Ori 12
“Awọn Ọjọ Ikẹhin” ati Ijọba Naa
1. (a) Awọn ibeere pataki wo ni wọn dide nisinsinyi? (b) Ki ni Ìwé Mímọ́ wí nipa ọjọ ikẹhin [i] fun ilẹ̀-ayé wa, [ii] fun awọn wọnni tí ń pa á run?
AWA ha ń gbé ní “awọn ọjọ ikẹhin” nisinsinyi bi? Ki ni “awọn ọjọ ikẹhin” tumọsi? Lọna ti ó dunmọni, ki yoo sí “awọn ọjọ ikẹhin” kankan fun ilẹ̀-ayé fúnraarẹ̀. Nitori Bibeli mú un dá wa lójú pe: “Ayé . . . kò lè ṣípòpadà laelae.” Ní ibamu pẹlu ete Jehofa ni ipilẹṣẹ, iwalaaye eniyan ati ti ẹranko ni a ó mú ki o maa baa lọ níhìn-ín titi gbére. (Orin Dafidi 104:5-24; 119:89, 90; Genesisi 1:27, 28; 8:21, 22) Bi ó ti wù ki ó rí, dajudaju “awọn ọjọ ikẹhin” wà fun awọn orilẹ-ede ati awọn eniyan buruku wọnyẹn tí ń pa ilẹ̀-ayé Ọlọrun run. ‘Dídé’ Ijọba naa ni yoo mú iparun débá awọn eniyan tí ń fà iparun wọnyẹn.—2 Peteru 3:3-7; Jakọbu 5:1-4; Ìfihàn 11:15-18.
2. Ní pataki ki ni Paulu sọtẹlẹ fun “awọn akoko bibanilẹru” wa?
2 Awa ha lè maa gbé ninu “awọn ọjọ ikẹhin” wọnyẹn nisinsinyi bi? Iwọ ṣáà gbé itumọ Bibeli eyikeyii ki o sì kà ohun tí Ọlọrun mísí aposteli Paulu lati sọtẹlẹ nipa “awọn ọjọ ikẹhin,” ninu Timoteu Keji ori 3, ẹsẹ 1 si 5. Nigba naa beere lọwọ araarẹ pe, Eyi ha ni bi ayé araye ṣe rí lonii bi? Níhìn-ín, aposteli naa sọtẹlẹ nipa “awọn akoko bibanilẹru,” ó sì fikun un pe:
“Awọn eniyan yoo jẹ́ olufẹ araawọn, olufẹ owó, olùṣògo, agberaga, ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú, aṣaigbọran si awọn obi wọn, alaimoore, aláìmọ́, alainifẹẹ, alaikiidarijini, afọrọ-eke banijẹ, alainikora-ẹni-nijaanu, òǹrorò, alainifẹẹ ohun daradara, aládàkàdekè, oníwàǹwara, ajọra-ẹni-lójú, awọn olufẹ adùn dipo jíjẹ́ olufẹ Ọlọrun—wọn ní aworan-irisi ìwà-bí-Ọlọrun ṣugbọn wọn sẹ́ agbara rẹ̀. Maṣe ní ajọṣepọ kankan pẹlu wọn.”—New International Version.
3. Eeṣe tí Paulu fi nilati maa tọkasi “awọn ọjọ ikẹhin” tí ó tubọ ṣe pataki jù ti eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Ju wọnni?
3 Ní kikọ ohun tí ó wà loke yii, aposteli naa kò tọkasi “awọn ọjọ ikẹhin” eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Ju. Eyiini kò lè rí bẹẹ, nitori pe Paulu kọ awọn ọ̀rọ̀ wọnyẹn ní nǹkan bii ọdun 65 C.E., nigba tí eyi tí ó jù 30 ọdun “awọn ọjọ ikẹhin” wọnni ti fẹrẹẹ pari tán, tí ó sì kù ọdun marun-un péré ṣaaju iparun Jerusalemu. Bẹẹ si ni ipò ìpẹ̀hìndà yii kò tíì dide laaarin awọn tí wọn sọ pe Kristian ni wọn. “Awọn ọjọ ikẹhin” eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Ju wọnni ti buru pupọ tó, ṣugbọn awọn iṣẹlẹ nigba “awọn ọjọ ikẹhin” gbogbo eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani yoo ta wọn yọ jàn-àn-ràn-jan-an-ran, nigba tí Jesu yoo pada dé lati gbé Ijọba rẹ̀ kalẹ.
IMUṢẸ ONÍṢẸ̀Ẹ́PO MÉJÌ
4. Ki ni fàá tí awọn ọmọ-ẹhin fi beere ibeere tí ó wà ninu Matteu 24:3?
4 Ninu àkàwé rẹ̀, Jesu ti sọrọ nipa “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” (Matteu 13:39, 40, 49, NW) Gẹgẹ bi ó ti bá ìwà ẹ̀dá mu, eyi ru ọkàn-ìfẹ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ soke, ati ní pataki gẹgẹ bi awọn mẹ̀kúnnù ti ń jiya pupọ tobẹẹ, àní nigba naa, lati ọ̀wọ́ iṣakoso oníkà ti Romu ati ti awọn aṣaaju isin Ju. Wọn reti pe Ijọba Ọlọrun yoo mú itura wá. Nitori naa, ọjọ mẹta ṣaaju ki a tó pa Jesu, mẹrin ninu awọn ọmọlẹhin sunmọ ọn bi ó ti jokoo lori Oke Olifi, tí ó dojukọ Jerusalemu, wọn sì bi i léèrè pe: “Sọ fun wa, Nigba wo ni nǹkan wọnyi yoo ṣẹ, ki ni yoo sì ṣe ami wíwàníhìn-ín rẹ̀ ati ti ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan?”—Matteu 24:3, NW; Marku 13:3, 4.
5. Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ tí Jesu fi fèsì yoo ṣe ní imuṣẹ?
5 Bi ó tilẹ jẹ́ pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu ń ronu nipa ọjọ-iwaju tí kò jinna, èsì Jesu ní akoko-iṣẹlẹ yẹn yoo ní itumọ oníṣẹ̀ẹ́pò méjì: èkínní nigba “awọn ọjọ ikẹhin” eto-igbekalẹ awọn nǹkan Ju, ati, igba pípẹ́ lẹhin naa, nigba “awọn ọjọ ikẹhin” eto-igbekalẹ ayé Satani ti o ni ninu gbogbo ibi tí eniyan ń gbé lori ilẹ̀-ayé patapata-porogodo.
6, 7. (a) Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu ninu Matteu 24:7-22 ṣe ní imuṣẹ ráńpẹ́? (b) Irannileti mímúná wo nipa eyi ni ó ṣì wà titi di isinsinyi?
6 Ohun tí Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin wọnni, gẹgẹ bi a ti kọ ọ silẹ ninu Matteu 24, ẹsẹ 7 si 22, ṣapejuwe ipa-ọna awọn iṣẹlẹ tí awọn kan ninu wọn yoo kíyèsíi lọna kekere jálẹ̀ 37 ọdun tí ó tẹle e titi dé 70 C.E. Fun awọn Ju ti iran Jesu, yoo jẹ́ igba yánpọnyánrin ti ogun, àìtó ounjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, ikoriira awọn Kristian ati ifarahan awọn eke Messia. Sibẹ “ihinrere ijọba yii” ni a ó waasu laaarin gbogbo ẹ̀dá gẹgẹ bi ẹ̀rí. Lákòótán, ‘ohun ìsúni-fún-ìríra’ yẹn, ẹgbẹ-ọmọ-ogun Romu abọriṣa naa, dajudaju kọlu “ibi mimọ” naa ni tẹmpili Jerusalemu. Lẹhin ìpadàsẹ́hìn kukuru kan, nigba tí ó fi ṣeeṣe fun awọn ọmọ-ẹhin Jesu lati ṣe igbọran si aṣẹ alasọtẹlẹ rẹ̀ nipa sísá lọ sori oke fun aabo, awọn ara Romu tún dé lẹẹkan sii labẹ Ọgagun Titus. Wọn run Jerusalemu ati awọn ọmọ rẹ̀ wómúwómú, wọn sì wó tẹmpili rẹ̀ palẹ̀, laifi okuta kan silẹ sori okuta miiran.—Tún wo Luku 19:43, 44; Kolosse 1:23.
7 Ní imuṣẹ “ami” Jesu, ìwọ́jọpọ̀ awọn ìjàngbọ̀n wọnyi pọ́n awọn Ju lójú, ó sì dé òtéńté rẹ̀ ninu iparun Jerusalemu ninu iná ní 70 C.E. Ó ju aadọta ọkẹ awọn Ju tí wọn ṣègbé pẹlu ilu wọn, awọn olulaaja ni a sì kó lọ ní ẹrú. Ẹnu ọna rìbìtì ti ijagunmolu Titus wà ní Romu titi di òní gẹgẹ bi irannileti mímúná nipa imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu. Bi ó ti wù ki ó rí, a ha kọ “ami” Jesu silẹ tí a sì tọju rẹ̀ pamọ ninu akọsilẹ gẹgẹ bi ikilọ kìkì fun awọn eniyan tí wọn gbé ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní nikan bi? Ó ha jẹ́ ‘òkú ìtàn’ kan lasan lonii bi? Idahun naa gbọdọ jẹ́, Bẹẹkọ!
ITUMỌ TÍ Ó KAN GBOGBO AYÉ
8. (a) Iyọrisi wo ni imuṣẹ awọn ọ̀rọ̀ Jesu lọna kekere yẹ ki ó ní lori wa lonii? (b) Awokọṣe alasọtẹlẹ awọn ohun titobiju wo ni eyi pese?
8 Imuṣẹ awọn ọ̀rọ̀ Jesu lọna kekere nigba “awọn ọjọ ikẹhin” eto-igbekalẹ awọn nǹkan Ju gbọdọ ṣiṣẹ lati fun igbagbọ wa lókun ninu agbara asọtẹlẹ atọrunwa. Bi ó ti wù ki ó rí, awọn iṣẹlẹ ọ̀rúndún kìn-ín-ní wọnyi tún pese apẹẹrẹ awokọṣe alasọtẹlẹ yiyanilẹnu nipa ohun tí yoo ṣẹlẹ lọna ti o tubọ gbooro sii nipa eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani kari-ayé. Eyi gbọdọ rí bẹẹ, nitori pe imuṣẹ idajọ Ọlọrun lori Jerusalemu ní 70 C.E. kii ṣe ipọnju ti o ti tobi julọ titi di akoko naa, bẹẹ ni kii si ṣe oun ni o kẹhin. Awọn ọ̀rọ̀ Jesu ninu Matteu 24:21, 22 ń durode imuṣẹ wọn ní kíkún:
“Nitori nigba naa ni ipọnju nla yoo wà, iru eyi tí kò sí lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwà di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ̀ ki yoo sì sí. Bi kò sì ṣe pe a ké ọjọ wọnni kúrú, kò sí ẹ̀dá tí ìbá lè là á; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ ni a ó fi ké ọjọ wọnni kúrú.”
9. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe awọn ọ̀rọ̀ Jesu ń tọkasi ọjọ ìjíhìn kan tí ó kárí-ayé?
9 Awọn ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ Jesu tí ń báa nìṣó, ninu Matteu 24:23–25:46, pẹlu fihan pe ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan’ yoo jẹ́ kárí-ayé. Ní òtéńté akoko wahala naa, nigba tí “Ọmọ-eniyan,” gẹgẹ bi ọba tí Ọlọrun ti gbeka ori ìtẹ́, bá mú idajọ ṣẹ sori ayé Satani, “gbogbo ẹya ayé yoo káàánú.” Eyiini yoo kan gbogbo araye tí wọn kọ̀ ipò ọba Jesu silẹ. Kii ṣe idajọ kan tí ó kan kìkì orilẹ-ede kanṣoṣo péré ati ilu rẹ̀, bikoṣe ọjọ ìjíhìn kan tí ó kárí-ayé.—Matteu 24:30.
10. (a) Gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ ninu asọtẹlẹ Jesu, bawo ni àtúnbọ̀tán awọn wọnni ‘tí wọn ń ṣe bi ó ti wù wọn’ ṣe yatọ si ti ‘awọn tí ń wá ijọba Ọlọrun kiri ṣaaju’? (b) Eeṣe tí eyi fi nilati jẹ́ ohun tí ó kárí-ayé?
10 Lẹẹkan sii ní titọka si bi idajọ Ọlọrun yoo ṣe gbooro kárí-ayé tó, asọtẹlẹ Jesu ń báa lọ lati ṣe ifiwera ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan’ pẹlu akoko tí ó wà ní gẹ́rẹ́ ṣaaju Ikun-omi ọjọ Noa, ní wiwi pe:
“Nitori pe bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kíkún omi, tí wọn ń jẹ, tí wọn ń mu, tí wọn ń gbé iyawo, tí a sì ń fà iyawo funni, titi ó fi di ọjọ tí Noa fi bọ́ sinu ọkọ̀, wọn kò sì mọ̀ titi omi fi dé, tí ó gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹẹ ni [wíwàníhìn-ín, NW] Ọmọ-eniyan yoo rí pẹlu.”
Àní gan-an gẹgẹ bi Ikun-omi akoko naa ti gbá gbogbo ayé awọn eniyan aláìwà-bí-Ọlọrun lọ yán-án-yán-án, bẹẹ gẹgẹ ni ipọnju ti ń jó bi ina naa ti o jẹ otente “wíwàníhìn-ín” Messia yoo ṣe gbá gbogbo awọn wọnni ti wọn dagunla si Ijọba naa nitori ‘ṣiṣe ohun ti o wù wọn’ kuro lori ilẹ̀-ayé. Lọna ti ó dunmọni, pupọ awọn eniyan tí wọn ti ‘wá ijọba Ọlọrun ati ododo kiri ṣaaju’ yoo laaja lati jogún ìyè ainipẹkun ninu paradise ilẹ̀-ayé. Iwọ yoo ha jẹ́ ọ̀kan lara awọn wọnyi bi?—Matteu 6:33; 24:37-39; 25:31-46.
11. Awọn asọtẹlẹ miiran wo ni ó fihan pe yoo kan gbogbo awọn orilẹ-ede, ati pe awọn olulaaja yoo wà?
11 Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn asọtẹlẹ Bibeli fihan pe “ipọnju nla” naa tí ń bọ̀ yoo kàn “gbogbo orilẹ-ede” ayé. (Orin Dafidi 2:2-9; Isaiah 34:1, 2; Jeremiah 25:31-33; Esekieli 38:23; Joeli 3:12-16; Mika 5:15; Habakkuku 3:1, 12, 13) Ṣugbọn awọn olulaaja yoo wà.—Isaiah 26:20, 21; Danieli 12:1; Joeli 2:31, 32.
WÍWÀNÍHÌN-ÍN ỌBA NAA NINU ÒGO TI ỌRUN
12. (a) Eeṣe tí “ami” wíwàníhìn-ín Jesu fi pọndandan? (b) Eeṣe tí kò fi ní di dandan fun un lati farahan lẹẹkan sii ninu ẹran-ara?
12 Asọtẹlẹ nla Jesu nipa “ami” wíwàníhìn-ín rẹ̀ sọ fun wa pe “nigba tí Ọmọ-eniyan yoo wá ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mímọ́ pẹlu rẹ̀, nigba naa ni yoo jokoo lori ìtẹ́ ògo rẹ̀.” (Matteu 25:31) Niwọn bi dídányanran ògo naa yoo ti ṣe ipalara fun ojú-ìríran eniyan, Ọba naa nilati jẹ́ aláìṣeéfojúrí fun araye. (Fiwe Eksodu 33:17-20; Heberu 12:2.) Idi niyẹn tí a fi ń fẹ́ ‘ami wíwàníhìn-ín rẹ̀.’ Nigba wíwá Messia lẹẹkeji kò tún ní pọndandan fun un mọ́ lati fi iwalaaye rẹ̀ gẹgẹ bi ẹda ẹmi ni ọrun silẹ ki ó baa lè farahan lori ilẹ̀-ayé ninu ẹran-ara, fun lílò gẹgẹ bi “ẹbọ ẹṣẹ.” Niwọn bi ó ti pese ẹbọ eniyan rẹ̀ lẹẹkan “fun gbogbo igba,” yoo dé “lẹẹkeji . . . laisi ẹṣẹ” gẹgẹ bi ọba ọrun alaiṣeefojuri kan.—Heberu 7:26, 27; 9:27, 28; 10:8-10; 1 Peteru 3:18.
13. Ki ni Luku 19:11-27 fihan nipa akoko tí Jesu padabọ ati itẹwọgba rẹ̀ laaarin awọn orilẹ-ede?
13 Ní òru rẹ̀ tí ó kẹhin pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ timọtimọ, Jesu ti sọ fun wọn pe: “Emi ń lọ pese àyè silẹ fun yin. Bi mo bá sì lọ pese àyè silẹ fun yin, emi yoo tún pada wá, emi yoo sì mú yin lọ sọdọ emi tikaraami.” (Johannu 14:2, 3) Ní ibamu pẹlu eyi, àkàwé Jesu ninu Luku 19:11-27 ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi “ọkunrin ọlọ́lá kan [tí ó] rè ilu òkèèrè lọ igbà ijọba fun araarẹ̀, ki ó sì pada.” Eyi yoo gbà akoko gígùn kan. Ṣugbọn “awọn ọlọ̀tọ̀ ilu rẹ̀ koriira rẹ̀, wọn sì rán ikọ̀ tẹle e, wi pe, Awa kò fẹ́ ki ọkunrin yii jọba lori wa.” Bẹẹ gẹgẹ, awọn eniyan wà lonii tí wọn sọ pe Kristian ni wọn, ṣugbọn tí wọn kọ “Ọba awọn ọba” silẹ ni yíyàn lati gbé iṣakoso eniyan aláìpé tiwọn funraawọn kalẹ. (Ìfihàn 19:16) Gẹgẹ bi awọn “ọlọ̀tọ̀” inu àkàwé Jesu, awọn wọnyi ni a ó fi ìyà jẹ lọna mímúná.
“IPILẸṢẸ IPỌNJU”
14. Laibikita fun atako ní ilodisi, ki ni awọn ohun tí ó ṣe itilẹhin fun ọdun 1914 C.E. gẹgẹ bi ọdun tí Kristi padabọ?
14 Nigba wo ni Ọba alagbara-nla yii, tí awọn orilẹ-ede kò fẹ́, bẹrẹsi ṣakoso lori ayé wa? Gbogbo ẹri, tọkasi ọdun naa 1914 C.E. Ṣugbọn ẹnikan lè fàáké-kọ́rí, ní wiwi pe, ‘Dipo mímú iṣakoso alaafia ti Kristi wọle dé, ọdun yẹn sami si ibẹrẹ sanmani oníjàngbọ̀n kan fun araye!’ Kókó naa gan-an niyẹn! Nitori pe, gẹgẹ bi asọtẹlẹ Bibeli ti wi, nigba tí ‘ijọba ayé bá di ijọba Jehofa Oluwa wa ati Kristi rẹ̀’ ni ‘inu yoo bí’ awọn orilẹ-ede ayé. (Ìfihàn 11:15, 18) Ó sì tún jẹ́ akoko naa pẹlu nigba tí Jehofa rán ajumọ jọba rẹ̀ jade, wi pe, “Iwọ jọba laaarin awọn ọ̀tá rẹ.” (Orin Dafidi 110:1, 2) Ṣugbọn awọn ọ̀tá wọnni ni a kò parun lẹsẹkẹsẹ.
15. Bawo ni Ìfihàn ori 12 ṣe ṣapejuwe ìbí Ijọba naa lọna ti o baamu wẹku?
15 Ìfihàn ori 12 ṣapejuwe iran yiyanilẹnu kan ninu eyi tí aposteli Johannu rí ìbí Ijọba Messia Ọlọrun lọna àmì. Gẹgẹ bi ọmọ-ọkunrin kan, eyi ni a mú jade lati ọ̀dọ̀ “obinrin” Ọlọrun—eto-ajọ awọn ẹda angẹli rẹ̀ ní ọrun. A sì gbà á “lọ soke sọdọ Ọlọrun, ati si ori ìtẹ́ rẹ̀,” nitori pe Ijọba naa nilati gbarale Jehofa ati ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ fun iṣiṣẹ rẹ̀.—Ìfihàn 12:1-5.
16, 17. (a) Ki ni fà awọn ègbé ori ilẹ̀-ayé lati 1914? (b) Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu ninu Matteu ati Luku ṣe ṣapejuwe ibẹrẹ awọn wahala wọnyi?
16 Tẹle eyi, ogun bẹ́sílẹ̀ ní ọrun! Ọba tí a gbeka ori ìtẹ́ naa ati awọn angẹli rẹ̀ bá Satani ati ẹgbẹ-ogun awọn ẹmi eṣu rẹ̀ jagun, wọn sì lé awọn wọnyi jade kuro ní ọrun ti Jehofa si agbegbe ilẹ̀-ayé wa. Nitori eyi, “Ègbé ni fun ayé ati fun òkun! nitori Eṣu sọkalẹ tọ̀ yin wá ní ibinu nla, nitori ó mọ̀ pe igba kukuru ṣá ni oun ní.” (Ìfihàn 12:7-12) Ní sáà “igba kukuru” naa, Ọba ń kó awọn eniyan tí wọn ní ifẹ si ododo jọ fun igbala tí ó sì ń ṣe ikilọ ìmúdàájọ́ṣẹ tí ó sunmọle gírígírí lori eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti ayé Satani.—Matteu 24:31-41; 25:31-33.
17 Lonii awa ń rí imuṣẹ “ami” Jesu, gẹgẹ bi a ti tò ó lẹsẹẹsẹ ninu Matteu ori 24 ati 25, Marku ori 13 ati Luku ori 21. Ṣakiyesi pe níhìn-ín Jesu ṣapejuwe “ipilẹṣẹ ipọnju,” ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi:
“Orilẹ-ede yoo dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: ìsẹ̀lẹ̀ nla yoo sì wà kaakiri, ati ìyàn ati ajakalẹ-arun; ohun ẹ̀rù, ati ami nla yoo sì ti ọrun wá.” (Matteu 24:3, 7, 8; Luku 21:10, 11)
Ǹjẹ́ irufẹ “ipọnju” bẹẹ ha ti ń yọ araye lẹ́nu lati 1914 C.E. siwaju bi?
18. Lati 1914, bawo ni ogun ṣe di ohun ẹ̀rù jẹ̀njẹ̀n?
18 Ní ọdun 1914 ni Ogun Nla naa (tí a pè ní “Ogun Agbaye I” lẹhin naa) bẹsilẹ, ati pẹlu rẹ̀ ni ajakalẹ-arun ati ìyàn dé. Ó ti ṣoro fun awọn onkọwe lati ṣapejuwe ìpáyà ńláǹlà tí ó gbà gbogbo pápá ijagun kan, bi araadọta ọkẹ ti ń ṣegbe ninu ihò ìjagun nigba ipakupa ti 1914 si 1918. Ninu iwe naa Eye Deep in Hell, Paul Nash ni a fà ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nigba tí ó ń sọrọ nipa pápá-ogun Europe pe: “Kò sí kálámù tabi aworan kankan tí ó lè ṣalaye orilẹ-ede yii—bi itolẹsẹẹsẹ ogun ti ń ṣẹlẹ lọ́sàn-án ati lóru, oṣu kan tẹle omiran. Iwa-ibi ati ìwà-ìkà tí ó gbé àwọ̀ eniyan wọ̀ nikan ni ó lè jẹ́ ọ̀gá ogun yii, kò sì sí itanṣan ọwọ́ Ọlọrun tí a rí nibikibi. . . . Awọn ẹ̀tù-abúgbàù kò figba kan dẹ́kun . . . pipanirun yán-án-yán-án, sisọni di aláàbọ̀-ara, sísínni níwín, wọn ń fi ipa muni lọ sinu sàréè tii ṣe ilẹ yii; sàréè titobi ràkàfò kan, ti wọn ń da oku awọn alainiranlọwọ eniyan sinu rẹ̀. Ó jẹ́ alaiṣeefẹnusọ, alaiwa-bi-Ọlọrun, alainireti.”
19. Ki ni awọn isọfunni-oniṣiro fihan niti igasoke awọn ìsẹ̀lẹ̀ lati 1914?
19 Pẹlupẹlu, “ìsẹ̀lẹ̀” jẹ́ apakan “ami” naa. Awọn ìsẹ̀lẹ̀ ha ti ga soke sii lati 1914 bi? Eyi lè jẹ́ iyalẹnu. Ṣugbọn awọn isọfunni-oniṣiro paapaa tilẹ tún yanilẹnu jù! Gẹgẹ bi Geo Malagoli ti sọ ninu Il Piccolo: “Laaarin sáà 1,059 ọdun (lati 856 si 1914) awọn orisun tí ó ṣeegbarale ṣe akọsilẹ kìkì 24 ìsẹ̀lẹ̀ pataki-pataki.” Akọsilẹ rẹ̀ fihan pe laaarin awọn ọdun wọnyẹn ipindọgba 1,800 eniyan ni wọn kú lọ́dún kọọkan ninu ìsẹ̀lẹ̀, nigba tí ó jẹ́ pe 43 awọn ìsẹ̀lẹ̀ titobi ni ó ti wà lati 1915, awọn wọnyi sì ti pa ipindọgba 25,300 eniyan lọ́dún kan.
“AMI NLA YOO SÌ TI ỌRUN WÁ”
20, 21. (a) Awọn “ohun ẹ̀rù” wo ni wọn ti farahan gbangba lati 1914, eesitiṣe? (b) Imuṣẹ Luku 21:25, 26 wo ni a rí lonii? (c) Bawo ni ‘awọn ami nla lati ọrun wá’ ṣe ń gbà afiyesi lọna tí ń pọ̀ sii?
20 Jesu tún sọtẹlẹ pẹlu pe: “Ohun ẹ̀rù, ati ami nla yoo sì ti ọrun wá.” (Luku 21:11) Ninu Ogun Agbaye I, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ẹ̀tù-abúgbàù alaidawọduro ti àgbá-ogun tọ́kasí ohun titun kan—ogun-jíjà àjàkú-akátá. Fun igba akọkọ, ọkọ̀ ogun ofuurufu ati lẹhin naa, lọna tí ó tún ṣe pataki jù, ọkọ̀ ofuurufu ṣí sanmani titun ti ìjagun lofuurufu silẹ. Nitootọ, ní 1914 si 1918, ibẹrẹ kan ni ó wulẹ jẹ́, ṣugbọn yoo yọrisi ipò naa tí Jesu ṣapejuwe siwaju sii ninu asọtẹlẹ rẹ̀, ní wiwi pe:
“Àmì yoo si wà ni oòrùn, ati ni oṣupa, ati ni ìràwọ̀; ati lori ilẹ̀-ayé idaamu fun awọn orilẹ-ede, [láìmọ̀ ọna abajade nitori híhó òkun ati ìrugùdù rẹ̀, NW]; àyà awọn eniyan yoo maa já fun ibẹru, ati ireti nǹkan wọnni tí ń bọ̀ sori ayé: nitori awọn agbara ọrun ni a ó mì tìtì.”—Luku 21:25, 26.
21 Ohun tí a fi ẹnu lasan pè ní iṣẹgun eniyan lori gbangba ojude ofuurufu ti pọkànpọ̀ sori “oòrùn ati oṣupa ati awọn irawọ,” awọn ami pe rẹ́rẹ́ fẹ́ rún sì ń bẹ pe awọn Alagbara Ogbontarigi ń pète lati lò awọn satẹlaiti fun ṣiṣe igbekalẹ awọn ibudo ológun nibi tí a o ti maa ta àtaré awọn ohun-ija ogun. Ṣugbọn ní bayii paapaa wọn ní imọ nipa bi a ti ń rọ̀jò awọn bọmbu atamátàsé agbókèèrè ṣọṣẹ́ lati gbangba ojude ofuurufu si ibibiki tí wọn bá yàn sọjú. Awọn àkójọ ohun-ija olóró atọmiki ti lọọlọọ, ti awọn orilẹ-ede tí wọn dojúùjàkọ araawọn ti tò jọ pelemọ, ti tó lati pa araye run yán-án-yán-án lọpọ igba leralera, a sì fojúdá a pe nigba tí ọ̀rúndún yii bá fi maa pari, nǹkan bii 35 orilẹ-ede ni o ṣeeṣe ki wọn ti dira pẹlu irufẹ awọn ohun ija ti ń panirun bẹẹrẹbẹ bẹẹ.
22. (a) Bawo ni “òkun” gidi naa ṣe ni ìhà titun kan lati 1914? (b) Ki ni awọn olóye eniyan kilọ nipa ewu tí ó dojukọ ilẹ̀-ayé wa?
22 “Òkun” naa, eyi tí ó ní àkọ̀tun irisi pẹlu imujade ọkọ̀ ogun abẹ omi ninu Ogun Agbaye I, eyi tí ó fa United States wọnú ogun naa, tilẹ tún ń muni ni imọlara ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ajalu ibi ti o pọ sii lonii. Awọn ọkọ̀ ogun abẹ omi tí wọn ti dira pẹlu ohun-ija atọmiki ti wà ní sẹpẹ́ nisinsinyi ninu awọn òkun. Kò si ilu-nla eyikeyii lori ilẹ̀-ayé tí o kọja ibi ti awọn àfọ̀njá agbókèèrè ṣọṣẹ́ naa lè dé. Iwe-irohin Times ti New York ti August 30, 1980, ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Marshall D. Shulman ògbógi kan ni U.S. State Department, ti o sọ pe ṣiṣeeṣe ki ogun atọmiki olóró bẹsilẹ “ni ó jọ bii pe yoo pọ̀ sii dipo ki ó dinku.” Ipolongo tí ó kún oju-iwe iwe-irohin Times ti New York ti March 2, 1980, eyi tí a ṣe agbátẹrù rẹ̀ nipasẹ awọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí ó jù 600 lọkunrin ati lobinrin, wi pe: “Ogun atọmiki olóró, kódà ọ̀kan tí ó ‘mọniwọn’ paapaa, yoo yọrisi iku, ipalara ati aisan lọna gbigbooro kan tí a kò tíì rí iru rẹ̀ rí ninu itan iwalaaye eniyan.” Wọn fikun un pe “ikọlura àjàkú-akátá kan pẹlu ohun-ija atọmiki olóró le pari ní wakati kan, ki ó sì pa iwalaaye tí ó pọ̀ julọ run ní ariwa ayé.” Ikọ̀ U.S. si Moscow, ní 1981, wi pe: “Mo woye pe ayé tubọ ń lewu sii ju bi ó ti jẹ́ rí ninu itan.” Ṣugbọn inawo lori awọn ohun-ija ti ń panirun bẹẹrẹbẹ ń baa lọ ni giga soke siwaju ati siwaju.
23. Ní imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu, ipò wo ni ó dabi pe arayé ti ń dé ninu itan?
23 Ó dabi ẹni pe araye ti ń dé ipele tí Harold C. Urey, ẹni ti o gba Ẹbun Nobel, sọtẹlẹ ni ọpọ ọdun sẹhin pe: “A ó maa jẹun ninu ibẹru, sùn ninu ibẹru, gbé ninu ibẹru, a ó sì kú ninu ibẹru.” Nitootọ, “idaamu awọn orilẹ-ede,” wà “láìmọ̀ ọna abajade . . . nigba tí awọn eniyan yoo maa dákú lati inu ibẹru ati ifojusọna fun awọn ohun tí ń bọ̀ wá sori ilẹ̀-ayé tí a ń gbé.”
24. Ta ni mọ̀ “ọna abajade,” eesitiṣe tí ó fi yẹ lati gbadura tọkantara fun ‘dídé’ Ijọba naa?
24 Ó munilayọ pe Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ, ẹni tí ó dá ayé yii fun ete rere rẹ̀, ‘mọ̀ ọna abajade,’ oun yoo sì pese ọna naa nipasẹ Ijọba Ọmọkunrin rẹ̀. Ṣugbọn ṣaaju ki a tó ṣe ayẹwo kúlẹ̀kúlẹ̀ “ọna abajade” naa, ẹ jẹ́ ki a tún pè afiyesi si asọtẹlẹ Jesu lẹẹkan sii, ki a sì ṣakiyesi bi awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nipa ogun agbaye, ìyàn ati ajakalẹ-arun, gẹgẹ bi awọn kókó “ami” naa, ti ṣedeedee lọna tí ó pẹtẹrí pẹlu asọtẹlẹ yiyanilẹnu kan tí ó wà ninu Ìfihàn. Ranti, Ijọba Ọlọrun nipasẹ Messia ni oògùn-àtúnṣe naa—Ijọba naa tí a ń fi tọkantara gbadura fun ‘dídé’ rẹ̀!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 115]
OHUN TÍ AWỌN OǸKỌ̀WÉ TI WÍ NIPA 1914
Ani lẹhin ogun agbaye keji paapaa, pupọ tọka pada si 1914 gẹgẹ bi iyipada ńláǹlà ninu itan ode-oni:
“Dajudaju 1914 dipo Hiroshima ni ó sami si iyipada pataki kan ní akoko wa.”—Rene Albrecht-Carrie, “The Scientific Monthly,” July 1951
“Lati 1914 wa, gbogbo ẹni tí bi awọn nǹkan ṣe ń lọ ninu ayé ń jẹlọkan ni a ti kó idaamu bá gidigidi nipasẹ ohun tí ó dabi ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́-rìn kan tí a ti kadara tí a sì ti pinnu tẹlẹ síhà ìjábá kan tí ó tubọ n buru sii. Ọpọlọpọ awọn eniyan onironu ti wá nimọlara pe kò si ohun tí a lè ṣe lati ṣe idiwọ fun iparun. Wọn rí iran eniyan, bii akọni inu eré Griki olopin ibanujẹ kan, tí awọn ọlọrun tí inu ń bí ń tì gọ̀ọ́gọ̀ọ́ tí oun kò sì tún lè ṣakoso àyànmọ́ mọ́.”—Bertrand Russell, New York “Times Magazine,” September 27, 1953
“Sanmani ode-oni . . . bẹrẹ ní 1914, kò sì sí ẹni tí ó mọ̀ igba tí yoo dopin tabi bi yoo ṣe dopin. . . . Ó lè pari si iparun yán-án-yán-án.”—Ọ̀rọ̀ olootu, ninu “The Seattle Times,” January 1, 1959
“Ní 1914 ni ayé, gẹgẹ bi a ti mọ̀ ọ́n tí a sì tẹwọgba á nigba naa, dopin.”—James Cameron, “1914,” tí a tẹjade ní 1959
“Ogun Agbaye Kìn-ín-ní jẹ́ ọ̀kan ninu awọn gìrì titobijulọ ninu itan.”—Barbara Tuchman, “The Guns of August,” 1962
“Awọn èrò ati aworan wá si ọkàn mi, . . . awọn ero lati inu awọn ọdun tí ó ṣaaju 1914 nigba tí alaafia tootọ, ìparọ́rọ́ ati ailewu wà lori ilẹ̀-ayé yii—akoko kan tí a kò mọ̀ ẹ̀rù. . . . Ailewu ati ìparọ́rọ́ ti pòórá ninu igbesi-aye awọn eniyan lati 1914.”—Oṣelu ara Germany naa Konrad Adenauer, 1965
“Gbogbo ayé niti gidi búgbàù nigba Ogun Agbaye I sibẹ a kò tíì mọ̀ eredi rẹ̀. . . . Eto-igbekalẹ pípé pérépéré wà nítòsí. Alaafia ati aásìkí ń bẹ. Nigba naa ni gbogbo nǹkan dàrú. A ti wà ní ipò ìsoríkọ́ lati igba naa wa.”—Dr. Walker Percy, “American Medical News,” November 21, 1977
“Ní 1914 ni ayé padanu ìgbọ́ra-ẹni-yé eyi tí kò tíì ṣeeṣe fun un lati gbà pada lati igba naa wa. . . . Eyi ti jẹ́ akoko idarudapọ ati ìwà-ipá yiyọyẹ, kii ṣe kiki rekọja awọn ààlà orilẹ-ede nikan ṣugbọn ninu wọn pẹlu.”—“The Economist,” London, August 4, 1979
“Ọ̀làjú ti wọ̀ inu aisan buruku kan ní 1914 boya ti o ṣeeṣe ki o ṣekupa á.”—Frank Peters, “Post-Dispatch” ti St. Louis, January 27, 1980
“Ohun gbogbo yoo kan maa dara si yùngba siwaju ati siwaju sii. Eyi ni ayé tí a bí mi sí. . . . Lojiji, lairotẹlẹ, ní owurọ kan ní 1914 gbogbo rẹ̀ wá si opin.”—Oṣelu ara Britain Harold Macmillan, New York “Times,” November 23, 1980