Àwọn Ohun Tó Lè Mú Ká Ní Ojúlówó Ayọ̀
BÍ ÈÈLÒ bá pọ̀ tó, oríṣiríṣi àrà ni ọlọ́wọ́-ṣíbí lè dá. Ó sì dà bíi pé bọ́ràn ṣe rí nìyẹn bó bá di pé kéèyàn láyọ̀. Ohun kan ṣoṣo péré kọ́ ló ń mú ayọ̀ wá, bí oríṣiríṣi èèlò oúnjẹ, ọ̀pọ̀ nǹkan lèèyàn gbọ́dọ̀ mú mọ́ra wọn kó tó lè láyọ̀. Lára àwọn nǹkan ọ̀hún ni iṣẹ́, eré, àkókò ìgbádùn pẹ̀lú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́, tó fi mọ́ àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ iṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì tún wà tó lè jẹ́ ká ní ayọ̀, ìyẹn ìwà ẹni, ohun tó wuni, àtàwọn nǹkan téèyàn ń lé nígbèésí ayé.
Ọpẹ́ ni pé kì í ṣe àwa fúnra wa la ó pinnu àwọn ohun tó lè mú ká ní ojúlówó ayọ̀. Kí nìdí ẹ̀? Ìdí ni pé Ẹlẹ́dàá wa ti fún wa ní Bíbélì, tó jẹ́ ìwé àgbàyanu tó ń fúnni ní ìtọ́ni. Odindi tàbí apá kan Bíbélì ti wà ní àwọn èdè àti èdè àdúgbò tó jẹ́ irínwó-lé-lẹ́gbàá ó dín mẹ́tàlélógún [2,377]. Kò sì sí ìwé tí wọ́n tíì tẹ̀ lédè tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí látijọ́ táláyé ti dáyé!
Wíwà tí Bíbélì wà nílé lóko yìí fi hàn pé ó jẹ Ọlọ́run lógún pé kí gbogbo èèyàn láyọ̀ kó sì ṣeé ṣe fún wọn láti jọ́sìn òun. (Ìṣe 10:34, 35; 17:26, 27) Òun fúnra rẹ̀ tiẹ̀ sọ pé: “Èmi . . . ni . . . Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” Bá a bá ṣe ohun tí àwọn òfin rẹ̀ fi kọ́ wa, ó ṣèlérí pé ọkàn wa á balẹ̀, àlàáfíà wa á sì “dà bí odò.”—Aísáyà 48:17, 18.
Ìlérí yẹn rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tá a fà yọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ọ̀rọ̀ nǹkan tẹ̀mí tá à ń sọ níbí kì í wulẹ̀ ṣe ìgbàgbọ́ oréfèé nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan tó ń nípa lórí ìgbésí ayé wa látòkè délẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ fi hàn pé a múra tán láti tẹ́tí sí Ọlọ́run a sì fẹ́ kó máa kọ́ wa, nítorí a mọ̀ pé ó mọ̀ wá gan-an ju bí a ti mọ ara wa lọ. Errol, ọkùnrin kan tó ti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ohun tó lé láàádọ́ta ọdún sọ pé: “Ohun tó tíì mú mi gbà gbọ́ jù lọ pé Bíbélì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa ni pé béèyàn bá fi àwọn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni ṣèwà hù, ó máa ń yọrí síbi tó dáa gan-an ni!” Bí àpẹẹrẹ, ìwọ wo ìmọ̀ràn tó jíire tí Bíbélì fúnni lórí irú àwọn ọ̀ràn bíi lílépa ọrọ̀ àti ìgbádùn.
Ìmọ̀ràn Tó Mọ́gbọ́n Dání Nípa Lílépa Owó
Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá látinú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn o, ohun tó o jẹ́ gan-an, pàápàá lójú Ọlọ́run, kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú bí owó tó o ní ní báńkì ṣe pọ̀ tó. Kódà, béèyàn bá ń lépa ọrọ̀, ńṣe ni àníyàn rẹ̀ á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Ìyẹn á mú kí ayọ̀ ẹ̀ máa pẹ̀dín, kò sì ní jẹ́ kó rí àkókò tó máa lò fún àwọn nǹkan míì tó túbọ̀ ṣe pàtàkì.—Máàkù 10:25; 1 Tímótì 6:10.
Gẹ́gẹ́ bí Richard Ryan, ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ìrònú òun ìhùwà, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe sọ, báwọn èèyàn bá ṣe ń fẹ́ kí àwọn nǹkan tara máa fún àwọn ní ìtẹ́lọ́rùn tó, bẹ́ẹ̀ náà ni àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn wọn á ṣe máa pọ̀ tó. Ọ̀nà tí òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Sólómọ́nì gbà sọ ọ́ ni pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.” (Oníwàásù 5:10) A wá lè fọ̀ràn náà wé ìgbà tí ojú ibi tí ẹ̀fọn ti jẹni bá ń yúnni—bá a bá ṣe ń họ ọ́ tó, bẹ́ẹ̀ lá máa yúnni tó, títí táá fi dégbò.
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ṣiṣẹ́ kára ká sì jadùn iṣẹ́ ọwọ́ wa. (Oníwàásù 3:12, 13) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á túbọ̀ máa fojú tó dáa wò wá, ohun ṣíṣe kókó míì tó sì tún lè jẹ́ ká láyọ̀ nìyẹn. Ó tún lè ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn díẹ̀ lára àwọn ohun tó lè mú káyé dùn bí oyin. Àmọ́ ṣá o, ìyàtọ̀ wà láàárín gbígbádùn díẹ̀ lára àwọn nǹkan tówó lè ṣe àti kéèyàn máa lépa àtilọ́rọ̀.
Ìgbádùn Náà Láàyè Tiẹ̀
Béèyàn bá mọyì àǹfààní tó wà nínú fífi ti Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbésí ayé ẹ̀, ìyẹn á ràn án lọ́wọ́ láti rí àǹfààní tó ga jù lọ látinú eré ìtura, eré ìnàjú àtàwọn nǹkan ìgbádùn míì. Jésù máa ń gbádùn àkókò ìtura níbi táwọn èèyàn ti ń jẹ tí wọ́n sì ti ń mu. (Lúùkù 5:29; Jòhánù 2:1-10) Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé bí kò bá rí àwọn nǹkan wọ̀nyí kò ní láyọ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run ló máa ń fún un láyọ̀ jù lọ, lára wọn ni ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé.—Jòhánù 4:34.
Sólómọ́nì Ọba dán onírúurú ohun tó lè mú kéèyàn gbádùn ara rẹ̀ wò láti rí i bóyá wọ́n lè fún òun láyọ̀. Ó sọ pé: “Èmi yóò bẹ́ gìjà sínú ayọ̀ kí n bàa lè gbádùn ara mi.” Ọ̀rọ̀ tí ọba tó lọ́rọ̀ yìí sọ kọjá tẹni tó rọra lúwẹ̀ẹ́ wọnú àríyá rẹpẹtẹ. Ó tì o, ńṣe ló tọ kọ́ṣọ́ wọnú ìgbádùn tó ń ṣàn! Síbẹ̀, kí lèrò ẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe rí fún un nígbẹ̀yìn gbẹ́yín? Ó kọ̀wé pé: “Òfoódòfo ni èyí pẹ̀lú.”—Oníwàásù 2:1, New English Bible.
Gbogbo ẹní bá ṣáà ti ń wá ìgbádùn rẹpẹtẹ ló máa padà rí i pé òfo àti òtúbáńtẹ́ náà ni gbogbo ẹ̀. Kódà, nígbà táwọn olùṣèwádìí fi lílépa ọrọ̀ wéra pẹ̀lú àwọn nǹkan bí iṣẹ́ tó ní láárí, àwọn ìgbòkègbodò tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run àti bíbá ìdílé ẹni ṣe nǹkan pọ̀, wọ́n rí i pé wíwá adùn kiri ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú báwọn tí wọ́n wádìí lọ́dọ̀ wọn náà ṣe ń láyọ̀ sí.
Jẹ́ Ọ̀làwọ́ Kó O sì Mọpẹ́ Dá
Àwọn tó máa ń láyọ̀ kì í ṣe àwọn tó mọ tara wọn nìkan, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n sábà máa ń jẹ́ ọ̀làwọ́, wọ́n sì máa ń nífẹ̀ẹ́ sáwọn ẹlòmíì. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Yàtọ̀ sí ká jẹ́ ọ̀làwọ́, a tún lè ṣe àwọn èèyàn lóore nípa lílo àkókò àti okun wa fún wọn. Irú ìyẹn gan-an sì ni àwọn ará ilé ẹni á mọrírì jù. Ó yẹ kí àwọn tọkọtaya máa lo àkókò pa pọ̀ kí nǹkan bàa lè máa lọ déédéé nínú ìdílé wọn kí wọ́n sì lè láyọ̀, ó sì yẹ káwọn òbí pàápàá máa wá àkókò tó pọ̀ tó fáwọn ọmọ wọn, kí wọ́n máa bá wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n máa fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn dénú, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń bára wọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀ báyìí, wọ́n á kẹ́sẹ járí, ilé wọn á sì di ibùgbé ayọ̀.
Òmíràn wá ni pé nígbà táwọn ẹlòmíì bá ṣe nǹkan fún ọ, bóyá tí wọ́n lo àkókò wọn fún ọ, tàbí tí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì, ǹjẹ́ o máa ń ‘fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́’? (Kólósè 3:15) Bá a bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, á mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn dán mọ́rán, ó sì lè fi kún ayọ̀ tiwa fúnra wa. Bí ẹnì kan bá dúpẹ́ tọkàntọkàn lọ́wọ́ rẹ, ṣé kì í mú kí inú rẹ dùn kí ara rẹ sì yá gágá?
Bá a bá jẹ́ ẹni tó mọpẹ́ dá, á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì àwọn nǹkan rere tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n dìídì ṣe, olùṣèwádìí kan ní Yunifásítì California tó wà ní ìlú Riverside, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ fún àwọn tó ń lò fún ìwádìí náà pé kí wọ́n ní ìwé kan tí wọ́n á máa kọ àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n tìtorí ẹ̀ ṣọpẹ́ sí. Kò yà á lẹ́nu láti rí i pé láàárín ohun tó lé lọ́sẹ̀ mẹ́fà, ìgbésí ayé túbọ̀ tẹ́ àwọn tí wọ́n lò fún ìwádìí náà lọ́rùn.
Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ nínú èyí? Ipò yòówù kó o bára ẹ, tàwọn ohun rere tó ò ń gbádùn nígbèésí ayé ẹ ni kó o máa rò. Kódà, Bíbélì gbà ọ́ níyànjú pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà tó sọ pé: “Máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, . . . máa dúpẹ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:16, 18) Àmọ́ ṣá o, ká tó lè di ẹni tó ń dúpẹ́, àfi ká máa sapá gidigidi láti rántí àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. O ò ṣe kúkú gbé ìyẹn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wàá máa ṣiṣẹ́ lé lórí?
Kéèyàn Bà A Lè Láyọ̀, Ìfẹ́ àti Ìrètí Ṣe Kókó
Àtàtà ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ ni pé ìfẹ́ lohun téèyàn nílò jù lọ láti ọjọ́ ìbí títí dọjọ́ ikú. Láìsí ìfẹ́ yìí, ńṣe lèèyàn á joro dà nù. Àmọ́ kí lohun tá à ń pè ní ìfẹ́ gan-an? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀rọ̀ náà bó ṣe wù wọ́n báyìí, Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in báyìí pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo.”—1 Kọ́ríńtì 13:4-8.
Àbí ẹ ò rí i pé ìfẹ́ tòótọ́ kì í mọ tara ẹ̀ nìkan! Nítorí pé “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan,” ohun tó máa mú àwọn ẹlòmíì láyọ̀ ló máa ń jẹ ẹ́ lógún ju tara ẹ̀ lọ. Ó bani nínú jẹ́ pé irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ti túbọ̀ ń dàwáàrí. Kódà, nínú àsọtẹ́lẹ̀ pípabanbarì tí Jésù sọ nípa ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ó sọ pé “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”—Mátíù 24:3, 12; 2 Tímótì 3:1-5.
Àmọ́ ṣá o, ipò nǹkan ò ní máa bá a lọ bó ṣe rí yìí títí láé, nítorí pé nǹkan àbùkù gbáà ló jẹ́ lójú Ẹlẹ́dàá—ẹni tó fi ìfẹ́ bora bí aṣọ! (1 Jòhánù 4:8) Láìpẹ́, Ọlọ́run á palẹ̀ gbogbo àwọn tó ní ìkórìíra lọ́kàn tí wọ́n sì gbé ìwọra wọ̀ bí ẹ̀wù mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Kìkì àwọn tó bá sa gbogbo ipá wọn láti ní irú ìfẹ́ tá a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí ni Ọlọ́run máa pa mọ́. Ohun tó sì máa jẹ́ àbájáde èyí ni pé àlàáfíà àti ayọ̀ á gbilẹ̀ kárí ayé. Ó dájú pé ìlérí Bíbélì á nímùúṣẹ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.
Ìwọ náà wo báyé á ṣe dára tó nígbà tí ibi gbogbo bá kún fún “inú dídùn kíkọyọyọ”! Ṣó wá yà ọ́ lẹ́nu nígbà náà pé Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí”? (Róòmù 12:12) Ṣé wàá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìrètí àgbàyanu tí Ọlọ́run fún aráyé onígbọràn? Nígbà náà, jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìtàn Àwọn Atàpátadìde—Ṣóòótọ́ Ni Ṣá?
A máa ń gbọ́ táwọn èèyàn máa ń sọ ìtàn àwọn atàpátadìde tí wọ́n bí sínú òṣì àti ìṣẹ́, àmọ́ tí wọ́n forí ṣe fọrùn ṣe tí wọ́n fi di ọlọ́rọ̀. Ìròyìn kan nípa ojúlówó ayọ̀ nínú ìwé ìròyìn San Francisco Chronicle ṣàlàyé pé: “Ìgbà míì wà tí wọ́n máa ń lo irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn kan wà tí wọn kì í láyọ̀ nígbà ọmọdé torí pé nínú òfíì, nínú ọ̀láà ni ọmọ páńdọ̀rọ̀ wọn gbó sí. Àmọ́ tó jẹ́ adùn ló pàpà gbẹ̀yìn ewúro fún wọn. Ìṣòro tó wà nínú èròǹgbà yìí ni pé wọ́n lè má fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀, kó kàn jẹ́ pé wọ́n wulẹ̀ rí towó ṣe ni.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ayọ̀ Ń Mú Kára Le
Inú dídùn ní mórí yá. Ìròyìn kan látinú ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ó dà bíi pé ayọ̀ tàbí ohunkóhun míì tó bá lè mú ìtura ọkàn wá, ìyẹn bíi kéèyàn ní àgbọ́kànlé, kéèyàn máa ro èrò rere àti kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn máa ń dín ewu àrùn tó jẹ mọ́ ọkàn àti òpójẹ̀, àrùn ẹ̀dọ̀fóró, àtọ̀gbẹ, ẹ̀jẹ̀ ríru, òtútù àti àkóràn tí kì í jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa kù.” Kò tán síbẹ̀, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Holland, tó dá lórí àwọn àgbàlagbà tó ń gbàtọ́jú nílé ìwòsàn, fi hàn pé ó lé lọ́dún mẹ́sàn-án gbáko tí iye àwọn tó ń kú fi dín kù sí ìdajì nítorí pé wọ́n ń fọkàn dàníyàn ohun tó dáa. Ìyàlẹ́nu gbáà sì nìyẹn jẹ́!
Àdìtú ṣì lọ̀rọ̀ bí ìbàlẹ̀ ọkàn ṣe ń nípa lórí ìlera jẹ́. Àmọ́, àwọn olùṣèwádìí ti fi hàn pé omi inú ara tó máa ń mú kí ara ga èèyàn, tó sì tún máa ń pa adènà àrùn inú ara, kì í sun nínú ara àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń fọkàn ro ohun tó dáa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Bó ṣe jẹ́ pé béèyàn bá rí èèlò oúnjẹ tó dáa, èèyàn lè fi gbọ́únjẹ àjẹpọ́nnulá, bẹ́ẹ̀ náà ni títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ṣe lè mú kéèyàn láyọ̀