Ìgbésí Ayé Tó Dára—Nísinsìnyí àti Títí Láé
ÌGBÉSÍ AYÉ rẹ lè dára nísinsìnyí pàápàá. Lọ́nà wo? Ìyẹn tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára wọn.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí [èèyàn] máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”—ONÍWÀÁSÙ 2:24.
Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé, a lè ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ tó dáa tá a bá ṣe. Béèyàn bá wà nínú ìṣòro tó le gan-an pàápàá, èèyàn ṣì lè rí ìtẹ́lọ́rùn ní ìgbésí ayé ẹni nísinsìnyí téèyàn bá ṣe iṣẹ́ ní àṣekára àti pẹ̀lú òótọ́ inú.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—ÌṢE 20:35.
Ọ̀pọ̀ ti rí i pé, fífi àkókò àti okun àwọn ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn tó wà nínú ìṣòro ti ṣe àwọ́n láǹfààní gan-an, ó sì ti mú kí wọ́n túbọ̀ gbádùn ìgbésí ayé wọn. Sólómọ́nì sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.”—Òwe 3:27.
Kíyè sí àpẹẹrẹ Ralph. Nígbà tó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, ó dara pọ̀ mọ́ ìyàwó rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn máa ń lo àkókò tó pọ̀ lóṣooṣù láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ralph sọ pé, “Nígbà tá a bá délé nírọ̀lẹ́, ó máa ń rẹ̀ wá gan-an, rírẹ̀ yìí kì í ṣe nítorí pé àgbà ti dé, àmọ́ ó jẹ́ nítorí pé a ti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu ìjọsìn wa sí Bàbá wa ọ̀run. Rírẹ̀ tó dára gan-an lèyí jẹ́!” Inú òun àti ìyàwó rẹ̀ ń dùn nítorí pé wọ́n ń fi àkókò wọn ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—ÒWE 17:17.
Ìṣòro máa ń rọrùn láti fara dà tí èèyàn bá rẹ́ni fọ̀rọ̀ lọ̀. Ọ̀gbẹ́ni Francis Bacon tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó máa ń kọ àròkọ sọ pé téèyàn ò bá lọ́rẹ̀ẹ́, “ńṣe ní ayé máa dà bí ìgbà téèyàn sọ nù sínú aginjù.” Béèyàn bá ní ọ̀rẹ́ tòótọ́, tí èèyàn náà sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́, èyí lè mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ rọrùn fúnni, kí ó gbádùn mọ́ni, á sì jẹ́ kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—MÁTÍÙ 5:3.
Ohun tí Jésù ń sọ níbí yìí ni pé, kéèyàn tó lè gbádùn àwọn ìlérí Ọlọ́run, ó yẹ kéèyàn fọwọ́ tó ṣe pàtàkì mú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwa èèyàn yàtọ̀ sí àwọn ẹranko, nítorí pé ó máa ń wù wá láti mọ ìdí tá a fi wà láyé. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló lè ṣèrànwọ́ fún wa lórí ọ̀ràn yìí, Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló sì ń lò láti ràn wá lọ́wọ́. Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé. Ó sọ ìdí tá a fi wà ní ayé, ìdí tí ìyà fi pọ̀ báyìí àti ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe. Ó ṣe pàtàkì pé ká lóye irú àwọn òtítọ́ tí Ìwé Mímọ́ sọ yìí kí ìgbésí ayé wa bàa lè dára, ká sì lè ní ìtẹ́lọ́rùn. Àwọn tó máa ń wá àyè láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì tí wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò máa ń láyọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé, wọ́n ń mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀” túbọ̀ dára sí i.—1 Tímótì 1:11.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí . . . kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé, tàbí tí àwọn ọdún náà yóò dé nígbà tí ìwọ yóò wí pé: ‘Èmi kò ní inú dídùn sí wọn.’”—ONÍWÀÁSÙ 12:1.
Àmọ̀ràn yìí tí Sólómọ́nì Ọba fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n lè má mọ̀ pé àjálù lè ṣẹlẹ̀ síni ní ìgbésí ayé lè ṣe gbogbo wa láǹfààní. Gbájú mọ́ jíjọ́sìn Ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbésí ayé rẹ. Èyí ló máa mú kí ìgbésí ayé rẹ túbọ̀ dára. Má ṣe fàyè gba èrò táwọn èèyàn máa ń ní pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́ríńtì 15:32) Ìwé Oníwàásù 8:12 sọ pé, tó o bá fi Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, nǹkan “yóò dára fún” ẹ.
Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Wendi rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tó wà ní kékeré, òun àti àbúrò rẹ̀ obìnrin kọ́ èdè Sípáníìṣì kí wọ́n bàa lè lọ sí orílẹ̀-èdè Dominican Republic, nítorí pé wọ́n nílò àwọn èèyàn púpọ̀ níbẹ̀ láti máa wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wendi sọ pé, “Ọ̀pọ̀ nǹkan la pa tì ká bàa lè lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀, àmọ́ a gbádùn àkókò yẹn gan-an ni. Kò sí nǹkan míì tí mo rò pé ó tọ́ láti fi oṣù mẹ́fà yẹn ṣe! Àwọn àǹfààní tá a rí pọ̀ gan-an ju ohun tá a pa tì lọ.”
Jíjẹ́ Olóòótọ́ sí Ọlọ́run Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Ẹni Dára
Níní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà lè mú kí ìgbésí ayé rẹ dára lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Lọ́nà wo? Yàtọ̀ sí pé Sátánì mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Ọlọ́run, ó tún sọ pé, kò sẹ́nì kankan tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tí wọ́n bá rí àdánwò. (Jóòbù 1:9-11; 2:4) Ìwọ náà lè ṣe ipa tìrẹ láti fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa! Báwo lo ṣe máa ṣe é? Bó o ṣe máa ṣe é ni pé, kó o jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kó o máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, kó o sì máa fi hàn pé o gbà pé, Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún wa pé ohun kan jẹ́ rere tàbí ó jẹ́ búburú.—Ìṣípayá 4:11.
Tá a bá fẹ́ máa ṣe ohun tó tọ́, ó lè gba pé ká fara da àwọn ìṣòro. Ṣé àwọn ìṣòro yẹn kò ní jẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa? Jẹ́ ká sọ pé, ọ̀tá kan tó jẹ́ òǹrorò ń sọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ tàbí ará ilé wa kan láìdáa. Bí ọ̀tá wa yìí bá hàn wá léèmọ̀ torí pé a gbèjà èèyàn wa, ǹjẹ́ ìyẹn á mú ká pàdánù ayọ̀ wa? Ó dájú pé a kò ní pàdánù rẹ̀! Tayọ̀tayọ̀ la máa fi fara da ìṣòro náà ká lè mú ẹ̀gàn yẹn kúrò. Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn tá a bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ lákòókò tí ayé kún fún ìwà ibi yìí, a óò máa múnú Ọlọ́run dùn.—Òwe 27:11.
Ìgbésí Ayé Tó Dára Títí Láé
Nítorí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti mọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Nígbà tí Ọlọ́run bá ti ṣe ohun tó ní lọ́kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ fún ayé, àwọn olóòótọ́ yóò gbádùn ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó dá èèyàn, ìyẹn ni pé kí wọ́n ní “ìyè àìnípẹ̀kun” lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà yẹn, ìgbésí ayé àwọn èèyàn á dára gan-an, wọ́n á sì ní ìtẹ́lọ́rùn.—Sáàmù 145:16.
Ibo lo ti lè rí ìmọ̀ tí Jésù sọ? Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Tó o bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ yìí, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí. Inú wọn á dùn, wọ́n á sì ṣètò pé kí ẹnì kan wá ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye ohun tí Bíbélì kọ́ni.