ní ìlú ìbílẹ̀ Pétérù, Pétérù béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mí, tí èmi yóò sì dárí jì í? Títí dé ìgbà méje ni bí?” Ó ṣeé ṣe kí Pétérù ti rò pé òun láàánú. Ó ṣe tán, ohun táwọn aṣáájú ìsìn ń kọ́ni nígbà yẹn ni pé ìgbà mẹ́ta péré ni kéèyàn máa dárí jini! Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.”—Mátíù 18:21, 22.
Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kí Pétérù máa ka iye ìgbà táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ ẹ́? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó sọ fún Pétérù pé kí ìgbà méje di ìgbà àádọ́rin lé méje, ohun tó ń sọ ni pé kò sí bí iye ìgbà téèyàn ṣẹ̀ wá ṣe lè pọ̀ tó, kí á dárí jì í. Jésù fi hàn pé orí kunkun àti ẹ̀mí àìní ìdáríjì tó gbòde kan nígbà yẹn ti ran Pétérù, ìyẹn bí wọ́n ṣe máa ń kọ iye ìgbà tí wọ́n dárí ji ẹnì kan sílẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run máa ń dárí jini lọ́pọ̀lọpọ̀!
Pétérù kò bá Jésù jiyàn. Ǹjẹ́ ohun tí Jésù kọ́ ọ yé e? Nígbà míì, a máa ń mọyì ìdáríjì gan-an nígbà tí àwa fúnra wa bá ri pé a nílò rẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pa dà wo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú. Ní àwọn ìgbà tí nǹkan le yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Pétérù ṣe tó fi nílò ìdáríjì Ọ̀gá rẹ̀.
Ìgbà Gbogbo Ni Èèyàn Nílò Ìdáríjì
Ní alẹ́ mánigbàgbé tó ṣáájú ọjọ́ ikú Jésù, ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó fẹ́ kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, lára rẹ̀ ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Jésù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa fífọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, èyí sì jẹ́ iṣẹ́ tí ìránṣẹ́ kan tí ipò rẹ̀ kéré jù lọ máa ń ṣe. Lákọ̀ọ́kọ́, Pétérù rò pé kò yẹ kí Jésù ṣe ohun tó fẹ́ ṣe yẹn. Kò gbà kí Jésù fọ ẹsẹ̀ òun. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá fi dandan lé e pé kì í ṣe ẹsẹ̀ òun nìkan ni kí Jésù fọ̀, àmọ́ kó tún fọ ọwọ́ àti orí òun pẹ̀lú! Jésù kò bínú, àmọ́, ó rọra ṣàlàyé bí ohun tóun ń ṣe ti ṣe pàtàkì tó àti ìdí tóun fi ṣe é.—Jòhánù 13:1-17.
Àmọ́ kété lẹ́yìn náà, àwọn àpọ́sítélì bẹ̀rẹ̀ sí ṣawuyewuye lórí ẹni tó ṣe pàtàkì jù láàárín wọn. Ó dájú pé Pétérù kópa nínú ìwà ìgbéraga tó ń tini lójú yìí. Síbẹ̀, Jésù fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà, ó sì gbóríyìn fún wọn bí wọ́n ṣe dúró gbágbáágbá ti òun Ọ̀gá wọn. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo wọn ló máa fi òun sílẹ̀. Pétérù jiyàn pé òun á dúró gbágbáágbá ti Jésù, àní títí dójú ikú. Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé lóru ọjọ́ yẹn gan-an, kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, Pétérù yóò sẹ́ òun lẹ́ẹ̀mẹ́ta. Kì í ṣe pé Pétérù sọ pé òun kò ní sẹ́ Jésù nìkan ni, àmọ́ ó tún fọ́nnu pé òun á jẹ́ olóòótọ́ ju àwọn àpọ́sítélì yòókù lọ!—Mátíù 26:31-35; Máàkù 14:27-31; Lúùkù 22:24-28.
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Pétérù kò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sú Jésù báyìí? Kódà, ní gbogbo àkókò wàhálà yìí, ohun tó dáa tó wà lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ aláìpé ni Jésù ń wò. Ó mọ̀ pé Pétérù yóò já òun kulẹ̀, síbẹ̀ ó sọ pé: “Èmi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí rẹ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa yẹ̀; àti ìwọ, ní gbàrà tí o bá ti padà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.” (Lúùkù 22:32) Jésù tipa báyìí fi hàn pé òun nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé pé Pétérù máa borí àṣìṣe rẹ̀, á sì tún máa fi òótọ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó. Ẹ ò rí irú ẹ̀mí ìdáríjì tí ìyẹn jẹ́!
Lẹ́yìn náà, nínú ọgbà Gẹtisémánì, ó ju ìgbà kan ṣoṣo lọ tí Pétérù nílò ìtọ́sọ́nà. Jésù sọ fún Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù pé kí wọ́n máa ṣọ́nà nígbà tóun ń gbàdúrà. Jésù ní ẹ̀dùn ọkàn, ó sì nílò ìrànlọ́wọ́, àmọ́ léraléra ni oorun ń gbé Pétérù àtàwọn yòókù lọ. Jésù fi hàn pé òun ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò àti ẹ̀mí ìdáríjì, torí náà, ó sọ nípa wọn pé: “Ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”—Máàkù 14:32-38.
Láìpẹ́, àwọn jàǹdùkú dé, wọ́n mú ètùfù, idà àti kóńdó lọ́wọ́. Àkókò nìyí láti lo ọgbọ́n àti ìṣọ́ra. Síbẹ̀, Pétérù fi ìwàǹwára hùwà, ó gbé idà sókè sí Málíkọ́sì, ẹrú olórí àlùfáà, ó sì gé ọ̀kan lára etí rẹ̀ dà nù. Jésù rọra tọ́ Pétérù sọ́nà, ó wo ọgbẹ́ náà sàn, ó sì ṣàlàyé pé ìwà ipá kò dára, èyí sì ni ìlànà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé títí dòní. (Mátíù 26:47-55; Lúùkù 22:47-51; Jòhánù 18:10, 11) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Pétérù ṣe tó fi nílò ìdáríjì Ọ̀gá rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí rán wa létí pé “gbogbo wa ni a ń ṣe àṣìṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà.” (Jakọbu 3:2, Ìròyìn Ayọ̀) Ta ni nínú wa tí kò nílò ìdáríjì Ọlọ́run lójoojúmọ́? Pétérù ṣì máa ṣe àṣìṣe ńlá lóru ọjọ́ yẹn.
Àṣìṣe Tó Ga Jù Lọ Tí Pétérù Ṣe
Jésù sọ fún àwọn jàǹdùkú náà pé tó bá jẹ́ pé òun ni wọ́n ń wá kí wọ́n jẹ́ kí àwọn àpọ́sítélì òun máa lọ. Ńṣe ni Pétérù kàn ń wò, kò lè ṣe nǹkan kan bí àwọn jàǹdùkú náà ṣe ń de Jésù. Lẹ́yìn náà ni Pétérù sá lọ bíi tàwọn àpọ́sítélì yòókù.
Nígbà tó yá, Pétérù àti Jòhánù kò sáré mọ́, wọ́n dúró, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítòsí ilé Àlùfáà Àgbà tẹ́lẹ̀ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ánásì, níbi tí wọ́n kọ́kọ́ mú Jésù lọ láti bí i ní ìbéèrè. Bí wọ́n ti mú Jésù láti ibẹ̀, Pétérù àti Jòhánù tẹ̀ lé wọn àmọ́ “ní òkèèrè réré.” (Mátíù 26:58; Jòhánù 18:12, 13) Pétérù kì í ṣe ojo rárá. Torí pé ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè tẹ̀ lé wọn. Àwọn jàǹdùkú yẹn kó àwọn ohun ìjà lọ́wọ́, Pétérù sì ti ṣe ọ̀kan lára wọn léṣe tẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, a kò tíì rí i nínú àpẹẹrẹ Pétérù pé ó jẹ́ irú adúróṣinṣin tó sọ pé òun máa jẹ́, pé òun múra tán láti kú pẹ̀lú Ọ̀gá òun bí ọ̀rọ̀ bá dà bẹ́ẹ̀.—Máàkù 14:31.
Bíi ti Pétérù, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń fẹ́ máa tẹ̀ lé Kristi “ní òkèèrè réré,” kí àwọn èèyàn má bàa kíyè sí wọn. Ṣùgbọ́n Pétérù fúnra rẹ̀ kọ̀wé nígbà tó yá pé, ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà tẹ̀ lé Kristi dáadáa ni pé kó máa tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó, kéèyàn máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ohun gbogbo, láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí.—1 Pétérù 2:21.
Níkẹyìn, Pétérù rọra dé ẹnubodè ọ̀kan lára ilé tó tóbi jù lọ ní Jerúsálẹ́mù. Ilé Káyáfà, àlùfáà àgbà tó lọ́rọ̀ tó sì lágbára ni. Àgbàlá sábà máa ń wà láàárín irú ilé bẹ́ẹ̀, ó sì máa ń ní ẹnubodè níwájú. Nígbà tí Pétérù dé ẹnubodè náà wọn kò jẹ́ kó wọlé. Jòhánù tó ti wọlé tẹ́lẹ̀ jáde wá bá aṣọ́bodè náà pé kó jẹ́ kí Pétérù wọlé. Ó jọ pé Pétérù kò dúró ti Jòhánù, kò sì jọ pé ó gbìyànjú láti wọlé kó lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọ̀gá rẹ̀. Ó dúró nínú àgbàlá níbi tí díẹ̀ lára àwọn ẹrú àtàwọn ìránṣẹ́ ti ń yáná lóru yẹn, ó ń wo bí àwọn tó ń jẹ́rìí èké sí Jésù ṣe ń wọlé tí wọ́n sì ń jáde níbi ìgbẹ́jọ́ náà.—Máàkù 14:54-57; Jòhánù 18:15, 16, 18.
Nínú ìmọ́lẹ̀ iná náà, ọmọbìnrin tó jẹ́ kí Pétérù gba ẹnubodè wọlé wá rí Pétérù dáadáa. Ó dá a mọ̀. Ó fẹ̀sùn kàn án pé: “Ìwọ, náà, wà pẹ̀lú Jésù ará Gálílì!” Ọ̀ràn náà bá Pétérù lábo, ó sẹ́ pé òun kò mọ Jésù, kódà ó tiẹ̀ sọ pé òun kò mọ ohun tí ọmọbìnrin náà ń sọ. Ó lọ dúró sí tòsí ẹnubodè náà, kò fẹ́ káwọn èèyàn rí òun, àmọ́ ọmọbìnrin míì rí i, ó sì sọ pé òun mọ̀ ọ́n, ó ní: “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ará Násárétì.” Pétérù búra pé: “Èmi kò mọ ọkùnrin náà!” (Mátíù 26:69-72) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Pétérù sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì ni ó gbọ́ tí àkùkọ kọ, àmọ́ àwọn nǹkan ti gbà á lọ́kàn tí kò fi rántí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ ní àwọn wákàtí tó ṣáájú.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Pétérù ṣì ń gbìyànjú gan-an pé káwọn èèyàn má ṣe rí òun. Àmọ́ àwọn èèyàn kan tí wọ́n dúró nínú àgbàlá náà sún mọ́ ọn. Ọkùnrin kan lára wọn jẹ́ ìbátan Málíkọ́sì, ìyẹn ẹrú tí Pétérù ṣe léṣe. Ó sọ fún Pétérù pé: “Mo rí ọ nínú ọgbà pẹ̀lú rẹ̀, àbí èmi kò rí ọ?” Pétérù fẹ́ fi dandan mú kí wọ́n gbà pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀, ló bá búra, ó sọ ni kedere pé kí èpè ja òun tó bá jẹ́ pé irọ́ lòun pa. Kò pẹ́ tó sọ bẹ́ẹ̀ ni àkùkọ kọ, ìyẹn ni ìgbà kejì tí Pétérù gbọ́ tí àkùkọ kọ lálẹ́ ọjọ́ yẹn.—Jòhánù 18:26, 27; Máàkù 14:71, 72.
Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde wá sí ọ̀dẹ̀dẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì tó dojú kọ àgbàlá náà ni. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, ìgbà yẹn ni ojú Jésù àti Pétérù ṣe mẹ́rin. Ó wá yé Pétérù kedere bó ti já Ọ̀gá rẹ̀ kulẹ̀ tó. Pétérù fi àgbàlá náà sílẹ̀, ẹ̀bi ohun tó ṣe kó ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi. Ó gba ojú pópó bí ìmọ́lẹ̀ òṣùpá tó ń wọ̀ọ̀kùn ti mọ́lẹ̀ sójú ọ̀nà tó ń gbà lọ. Ojú rẹ̀ ń ṣe bàìbàì, omijé bò ó lójú. Ó bú sẹ́kún, ó sì sunkún kíkorò.—Máàkù 14:72; Lúùkù 22:61, 62.
Nínú irú ipò ìjákulẹ̀ yìí, èèyàn lè tètè rò pé ẹ̀ṣẹ̀ òun ti pọ̀ jù, pé òun kò lè rí ìdáríjì gbà. Pétérù ti lè rò bẹ́ẹ̀ nípa ara rẹ̀. Ṣé á rí ìdáríjì gbà lóòótọ́?
Ṣé Ọ̀ràn Pétérù Ti Kọjá Ìdáríjì?
Ó ṣòro láti mọ bí ìrora Pétérù ṣe pọ̀ tó bí ilẹ̀ ti mọ́ lọ́jọ́ yẹn, tí iṣẹ́ ọjọ́ náà sì bẹ̀rẹ̀. Ẹ wo bí Pétérù ṣe máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi tó nígbà tí Jésù kú lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn lẹ́yìn tó ti jẹ ọ̀pọ̀ ìrora! Ìbànújẹ́ ti ní láti bá Pétérù bó ṣe ń ronú nípa bóun ṣe fi kún ìrora Ọ̀gá òun lálẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tó kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Pétérù bà jẹ́ kọjá àfẹnusọ, kò sọ ìrètí nù. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé, ó wá dára pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù. (Lúùkù 24:33) Kò sí àní-àní pé gbogbo àwọn àpọ́sítélì ló kábàámọ̀ ìwà tí wọ́n hù lálẹ́ ọjọ́ tí nǹkan kò rọgbọ yẹn, àmọ́ wọ́n tu ara wọn nínú.
Bó ti wù kó rí, a rí ọ̀kan lára ohun tó dáa tí Pétérù ṣe. Nígbà tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ṣe àṣìṣe, kì í ṣe bí àṣìṣe náà ṣe pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì bí kò ṣe bí ìpinnu rẹ̀ ti lágbára tó láti ṣàtúnṣe. (Òwe 24:16) Pétérù fi ìgbàgbọ́ tòótọ́ hàn nípa dídara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù láìka bí ìbànújẹ́ tó bá a ṣe pọ̀ tó. Nígbà tí ìbànújẹ́ bá báni tàbí téèyàn bá kábàámọ̀ ohun kan, èèyàn lè fẹ́ láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, àmọ́ ó léwu gan-an. (Òwe 18:1) Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn sún mọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kó bàa lè lókun nípa tẹ̀mí pa dà.—Hébérù 10:24, 25.
Nítorí pé Pétérù wà lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí, ó gbọ́ ìròyìn kan tó ń dáyà jáni pé òkú Jésù kò sí nínú ibojì mọ́. Pétérù àti Jòhánù sáré lọ wo ibojì tí wọ́n sin Jésù sí, èyí tí wọ́n ti ẹnu àbáwọlé rẹ̀ pa. Jòhánù tó ṣeé ṣe kí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré ló kọ́kọ́ dé ibẹ̀. Ó lọ́ra láti wọlé, torí ó bá ibi àbáwọlé ibojì náà ni ṣíṣí sílẹ̀. Àmọ́ nígbà tí Pétérù dé, pẹ̀lú bó ṣe ń mí hẹlẹhẹlẹ, ńṣe ló wọlé tààrà. Ó bá ibẹ̀ lófo!—Jòhánù 20:3-9.
Ṣé Pétérù gbà pé Jésù ti jíǹde? Kò kọ́kọ́ gbà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin olóòótọ́ ti ròyìn fún un pé àwọn áńgẹ́lì fara han àwọn láti kéde pé Jésù ti jíǹde. (Lúùkù 23:55–24:11) Àmọ́ nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà fi máa ṣú, gbogbo ìbànújẹ́ àti iyè méjì tó wà lọ́kàn Pétérù ti pòórá. Jésù ti wà láàyè, àmọ́ ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni nísinsìnyí! Ó fara han gbogbo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ó kọ́kọ́ ṣe ohun kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kọ̀ọ̀kan ló ṣe é fún. Àwọn àpọ́sítélì sọ lọ́jọ́ yẹn pé: “Ní ti tòótọ́ ni a gbé Olúwa dìde, ó sì fara han Símónì!” (Lúùkù 24:34) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lẹ́yìn náà nípa ọjọ́ àrà ọ̀tọ̀ yẹn pé Jésù “fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà.” (1 Kọ́ríńtì 15:5) Kéfà àti Símónì ni orúkọ míì tí Pétérù ń jẹ́. Jésù fara hàn án lọ́jọ́ yẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nígbà tí Pétérù dá wà.
Bíbélì kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jésù àti Pétérù ní àkókò alárinrin tí wọ́n pa dà ríra wọn. Ẹ fojú inú wo bí inú Pétérù á ti dùn tó pé òun tún rí Olúwa òun àtàtà tó tún pa dà wà láàyè, tí òun sì tún ní àǹfààní láti sọ ẹ̀dùn ọkàn òun, kóun sì fi ìrònúpìwàdà hàn. Ohun tí Pétérù ń fẹ́ jù lọ ni ìdáríjì. Kò sí àní-àní pé Jésù dárí ji Pétérù lọ́pọ̀ yanturu. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni tí wọ́n ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ lónìí máa rántí ọ̀ràn Pétérù. Ká má ṣe rò pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti kọjá kí Ọlọ́run dárí jì wá. Ní gbogbo ọ̀nà ni Jésù gbà gbé ìwà Bàbá rẹ̀ yọ, ẹni tí ‘yóò dárí jini lọ́nà títóbi.’—Aísáyà 55:7.
Ẹ̀rí Míì Tó Fi Hàn Pé Pétérù Rí Ìdáríjì Gbà
Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n lọ sí Gálílì, níbi tí wọ́n á ti pàdé òun. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Pétérù sọ pé òun fẹ́ lọ pẹja ní Òkun Gálílì. Àwọn míì náà bá a lọ. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Pétérù tún bá ara rẹ̀ lórí adágún omi níbi tó ti lo ọ̀pọ̀ lára ìgbésí ayé rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀. Bí ọkọ̀ ṣe ń lọ yàà lórí omi, bí ìgbì omi ṣe ń bì lu ọkọ̀ àti bí àwọ̀n náà ṣe rí lọ́wọ́ rẹ̀ mú kí ara tù ú kó sì rántí àwọn ìgbà ìṣáájú. Ǹjẹ́ Pétérù tiẹ̀ ronú lórí bó ṣe yẹ kó lo ìgbésí ayé rẹ̀ nísinsìnyí tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ti parí? Ǹjẹ́ ìgbésí ayé apẹja ló tún ń wù ú? Èyí ó wù kó jẹ́, wọ́n kò rí ẹja pa lálẹ́ ọjọ́ yẹn.—Mátíù 26:32; Jòhánù 21:1-3.
Ní àfẹ̀mọ́jú, ẹnì kan pè wọ́n láti etíkun, ó sì ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ju àwọ̀n wọn sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ náà. Wọ́n gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì fa ọ̀pọ̀ ẹja tí àwọ̀n wọn kó sínú ọkọ̀, iye rẹ̀ jẹ́ àádọ́jọ lé mẹ́ta [153]! Pétérù mọ ẹni náà. Ó bẹ́ kúrò nínu ọkọ̀ ó sì wẹ̀ lọ sí etíkun. Jésù wà ní etíkun, ó sì fún wọn ní oúnjẹ tó fi ẹja sè lórí ẹyín iná. Ó darí àfiyèsí rẹ̀ sọ́dọ̀ Pétérù.
Jésù béèrè lọ́wọ́ Pétérù bóyá ó nífẹ̀ẹ́ Olúwa rẹ̀ “ju ìwọ̀nyí lọ,” ìyẹn ẹja rẹpẹtẹ tí wọ́n pa. Lọ́kàn Pétérù, ṣé ìfẹ́ iṣẹ́ ẹja pípa yóò wá borí ìfẹ́ fún Jésù? Bí Pétérù ṣe sẹ́ Olúwa rẹ̀ nígbà mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù fún un ní àǹfààní láti fìdí ìfẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ fún òun nígbà mẹ́ta níwájú àwọn ọmọlẹ́yìn yòókù. Nígbà tí Pétérù ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù sọ bó ṣe máa fi ìfẹ́ yẹn hàn, ìyẹn ni pé kó máa fi iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ṣááju ohun gbogbo míì, kó máa bọ́ àwọn àgùntàn Kristi, kó sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Kristi, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn òun olóòótọ́.—Jòhánù 21:4-17.
Jésù fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Pétérù ṣì wúlò fún òun àti Bàbá òun. Pétérù yóò kó ipa pàtàkì nínú ìjọ lábẹ́ ìdarí Kristi. Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí tó lágbára pé Jésù ti dárí jì í pátápátá lèyí jẹ́! Ó dájú pé Pétérù mọyì àánú tí Jésù fi hàn sí i, kò sì lè gbàgbé láé.
Ọ̀pọ̀ ọdún ni Pétérù fi fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé e lọ́wọ́. Ó fún àwọn arákùnrin rẹ̀ lókun, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti pa á láṣẹ fún un ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa á. Pétérù fi àánú àti sùúrù ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, ó sì ń bọ́ wọn. Orúkọ tí Jésù fún Símónì rò ó, ìyẹn Pétérù tàbí Àpáta, nítorí ó di ẹni tó ń ṣe déédéé, tó lágbára, tó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé nínú ìjọ. A rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi èyí hàn nínú lẹ́tà méjì tó mórí ẹni wú tí Pétérù kọ tó wá di ìwé tó ṣeyebíye nínú Bíbélì. Àwọn lẹ́tà yẹn pẹ̀lú fi hàn pé Pétérù kò gbàgbé ẹ̀kọ́ tó rí kọ́ lọ́dọ̀ Jésù nípa ìdáríjì.—1 Pétérù 3:8, 9; 4:8.
Ó yẹ kí àwa náà kọ́ ẹ̀kọ́ yẹn pẹ̀lú. Ǹjẹ́ a máa ń tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ fún àṣìṣe wa tó pọ̀ rẹpẹtẹ? Ǹjẹ́ a tẹ́wọ́ gba ìdáríjì yẹn tí a sì nígbàgbọ́ pé ó lágbára láti wẹ̀ wá mọ́. Ṣé àwa náà máa ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Pétérù àti àánú Ọ̀gá rẹ̀.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
Pétérù ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó fi nílò ìdáríjì Ọ̀gá rẹ̀ àmọ́ ta ni nínú wa tí kò nílò ìdáríjì lójoojúmọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Olúwa sì yí padà, ó sì bojú wo Pétérù”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
“Olúwa . . . fara han Símónì!”