Mímú Àwọn Ọjọ́ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Lórí Ilẹ̀ Ayé Wá sí Ìrántí
ỌJỌ́ keje, oṣù Nísàn ti àwọn Júù ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni. Fọkàn yàwòrán rẹ̀ pé o ń kíyè sí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ẹkùn Róòmù ti Jùdíà. Ní fífi Jẹ́ríkò àti ewéko tútù yọ̀yọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, Jésù Kristi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń fẹsẹ̀ rin ojú ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ kan, tí ó jẹ́ eléruku. Ọ̀pọ̀ arìnrìn àjò mìíràn pẹ̀lú ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù fún ayẹyẹ Ìrékọjá ọdọọdún. Ṣùgbọ́n, ohun tí ó wà lọ́kàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ju pípọ́n òkè tí ń kó àárẹ̀ báni yìí lọ.
Àwọn Júù ti ń yán hànhàn fún Mèsáyà tí ó lè tú wọn sílẹ̀ kúrò nínú àjàgà àwọn ará Róòmù. Ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé Jésù ará Násárétì ni Olùgbàlà náà, tí àwọn ti ń retí tipẹ́tipẹ́. Fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀, ó ti ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó ti mú àwọn aláìsàn lára dá, ó sì ti bọ́ àwọn tí ebi ń pa. Bẹ́ẹ̀ ni, ó ti tu àwọn ènìyàn nínú. Àmọ́ inú ń bí àwọn aṣáájú ìsìn gidigidi nítorí fífi tí Jésù fi wọ́n bú lọ́nà gbígbóná janjan, wọ́n sì ń wọ́nà lójú méjèèjì láti pa á. Síbẹ̀, òun kan náà ni ó ń rìn lọ kánmọ́kánmọ́ lójú ọ̀nà gbígbẹ táútáú yìí, níwájú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.—Máàkù 10:32.
Bí oòrùn ti ń wọ̀ lẹ́yìn Òkè Ólífì tí ó wà níwájú, Jésù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dé abúlé Bẹ́tánì, níbi tí wọn yóò ti sun oorun ọjọ́ mẹ́fà tí ó tẹ̀ lé e. Ọ̀rẹ́ wọn àtàtà, Lásárù, Màríà, àti Màtá, wà níbẹ̀ láti kí wọn káàbọ̀. Lẹ́yìn rírìnrìn àjò nínú oòrùn mímú hánhán náà, wíwọ̀ rẹ̀ mú kí ara wọn silẹ̀, ó sì sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ Sábáàtì ti Nísàn 8.—Jòhánù 12:1, 2.
Nísàn 9
Lẹ́yìn Sábáàtì náà, rọ̀tìrọ̀tì pọ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àlejò ti kóra jọ pọ̀ sínú ìlú náà fún Ìrékọjá. Ṣùgbọ́n ariwo ìkọlùkọgbà tí a ń gbọ́ ṣàjèjì ní àkókò yìí nínú ọdún. Àwọn èrò tí wọ́n fẹ́ ṣe ojúùmító ń wọ́ tìrítìrí lọ sí pópó tóóró tí ó lọ sí ẹnubodè ìlú náà. Bí wọ́n ti ń ti ara wọn láti lè gba ẹnubodè tí èrò kún fọ́fọ́ náà jáde, ohun tí wọ́n rí mà ga o! Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń yọ̀ ṣìnkìn ń sọ̀kalẹ̀ láti orí Òkè Ólífì bọ́ sí ojú ọ̀nà tí ó wá láti Bẹtifágè. (Lúùkù 19:37) Èwo ni gbogbo èyí?
Wò ó! Jésù ará Násárétì ní ń gun agódóńgbó bọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn tẹ́ aṣọ wọn sójú ọ̀nà níwájú rẹ̀. Àwọn mìíràn ń ju imọ̀ ọ̀pẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ́, wọ́n sì ń fi ìdùnnú kígbe pé: “Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà, àní ọba Ísírẹ́lì!”—Jòhánù 12:12-15.
Bí ogunlọ́gọ̀ náà ti ń sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, Jésù wo ìlú náà, àánú sì ṣe é. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, a sì gbọ́ tí ó ń sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò pa ìlú yìí run. Nígbà tí Jésù dé sí tẹ́ńpìlì, láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó kọ́ ogunlọ́gọ̀ náà lẹ́kọ̀ọ́, ó la ojú afọ́jú, ó sì mú àwọn amúkùn-ún tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ lára dá.—Mátíù 21:14; Lúùkù 19:41-44, 47.
Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé kò ṣàì kíyè sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Inú mà bí wọn gan-an o láti rí àwọn ohun àgbàyanu tí Jésù ṣe àti bí ogunlọ́gọ̀ náà ṣe ń yọ̀ ṣìnkìn! Láìlè pa ìbínú wọn mọ́ra, àwọn Farisí pàṣẹ pé: “Olùkọ́, bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ wí lọ́nà mímúná.” Jésù fèsì pé: “Mo sọ fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá dákẹ́, àwọn òkúta yóò ké jáde.” Kí ó tó kúrò níbẹ̀, Jésù kíyè sí ìgbòkègbodò kátàkárà tí ń lọ lọ́wọ́ nínú tẹ́ńpìlì.—Lúùkù 19:39, 40; Mátíù 21:15, 16; Máàkù 11:11.
Nísàn 10
Jésù tètè dé sí tẹ́ńpìlì. Lánàá, sísọ tí wọ́n sọ ìjọsìn Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run, di òwò tí ó hàn gbangba mú kí ìbínú rẹ̀ ru sókè. Nítorí náà, pẹ̀lú ìtara ńláǹlà, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo àwọn tí ń tà àti àwọn tí ń rà nínú tẹ́ńpìlì náà síta. Lẹ́yìn náà, ó sojú tábìlì àwọn oníwọra olùpààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tí ń ta àdàbà. Jésù kígbe pé: “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà,’ ṣùgbọ́n ẹ ń sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.”—Mátíù 21:12, 13.
Àwọn olórí àlùfáà, àwọn akọ̀wé, àti àwọn sàràkí-sàràkí kórìíra ìgbésẹ̀ Jésù àti ìkọ́ni rẹ̀ ní gbangba. Ẹ wo bí wọ́n ti ń hára gàgà tó láti pa á! Ṣùgbọ́n ogunlọ́gọ̀ náà dí wọn lọ́wọ́ nítorí pé háà ṣe àwọn ènìyàn náà sí ẹ̀kọ́ Jésù, wọ́n sì “ń rọ̀ mọ́ ọn ṣáá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.” (Lúùkù 19:47, 48) Nígbà tí ó ń dọwọ́ alẹ́, Jésù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ rin ìrìn fàájì padà sí Bẹ́tánì láti gbádùn orun alẹ́ atunilára.
Nísàn 11
Òwúrọ̀ kùtùkùtù ni, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ti ń kọjá Òkè Ólífì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Bí wọ́n ti dé sí tẹ́ńpìlì náà, kíá ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin ko Jésù lójú. Wọ́n ṣì ń rántí ohun tí ó ṣe sí àwọn olùpààrọ̀ owó àti oníṣòwò nínú tẹ́ńpìlì dáadáa. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ fi ìkórìíra béèrè pé: “Ọlá àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ta ní sì fún ọ ní ọlá àṣẹ yìí?” Jésù náà fèsì pé: “Dájúdájú, èmi, pẹ̀lú, yóò béèrè ohun kan lọ́wọ́ yín. Bí ẹ bá sọ ọ́ fún mi, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín: Ìbatisí láti ọwọ́ Jòhánù, láti orísun wo ni ó ti wá? Ṣé láti ọ̀run ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?” Àwọn alátakò náà forí korí, wọ́n sì ronú pé: “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ yóò sọ fún wa pé, ‘Èé ṣe, nígbà náà, tí ẹ kò gbà á gbọ́?’ Ṣùgbọ́n, bí àwa bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ ẹ̀rù ogunlọ́gọ̀ yìí ń bà wá, nítorí gbogbo wọn ka Jòhánù sí wòlíì.” Nítorí tí ọkàn wọ́n dàrú, wọ́n fèsì bí ẹni tí àárẹ̀ mú pé: “Àwa kò mọ̀.” Jésù fèsì lọ́nà pẹ̀lẹ́ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.”—Mátíù 21:23-27.
Wàyí o, àwọn ọ̀tá Jésù ń gbìyànjú láti dẹ pańpẹ́ fún un kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n lè fàṣẹ ọba mú un lé lórí. Wọ́n béèrè pé: “Ó ha bófin mu láti san owó orí fún Késárì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Jésù fèsì pé: “Ẹ fi ẹyọ owó ti owó orí hàn mí.” Ó béèrè pé: “Àwòrán àti àkọlé ta ni èyí?” Wọ́n fèsì pé: “Ti Késárì.” Ní mímú kí ọkàn wọn pòrúurùu, Jésù sọ ní kedere létígbọ̀ọ́ gbogbo ènìyàn pé: “Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Mátíù 22:15-22.
Lẹ́yìn tí ó ti fi ìjiyàn tí kò ṣeé já ní koro pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ lẹ́nu mọ́, wàyí, Jésù wá ń sọ òkò ọ̀rọ̀ sí wọn níwájú ogunlọ́gọ̀ náà àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Fetí sí bí ó ṣe ń fi àìṣojo fi àwọn akọ̀wé àti Farisí bú. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣe wọn, nítorí wọn a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe.” Tìgboyàtìgboyà, ó ké ọ̀wọ́ àwọn ègbé lé wọn lórí, ó fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú afinimọ̀nà àti alágàbàgebè. Jésù sọ pé: “Ẹ̀yin ejò, ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ ó ṣe sá kúrò nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà?”—Mátíù 23:1-33.
Àwọn ìfibú gbígbóná janjan wọ̀nyí kò túmọ̀ sí pé Jésù kò rí àwọn ànímọ́ rere tí àwọn ẹlòmíràn ní. Lẹ́yìn náà, ó rí àwọn ènìyàn tí ń ju owó sínú àwọn àpótí ìṣúra tí ó wà nínú tẹ́ńpìlì. Ẹ wo bí ó ti wúni lórí tó láti rí opó aláìní kan tí ń ju gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé rẹ̀—ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an—sínú àpótí! Pẹ̀lú ìmọrírì jíjinlẹ̀, Jésù tọ́ka sí i pé, ní ti gidi, ohun tí obìnrin náà sọ sínú àpótí ju ti gbogbo àwọn tí wọ́n ti ṣètọrẹ ńlá “láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn” lọ. Nínú ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀, Jésù ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún ohunkóhun tí ẹnì kan bá lè ṣe.—Lúùkù 21:1-4.
Jésù ń fi tẹ́ńpìlì sílẹ̀ nísinsìnyí fún ìgbà ìkẹyìn. Àwọn kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ nípa bí ó ti jẹ́ ilé tí ó bùáyà tó, pé a “ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn òkúta àtàtà àti àwọn ohun tí a yà sí mímọ́.” Sí ìyàlẹ́nu wọn, Jésù fèsì pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé nínú èyí tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín, tí a kì yóò wó palẹ̀.” (Lúùkù 21:5, 6) Bí àwọn àpọ́sítélì ṣe tẹ̀ lé Jésù jáde kúrò nínú ìlú tí ó kún fọ́fọ́ náà, wọ́n ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ó ní lọ́kàn.
Tóò, nígbà tí ó ṣe díẹ̀ sí i, Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jókòó, wọ́n sì gbádùn àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ orí Òkè Ólífì. Bí wọ́n ti ń wo ìran fífanimọ́ra ti Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù, àti Áńdérù fẹ́ kí Jésù túbọ̀ là wọ́n lóye nípa àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó múni gbọ̀n rìrì. Wọ́n sọ pé: “Sọ fún wa, Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”—Mátíù 24:3; Máàkù 13:3, 4.
Ní ìfèsìpadà, Ọ̀gá Olùkọ́ náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti gidi. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ogun gbígbóná janjan, ìsẹ̀lẹ̀, àìtó oúnjẹ, àti àjàkálẹ̀ àrùn. Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò wàásù ìhìn rere Ìjọba náà jákèjádò ilẹ̀ ayé. Ó kìlọ̀ pé: “Nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.”—Mátíù 24:7, 14, 21; Lúùkù 21:10, 11.
Àwọn àpọ́sítélì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí Jésù ti ń jíròrò àwọn apá mìíràn ti ‘àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀.’ Ó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ‘bíbá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.’ Èé ṣe? Ó sọ pé: “Nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.”—Mátíù 24:42; Máàkù 13:33, 35, 37.
Èyí jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé kan fún Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ní ti gidi, ó jẹ́ ọjọ́ tí ó kẹ́yìn tí Jésù lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba kí a tó fàṣẹ ọba mú un, kí ó tó jẹ́jọ́, kí a sì tó pa á. Nítorí pé ilẹ̀ ti ń ṣú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fẹsẹ̀ rìn bọ̀ láti orí òkè náà tí kò jìnnà sí Bẹ́tánì.
Nísàn 12 àti 13
Jésù lo Nísàn 12 pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan. Ó mọ̀ pé àwọn aṣáájú ìsìn ti ń wọ́nà lójú méjèèjì láti pa òun, kò sì fẹ́ kí wọ́n dí ayẹyẹ Ìrékọjá tí òun fẹ́ ṣe ní alẹ́ ọjọ́ kejì lọ́wọ́. (Máàkù 14:1, 2) Ní ọjọ́ kejì, Nísàn 13, ọwọ́ àwọn ènìyàn dí fún ṣíṣètò ìkẹyìn ní ìmúrasílẹ̀ fún Ìrékọjá. Kí ọ̀sán tó pọ́n gan-an, Jésù rán Pétérù àti Jòhánù láti múra Ìrékọjá sílẹ̀ fún wọn nínú iyàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. (Máàkù 14:12-16; Lúùkù 22:8) Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí oòrùn wọ̀, Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mẹ́wàá yòókù dara pọ̀ mọ́ wọn níbẹ̀ fún ayẹyẹ Ìrékọjá àṣekẹ́yìn.
Nísàn 14, Lẹ́yìn Tí Oòrùn Wọ̀
Ìmọ́lẹ̀ alẹ́ yẹ́ríyẹ́rí mọ́lẹ̀ sórí Jerúsálẹ́mù bí òṣùpá àrànmọ́jú ti yọ lórí Òkè Ólífì. Nínú iyàrá ńlá kan tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ dáradára, Jésù àti àwọn 12 nì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì tí a ṣètò. Ó wí pé: “Mo ti fẹ́ gidigidi láti jẹ ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà.” (Lúùkù 22:14, 15) Nígbà tí ó ṣe, ẹnu ya àwọn àpọ́sítélì láti rí Jésù tí ó dìde, tí ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lélẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ó mú aṣọ ìnura, ó gbé bàsíà omi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ ẹsẹ̀ wọn. Ẹ̀kọ́ ńlá tí kò ṣeé gbàgbé nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni èyí mà jẹ́ o!—Jòhánù 13:2-15.
Ṣùgbọ́n, Jésù mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí—Júdásì Ísíkáríótù—ti ṣètò láti fi òun lé àwọn aṣáájú ìsìn lọ́wọ́. Lọ́nà tí ó yéni, ìdààmú bá a. Ó ṣí i payá pé: “Ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.” Èyí mú ẹ̀dùn-ọkàn bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ gidigidi. (Mátíù 26:21, 22) Lẹ́yìn ṣíṣayẹyẹ Ìrékọjá, Jésù sọ fún Júdásì pé: “Ohun tí ìwọ ń ṣe túbọ̀ ṣe é kíákíá.”—Jòhánù 13:27.
Gbàrà tí Júdásì ti lọ, Jésù gbé oúnjẹ kan kalẹ̀ láti ṣayẹyẹ ikú rẹ̀ tí ń bọ̀. Ó mú ìṣù búrẹ́dì tí a kò fi ìwúkàrà sí, ó gbàdúrà ìdúpẹ́ sí i, ó bù ú, ó sì ní kí àwọn 11 náà jẹ nínú rẹ̀. Ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Lẹ́yìn náà, ó mú ife wáìnì pupa. Lẹ́yìn gbígbàdúrà sí i, ó gbé ife náà fún wọn, ó sọ pé kí wọ́n mu nínú rẹ̀. Jésù fi kún un pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.”—Lúùkù 22:19, 20; Mátíù 26:26-28.
Ní alẹ́ mánigbàgbé yẹn, Jésù kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olùṣòtítọ́ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì, ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí ni ìjẹ́pàtàkì ìfẹ́ ará. (Jòhánù 13:34, 35) Ó mú un dá wọn lójú pé wọn yóò gba “olùrànlọ́wọ́,” ìyẹn ni ẹ̀mí mímọ́. Yóò mú kí wọ́n rántí gbogbo ohun tí ó ti sọ fún wọn. (Jòhánù 14:26) Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ yẹn, àdúrà onítara tí Jésù gbà fún wọn ti ní láti fún wọn níṣìírí. (Jòhánù, orí 17) Lẹ́yìn kíkọ orin ìyìn, wọ́n fi iyàrá òkè sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù lọ síta, sínú atẹ́gùn alẹ́ tí ó tutù.
Ní ríré Àfonífojì Kídírónì kọjá, Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ forí lé ọ̀kan nínú àwọn ibi tí wọ́n yàn láàyò jù lọ, ọgbà Gẹtisémánì. (Jòhánù 18:1, 2) Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń dúró, Jésù rìn síwájú díẹ̀ láti lọ gbàdúrà. Másùnmáwo tí ìmọ̀lára rẹ̀ mú bá a kò ṣeé fẹnu sọ bí ó ti ń fi taratara bẹ Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́. (Lúùkù 22:44) Ìrònú ẹ̀gàn tí yóò bá Bàbá rẹ̀ ọ̀wọ́n tí ń bẹ ní ọ̀run, bí òun bá kùnà, ń kó ìrora bá a dé góńgó.
Jésù kò tíì gbàdúrà tán nígbà tí Júdásì Ísíkáríótù dé pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n mú idà, kùmọ̀, àti òtùfù dání. Ní fífẹnu ko Jésù lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, Júdásì sọ pé: “Kú déédéé ìwòyí o, Rábì!” Èyí ni àmì fún àwọn ọkùnrin tí ó fẹ́ fàṣẹ ọba mú Jésù. Lójijì, Pétérù fa idà rẹ̀ yọ, ó sì gé etí ẹrú àlùfáà àgbà dànù. Bí Jésù ti ń lẹ etí ọkùnrin náà padà, ó wí pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.”—Mátíù 26:47-52.
Gbogbo rẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ kíákíá! A ti fàṣẹ ọba mú Jésù, a sì ti dè é. Nínú ìbẹ̀rù àti ìdàrúdàpọ̀, àwọn àpọ́sítélì fi Ọ̀gá wọn sílẹ̀, wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ. A mú Jésù lọ sí ọ̀dọ̀ Ánásì, àlùfáà àgbà tẹ́lẹ̀ rí. Lẹ́yìn náà, a mú un lọ sọ́dọ̀ Káyáfà, àlùfáà àgbà lọ́ọ́lọ́ọ́, láti gbẹ́jọ́ rẹ̀. Ní ìdájí, Sànhẹ́dírìn fi ẹ̀sùn èké pé ó sọ̀rọ̀ òdì kan Jésù. Lẹ́yìn èyí, Káyáfà pàṣẹ pé kí a mú un lọ sọ́dọ̀ gómìnà Róòmù náà, Pọ́ńtíù Pílátù. Pílátù ní kí a mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù Áńtípà, olùṣàkóso Gálílì. Hẹ́rọ́dù àti àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ fi Jésù ṣẹlẹ́yà. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún mú un padà lọ sọ́dọ̀ Pílátù. Pílátù jẹ́rìí sí àìmọwọ́mẹsẹ̀ Jésù. Ṣùgbọ́n àwọn aṣáájú ìsìn Júù fipá mú un láti dájọ́ ikú fún Jésù. Lẹ́yìn tí wọ́n ti bú Jésù gan-an, tí wọ́n sì lù ú, wọ́n mú Jésù lọ sí Gọ́gọ́tà, níbi tí wọ́n ti fi ìwà ìkà kàn án mọ́ igi oró, tí ó sì kú ikú onírora gógó.—Máàkù 14:50–15:39; Lúùkù 23:4-25.
Ká ní ikú Jésù ti mú òpin pátápátá bá ìwàláàyè rẹ̀ ni, ì bá ti jẹ́ ọ̀ràn tí ó bani nínú jẹ́ jù lọ nínú ìtàn. Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Ní Nísàn 16, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ẹnu ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti rí i pé a ti jí i dìde kúrò nínú òkú. Bí àkókò ti ń lọ, ó ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn tí ó lé ní 500 láti jẹ́rìí sí i pé Jésù wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní 40 ọjọ́ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, àwùjọ àwọn olùṣòtítọ́ ọmọlẹ́yìn kan rí i tí ń gòkè re ọ̀run.—Ìṣe 1:9-11; 1 Kọ́ríńtì 15:3-8.
Ìgbésí Ayé Jésù àti Ìwọ
Ipa wo ni èyí ní lórí rẹ—ní tòótọ́, lórí gbogbo wa? Tóò, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ikú rẹ̀, àti àjíǹde rẹ̀ gbé Jèhófà Ọlọ́run ga, wọ́n sì ṣe pàtàkì sí ìmúṣẹ ète Rẹ̀ títóbilọ́lá. (Kólósè 1:18-20) Wọ́n ṣe pàtàkì gidi fún wa ní ti pé, a lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù, a sì lè tipa báyìí ní ipò ìbátan ara ẹni pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run.—Jòhánù 14:6; 1 Jòhánù 2:1, 2.
Àní ó nípa lórí àwọn aráyé tí ó ti kú pàápàá. Àjíǹde Jésù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún mímú wọn padà wá sí ìyè nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ti ṣèlérí. (Lúùkù 23:39-43; 1 Kọ́ríńtì 15:20-22) Bí o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, a ké sí ọ láti wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi tí yóò wáyé ní April 11, 1998, ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ní àgbègbè rẹ.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
“Hòrò Àwọn Ọlọ́ṣà”
JÉSÙ ní ìdí púpọ̀ láti sọ pé àwọn oníwọra oníṣòwò ti sọ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.” (Mátíù 21:12, 13) Láti san owó orí tẹ́ńpìlì, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe láti ilẹ̀ mìíràn ní láti pààrọ̀ owó ilẹ̀ òkèèrè tí ó wà lọ́wọ́ wọn sí owó tí wọ́n lè ná. Nínú ìwé rẹ̀, The Life and Times of Jesus the Messiah, Alfred Edersheim ṣàlàyé pé àwọn olùpààrọ̀ owó máa ń gbé òwò wọn kalẹ̀ ní àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ ní Adar 15, oṣù kan ṣáájú Ìrékọjá. Tí ó bá di Adar 25, wọn yóò lọ sí àgbègbè tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù láti kó àwọn Júù àti aláwọ̀ṣe tí ń rọ́ wọ̀lú nífà. Òwò àwọn oníṣòwò náà ń búrẹ́kẹ gan-an, wọ́n ń bu iye kan pàtó lé owó tí wọ́n bá pààrọ̀. Títọ́ka tí Jésù tọ́ka sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọlọ́ṣà fi hàn pé iye tí wọ́n ń bù pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé, a lè sọ pé ṣe ni wọ́n ń lọ́ àwọn òtòṣì lọ́wọ́ gbà.
Àwọn kan kò lè mú ẹran tí wọn yóò fi rúbọ wá. Ẹni tí ó bá sì rí tirẹ̀ mú wá ní láti jẹ́ kí olùṣàyẹ̀wò tẹ́ńpìlì yẹ ẹran náà wò—yóò sanwó àyẹ̀wò náà. Ọ̀pọ̀ ń tọ àwọn oníṣòwò elérè àjẹpajúdé tí wọ́n wà nínú tẹ́ńpìlì lọ láti ra ẹran, tí àwọn ọmọ Léfì “ti fọwọ́ sí,” nítorí tí wọn kò fẹ́ fi ara wọn wewu ti pé kí a kọ ẹran kan tí a mú ti ọ̀nà jínjìn wá. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “A ń rẹ́ ọ̀pọ̀ mẹ̀kúnnù jẹ dáadáa níbẹ̀.”
Ẹ̀rí wà pé Ánásì, àlùfáà àgbà nígbà kan rí, àti ìdílé rẹ̀ ń rí èrè tiwọn lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò tẹ́ńpìlì. Àwọn àkọsílẹ̀ rábì sọ nípa “títà tí àwọn ọmọ Ánásì ń ta ọjà Bàsá nínú [tẹ́ńpìlì].” Ọ̀kan nínú olórí Ibi tí owó ti ń wọlé fún wọn ni èyí tí wọ́n ń rí láti ọ̀dọ̀ àwọn olùpààrọ̀ owó àti èyí tí wọ́n ń rí lórí ẹran títà nínú tẹ́ńpìlì. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé lílé tí Jésù lé àwọn oníṣòwò jáde “kì í ṣe láti dín iyì àwọn àlùfáà kù nìkan, ṣùgbọ́n, láti dín owó tí ń wọnú àpò wọn kù pẹ̀lú.” Ohun yòówù tí ì báà jẹ́, ó dájú ṣáká pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ fẹ́ pa á!—Lúùkù 19:45-48.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn Ọjọ́ Tí Ó Kẹ́yìn Ìgbésí Ayé Jésù Gẹ́gẹ́ Bí Ẹ̀dá Ènìyàn
Nísàn 33 C.E. Ìṣẹ̀lẹ̀ Ọkùnrin Títóbilọ́lá Jùlọ*
7 Friday Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn 101 ìpínrọ̀ 1
rẹ̀ rìnrìn àjò láti
Jẹ́ríkò lọ sí
Jerúsálẹ́mù (Nísàn 7 bọ́
sí Sunday, April 5,
1998, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn
Hébérù máa ń ka ọjọ́ tiwọn
láti ìrọ̀lẹ́ kan sí èkejì)
8 Ìrọ̀lẹ́ Friday Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ 101, ìpínrọ̀ 2
dé sí Bẹ́tánì; Sábáàtì bẹ̀rẹ̀ sí 4
Saturday Sábáàtì (Monday, 101, ìpínrọ̀ 4
April 6, 1998)
9 Ìrọ̀lẹ́ Saturday Wọ́n jẹun pẹ̀lú Símónì adẹ́tẹ̀; 101, ìpínrọ̀ 5
Màríà tú náádì sí Jésù lára; sí 9
ọ̀pọ̀ ti Jerúsálẹ́mù wá láti rí
Jésù, kí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀
Sunday Fífi ayọ̀ ìṣẹ́gun wọnú Jerúsálẹ́mù; 102
ó kọ́ni ní tẹ́ńpìlì
10 Monday Ìrìn àjò òwúrọ̀ kùtù sí 103, 104
Jerúsálẹ́mù; ó fọ tẹ́ńpìlì mọ́;
Jèhófà sọ̀rọ̀ láti ọ̀run
11 Tuesday Ní Jerúsálẹ́mù, ó kọ́ni ní 105 sí 112,
tẹ́ńpìlì ní lílo àkàwé; ó dẹ́bi ìpínrọ̀ 1
fún àwon Farisí; ó kíyè sí ọrẹ
opó kan; ó fúnni ní àmì
wíwàníhìn-ín rẹ̀ ọjọ́ ọla
12 Wednesday Ọjọ́ tí ó lò pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn 112, ìpínrọ́ 2
rẹ̀ nìkan ní Bẹ́tánì; Júdásì gbìmọ̀ sí 4
bí yóò ti dà á
13 Thursday Pétérù àti Jòhánù múra sílẹ̀ fún 112, ìpínrọ̀ 5
Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù; Jésù 113, ìpínrọ̀ 1
àti sí àwọn àpọ́sítélì mẹ́wàá
yòókù dara pọ̀ mọ́ wọn ní ìrọ̀lẹ́
(Saturday, April 11,1998)
14 Ìrọ̀lẹ́ Ayẹyẹ Ìrékọjá; Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn 113, ìpínrọ̀ 2
Thursday àpọ́sítélì rẹ̀; Júdásì jáde lọ sí 117
láti da Jésù; Kristi dá Ìṣe
Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ (Lẹ́yìn tí
oòrùn bá wọ̀, ní Saturday,
April 11, 1998)
Lẹ́yìn ọ̀gànjọ́ A dà á, a sì fàṣẹ ọba mú un 118 sí 120
òru ní ọgbà Gẹtisémánì; àwọn
àpọ́sítélì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ; ìgbẹ́jọ́
nìwájú àwọn olórí àlùfáà àtì
Sànhẹ́dírìn; Pétérù sẹ́ Jésù
Friday ìgbà Níwájú Sànhẹ́dírìn lẹ́ẹ̀kan sí i; 121 sí 127
tí oòrùn yọ sọ́dọ̀ Pílátù, lẹ́yìn náà sọ́dọ̀ ìpínrọ̀ 7
títí di Hẹ́rọ́dù, lẹ́yìn náà padà sọ́dọ̀
ìgba tí Pílátù; a dájọ́ ikú fún un;
oòrùn wọ̀ a kàn án mọ́gi; a sin ín
15 Saturday Sábáàtì; Pílátù gbà kí àwọn ẹ̀ṣọ́ 127, ìpínrọ̀
máa ṣọ́ ibojì Jésù 8 sí 10
16 Sunday A jí Jésù dìde 128
* Àwọn nọ́ńbà tí ń tọ́ka sí àwọn àkòrí inú ìwé náà, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, ni a kọ síhìn-ín. Fún ṣáàtì tí ó ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtọ́kasí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tí ó kẹ́yìn, wo “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” ojú ìwé 290. Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ni ó tẹ àwọn ìwé wọ̀nyí jáde.