‘Kí Ni Yóò Ṣe Àmì Wíwàníhìn-Ín Rẹ?’
“Nígbà wo ni àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ, kí ni yóò sì ṣe àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?”—MATTEU 24:3, NW.
1, 2. Kí ni ó fihàn pé àwọn ènìyàn ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ọjọ́-ọ̀la?
Ọ̀ PỌ̀ ènìyàn ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ọjọ́-ọ̀la. Ìwọ náà ń kọ́? Nínú ìwé rẹ̀ Future Shock, Ọ̀jọ̀gbọ́n Alvin Toffler ṣàkíyèsí “ìbísí yanturu òjijì nínú iye àwọn ètò-àjọ tí a yàsọ́tọ̀ fún ṣíṣèwádìí nípa ọjọ́-ọ̀la.” Ó fikún un pé: ‘Àwa ti rí ìdásílẹ̀ àwọn àjọ-ẹgbẹ́ olùṣèwádìí tí wọ́n dálórí ọjọ́-ọ̀la; ìfarahàn àwọn ìwé ìròyìn tí ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la ní England, France, Italy, Germany àti United States; ìtànkálẹ̀ àwọn abala ẹ̀kọ́ nípa àsọbádé ní yunifásítì.’ Toffler parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Níti gidi kò sí ẹnìkan tí ó lè ‘mọ’ ọjọ́-ọ̀la ní ọ̀nà kan tí ó dájú hán-ún-hánún.”
2 Ìwé náà Signs of Things to Come sọ pé: “Wíwo ìlà-ọwọ́, wíwo díígí láti sọtẹ́lẹ̀, ìwòràwọ̀, títa káàdì láti mọ ọjọ́-ọ̀la, kíkàwé I Ching ni gbogbo wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àwọn ọ̀nà ọgbọ́n dídíjú láti fún wa ní èrò díẹ̀ nípa ohun náà gan-an tí ọjọ́-ọ̀la wa lè ní ní ìpamọ́.” Ṣùgbọ́n dípò yíyíjú sí àwọn ọ̀nà tí ènìyàn hùmọ̀, yóò sàn jù kí a yíjú sí orísun pípegedé kan—Jehofa.
3. Èéṣe tí ó fi jẹ́ ohun yíyẹ láti yíjúsí Ọlọrun fún ìmọ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la?
3 Ọlọrun òtítọ́ náà sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.” (Isaiah 14:24, 27; 42:9) Bẹ́ẹ̀ni, ó ti ṣeéṣe fún Jehofa láti fún aráyé ní ìmọ̀ràn nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà nípasẹ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ agbẹnusọ̀. Ọ̀kan lára àwọn wòlíì wọ̀nyí kọ̀wé pé: “Oluwa Ọlọrun kì óò ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n ó fi ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ han àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.”—Amosi 3:7, 8; 2 Peteru 1:20, 21.
4, 5. (a) Èéṣe tí Jesu fi lè ràn wá lọ́wọ́ nípa ọjọ́-ọ̀la? (b) Ìwádìí alápá púpọ̀ wo ní àwọn aposteli rẹ̀ ṣe?
4 Jesu Kristi ni wòlíì Ọlọrun tí ó gba ìwájú jùlọ. (Heberu 1:1, 2) Ẹ jẹ́ kí a darí àfiyèsí sí ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ṣíṣe pàtàkì ti Jesu tí ó sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká wa nísinsìnyí. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún mú kí a ní ìjìnlẹ̀-òye nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ bí opin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí ti ń parí lọ tí Ọlọrun yóò si fi paradise orí ilẹ̀-ayé kan rọ́pò rẹ̀.
5 Jesu fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ wòlíì. (Marku 6:4; Luku 13:33; 24:19; Johannu 4:19; 6:14; 9:17) Nípa báyìí, a lè lóye ìdí rẹ̀ tí àwọn aposteli rẹ̀, ní jíjókòó pẹ̀lú rẹ̀ lórí Òkè Olifi tí wọ́n sì ń wo Jerusalemu nísàlẹ̀, yóò fi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la pé: “Nígbà wo ni àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ, kí ni yóò sì ṣe àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?”—Matteu 24:3, NW; Marku 13:4.
6. Kí ni ìbátan tí ó wà láàárín Matteu 24, Marku 13, àti Luku 21; ìbéèrè wo ni a sì gbọ́dọ̀ fi ìháragàgà nífẹ̀ẹ́ sí?
6 Ìwọ yóò rí ìbéèrè wọn àti èsì Jesu ní Matteu orí 24, Marku orí 13, àti Luku orí 21.a Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà àwọn àkọsílẹ̀ náà jẹ́ àṣekún fún araawọn, ṣùgbọ́n wọn kò baramu délẹ̀délẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Luku nìkan ni o mẹ́nuba ‘àjàkálẹ̀-àrùn láti ibìkan sí ibòmíràn.’ (Luku 21:10, 11, NW; Matteu 24:7; Marku 13:8) Lọ́nà tí ó bá ọgbọ́n ìrònú mu, a níláti béèrè pé, Jesu ha ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ kìkì àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò wáyé ní àkókò ìgbésí-ayé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ni bí, tàbí o ha fi àkókò wa àti ohun tí ọjọ́-ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún wa kún un bí?
Àwọn Aposteli Fẹ́ Láti Mọ̀
7. Kí ni ohun náà ní pàtàkì tí àwọn aposteli béèrè nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n báwo ni èsì Jesu ti gbòòrò tó?
7 Ní ìwọ̀nba ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú kí a tó pa á, Jesu polongo pé Ọlọrun ti kọ Jerusalemu, olú-ìlú àwọn Ju sílẹ̀. Ìlú-ńlá náà àti tẹmpili rẹ̀ pípinmirin ni a ó parun. Nítorí náà díẹ̀ lára àwọn aposteli béèrè fún ‘àmì wíwàníhìn-ín Jesu àti ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.’ (Matteu 23:37–24:3, NW) Láìsí iyèméjì, pàtàkì ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju àti Jerusalemu, nítorí pé wọn kò lóye bí ohun tí ó wà níwájú ti gbòòrò tó. Ṣùgbọ́n ní dída wọn lóhùn Jesu wo jìnnà rékọjá ohun tí ó ṣẹlẹ̀ títí di 70 C.E. àti ìgbà yẹn, nígbà tí àwọn ará Romu pa Jerusalemu run.—Luku 19:11; Iṣe 1:6, 7.
8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé yóò bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹlẹ̀?
8 Gẹ́gẹ́ bí o ti lè kà á nínú àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìnrere mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, Jesu sọ̀rọ̀ nípa ìdìde orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀-ọba sí ilẹ̀-ọba, àìtó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, àwọn ìran bíbanilẹ́rù, àti àwọn àmì ní ojú ọ̀run. Ní àwọn ọdún tí ń bẹ́ láàárín àkókò tí Jesu fúnni ní àwọn àmì náà (33 C.E.) àti ìsọdahoro Jerusalemu (66 sí 70 C.E.), àwọn wòlíì èké àti èké Kristi yóò dìde. Àwọn Ju yóò ṣenúnibíni sí àwọn Kristian, tí wọ́n ń wàásù ìhìn-iṣẹ́ Jesu.
9. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ṣe ní ìmúṣẹ ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní?
9 Àwọn apá-ẹ̀ka àmì wọ̀nyí wáyé nítòótọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn bíi Flavius Josephus pàápàá ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀. Ó kọ̀wé pé ṣáájú kí àwọn ará Romu tó gbéjàkò wọ́n rárá, àwọn èké Messia ru ìṣọ̀tẹ̀ sókè. Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní Judea àti ní àwọn ibòmíràn. Ogun bẹ́ sílẹ̀ ní àwọn apá ibi púpọ̀ ní Ilẹ̀-Ọba Romu. Àwọn ìyàn ńlá ha mú bí? Bẹ́ẹ̀ni, nítòótọ́. (Fiwé Iṣe 11:27-30.) Ìwàásù Ìjọba náà ń kọ́? Ní 60 tàbí 61 C.E., nígbà tí a kọ ìwé Kolosse, “ìrètí ìhìnrere” Ìjọba Ọlọrun ni a ti gbọ́ lọ́nà gbígbòòrò ní Africa, Asia, àti Europe.b—Kolosse 1:23.
“NÍGBÀ NÁÀ” ni Òpin
10. Èéṣe tí a fi gbọ́dọ̀ ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ Griki náà toʹte, kí sì ní ìjẹ́pàtàkì rẹ̀?
10 Nínú àwọn ọ̀ràn kan, Jesu gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kalẹ̀ bí ẹni pé wọ́n ń ṣẹlẹ̀ ní ìtòtẹ̀léra. Ó wí pé: “A ó sì wàásù ìhìnrere ìjọba yìí . . . , nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Àwọn Bibeli lédè Gẹ̀ẹ́sì sábà máa ń lo “then” [nígbà náà] pẹ̀lú ìtumọ̀ rírọrùn náà “nítorí náà” tàbí “ṣùgbọ́n.” (Marku 4:15, 17; 13:23) Bí ó ti wù kí ó rí, ní Matteu 24:14 (NW), “nígbà náà” ní a gbékarí ọ̀rọ̀-àpọ́nlé èdè Griki náà toʹte.c Àwọn ògbóǹkangí nínú èdè Griki ṣàlàyé pé toʹte jẹ́ “ọ̀rọ̀-àpọ́nlé tí ń fi àkókò hàn” tí a ń lò “láti nasẹ̀ àkókò tí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ tẹ̀léra” tàbí “láti nasẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tẹ̀lé e.” Jesu tipa báyìí sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìwàásù Ìjọba kan yóò wà àti nígbà náà (‘lẹ́yìn ìyẹn’ tàbí ‘tẹ̀lé èyí’) “òpin” yóò sì dé. Òpin wo?
11. Báwo ni Jesu ṣe pa àfiyèsí pọ̀ sórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sopọ̀ ní tààràtà mọ́ ìparun Jerusalemu?
11 Ìmúṣẹ kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ni a lè rí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó jálẹ̀ sí òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju. Àwọn ogun, ìsẹ̀lẹ̀, àìtó oúnjẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ wáyé la àwọn ẹ̀wádún mẹ́ta já. Síbẹ̀, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Matteu 24:15, Marku 13:14, àti Luku 21:20, a kà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sopọ̀ ní tààràtà mọ́ ìparun sísúnmọ́lé gírígírí, nígbà tí òpin ti wà lẹ́nu ilẹ̀kùn.—Ṣàkíyèsí ìlà gígùn tótòtó ẹlẹ́yọkan lórí ṣáàtì.
12. Báwo ni ìmúṣẹ Matteu 24:15 ṣe ní àwọn ẹgbẹ́-ọmọ-ogun Romu nínú?
12 Ní ìhùwàpadà sí ìṣọ̀tẹ̀ kan láti ọ̀dọ̀ àwọn Ju ní 66 C.E., lábẹ́ Cestius Gallus àwọn ará Romu lọ láti gbógunti Jerusalemu, ní yíyí ìlú-ńlá tí àwọn Ju kà sí mímọ́ yìí ká. (Matteu 5:35) Láìka ìpadà gbéjàkoni láti ọ̀dọ̀ àwọn Ju sí, àwọn ará Romu fi ipá wọnú ìlú-ńlá náà. Lọ́nà yìí wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí “dúró ní ibi mímọ́,” gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọtẹ́lẹ̀ ṣáájú ní Matteu 24:15 àti Marku 13:14. Nígbà náà ni ohun kan tí ó ṣeni ní kàyéfì bẹ̀rẹ̀ síí farahàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti yí ìlú-ńlá náà ká, àwọn ará Romu náà fàsẹ́yìn lójijì. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn Kristian mọ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jesu dájú, ìfàsẹ́yìn náà sì yọ̀ǹda fún wọ́n láti sálọ sí Judea sórí àwọn òkè-ńlá tí ó wà ní òdìkejì Jordani. Ọ̀rọ̀-ìtàn sọ pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
13. Èéṣe tí ó fi ṣeéṣe fún àwọn Kristian láti kọbiara sí ìkìlọ̀ Jesu láti sálọ?
13 Ṣùgbọ́n bí àwọn ará Romu bá fàsẹ́yìn kúrò ní àyíká Jerusalemu, èéṣe tí ẹnikẹ́ni fi níláti sálọ? Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu fihàn pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ náà jẹ́ ẹ̀rí pé ‘ìsọdahoro Jerusalemu ti súnmọ́lé.’ (Luku 21:20, NW) Bẹ́ẹ̀ni, ìsọdahoro. Ó sàsọtẹ́lẹ̀ ‘ìpọ́njú irú èyí tí kò tíì wáyé rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ tí kì yóò sì tún wáyé mọ́.’ Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, ní 70 C.E., Jerusalemu ní ìrírí “ìpọ́njú ńlá” náà níti gidi láti ọwọ́ ẹgbẹ́-ọmọ-ogun Romu lábẹ́ Ọ̀gágun Titus. (Matteu 24:21, NW; Marku 13:19) Ṣùgbọ́n, èéṣe tí Jesu fi ṣàpèjúwe èyí gẹ́gẹ́ bí ìpọ́njú tí ó tóbi ju èyíkéyìí tí ó tíì ṣẹlẹ̀ ṣáájú tàbí láti ìgbà náà wá?
14. Èéṣe tí a fi lè sọ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalemu ní 70 C.E. jẹ́ “ìpọ́njú ńlá” irú èyí tí kò tíì wáyé tàbí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà yìí wá?
14 Jerusalemu ni àwọn ará Babiloni run bàjẹ́ ní 607 B.C.E., ìlú-ńlá náà sì ti rí ìjà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ nínú ọ̀rúndún wa yìí. Síbẹ̀, ohun tí ó wáyé ní 70 C.E. jẹ́ ìpọ́njú ńlá aláìlẹ́gbẹ́. Ní àkókò ogun tí ó gbà tó oṣù márùn-ún, àwọn jagunjagun Titus ṣẹ́gun àwọn Ju. Wọn pa nǹkan bíi 1,100,000 wọ́n sì kó iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 100,000 lẹ́rú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ará Romu wó Jerusalemu palẹ̀. Èyí fi ẹ̀rí hàn pé ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju tí a gbé ìjọsìn rẹ̀ tí ó ṣètẹ́wọ́gbà tẹ́lẹ̀ karí tẹ́ḿpìlì ti dópin títí gbére. (Heberu 1:2) Bẹ́ẹ̀ni, lọ́nà tí ó tọ̀nà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ 70 C.E. ni a lè kà sí ‘ìpọ́njú irúfẹ́ èyí tí kò tíì wáyé [sórí ìlú-ǹlá, orílẹ̀-èdè, àti ètò-ìgbékalẹ̀ yẹn] rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún wáyé mọ́.’—Matteu 24:21, NW.d
Gẹ́gẹ́ Bí A ti Sọtẹ́lẹ̀, Púpọ̀ Síi Ṣì Ń Bọ̀
15. (a) Irú àwọn ohun wo ni Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé yóò bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú tí ń bọ̀ sórí Jerusalemu? (b) Lójú-ìwòye ọ̀rọ̀ inú Matteu 24:23-28, kí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìparí èrò wa nípa ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jesu?
15 Bí o ti wù kí ó rí, Jesu kò fi àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ mọ sórí ìpọ́njú ti ọ̀rúndún kìn-ín-ní. Bibeli fihàn pé púpọ̀ síi yóò tẹ̀lé ìpọ́njú yẹn, gẹ́gẹ́ bí ìlò toʹte, tàbí “nígbà náà,” ní Matteu 24:23 àti Marku 13:21 ti dámọ̀ràn rẹ̀. Kí ni àwọn nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ nínú sáà tí ó tẹ̀lé 70 C.E.? Lẹ́yìn ìpọ́njú tí ó wá sórí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju, àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké púpọ̀ síi yóò farahàn. (Ṣèfiwéra Marku 13:6 pẹ̀lú 13:21-23.) Ọ̀rọ̀-ìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irú àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ti dìde la àwọn ọ̀rúndún já láti ìgbà ìparun Jerusalemu ní 70 C.E., bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tíì ṣi àwọn ènìyàn tí agbára ìríran tẹ̀mí wọn ṣe ṣámúṣámú tí wọ́n ti ń wọ̀nà fún “wíwàníhìn-ín” Kristi lọ́nà. (Matteu 24:27, 28) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ síí farahàn lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá 70 C.E. wọ̀nyí parapọ̀ fi ohun kan hàn pé Jesu ń wò rékọjá ìpọ́njú yẹn, tí ó jẹ́ kìkì ìmúṣẹ́ àkọ́kọ́ lásán.
16. Apá-ìhà wo ni Luku 21:24 fikún àsọtẹ́lẹ̀ Jesu, ìjẹ́pàtàkì wo sì ni èyí ní?
16 Bí a bá ṣe ìfiwéra Matteu 24:15-28 àti Marku 13:14-23 pẹ̀lú Luku 21:20-24, a óò rí ohun kejì tí ó fihàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Jesu gbòòrò rékọjá ìparun Jerusalemu. Rántí pé Luku nìkanṣoṣo ni ó mẹ́nukan àjàkálẹ̀-àrùn. Bákàn náà, òun nìkanṣoṣo ni ó mú ẹ̀ka-ìpín yìí wá sí ìparí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu náà pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerusalemu mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè [“àkókò àwọn Keferi,” King James Version] yóò fi pé.”e (Luku 21:24, NW) Àwọn ará Babiloni mú ọba àwọn Ju tí ó jẹ kẹ́yìn kúrò ní 607 B.C.E., lẹ́yìn èyíinì, Jerusalemu, tí ó dúró fún Ìjọba Ọlọrun, ni a tẹ̀ mọ́lẹ̀. (2 Awọn Ọba 25:1-26; 1 Kronika 29:23; Esekieli 21:25-27) Ní Luku 21:24, Jesu fihàn pé ipò-ọ̀ràn náà yóò máa báa lọ wọnú ọjọ́-ọ̀la títí di ìgbà tí àkókò náà bá tó fún Ọlọrun láti tún Ìjọba kan gbé kalẹ̀.
17. Kí ni ohun kẹta tí ó fihàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Jesu yóò rìn jìnnà wọnú ọjọ́-ọ̀la jíjìnnà-réré?
17 Èyí sì ni ohun kẹta tí ó fihàn pé Jesu tún ń tọ́ka sí ìmúṣẹ ọjọ́ iwájú jíjìnnà-réré kan: Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, Messia níláti kú ki a sì jí i díde, lẹ́yìn èyí tí yóò jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun títí tí Baba yóò fi rán an jáde láti lọ bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹ́gun. (Orin Dafidi 110:1, 2) Jesu sọ̀rọ̀ nípa jíjókòó òun ní ọwọ́ ọ̀tún Baba òun. (Marku 14:62) Aposteli Paulu fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jesu tí a jí dìde náà wà ní ọwọ́ ọ̀tún Jehofa ní dídúró de àkókò náà tí yóò di Ọba àti Amúdàájọ́ṣẹ ti Ọlọrun.—Romu 8:34; Kolosse 3:1; Heberu 10:12, 13.
18, 19. Ìsopọ̀ wo ni Ìfihàn 6:2-8 ní pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tí ó bá a dọ́gba nínú àwọn Ìhìnrere?
18 Fún ohun kẹrin àti èyí tí ó fòpin sí iyèméjì èyíkéyìí tí ó fihàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Jesu nípa ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ní ìfisílò tí ó rékọjá ti ọ̀rúndún kìn-ín-ní, a lé yíjúsí Ìfihàn orí 6. Ní kíkọ̀wé ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lẹ́yìn 70 C.E., aposteli Johannu ṣàpèjúwe ìran agbàfíyèsí kan nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin agbékánkánṣiṣẹ́. (Ìfihàn 6:2-8) Ìran alásọtẹ́lẹ̀ yìí nípa “ọjọ́ Oluwa”—ọjọ́ wíwàníhìn-ín rẹ̀—fi ọ̀rúndún ogún wa hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí àkókò ogun àjàkú-akátá (ẹsẹ 4), àìtó oúnjẹ tí ó gbòde (ẹsẹ 5 àti 6), àti “ìyọnu-àjàkálẹ̀ tí ń ṣekúpani” (ẹsẹ 8). Ní kedere, èyí báradọ́gba pẹ̀lú ohun tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ nínú àwọn Ìhìnrere ó sì fi ẹ̀rí hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní ìmúṣẹ tí ó tóbi síi ní “ọjọ́ Oluwa” yìí.—Ìfihàn 1:10.
19 Àwọn amòye ènìyàn gbà pé àmì alápá púpọ̀ náà tí a sọtẹ́lẹ̀ ní Matteu 24:7-14 àti Ìfihàn 6:2-8 ti ń farahàn láti ìgbà tí ogun àgbáyé tí kọ́kọ́ bẹ́ sílẹ̀ ní 1914. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti kéde kárí-ayé pé àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ti ń ní ìmúṣẹ rẹ̀ kejì àti èyí tí ó tóbi jù nísinsìnyí, gẹ́gẹ́ bí àwọn ogun rírorò, ìsẹ̀lẹ̀ tí ń panirun, ìyàn runlé-rùnnà, àti àrùn tí ó gbòdekan ti jẹ́rìí sí i. Lórí kókó tí ó gbẹ̀yìn yìí, ìwé-ìròyìn U.S.News & World Report (July 27, 1992) wí pé: “Àjàkálẹ̀ àrùn AIDS . . . ń pa ọ̀pọ̀ million àwọn òjìyà ìpalára rẹ̀ ó sì lè di ìyọnu àjàkálẹ̀ aṣenilófò àti alájàálù jùlọ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn láìpẹ́. Àjàkálẹ̀ Àrùn Gbẹ̀mígbẹ̀mí pa nǹkan bí àádọ́ta-ọ̀kẹ́ 25 ọkàn tí ń jìyà ní ọ̀rúndún kẹrìnlá. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá fi máa di ọdún 2000, àádọ́ta-ọ̀kẹ́ lọ́nà 30 sí àádọ́ta-ọ̀kẹ́ lọ́nà 110 ènìyàn ni yóò ti ní HIV lára, kòkòrò fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn AIDS, ìgasókè láti orí iye tí ó tó àádọ́ta-ọ̀kẹ́ 12 lónìí. Bí wọn kò bá rí ìwòsàn, gbogbo wọn dojúkọ ikú tí kò ṣeéyẹ̀sílẹ̀.”
20. Kí ni ìmúṣẹ àkọ́kọ́ Matteu 24:4-22 yóò kárí, ṣùgbọ́n àwọn ìmúṣẹ mìíràn wo ni ó ṣe kedere?
20 Nígbà náà, kí ni a níláti parí èrò sí nípa bí Jesu ṣe dáhùn ìwádìí àwọn aposteli? Lọ́nà pípéye, àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sọ ṣáájú nípa àwọn nǹkan tí yóò jálẹ̀ sí tí yóò sì ní ìparun Jerusalemu nínú, ó sì mẹ́nukan àwọn ohun tí yóò tẹ̀lé 70 C.E. Ṣùgbọ́n èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú èyí ni yóò ní ìmúṣẹ kejì àti èyí tí ó tóbi jù ní ọjọ́-ìwájú, ní jíjálẹ̀ sí ìpọ́njú ńlá kan tí yóò fòpin sí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí. Èyí túmọ̀sí pé ìsọtẹ́lẹ̀ Jesu ní Matteu 24:4-22, àti àwọn tí ó bá a dọ́gba ní Marku àti Luku, ni ìmúṣẹ wọn bẹ̀rẹ̀ láti 33 C.E. títí di ìgbà ìpọ́njú 70 C.E. Síbẹ̀, àwọn ẹsẹ kan-náà yẹn yóò ní ìmúṣẹ kejì, tí yóò ní ìpọ́njú títóbi jù kan nínú ní ọjọ́-iwájú. Ìmúṣẹ títóbi jù yìí ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa; lójoojúmọ́ ni a ń rí i.f
Ní Jíjálẹ̀ sí Kí Ni?
21, 22. Níbo ni a ti rí àwọn ìtọ́kasí alásọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ohun mìíràn síi yóò ṣẹlẹ̀ ní àfikún?
21 Jesu kò fi mímẹ́nuba àwọn wòlíì èké tí ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tí ń tannijẹ ní sáà-àkókò gígùn náà ṣáájú kí ‘àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè tó ní ìmúṣẹ’ parí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. (Luku 21:24; Matteu 24:23-26; Marku 13:21-23) Ó tẹ̀síwájú láti sọ nípa àwọn ohun tí ń múnitagìrì mìíràn tí yóò wáyé, àwọn ohun tí a óò kíyèsí jákèjádò ayé. Ìwọ̀nyí yóò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú dídé Ọmọkùnrin ènìyàn nínú agbára àti ògo. Marku 13:24-27 (NW) jẹ́ àpẹẹrẹ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ń báa lọ náà:
22 “Ṣùgbọ́n ní àwọn ọjọ́ wọnnì, lẹ́yìn ìpọ́njú yẹn, oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì máa jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run ni a óò sì mì. Nígbà náà ni wọn yóò sì rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. Nígbà náà ni òun yóò sì rán àwọn angẹli jáde yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ilẹ̀-ayé títí dé ìkángun ọ̀run.”
23. Èéṣe tí a fi lè wọ̀nà fún ìmúṣẹ Matteu 24:29-31 ní ọjọ́ iwájú jíjìnnà lẹ́yìn ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E.?
23 Ọmọkùnrin ènìyàn, Jesu Kristi tí a ti jí dìde, kò wá ní irú ọ̀nà apàfiyèsí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn òpin tí ó mú ìparun débá ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju ní 70 C.E. Dájúdájú gbogbo ẹ̀yà ayé kò mọ̀ ọ́n, gẹ́gẹ́ bí Matteu 24:30 ti sọ, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn angẹli ọ̀run kò kó gbogbo àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró jọpọ̀ láti gbogbo apá ilẹ̀-ayé nígbà náà. Nítorí náà nígbà wo ni apá tí ó jẹ́ àfikún àsọtẹ́lẹ̀ kíkàmàmà Jesu yìí yóò ní ìmúṣẹ? Ó ha ń ní ìmúṣẹ nínú àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká wa nísinsìnyí, tàbí kẹ̀, ó ha ń fúnni ní ìjìnlẹ̀-òye àtọ̀runwá nípa ohun tí a lè retí ní ọjọ́-ọ̀la tí kò jìnnà mọ́? Dájúdájú àwa yóò fẹ́ láti mọ̀, nítorí pé Luku ṣàkọsílẹ̀ ìṣílétí Jesu pé: “Nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”—Luku 21:28.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn apákan ìpín orí wọ̀nyí ni a lè rí nínú ṣáàtì ní ojú-ìwé 14 àti 15; àwọn ìlà gígùn tótòtó sàmì sí àwọn ẹ̀ka ìpín tí ó báradọ́gba.
b Fún àwọn ọ̀rọ̀-ìtàn tí a fàyọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, wo Ilé-Ìṣọ́nà ti December 15, 1970, ojú-ìwé 744 sí 746.
c Toʹte farahàn ní ìgbà tí ó ju 80 lọ ní Matteu (ìgbà 9 ní orí 24) àti ìgbà 15 nínú ìwé Luku. Marku lo toʹte ní ìgbà mẹ́fà péré, ṣùgbọ́n mẹ́rin nínú ìwọ̀nyẹn wémọ́ “àmì náà.”
d Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Matthew Henry ṣàlàyé pé: “Ìparun Jerusalemu láti ọwọ́ àwọn ara Kaldea banilẹ́rù gan-an, ṣùgbọ́n èyí rékọjá rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìparẹ́ ráúráú gbogbo àwọn . . . Ju.”
e Ọ̀pọ̀ rí ìyípadà nínú ìtẹnumọ́ nínú àkọsílẹ̀ Luku lẹ́yìn Luku 21:24. Dókítà Leon Morris sọ pé: “Jesu ń báa lọ láti sọ̀rọ̀ nípa àkókò àwọn Keferi. . . . Gẹ́gẹ́ bí èrò ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, àfiyèsí ti yí sórí ìpadàbọ̀ Ọmọkùnrin ènìyàn báyìí.” Ọ̀jọ̀gbọ́n R. Ginns kọ̀wé pé: “Ìpadàbọ̀ Ọmọkùnrin Ènìyàn—(Mt 24:29-31; Mk 13:24-27). Mímẹ́nukan ‘àkókò àwọn Keferi’ pèsè ìnasẹ̀-ọ̀rọ̀ fún ẹṣin-ọ̀rọ̀ yìí; ojú-ìwòye [ti Luku] nísinsìnyí ni a mú ríran rékọjá ìparun Jerusalemu wọnú ọjọ́-ọ̀la.”
f Ọ̀jọ̀gbọ́n Walter L. Liefeld kọ̀wé pé: “Ó ṣeéṣe nítòótọ́ láti tànmọ́ọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ní àwọn ìpele ìdàgbàsókè méjì nínú: (1) àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ A.D. 70 tí wọ́n wémọ́ tẹmpili náà àti (2) àwọn wọnnì tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú jíjìnnà-réré, tí a fi ọ̀rọ̀ tí ó túbọ̀ jẹ́ ti ìṣípayá ṣàpèjúwe.” Àlàyé-ọ̀rọ̀ tí J. R. Dummelow jẹ́ olùyẹ̀wòṣàtúnṣe fún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìṣòro lílekoko inú ọ̀rọ̀-àwíyé ńlá yìí pòórá nígbà tí ó di mímọ̀ pé Oluwa wa kò tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ kanṣoṣo nínú rẹ̀ bíkòṣe méjì, àti pé èyí àkọ́kọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ-òjìji fún èyí èkejì. . . . Ní pàtàkì [Luku] 21:24, tí ó sọ̀rọ̀ nípa ‘àkókò àwọn Keferi,’ . . . pààlà àkókò kan tí kò ṣe pàtó sáàárín ìṣubú Jerusalemu àti òpin ayé.”
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Ìmúṣẹ wo tí ó nasẹ̀ dé 70 C.E. ni ìdáhùn Jesu sí ìbéèrè tí ó wà ní Matteu 24:3 ní?
◻ Báwo ni ìlò ọ̀rọ̀ náà toʹte ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àsọtẹ́lẹ̀ Jesu?
◻ Ní èrò-ìtumọ̀ wo ni “ìpọ́njú ńlá” tí irú rẹ̀ kò tíì wáyé rí fi wà ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní?
◻ Àwọn apá-ìhà aláìlẹ́gbẹ́ méjì wo nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jesu tí ó kàn wá lónìí ni Luku tọ́kasí?
◻ Àwọn ohun wo ní wọ́n tọ́ka sí ìmúṣẹ kejì àti èyí tí ó tóbi jùlọ ti àsọtẹ́lẹ̀ inú Matteu 24:4-22?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 14, 15]
MATTEU 24 (NW)
4 “Jesu wí fún wọn pé: ‘Ẹ ṣọ́ra kí ẹni kankan má ṣì yín lọ́nà; 5 nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá lórí ìpìlẹ̀ orúkọ mi, wí pé, “Èmi ni Kristi,” wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. 6 Ẹ̀yin yóò gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun; ẹ rí i pé ẹ̀yin kò jáyà. Nítorí nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kìí ṣe ìsinsìnyí.
7 “ ‘Nítorí orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibìkan dé ibòmíràn. 8 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó ìdààmú.
9 “ ‘Nígbà náà ni àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́ wọn yóò sì pa yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nítìtorí orúkọ mi. 10 Nígbà náà, pẹ̀lú, a óò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀ wọn yóò sì da ara wọn lẹ́nìkínní kejì wọn yóò sì kórìíra ara wọn lẹ́nìkínní kejì. 11 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké yóò sì dìde wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà; 12 àti nítorí pípọ̀ síi ìwà-àìlófin ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jùlọ yóò di tútù. 13 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá faradà á dé òpin ni ẹni tí a óò gbàlà. 14 A ó sì wàásù ìhìnrere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.
------------------------------------------------------------------
15 “‘Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá tajúkán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ láti ẹnu wòlíì Danieli, (kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀,) 16 nígbà náà ni kí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní Judea bẹ̀rẹ̀ síí sá lọ sí àwọn òkè-ńlá. 17 Kí ọkùnrin tí ń bẹ ní orí ilé máṣe sọ̀kalẹ̀ láti kó àwọn ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀; 18 kí ọkùnrin tí ó wà ní pápá má sì ṣe padà sí ilé láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. 19 Ègbé ni fún àwọn obìnrin aboyún àti àwọn wọnnì tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ní ọjọ́ wọnnì! 20 Ẹ máa gbàdúrà kí sísá yín maṣe ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù, tàbí ní ọjọ́ ìsinmi; 21 nítorí nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà irúfẹ́ èyí tí kò tíì wáyé rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún wáyé mọ́. 22 Níti tòótọ́, bíkòṣe pé a ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran-ara kankan tí à bá gbàlà; ṣùgbọ́n nítìtorí àwọn àyànfẹ́ a óò ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú.
------------------------------------------------------------------
23 “‘Nígbà náà bí ẹnikẹ́ni bá wí fún yín pé, “Ẹ wò ó! Kristi nìyí níhìn-ín,” tàbí, “Lọ́hùn-ún!” ẹ máṣe gbà èyí gbọ́. 24 Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde wọn yóò sì fúnni ní àwọn àmì ńláǹlà àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà, bí ó bá ṣeéṣe. 25 Ẹ wò ó! Mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀. 26 Nítorí náà, bí àwọn ènìyàn bá wí fún yín pé, “Ẹ wò ó! Ó wà ní aginjù,” ẹ máṣe jáde lọ; “Ẹ wò ó! Ó wà ní àwọn iyẹ̀wù inú lọ́hùn-ún,” ẹ máṣe gbà á gbọ́. 27 Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí mànàmáná ti ń jáde wá láti àwọn apá ìlà-oòrùn tí ó sì ń mọ́lẹ̀ dé àwọn apá ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yóò rí. 28 Ibi yòówù tí òkú bá wà, níbẹ ni àwọn idì yóò kójọpọ̀ sí.
------------------------------------------------------------------
------------------------------------------------------------------
29 “‘Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú náà ti àwọn ọjọ́ wọnnì oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára ọ̀run ni a óò sì mì. 30 Nígbà náà sì ni àmì Ọmọkùnrin ènìyàn yóò farahàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀-ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 31 Òun yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde lọ pẹ̀lú ìró ńlá kàkàkí, wọn yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun kan àwọn ọ̀run sí ìkángun wọn kejì.’ ”
MARKU 13 (NW)
5 “Nítorí náà Jesu bẹ̀rẹ̀ síí wí fún wọn pé: ‘Ẹ ṣọ́ra kí ẹni kankan má ṣì yín lọ́nà. 6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá lórí ìpìlẹ̀ orúkọ mi, wí pé, “Èmi ní ẹni náà,” wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. 7 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun, ẹ máṣe jáyà; nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kìí ṣe ìsinsìnyí.
8 “‘Nítorí orílẹ̀-èdè yóò dìde lòdìsí orílẹ̀-èdè àti ìjọba lòdìsí ìjọba, ìsẹ̀lẹ̀ yóò wà láti ibìkan dé ibòmíràn, àìtó oúnjẹ yóò wà. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó ìdààmú.
9 “‘Ní tiyín, ẹ máa ṣọ́ra yín; àwọn ènìyàn yóò fà yín lé àwọn ilé-ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́, wọn yóò sì lù yín nínú àwọn sinagọgu a óò sì mú yín dúró níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn. 10 Pẹ̀lúpẹ̀lù, a níláti kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. 11 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń mú yín lọ láti fà yín léni lọ́wọ́, ẹ máṣe ṣàníyàn ṣáájú nípa ohun tí ẹ óò sọ; ṣùgbọ́n ohun yòówù tí a bá fifún yín ní wákàtí yẹn, ẹ sọ èyí, nítorí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ ni. 12 Síwájú sí i, arákùnrin yóò fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, baba yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọmọ, àwọn ọmọ yóò sì dìde lòdìsí àwọn òbí wọn yóò si ṣe ikú pa wọ́n; 13 ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítìtorí orúkọ mi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá faradà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbàlà.
------------------------------------------------------------------
14 “‘Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ẹ̀ bá tajúkán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro tí ó dúró níbi tí kò yẹ (kí òǹkáwé lo ìfòyemọ̀), nígbà náà kí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní Judea bẹ̀rẹ̀ síí sálọ sí àwọn òkè-ńlá. 15 Kí ọkùnrin tí ó wà ní orí ilé máṣe sọ̀kalẹ̀, tàbí wọlé lọ mú ohunkóhun jáde kùró nínú ilé rẹ̀; 16 kí ọkùnrin tí ó wà ní pápá má sì ṣe padà sí àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. 17 Ègbé ni fún àwọn obìnrin aboyún àti àwọn wọnnì tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ní ọjọ́ wọnnì! 18 Ẹ máa gbàdúrà kí ó má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù; 19 nítorí ọjọ́ wọnnì yóò jẹ́ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú kan irúfẹ́ èyí tí kò ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọrun dá títí di àkókò yẹn, kì yóò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́. 20 Níti tòótọ́, bíkòṣe pé Jehofa ti ké àwọn ọjọ́ náà kúrú, kò sí ẹran-ara kankan tí à bá gbàlà. Ṣùgbọ́n nítìtorí àwọn àyànfẹ́ tí òun ti yàn ó ti ké àwọn ọjọ́ náà kúrú.
------------------------------------------------------------------
21 “‘Nígbà náà, pẹ̀lú, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún yín pé, “Ẹ wò ó! Kristi nìyí níhìn-ín,” “Ẹ wò ó! Òun nìyẹn lọ́hùn-ún,” ẹ máṣe gbà èyí gbọ́. 22 Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde wọn yóò sì fúnni ní àwọn àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu láti mú àwọn àyànfẹ́ ṣáko lọ, bí ó bá ṣeéṣe. 23 Nígbà náà, ẹ ṣọ́ra; mo ti sọ ohun gbogbo fún yín tẹ́lẹ̀.
------------------------------------------------------------------
------------------------------------------------------------------
24 “‘Ṣùgbọ́n ní àwọn ọjọ́ wọnnì, lẹ́yìn ìpọ́njú yẹn, oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, 25 àwọn ìràwọ̀ yóò sì máa jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run ni a óò sì mì. 26 Nígbà náà ni wọn yóò sì rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ nínú àwọn àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 27 Nígbà náà ni òun yóò sì rán àwọn angẹli jáde yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ilẹ̀-ayé títí dé ìkángun ọ̀run.’ ”
LUKU 21 (NW)
8 “Ó wí pé: ‘Ẹ ṣọ́ra kí a má baá ṣì yín lọ́nà; nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá lórí ìpìlẹ̀ orúkọ mi, wí pé, “Èmi ni ẹni náà,” àti pé, “Àkókò yíyẹ ti súnmọ́lé.” Ẹ máṣe tẹ̀lé wọn. 9 Síwájú sí i, nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa awọn ogun àti rúdurùdu, ẹ máṣe jáyà. Nítorí nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì yóò wáyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.’
10 “Nígbà náà ni ó tẹ̀síwájú láti wí fún wọn pé: ‘Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; 11 àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti láti ibi kan sí ibòmíràn àwọn àjàkálẹ̀-àrùn àti àìtó oúnjẹ; àwọn ohun ìran akúnfúnbẹ̀rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run wá.
12 “‘Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí àwọn ènìyàn yóò gbé ọwọ́ wọn lé yín wọn yóò sì ṣe inúnibíni sí yín, ní fífà yín lé àwọn sinagọgu àti ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, ní fífipá fà yín lọ sí iwájú àwọn ọba àti gómìnà nítorí orúkọ mi. 13 Yóò jásí ẹ̀rí fún yín. 14 Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ nínú ọkàn-àyà yín láti máṣe fi bí ẹ óò ṣe gbèjà ara yín ṣe ìfidánrawò ṣáájú, 15 nítorí èmi yóò fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, èyí tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ kò ní lè dúró tiiri lòdìsí tàbí bá ṣe awuyewuye. 16 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àní a ó fà yín léni lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn òbí àti àwọn arákùnrin àti àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá, wọn yóò si pa àwọn díẹ̀ nínú yín; 17 ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi. 18 Síbẹ̀ kò sì sí ọ̀kan nínú irun orí yín tí yóò ṣègbé lọ́nàkọnà. 19 Nípa ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ̀yin yóò fi jèrè ọkàn yín.
------------------------------------------------------------------
20 “‘Síwájú síi, nígbà tí ẹ̀yin bá rí Jerusalemu tí àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n tẹ̀dó yí i ká, nígbà náà kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti súnmọ́lé. 21 Nígbà náà kí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní Judea bẹ̀rẹ̀ síí sá lọ sí àwọn òkè-ńlá, kí àwọn wọnnì tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fà sẹ́yìn, kí àwọn wọnnì tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko máṣe wọ inú rẹ̀; 22 nítorí ìwọ̀nyí ni àwọn ọjọ́ fún wíwọn ìdájọ́-òdodo fúnni, kí gbogbo àwọn ohun tí a ti kọ lè ní ìmúṣẹ. 23 Ègbé ni fún àwọn obìnrin aboyún àti àwọn tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ní ọjọ́ wọnnì! Nítorí àìgbọ́dọ̀máṣe ńlá yóò wà lórí ilẹ̀ náà àti ìbínú-ńlá lórí àwọn ènìyàn yìí; 24 wọn yóò sì ti ojú idà ṣubú a ó sì kó wọn lọ ní òǹdè sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;
------------------------------------------------------------------
àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerusalemu mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi pé.
------------------------------------------------------------------
------------------------------------------------------------------
25 “ ‘Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn àmì yóò wà nínú oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, àti lórí ilẹ̀-ayé làásìgbò àwọn orílẹ̀-èdè, láìmọ ọ̀nà àbájáde nítorí híhó òkun àti ìrugùdù rẹ̀, 26 nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa dákú láti inú ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀-ayé tí a ń gbé; nítorí àwọn agbára àwọn ọ̀run ni a óò mì. 27 Nígbà náà ni wọn yóò sì rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 28 Ṣùgbọ́n bí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nàró ṣánṣán kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń súnmọ́lé.’ ”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìpọ́njú 70 C.E. ni èyí tí ó tóbi jùlọ tí Jerusalemu àti ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju tíì ní ìrírí rẹ̀ rí