Ìfẹ́ Aládùúgbò Ṣeéṣe
ÀPÈJÚWE Jesu Kristi nípa ará Samaria náà fi ohun tí ojúlówó ìfẹ́ aládùúgbò túmọ̀sí níti gidi hàn. (Luku 10:25-37) Jesu tún kọ́ni pé: “Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ. Èyí ni èkínní àti òfin ńlá. Èkejì sì dàbí rẹ̀, Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí araàrẹ.”—Matteu 22:37-39.
Bíi ti ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó ha ṣòro fún ọ láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ tí ó jẹ́ ti àwùjọ ẹ̀yà-ìran kan tí ó yàtọ̀ sí tìrẹ bí? Bóyá èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti kọ́ tàbí o ti nírìírí àìbánilò lọ́gbọọgba àti àìṣèdájọ́ òdodo. Ìwọ tàbí àwọn olólùfẹ́ rẹ tilẹ̀ lè ti jìyà ìloninílòkulò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àwùjọ mìíràn.
Níwọ̀n bí Jesu ti fihàn pé ọ̀kan nínú àwọn òfin Ọlọrun ni pé kí a nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa, ó gbọ́dọ̀ ṣeéṣe láti borí irú àwọn ìmọ̀lára alágbára bẹ́ẹ̀. Kọ́kọ́rọ́ náà sí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni láti wo àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun àti Kristi ti ń wò wọ́n. Nípa èyí ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ ti Jesu àti àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀.
Àpẹẹrẹ Rere ti Jesu
Àwọn Ju ọ̀rúndún kìn-ín-ní ní àwọn ìmọ̀lára alágbára lòdìsí àwọn ará Samaria, àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń gbé ní àgbègbè kan láàárín Judea àti Galili. Ní àkókò kan àwọn alátakò tí wọ́n jẹ́ Ju fi tẹ̀gàntẹ̀gàn béèrè lọ́wọ́ Jesu pé: “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ í ṣe, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?” (Johannu 8:48) Èrò òdì sí àwọn ará Samaria lágbára débi pé àwọn Ju kan tilẹ̀ gégùn ún fún àwọn ará Samaria ní gbangba nínú sinagọgu tí wọ́n sì ń gbàdúrà lójoojúmọ́ pé kí àwọn ará Samaria má rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà.
Ìmọ̀ nípa ìkórìíra tí ó fìdí múlẹ̀ yìí láìṣe àníàní ni ó sún Jesu láti sọ àkàwé nípa ará Samaria náà tí ó fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ aládùúgbò tòótọ́ nípa bíbójútó ọkùnrin Ju náà tí awọ́n ọlọ́ṣà lù. Báwo ni Jesu ìbá ti dáhùn nígbà tí ọkùnrin Ju náà tí ó mọ Òfin Mose dáradára béèrè pé: “Ta ni ha sì ni ẹnìkejì mi?” (Luku 10:29) Ó dára, Jesu ìbá ti dáhùn ní tààràtà nípa sísọ pé: ‘Àwọn aládùúgbò rẹ ní nínú kìí ṣe kìkì àwọn Ju ẹlẹgbẹ́ rẹ nìkan ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mìíràn pẹ̀lú, àní ará Samaria kan.’ Bí ó ti wù kí ó rí, ìbá ti ṣòro fún àwọn Ju láti gba ìyẹn. Nítorí náà ó ṣe àkàwé nípa Ju kan tí ó rí àánú ará Samaria kan gbà. Jesu tipa bẹ́ẹ̀ ran àwọn Ju olùtẹ́tísílẹ̀ lọ́wọ́ láti dé ìparí-èrò náà pé ìfẹ́ aládùúgbò tòótọ́ yóò nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn tí wọn kìí ṣe Ju.
Jesu kò ní èrò òdì sí àwọn ará Samaria. Nígbà tí ó ń rìnrìn-àjò gba Samaria kọjá ní ìgbà kan, ó sinmi lẹ́bàá kànga kan nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ìlú-ńlá tí ó wà nítòsí láti ra oúnjẹ. Nígbà tí obìnrin ará Samaria kan wá láti fa omi, ó wí pé: “Fún mi mu.” Níwọ̀n bí àwọn Ju kò ti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Samaria, òun béèrè pé: “Èétirí tí ìwọ tí í ṣe Ju, fi ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi, èmi ẹni tí í ṣe obìnrin ará Samaria?” Nígbà náà ni Jesu wá jẹ́rìí fún un, tí ó tilẹ̀ polongo ní gbangba pé òun ni Messia náà. Ó dáhùnpadà nípa lílọ sí inú ìlú-ńlá náà tí ó sì pe àwọn ẹlòmíràn láti wá kí wọ́n sì tẹ́tísílẹ̀ sí i. Àbájáde rẹ̀ ti jẹ́? “Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá [wọ́n] sì gbà á gbọ́.” Ẹ wo irú àbájáde dáradára tí èyí jẹ́ nítorí pé Jesu kò sí nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìhùwàsí àwọn Ju ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó gbilẹ̀!—Johannu 4:4-42.
Ọlọrun Kìí Ṣe Ojúṣàájú
Ète Ọlọrun ni pé kí Jesu wàásù ní pàtàkì fún àwọn Ju, “àwọn àgùtàn ilé Israeli tí ó nù.” (Matteu 15:24) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ipò àtilẹ̀wá wọn jẹ́ ti Ju. Ṣùgbọ́n ní kìkì ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ ní Pentekosti 33 C.E., Jehofa mú kí ó hàn kedere pé òun ń fẹ́ kí àwọn Ju onígbàgbọ́ nasẹ̀ iṣẹ́ sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè, àwọn Kèfèrí.
Nínú èrò-inú ẹnìkan tí í ṣe Ju, nínífẹ̀ẹ́ ara Samaria kan gẹ́gẹ́ bí ara-ẹni yóò ṣòro gan-an. Yóò tilẹ̀ le jù láti fi ìfẹ́ aládùúgbò hàn sí àwọn Kèfèrí aláìkọlà, àwọn ènìyàn tí àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn Ju kò tó ti àwọn ará Samaria. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìhùwásí àwọn Ju síhà àwọn Kèfèrí, The International Standard Bible Encyclopaedia sọ pé: “A rí ìríra tí ó légbákan jùlọ, ìkẹ́gàn àti ìkórìíra, ní àwọn àkókò tí a kọ M[ajẹmu] T[itun]. Àwọn [Kèfèrí] ní a kà sí aláìmọ́, àwọn ẹni tí òfin kọ̀ pé a kò gbọ́dọ̀ ní àjọṣepọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ èyíkéyìí pẹ̀lú. Wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun àti àwọn ènìyàn Rẹ̀, àwọn ẹni tí a fi ìmọ̀ Ọlọrun dù àyàfi bí wọ́n bá di aláwọ̀ṣe, lójú ìyẹn pàápàá a kò lè, gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbà àtijọ́, gbà wọ́n wọnú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ní kíkún. A kà á léèwọ̀ fún àwọn Ju láti gbà wọ́n nímọ̀ràn, bí wọ́n bá sì béèrè nípa àwọn ohun tí ó tanmọ́ Ọlọrun a gbọ́dọ̀ fi wọ́n gégùn ún.”
Nígbà tí àwọn púpọ̀ di ojú-ìwòye yìí mú, Jehofa mú kí aposteli Peteru ní ìrírí ìran-ìfihàn kan nínú èyí tí a ti sọ fún un láti ‘jáwọ́ nínú pípe àwọn ohun ti Ọlọrun ti wẹ̀ ní àìmọ́.’ Ọlọrun wá darí rẹ̀ lẹ́yìn náà sí ilé Korneliu Kèfèrí. Peteru jẹ́rìí nípa Kristi fun Korneliu, ìdílé rẹ̀, àti àwọn Kèfèrí mìíràn. Peteru wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọrun kìí ṣe ojúsàájú ènìyàn: Ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.” Bí Peteru ṣe ń wàásù lọ́wọ́, ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn onígbàgbọ́ titun náà, àwọn tí a baptisi nígbà náà tí wọ́n sì di àwọn Kèfèrí àkọ́kọ́ ti wọn di ọmọlẹ̀yìn Kristi.—Iṣe, orí 10.
Àwọn ọmọlẹ̀yìn tí wọn jẹ́ Ju tẹ́wọ́gba ìdàgbàsókè yìí, ní mímọ̀ pé àṣẹ Jesu náà láti ‘sọ àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè gbogbo di ọmọ-ẹ̀yìn’ kò pin sọ́dọ̀ àwọn Ju ní gbogbo ilẹ̀ ṣùgbọ́n ó ní àwọn Kèfèrí nínú. (Matteu 28:19, 20; Iṣe 11:18) Ní bíborí àwọn ìmọ̀lára òdì èyíkéyìí sí àwọn Kèfèrí tí wọ́n lè ti ní, wọn fi ìtara ṣètò ìgbétáásì ìwàásù kan láti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ-ẹ̀yìn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ní ohun tí ó dín sí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, a lè sọ pé ìròyìn rere náà ni a ti wàásù “nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọrun.”—Kolosse 1:23.
Aposteli Paulu ni ẹni tí ó tún ṣe òléwájú iṣẹ́ ìwàásù yìí, òun fúnraarẹ̀ jẹ́ Kristian kan tí ipò àtilẹ̀wá rẹ̀ jẹ́ ti Ju. Ṣáájú kí ó tó di ọmọ-ẹ̀yìn Kristi, òun ti jẹ́ mẹ́ḿbà onítara nínú ẹ̀ya ìsìn àwọn Farisi. Wọ́n fojú tẹ́ḿbẹ́lú kìí ṣe kìkì àwọn Kèfèrí nìkan ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn gbáàtúù tí wọ́n jẹ́ ti ẹ̀yà wọ́n pẹ̀lú. (Luku 18:11, 12) Ṣùgbọ́n Paulu kò fààyè gba àwọn ojú-ìwòye wọ̀nyẹn láti fà á sẹ́yìn kúrò nínú fífi ìfẹ́ aládùúgbò hàn sí àwọn ẹlòmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó di “aposteli àwọn Kèfèrí,” ní yíya ìgbésí-ayé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn la gbogbo àwọn ilẹ̀ Meditereniani já.—Romu 11:13.
Nígbà iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀, a sọ Paulu lókùúta, a lù ú, a sì fi í sí túbú. (Iṣe 14:19; 16:22, 23) Ǹjẹ́ irú àwọn ìrírí lílekoko bẹ́ẹ̀ ha sún un láti bínú kíkorò àti láti parí èrò sí pé òun ń fi àkókò ṣòfò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kan àti àwọn àwùjọ ẹ̀yà-ìran kan bí? Bẹ́ẹ̀kọ́ rárá. Ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn aláìlábòsí-ọkàn tí wọ́n wà káàkiri àwùjọ ẹ̀yà-ìran púpọ̀ ti ọjọ́ rẹ̀ wà.
Nígbà tí Paulu rí àwọn Kèfèrí tí wọ́n ń fẹ́ láti di ẹni tí a kọ́ ní àwọn ọ̀nà Ọlọrun, o nífẹ̀ẹ́ wọn. Fún àpẹẹrẹ, sí àwọn ará Tessalonika òun kọ̀wé pé: “Àwa ń ṣe pẹ̀lẹ́ lọ́dọ̀ yín, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti ń tọ́jú àwọn ọmọ òun tìkáraarẹ̀: Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín kìí ṣe ìhìnrere Ọlọrun nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa tìkáraawa pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tessalonika 2:7, 8) Àwọn ọ̀rọ̀ àtọkànwá wọ̀nyí fihàn pé Paulu níti tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ àwọn Kèfèrí ará Tessalonika òun kò sì fààyè gba ohunkohun láti ba ayọ̀ ìbátan rere kan pẹ̀lú wọn jẹ́.
Ìfẹ́ Aládùúgbò Lẹ́nu Iṣẹ́
Lónìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, àwọn tí wọ́n so araawọn pọ̀ mọ́ ìjọ Kristian mú ìfẹ́ aládùúgbò dàgbà fún àwọn ènìyàn láti inú gbogbo àwùjọ́ ẹ̀yà-ìran. Nípa mímú ojú-ìwòye bíi ti Ọlọrun dàgbà nípa àwọn ẹlòmíràn àti nípa ṣíṣàjọpín ìhìnrere Ìjọba náà pẹ̀lú wọn, àwọn Kristian tòótọ́ ti mú òye wọn gbòòrò síi nípa àwọn ènìyàn tí wọn kì bá ti mọ̀ láé bí kìí bá ṣe pé wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjọ. Wọ́n tilẹ̀ ní ìfẹ́ ará fún wọn. (Johannu 13:34, 35) Èyí lè jẹ́ ìrírí rẹ pẹ̀lú.
Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí wọn ní 229 ilẹ̀ tí wọ́n sì ṣojú fún “orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti . . . èdè.” (Ìfihàn 7:9) Gẹ́gẹ́ bi ẹgbẹ́ ará kárí ayé, wọ́n sopọ̀ṣọ̀kan nínú ìjọsìn Jehofa, nínú kíkọ̀ wọn láti kópa nínu àwọn ìforígbárí àwùjọ ẹ̀yà-ìran àti ìbánidíje, àti nínú kíkọ̀ tí wọ́n kọ ẹ̀tanú tí ó ja àwọn ènìyàn lólè ìbátan ọlọ́yàyà pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ wọn sílẹ̀.
Kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí, ìwọ yóò sì ṣàkíyèsí bí àwọn ènìyàn láti inú ipò àtilẹ̀wá tí gbogbo àwùjọ ẹ̀yà-ìran ṣe ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. Ìwọ yóò rí ìfẹ́ aládùúgbò lẹ́nu iṣẹ́ bí wọ́n ti ń pòkìkí ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. Bẹ́ẹ̀ni, àti nínú àwọn ìjọ wọn, ìwọ yóò pàdé àwọn ènìyàn onínúure, olótìítọ́-ọkàn tí wọ́n fihàn nípa ìgbésí-ayé wọn pé wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn nítòótọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Nínú àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ìwọ yóò rí àwọn ènìyàn aláyọ̀ láti inú ẹ̀yà gbogbo wá
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Dídé Aláàánú Ará Samaria náà sí Ilé Èrò/The Doré Bible Illustrations/Dover Publications, Inc.