Bí a Ṣe Lè Ní Èrò Kristi Nípa Ipò Ọlá
“Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín.”—MÁTÍÙ 20:26.
1. Kí ni èrò táráyé ní nípa ipò ọlá?
NÍTÒSÍ ìlú Íjíbítì àtijọ́ tó ń jẹ́ Tíbésì (tá a mọ̀ sí Karnak lóde òní), tó wà ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà ní gúúsù ìlú Cairo, ni ère Pharaoh Amenhotep Kẹta wà. Gíga ère náà jẹ́ mítà méjìdínlógún. Téèyàn bá dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ère gìrìwò yìí, ńṣe lèèyàn máa rí pínníṣín. Ère tí wọ́n dìídì gbé kalẹ̀ láti mú káwọn èèyàn máa júbà alákòóso yìí, ṣàpẹẹrẹ èrò táráyé ní nípa ipò ọlá, ìyẹn kéèyàn máa ṣe bí èèyàn ńlá, kó máa wo àwọn ẹlòmíì bi ẹni tí kò jẹ́ nǹkankan.
2. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àwọn ìbéèrè wo ló wá yẹ ká bi ara wa?
2 Wá fi èrò táráyé ní nípa ipò ọlá yìí wé èyí tí Jésù Kristi fi kọ́ni. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù ni “Olúwa àti Olùkọ́” àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó kọ́ wọn pé lílo ara ẹni fún àwọn ẹlòmíràn ló ń sọni dẹni ńlá. Ní ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ó fi àpẹẹrẹ nǹkan tó fi ń kọ́ni lélẹ̀ nípa wíwẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹ ò ri pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ gidi nìyẹn! (Jòhánù 13:4, 5, 14) Èwo ló wù ọ́ jú nínú kó o máa ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíì tàbí káwọn ẹlòmíì máa ṣe nǹkan fún ọ́? Ǹjẹ́ àpẹẹrẹ Kristi mú kó wù ọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bíi tirẹ̀? Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí èrò tí Kristi ní nípa ipò ọlá ṣe yàtọ̀ sí èrò tó wọ́pọ̀ nínú ayé.
Yẹra fún Èrò Táráyé Ní Nípa Ipò Ọlá
3. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ láburú tí àwọn tó ń wá ògo lọ́dọ̀ èèyàn máa ń rí?
3 Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé èrò táráyé ní nípa ipò ọlá máa ń yọrí sí àjálù. Ẹ wo àpẹẹrẹ ti Hámánì alágbára tó gbajúmọ̀ gan-an láàfin ilẹ̀ Páṣíà nígbà ayé Ẹ́sítérì àti Módékáì. Ògo tí Hámánì ń wá fún ara rẹ̀ lójú méjèèjì ló mú kó dẹni ẹ̀tẹ́, tó sì kú. (Ẹ́sítérì 3:5; 6:10-12; 7:9, 10) Nebukadinésárì agbéraga tó ya wèrè lákòókò tí agbára ìjọba rẹ̀ gadabú ńkọ́? Ẹ gbọ́ bó ṣe sọ èrò tí kò tọ̀nà tó ní nípa ipò ọlá, ó sọ pé: “Bábílónì Ńlá kọ́ yìí, tí èmi fúnra mi fi okun agbára ńlá mi kọ́ fún ilé ọba àti fún iyì ọlá ọba tí ó jẹ́ tèmi?” (Dáníẹ́lì 4:30) Àpẹẹrẹ mìíràn ni Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní tó jẹ́ agbéraga, dípò kó fi ògo fún Ọlọ́run, ó lọ ń gba ògo tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. “Àwọn kòkòrò mùkúlú . . . jẹ ẹ́, ó sì gbẹ́mìí mì.” (Ìṣe 12:21-23) Nítorí pé àwọn èèyàn tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kùnà láti ní èrò Jèhófà nípa ipò ọlá ni wọ́n ṣe kàgbákò.
4. Ta lẹni tó fa ẹ̀mí ìgbéraga tó wà nínú ayé?
4 Kì í ṣe ohun tó burú tá a bá fẹ́ lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tó máa jẹ́ káwọn èèyàn yẹ wa sí tí wọ́n á sì bọ̀wọ̀ fún wa. Àmọ́, Èṣù máa ń lo ìfẹ́ ọkàn yìí láti gbin ẹ̀mí ìgbéraga sọ́kàn àwọn èèyàn, èyí tó fi irú ẹ̀mí tóun fúnra rẹ̀ ní hàn. (Mátíù 4:8, 9) Má ṣe gbàgbé pé òun ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” ó sì ti pinnu láti tan èrò rẹ̀ káàkiri ayé. (2 Kọ́ríńtì 4:4; Éfésù 2:2; Ìṣípayá 12:9) Nítorí pé àwọn Kristẹni mọ ibi tí irú èrò bẹ́ẹ̀ ti wá ni wọn ò ṣe gba èrò táráyé ní nípa ipò ọlá.
5. Ṣé ó dájú pé téèyàn bá ṣáà ti gbé nǹkan ṣe láyé, tó ti gbajúmọ̀, tó tún lọ́rọ̀, ìṣòro ẹ̀ ti tán nìyẹn? Ṣàlàyé.
5 Èrò kan tí Èṣù ń gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn ni pé, téèyàn kan bá jẹ́ni ńlá nínú ayé, táwọn èèyàn gba tiẹ̀, tó tún lówó lọ́wọ́ bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n ní ó di dandan kó láyọ̀. Àmọ́, ṣóòótọ́ ni? Ṣé ó dájú pé téèyàn bá ṣáà ti gbé nǹkan ṣe láyé, tó ti gbajúmọ̀, tó tún lọ́rọ̀, ìṣòro ẹ̀ ti tán nìyẹn? Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn firú ìrònú yẹn tàn wá jẹ. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Èmi alára sì ti rí gbogbo iṣẹ́ àṣekára àti gbogbo ìgbóṣáṣá nínú iṣẹ́, pé ó túmọ̀ sí bíbá ẹnì kìíní-kejì díje; asán ni èyí pẹ̀lú àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:4) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn ṣíṣẹ kí wọ́n lè dẹni ńlá nínú ayé ló gbà pé òótọ́ pọ́ńbélé ni àmọ̀ràn onímìísí tó wà nínú Bíbélì yẹn. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọkùnrin kan tó bá wọn yàwòrán bí ọkọ́ tá à ń gbé lọ sójú sánmà ṣe máa rí, tó bá wọn ṣe ọkọ̀ ọ̀hún, tó tún gbé e fò láti mọ̀ bóyá ó dáa tàbí kò dáa. Ọkùnrin náà sọ pé: “Mo ti ṣiṣẹ́ àṣekára títí débi pé mo di ìjìmì nídìí iṣẹ́ ọ̀hún. Síbẹ̀ náà, asán ni gbogbo ẹ̀ já sí, kò fún mi láyọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn tó wà pẹ́ títí.”a Kò sí ìdánilójú pé nǹkan táráyé kà sí ipò ọlá máa fún èèyàn láyọ̀ tó wà pẹ́ títí, nídìí ìṣòwò ni o, eré ìdárayá ni o tàbí ère ìnàjú.
Iṣẹ́ Téèyàn Fi Ìfẹ́ Ṣe Ló Ń Sọni Dẹni Ńlá
6. Kí ló fi hàn pé èrò tí Jákọ́bù àti Jòhánù ní nípa ipò ọlá kò tọ̀nà?
6 Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jésù jẹ́ ká mọ ohun tí jíjẹ́ ẹni ńlá túmọ̀ sí. Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ Ìrékọjá ti ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Bí wọ́n ti ń lọ lójú ọ̀nà, méjì lára àwọn ìbátan Jésù, ìyẹn Jákọ́bù àti Jòhánù, fi èrò tí kò tọ̀nà hàn nípa ipò ọlá. Wọ́n ní kí ìyá wọn bá wọn sọ fún Jésù pé: ‘Sọ ọ̀rọ̀ náà kí àwa lè jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú ìjọba rẹ.’ (Mátíù 20:21) Láàárín àwọn Júù, nǹkan iyì àti ẹ̀yẹ ló jẹ́ láti jókòó sọ́wọ́ ọ̀tún tàbí sọ́wọ́ òsì. (1 Àwọn Ọba 2:19) Jákọ́bù àti Jòhánù fẹ́ gba ọ̀nà ẹ̀bùrú dé ipò tó gbayì jù lọ. Wọ́n fẹ́ wà nípò aláṣẹ. Jésù mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn méjèèjì, torí náà ó lo àǹfààní yẹn láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé èrò tí wọ́n ní nípa ipò ọlá yẹn kò tọ̀nà.
7. Kí lohun tí Jésù sọ pé ó máa ń sọ Kristẹni kan dẹni ńlá ní ti gidi?
7 Jésù mọ̀ pé nínú ayé onígbèéraga yìí, ẹni táwọn èèyàn kà sẹ́ni ńlá ni ẹni tó máa ń darí àwọn èèyàn tó sì máa ń pàṣẹ fún wọn, tó jẹ́ pé ohun yòówù tó bá ní kí wọ́n ṣe ni wọ́n á ṣe lójú ẹsẹ̀. Àmọ́ láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ẹni tó bá ń ṣe iṣẹ́ rírẹlẹ̀ lẹni ńlá. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.”—Mátíù 20:26, 27.
8. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ òjíṣẹ́, àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa?
8 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tá a tú sí “òjíṣẹ́” nínú Bíbélì tọ́ka sí ẹnì kan tó máa ń sapá lójú méjèèjì láti lo ara rẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn. Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan ni Jésù ń kọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn ni pé: Kì í ṣe kí ẹnì kan máa pàṣẹ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣe tibí tàbí kí wọ́n ṣe tọ̀hún ló máa ń sọni dẹni ńlá, àmọ́ fífi ìfẹ́ lo ara ẹni fáwọn ẹlòmíràn lohun tó ń sọni dẹni ńlá. Wá bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Ká lémi ni Jákọ́bù tàbí Jòhánù, kí ni ǹ bá ṣe ná? Ṣé ì bá yé mi pé fífi ìfẹ́ lo ara ẹni fún àwọn ẹlòmíràn ló ń sọni dẹni ńlá?’—1 Kọ́ríńtì 13:3.
9. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nínú bó ṣe bá àwọn èèyàn lò?
9 Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ pé ohun tó ń mú kí aráyé ka ẹnì kan sẹ́ni ńlá yàtọ̀ sóhun tí Kristi fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀ pé ó ń sọni dẹni ńlá. Kì í hùwà sí àwọn tó ń lo ara rẹ̀ fún bíi pé òun sàn ju wọ́n lọ, bẹ́ẹ̀ ni kò mú kí wọ́n máa rò pé àwọn ò jẹ́ nǹkankan. Kò sẹ́ni tó máa wà lọ́dọ̀ Jésù tára ẹ̀ kì í balẹ̀, ì báà jẹ́ ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé, olówó, tálákà, àwọn alágbára títí kan àwọn tó ti jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá pàápàá. (Máàkù 10:13-16; Lúùkù 7:37-50) Àwọn èèyàn kì í sábà fẹ́ ṣe sùúrù fáwọn tó bá ní àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó kan. Àmọ́ ti Jésù yàtọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà mìíràn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ máa ń hùwà tó kù díẹ̀ káàtó, tí wọ́n sì máa ń ṣawuyewuye láàárín ara wọn, síbẹ̀ Jésù fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà, tó fi hàn pé lóòótọ́ ló lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti inú tútù.—Sekaráyà 9:9; Mátíù 11:29; Lúùkù 22:24-27.
10. Báwo lọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ látòkèdélẹ̀ ṣe fi hàn pé kò fẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ṣe ìránṣẹ́ fáwọn èèyàn?
10 Àpẹẹrẹ tí kò fẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan hàn tí Ọmọ Ọlọ́run tó gbawájú jù lọ yìí fi lélẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tí ipò ọlá túmọ̀ sí ní ti gidi. Kì í ṣe káwọn èèyàn lè máa lo ara wọn fún Jésù ló ṣe wá sáyé, àmọ́ tìtorí kó lè máa lo ara rẹ̀ fún àwọn èèyàn ló ṣe wá, ó ń wo “onírúurú àìsàn” sàn, ó sì ń gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ agbára ẹ̀mí èṣù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rẹ òun náà tó sì ní láti wá àyè fún ìsinmi, síbẹ̀ gbogbo ìgbà ló máa ń fi ire àwọn ẹlòmíì ṣáájú tirẹ̀ tó sì máa ń sapá gidigidi láti tù wọ́n nínú. (Máàkù 1:32-34; 6:30-34; Jòhánù 11:11, 17, 33) Ìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn ló mú kó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, kó sì máa gba ojú ọ̀nà eléruku lọ sáwọn ibi tó jìnnà réré láti lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. (Máàkù 1:38, 39) Láìsí àní-àní, Jésù ò fi ọ̀ràn ṣíṣe ìránṣẹ́ fáwọn èèyàn ṣeré.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Kristi
11. Àwọn ànímọ́ wo làwọn arákùnrin tá a yàn láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínu ìjọ gbọ́dọ̀ ní?
11 Níparí àwọn ọdún 1800, a sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa irú ẹ̀mí tó yẹ káwọn Kristẹni alábòójútó ní nígbà tá a yan àwọn aṣojú arìnrìn àjò tí yóò máa bójú tó ọ̀ràn àwọn èèyàn Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Zion’s Watch Tower ti September 1, 1894 sọ, àwọn tá à ń wá ni àwọn ọkùnrin “tó lọ́kàn tútù—tí wọn ò ní máa gbéra ga . . . , àmọ́ tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí wọn ò ní máa sọ̀rọ̀ ara wọn bí kò ṣe ti Kristi—tí wọn ò ní máa fi ìmọ̀ wọn ṣe fọ́ńté, àmọ́ tí wọ́n á máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni lédè tó tètè yéni tó sì máa lágbára lọ́kàn èèyàn.” Ní kedere, ìdí táwọn Kristẹni fi ń wá ẹrù iṣẹ́ kò yẹ kó jẹ́ nítorí ìlépa ara ẹni, àtidé ipò ọlá, àtidi gbajúmọ̀, àtiní agbára tàbí láti máa darí àwọn ẹlòmíràn. Alábòójútó tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ò ní gbàgbé pé “iṣẹ́ àtàtà” lòun ń ṣe, pé kì í ṣe pé òun wà ní ipò gíga kan tóun á máa fi fògo fún ara òun. (1 Tímótì 3:1, 2) Ó yẹ kí gbogbo alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sa gbogbo ipa wọn láti máa fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n máa mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́, kí wọ́n sì máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn míì láti tẹ̀ lé.—1 Kọ́ríńtì 9:19; Gálátíà 5:13; 2 Tímótì 4:5.
12. Àwọn ìbéèrè wo làwọn tó ń fẹ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ lè bi ara wọn?
12 Arákùnrin kan tó ń fẹ́ láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lè bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń wá ọ̀nà láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, àbí ńṣe ni mo máa ń fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe ìránṣẹ́ fún mí? Ǹjẹ́ mo ṣe tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó jọjú àmọ́ táwọn èèyàn ò ní tètè kíyè sí?’ Bí àpẹẹrẹ, ó lè yá ọ̀dọ́kùnrin kan lára láti fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí pèpéle nínú ìjọ Kristẹni àmọ́ kó máa lọ́ tìkọ̀ tó bá di pé kó ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́. Ó sì lè máa gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ, àmọ́ kó máà yá a lára láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ó yẹ kírú ọ̀dọ́kùnrin bẹ́ẹ̀ bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ apá tó ń mú kéèyàn gbayì nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìkan ni mo máa ń fẹ́ láti ṣe? Ṣé mò ń lépa láti gbayì lójú àwọn èèyàn ni?’ Tó bá jẹ́ pé ara wa là ń wá ògo fún, ó dájú pé kì í ṣe Jésù là ń fara wé.—Jòhánù 5:41.
13. (a) Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí alábòójútó kan bá fi hàn ṣe lè nípa lórí àwọn ẹlòmíì? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó jẹ́ ọ̀ranyàn fáwọn Kristẹni láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tàbí ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú?
13 Tá a bá sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Kristi, àá fẹ́ láti lo ara wa fáwọn ẹlòmíì. Wo àpẹẹrẹ alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá kan tó ń ṣàyẹ̀wò bí nǹkan ṣe ń lọ sí ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ alábòójútó yìí dí gan-an tó sì tún ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe, síbẹ̀ ó dúró láti ran arákùnrin ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ níbi tó ti ń gbìyànjú láti tún ẹ̀rọ ìdìwé kan tò kó lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Arákùnrin náà sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi! Ó sọ fún mi pé irú ẹ̀rọ tóun lò nìyẹn nígbà tóun wà lọ́dọ̀ọ́ ní Bẹ́tẹ́lì, ó lóun rántí bó ṣe ṣòro tó láti mú kí ẹ̀rọ náà máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Ó bá mi ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀rọ ìdìwé náà fúngbà díẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan pàtàkì mìíràn láti ṣe. Ohun tó ṣe yẹn jọ mi lójú gan-an ni.” Arákùnrin ọ̀dọ́ yìí tóun alára ti di alábòójútó ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì máa ń rántí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá yẹn lò lọ́jọ́ náà. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ronú pé a ti kọjá ẹni tó ń ṣiṣẹ́ rírẹlẹ̀ tàbí pé a ṣe pàtàkì ju ká máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Dípò ìyẹn, ńṣe ló yẹ ká fi “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú” di ara wa lámùrè. Àní, ọ̀ranyàn ni pé ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wà lára “àkópọ̀ ìwà tuntun” tí Kristẹni kan gbọ́dọ̀ fi wọ ara rẹ̀ láṣọ.—Fílípì 2:3; Kólósè 3:10, 12; Róòmù 12:16.
Bá A Ṣé Lé Ní Èrò Kristi Nípa Ipò Ọlá
14. Báwo ni ríronú nípa àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn ọmọnìkejì wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ̀nà nípa ipò ọlá?
14 Báwo la ṣe lè ní èrò tó tọ̀nà nípa ipò ọlá? Ọ̀nà kan ni pé ká máa ronú nípa àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Ọlá ńlá rẹ̀, agbára rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ mú kó wà nípò tó ju téèyàn lọ ní gbogbo ọ̀nà. (Aísáyà 40:22) Tá a bá tún ń ronú nípa àjọse tá a ní pẹ̀lú àwọn ọmọnìkejì wa, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a lè mọ àwọn nǹkan míì ṣe ju àwọn kan lọ, bẹ́ẹ̀ làwọn náà lè tún ta wá yọ láwọn apá kan tó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé, tàbí àwọn Kristẹni arákùnrin wa lè ní àwọn ànímọ́ kan táwa ò ní. Tá a bá ní ká sọ ọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ṣeyebíye lójú Ọlọ́run làwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀.—Òwe 3:34; Jákọ́bù 4:6.
15. Báwo ni ìwà títọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe fi hàn pé kò sídìí fún ẹnikẹ́ni láti máa rò pé òun sàn ju àwọn míì lọ?
15 Ìrírí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí ìgbàgbọ́ wọn gbé kókó yẹn yọ dáadáa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn táráyé kà sí gbáàtúù ló máa ń pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí Ọlọ́run nígbà àdánwò líle. Ríronú lórí irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì lè mú ká “má ṣe ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.”—Róòmù 12:3.b
16. Báwo ni gbogbo àwọn ará ìjọ ṣe lè dẹni ńlá nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀?
16 Ó yẹ kí gbogbo Kristẹni, àtọmọdé àtàgbà sapá láti ní èrò Kristi nípa ipò ọlá. Àwọn iṣẹ́ tó yẹ ṣíṣe nínú ìjọ pọ̀. Má ṣe bínú láé tí wọ́n bá ní kó o ṣe àwọn iṣẹ́ tó dà bíi pé ó rẹlẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 25:41; 2 Àwọn Ọba 3:11) Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ máa ń gba àwọn ọmọ yín kékeré àtàwọn tó wà lọ́dọ̀ọ́ níyànjú pé kí wọ́n máa fayọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá fún wọn ṣe, ì báà jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní gbọ̀ngàn àpéjọ? Ṣé wọ́n máa ń rí ẹ̀yin náà pé ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ rírẹlẹ̀? Arákùnrin kan tó ń sìn ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí rántí àpẹẹrẹ àwọn òbí rẹ̀ dáadáa. Arákùnrin náà sọ pé: “Ọwọ́ táwọn òbí mi fi mú iṣẹ́ ìmọ́tótó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní gbọ̀ngàn àpéjọ jẹ́ kí n mọ̀ pé iṣẹ́ ọ̀hún ṣe pàtàkì lójú wọn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó máa ṣe ìjọ tàbí ẹgbẹ́ àwọn ará láǹfààní, bó ti wù kí iṣẹ́ ọ̀hún rẹlẹ̀ tó. Ẹ̀mí táwọn òbí mi ní yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n yàn fún mi ní Bẹ́tẹ́lì tọkàntọkàn.”
17. Àwọn ọ̀nà wo làwọn obìnrin onírẹ̀lẹ̀ lè gbà jẹ́ ìbùkún fún ìjọ?
17 Ní ti ká fi ire àwọn ẹlòmíràn ṣáájú tara ẹni, àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì tayọ. Ó di ayaba Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Tiwa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ààfin ló ń gbé, síbẹ̀ obìnrin yìí ṣe tán láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nítorí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì ń ṣe èyí níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Ẹ́sítérì 1:5, 6; 4:14-16) Lónìí, láìka ipò táwọn Kristẹni obìnrin wà, àwọn náà lè fi irú ẹ̀mí tí Ẹ́sítérì ní hàn nípa títu àwọn tó ní ìdààmú ọkàn nínú, bíbẹ àwọn tó ń ṣàìsàn wò, kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti bíbá àwọn alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ẹ ò ri pé ìbùkún làwọn arábìnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ fún ìjọ!
Ìbùkún Tó Wà Nínú Níní Èrò Kristi Nípa Ipò Ọlá
18. Kí làwọn àǹfààní tó wà nínú níní irú èrò tí Kristi ní nípa ipò ọlá?
18 Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni wàá rí tó o bá ní èrò tí Kristi ní nípa ipò ọlá tó o sì ń báa lọ bẹ́ẹ̀. Tí kì í bá ṣe ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan lo fi ń lo ara rẹ fún àwọn ẹlòmíràn, àwọn tó ò ń lo ara re fún àti ìwọ alára yóò láyọ̀. (Ìṣe 20:35) Bó o ṣe múra tán lọ́jọ́kọ́jọ́ láti lo ara rẹ fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ tinútinú, wọ́n á túbọ̀ fẹ́ràn rẹ. (Ìṣe 20:37) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jèhófà ka ohun tó o bá ṣe láti fi gbọ́ táwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni sí ẹbọ ìyìn tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ òun.—Fílípì 2:17.
19. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa lórí èrò Kristi nípa ipò ọlá?
19 Ó yẹ kí olúkúlùkù wa yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa, ká sì bi ara wa léèrè pé: ‘Ṣé mo kàn ń sọ lẹ́nu lásán ni pé kéèyàn ní èrò Kristi nípa ipò ọlá àbí màá sapá láti máa fi ṣèwà hù?’ Èrò Jèhófà nípa àwọn agbéraga ṣe kedere. (Òwe 16:5; 1 Pétérù 5:5) Ǹjẹ́ kí ìwà àti ìṣe wa fi hàn pé inú wa dùn sí èrò Kristi nípa ipò ọlá, ì báà jẹ́ nínu ìjọ Kristẹni, nínu ìdílé wa, tàbí nínú àjọse wa pẹ̀lú àwọn èèyàn lójoojúmọ́, ká máa ṣe ohun gbogbo fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 10:31.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ninu Iwakiri Aṣeyọri” tó wà nínú Ile-Iṣọ Naa, November 1, 1982, ojú ìwé 3 sí 6.
b Bí àpẹẹrẹ, wo 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 181 àti 182, àti Ilé Ìṣọ́ ti September 1, 1993, ojú ìwé 27 sí 31.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fún èrò táráyé ní nípa ipò ọlá?
• Kí ni Jésù sọ pé ó ń sọni dẹni ńlá?
• Báwo làwọn alábòójútó ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Kristi ní?
• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti di irú ẹni ńlá tí Kristi fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lé lẹ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Ta Lẹni Tó Ní Èrò Tí Kristi Ní Nípa Ipò Ọlá?
Ṣé ẹni tó fẹ́ ká máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun ni àbí ẹni tó ṣe tán láti ṣe ìránṣẹ́ fáwọn ẹlòmíì?
Ṣé ẹni tó fẹ́ yọrí ọlá láwùjọ ni àbí ẹni tó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ rírẹlẹ̀?
Ṣé ẹni tó ń gbé ara rẹ̀ ga ni àbí ẹni tó ń gbé àwọn ẹlòmíì ga?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ère Pharaoh Amenhotep Kẹta tó rí gìrìwò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fá ìṣubú Hámánì?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ǹjẹ́ o máa ń wá ọ̀nà láti lo ara rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì?