ORÍ KẸWÀÁ
“A Ti Kọ Ọ́ Pé”
1-3. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jésù fẹ́ káwọn ará ìlú Násárétì kọ́, ẹ̀rí wo ló sì fún wọn?
ÌBẸ̀RẸ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀. Kristi ti padà sí Násárétì, ìyẹn ìlú tí wọ́n ti bí i. Ó lọ síbẹ̀ láti mú káwọn èèyàn mọ ohun pàtàkì kan: Pé òun ni Mèsáyà náà tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ látọjọ́ tó pẹ́! Ẹ̀rí wo ló fún wọn?
2 Ó dájú pé ohun tí ọ̀pọ̀ á máa retí ni pé kó ṣiṣẹ́ ìyanu kan. Wọ́n ti gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ àmì tó ń ṣeni ní kàyéfì tí Jésù ti ṣe. Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, kò fún wọn nírú àmì yẹn. Dípò ìyẹn, inú sínágọ́gù ló gbà lọ bí ìṣe rẹ̀. Ó dìde dúró láti kàwé, wọ́n sì fi àkájọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà lé e lọ́wọ́. Àkájọ ìwé tó gùn gan-an ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ká a mọ́ igi méjì. Jésù sì fara balẹ̀ ká àkájọ náà látara igi kìíní sára igi kejì títí tó fi rí ẹsẹ tó ń wá. Lẹ́yìn náà ló wá ka ibì kan sókè ketekete. Ibi tó kà yẹn la wá mọ̀ lónìí sí Aísáyà 61:1-3.—Lúùkù 4:16-19.
3 Àwọn tó wà níbẹ̀ yẹn mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó kà yẹn dáadáa. Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Mèsáyà ni. Ńṣe ni gbogbo àwọn tó wà nínú sínágọ́gù da ojú bò ó, tí kẹ́kẹ́ sì pa. Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé, ó ṣeé ṣe kó tiẹ̀ ṣe àwọn àlàyé kan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ó ní: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ.” Ẹnu yà wọ́n torí ọ̀rọ̀ alárinrin tó ń jáde látẹnu rẹ̀, àmọ́ ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ ló ṣì ń fẹ́ kó ṣe iṣẹ́ àmì kan lójú wọn. Dípò tí Jésù ì bá sì fi ṣiṣẹ́ ìyanu, tìgboyà tìgboyà ló fi lo àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́ láti tú àṣírí àìnígbàgbọ́ wọn. Láìpẹ́ sígbà náà, àwọn ará Násárétì gbìyànjú láti pa á!—Lúùkù 4:20-30.
4. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, kí la sì máa jíròrò ní orí yìí?
4 Nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jésù fi àpẹẹrẹ kan lélẹ̀, èyí tó dúró lé lórí títí tó fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ìyẹn ni pé orí Ìwé Mímọ́ ni ìpìlẹ̀ tó lágbára tó gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà. Òótọ́ ni pé ipa kékeré kọ́ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe máa ń kó nínú jíjẹ́ káwọn èèyàn rí i pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀. Síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ ni Jésù kà sí pàtàkì jù lọ. Ẹ jẹ́ ká wá gbé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ lórí kókó yìí yẹ̀ wò. A máa jíròrò bí Ọ̀gá wa ṣe máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bó ṣe ń gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti bó ṣe ń ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Bó Ṣe Máa Ń Fa Ọ̀rọ̀ Yọ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
5. Kí ni Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀, ọ̀nà wo ló sì gbà fi hàn pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tóun ń sọ?
5 Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ ibi tóun ti ń rí ọ̀rọ̀ tóun ń sọ. Ó ní: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Lákòókò míì, ó ní: “Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” (Jòhánù 8:28) Ìgbà kan tún wà tó sọ pé: “Àwọn nǹkan tí mo ń sọ fún yín ni èmi kò sọ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n Baba tí ó dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 14:10) Ọ̀nà kan tí Jésù gbà fi hàn pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn ni bó ṣe máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọọ́lẹ̀ lemọ́lemọ́.
6, 7. (a) Báwo ni Jésù ṣe máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ tó látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kí sì nìdí tí èyí fi wú wa lórí? (b) Ọ̀nà wo ni ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni gbà yàtọ̀ sí tàwọn akọ̀wé òfin?
6 Nígbà tá a fara balẹ̀ wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tó wà nínú Bíbélì, a rí i pé ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú èyí tó ju ìdajì lọ lára àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó fa àwọn kan yọ ní tààràtà, ó sì tọ́ka sáwọn míì. O lè máa rò pé ìyẹn kì í ṣe nǹkan bàbàrà. O lè máa ronú nípa ìdí tí kì í fi í ṣe inú gbogbo ìwé tó para pọ̀ di Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló ti fa ọ̀rọ̀ yọ ní gbogbo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi wàásù tó sì kọ́ àwọn èèyàn ní gbàngba. Àmọ́ tá a bá wò ó dáadáa, àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé látinú gbogbo ìwé náà ló ti fa ọ̀rọ̀ yọ. Má gbàgbé pé díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ àtohun tó ṣe ni wọ́n kọ sílẹ̀. (Jòhánù 21:25) Ká sòótọ́, tó o bá ka gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tí wọ́n kọ sílẹ̀, ó lè má gbà ọ́ ju wákàtí mélòó kan lọ. Kó o fi lè mọ̀ pé ibi tí Jésù fà yọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò kéré, jẹ́ ká gbà pé ò ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ fún ìwọ̀nba wákàtí bíi mélòó kan, tó o sì wá gbìyànjú láti tọ́ka sí iye tó ju ìdajì lọ lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù lẹ́nu ìwọ̀nba àkókò kéréje yẹn, ṣéyẹn ò pọ̀ tó? Ohun tó mú kí ohun tí Jésù ṣe túbọ̀ wúni lórí ni pé kò ní àkájọ ìwé wọ̀nyẹn lọ́wọ́. Ìgbà tó ń ṣe ìwàásù tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Ìwàásù Lórí Òkè, àìmọye ìtọ́ka ló ṣe sínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, yálà ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ láti orí wá!
7 Bí Jésù ṣe ń fa àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ yọ fi hàn pé ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ ló ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ńṣe ni “háà sì ṣe wọ́n [ìyẹn àwọn olùgbọ́ rẹ̀] sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, nítorí pé níbẹ̀, ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní ọlá àṣẹ, kì í sì í ṣe bí àwọn akọ̀wé òfin.” (Máàkù 1:22) Báwọn akọ̀wé òfin bá ń kọ́ni, ó ti mọ́ wọn lára láti máa tọ́ka sí ohun táwọn èèyàn ń pè ní òfin àtẹnudẹ́nu, wọ́n a máa fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ọ̀rọ̀ táwọn rábì ti sọ nígbà kan rí. Jésù ò bá wọn tọ́ka sí àwọn òfin àtẹnudẹ́nu bẹ́ẹ̀ rí, kò sì bá wọn gba ọ̀rọ̀ rábì èyíkéyìí sọ. Dípò ìyẹn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló kà sí ohun tí abẹ gé. Léraléra ló máa ń sọ pé: “A ti kọ ọ́ pé,” tàbí kó sọ gbólóhùn tó jọ ọ́ láti fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àti láti fi tọ́ wọn sọ́nà.
8, 9. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé àṣẹ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lòun ń tẹ̀ lé nígbà tó fọ tẹ́ńpìlì mọ́? (b) Lọ́nà wo làwọn aṣáájú ìsìn tó wà ní tẹ́ńpìlì gbà tàbùkù tó lé kenkà sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
8 Nígbà tí Jésù ń lé àwọn tó ń ṣòwò nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù jáde, ó ní: “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà,’ ṣùgbọ́n ẹ ń sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.” (Mátíù 21:12, 13; Aísáyà 56:7; Jeremáyà 7:11) Ní ọjọ́ tó ṣáájú èyí, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àrà ló gbé ṣe níbẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin kéékèèké tí inú wọ́n dùn sí ohun tó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í yìn ín. Àmọ́ ńṣe làwọn aṣáájú ìsìn tí inú wọn ń ru ṣùù ń bi Jésù bó bá gbọ́ ohun táwọn ọmọ yẹn ń sọ. Ó dá wọn lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ẹ kò tíì ka èyí rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde’?” (Mátíù 21:16; Sáàmù 8:2) Jésù fẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fọwọ́ sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn.
9 Nígbà tó yá, àwọn aṣáájú ìsìn yẹn wá pé jọ láti ko Jésù lójú, wọ́n ń bi í pé: “Ọlá àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?” (Mátíù 21:23) Jésù ti fún wọn ní ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti jẹ́ kí wọ́n mọ Orísun àṣẹ tó ń lò. Ẹ̀kọ́ tuntun kọ́ ló ń kọ́ wọn, kò sì kọ́ wọn pé kí wọ́n gba ohun tuntun gbọ́. Ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ tí Bàbá rẹ̀ mí sí ló kàn ń tẹ̀ lé. Nítorí náà, a wá lè rí i pé ńṣe làwọn àlùfáà àtàwọn akọ̀wé òfin yẹn ń tàbùkù tó lé kenkà sí Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó tọ́ sí wọn gan-an pé kí Jésù kàn wọ́n lábùkù, nítorí búburú ọkàn wọn.—Mátíù 21:23-46.
10. Ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bó ṣe lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn nǹkan wo sì ni Jésù ò ní lákòókò tiẹ̀?
10 Bíi ti Jésù, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwọn Kristẹni tòótọ́ òde òní gbára lé bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Kárí ayé làwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé a máa ń fẹ́ wàásù ọ̀rọ̀ inú Bíbélì fáwọn ẹlòmíì. Léraléra làwọn ìtẹ̀jáde wa máa ń tọ́ka sí Bíbélì, tí wọ́n sì máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Bíbélì. Ohun kan náà la sì máa ń gbìyànjú láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, à ń gbìyànjú láti lo Bíbélì ní gbogbo ìgbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. (2 Tímótì 3:16) Ẹ ẹ̀ rí bí inú wa ṣe máa ń dùn tó bá a bá rẹ́ni tó gbà wá láyè láti ka Bíbélì tó sì jẹ́ ká ṣàlàyé ọ̀nà tó gbà wúlò àti ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túmọ̀ sí fóun! Lóòótọ́ la ò lè rántí nǹkan lọ́nà pípé pérépéré bíi ti Jésù, ṣùgbọ́n a ní àwọn nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́ tí Jésù ò ní lákòókò tiẹ̀. Láfikún sí odindi Bíbélì tí wọ́n ń tẹ́ lónírúurú èdè tó ń pọ̀ si ṣáá, a tún ní àwọn ìtẹ̀jáde tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti wá àwọn ẹsẹ Bíbélì yòówù tá a bá ń wá láwàárí. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Bíbélì, ká sì máa tọ́ka sí i fáwọn èèyàn ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ bá ti ṣí sílẹ̀!
Bó Ṣe Gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
11. Kí nìdí tí Jésù fi ní láti máa gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lemọ́lemọ́ bẹ́ẹ̀?
11 Jésù rí i pé léraléra làwọn èèyàn máa ń ba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́, ṣùgbọ́n ó dájú pé ìyẹn ò yà á lẹ́nu. Nígbà tó ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀, ó ní: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Jésù sì mọ̀ dáadáa pé “òpùrọ́” “àti baba irọ́” ni Sátánì tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 8:44; 14:30) Inú Ìwé Mímọ́ ni Jésù ti fa ọ̀rọ̀ yọ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó fi ń kọ̀ fún Sátánì láti dán òun wò. Sátánì fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ kan nínú Sáàmù, ó sì dìídì gbé ìtúmọ̀ rẹ̀ gba ibi tó fẹ́, àmọ́ Jésù dá a lóhùn nípa ṣíṣàì jẹ́ kó yí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run síbi tó wù ú.—Mátíù 4:6, 7.
12-14. (a) Àwọn ọ̀nà wo làwọn aṣáájú ìsìn gbà fi hàn pé àwọn ò pa Òfin Mósè mọ́? (b) Báwo ni Jésù ṣe gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
12 Jésù kì í gbà kí wọ́n lo Ìwé Mímọ́ nílòkulò, kì í gbà kí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sódì kì í sì í gbà kí wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà òdì. Àwọn olùkọ́ òfin tó wà nígbà ayé rẹ̀ máa ń sọ pé Ìwé Mímọ́ sọ ohun tí kò sọ. Wọ́n ń rin kinkin pé èèyàn gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn apá kan nínú Òfin Mósè dórí bíńtín, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọn kì í jẹ́ káwọn èèyàn rí bí wọ́n ṣe lè ṣàmúlò àwọn ìlànà táwọn òfin náà wà fún. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe ìjọsìn tí kò dọ́kàn, ìjọsìn ojú ayé lásán dípò kí wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn tó túbọ̀ wúwo bíi ṣíṣe ẹ̀tọ́, fífi àánú àti ìṣòtítọ́ hàn. (Mátíù 23:23) Báwo ni Jésù ṣe gbèjà Òfin Ọlọ́run?
13 Nígbà tí Jésù ń wàásù lórí òkè, bó bá fẹ́ sọ àṣẹ kan tó wà nínú Òfin Mósè, léraléra ló máa ń lo gbólóhùn bíi, “ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé.” Lẹ́yìn tó bá ti sọ òfin yẹn tán, kó tó ṣàlàyé ìlànà tó jinlẹ̀ ju wíwulẹ̀ tẹ̀ lé Òfin, á sọ gbólóhùn bíi “ṣùgbọ́n mo sọ fún yín pé.” Ṣé kì í ṣe pé ó ń ta ko Òfin? Rárá o, ńṣe ló ń gbèjà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn mọ òfin tó sọ pé “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn” lámọ̀dunjú. Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé ẹni tó bá kórìíra ọmọnìkejì rẹ̀ ti tàpá sí ìlànà tó wà nídìí òfin yẹn. Bákan náà ló sọ pé ẹni tó bá ń ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ rẹ̀ ti ṣẹ̀ sí ìlànà tó wà nínú òfin Ọlọ́run tó sọ pé kéèyàn má ṣe ṣe panṣágà.—Mátíù 5:17, 18, 21, 22, 27-39.
14 Àpẹẹrẹ tó kẹ́yìn lára èyí tó fún wọn nínú Ìwàásù Lórí Òkè ni èyí tó sọ fún wọn pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:43, 44) Ǹjẹ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ti mú àṣẹ tó sọ pé, “kórìíra ọ̀tá rẹ”? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá, àtọwọ́dá àwọn aṣáájú ìsìn ni. Wọ́n fi èrò èèyàn sọ Òfin Ọlọ́run tó jẹ́ pípé di yẹpẹrẹ. Láìṣojo, Jésù dáàbò bo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kò jẹ́ kó díbàjẹ́ látàrí báwọn èèyàn kan ṣe fẹ́ fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn sọ ọ́ dìdàkudà.—Máàkù 7:9-13.
15. Báwo ni Jésù ṣe gbèjà Òfin Ọlọ́run nígbà tó dà bíi pé àwon kan fẹ mú un le koko jù láti máa fi ni àwọn èèyàn lára?
15 Àwọn aṣáájú ìsìn tún máa ń ba Òfin Ọlọ́run jẹ́ nípa bí wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó fi dà bíi pé ó ti le ju, ó sì ń ni àwọn èèyàn lára. Nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń rìn la àárín oko ọkà kọjá, wọ́n ya àwọn erín ọkà díẹ̀, làwọn Farisí kan bá fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń rú òfin Sábáàtì. Jésù wá lo àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́ láti lè fìdí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run múlẹ̀ kó bàa lè tún èrò wọn ṣe. Ó tọ́ka sí ibì kan ṣoṣo nínú Ìwé Mímọ́ tó ṣàlàyé nípa bí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin rẹ̀ tébi ń pa ṣe jẹ búrẹ́dì àgbékawájú níbòmíì yàtọ̀ sí inú ibùjọsìn. Jésù fi han àwọn Farisí wọ̀nyẹn pé ẹ̀kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú àti oníyọ̀ọ́nú kò yé wọn.—Máàkù 2:23-27.
16. Kí làwọn aṣáájú ìsìn ṣe sí àṣẹ inú Òfin Mósè nípa ìkọ̀sílẹ̀, kí sì ni Jésù ṣe lórí rẹ̀?
16 Àwọn aṣáájú ìsìn tún wá ibi tí wọ́n máa sá pa mọ́ sí nínú Òfin Ọlọ́run láti lè sọ òfin náà di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Òfin gbà kí ọkùnrin kan kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ bó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ká “ohun àìbójúmu kan” mọ́ ọn lọ́wọ́, ó sì dájú pé èyí ní láti jẹ́ ìṣòro tó burú jáì tó lè kó ìtìjú bá àwọn ará ilé yẹn. (Diutarónómì 24:1) Àmọ́ nígbà tí Jésù wà láyé, ńṣe làwọn aṣáájú ìsìn ń lo ìyẹn bí àwáwí láti jẹ́ káwọn ọkùnrin kọ aya wọn sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn èyíkéyìí, kódà ọkùnrin kan lè kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ bí aya náà bá se oúnjẹ jóná!a Jésù fi hàn pé gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ni ìtúmọ̀ òdì wọn yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Mósè láti sọ. Lẹ́yìn náà ló jẹ́ kí wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run látilẹ̀wá lórí ìgbéyàwó, pé ọkọ kan aya kan ni Ọlọ́run fẹ́ àti pé ìṣekúṣe nìkan ni ìdí tó bójú mu tí tọkọtaya kan fi lè kọ ara wọn sílẹ̀.—Mátíù 19:3-12.
17. Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú gbígbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
17 Bákan náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi òde òní rí i pé àwọn gbọ́dọ̀ gbèjà Ìwé Mímọ́, torí àwọn tó ń ta kò ó. Ńṣe làwọn aṣáájú ìsìn ń dọ́gbọ́n ta ko Bíbélì nígbà tí wọ́n sọ pé àwọn ìwà rere tí Bíbélì sọ pé ká máa hù ò bóde mu mọ́. Wọ́n tún máa ń parọ́ mọ́ Bíbélì nípa bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ èké tí wọ́n sì ń sọ pé inú Bíbélì làwọn ti rí i. Àǹfààní ló jẹ́ fáwa láti gbèjà ògidì òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ ká mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kì í ṣe mẹ́talọ́kan. (Diutarónómì 4:39) Síbẹ̀, bá a ṣe ń gbèjà rẹ̀ náà, ó yẹ ká máa fọgbọ́n ṣe é, ká jẹ́ onínú tútù ká sì máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n.—1 Pétérù 3:15.
Bó Ṣe Ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
18, 19. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jésù lè ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó sì jọ ẹni tó ń ṣàlàyé fún lójú?
18 Jésù wà lọ́run nígbà tí wọ́n ń kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ẹ ò rí bí inú rẹ̀ á ti dùn tó fún àǹfààní tó ní láti wá sáyé kó sì lọ́wọ́ nínú ṣíṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Bí àpẹẹrẹ, wo ọjọ́ mánigbàgbé yẹn lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ tó dara pọ̀ mọ́ méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń lọ sí abúlé Ẹ́máọ́sì. Kí wọ́n tó mọ̀ pé òun ni, wọ́n ti kẹ́jọ́ balẹ̀ nípa bí inú wọn ṣe bà jẹ́ tó àti bí gbogbo nǹkan ṣe tojú sú wọn nítorí ikú Ọ̀gá wọn ọ̀wọ́n. Kí lèsì Jésù? Ńṣe ló “bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì, ó túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹmọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.” Báwo ló ṣe rí lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Wọ́n wí fún ara wọn nígbà tó yá pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà, bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?”—Lúùkù 24:15-32.
19 Nígbà tó tún ṣe, lọ́jọ́ yẹn kan náà, Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àtàwọn míì. Kíyè sí ohun tó ṣe fún wọn: “Ó . . . ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.” (Lúùkù 24:45) Kò síyè méjì pé ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò tí ìdùnnú ṣubú layọ̀ yẹn ti gbọ́dọ̀ mú kí wọ́n rántí àìmọye ìgbà tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn, àti fún àwọn tó bá ṣe tán láti fetí sílẹ̀. Ó sábà máa ń tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n mọ̀ bí ẹní mowó tẹ́lẹ̀, á wá ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tí á fi ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ẹni tó ń gbọ́, ìyẹn ni pé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ máa ń ní òye tó túbọ̀ jinlẹ̀ sí i nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
20, 21. Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè níbi tí igbó ti ń jó?
20 Nírú àkókò kan bẹ́ẹ̀, àwùjọ àwọn Sadusí ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀. Wọ́n jẹ́ ẹ̀ya ìsìn àwọn Júù tó ní ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn Júù nínú, wọn ò sì gbà pé àjíǹde wà. Jésù sọ fún wọn pé: “Ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ kò ka ohun tí Ọlọ́run sọ fún yín ni, pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’? Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè.” (Mátíù 22:31, 32) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, àwọn Sadusí mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí bí ẹní mowó, torí Mósè, ẹni tí wọ́n kà sí gidigidi ló kọ ọ́ sílẹ̀. Ṣó o ti wá rí bí àlàyé tí Jésù ń ṣe lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ṣe rinlẹ̀ tó?
21 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ níbi igbó tó ń jó ní nǹkan bí ọdún 1514 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Ẹ́kísódù 3:2, 6) Ní àkókò yẹn, ó ti di ọ̀ọ́dúnrún lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [329] ọdún tí Ábúráhámù ti dolóògbé. Ó ti di okòólénígba ó lé mẹ́rin [224] ọdún tí Ísákì ti kú, ó sì jẹ́ igba ó dín mẹ́ta [197] ọdún tí Jékọ́bù ti ṣàìsí. Síbẹ̀ Jèhófà ṣì sọ pé: “Èmi ni” Ọlọ́run wọn. Àwọn Sadusí yẹn mọ̀ pé Jèhófà ò dà bí àwọn ọlọ́run èké táwọn aláìgbàgbọ́ ń sọ pé wọ́n ń jọba lórí àwọn òkú tó wà láàyè lábẹ́ ilẹ̀. Rárá o, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, Ọlọ́run “àwọn alààyè” ni. Kí nìyẹn ní láti túmọ̀ sí? Kókó tí Jésù fà yọ nínú rẹ̀ lágbára gan-an ni, ó ní: “Gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:38) Jèhófà ò gbàgbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n tí wọ́n ti kú, torí pé kì í gbàgbé nǹkan. Ìfẹ́ Jèhófà láti jí irú àwọn ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀ dìde á ṣẹ dandan ni, ó dájú tó bẹ́ẹ̀ tá a fi lè sọ pé, wọ́n wà láàyè. (Róòmù 4:16, 17) Ǹjẹ́ àlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí kò fa kíki? Abájọ tí “háà [fi] ṣe àwọn ogunlọ́gọ̀ náà”!—Mátíù 22:33.
22, 23. (a) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ṣíṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Kí la máa jíròrò ní orí tó kàn?
22 Àwọn Kristẹni òde òní náà láǹfààní láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọ̀nà tí Jésù gbà ń ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Òtítọ́ ni pé òye wa ò tó ti Jésù. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan táwọn èèyàn ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ fún wọn, tá a sì máa ṣàlàyé àwọn kan tí wọ́n tiẹ̀ lè má tíì ronú kàn rí fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ti máa ka “Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ,” àti “Ki ijọba rẹ de” látìgbà tí wọ́n ti bí wọn, kí wọ́n sì má mọ orúkọ Ọlọ́run tàbí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí. (Mátíù 6:9, 10, Bibeli Mimọ) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ǹlá ló jẹ́ bá a bá rẹ́ni tó gbà wá láyè láti ṣàlàyé tó ṣe yékéyéké, tó sì ṣe kedere fún un nípa òtítọ́ Bíbélì!
23 Àwọn ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú kíkọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ ni, fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbígbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣàlàyé rẹ̀. Ẹ wá jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀nà mélòó kan tí Jésù gbà mú kí òtítọ́ wọ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ lọ́kàn yẹ̀ wò.
a Josephus, òpìtàn kan ní ọ̀rúndún kìíní, tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ Farisí tó ti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ sọ nígbà tó yá pé ẹni tó bá fẹ́ lè kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ “nítorí ohunkóhun (àti pé àìmọye irú ẹ̀ ló ti ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọkùnrin).”